ORÍ 7
Agbára Ààbò—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”
1, 2. Inú ewu wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà bí wọ́n ṣe ń wọ agbègbè ilẹ̀ Sínáì lọ́dún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, báwo ni Jèhófà sì ṣe fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?
INÚ ewu làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà bí wọ́n ṣe ń wọ agbègbè ilẹ̀ Sínáì níbẹ̀rẹ̀ ọdún 1513 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ìrìn àjò náà ò lè rọrùn rárá, torí wọ́n ní láti gba inú “aginjù tí ó tóbi tó sì ń bani lẹ́rù, tó ní àwọn ejò olóró àti àwọn àkekèé.” (Diutarónómì 8:15) Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lójú ọ̀nà tún kórìíra wọn, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n gbéjà kò wọ́n. Jèhófà Ọlọ́run wọn ló ní kí wọ́n rin ìrìn àjò yẹn. Ṣé ó máa lè dáàbò bò wọ́n?
2 Ọ̀rọ̀ Jèhófà fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ gan-an, ó ní: “Ẹ ti fojú ara yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Íjíbítì, kí n lè fi àwọn ìyẹ́ idì gbé yín wá sọ́dọ̀ ara mi.” (Ẹ́kísódù 19:4) Jèhófà sọ pé òun gbé wọn bíi ti ẹyẹ idì kó lè rán wọn létí pé òun lòun gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, tóun sì gbé wọn dé ibi ààbò. Àmọ́, àwọn ìdí míì tún wà tó fi bá a mu bí Jèhófà ṣe fi “ìyẹ́ idì” ṣàpèjúwe bóun ṣe ń dáàbò boni.
3. Kí nìdí tí Jèhófà fi fi “ìyẹ́ idì” ṣàpèjúwe bóun ṣe ń dáàbò boni?
3 Ẹyẹ idì máa ń fi ìyẹ́ rẹ̀ fò, ó sì máa ń fi ṣe àwọn nǹkan míì. Téèyàn bá wọn ìyẹ́ apá ẹyẹ idì láti apá kan sí ìkejì, ó máa ń gùn tó èèyàn tó ga dáadáa. Nígbà tí oòrùn bá mú gan-an, abo idì máa na ìyẹ́ apá ẹ̀ láti fi ṣíji bo àwọn ọmọ ẹ̀ kéékèèké kúrò lọ́wọ́ oòrùn tó gbóná gan-an. Ó tún máa ń fi ìyẹ́ apá ẹ̀ bo àwọn ọmọ ẹ̀ nígbà òtútù, kí ara wọn lè móoru. Bí ẹyẹ idì ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnyẹ̀ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di orílẹ̀-èdè. Ní báyìí tí wọ́n ti wà nínú aginjù, Jèhófà á ṣì máa dáàbò bò wọ́n bíi pé wọ́n wà lábẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ, ìyẹn tí wọ́n bá ń bá a lọ láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Diutarónómì 32:9-11; Sáàmù 36:7) Ṣé àwa náà lè retí pé kí Ọlọ́run dáàbò bò wá?
Jèhófà Ṣèlérí Pé Òun Máa Dáàbò Bo Àwọn Ìránṣẹ́ Òun
4, 5. Kí nìdí tá a fi lè gbọ́kàn lé ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun máa dáàbò bò wá?
4 Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bíbélì pè é ní “Ọlọ́run Olódùmarè,” orúkọ yìí sì fi hàn pé kò sẹ́ni tó lè dí i lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó bá ní lọ́kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 17:1) Agbára Jèhófà ò láàlà, kò sì sóhun tó lè dá a dúró. Ní báyìí tá a ti mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti ṣe ohunkóhun tó bá wù ú, a lè béèrè pé, ‘Ṣé ó wu Jèhófà láti fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?’
5 Bẹ́ẹ̀ ni! Jèhófà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé òun máa dáàbò bo àwọn èèyàn òun. Sáàmù 46:1 sọ pé: “Ọlọ́run ni ibi ààbò wa àti okun wa, ìrànlọ́wọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní àkókò wàhálà.” Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ‘ò lè parọ́,’ torí náà a lè gbọ́kàn lé ìlérí tó ṣe pé òun máa dáàbò bò wá. (Títù 1:2) Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn àpèjúwe tí Jèhófà lò láti jẹ́ ká mọ bó ṣe ń lo agbára rẹ̀ láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀.
6, 7. (a) Kí làwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń ṣe láti dáàbò bo àwọn àgùntàn wọn láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe Jèhófà kó lè túbọ̀ dá wa lójú pé ó wù ú kó dáàbò bò wá?
6 Jèhófà fi ara ẹ̀ wé Olùṣọ́ Àgùntàn, ó sì pè wá ní “èèyàn rẹ̀ àti àgùntàn ibi ìjẹko rẹ̀.” (Sáàmù 23:1; 100:3) Àwọn àgùntàn ò lè dáàbò bo ara wọn rárá. Torí náà, láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní láti jẹ́ onígboyà kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn àgùntàn wọn lọ́wọ́ kìnnìún, ìkookò, béárì àtàwọn olè. (1 Sámúẹ́lì 17:34, 35; Jòhánù 10:12, 13) Àmọ́, àwọn ìgbà míì wà tó máa gba pé kí olùṣọ́ àgùntàn ṣe àwọn àgùntàn jẹ́jẹ́ kó lè dáàbò bò wọ́n. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan kì í sábà rọrùn fún àgùntàn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, ní pàtàkì tí ibi tó bímọ sí bá jìnnà síbi táwọn tó kù wà. Nírú àsìkò yìí, olùṣọ́ àgùntàn tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ á rọra máa bójú tó àgùntàn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ náà, á sì gbé ọmọ ẹ̀ lọ síbi táwọn tó kù wà.
7 Nígbà tí Jèhófà fi ara ẹ̀ wé olùṣọ́ àgùntàn, ńṣe ló fẹ́ ká mọ̀ dájú pé ó wu òun pé kóun dáàbò wá. (Ìsíkíẹ́lì 34:11-16) Ṣé o rántí ohun tí Àìsáyà 40:11 sọ nípa Jèhófà bá a ṣe jíròrò ẹ̀ ní Orí 2 ìwé yìí? Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Ó máa bójú tó agbo ẹran rẹ̀ bíi ti olùṣọ́ àgùntàn. Ó máa fi apá rẹ̀ kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ, ó sì máa gbé wọn sí àyà rẹ̀.” Báwo ni ọ̀dọ́ àgùntàn yẹn ṣe dé “àyà” olùṣọ́ àgùntàn náà, tó sì fi aṣọ ẹ̀ wé e? Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe ni àgùntàn yẹn lọ sọ́dọ̀ olùṣọ́ àgùntàn náà, bóyá kó tiẹ̀ máa forí nù ún lẹ́sẹ̀. Àmọ́, ó dájú pé olùṣọ́ àgùntàn yẹn fúnra ẹ̀ ló máa bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, táá sì gbé ọ̀dọ́ àgùntàn náà sí àyà rẹ̀ kó lè dáàbò bò ó. Àpèjúwe yìí jẹ́ ká rí i pé ó wu Jèhófà tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn wa láti bójú tó wa, kó sì dáàbò bò wá. Ìyẹn mà fini lọ́kàn balẹ̀ o!
8. (a) Àwọn wo ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò, báwo ni Òwe 18:10 sì ṣe fi èyí hàn? (b) Kí ló túmọ̀ sí láti fi orúkọ Ọlọ́run ṣe ààbò?
8 Àmọ́ o, àwọn tó bá sún mọ́ Jèhófà nìkan ni Jèhófà ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò. Òwe 18:10 sọ pé: “Orúkọ Jèhófà jẹ́ ilé gogoro tó lágbára. Olódodo sá wọ inú rẹ̀, ó sì rí ààbò.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, wọ́n sábà máa ń kọ́ ilé gogoro sínú aginjù káwọn èèyàn lè wá ààbò lọ síbẹ̀. Tí ẹni tó wà nínú ewu bá fẹ́ rí ààbò, ó ní láti sá lọ sínú ilé gogoro náà. Bọ́rọ̀ ṣe rí pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run nìyẹn, a lè fi ṣe ààbò. Àmọ́, ìyẹn kọjá pé ká kàn máa pe orúkọ náà léraléra, torí kì í ṣe oògùn ajẹ́bíidán. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ní láti mọ ẹni tó ń jẹ́ orúkọ náà, ká gbẹ́kẹ̀ lé e, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Inú rere Jèhófà mà pọ̀ o, ó fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tá a bá nígbàgbọ́ tó lágbára, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé òun, òun máa di ilé gogoro tó lágbára fún wa, òun á sì dáàbò bò wá!
“Ọlọ́run Wa . . . Lè Gbà Wá Sílẹ̀”
9. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀?
9 Jèhófà ṣe ju kó kàn ṣèlérí pé òun máa dáàbò bo àwọn èèyàn òun. Nínú Bíbélì, a rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí tó fi hàn pé ó máa ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà ìyanu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà fi “ọwọ́” agbára ńlá rẹ̀ gba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tó lágbára jù wọ́n lọ. (Ẹ́kísódù 7:4) Àmọ́, Jèhófà tún máa ń lo agbára rẹ̀ láti fi dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.
10, 11. Àwọn àpẹẹrẹ inú Bíbélì wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan?
10 Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta náà, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò. Nígbà tí wọ́n kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì ṣe, inú bí ọba náà, ó sì halẹ̀ mọ́ wọn pé òun máa jù wọ́n sínú iná ìléru tó gbóná gan-an. Nebukadinésárì ni ọba tó lágbára jù lọ láyé ìgbà yẹn, torí náà ó pẹ̀gàn Jèhófà, ó ní: “Ta . . . ni ọlọ́run tó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ mi?” (Dáníẹ́lì 3:15) Àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà mọ̀ pé alágbára ni Ọlọ́run wọn, ó sì dá wọn lójú pé ó lè dáàbò bò wọ́n, àmọ́ wọn ò sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀. Torí náà, wọ́n sọ pé: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ọba, Ọlọ́run wa tí à ń sìn lè gbà wá sílẹ̀.” (Dáníẹ́lì 3:17) Lẹ́yìn ìyẹn, ọba ní kí wọ́n mú kí iná ìléru náà gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, àmọ́ ìyẹn ò tó nǹkan kan rárá lójú Ọlọ́run wọn, torí pé agbára rẹ̀ ò ní ààlà. Ọlọ́run dáàbò bo àwọn ọ̀dọ́kùnrin yẹn, ìyẹn sì ya ọba náà lẹ́nu débi tó fi sọ pé: “Kò sí ọlọ́run míì tó lè gbani là bí èyí.”—Dáníẹ́lì 3:29.
11 Jèhófà tún fi hàn pé òun lágbára láti dáàbò boni nígbà tó fi ẹ̀mí Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo sínú ilé ọlẹ̀ wúńdíá Júù kan tó ń jẹ́ Màríà. Áńgẹ́lì kan sọ fún Màríà pé: “O máa lóyún, o sì máa bí ọmọkùnrin kan.” Áńgẹ́lì náà ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí mímọ́ máa bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ sì máa ṣíji bò ọ́.” (Lúùkù 1:31, 35) Ó dájú pé ẹ̀mí Ọmọ Ọlọ́run wà nínú ewu lásìkò yẹn. Ṣé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tí Màríà ti jogún ò ní kó àbààwọ́n bá a nígbà tó wà nínú ilé ọlẹ̀ náà? Ṣé Sátánì ò ní ṣe ọmọ náà ní jàǹbá tàbí kó tiẹ̀ pa á kí wọ́n tó bí i? Rárá o! Jèhófà dáàbò bo ọmọ náà ní gbogbo ìgbà tó fi wà nínú ikùn ìyá rẹ̀. Kò jẹ́ kí ohunkóhun tàbí ẹnikẹ́ni ṣèpalára fún un, ì báà jẹ́ àìpé, àwọn ẹ̀mí èṣù tàbí àwọn tó gbìyànjú láti pa á. Jèhófà tún ń bá a lọ láti dúró ti Jésù bó ṣe ń dàgbà. (Mátíù 2:1-15) Ọlọ́run ń bá a lọ láti dáàbò bo Jésù látìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ títí dìgbà tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ.
12. Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì?
12 Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà ìyanu? Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jèhófà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí ìfẹ́ rẹ̀ lè ṣẹ, torí pé ìyẹn lohun tó ṣe pàtàkì jù. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé àwọn ọ̀tá rí Jésù pa nígbà tó wà ní kékeré ni, ìfẹ́ Ọlọ́run pé káwọn èèyàn máa gbé ayé títí láé ò ní ṣẹ. A lè ka ìtàn nípa onírúurú ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú Bíbélì. Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n kọ àwọn ìtàn náà “fún wa láti gba ẹ̀kọ́, kí a lè ní ìrètí nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú látinú Ìwé Mímọ́.” (Róòmù 15:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn àpẹẹrẹ yìí máa ń jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ó sì ń jẹ́ ká fọkàn tán Ọlọ́run wa tí agbára rẹ̀ kò ní ààlà. Àmọ́ o, ṣé bí Ọlọ́run ṣe dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà yẹn náà ló ṣe máa dáàbò bò wá lónìí?
Ṣé Gbogbo Ìgbà Ni Ọlọ́run Máa Ń Dáàbò Bo Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀?
13. Ṣé ó pọn dandan kí Jèhófà máa ṣe iṣẹ́ ìyanu torí tiwa? Ṣàlàyé.
13 Ọlọ́run ṣèlérí pé òun máa dáàbò bò wá lóòótọ́, àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé ó gbọ́dọ̀ dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu. Ọlọ́run ò ṣèlérí pé a ò ní níṣòro kankan nínú ayé yìí. Kódà, ọ̀pọ̀ lára àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà ló ti dojú kọ àwọn ìṣòro tó le gan-an, irú bí àìlówó lọ́wọ́, ogun, àìsàn àti ikú. Jésù dìídì sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n pa àwọn kan lára wọn nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Torí náà, ó tẹnu mọ́ ọn pé ó yẹ kí wọ́n fara dà á dé òpin. (Mátíù 24:9, 13) Tí Jèhófà bá ń dáàbò bò wá lọ́nà ìyanu ní gbogbo ìgbà, Sátánì máa pẹ̀gàn Jèhófà, á sọ pé ohun tá à ń rí gbà lọ́wọ́ Jèhófà ló ń mú ká jọ́sìn rẹ̀ kì í ṣe torí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ látọkànwá.—Jóòbù 1:9, 10.
14. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló fi hàn pé Jèhófà kì í dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà kan náà?
14 Kódà láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, Jèhófà ò dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kí wọ́n má bàa kú ikú òjijì. Bí àpẹẹrẹ, Hẹ́rọ́dù pa àpọ́sítélì Jémíìsì lọ́dún 44 Sànmánì Kristẹni, àmọ́ kò pẹ́ sígbà yẹn ni Ọlọ́run gba Pétérù sílẹ̀ “lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù.” (Ìṣe 12:1-11) Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Jòhánù arákùnrin Jémíìsì pẹ́ láyé ju Pétérù àti Jémíìsì lọ. Ó dájú pé a ò lè retí pé kí Ọlọ́run máa dáàbò bo gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́nà kan náà. Ó ṣe tán, gbogbo wa pátá ni “ìgbà àti èèṣì” ń ṣẹlẹ̀ sí. (Oníwàásù 9:11) Báwo ni Jèhófà ṣe wá ń dáàbò bò wá lónìí?
Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tara
15, 16. (a) Ẹ̀rí wo ló fi hàn pé Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀? (b) Kí nìdí tó fi dá wa lójú pé Jèhófà máa dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ ní báyìí àti nígbà “ìpọ́njú ńlá”?
15 Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá tó sì ń dá ẹ̀mí wa sí. Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lápapọ̀. Rò ó wò ná: Gbogbo ọ̀nà ni Sátánì tó jẹ́ “alákòóso ayé yìí” fi ń wá bó ṣe máa pa àwa ìránṣẹ́ Jèhófà run kó lè fòpin sí ìjọsìn mímọ́. Ká sọ pé Jèhófà ò dáàbò bò wá ni, Sátánì ì bá ti pa wá run. (Jòhánù 12:31; Ìfihàn 12:17) Ọ̀pọ̀ àwọn ìjọba tó lágbára jù lọ láyé ló ti ṣòfin pé a ò gbọ́dọ̀ wàásù, tí wọ́n sì ti gbìyànjú láti pa wá run. Síbẹ̀, àwọn èèyàn Jèhófà jẹ́ adúróṣinṣin sí i, wọ́n sì ń bá a lọ láti máa fìgboyà wàásù! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn Jèhófà kéré, tá ò sì lágbára tó àwọn ìjọba ayé, kí nìdí táwọn ìjọba yẹn ò fi lè fòpin sí iṣẹ́ wa? Ìdí ni pé Jèhófà ń fi ìyẹ́ apá rẹ̀ tó lágbára dáàbò bò wá!—Sáàmù 17:7, 8.
16 Ṣé Jèhófà máa dáàbò bò wá nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ń bọ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Kò sídìí fún wa láti máa bẹ̀rù nígbà tí Ọlọ́run bá mú ìdájọ́ wá sórí àwọn ẹni burúkú. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà mọ bó ṣe ń gba àwọn èèyàn tó ń sìn ín tọkàntọkàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àdánwò, síbẹ̀ ó mọ bó ṣe máa fi àwọn aláìṣòdodo pa mọ́ de ìparun ní ọjọ́ ìdájọ́.” (Ìfihàn 7:14; 2 Pétérù 2:9) Títí dìgbà yẹn, ẹ jẹ́ kí àwọn nǹkan méjì yìí máa fi wá lọ́kàn balẹ̀. Àkọ́kọ́, Jèhófà ò ní gbà kí Sátánì pa gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ run. Ìkejì, Jèhófà máa jẹ́ kí gbogbo àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sí i wà láàyè títí láé nínú ayé tuntun. Táwọn kan lára wọn bá tiẹ̀ kú kí ayé tuntun yẹn tó dé, ọkàn wa balẹ̀ pé Jèhófà ò ní gbàgbé wọn, ó máa jí wọn dìde.—Jòhánù 5:28, 29.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáàbò bò wá?
17 Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà dáàbò bò wá ní báyìí ni pé ó ń fi “ọ̀rọ̀” rẹ̀ tù wá nínú, ó fi ń tún ayé wa ṣe, ìyẹn sì ń jẹ́ ká láyọ̀. (Hébérù 4:12) Tá a bá ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì, a ò ní máa ṣe àwọn nǹkan tó lè pa wá lára tàbí àwọn nǹkan tó lè ba ayé wa jẹ́. Àìsáyà 48:17 sọ pé: “Èmi, Jèhófà, . . . ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní.” Ká sòótọ́, tá a bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nígbèésí ayé wa, ó lè mú kí ìlera wa dáa sí i, kí ẹ̀mí wa sì gùn. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká máa sá fún àgbèrè, ó tún ní ká wẹ ara wa mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀gbin. Torí pé à ń fi àwọn ìmọ̀ràn yìí sílò, a ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìwà àìmọ́ àtàwọn ìwà burúkú míì tó ń bayé ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ torí pé wọn ò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. (Ìṣe 15:29; 2 Kọ́ríńtì 7:1) A mà dúpẹ́ o pé Ọlọ́run ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ dáàbò bò wá!
Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tẹ̀mí
18. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí?
18 Yàtọ̀ sí pé Jèhófà ń dáàbò bò wá nípa tara, ó tún máa ń dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí, èyí ló sì ṣe pàtàkì jù. Báwo ló ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀? Ó ń gbà wá lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè ba àjọṣe tá a ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́, ó sì ń pèsè àwọn nǹkan tá a nílò ká lè máa fara da àwọn ìṣòro wa. Bí Jèhófà ṣe ń dáàbò bò wá lọ́nà yìí ló máa jẹ́ ká lè wà láàyè títí láé. Ẹ ò rí i pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an! Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run ń gbà ràn wá lọ́wọ́ ká lè túbọ̀ ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀.
19. Báwo ni ẹ̀mí Jèhófà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àdánwò èyíkéyìí?
19 “Olùgbọ́ àdúrà” ni Jèhófà. (Sáàmù 65:2) Tó bá dà bíi pé ìṣòro wa fẹ́ kọjá agbára wa, tá a bá sọ gbogbo ohun tó wà lọ́kàn wa fún un nínú àdúrà, ara máa tù wá. (Fílípì 4:6, 7) Jèhófà lè má ṣe iṣẹ́ ìyanu láti mú ìṣòro wa kúrò, àmọ́ ó lè fún wa ní ọgbọ́n tá a máa fi bójú tó ìṣòro náà. (Jémíìsì 1:5, 6) Yàtọ̀ síyẹn, tá a bá ní kí Jèhófà fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀, ó máa fún wa. (Lúùkù 11:13) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lágbára gan-an, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro èyíkéyìí tá a bá ní. Ó lè fún wa ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” ká lè máa fara da àwọn ìṣòro wa títí dìgbà tí Jèhófà fi máa mú gbogbo ìṣòro wa kúrò, ìyẹn nínú ayé tuntun tí kò ní pẹ́ dé mọ́.—2 Kọ́ríńtì 4:7.
20. Báwo ni Jèhófà ṣe lè lo àwọn ará wa láti dáàbò bò wá?
20 Nígbà míì, Jèhófà máa ń lo àwọn tá a jọ ń sìn ín láti dáàbò bò wá. Lónìí, Ọlọ́run ń fa àwa èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀ ká lè máa sìn ín, ó sì sọ wá di ẹgbẹ́ “ará” tó wà níṣọ̀kan kárí ayé. (1 Pétérù 2:17; Jòhánù 6:44) Ìfẹ́ tó jinlẹ̀ ló wà láàárín wa, èyí sì jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń darí wa. Ẹ̀mí mímọ́ máa ń jẹ́ ká láwọn ìwà tó dáa, irú bí ìfẹ́, inú rere àti ìwà rere. (Gálátíà 5:22, 23) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé tá a bá wà nínú ìṣòro, àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà máa ń fún wa láwọn ìmọ̀ràn tó dáa tàbí kí wọ́n fún wa níṣìírí kí ara lè tù wá. A mà dúpẹ́ o pé Jèhófà ń lo àwọn ará wa láti dáàbò bò wá!
21. (a) Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ń pèsè fún wa nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye”? (b) Ọ̀nà wo lo ti gbà jàǹfààní látinú àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè láti fi dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí?
21 Ọ̀nà míì tí Jèhófà ń gbà dáàbò bò wá ni pé ó máa ń kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ tó ń mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kí wọ́n lè máa ṣàlàyé Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, ẹrú yìí máa ń tẹ oríṣiríṣi ìwé kí wọ́n lè kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́, lára wọn ni Ilé Ìṣọ́ àti Jí!, wọ́n tún máa ń lo ìkànnì jw.org, àwọn ìpàdé ìjọ, àwọn àpéjọ àyíká àti ti agbègbè láti fi pèsè ‘oúnjẹ ní àkókò tó yẹ,’ ìyẹn ni pé wọ́n ń pèsè àwọn ohun tá a nílò lásìkò. (Mátíù 24:45) Ṣé o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ kan rí nípàdé ìjọ, tó fún ẹ lókun àti ìṣírí tó o nílò gẹ́lẹ́, bóyá nínú ìdáhùn ẹnì kan, àsọyé tàbí nínú àdúrà? Àbí ṣe lo ka àpilẹ̀kọ kan nínú ọ̀kan lára àwọn ìwé wa tó ṣe ẹ́ láǹfààní gan-an? Má gbàgbé pé Jèhófà ló ń fún wa láwọn nǹkan yìí kó lè dáàbò bò wá nípa tẹ̀mí.
22. Kí ló máa ń mú kí Jèhófà fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀, báwo nìyẹn sì ṣe ń ṣe wá láǹfààní?
22 A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà jẹ́ apata “fún gbogbo àwọn tó fi í ṣe ibi ààbò.” (Sáàmù 18:30) Ní báyìí, Jèhófà kì í yọ wá nínú gbogbo ìṣòro. Àmọ́, ó máa ń fi agbára rẹ̀ dáàbò bo àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ nígbà tó bá pọn dandan, kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Tó bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó máa ń ṣe wá láǹfààní. Tá a bá sún mọ́ Jèhófà tá a sì ń ṣe ohun tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu, Jèhófà máa jẹ́ ká wà láàyè títí láé, àá sì ní ìlera pípé. Èyí ń fi wá lọ́kàn balẹ̀, torí a mọ̀ pé ńṣe làwọn ìṣòro tó ń dojú kọ wá ní báyìí wà ‘fún ìgbà díẹ̀, wọn ò sì lágbára’ tá a bá fi wọ́n wé àwọn nǹkan rere tí Jèhófà máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú.—2 Kọ́ríńtì 4:17.