“Ó Ń Fi Agbára fún Ẹni Tí Ó Ti Rẹ̀”
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2018: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà.”—AÍSÁ. 40:31.
1. Àwọn ìṣòro wo là ń fara dà lásìkò yìí, àmọ́ kí nìdí tí inú Jèhófà fi ń dùn sí wa? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)
BÍ GBOGBO wa ṣe mọ̀, àwọn nǹkan ò dẹrùn rárá lásìkò yìí. Ọ̀pọ̀ lára ẹ̀yin ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń fara da àìsàn tó le. Ara ti ń dara àgbà fáwọn kan, síbẹ̀ wọ́n tún láwọn arúgbó tí wọ́n ń tọ́jú. Ṣe làwọn kan ń tiraka kí wọ́n lè rọ́wọ́ mú lọ sẹ́nu, bí wọ́n ṣe máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn ni wọ́n ń wá, kì í ṣe bí wọ́n ṣe máa ní ànító àti àníṣẹ́kù. Bá a ṣe mọ̀, ńṣe làwọn ìṣòro yìí ń rọ́ lura fáwọn kan lára wa, ó mà ṣe o! Àwọn ìṣòro yìí ń gbani ní ọ̀pọ̀ àkókò, wọ́n ń kó ẹ̀dùn ọkàn báni, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń náni lówó gọbọi. Láìfi gbogbo ìyẹn pè, ìgbẹ́kẹ̀lé yín nínú Jèhófà dájú, ẹ ò sì ṣiyèméjì pé ọ̀la máa dáa. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ tẹ́ ẹ ní ń múnú Jèhófà dùn gan-an!
2. Báwo ni ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 40:29 ṣe fún wa níṣìírí, àmọ́ àṣìṣe wo lẹnì kan lè ṣe tó bá níṣòro?
2 Ǹjẹ́ o máa ń ronú pé àwọn ìṣòro rẹ pọ̀ lápọ̀jù àti pé bóyá ni wàá lè fara dà á mọ́? Ó ti ṣe àwọn kan náà bẹ́ẹ̀ rí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kan láyé àtijọ́ gbà pé ìṣòro àwọn kọjá nǹkan táwọn lè fara dà. (1 Ọba 19:4; Jóòbù 7:7) Àmọ́ dípò tí wọ́n fi máa bọ́hùn, ṣe ni wọ́n bẹ Jèhófà pé kó fún wọn lókun. Jèhófà dáhùn àdúrà wọn torí pé Jèhófà Ọlọ́run wa máa ń “fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀.” (Aísá. 40:29) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn kan lára wa ronú pé á dáa táwọn bá jáwọ́ fúngbà díẹ̀ ná, táwọn bá ti yanjú ìṣòro àwọn tán àwọn á pa dà wá sin Jèhófà. Lójú wọn, ṣe ló dà bíi pé ẹrù ìnira làwọn ìgbòkègbodò tá à ń ṣe nínú ìjọsìn Jèhófà dípò ìbùkún. Nípa bẹ́ẹ̀, wọn kì í ka Bíbélì mọ́, wọn ò wá sípàdé mọ́, wọn ò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́. Àṣìṣe gbáà nìyẹn jẹ́, ohun tí Sátánì sì fẹ́ kí wọ́n ṣe gan-an nìyẹn.
3. (a) Kí la lè ṣe tí Sátánì kò fi ní mú ká dẹwọ́ nínú ìjọsìn wa? (b) Kí la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?
3 Sátánì mọ̀ pé a máa lókun nípa tẹ̀mí tá a bá ń fìtara kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni, àmọ́ kò fẹ́ ká rókun gbà. Tó bá ń ṣe ẹ́ bíi pé o ò lókun mọ́, má ṣe fi Jèhófà sílẹ̀. Ìgbà yẹn gan-an ló yẹ kó o sún mọ́ ọn torí pé á ‘fìdí rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ ẹ́ di alágbára.’ (1 Pét. 5:10; Ják. 4:8) Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa jíròrò nǹkan méjì tó lè mú ká dẹwọ́ nínú ìjọsìn Jèhófà, a sì máa sọ bí àwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń fi wọ́n sílò. Àmọ́ ní báyìí ná, ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ jíròrò bí Jèhófà ṣe ń fún wa lágbára, bó ṣe wà nínú Aísáyà 40:26-31.
ÀWỌN TÓ NÍ ÌRÈTÍ NÍNÚ JÈHÓFÀ YÓÒ JÈRÈ AGBÁRA PA DÀ
4. Kí la rí kọ́ nínú Aísáyà 40:26?
4 Ka Aísáyà 40:26. Kò sẹ́ni tó tíì lè ka gbogbo ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé iye ìràwọ̀ tó wà nínú ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Milky Way tí ayé yìí wà tó irínwó [400] bílíọ̀nù. Síbẹ̀, Jèhófà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìràwọ̀ yẹn lórúkọ. Kí lèyí kọ́ wa nípa Jèhófà? Tí Jèhófà bá ń kíyè sí àwọn nǹkan tí kò lẹ́mìí, mélòómélòó wá ni ìwọ tó ò ń fi tọkàntọkàn sìn ín torí pé o nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (Sm. 19:1, 3, 14) Baba wa ọ̀run mọ̀ ẹ́ dáadáa. Kódà, ‘gbogbo irun orí rẹ ni Jèhófà ti kà.’ (Mát. 10:30) Onísáàmù náà tún jẹ́ kó dá wa lójú pé Jèhófà mọ ohun táwọn aláìní-àléébù ń kojú. (Sm. 37:18) Ó mọ gbogbo ìṣòro tó ò ń dojú kọ, ó sì máa fún ẹ lókun láti fara dà á.
5. Kí ló mú kó dá wa lójú pé Jèhófà lè fún wa lókun tá a nílò?
5 Ka Aísáyà 40:28. Jèhófà ni Orísun gbogbo agbára. Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo bí agbára oòrùn ti pọ̀ tó. Onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan tó ń jẹ́ David Bodanis sọ pé: ‘Iye agbára tó ń jáde lára Oòrùn ní ìṣẹ́jú àáyá kan péré pọ̀ débi pé ó tó iye agbára tí ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù bọ́ǹbù átọ́míìkì máa ń mú jáde.’ Olùṣèwádìí míì tún ṣírò iye agbára tó ń jáde lára oòrùn. Ó ní: “Iye agbára tó ń jáde lára oòrùn ní ìṣẹ́jú àáyá kan ṣoṣo tó aráyé lò fún odindi ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún méjì [200,000] ọdún”! Ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni wá lè sọ pé ẹni tó ń fún oòrùn lágbára tó tó báyìí kò lè fún òun lókun láti kojú ìṣòro èyíkéyìí?
6. Kí nìdí tá a fi lè sọ pé àjàgà Jésù rọrùn, báwo ló sì ṣe yẹ kíyẹn rí lára wa?
6 Ka Aísáyà 40:29. Ayọ̀ tá a máa rí nínú sísin Jèhófà ò kéré. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín.” Ó tún fi kún un pé: “Ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Òótọ́ pọ́ńbélé lọ̀rọ̀ yìí! Bí àpẹẹrẹ, tá a bá fẹ́ lọ sípàdé tàbí òde ẹ̀rí nígbà míì, ó lè rẹ̀ wá ká tó kúrò nílé. Àmọ́ nígbà tá a bá pa dà dé, báwo lara wa ṣe máa ń rí? Ṣe lara máa ń tù wá pẹ̀sẹ̀, á sì rọrùn fún wa láti kojú àwọn ìṣòro tá a ní. Ẹ ò rí i pé àjàgà Jésù rọrùn lóòótọ́!
7. Sọ ìrírí kan tó fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tó wà nínú Mátíù 11:28-30.
7 Arábìnrin wa kan ní àrùn tó máa ń jẹ́ kó rẹni, tí kì í sì í jẹ́ kéèyàn rí oorun sùn. Yàtọ̀ síyẹn, inú rẹ̀ kì í dùn, gbogbo ìgbà lorí sì máa ń fọ́ ọ. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í lè lọ sípàdé nítorí àìlera ẹ̀. Àmọ́ lọ́jọ́ kan ó rọ́jú wá sípàdé, lẹ́yìn ìpàdé náà ó sọ pé: “Ohun tí àsọyé tí wọ́n sọ lọ́jọ́ yẹn dá lé ni ìrẹ̀wẹ̀sì. Àsọyé yẹn jẹ́ kí n mọ̀ pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe ń rí lára wa àti pé ó ń gba tiwa rò. Ọ̀rọ̀ náà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, kódà mi ò mọ ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú. Àsọyé yẹn tún jẹ́ kí n rí i pé ó ṣe pàtàkì kí n máa wá sípàdé tí mo bá máa rókun gbà.” Ó dájú pé inú rẹ̀ dùn gan-an pé ó wá sí ìpàdé lọ́jọ́ yẹn!
8, 9. Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára”?
8 Ka Aísáyà 40:30. Bó ti wù ká ní òye tàbí ìrírí tó, ó lójú ohun tá a lè dá ṣe. Kókó pàtàkì nìyí, ó sì yẹ ká máa fi í sọ́kàn. Àpẹẹrẹ kan ni ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nǹkan ló ṣe, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ohun tó wù ú láti ṣe ló ṣe torí pé ẹlẹ́ran ara lòun náà. Nígbà tó sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ fún Ọlọ́run, Ọlọ́run sọ fún un pé: “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Ohun tí Ọlọ́run sọ yé Pọ́ọ̀lù dáadáa, abájọ tó fi sọ pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (2 Kọ́r. 12:7-10) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?
9 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé láìsí ìrànwọ́ Ọlọ́run, ó lójú ohun tí òun lè dá ṣe. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí Pọ́ọ̀lù ní agbára. Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tún mú kí Pọ́ọ̀lù ṣe àwọn nǹkan tó ju agbára òun fúnra rẹ̀ lọ. Bíi ti Pọ́ọ̀lù lọ̀rọ̀ tiwa náà rí. Tá a bá rí okun gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, ó dájú pé àwa náà máa ní agbára láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́!
10. Báwo ni Jèhófà ṣe ran Dáfídì lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó ní?
10 Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Dáfídì rí agbára gbà nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà. Ó kọ ọ́ lórin pé: “Nítorí nípasẹ̀ rẹ, mo lè sáré ní ìgbéjàko ẹgbẹ́ onísùnmọ̀mí; àti pé nípasẹ̀ Ọlọ́run mi, mo lè gun ògiri.” (Sm. 18:29) Àwọn ìṣòro kan wà tó dà bí ògiri tá ò lè dá “gùn,” àfi kí Jèhófà gbé wa gùn ún.
11. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro?
11 Ka Aísáyà 40:31. Kì í ṣe agbára tí ẹyẹ idì ní ló mú kó lè máa fò lókè tàbí fò lọ sọ́nà jíjìn. Atẹ́gùn tó móoru tó ń lọ sókè ló máa ń ran ẹyẹ idì lọ́wọ́ tó bá ń fò, kó bàa lè dín agbára tó máa lò kù. Torí náà, tó o bá kojú ìṣòro tó dà bí òkè, rántí ẹyẹ idì. Bẹ Jèhófà pé kó gbé ẹ ró nípasẹ̀ “olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́.” (Jòh. 14:26) Inú wa dùn pé kò sígbà tá a nílò rẹ̀ tí kì í wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa nígbà gbogbo àti níbikíbi. A túbọ̀ nílò ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run tá a bá ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹnì kan nínú ìjọ. Àmọ́ kí nìdí tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi ń wáyé?
12, 13. (a) Kí nìdí tí èdèkòyédè fi máa ń wáyé láàárín àwa Kristẹni? (b) Kí lohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù kọ́ wa nípa Jèhófà?
12 Èdèkòyédè máa ń wáyé láàárín àwa Kristẹni torí pé aláìpé ni wá. Torí náà, ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe ẹnì kan lè múnú bí wa, ọ̀rọ̀ àti ìṣe tiwa náà sì lè múnú bí ẹlòmíì. Ká sòótọ́, ìyẹn lè dán ìgbàgbọ́ wa wò. Àmọ́, á jẹ́ ká lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà. Lọ́nà wo? A lè fi hàn pé a jẹ́ adúróṣinṣin tá a bá ń fìfẹ́ bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa lò tá a sì ń rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìpé ni wọ́n.
13 Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jósẹ́fù mú kó ṣe kedere pé Jèhófà máa ń fàyè gba pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kojú àdánwò nígbà míì. Ìgbà tí Jósẹ́fù wà lọ́dọ̀ọ́ làwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tà á sóko ẹrú torí pé wọ́n ń jowú rẹ̀, bó ṣe dèrò Íjíbítì nìyẹn. (Jẹ́n. 37:28) Jèhófà rí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì dájú pé inú rẹ̀ ò dùn bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n Jósẹ́fù ọ̀rẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀, Jèhófà kò dá a nídè. Nígbà tó yá, wọ́n fẹ̀sùn kan Jósẹ́fù pé ó fẹ́ fipá bá ìyàwó Pọ́tífárì sùn, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, Jèhófà ò dá sí i. Àmọ́ ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé Jèhófà gbàgbé Jósẹ́fù? Rárá, kò rí bẹ́ẹ̀ torí Bíbélì sọ pé: ‘Jèhófà ń mú kí ohun tí Jósẹ́fù ń ṣe yọrí sí rere.’—Jẹ́n. 39:21-23.
14. Àwọn àǹfààní wo lèèyàn á rí tó bá “jáwọ́” nínú ìbínú?
14 Àpẹẹrẹ míì ni ti Dáfídì. Àwọn èèyàn fojú Dáfídì rí màbo, ṣàṣà làwọn tírú ẹ̀ tíì ṣẹlẹ̀ sí. Síbẹ̀, ọ̀rẹ́ Ọlọ́run yìí kò jẹ́ kíyẹn mú òun ṣìwà hù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀; má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” (Sm. 37:8) Ìdí to ṣe pàtàkì jù tó fi yẹ ká “jáwọ́” nínú ìbínú ni pé a fẹ́ fìwà jọ Jèhófà, tí “kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.” (Sm. 103:10) Yàtọ̀ síyẹn, àá jàǹfààní nípa tara tá a bá “jáwọ́” nínú ìbínú. Ìdí sì ni pé ìbínú máa ń fa àìsàn bí ẹ̀jẹ̀ ríru, àrùn ẹ̀dọ̀, kéèyàn má lè mí dáadáa tàbí kí ẹ̀yà ara tá à ń pè ní àmọ́ má ṣiṣẹ́ dáadáa, bẹ́ẹ̀ ni kì í jẹ́ kí oúnjẹ dà nínú bó ṣe yẹ. Téèyàn bá ń bínú, kò ní lè ronú lọ́nà tó já geere. Lọ́pọ̀ ìgbà, téèyàn bá fara ya, ó lè mú kéèyàn ní ìsoríkọ́ tí kì í tán bọ̀rọ̀. Àmọ́, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà píparọ́rọ́ ni ìwàláàyè ẹ̀dá alààyè ẹlẹ́ran ara.” (Òwe 14:30) Kí wá la lè ṣe tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá nínú ìjọ, báwo la sì ṣe lè mú kí àlàáfíà jọba láàárín wa? Ohun tá a lè ṣe ni pé ká fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò.
TÍ ẸNÌ KAN BÁ ṢẸ̀ WÁ NÍNÚ ÌJỌ
15, 16. Àwọn ìgbésẹ̀ wo ló yẹ ká gbé tẹ́nì kan bá ṣẹ̀ wá?
15 Ka Éfésù 4:26. Kì í yà wá lẹ́nu táwọn èèyàn ayé bá hùwà àìdáa sí wa. Àmọ́ tí ará kan tàbí mọ̀lẹ́bí wa bá ṣẹ̀ wá, ó máa ń dùn wá wọ eegun. Tó bá nira fún wa láti gbàgbé ọ̀rọ̀ náà ńkọ́? Ṣó wá yẹ ká di ẹni náà sínú fún ọ̀pọ̀ ọdún? Ǹjẹ́ kò ní dáa ká tẹ̀lé ìmọ̀ràn Bíbélì pé ká tètè yanjú ọ̀rọ̀ náà? Bí ọ̀rọ̀ náà bá ṣe ń pẹ́ nílẹ̀, bẹ́ẹ̀ lá túbọ̀ máa nira fún wa láti wà ní àlàáfíà pẹ̀lú arákùnrin tàbí arábìnrin wa.
16 Jẹ́ ká gbà pé ohun tí ará kan ṣe fún ẹ dùn ẹ́ débi pé o ò lè gbọ́rọ̀ náà kúrò lọ́kàn. Àwọn ìgbésẹ̀ wo lo lè gbé táá jẹ́ kí àlàáfíà jọba láàárín yín? Àkọ́kọ́, rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà. Ní kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè fi ahọ́n tútù bá arákùnrin rẹ sọ̀rọ̀. Rántí pé ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ Jèhófà ni arákùnrin náà, Jèhófà sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ gan-an. (Sm. 25:14) Jèhófà máa ń fàánú hàn sáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, ohun tó fẹ́ káwa náà máa ṣe nìyẹn. (Òwe 15:23; Mát. 7:12; Kól. 4:6) Ohun kejì ni pé kó o ronú dáadáa nípa ohun tó o fẹ́ bá arákùnrin náà sọ. Má ṣe ronú pé ńṣe ni arákùnrin náà mọ̀ọ́mọ̀ ṣẹ̀ ẹ́, torí náà gbà pé kò mọ̀ọ́mọ̀. Bákan náà, fi sọ́kàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwọ náà dá kún ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín yín. O lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ báyìí, “Ó jọ pé mo jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yẹn ká mi lára ju bó ṣe yẹ lọ, àmọ́ ọ̀rọ̀ tó o sọ lánàá mú kí n . . . ” Tí ìjíròrò yín kò bá yanjú ọ̀rọ̀, wá ìgbà míì tó wọ̀ láti yanjú ọ̀rọ̀ náà. Títí dìgbà tọ́rọ̀ náà fi máa yanjú, máa gbàdúrà fún arákùnrin rẹ, ní kí Jèhófà máa bù kún un. Bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kó o máa wo ibi tí arákùnrin náà dáa sí, dípò ibi tó kù sí. Yálà ọ̀rọ̀ náà yanjú tàbí kò yanjú, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé inú Jèhófà dùn sí ẹ torí pé o ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe láti jèrè arákùnrin rẹ.
TÁWỌN Ẹ̀ṢẸ̀ TÓ O DÁ SẸ́YÌN BÁ Ń KÓ Ẹ̀DÙN ỌKÀN BÁ Ẹ
17. Báwo ni Jèhófà ṣe lè mú ká kọ́fẹ pa dà lẹ́yìn tá a bá dẹ́ṣẹ̀, kí sì nìdí tó fi yẹ ká tètè gbé ìgbésẹ̀?
17 Àwọn kan máa ń ronú pé àwọn ò yẹ lẹ́ni tó lè sin Jèhófà torí ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá sẹ́yìn. Ká sòótọ́, tí ẹ̀rí ọkàn bá ń dáni lẹ́bi, bí ẹni nani ní pàṣán ni. Ọba Dáfídì tí ẹ̀rí ọkàn ti nà ní pàṣán rí sọ pé: “Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni ọwọ́ rẹ wúwo lára mi.” Àmọ́ nígbà tó yá, Dáfídì ṣe ohun tó yẹ kéèyàn Ọlọ́run ṣe láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Ó sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, . . . ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Sm. 32:3-5) Tó o bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà ṣe tán láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè kọ́fẹ pa dà. Àmọ́ o, ìwọ náà gbọ́dọ̀ tọ àwọn alàgbà lọ kí wọ́n lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. (Òwe 24:16; Ják. 5:13-15) Torí náà, má jáfara, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ ìyè àìnípẹ̀kun lo fi ń ṣeré yẹn! Àmọ́, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn rẹ ṣì ń dá ẹ lẹ́bi lẹ́yìn tí Jèhófà ti dárí jì ẹ́, kí lo lè ṣe?
18. Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe lè ṣèrànwọ́ fáwọn tó ń ronú pé àwọn ò yẹ ní ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
18 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn tó bá ń rántí àwọn ìwà àìdáa tó ti hù sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Èmi ni mo kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì, èmi kò sì yẹ ní ẹni tí a ń pè ní àpọ́sítélì, nítorí mo ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run.” Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù fi kún un pé: “Ṣùgbọ́n nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́.” (1 Kọ́r. 15:9, 10) Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni Pọ́ọ̀lù, síbẹ̀ ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì fẹ́ kí Pọ́ọ̀lù náà mọ̀ bẹ́ẹ̀. Tó bá jẹ́ pé tọkàntọkàn lo ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tó o dá, tó o gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀, tó o sì tún sọ fáwọn alàgbà tó bá yẹ bẹ́ẹ̀, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà kò ní ka ẹ̀ṣẹ̀ náà sí ẹ lọ́rùn mọ́. Torí náà, gbà pé Jèhófà ti dárí jì ẹ́ pátápátá!—Aísá. 55:6, 7.
19. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2018, kí sì nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú?
19 Bí ayé búburú yìí ṣe ń lọ sópin, a lè retí pé àwọn ìṣòro ìgbésí ayé á túbọ̀ máa peléke. Àmọ́, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run tó ‘ń fi agbára fún ẹni tí ó ti rẹ̀, tó sì ń mú kí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ agbára ńlá pọ̀ gidigidi fún ẹni tí kò ní okun’ máa fún ẹ ní gbogbo ohun tó o nílò kó o lè fara dà á. (Aísá. 40:29; Sm. 55:22; 68:19) Jálẹ̀ ọdún 2018, ìgbà gbogbo làá máa rántí kókó yìí tá a bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba bá a ṣe ń rí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tọdún yìí tó sọ pé: “Àwọn tí ó ní ìrètí nínú Jèhófà yóò jèrè agbára padà.”—Aísá. 40:31.