Orí Kejì
Àsọtẹ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ìtùnú Tí Ó Kàn Ọ́
1. Kí ni ìdí tó fi yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?
NǸKAN bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọdún sẹ́yìn ni Aísáyà ti kọ ìwé tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀, àmọ́ ó wúlò fún wa gidigidi lónìí. A lè rí àwọn ìlànà tó ṣe kókó kọ́ látinú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó jẹ́ mánigbàgbé tó kọ sílẹ̀. Bí a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ó kọ sílẹ̀ lórúkọ Jèhófà, a lè fi wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wa ró. Wòlíì Ọlọ́run alààyè ni Aísáyà ní tòótọ́. Jèhófà mí sí i láti kọ ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú sílẹ̀, ìyẹn ni, láti sọ bí àwọn nǹkan ṣe máa ṣẹlẹ̀ gẹ́lẹ́ kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Jèhófà tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun lè sọ bí ọjọ́ ọ̀la ṣe máa rí, òun sì lè darí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Lẹ́yìn tí àwọn Kristẹni tòótọ́ bá ti ka ìwé Aísáyà, wọ́n máa ń ní ìdánilójú pé Jèhófà yóò mú gbogbo ohun tó ti ṣèlérí ṣẹ.
2. Báwo ni nǹkan ti rí ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí Aísáyà kọ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀, àyípadà wo ló sì máa tó bá wọn?
2 Nígbà tí Aísáyà fi máa parí kíkọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, Jerúsálẹ́mù ti bọ́ lọ́wọ́ inú fu ẹ̀dọ̀ fu tí Ásíríà kó wọn sí. Mìmì kan ò sì mi tẹ́ńpìlì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn èèyàn ṣì ń bá ìgbòkègbodò wọn ojoojúmọ́ nìṣó bí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ látọdúnmọ́dún. Àmọ́ o, nǹkan máa tó yí padà. Ìgbà ń bọ̀ tí wọn yóò kó dúkìá àwọn ọba Júù lọ sí Bábílónì, tí àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Júù yóò sì di òṣìṣẹ́ láàfin Bábílónì.a (Aísáyà 39:6, 7) Èyí yóò ṣẹlẹ̀ ní ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ lẹ́yìn náà.—2 Àwọn Ọba 24:12-17; Dáníẹ́lì 1:19.
3. Iṣẹ́ wo ló wà nínú Aísáyà orí kọkànlélógójì?
3 Ṣùgbọ́n o, iṣẹ́ ìdálẹ́bi nìkan kọ́ ni Ọlọ́run gbẹnu Aísáyà sọ. “Ẹ tu àwọn ènìyàn mi nínú” ni gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ orí ogójì ìwé rẹ̀.b Ìdánilójú tí àwọn Júù rí gbà pé yálà àwọn tàbí ọmọ àwọn yóò lè padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn máa jẹ́ ìtùnú fún wọn. Iṣẹ́ ìtùnú yẹn ló ń bá a lọ ní orí kọkànlélógójì, orí yẹn sì sọ tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà yóò gbé ọba alágbára kan dìde tí yóò mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Ó fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì fún wọn níṣìírí pé kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Ó tún tú àwọn òrìṣà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè gbẹ́kẹ̀ lé fó pé ọlọ́run èké ni wọ́n. Gbogbo ìwọ̀nyí ló sì kún fún àwọn ohun tó lè fún ìgbàgbọ́ lókun, ì bá à jẹ́ nígbà ayé Aísáyà o tàbí nígbà tiwa yìí.
Jèhófà Pe Àwọn Orílẹ̀-Èdè Níjà
4. Ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà fi pe àwọn orílẹ̀-èdè níjà?
4 Jèhófà gbẹnu wòlíì rẹ̀ sọ pé: “Ẹ tẹ́tí sí mi ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin erékùṣù; kí àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè pàápàá sì jèrè agbára padà. Kí wọ́n sún mọ́ tòsí. Ní àkókò yẹn, kí wọ́n sọ̀rọ̀. Ẹ jẹ́ kí a jọ sún mọ́ tòsí fún ìdájọ́.” (Aísáyà 41:1) Ọ̀rọ̀ yìí ni Jèhófà sọ láti fi pe àwọn orílẹ̀-èdè tó tako àwọn èèyàn rẹ̀ níjà. Kí wọ́n wá dúró níwájú rẹ̀ ni o, kí wọ́n sì gbára dì láti sọ̀rọ̀! Bí a ṣe máa wá padà rí i, ńṣe ni Jèhófà sọ fún àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, bí ẹni pé ó jẹ́ adájọ́ ní kóòtù, pé kí wọ́n kó ẹ̀rí wá láti fi hàn pé ọlọ́run làwọn òrìṣà àwọn lóòótọ́. Ṣé àwọn ọlọ́run wọ̀nyí lè sọ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀nà báyìí-báyìí làwọn yóò gbà gba àwọn tó ń sin àwọn là tàbí báyìí-báyìí làwọn yóò ṣe dá àwọn ọ̀tá àwọn lẹ́jọ́? Bí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé wọ́n lè mú irú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣẹ? Rárá ni o. Jèhófà nìkan ló lè ṣe nǹkan wọ̀nyí.
5. Ṣàlàyé bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ní ìmúṣẹ ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ.
5 Bí a ṣe ń gbé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yẹ̀ wò, ẹ jẹ́ kí á fi í sọ́kàn pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìmúṣẹ ju ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lọ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe rí. Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, Júdà yóò dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì. Àmọ́, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣí i payá pé Jèhófà yóò dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n mú lóǹdè sọ́hùn-ún nídè. Èyí wáyé lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìdáǹdè kan tó bá ìyẹn dọ́gba wáyé lápá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún yìí. Lásìkò ogun àgbáyé kìíní, àwọn ẹni àmì òróró, ìránṣẹ́ Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé, la àkókò ìpọ́njú kan kọjá. Lọ́dún 1918, ìdààmú látọwọ́ ayé Sátánì fẹ́rẹ̀ẹ́ mú kí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà tí a fètò sí dáwọ́ dúró, bẹ́ẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù tó jẹ́ apá pàtàkì jù lọ nínú Bábílónì Ńlá ní ń bẹ nídìí rẹ̀. (Ìṣípayá 11:5-10) Ńṣe ni wọ́n kó àwọn sàràkí-sàràkí inú àjọ Watch Tower Society sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn awúrúju. Àfi bíi pé ayé ti borí nínú ìjà tí wọ́n ń bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run jà ni. Lọ̀ràn bá tún wá rí bí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà dá wọn nídè lójijì. Lọ́dún 1919, wọ́n dá àwọn sàràkí-sàràkí tí wọ́n kó sẹ́wọ̀n yìí sílẹ̀, wọ́n sì fagi lé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n yẹn lẹ́yìn-ọ-rẹyìn. Àpéjọpọ̀ kan tí wọ́n ṣe ní ìlú Cedar Point, Ohio, ní September 1919 ló fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lókun láti tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Ìṣípayá 11:11, 12) Láti ìgbà yẹn wá, iṣẹ́ ìwàásù yẹn ti wá gbòòrò sí i lọ́nà tó bùáyà. Ẹ̀wẹ̀, ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ Aísáyà ni yóò ṣẹ lọ́nà àgbàyanu nínú Párádísè ilẹ̀ ayé tó ń bọ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọ̀rọ̀ tí Aísáyà ti sọ látọdúnmọ́dún yìí kan àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn èèyàn òde òní.
Jèhófà Pe Olùdáǹdè Jáde Wá
6. Báwo ni wòlíì yìí ṣe ṣàpèjúwe aṣẹ́gun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú?
6 Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa aṣẹ́gun kan tí yóò gba àwọn èèyàn Ọlọ́run là kúrò lọ́wọ́ Bábílónì, tí yóò sì dá àwọn ọ̀tá wọn lẹ́jọ́. Jèhófà béèrè pé: “Ta ni ó ti gbé ẹnì kan dìde láti yíyọ oòrùn? Ta ni ó tẹ̀ síwájú nínú òdodo láti pè é wá síbi ẹsẹ̀ Rẹ̀, láti fi àwọn orílẹ̀-èdè fún un níwájú rẹ̀, àti láti mú kí ó máa tẹ àwọn ọba pàápàá lórí ba nìṣó? Ta ni ó ń fi wọ́n fún un bí ekuru fún idà rẹ̀, tí ó fi jẹ́ pé a ń fi ọrun rẹ̀ gbá wọn kiri bí àgékù pòròpórò lásán-làsàn? Ta ni ó ń lépa wọn, tí ó ń fi ẹsẹ̀ rìn lọ ní àlàáfíà ní ipa ọ̀nà tí òun kò gbà wá? Ta ni ó ti ń gbé kánkán ṣiṣẹ́, tí ó sì ti ṣe èyí, tí ó ń pe àwọn ìran jáde láti ìbẹ̀rẹ̀? Èmi, Jèhófà ni, tí í ṣe Ẹni Àkọ́kọ́; àti pẹ̀lú àwọn ẹni ìkẹyìn, èmi kan náà ni.”—Aísáyà 41:2-4.
7. Ta ni aṣẹ́gun tí ń bọ̀, kí ló sì gbé ṣe?
7 Ta ni Jèhófà fẹ́ gbé dìde láti yíyọ oòrùn, láti ìhà ìlà-oòrùn? Ìhà ìlà-oòrùn ni orílẹ̀-èdè Mídíà òun Páṣíà àti orílẹ̀-èdè Élámù wà sí Bábílónì. Ibẹ̀ ni Kírúsì ará Páṣíà tòun ti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ alágbára ńlá ti gbéra wá. (Aísáyà 41:25; 44:28; 45:1-4, 13; 46:11) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùjọsìn Jèhófà kọ́ ni Kírúsì, ó ṣe ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run òdodo fẹ́. Kírúsì borí àwọn ọba, tí àwọn ọba yẹn sì fọ́n ká bí ekuru níwájú rẹ̀. Nínú bí ó ṣe ń lépa ìṣẹ́gun, ṣe ló ń rìn lọ “ní àlàáfíà” tàbí láìséwu lójú ọ̀nà tí wọn kì í rìn déédéé, tó ń borí gbogbo ìdènà. Ní nǹkan bí ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Kírúsì dé ìlú ńlá Bábílónì alágbára, ó sì ṣẹ́gun rẹ̀. Àbáyọrí rẹ̀ ni pé àwọn èèyàn Ọlọ́run gba ìdáǹdè kí wọ́n lè padà sí Jerúsálẹ́mù láti tún lọ fìdí ìjọsìn tòótọ́ múlẹ̀.—Ẹ́sírà 1:1-7.c
8. Kí ni nǹkan náà tó jẹ́ pé Jèhófà nìkan ló lè ṣe é?
8 Nípa báyìí, Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìdìde Kírúsì tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí ọba yẹn. Àfi Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ló lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tí kò sì ní yẹ̀. Kò sí ìkankan lára gbogbo òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè tó bá Jèhófà dọ́gba. Ìdí rèé tí Jèhófà fi sọ pé: “Èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.” Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé: “Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan.”—Aísáyà 42:8; 44:6, 7.
Àwọn Tí JìnnìJìnnì Bò Lọ Gbẹ́kẹ̀ Lé Àwọn Òrìṣà
9-11. Kí ni àwọn orílẹ̀-èdè ṣe nítorí ogun tí Kírúsì ń gbé bọ̀?
9 Aísáyà wá ṣàpèjúwe ohun tí àwọn orílẹ̀-èdè ṣe nítorí aṣẹ́gun ọjọ́ iwájú yìí, ó ní: “Àwọn erékùṣù rí i, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀rù. Àní àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì. Wọ́n sún mọ́ tòsí, wọ́n sì ń bọ̀. Olúkúlùkù wọn ń ran alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ọ̀kan a sì wí fún arákùnrin rẹ̀ pé: ‘Jẹ́ alágbára.’ Bẹ́ẹ̀ ni oníṣẹ́ ọnà ń fún oníṣẹ́ irin lókun; ẹni tí ń fi ọmọ owú mú nǹkan jọ̀lọ̀ ń fún ẹni tí ń fi òòlù lu nǹkan nídìí owú lókun, ó ń sọ nípa ìjópọ̀ pé: ‘Ó dára.’ Níkẹyìn, ẹnì kan fi ìṣó kàn án, tí a kò fi lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.”—Aísáyà 41:5-7.
10 Jèhófà wo nǹkan bí igba ọdún níwájú, ó ń wo ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ láyé ìgbà yẹn. Ẹgbẹ́ ọmọ ogun alágbára tó wà níkàáwọ́ Kírúsì ń báṣẹ́ lọ kánkán láìdáwọ́ró, wọ́n ń borí àtakò gbogbo. Ni jìnnìjìnnì bá bo àwọn èèyàn bó ṣe ń sún mọ́ tòsí wọn, kódà títí kan àwọn tí ń gbé ní àwọn erékùṣù, àwọn tó wà lọ́nà jíjìn réré. Ìbẹ̀rù yẹn ló mú kí wọ́n para pọ̀ láti gbéjà ko ẹni tí Jèhófà pè láti ìlà oòrùn wá pé kó wá mú ìdájọ́ ṣẹ. Wọ́n gbìyànjú láti fún ara wọn níṣìírí, pé: “Jẹ́ alágbára.”
11 Àwọn oníṣọ̀nà pawọ́ pọ̀ ṣe àwọn òrìṣà láti fi gba àwọn èèyàn náà. Káfíńtà gbẹ́ igi kan lére, ó sì wá rọ alágbẹ̀dẹ wúrà pé kó fi ohun ajẹmọ́-irin, bóyá bíi wúrà, bò ó. Oníṣẹ́ ọ̀nà wá fi ọmọ owú lù ú tó fi jọ̀lọ̀, ó sì gbà pé wọ́n jó o pọ̀ dáadáa. Bóyá láti fi tẹ́ ẹ ni wọ́n ṣe sọ pé wọ́n fi ìṣó kàn án kí ó má bàa ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n tàbí kí ó di yọ̀gẹ̀yọ̀gẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ère Dágónì tó wó lulẹ̀ síwájú àpótí Jèhófà.—1 Sámúẹ́lì 5:4.
Ẹ Má Bẹ̀rù!
12. Ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ni Jèhófà fún Ísírẹ́lì?
12 Jèhófà wá yí àfiyèsí sí àwọn èèyàn rẹ̀ wàyí. Kò sídìí fún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tòótọ́ láti bẹ̀rù rárá, wọn kò dà bí àwọn orílẹ̀-èdè tó gbẹ́kẹ̀ lé òrìṣà, ohun aláìlẹ́mìí. Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nípa rírán wọn létí pé Ísírẹ́lì jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ òun. Àyọkà tí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ tuni lọ́kàn gidigidi ni Aísáyà fi gbé ọ̀rọ̀ Jèhófà jáde, ó ní: “Ìwọ, Ísírẹ́lì, ni ìránṣẹ́ mi, ìwọ, Jékọ́bù, ẹni tí mo ti yàn, irú-ọmọ Ábúráhámù ọ̀rẹ́ mi; ìwọ, tí mo ti dì mú láti àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé, àti ìwọ, tí mo ti pè àní láti àwọn apá rẹ̀ jíjìnnàréré. Mo sì tipa báyìí sọ fún ọ pé, ‘Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi; mo ti yàn ọ́, èmi kò sì kọ̀ ọ́. Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́. Èmi yóò fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin ní ti tòótọ́.’”—Aísáyà 41:8-10.
13. Kí ni ìdí tí ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò fi jẹ́ ìtùnú fún àwọn Júù tó wà ní ìgbèkùn?
13 Ìtùnú gbáà lọ̀rọ̀ yìí yóò jẹ́ fún àwọn Júù olóòótọ́ tó wà ní ìgbèkùn ní ilẹ̀ òkèèrè! Yóò mà jẹ́ ìṣírí fún wọn o láti gbọ́ pé Jèhófà pe àwọn ní “ìránṣẹ́ mi” lásìkò tí wọ́n ṣì jẹ́ ìgbèkùn, tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ fún ọba Bábílónì! (2 Kíróníkà 36:20) Lóòótọ́, Jèhófà máa jẹ wọ́n níyà nítorí àìṣòótọ́ wọn, àmọ́ kò ní kọ̀ wọ́n. Ti Jèhófà ni Ísírẹ́lì, kì í ṣe ti Bábílónì. Kò sí ìdí tí jìnnìjìnnì yóò fi bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run torí pé Kírúsì aṣẹ́gun ń bọ̀. Jèhófà yóò wà pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́.
14. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì sọ ṣe ń tu àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú lóde òní?
14 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn ń fi àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lọ́kàn balẹ̀, ó sì ń fún wọn lókun títí di ọjọ́ wa lónìí pàápàá. Lọ́dún 1918 lọ́hùn-ún, wọ́n ń fẹ́ gidigidi láti mọ ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún àwọn. Wọ́n ń fi taratara wọ̀nà fún ìdáǹdè kúrò nínú ìgbèkùn tí wọ́n wà nípa tẹ̀mí. Lóde òní, à ń wá ọ̀nà àjàbọ́ lójú méjèèjì kúrò lọ́wọ́ ìnira tí Sátánì, ayé, àti àìpé àwa fúnra wa ń kó wa sí. Ṣùgbọ́n, a mọ̀ dájú pé Jèhófà mọ àkókò tó yẹ àti ọ̀nà tó yẹ wẹ́kú láti fi gbé ìgbésẹ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ̀. Bí ọmọ kékeré la ṣe rọ̀ mọ́ ọwọ́ rẹ̀ alágbára pẹ̀lú ìdánilójú pé yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa forí tì í nìṣó. (Sáàmù 63:7, 8) Jèhófà ka àwọn tó ń sìn ín sí iyebíye. Ó ń tì wá lẹ́yìn lóde òní gẹ́lẹ́ bó ṣe ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn ní gbogbo ìgbà ìnira ọdún 1918 sí 1919, àti gẹ́gẹ́ bó ṣe ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olóòótọ́ lẹ́yìn láyé ọjọ́un.
15, 16. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì, ọ̀nà wo sì ni Ísírẹ́lì gbà dà bíi kòkòrò mùkúlú? (b) Ìkọlù tí ń bọ̀ wo ló mú kí ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ ìṣírí lóde òní ní pàtàkì?
15 Wo ohun tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ tẹ̀ lé ìyẹn: “‘Wò ó! Gbogbo àwọn tí ń gbaná jẹ mọ́ ọ ni ojú yóò tì, tí a ó sì tẹ́ lógo. Àwọn ènìyàn tí ń bá ọ ṣe aáwọ̀ yóò rí bí aláìjámọ́ nǹkan kan, wọn yóò sì ṣègbé. Ìwọ yóò wá wọn kiri, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò rí wọn, àwọn ènìyàn tí ń bá ọ jìjàkadì. Wọn yóò rí bí aláìsí àti bí aláìjámọ́ nǹkan kan, àwọn tí ń bá ọ jagun. Nítorí pé èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, “Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.” Má fòyà, ìwọ Jékọ́bù kòkòrò mùkúlú, ẹ̀yin ọkùnrin Ísírẹ́lì. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́,’ ni àsọjáde Jèhófà, àní Olùtúnnirà rẹ, Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Aísáyà 41:11-14.
16 Àwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì ò ní borí o. Ńṣe ni ojú yóò ti àwọn tí ń gbaná jẹ mọ́ Ísírẹ́lì. Àwọn tí ń bá a jà yóò ṣègbé. Òótọ́ ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn lè dà bí aláìlágbára, tí kò lè gba ara rẹ̀, bíi kòkòrò mùkúlú tó ń rá pálá nínú erùpẹ̀, àmọ́ Jèhófà yóò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ìṣírí gidi lèyí mà jẹ́ o nínú gbogbo “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí tí àwọn Kristẹni tòótọ́ ń dojú kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àtakò àwọn tó kanlẹ̀ pinnu láti gbógun tì wọ́n! (2 Tímótì 3:1) Ìlérí Jèhófà mà sì fúnni lókun gan-an o, pàápàá tí ìkọlù Sátánì, ẹni tí àsọtẹ́lẹ̀ pè ní “Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù” máa tó wáyé! Nígbà tí Gọ́ọ̀gù bá ń gbéjà kò wọ́n burúkú-burúkú, bíi kòkòrò mùkúlú tí kò lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀ ni àwọn èèyàn Jèhófà yóò ṣe rí, ìyẹn bí àwọn èèyàn tí “ń gbé láìsí ògiri,” tí wọn kò sì ní “ọ̀pá ìdábùú àti àwọn ilẹ̀kùn pàápàá.” Síbẹ̀, kò ní sídìí fún àwọn tó ní ìrètí nínú Jèhófà láti máa gbọ̀n jìnnìjìnnì. Olódùmarè fúnra rẹ̀ ni yóò jà láti gbà wọ́n.—Ìsíkíẹ́lì 38:2, 11, 14-16, 21-23; 2 Kọ́ríńtì 1:3.
Ìtùnú fún Ísírẹ́lì
17, 18. Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe bí Ísírẹ́lì yóò ṣe gba agbára, ìmúṣẹ wo ló sì dá wa lójú pé yóò ní?
17 Jèhófà ń bá a lọ láti máa fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ìtùnú, ó ní: “Wò ó! Mo ti ṣe ọ́ ní ohun èlò ìpakà, ohun èlò ìpakà tuntun tí ó ní eyín olójú méjì. Ìwọ yóò tẹ àwọn òkè ńláńlá mọ́lẹ̀, ìwọ yóò sì fọ́ wọn túútúú; àwọn òkè kéékèèké ni ìwọ yóò sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìyàngbò. Ìwọ yóò fẹ́ wọn bí ọkà, àní ẹ̀fúùfù yóò sì gbé wọn lọ, ìjì ẹlẹ́fùúùfù pàápàá yóò sì gbá wọn lọ sí ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwọ fúnra rẹ yóò sì kún fún ìdùnnú nínú Jèhófà. Ìwọ yóò máa fi Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì ṣògo nípa ara rẹ.”—Aísáyà 41:15, 16.
18 Ísírẹ́lì yóò gba agbára tí yóò fi lè dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó dà bí òkè yìí, tí yóò sì borí wọn nípa tẹ̀mí. Nígbà tí Ísírẹ́lì bá sì padà dé láti ìgbèkùn, yóò ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó ń gbìyànjú láti dènà iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì àti odi Jerúsálẹ́mù. (Ẹ́sírà 6:12; Nehemáyà 6:16) Àmọ́ ara “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ni ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò ti ṣẹ lọ́nà kíkọyọyọ. (Gálátíà 6:16) Jésù ṣèlérí fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé: “Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun, tí ó sì pa àwọn iṣẹ́ mi mọ́ títí dé òpin ni èmi yóò fún ní ọlá àṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì fi ọ̀pá irin ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn ènìyàn tó bẹ́ẹ̀ tí a óò fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ bí àwọn ohun èlò amọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti gbà láti ọwọ́ Baba mi.” (Ìṣípayá 2:26, 27) Ó dájú pé ìgbà ń bọ̀ tí àwọn arákùnrin Jésù tó jíǹde sí ògo ti ọ̀run yóò lọ́wọ́ nínú pípa àwọn ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run run.—2 Tẹsalóníkà 1:7, 8; Ìṣípayá 20:4, 6.
19, 20. Kí ni Aísáyà kọ nípa ìmúbọ̀sípò Ísírẹ́lì sí ibi ẹlẹ́wà, báwo sì ni èyí ṣe ṣẹ?
19 Jèhófà wá lo èdè àpèjúwe wàyí láti fi mú kí ìlérí tí ó ṣe láti mú ìtura bá àwọn èèyàn rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti àwọn òtòṣì ń wá omi, ṣùgbọ́n kò sí rárá. Àní ahọ́n wọn ti gbẹ nítorí òùngbẹ. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò dá wọn lóhùn. Èmi, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, kì yóò fi wọ́n sílẹ̀. Lórí àwọn òkè kéékèèké dídán borokoto, èmi yóò ṣí àwọn odò, àti ní àárín àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì, èmi yóò ṣí àwọn ìsun. Èmi yóò sọ aginjù di adágún omi tí ó kún fún esùsú, èmi yóò sì sọ ilẹ̀ aláìlómi di àwọn orísun omi. Aginjù ni èmi yóò fìdí igi kédárì, igi bọn-ọ̀n-ní àti igi mátílì àti igi òróró kalẹ̀ sí. Pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ni èmi yóò fi igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì sí lẹ́ẹ̀kan náà; kí àwọn ènìyàn lè rí, kí wọ́n sì mọ̀, kí wọ́n sì kọbi ara sí i, kí wọ́n sì ní ìjìnlẹ̀ òye lẹ́ẹ̀kan náà, pé ọwọ́ Jèhófà gan-an ni ó ṣe èyí, àti pé Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì tìkára rẹ̀ ni ó dá a.”—Aísáyà 41:17-20.
20 Olú ìlú orílẹ̀-èdè tó lọ́rọ̀ tó sì tún jẹ́ agbára ayé ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn ń gbé lóòótọ́, àmọ́ lójú tiwọn, bí aṣálẹ̀ aláìlómi ló ṣe rí. Bọ́ràn ṣe rí lára Dáfídì nígbà tó ń sá pamọ́ fún Sọ́ọ̀lù Ọba ló ṣe rí lára àwọn náà. Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti padà sí Júdà láti lọ tún tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́ ní Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ìsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Jèhófà alára sì bù kún wọn. Nínú àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tí Aísáyà sọ lẹ́yìn èyí, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ó dájú pé Jèhófà yóò tu Síónì nínú. Ó dájú pé òun yóò tu gbogbo ibi ìparundahoro rẹ̀ nínú, òun yóò sì ṣe aginjù rẹ̀ bí Édẹ́nì àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ rẹ̀ bí ọgbà Jèhófà.” (Aísáyà 51:3) Èyí ṣẹlẹ̀ ní ti gidi lẹ́yìn tí àwọn Júù padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn.
21. Ìmúbọ̀sípò wo ló wáyé lásìkò òde òní, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú?
21 Ohun tó jọ èyí ṣẹlẹ̀ lásìkò òde òní nígbà tí Kírúsì Ńlá náà, Kristi Jésù, dá àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nídè kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí, kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu láti mú ìsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Párádísè tẹ̀mí tó ní ìpèsè yanturu, ọgbà Édẹ́nì ìṣàpẹẹrẹ, ni wọ́n fi jíǹkí àwọn olóòótọ́ wọ̀nyẹn. (Aísáyà 11:6-9; 35:1-7) Láìpẹ́, nígbà tí Ọlọ́run bá pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run, gbogbo ilẹ̀ ayé yóò yí padà di Párádísè ní ti gidi, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣèlérí fún aṣebi tó wà lórí òpó igi yẹn.—Lúùkù 23:43.
Jèhófà Pe Àwọn Ọ̀tá Ísírẹ́lì Níjà
22. Ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà tún sọ láti fi pe àwọn orílẹ̀-èdè níjà?
22 Jèhófà wá padà sórí àríyànjiyàn tó wà láàárín òun àti àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn òrìṣà wọn, ó ní: “‘Ẹ mú ọ̀ràn àríyànjiyàn yín wá síwájú,’ ni Jèhófà wí. ‘Ẹ gbé ìjiyàn yín jáde,’ ni Ọba Jékọ́bù wí. ‘Ẹ gbé e jáde kí ẹ sì sọ àwọn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ fún wa. Àwọn ohun àkọ́kọ́—ohun tí wọ́n jẹ́—ẹ sọ, kí a lè fi ọkàn-àyà wa sí i, kí a sì mọ ọjọ́ ọ̀la wọn. Tàbí kẹ̀, ẹ mú kí a gbọ́, àní àwọn ohun tí ń bọ̀ wá. Ẹ sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ lẹ́yìnwá ọ̀la, kí a lè mọ̀ pé ọlọ́run ni yín. Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ kí ẹ ṣe rere tàbí kí ẹ ṣe búburú, kí a lè wò yí ká, kí a sì rí i lẹ́ẹ̀kan náà. Wò ó! Ohun tí kò sí ni yín, àṣeyọrí yín kò sì jámọ́ nǹkan kan. Ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yàn yín.’” (Aísáyà 41:21-24) Ǹjẹ́ àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ pípé pérépéré kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn ní ìmọ̀ tó ré kọjá ti ẹ̀dá ènìyàn? Bí wọ́n bá lè ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé ó yẹ kí nǹkan kan sáà tẹ̀yìn rẹ̀ yọ, yálà rere ni o tàbí búburú, tí yóò ti ohun tí wọ́n sọ lẹ́yìn. Ní tòdodo ṣá o, àwọn òrìṣà ò lè gbé ohunkóhun ṣe, ńṣe ni wọ́n dà bí ohun tí kò tilẹ̀ sí rárá.
23. Èé ṣe tí Jèhófà fi gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ bẹnu àtẹ́ lu òrìṣà léraléra bẹ́ẹ̀?
23 Láyé òde òní, àwọn kan lè máa ṣe kàyéfì nípa ìdí tí Jèhófà fi lo àkókò púpọ̀ bẹ́ẹ̀ lórí bíbẹnu àtẹ́ lu ìwà òmùgọ̀ tí ń bẹ nínú ìbọ̀rìṣà bí ó ti gbẹnu Aísáyà àti àwọn wòlíì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sọ ọ́. Jíjẹ́ tí àwọn òrìṣà tí èèyàn ṣe jẹ́ òtúbáńtẹ́ lè dà bíi pé ó hàn kedere sí ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní. Ṣùgbọ́n bí àwọn èèyàn bá ti gbé ọ̀wọ́ ìgbàgbọ́ èké kan kalẹ̀ pẹ́nrẹ́n, tó sì ti gbilẹ̀ káàkiri, ó máa ń nira láti fà á tu lọ́kàn àwọn tó gbà á gbọ́. Ọ̀pọ̀ ohun tí àwọn èèyàn gbà gbọ́ lóde òní pẹ̀lú kò mọ́gbọ́n dání rárá, ńṣe ló dà bíi tàwọn tó gbà gbọ́ pé ère tí kò lẹ́mìí jẹ́ ọlọ́run lóòótọ́. Síbẹ̀, ńṣe làwọn èèyàn ń wonkoko mọ́ àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yẹn, láìka gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé téèyàn lè ṣe sí láti jẹ́ kí wọ́n rí i pé kò tọ̀nà. Ìgbà tí àwọn kan bá tó gbọ́ òtítọ́ ọ̀rọ̀ léraléra ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa ń rí ọgbọ́n tí ń bẹ nínú gbígbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
24, 25. Ọ̀rọ̀ wo ni Jèhófà tún sọ nípa Kírúsì, àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn wo sì ni èyí mú wa rántí?
24 Jèhófà tún wá sọ̀rọ̀ nípa Kírúsì, ó ní: “Mo ti gbé ẹnì kan dìde láti àríwá, yóò sì wá. Láti yíyọ oòrùn ni yóò ti ké pe orúkọ mi. Yóò sì wá sórí àwọn ajẹ́lẹ̀ bí ẹni pé amọ̀ ni wọ́n àti gan-an gẹ́gẹ́ bí amọ̀kòkò tí ń tẹ ohun èlò rírin mọ́lẹ̀.” (Aísáyà 41:25)d Jèhófà kò dà bí àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè, alèwílèṣe lòun ní tiẹ̀. Nígbà tí Ọlọ́run bá mú Kírúsì wá láti ìlà oòrùn, láti “yíyọ oòrùn,” yóò tipa bẹ́ẹ̀ fi agbára rẹ̀ hàn pé òun lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ kí òun sì darí ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la lọ́nà tí àsọtẹ́lẹ̀ òun yóò fi ṣẹ.
25 Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí mú wa rántí àsọtẹ́lẹ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù fi ṣàpèjúwe àwọn ọba kan tí nǹkan kan máa mú kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ lásìkò tiwa. A kà á ní Ìṣípayá 16:12 pé a ó palẹ̀ ọ̀nà mọ́ “fun àwọn ọba láti ibi yíyọ oòrùn.” Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi kúkú ni àwọn ọba yẹn, kì í ṣe ẹlòmíràn. Gẹ́lẹ́ bí Kírúsì ṣe dá àwọn èèyàn Ọlọ́run nídè nígbà náà lọ́hùn-ún ni àwọn ọba tó lágbára ńláǹlà jù ú lọ yìí yóò ṣe pa àwọn ọ̀tá Jèhófà run, tí wọn yóò sì ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ̀ gba inú ìpọ́njú ńlá bọ́ sínú ayé tuntun òdodo.—Sáàmù 2:8, 9; 2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 7:14-17.
Jèhófà Lọ̀gá!
26. Ìbéèrè wo ni Jèhófà wá béèrè wàyí, ǹjẹ́ ó sì rí èsì kankan gbà?
26 Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà kéde òtítọ́ náà pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́. Ó béèrè pé: “Ta ni ó ti sọ ohunkóhun láti ìbẹ̀rẹ̀, kí a lè mọ̀, tàbí láti àwọn ìgbà tí ó ti kọjá, kí a lè sọ pé, ‘Ó tọ̀nà’? Ní ti tòótọ́, kò sí ẹni tí ó sọ ọ́. Ní ti tòótọ́, kò sí ẹni tí ó mú kí ènìyàn gbọ́. Ní ti tòótọ́, kò sí ẹni tí ó gbọ́ àsọjáde yín kankan.” (Aísáyà 41:26) Òrìṣà kankan ò kéde pé aṣẹ́gun kan ń bọ̀ wá dá àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé òun nídè. Ohun aláìlẹ́mìí ni gbogbo òrìṣà wọ̀nyẹn, ṣe ni wọ́n yadi. Wọn kì í ṣe ọlọ́run rárá ni.
27, 28. Òtítọ́ pàtàkì wo ni àwọn ẹsẹ tó parí Aísáyà orí kọkànlélógójì tẹnu mọ́, kìkì àwọn èèyàn wo ló sì ń pòkìkí èyí?
27 Lẹ́yìn tí Aísáyà kéde ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tó pabanbarì yìí, ó wá kúkú la òtítọ́ ọ̀rọ̀ pàtàkì kan mọ́lẹ̀, ó ní: “Ẹni àkọ́kọ́ wà, tí ó wí fún Síónì pé: ‘Wò ó! Àwọn rèé!’ èmi yóò sì fún Jerúsálẹ́mù ní olùmú ìhìn rere wá. Mo sì ń wò, kò sì sí ènìyàn kankan; lára àwọn wọ̀nyí, kò sì sí ẹni tí ń fúnni ní ìmọ̀ràn. Mo sì ń bi wọ́n léèrè ṣáá, kí wọ́n lè fèsì. Wò ó! Gbogbo wọn jẹ́ ohun tí kò sí. Iṣẹ́ wọn kò jámọ́ nǹkan kan. Àwọn ère dídà wọn jẹ́ ẹ̀fúùfù àti òtúbáńtẹ́.”—Aísáyà 41:27-29.
28 Jèhófà ni ẹni àkọ́kọ́. Òun lọ̀gá! Òun ni Ọlọ́run tòótọ́ tó kéde ìdáǹdè fún àwọn èèyàn rẹ̀, tó sọ ìhìn rere fún wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí tirẹ̀ nìkan ló sì ń polongo ìtóbilọ́lá rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè. Jèhófà wá bẹnu àtẹ́ lu àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé ìbọ̀rìṣà, ó fi wọn ṣẹlẹ́yà, ó ní àwọn òòṣà wọn jẹ́ “ẹ̀fúùfù àti òtúbáńtẹ́.” Ìdí alágbára tó fi yẹ kéèyàn rọ̀ mọ́ Ọlọ́run tòótọ́ mà rèé o! Àfi Jèhófà nìkan ṣoṣo ló tó gbẹ́kẹ̀ lé láìmikàn.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
c Ní ti ẹni tí í ṣe Kírúsì Ńlá tó dá “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” nídè kúrò ní ìgbèkùn nípa tẹ̀mí lọ́dún 1919, Jésù Kristi tó gorí àlééfà gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run láti 1914 kúkú ni.—Gálátíà 6:16.
d Lóòótọ́ o, ìhà ìlà oòrùn ni ìlú ìbílẹ̀ Kírúsì wà sí Bábílónì, àmọ́, nígbà tó fi máa wá gbéjà ko ìlú Bábílónì níkẹyìn, ìhà àríwá ló ti wá, láti Éṣíà Kékeré.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé abọ̀rìṣà ni Kírúsì, Ọlọ́run yàn án láti ṣe iṣẹ́ rẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Àwọn ère tí kò lẹ́mìí làwọn orílẹ̀-èdè gbẹ́kẹ̀ lé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Bí “ohun èlò ìpakà” ni Ísírẹ́lì yóò ṣe ‘fọ́ àwọn òkè túútúú’