Ǹjẹ́ o Mọrírì Ìrànlọ́wọ́ Jèhófà?
“Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà.”—HÉBÉRÙ 13:6.
1, 2. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé láti gbà kí Jèhófà ràn wá lọ́wọ́ kó sì máa tọ́ wa sọ́nà nínú ìgbésí ayé wa?
FOJÚ inú wò ó pé ilẹ̀ ti ṣù, ò sì ń gba ọ̀nà kan tí o kò gbà rí, ìwọ nìkan kọ́ ló ń dá rìn ò, ẹnì kan tó mọ̀ ọ̀nà náà dáadáa ti gbà láti bá ọ lọ. Ẹni tẹ́ ẹ jọ ń lọ yìí mọ ọ̀nà yẹn dáadáa. Ó mọ ibi tó ò ń lọ ó sì mọ ọ̀nà tó débẹ̀, kò tiẹ̀ kánjú rárá, ńṣe ló rọra fi sùúrù ń bá ọ rìn lọ. Nígbà tó rí i pé ò ń já sí kòtò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó ń fi ibi tó o máa gbà hàn ọ́, kó o má bàa ṣìnà kó o má sì já sí kòtò mọ́. Ṣé wàá sọ pé kó má ràn ọ́ lọ́wọ́? Ó dájú pé o ò ní sọ bẹ́ẹ̀! Nítorí o ò fẹ́ ṣèṣe.
2 Ojú ọ̀nà kan tó léwu ló wà níwájú àwa tá a jẹ́ Kristẹni láti rìn. Ǹjẹ́ ó wá yẹ ká dá nìkan rin ọ̀nà híhá yẹn? (Mátíù 7:14) Rárá o, Bíbélì fi hàn pé Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Afinimọ̀nà gíga jù lọ gbà pé ká máa bá òun rìn. (Jẹ́nẹ́sísì 5:24; 6:9) Ǹjẹ́ Jèhófà ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń rin ìrìn yìí? Ó sọ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’” (Aísáyà 41:13) Bíi ti afinimọ̀nà tá a mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe wa yẹn, Jèhófà sọ pé òun máa ran àwọn tó bá fẹ́ bá òun rìn lọ́wọ́, ó sì ní kí wọ́n wá bá òun dọ́rẹ̀ẹ́. Ó dájú pé kò sẹ́ni tí kò ní fẹ́ kó ran òun lọ́wọ́ nínú wa!
3. Àwọn ìbéèrè wo la ó gbé yẹ̀ wò bá a ṣe ń bá ìjíròrò yìí lọ?
3 Nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, a jíròrò ọ̀nà mẹ́rin tí Jèhófà gbà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láyé ọjọ́un. Ǹjẹ́ ó máa ń ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ bákan náà lóde òní? Báwo la sì ṣe lè rí i dájú pé a gba irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyẹn yẹ̀ wò. Tá a bá gbé àwọn ìbéèrè náà yẹ̀ wò, yóò túbọ̀ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ wa.—Hébérù 13:6.
Ìrànlọ́wọ́ Àwọn Áńgẹ́lì
4. Kí nìdí tí ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fi lè balẹ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ń ti àwọn lẹ́yìn lóde òní?
4 Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì ń ran àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lọ́wọ́ lóde òní? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lóòótọ́, wọn kì í fara han kí wọ́n tó yọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ nínú ewu. Kódà lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì pàápàá, wọn kì í sábà fara han àwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́. Bíi tòde òní, ọ̀pọ̀ ju lọ ohun tí wọ́n ṣe nígbà yẹn lọ́hùn-ún làwọn èèyàn ò fojú rí. Síbẹ̀, ọkàn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ń balẹ̀ gan-an nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn áńgẹ́lì ṣe tán láti ràn wọ́n lọ́wọ́. (2 Àwọn Ọba 6:14-17) Bó ṣe yẹ kí ọkàn tiwa náà balẹ̀ nìyẹn.
5. Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà lóde òní?
5 Àwọn áńgẹ́lì Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ pàtàkì kan tá a ń ṣe. Iṣẹ́ wo nìyẹn? A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú Ìṣípayá 14:6, tó kà pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn.” Ó hàn gbangba pé “ìhìn rere àìnípẹ̀kun” yìí wé mọ́ “ìhìn rere ìjọba” tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘a ó sì wàásù rẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’ kí òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí tó dé. (Mátíù 24:14) Àmọ́ kì í ṣe pé àwọn áńgẹ́lì ń wàásù ní tààrà o. Àwa èèyàn ni Jésù gbé iṣẹ́ pàtàkì yìí lé lọ́wọ́. (Mátíù 28:19, 20) Ǹjẹ́ inú wa ò dùn láti mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì mímọ́, ìyẹn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó gbọ́n tó sì lágbára ń ràn wá lọ́wọ́ bá a ti ń ṣe iṣẹ́ náà?
6, 7. (a) Kí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń ti iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lẹ́yìn? (b) Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé àwọn áńgẹ́lì Jèhófà yóò tì wá lẹ́yìn?
6 Ẹ̀rí hàn gbangba pé àwọn áńgẹ́lì ń ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń gbọ́ pé nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn, wọ́n rí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́ láti rí òtítọ́. Irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ máa ń wáyé lọ́pọ̀ ìgbà ju ohun téèyàn á fi sọ pé ńṣe ló ṣèèṣì rí bẹ́ẹ̀. Ìrànlọ́wọ́ àwọn áńgẹ́lì yìí ti mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn kẹ́kọ̀ọ́ láti ṣe ohun tí “áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run” polongo rẹ̀ pé: “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.”—Ìṣípayá 14:7.
7 Ṣé o fẹ́ káwọn áńgẹ́lì alágbára wọ̀nyí máa tì ọ́ lẹ́yìn? A jẹ́ pé wàá túbọ̀ máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lójú méjèèjì nìyẹn o. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Bá a ṣe ń fi gbogbo ara àti ọkàn wa ṣe iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà yàn fún wa yìí, ó dá wa lójú pé àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ á ràn wá lọ́wọ́.
Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Olórí Àwọn Áńgẹ́lì
8. Ipò gíga wo ni Jésù wà lókè ọ̀run, kí sì nìdí tíyẹn fi fi wá lọ́kàn balẹ̀?
8 Jèhófà tún pèsè ìrànlọ́wọ́ áńgẹ́lì mìíràn tó yàtọ̀. Ìṣípayá 10:1 ṣàpèjúwe àgbàyanu “áńgẹ́lì alágbára” kan tí “ojú rẹ̀ . . . dà bí oòrùn.” Ó hàn gbangba pé Jésù Kristi tí a ṣe lógo nínú agbára lọ́run ni áńgẹ́lì tó wà nínú ìran yìí. (Ìṣípayá 1:13, 16) Ṣé áńgẹ́lì ni Jésù lóòótọ́? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, nítorí pé òun ni olú-áńgẹ́lì. (1 Tẹsalóníkà 4:16) Kí ni olú-áńgẹ́lì túmọ̀ sí? Ó túmọ̀ sí “olórí àwọn áńgẹ́lì.” Jésù ló lágbára jù lọ nínú gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀mí tí Jèhófà ní. Jèhófà sì ti fi ṣe aláṣẹ lórí gbogbo àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rẹ̀. Olú-áńgẹ́lì yìí ń ràn wá lọ́wọ́ gan-an. Láwọn ọ̀nà wo?
9, 10. (a) Báwo ni Jésù ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀? (b) Ìrànlọ́wọ́ wo la lè rí nínú àpẹẹrẹ Jésù?
9 Àpọ́sítélì Jòhánù tó ti di arúgbó kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi, ẹni tí í ṣe olódodo.” (1 Jòhánù 2:1) Kí nìdí tí Jòhánù fi sọ pé Jésù ni “olùrànlọ́wọ́” wà àgàgà nígbà tá a “bá dá ẹ̀ṣẹ̀”? Ó dára, ojoojúmọ́ là ń dẹ́ṣẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ sì máa ń yọrí sí ikú. (Oníwàásù 7:20; Róòmù 6:23) Àmọ́, Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Baba wa aláàánú, ó ń bá wa bẹ̀bẹ̀. Gbogbo wa la nílò irú ìrànlọ́wọ́ yẹn. Báwo la ṣe lè rí i gbà? A gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ká sì tọrọ ìdáríjì lọ́lá ẹbọ Jésù. A tún gbọ́dọ̀ rí i pé a ò dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́.
10 Yàtọ̀ sí pé Jésù kú nítorí wa, ó tún fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa. (1 Pétérù 2:21) Àpẹẹrẹ rẹ̀ ń tọ́ wá sọ́nà, ó si ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣọ́ ìrìn wa ká lè yẹra fún dídá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo ká sì máa múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn. Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé à ń rí irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gbà? Jésù ṣèlérí fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé a ó fún wọn ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn.
Ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́
11, 12. Kí ni ẹ̀mí Jèhófà, báwo ló ṣe lágbára tó, kí sì nìdí tá a fi nílò rẹ̀ lóde òní?
11 Jésù ṣèlérí pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé, ẹ̀mí òtítọ́ náà, èyí tí ayé kò lè gbà.” (Jòhánù 14:16, 17) “Ẹ̀mí òtítọ́” yìí, tàbí ẹ̀mí mímọ́, kì í ṣe ènìyàn kan bí kò ṣe agbára kan, ìyẹn agbára ìṣiṣẹ́ Jèhófà fúnra rẹ̀. Agbára náà kò láàlà. Agbára yìí ni Jèhófà fi dá ọ̀run òun ayé, òun ló fi ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu kíkàmàmà, òun ni Jèhófà si lò láti ṣí àwọn ohun tó fẹ́ ṣe payá nínú ìran tó fi han àwọn èèyàn. Ṣé bí Jèhófà ò ṣe lo ẹ̀mí rẹ̀ ní irú àwọn ọ̀nà yẹn mọ́ lónìí wá túmọ̀ sí pé a ò nílò rẹ̀?
12 Rárá o! “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí gan-an la nílò agbára náà ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (2 Tímótì 3:1) Òun ló ń fún wa lókun láti fara da àwọn àdánwò. Ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ àtàtà tó ń mú ká sún mọ́ Jèhófà àtàwọn arákùnrin àti arábìnrin wa nípa tẹ̀mí. (Gálátíà 5:22, 23) Báwo la ṣe lè wá jàǹfààní látinú àgbàyanu ìrànlọ́wọ́ tó ń wá látọ̀dọ̀ Jèhófà yìí?
13, 14. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kó dá wa lójú pé tinútinú ni Jèhófà fi máa ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀? (b) Irú ìwà wo la lè máa hù táá fi hàn pé a ò fi gbogbo ara nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́?
13 Lákọ̀ọ́kọ́, a ní láti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́. Jésù sọ pé “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!” (Lúùkù 11:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, kò sí Baba tó ṣeé fara tì bíi Jèhófà. Tá a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ tá ò sì ṣiyèméjì, ó dájú pé kò ní fi ẹ̀bùn yìí dù wá. Ìbéèrè tó wá yẹ ká bi ara wa ni pé, Ǹjẹ́ a máa ń bẹ̀bẹ̀ pé kó fún wa ní ẹ̀mí mímọ́? Ńṣe ló yẹ ká máa bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀mí mímọ́ yìí nínú àdúrà wa ojoojúmọ́.
14 Èkejì, a máa ń rí ẹ̀bùn yìí gbà tá a bá ṣiṣẹ́ níbàámu pẹ̀lú rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ: Ká ní Kristẹni kan ń sa gbogbo ipá rẹ̀ láti rí i pé òun ò wo àwọn ohun arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè. Ó ti gbàdúrà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ran òun lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú àṣà ẹlẹ́gbin yìí. Ó ti lọ gbàmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn Kristẹni alàgbà, wọ́n sì ti gbà á nímọ̀ràn pé kó tètè wá nǹkan ṣe sí ọ̀ràn náà, kó má tiẹ̀ sún mọ́ tòsí irú àwọn ohun tí kò bójú mu bẹ́ẹ̀ rárá. (Mátíù 5:29) Tí kò bá ka ìmọ̀ràn wọn sí ńkọ́, tó sì ń wo irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ a lè sọ pé ó ń ṣe ohun tó wà níbàámu pẹ̀lú àdúrà tó ń gbà pé kí ẹ̀mí mímọ́ ran òun lọ́wọ́? Ǹjẹ́ kì í ṣe pé ó fẹ́ ba ẹ̀mí Ọlọ́run nínú jẹ́ kó sì tipa bẹ́ẹ̀ kùnà àtirí ẹ̀bùn yìí gbà nìyẹn? (Éfésù 4:30) Láìsí àní-àní, gbogbo wa ló yẹ kó ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti rí i dájú pé à ń rí ìrànlọ́wọ́ àgbàyanu yìí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà.
Ìrànlọ́wọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
15. Báwo la ṣe lè fi hàn pé a ò ka Bíbélì sí ìwé kan ṣáá?
15 Ó ti pẹ́ gan-an tí Bíbélì ti jẹ́ orísun ìrànlọ́wọ́ fún àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Jèhófà. Dípò tá a ó fi máa rò pé ìwé kan ṣáá ni Bíbélì jẹ́, ó yẹ ká máa rántí pé ìwé tó lágbára láti ràn wá lọ́wọ́ ni. Àmọ́, ó gba ìsapá kéèyàn tó lè rí ìrànlọ́wọ́ yẹn gbà. A ní láti rí i pé à ń ka Bíbélì lójoojúmọ́.
16, 17. (a) Báwo ni Sáàmù 1:2, 3 ṣe ṣàpèjúwe àǹfààní tó wà nínú kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (b) Báwo ni Sáàmù 1:3 ṣe fi hàn pé a gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ àṣekára?
16 Ohun tí Sáàmù 1:2, 3 sọ nípa èèyàn Ọlọ́run ni pé: “Inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” Ǹjẹ́ o lóye ohun tí ibẹ̀ yẹn ń sọ gan-an? Ó rọrùn láti ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn kéèyàn sì sọ pé ńṣe ni wọ́n kàn fẹ́ ká fọkàn yàwòrán ibì kan tó lẹ́wà tó tutù nini, ìyẹn abẹ́ igi ràgàjì kan tó wà lẹ́bàá odò. Ẹ ò rí i pé irú ibi bẹ́ẹ̀ á dùn ún tẹ́ ẹní sí kéèyàn sì rẹjú níbẹ̀ lọ́sàn-án! Àmọ́ kì í ṣe pé sáàmù yìí fẹ́ ká máa ronú nípa ìsinmi. Ohun tó yàtọ̀ síyẹn pátápátá ló ń sọ, ọ̀rọ̀ nípa ṣíṣe iṣẹ́ àṣekára ló ń sọ. Lọ́nà wo?
17 Kíyè sí i pé igi tá a ń sọ níhìn-ín kì í wulẹ̀ ṣe igi ràgàjì kan ṣáá tó kàn ṣàdédé wà lẹ́bàá odò kan. Igi tó ń so èso ni, tí wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ “gbìn” síbi tí wọ́n fẹ́ kó wà, ìyẹn ‘lẹ́bàá àwọn ìṣàn omi.’ Báwo ni igi kan ṣoṣo ṣe lè wà lẹ́bàá àwọn ìṣàn omi tó ju ẹyọ kan lọ? Ó dára, ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan tó ní ọgbà igi eléso gbẹ́ àwọn kòtò tí omi á máa gbà ṣàn dé ìdí àwọn igi tó gbìn. Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ yìí yé wa báyìí, àbí? Tí àwa náà bá so èso bíi ti igi yìí nípa tẹ̀mí, á jẹ́ pé ẹnì kan ti sapá gidigidi láti ràn wá lọ́wọ́ nìyẹn. Inú ètò àjọ kan tó ń mú omi òtítọ́ mímọ́ gaara wá fún wa la wà, àmọ́ a gbọ́dọ̀ ṣe ipa tiwa. A gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti máa mu omi ṣíṣeyebíye yìí, ká máa ṣe àṣàrò, ká sì máa ṣe ìwádìí nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kí òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè dé inú ọkàn wa. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà yóò so èso rere.
18. Kí ló yẹ ká ṣe ká tó lè rí àwọn ìdáhùn tó bá Bíbélì mu sí àwọn ìbéèrè wa?
18 Bíbélì ò lè ṣe wá láǹfààní kankan tá a bá kàn gbé e síbi ìkówèésí tá a ò bá kà á. Bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì kì í ṣe ìwé idán tá a lè máa retí pé bá a tiẹ̀ di ojú wa, á fúnra rẹ̀ ṣí síbi tó bá wù ú, a ó sì rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa. Nígbà tá a bá fẹ ṣe ìpinnu, a ní láti walẹ̀ láti rí “ìmọ̀ Ọlọ́run” bí ẹni tó ń wá ìṣúra kan tí a fi pa mọ́. (Òwe 2:1-5) Ó máa ń dára gan-an láti ṣe ìwádìí dáadáa nínú àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ká lè rí àwọn ìmọ̀ràn tó bá Ìwé Mímọ́ mu lórí àwọn ọ̀ràn kan tó ń jẹ wá lọ́kàn. Ọ̀pọ̀ àwọn ìwé tó ní ọ̀rọ̀ Bíbélì nínú ló wà tá a lè fi ṣe ìwádìí yìí. Bá a ṣe ń lo àwọn ìwé wọ̀nyí láti wá ọgbọ́n tó ṣeyebíye nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ńṣe là ń jàǹfààní ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.
Ìrànlọ́wọ́ Látọ̀dọ̀ Àwọn Ta A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́
19. (a) Kí nìdí tá a fi lè gbà pé àwọn àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! jẹ́ ìrànlọ́wọ́ tó wá látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́? (b) Ọ̀nà wo ni àpilẹ̀kọ kan látinú àwọn ìwé ìròyìn wa ti gbà ràn ọ́ lọ́wọ́?
19 Àwọn èèyàn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń ran ara wọn lọ́wọ́ dáadáa. Ṣé èrò Jèhófà lórí ọ̀ràn yìí ti wá yí padà ni? Rárá o. Ó dájú pé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè rántí àwọn àkókò kan táwọn onígbàgbọ́ bíi tiwa ràn wá lọ́wọ́ lákòókò tá a nílò ìrànlọ́wọ́ náà gan-an. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè rántí àwọn àpilẹ̀kọ kan nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tó tù ọ́ nínú nígbà tó o nílò ìtùnú tàbí tó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro kan tàbí láti kojú àwọn wàhálà kan tó fẹ́ fi ìgbàgbọ́ rẹ sínú ewu? Jèhófà pèsè ìrànlọ́wọ́ yẹn fún ọ nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” tó ti yàn láti pèsè “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”—Mátíù 24:45-47.
20. Àwọn ọ̀nà wo làwọn Kristẹni alàgbà ń gbà fi hàn pé “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” làwọn?
20 Àmọ́ ṣá o, ìrànlọ́wọ́ tá a máa ń rí gbà látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ máa ń wá lọ́nà tó ṣe tààrà jùyẹn lọ lọ́pọ̀ ìgbà. Alàgbà kan lè sọ àsọyé kan tó wọ̀ wá lọ́kàn gan-an, tàbí kí ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn tó wá ṣe sọ́dọ̀ wa ṣèrànwọ́ fún wa lásìkò tí nǹkan ò rọgbọ fún wa, tàbí kó fún wa ní ìmọ̀ràn tó ràn wá lọ́wọ́ láti rí ibi tá a kù díẹ̀ káàtó sí àti bá a ṣe lè ṣàtúnṣe. Kristẹni kan tó mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí alàgbà kan ṣe fún un sọ pé: “Nígbà tá a jọ wà lóde ẹ̀rí, o sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú kí n sọ ohun tó ń jẹ mí lọ́kàn. Mo ti gbàdúrà sí Jèhófà kílẹ̀ ọjọ́ yẹn tó mọ́ pé kó jẹ́ kí n rí ẹnì kan tí mo lè sọ ohun tó ń jẹ́ mi lọ́kàn fún. Ọjọ́ yẹn gan-an ni arákùnrin yìí bá mi sọ̀rọ̀ tìyọ́nútìyọ́nú. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà ń ràn mí lọ́wọ́ láti ọjọ́ pípẹ́. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó rán alàgbà yìí sí mi.” Gbogbo àwọn ọ̀nà báyẹn làwọn Kristẹni alàgbà gbà ń fi hàn pé “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” làwọn, èyí tí Jèhófà tipasẹ̀ Jésù Kristi ọmọ rẹ̀ pèsè láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fara dà á ní ojú ọ̀nà tó lọ sí ìyè.—Éfésù 4:8.
21, 22. (a) Báwo ni nǹkan á ṣe rí nígbà táwọn tó wà nínú ìjọ bá ń fi ìmọ̀ràn tó wà nínú Fílípì 2:4 sílò? (b) Kí nìdí táwọn ìrànlọ́wọ́ kéékèèké pàápàá fi ṣe pàtàkì?
21 Yàtọ̀ sáwọn alàgbà, Kristẹni tòótọ́ kọ̀ọ̀kan ní láti fi àṣẹ tí Ọlọ́run mí sí náà sílò, èyí tó sọ pé “ẹ má ṣe máa mójú tó ire ara ẹni nínú kìkì àwọn ọ̀ràn ti ara yín nìkan, ṣùgbọ́n ire ara ẹni ti àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.” (Fílípì 2:4) Nígbà táwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni bá fi ìmọ̀ràn yẹn sílò, ìwà àtàtà tó fi inú rere hàn ni wọ́n á máa hù. Bí àpẹẹrẹ, ìdílé kan kàgbákò lójijì. Bàbá kan mú ọmọ rẹ̀ obìnrin lọ sílé ìtajà. Bí wọ́n ṣe ń padà bọ̀ wá sílé ni jàǹbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀. Ọmọ náà kú, bàbá rẹ̀ sì fara pa gan-an. Nígbà tí ọkùnrin náà kọ́kọ́ dé láti ọsibítù, kò lè ṣe ohunkóhun fúnra rẹ̀. Ọkàn ìyàwó rẹ̀ náà dà rú débi pé kò lè dá nìkan máa tọ́jú rẹ̀. Ni tọkọtaya kan nínú ìjọ wọn bá ní kí àwọn tọkọtaya tó wà nínú ìbànújẹ́ yìí máa bọ̀ nílé àwọn, wọ́n sì bójú tó wọn fún ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan.
22 Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe gbogbo ìrànlọ́wọ́ ló máa ń jẹ́ ọ̀ràn irú àjálù bẹ́ẹ̀ tó sì máa ń gba pé kéèyàn ṣe oore tó pọ̀ tó yẹn. Ọ̀pọ̀ ìrànlọ́wọ́ táwọn èèyàn máa ń ṣe fún wa ló jẹ́ lórí àwọn ohun kéékèèké. Àmọ́ bó ti wù kí ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kéré tó, a mọrírì rẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ o lè rántí ìgbà kan tí ọ̀rọ̀ tí arákùnrin tàbí arábìnrin kan bá ọ sọ tàbí ohun rere kan tó ṣe fún ọ tánṣòro rẹ̀ lákòókò yẹn? Irú àwọn ọ̀nà yẹn ni Jèhófà máa ń gbà bójú tó wa.—Òwe 17:17; 18:24.
23. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìrànlọ́wọ́ tá a bá ṣe?
23 Ṣé wàá fẹ́ kí Jèhófà lò ọ́ láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lo máa yọ̀ǹda ara rẹ o. Ká sòótọ́, Jèhófà á mọrírì rẹ̀ gan-an tó o bá sapá láti ṣe bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ẹni tí ń fi ojú rere hàn sí ẹni rírẹlẹ̀, Jèhófà ni ó ń wín, Òun yóò sì san ìlòsíni rẹ̀ padà fún un.” (Òwe 19:17) Ayọ̀ ńlá la máa ní tá a bá lo ara wa fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. (Ìṣe 20:35) Àwọn tó ya ara wọn láṣo kì í ní ayọ̀ téèyàn máa ń ní tó bá ṣe irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀, ìṣírí téèyàn sì máa ń rí nígbà tó bá gba irú ìrànlọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ kì í sì í kàn wọ́n. (Òwe 18:1) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká máa wá sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé ká lè máa fún ara wa níṣìírí.—Hébérù 10:24, 25.
24. Kí nìdí tí ò fi yẹ ká ronú pé Jèhófà ti fi ohun kan dù wá nítorí pé a ò rí àwọn iṣẹ́ ìyanu pípabanbarì tó ṣe láyé ọjọ́un?
24 Ǹjẹ́ inú wa kì í dùn nígbà tá a bá ronú kan àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò sí láyé nígbà tí Jèhófà máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu pípabanbarì láti mú àwọn ète rẹ̀ ṣẹ, síbẹ̀ a ò ní láti ronú pé ó ń fi ohunkóhun dù wá. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé Jèhófà ń fún wa ní gbogbo ìrànlọ́wọ́ tá a nílò ká lè máa bá ìṣòtítọ́ wa lọ. Tí gbogbo wa bá sì ní ìforítì tá ò yẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ wa, a óò rí àwọn iṣẹ́ àrà tó ju ti ìgbàkígbà rí lọ̀ tí Jèhófà yóò ṣe! Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká mọrírì ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ń fún wa ká sì lò ó lọ́nà tó dáa, káwa náà lè sọ ohun tó wà nínú ẹṣin ọdún wa ti 2005, tó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.
Kí Lèrò Rẹ?
• Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń tipasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì pèsè ìrànlọ́wọ́ tá a nílò lóde òní?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ lóde òní?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó ní ìmísí pèsè ìrànlọ́wọ́ tá a nílò lóde òní?
• Báwo ni Jèhófà ṣe ń tipasẹ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ pèsè ìrànlọ́wọ́ ta a nílò lóde òní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Mímọ̀ tá a mọ̀ pé àwọn áńgẹ́lì ń tì wá lẹ́yìn nínú iṣẹ́ ìwàásù náà ń múnú wa dùn gan-an
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Jèhófà lè lo ọ̀kan lára àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ láti tù wá nínú