Orí Kẹta
“Àyànfẹ́ Mi, Ẹni Tí Ọkàn Mi Tẹ́wọ́ Gbà!”
1, 2. Kí ni ìdí tí àwọn Kristẹni lóde òní fi nífẹ̀ẹ́ sí orí kejìlélógójì ìwé Aísáyà?
“‘Ẹ̀YIN ni ẹlẹ́rìí mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘àní ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn.’” (Aísáyà 43:10) Ìkéde Jèhófà yìí, tí wòlíì Aísáyà kọ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, fi hàn pé àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú láyé àtijọ́ para pọ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí ó jẹ́ ẹlẹ́rìí. Ọlọ́run ti yàn wọ́n ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀. Nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá [2,600 ] ọdún lẹ́yìn náà, lọ́dún 1931, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kéde fáyé gbọ́ pé ọ̀rọ̀ kan náà yìí ṣẹ sí àwọn lára. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fi tọkàntọkàn tẹ́rí gba àwọn ẹrù iṣẹ́ tó wé mọ́ jíjẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí ilẹ̀ ayé.
2 Tọkàntara ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń fẹ́ láti ṣe ohun tó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Nítorí náà, olúkúlùkù wọn ló nífẹ̀ẹ́ sí orí kejìlélógójì ìwé Aísáyà gidigidi, nítorí pé ó ṣe àpèjúwe tó hàn kedere nípa ìránṣẹ́ tí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà àti ìránṣẹ́ tó kọ̀. Àyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ yìí àti ìmúṣẹ rẹ̀ ń fúnni ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ohun tó lè múni rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run àti èyí tó lè múni rí ìbínú rẹ̀.
“Èmi Ti Fi Ẹ̀mí Mi Sára Rẹ̀”
3. Kí ni Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa “ìránṣẹ́ mi”?
3 Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìránṣẹ́ kan tóun yóò fúnra òun yàn, ó ní: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi, tí mo dì mú ṣinṣin! Àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà! Èmi ti fi ẹ̀mí mi sára rẹ̀. Ìdájọ́ òdodo fún àwọn orílẹ̀-èdè ni ohun tí yóò mú wá. Kì yóò ké jáde tàbí kí ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, kì yóò sì jẹ́ kí a gbọ́ ohùn òun ní ojú pópó. Kò sí esùsú fífọ́ tí òun yóò ṣẹ́; àti ní ti òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó bàìbàì, òun kì yóò fẹ́ ẹ pa. Nínú òótọ́ ni òun yóò mú ìdájọ́ òdodo wá. Òun kì yóò di bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò tẹ̀ ẹ́ rẹ́ títí yóò fi gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé; òfin rẹ̀ sì ni àwọn erékùṣù pàápàá yóò máa dúró dè.”—Aísáyà 42:1-4.
4. Ta ni “àyànfẹ́” tí àsọtẹ́lẹ̀ wí, báwo la sì ṣe mọ èyí?
4 Ta ni Ìránṣẹ́ tí ibí yìí ń sọ? Ìdáhùn rẹ̀ kò fara sin rárá. A rí i pé wọ́n fa àwọn ọ̀rọ̀ yìí yọ nínú Ìhìn Rere Mátíù, Jésù Kristi ni wọ́n sì lò ó fún. (Mátíù 12:15-21) Jésù ni ààyò Ìránṣẹ́ yẹn, tó jẹ́ “àyànfẹ́.” Ìgbà wo ni Jèhófà fi ẹ̀mí rẹ̀ sára Jésù? Ọdún 29 Sànmánì Tiwa ni, nígbà tí Jésù ṣe batisí. Àkọsílẹ̀ onímìísí sọ bí batisí yẹn ṣe lọ, ó sì sọ pé bí Jésù ṣe jáde nínú omi, “ọ̀run ṣí sílẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ní ìrí ti ara bí àdàbà bà lé e, ohùn kan sì jáde wá láti inú ọ̀run pé: ‘Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.’” Bí Jèhófà ṣe fúnra rẹ̀ sọ ẹni tó jẹ́ Ìránṣẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n nìyẹn. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe lẹ́yìn náà fi hàn pé ẹ̀mí Jèhófà wà lára rẹ̀ lóòótọ́.—Lúùkù 3:21, 22; 4:14-21; Mátíù 3:16, 17.
‘Yóò Mú Ìdájọ́ Òdodo Wá fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè’
5. Kí ni ìdí tí wọ́n fi nílò àlàyé ohun tí ìdájọ́ òdodo túmọ̀ sí ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa?
5 Ńṣe ni Àyànfẹ́ Jèhófà yóò “mú” ìdájọ́ òdodo tòótọ́ “wá,” tàbí pé yóò jẹ́ kó hàn kedere. “Ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ni yóò sì mú ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 12:18) Ìyẹn gan-an sì ni wọ́n nílò ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa! Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù ti kọ́ wọn ní ìkọ́kúkọ̀ọ́ nípa ohun tí í ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo. Wọ́n ń fẹ́ di olódodo nípa títẹ̀lé àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀ tí wọ́n fi de ara wọn pinpin, àwọn fúnra wọn ló sì ṣe ọ̀pọ̀ lára òfin wọ̀nyẹn o. Ìdájọ́ òdodo wọn tó dá lórí títẹ̀lé gbogbo ọ̀rínkinniwín òfin, kò láàánú àti ìyọ́nú nínú rárá.
6. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà mú kí ìdájọ́ òdodo tòótọ́ di mímọ̀?
6 Jésù kò dà bíi tiwọn ṣá, ó fi èrò Ọlọ́run nípa ìdájọ́ òdodo hàn. Ní ọ̀nà tí Jésù gbà kọ́ni àti bó ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀, ó fi hàn pé ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ní ìyọ́nú àti àánú nínú. Ẹ sáà tiẹ̀ gbé Ìwàásù Lórí Òkè tó ṣe yẹ̀ wò. (Mátíù, orí karùn-ún sí ìkeje) Àgbà àlàyé nípa bó ṣe yẹ kéèyàn ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo mà nìyẹn o! Nígbà tí a bá ka àwọn ìtàn inú Ìhìn Rere, ǹjẹ́ bí Jésù ṣe fi ìyọ́nú hàn sí àwọn tálákà àti àwọn tí ìyà ń jẹ kì í wú wa lórí? (Mátíù 20:34; Máàkù 1:41; 6:34; Lúùkù 7:13) Ó mú ìhìn ìtùnú rẹ̀ dé ọ̀dọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn tó dà bí esùsú fífọ́ tó ti ṣẹ́po tí a sì ń gbá káàkiri. Wọ́n dà bí òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tó ń jó lọ́úlọ́ú, tí ẹ̀ṣẹ́ná ìkẹyìn tó kù fún wọn ní ìgbésí ayé sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Jésù kò ṣẹ́ “esùsú fífọ́” kankan bẹ́ẹ̀ ni kò sì fẹ́ “òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó bàìbàì” kankan pa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti oníyọ̀ọ́nú ń tu àwọn ọlọ́kàn tútù nínú.—Mátíù 11:28-30.
7. Kí ni ìdí tí àsọtẹ́lẹ̀ fi lè sọ pé Jésù ‘kì yóò ké jáde tàbí kí ó gbé ohùn rẹ̀ sókè ní ojú pópó’?
7 Àmọ́ ṣá o, kí ni ìdí tí àsọtẹ́lẹ̀ fi sọ pé Jésù ‘kì yóò ké jáde tàbí kí ó gbé ohùn rẹ̀ sókè, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò jẹ́ kí wọ́n gbọ́ ohùn òun ní ojú pópó’? Ìdí ni pé kò pariwo ara rẹ̀ káàkiri bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ayé ìgbà tirẹ̀ ti ṣe. (Mátíù 6:5) Nígbà tí ó wo adẹ́tẹ̀ kan sàn, ó sọ fún ọkùnrin tó wò sàn pé: “Rí i pé ìwọ kò sọ ohun kan fún ẹnikẹ́ni.” (Máàkù 1:40-44) Dípò tí Jésù ì bá fi wá ọ̀nà bí wọn yóò ṣe máa polongo òun káàkiri, kí àwọn èèyàn sì tipa àtamọ́-àtamọ̀ ìròyìn àtẹnudẹ́nu tí wọ́n gbọ́ nípa òun máa sọ èrò tiwọn, ńṣe ni Jésù ń fẹ́ kí àwọn èèyàn fúnra wọn tipa ẹ̀rí tó ṣe gúnmọ́ mọ̀ pé òun ni Kristi, Ìránṣẹ́ tí Jèhófà fòróró yàn.
8. (a) Báwo ni Jésù ṣe mú “ìdájọ́ òdodo” wá “fún àwọn orílẹ̀-èdè”? (b) Kí ni àpèjúwe Jésù nípa ará Samáríà onínúure fi kọ́ wa nípa ìdájọ́ òdodo?
8 Ńṣe ni Àyànfẹ́ Ìránṣẹ́ yìí yóò mú “ìdájọ́ òdodo” wá “fún àwọn orílẹ̀-èdè.” Ìyẹn ni Jésù sì ṣe. Yàtọ̀ sí pé kò mẹ́nu kúrò lórí bí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run ṣe níyọ̀ọ́nú, Jésù fi kọ́ni pé kò yẹ kó yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Nígbà kan, Jésù rán ọkùnrin kan tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin létí pé ó ní láti nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti aládùúgbò rẹ̀. Ni ọkùnrin yìí bá bi Jésù léèrè pé: “Ní ti gidi ta ni aládùúgbò mi?” Bóyá ó ń retí pé kí Jésù fèsì pé: “Àwọn tí ẹ jọ jẹ́ Júù ni.” Ṣùgbọ́n o, àkàwé kan nípa ará Samáríà onínúure ni Jésù dẹ́nu lé. Nínú àkàwé yẹn, ará Samáríà kan ló wá ran ọkùnrin kan tí olè dá lọ́nà lọ́wọ́, tó sì jẹ́ pé ọmọ Léfì kan àti àlùfáà kan ti kọ̀ láti ràn án lọ́wọ́. Bó ṣe di pé ẹni tó béèrè ìbéèrè yẹn ṣe gbà nìyẹn, pé lọ́tẹ̀ yìí o, ará Samáríà tí àwọn ń fojú tín-ínrín ni aládùúgbò yìí, kì í ṣe ọmọ Léfì tàbí àlùfáà yẹn. Jésù wá fi ìmọ̀ràn yìí parí àkàwé yẹn, ó ní: “Kí ìwọ alára sì máa ṣe bákan náà.”—Lúùkù 10:25-37; Léfítíkù 19:18.
“Kì Yóò Di Bàìbàì, Bẹ́ẹ̀ Ni A Kì Yóò Tẹ̀ Ẹ́ Rẹ́”
9. Báwo ni mímọ̀ tí a bá mọ ohun tí ìdájọ́ òdodo tòótọ́ jẹ́ ní ti gidi yóò ṣe nípa lórí wa?
9 Níwọ̀n bí Jésù ti mú kí ohun tí ìdájọ́ òdodo tòótọ́ jẹ́ ní ti gidi ṣe kedere, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kọ́ bí a ṣe ń hù ú níwà. Àwa pẹ̀lú ní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a ní láti tẹ́wọ́ gba ìlànà Ọlọ́run nípa ohun tó jẹ́ rere àti ohun tó jẹ́ búburú, nítorí pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti pinnu ohun tí ó tọ́ tó sì jẹ́ òdodo. Bí a ṣe ń sapá láti ṣe àwọn nǹkan lọ́nà tí Jèhófà ń fẹ́, ìwà títọ́ wa yóò jẹ́ kí ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ní tòótọ́ hàn kedere sí aráyé.—1 Pétérù 2:12.
10. Kí ni ìdí tí fífi ìdájọ́ òdodo hàn fi kan lílọ́wọ́ nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni?
10 Ìdájọ́ òdodo tòótọ́ la tún ń fi hàn nígbà tí a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni. Jèhófà ti fi ìwà ọ̀làwọ́ pèsè ìmọ̀ tó ń gbẹ̀mí là nípa ara rẹ̀, nípa Ọmọ rẹ̀, àti nípa àwọn ète rẹ̀. (Jòhánù 17:3) Kò ní tọ́, kò sì ní bá ìdájọ́ òdodo mu tí a bá lọ fi ìmọ̀ yìí mọ sọ́dọ̀ ara wa nìkan. Sólómọ́nì sọ pé: “Má fawọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ẹni tí ó yẹ kí o ṣe é fún, nígbà tí ó bá wà ní agbára ọwọ́ rẹ láti ṣe é.” (Òwe 3:27) Ẹ jẹ́ kí a fi tọkàntọkàn ṣàjọpín ohun tí a mọ̀ nípa Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo èèyàn, láìka ẹ̀yà, èdè, tàbí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti wá sí.—Ìṣe 10:34, 35.
11. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, báwo ló ṣe yẹ kí a máa hùwà sí ọmọnìkejì wa?
11 Síwájú sí i, ojúlówó Kristẹni a máa hùwà sí ọmọnìkejì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe hùwà síni. Lóde òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló dojú kọ àwọn ìṣòro tó ń bani lọ́kàn jẹ́, wọ́n sì ń fẹ́ ìyọ́nú àti ìṣírí. Àní ìpọ́njú ńláǹlà lè bá àwọn kan lára àwọn Kristẹni tó ti ya ara wọn sí mímọ́ débi tí wọ́n á fi dà bí esùsú fífọ́ tàbí òwú àtùpà tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú. Ǹjẹ́ wọn ò nílò ìtìlẹyìn wa? (Lúùkù 22:32; Ìṣe 11:23) Ìtura gbáà ló jẹ́ láti jẹ́ ara àwùjọ àwọn Kristẹni tòótọ́ tó ń ṣakitiyan láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nínú lílo ìdájọ́ òdodo!
12. Kí ni ìdí tó fi lè dá wa lójú pé ìdájọ́ òdodo fún gbogbo èèyàn káríkárí yóò wáyé láìpẹ́?
12 Ǹjẹ́ gbogbo èèyàn lè rí ìdájọ́ òdodo gbà káríkárí? Bẹ́ẹ̀ ni. Àyànfẹ́ Jèhófà “kì yóò di bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò tẹ̀ ẹ́ rẹ́ títí yóò fi gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé.” Láìpẹ́ Ọba tó ti gorí ìtẹ́, ìyẹn Kristi Jésù tó jíǹde, yóò “mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run.” (2 Tẹsalóníkà 1:6-9; Ìṣípayá 16:14-16) Ìjọba Ọlọ́run yóò wá rọ́pò ìṣàkóso ènìyàn. Ìdájọ́ òdodo àti òdodo yóò wá gbòde. (Òwe 2:21, 22; Aísáyà 11:3-5; Dáníẹ́lì 2:44; 2 Pétérù 3:13) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà níbi gbogbo, àní títí kan àwọn tó wà níbi jíjìnnà réré, ìyẹn “àwọn erékùṣù,” ló ń fi ìháragàgà dúró de ọjọ́ yẹn.
‘Èmi Yóò Fi Í Fúnni Gẹ́gẹ́ Bí Ìmọ́lẹ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè’
13. Kí ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Àyànfẹ́ Ìránṣẹ́ rẹ̀?
13 Aísáyà ń bọ́rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, wí, Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti Ẹni Atóbilọ́lá tí ó nà án; Ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ ayé àti èso rẹ̀, Ẹni tí ó fi èémí fún àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí rẹ̀, àti ẹ̀mí fún àwọn tí ń rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 42:5) Áà, àgbà àpèjúwe nípa Jèhófà Ẹlẹ́dàá rèé! Ìránnilétí yìí nípa bí Jèhófà ṣe tóbi lọ́ba mú kí ohun tí ó sọ túbọ̀ rinlẹ̀ sí i. Jèhófà sọ pé: “Èmi tìkára mi, Jèhófà, ti pè ọ́ nínú òdodo, mo sì tẹ̀ síwájú láti di ọwọ́ rẹ mú. Èmi yóò sì máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ, èmi yóò sì fi ọ́ fúnni gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè, kí o lè la àwọn ojú tí ó fọ́, kí o lè mú ẹlẹ́wọ̀n jáde kúrò nínú àjà ilẹ̀, kí o lè mú àwọn tí ó jókòó sínú òkùnkùn jáde kúrò ní àtìmọ́lé.”—Aísáyà 42:6, 7.
14. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà pé Jèhófà di ọwọ́ Ìránṣẹ́ rẹ̀ tó tẹ́wọ́ gbà mú? (b) Ipa wo ni Àyànfẹ́ Ìránṣẹ́ yẹn kó?
14 Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá àgbáyé, Olùfúnni ní ìwàláàyè àti Agbẹ́mìíró, di ọwọ́ Àyànfẹ́ Ìránṣẹ́ rẹ̀ mú, ó sì ṣèlérí pé gbágbáágbá lòun wà lẹ́yìn rẹ̀ nígbàkigbà. Èyí mà fini lọ́kàn balẹ̀ o! Jèhófà tún wá pa á mọ́ láti lè fi í fúnni “gẹ́gẹ́ bí májẹ̀mú àwọn ènìyàn.” Májẹ̀mú jẹ́ àdéhùn, ẹ̀jẹ́, tàbí ìlérí tó jinlẹ̀. Àṣẹ tó dájú ni. Dájúdájú, Jèhófà ti sọ Ìránṣẹ́ rẹ̀ di “májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn.”—An American Translation.
15, 16. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”?
15 Gẹ́gẹ́ bí “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” ńṣe ni Ìránṣẹ́ tí Jèhófà ṣèlérí yìí yóò la “àwọn ojú tí ó fọ́,” yóò sì dá “àwọn tí ó jókòó sínú òkùnkùn” nídè. Ohun tí Jésù ṣe nìyẹn. Nípa jíjẹ́rìí tí Jésù jẹ́rìí sí òtítọ́, ó yin orúkọ Baba rẹ̀ ọ̀run lógo. (Jòhánù 17:4, 6) Ó táṣìírí irọ́ àwọn ẹlẹ́sìn, ó wàásù ìhìn rere Ìjọba, ó sì ṣí ọ̀nà òmìnira nípa tẹ̀mí sílẹ̀ fún àwọn tó wà nígbèkùn ẹ̀sìn. (Mátíù 15:3-9; Lúùkù 4:43; Jòhánù 18:37) Ó kìlọ̀ pé kéèyàn má ṣe iṣẹ́ òkùnkùn, ó sì táṣìírí Sátánì pé òun ni “baba irọ́” àti “olùṣàkóso ayé.”—Jòhánù 3:19-21; 8:44; 16:11.
16 Jésù sọ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Jòhánù 8:12) Ó fi hàn lọ́nà tó tayọ pé ìmọ́lẹ̀ ayé ni òun lóòótọ́ nígbà tó fi ìwàláàyè rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn pípé rú ẹbọ ìràpadà. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ kí wọ́n lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, kí àjọṣe àwọn àti Ọlọ́run dán mọ́rán, kí wọ́n sì ní ìrètí ìyè ayérayé. (Mátíù 20:28; Jòhánù 3:16) Bí Jésù ṣe jẹ́ olùfọkànsin Ọlọ́run lọ́nà pípé pérépéré jálẹ̀ gbogbo ayé rẹ̀, ńṣe ló gbé ipò ọba aláṣẹ àgbáyé Jèhófà lárugẹ, tó sì fi Èṣù hàn ní òpùrọ́. Ní tòótọ́, Jésù jẹ́ olùla ojú afọ́jú àti olùdáǹdè àwọn tó wà ní àtìmọ́lé òkùnkùn nípa tẹ̀mí.
17. Àwọn ọ̀nà wo la ń gbà jẹ́ atànmọ́lẹ̀?
17 Nínú Ìwàásù Lórí Òkè, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ìmọ́lẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:14) Àbí kì í ṣe atànmọ́lẹ̀ làwa náà? Nípa bí a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa àti nípa iṣẹ́ ìwàásù wa, a láǹfààní láti fi àwọn ẹlòmíràn mọ Jèhófà, Orísun ìlàlóye tòótọ́. Ní títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù, a ń sọ orúkọ Jèhófà di mímọ̀, a ń gbé ipò ọba aláṣẹ Rẹ̀ lárugẹ, a sì ń pòkìkí Ìjọba Rẹ̀ pé ìyẹn nìkan ni ìrètí tí aráyé ní. Ẹ̀wẹ̀, gẹ́gẹ́ bí atànmọ́lẹ̀, à ń táṣìírí irọ́ àwọn ẹlẹ́sìn, à ń kìlọ̀ fún àwọn èèyàn pé kí wọ́n jáwọ́ nínú iṣẹ́ òkùnkùn, a sì ń táṣìírí Sátánì, ẹni búburú nì.—Ìṣe 1:8; 1 Jòhánù 5:19.
“Ẹ Kọ Orin Tuntun sí Jèhófà”
18. Kí ni Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀?
18 Jèhófà wá yí àfiyèsí sí àwọn èèyàn rẹ̀ wàyí, ó ní: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín. Àwọn nǹkan àkọ́kọ́—àwọn ni ó ń ṣẹlẹ̀ yìí, ṣùgbọ́n àwọn nǹkan tuntun ni mo ń sọ jáde. Kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí rú yọ, mo mú kí ẹ gbọ́ wọn.” (Aísáyà 42:8, 9) Ẹnu ọ̀kan nínú àwọn òrìṣà aláìwúlò kọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ìránṣẹ́ mi” ti jáde wá o, ẹnu Ọlọ́run alààyè, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló ti jáde wá. Dandan ni kó ṣẹ, ó sì kúkú ṣẹ. Ní ti tòótọ́, Jèhófà Ọlọ́run ni Orísun àwọn ohun tuntun, ó sì máa ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ mọ̀ nípa wọn kí wọ́n tó ṣẹlẹ̀. Ìhà wo ló yẹ ká wá kọ sí i?
19, 20. (a) Orin wo la ní láti kọ? (b) Àwọn wo ló ń kọ orin ìyìn sí Jèhófà lónìí?
19 Aísáyà kọ̀wé pé: “Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà, ìyìn rẹ̀ láti ìkángun ilẹ̀ ayé, ẹ̀yin tí ẹ ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú òkun àti ohun tí ó kún inú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn. Kí aginjù àti àwọn ìlú ńlá rẹ̀ gbé ohùn wọn sókè, àwọn ibi ìtẹ̀dó tí Kídárì ń gbé. Kí àwọn olùgbé orí àpáta gàǹgà fi ìdùnnú ké jáde. Kí àwọn ènìyàn ké sókè láti orí àwọn òkè ńlá. Kí wọ́n gbé ògo fún Jèhófà, kí wọ́n sì sọ ìyìn rẹ̀ jáde àní ní àwọn erékùṣù.”—Aísáyà 42:10-12.
20 Àwọn tí ń gbé inú ìlú ńlá, àwọn tí ń gbé lábúlé inú aginjù, àwọn tí ń gbé lérékùṣù, kódà àwọn tí ń gbé “Kídárì,” tàbí ibi ìtẹ̀dó inú aginjù pàápàá, àní àwọn èèyàn níbi gbogbo, ni ó rọ̀ láti kọrin ìyìn sí Jèhófà. Ó mà wúni lórí o pé lọ́jọ́ wa yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ti ṣe ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí rọni láti ṣe! Wọ́n ti tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ti fi Jèhófà ṣe Ọlọ́run wọn. Àwọn èèyàn Jèhófà ń kọ orin tuntun yìí, àní wọ́n ń fi ògo fún Jèhófà ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ. Ìdùnnú ńláǹlà ló mà jẹ́ o láti kópa nínú ègbè orin tó jẹ́ pé àwọn tó jùmọ̀ ń kọ ọ́ wá látinú onírúurú àṣà ìbílẹ̀ tó pọ̀ lọ jàra, tí èdè wọn pọ̀ lọ súà, tí wọ́n sì wá látinú onírúurú ẹ̀yà!
21. Kí ni ìdí tí àwọn ọ̀tá èèyàn Ọlọ́run ò fi ní ṣàṣeyọrí láti mú kí orin ìyìn sí Jèhófà dáwọ́ dúró?
21 Ǹjẹ́ àwọn alátakò lè gbéjà ko Ọlọ́run kí wọ́n sì mú kí orin ìyìn yìí dáwọ́ dúró? Ká má ri! “Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò jáde lọ bí alágbára ńlá. Òun yóò jí ìtara dìde bí jagunjagun. Yóò kígbe, bẹ́ẹ̀ ni, yóò fi igbe ogun ta; yóò fi ara rẹ̀ hàn ní alágbára ńlá ju àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ.” (Aísáyà 42:13) Alágbára wo ló lè ko Jèhófà lójú ná? Ní nǹkan bí egbèjìdínlógún ó dín ọgọ́rùn-ún [3,500] ọdún sẹ́yìn, wòlíì Mósè àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bú sí orin pé: “Jèhófà jẹ́ akin lójú ogun. Jèhófà ni orúkọ rẹ̀. Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ni ó sọ sínú òkun, ààyò àwọn jagunjagun rẹ̀ sì ni a ti rì sínú Òkun Pupa.” (Ẹ́kísódù 15:3, 4) Jèhófà borí agbo ọmọ ogun tó lágbára jù lọ lásìkò yẹn. Kò sí ọ̀tá àwọn èèyàn Ọlọ́run kankan tó lè ṣàṣeyọrí nígbà tí Jèhófà bá jáde lọ bíi jagunjagun alágbára.
“Mo Ti Dákẹ́ Jẹ́ẹ́ fún Ìgbà Pípẹ́”
22, 23. Èé ṣe tí Jèhófà fi “dákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ìgbà pípẹ́”?
22 Jèhófà kì í ṣègbè, ó sì máa ń ṣe ẹ̀tọ́, kódà nígbà tó bá ń dá àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́jọ́ pàápàá. Ó ní: “Mo ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ fún ìgbà pípẹ́. Mo ń bá a lọ ní dídákẹ́. Mo ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó fẹ́ bímọ, èmi yóò kérora, èmi yóò mí hẹlẹ, èmi yóò sì mí gúlegúle lẹ́ẹ̀kan náà. Èmi yóò pa àwọn òkè ńláńlá àti òkè kéékèèké run di ahoro, gbogbo ewéko wọn sì ni èmi yóò mú gbẹ dànù. Ṣe ni èmi yóò sọ àwọn odò di àwọn erékùṣù, àwọn odò adágún tí ó kún fún esùsú ni èmi yóò sì mú gbẹ táútáú.”—Aísáyà 42:14, 15.
23 Ó máa ń pẹ́ kí Jèhófà tó dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́, kí àwọn tó ṣàìtọ́ lè láǹfààní láti yí padà kúrò nínú àwọn ọ̀nà ibi wọn. (Jeremáyà 18:7-10; 2 Pétérù 3:9) Ẹ wo ọ̀ràn ti àwọn ará Bábílónì, bó ti jẹ́ pé, àwọn ni agbára ayé tí ń bẹ lójú ọpọ́n, àwọn ló pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìwà àìṣòótọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló jẹ́ kí Jèhófà gba èyí láyè, láti fi bá wọn wí. Ni àwọn ará Bábílónì ò bá mà mọ̀wọ̀n ara wọn o. Wọ́n wá ṣe àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣúkaṣùka kọjá ohun tó bá ìdájọ́ Ọlọ́run mu. (Aísáyà 47:6, 7; Sekaráyà 1:15) Ẹ wo bí ara yóò ti ta Ọlọ́run tó bí ọwọ́ ìyà ṣe ba àwọn èèyàn rẹ̀! Àmọ́, ó séra ró títí dìgbà tí àkókò wá tó. Ló bá rọbí bí obìnrin tó fẹ́ bímọ, ó wá dá àwọn èèyàn tí ó bá a dá májẹ̀mú nídè, ó sì mú wọn jáde wá láti di orílẹ̀-èdè olómìnira kan. Láti lè ṣe èyí, ó mú kí Bábílónì àti ètò ààbò rẹ̀ gbẹ dànù, ó sì pa á run di ahoro lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa.
24. Kí ni Jèhófà mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ Ísírẹ́lì máa retí?
24 Ara àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò mà yá gágá o nígbà tó bá di pé ọ̀nà ṣí sílẹ̀ fún wọn níkẹyìn láti lọ ilé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún nígbèkùn! (2 Kíróníkà 36:22, 23) Ìdùnnú ni yóò jẹ́ fún wọn láti rí ìmúṣẹ ìlérí Jèhófà pé: “Èmi yóò sì mú kí àwọn afọ́jú rìn ní ọ̀nà tí wọn kò mọ̀; òpópónà tí wọn kò mọ̀ ni èmi yóò mú kí wọ́n rìn. Èmi yóò sọ ibi tí ó ṣókùnkùn níwájú wọn di ìmọ́lẹ̀, èmi yóò sì sọ àgbègbè ilẹ̀ kángunkàngun di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ. Ìwọ̀nyí ni nǹkan tí èmi yóò ṣe fún wọn, dájúdájú, èmi kì yóò fi wọ́n sílẹ̀.”—Aísáyà 42:16.
25. (a) Ìdánilójú wo làwọn èèyàn Jèhófà lónìí lè ní? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
25 Báwo ni ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣe ṣẹ lóde òní? Ó ṣẹlẹ̀ pé, látìgbà pípẹ́ wá, àní fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún, Jèhófà ti jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe bó ṣe wù wọ́n. Àmọ́, àsìkò tirẹ̀ tí yóò yanjú ọ̀ràn ti wá kù sí dẹ̀dẹ̀. Láyé òde òní, ó ti gbé àwọn èèyàn kan dìde láti jẹ́rìí sí orúkọ rẹ̀. Ní sísọ tó ń sọ òkè àtakò dilẹ̀ fún wọn, ńṣe ló mú kí ilẹ̀ tẹ́jú pẹrẹsẹ fún wọn kí wọ́n lè jọ́sìn rẹ̀ “ní ẹ̀mí àti òtítọ́.” (Jòhánù 4:24) Ìlérí tó ṣe ni pé: “Èmi kì yóò fi wọ́n sílẹ̀,” kò sì yẹhùn lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àwọn tó wá wonkoko mọ́ sísin àwọn òrìṣà ńkọ́? Jèhófà sọ pé: “A óò dá wọn padà, ojú yóò tì wọ́n gidigidi, àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ère gbígbẹ́, àwọn tí ń wí fún ère dídà pé: ‘Ẹ̀yin ni ọlọ́run wa.’” (Aísáyà 42:17) Ó mà wá ṣe pàtàkì o pé ká jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà bíi ti Àyànfẹ́ rẹ̀ o!
‘Ìránṣẹ́ Tó Dití Tó sì Fọ́jú’
26, 27. Báwo ni Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ ‘ìránṣẹ́ tó dití tó sì fọ́jú,’ kí sì ni àbáyọrí rẹ̀?
26 Jésù Kristi, Àyànfẹ́ Ìránṣẹ́ Ọlọ́run, jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú. Ṣùgbọ́n, Ísírẹ́lì èèyàn Jèhófà jẹ́ ìránṣẹ́ aláìṣòótọ́, adití àti afọ́jú nípa tẹ̀mí. Àwọn ni Jèhófà ń bá wí, tó fi sọ pé: “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin adití; kí ẹ sì wo iwájú láti ríran, ẹ̀yin afọ́jú. Ta ni ó fọ́jú, bí kì í bá ṣe ìránṣẹ́ mi, ta sì ni ó dití bí ońṣẹ́ mi tí mo rán? Ta ni ó fọ́jú bí ẹni tí a san lẹ́san, tàbí tí ó fọ́jú bí ìránṣẹ́ Jèhófà? Ó jẹ́ ọ̀ràn rírí ohun púpọ̀, ṣùgbọ́n ìwọ kò kíyè sí i. Ó jẹ́ ọ̀ràn líla etí, ṣùgbọ́n ìwọ kò fetí sílẹ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀, nítorí òdodo rẹ̀, ti ní inú dídùn ní ti pé kí ó gbé òfin ga lọ́lá, kí ó sì sọ ọ́ di ọlọ́lá ọba.”—Aísáyà 42:18-21.
27 Ísírẹ́lì mà kúkú ya ìyàkuyà o! Léraléra làwọn èèyàn rẹ̀ lọ ń bọ àwọn òrìṣà ẹ̀mí èṣù àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Jèhófà rán wòlíì rẹ̀ sí wọn léraléra, ṣùgbọ́n etí dídi làwọn èèyàn rẹ̀ kọ sí wọn. (2 Kíróníkà 36:14-16) Aísáyà wá sọ àsọtẹ́lẹ̀ àbáyọrí rẹ̀ pé: “Ó jẹ́ àwọn ènìyàn tí a piyẹ́, tí a sì kó ní ìkógun, gbogbo wọn ni a dẹ pańpẹ́ mú nínú àwọn ihò, inú àwọn àtìmọ́lé sì ni a fi wọ́n pa mọ́ sí. Wọ́n ti wá wà fún ìpiyẹ́ láìsí olùdáǹdè, fún ìkógun láìsí ẹnikẹ́ni láti sọ pé: ‘Kó o padà!’ Ta ni yóò fi etí sí èyí nínú yín? Ta ni yóò fiyè sílẹ̀, tí yóò sì fetí sílẹ̀ nítorí ọjọ́ iwájú? Ta ni ó fi Jékọ́bù fún ìkógun lásán-làsàn, àti Ísírẹ́lì fún àwọn olùpiyẹ́? Jèhófà ha kọ́, Ẹni tí a dẹ́ṣẹ̀ sí, ẹni tí wọn kò fẹ́ láti rìn ní ọ̀nà rẹ̀, ẹni tí wọn kò sì fetí sí òfin rẹ̀? Nítorí náà, Ó ń bá a nìṣó ní dída ìhónú lé e lórí, ìbínú rẹ̀, àti okun ogun. Ó sì ń jẹ ẹ́ run nìṣó yí ká, ṣùgbọ́n kò fiyè sí i; ó sì ń jó o nìṣó, ṣùgbọ́n kò jẹ́ fi nǹkan kan sí ọkàn-àyà.”—Aísáyà 42:22-25.
28. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni àpẹẹrẹ àwọn ará Júdà kọ́ wa? (b) Báwo ni a ṣe lè wá ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà?
28 Nítorí ìwà àìṣòótọ́ àwọn ará Júdà, Jèhófà yọ̀ǹda kí wọ́n kó ilẹ̀ Júdà ní ìkógun kí wọ́n sì piyẹ́ rẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ni àwọn ará Bábílónì bá finá sun tẹ́ńpìlì Jèhófà, wọ́n sọ Jerúsálẹ́mù di ahoro, wọ́n sì kó àwọn Júù nígbèkùn. (2 Kíróníkà 36:17-21) Ǹjẹ́ kí á fi àpẹẹrẹ ìkìlọ̀ yìí sọ́kàn o, kí á má sì ṣe kọ etí dídi sí ìtọ́ni Jèhófà láé, tàbí kí á dijú sí àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kí á wá ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà nípa ṣíṣàfarawé Kristi Jésù, Ìránṣẹ́ tí Jèhófà fúnra rẹ̀ tẹ́wọ́ gbà. Kí á sọ ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ní tòótọ́ di mímọ̀ lọ́rọ̀ àti ní ìṣe wa, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. Lọ́nà bẹ́ẹ̀, a óò máa bá a lọ láti wà lára àwọn èèyàn Jèhófà, tó jẹ́ atànmọ́lẹ̀ tó ń fìyìn fún Ọlọ́run tòótọ́, tó sì ń yìn ín lógo.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 33]
Ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ní ìyọ́nú àti àánú nínú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 34]
Nínú àkàwé nípa ará Samáríà onínúure, Jésù fi hàn pé ìdájọ́ òdodo tòótọ́ kò yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 36]
Bí a bá jẹ́ afinilọ́kànbalẹ̀ àti onínúure, a ń lo ìdájọ́ òdodo tí Ọlọ́run ń fẹ́ nìyẹn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 39]
Nípa iṣẹ́ ìwàásù wa, a ń fi ìdájọ́ òdodo tí Ọlọ́run ń fẹ́ hàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 40]
Ọlọ́run fi Ìránṣẹ́ tí ó tẹ́wọ́ gbà fúnni “gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè”