Nígbà tí Ìlà-Oòrùn Pàdé Ìwọ̀-Oòrùn
“ÓÒ, ÌLÀ-OÒRÙN ni Ìlà-Oòrùn yóò máa jẹ́, Ìwọ̀-Oòrùn sì ni Ìwọ̀-Oòrùn yóò máa jẹ́, àwọn méjèèjì kò sì ní pàdéra láé.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí akéwì ọmọ ilẹ̀ Britain náà Rudyard Kipling sọ rán wa létí àwọn ìyàtọ̀ jíjinlẹ̀ níti àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ tí ó pín aráyé sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, èyí tí ó dákún àwọn ìkórìíra níti ẹ̀yà, ẹ̀yà-ìran, àti ti orílẹ̀-èdè èyí tí ń rujáde ní gbogbo àyíká wa lónìí. Ọ̀pọ̀ ń béèrè pé, Ọlọrun kò ha lè ṣe nǹkankan nípa ipò-ọ̀ràn yìí ni bí? Bẹ́ẹ̀ni, ó lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ó sì ń ṣe ohun kan nísinsìnyí pàápàá! Ìlà tí ó tẹ̀lé e nínú ewì Kipling tọ́ka sí èyí. Báwo ní ìpínyà tí ó wà láàárín Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn yóò ti pẹ́ tó? Akéwì náà wí pé: “Títí di ìgbà tí Ayé òun Ọ̀run bá dúró láìpẹ́ níwájú Ìjókòó Ìdájọ́ ńlá ti Ọlọrun.”
Ọlọrun ti yan ẹrù-iṣẹ́ ìdájọ́ lé Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi lọ́wọ́. (Johannu 5:22-24, 30) Ṣùgbọ́n nígbà wo ni àkókò ìdájọ́ yẹn bẹ̀rẹ̀? Àwọn wo ni a dájọ́ fún, pẹ̀lú ìyọrísí wo sì ni? Jesu ni ó ṣàpèjúwe àwọn ogun àgbáyé àti àwọn ìdààmú tí ń bá wọn rìn èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ síí pọ́n aráyé lójú ní ọdún 1914 nínú àsọtẹ́lẹ̀. Ó sọ pé ìwọ̀nyí ni ó ‘sàmìsí’ ‘wíwàníhìn-ín’ rẹ̀ tí kò ṣeéfojúrí ‘àti ti ìparí ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan.’—Matteu 24:3-8, NW.
Ní òtéńté àsọtẹ́lẹ̀ ńlá yìí, Jesu fi àkókò tí a wà yìí hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan tí ó jẹ́ ti ìdájọ́, ní sísọ nípa araarẹ̀ pé: “Nígbà tí Ọmọ-ènìyàn yóò wá nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn angẹli mímọ́ pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀: níwájú rẹ̀ ni a ó sì kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ: yóò sì yà wọ́n sí ọ̀tọ̀ kúrò nínú ara wọn gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùtàn tií ya àgùtàn rẹ̀ kúrò nínú ewúrẹ́: òun ó sì fi àgùtàn sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ewúrẹ́ sí ọwọ́ òsì.” Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, gbogbo àwọn ènìyàn lórí ilẹ̀-ayé ni a kójọ nísinsìnyí síwájú Onídàájọ́ náà wọn yóò sì jíhìn fún ọ̀nà tí wọ́n gbà dáhùn sí ìhìn-iṣẹ́ ìgbàlà rẹ̀. Láìpẹ́ nígbà tí a bá mú ìdájọ́ ṣẹ ní kíkún nígbà ìpọ́njú ńlá, àwọn aláìgbọràn ẹni-bí-ewúrẹ́ “yóò sì kọjá lọ sínú [ìkékúrò, NW] àìnípẹ̀kun: ṣùgbọ́n àwọn olóòótọ́ [àwọn onígbọràn ẹni-bí-àgùtàn] sí ìyè àìnípẹ̀kun.”—Matteu 25:31-33, 46; Ìfihàn 16:14-16.
‘Láti Gábásì àti Láti Yámà’
Ìdájọ́ ayé yìí bẹ̀rẹ̀ níti gidi ní àwọn ọdún onírúkèrúdò ti Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní. Ní àkókò yẹn, àwùjọ-àlùfáà Kristẹndọm fi tọkàntara ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹ̀yà-ẹgbẹ́ tí ń jagun. Èyí fi wọ́n hàn yàtọ̀ gẹ́gẹ́ bí apákan ayé oníwà-ìbàjẹ́ tí “ìbínú Ọlọrun” tọ́ sí. (Johannu 3:36) Síbẹ̀ kí ni nípa ti àwọn Kristian olùfẹ́ àlàáfíà tí wọ́n lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun? Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1919, àwọn wọ̀nyí ni a bẹ̀rẹ̀ síí kójọ síhà ọ̀dọ̀ Ọba náà, Kristi Jesu.
Láti apá ibi gbogbo nínú ayé ni wọ́n ti wá, lákọ̀ọ́kọ́ àṣẹ́kù 144,000 àwọn ẹni-àmì-òróró, tí a ṣàyàn títí jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún sànmánì Kristian. Àwọn wọ̀nyí ni wọn yóò jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi” nínú Ìjọba rẹ̀ ti ọ̀run. (Romu 8:17) Wòlíì Ọlọrun sọ fún àwọn wọ̀nyí pé: “Má bẹ̀rù: nítorí èmi wà pẹ̀lú rẹ; èmi óò mú irú-ọmọ rẹ láti gábásì wá, èmi ó sì ṣà ọ́ jọ láti yámà wá. Èmi óò wí fún àríwá pé, Dà sílẹ̀; àti fún gúúsù pé, Máṣe dá dúró; mú àwọn ọmọ mi ọkùnrin láti òkèèrè wá, àti àwọn ọmọ mi obìnrin láti òpin ilẹ̀ wá. Olúkúlùkù ẹni tí a ń pè ní orúkọ mi: nítorí mo ti dá a fún ògo mi, mo ti mọ ọ́n, àní, mo ti ṣe é pé.”—Isaiah 43:5-7.
Ṣùgbọ́n kò mọ síbẹ̀! Ní pàtàkì láti àwọn ọdún 1930, ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, tí iye wọn tó ọ̀pọ̀ million nísinsìnyí, ni a bẹ̀rẹ̀ síí kójọ. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn “àgùtàn” náà tí Jesu tọ́ka sí ní Matteu 25:31-46. Bíi ti àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró tí ó wà ṣáájú wọn, àwọn wọ̀nyí wá ‘ní ìgbàgbọ́’ nínú Ẹni náà tí ó polongo pé: ‘Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, Èmi sì ni Ọlọrun.’ (Isaiah 43:10-12) Ìkójọ ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí pẹ̀lú ń lọ ‘láti gábásì àti yámà, láti àríwá àti gúúsù, àti láti àwọn ìkangun ilẹ̀-ayé.’
Àwọn àgùtàn olùfẹ́ àlàáfíà wọ̀nyí ni a ń sopọ̀ṣọ̀kan di ẹgbẹ́-àwọn-ará kan kárí-ayé. Wọ́n ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè ti àwọn orílẹ̀-èdè 231 nínú èyí tí wọ́n ń gbé. Síbẹ̀ wọ́n wà ní ìṣọ̀kan nípa tẹ̀mí nínú kíkọ́ “èdè mímọ́gaara” ti ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba ti ń bẹ nínú Bibeli, “kí gbogbo wọn baà lè máa képe orúkọ Jehofa, láti lè máa ṣiṣẹ́sìn-ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefaniah 3:9, NW) Ìṣọ̀kan wọn níti èrò-ìgbàgbọ́, ète, àti ìṣesí pèsè ẹ̀rí àgbàyanu pé nítòótọ́ ni Ìlà-Oòrùn ti pàdé Ìwọ̀-Oòrùn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn láti apá ibi gbogbo, láti lè ṣiṣẹ́sin Jehofa Oluwa Ọba-Aláṣẹ kí wọ́n sì yìn ín.
Ní àwọn ilẹ̀ kan ìkójọ yìí ń wáyé lábẹ́ àwọn àyíká-ipò pípẹtẹrí jùlọ, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìròyìn tí ó tẹ̀lé e yóò ti fihàn.