Ta Ni Wọ́n?
Ó WU àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí o mọ àwọn dunjú. O ti lè bá wọn pàdé bí ẹ bá jọ jẹ́ aládùúgbò, bí iṣẹ́ bá dà yín pọ̀ tàbí lẹ́nu ìgbòkègbodò ìgbésí ayé ojoojúmọ́ mìíràn. O lè ti máa rí wọn ní ìgboro, kí wọ́n máa fi ìwé ìròyìn lọ àwọn tó ń kọjá. Ẹ sì ti lè jọ sọ̀rọ̀ ráńpẹ́ lẹ́nu ọ̀nà rẹ.
Ní tòdodo, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn rẹ, ire rẹ sì jẹ wọ́n lọ́kàn. Wọ́n ń fẹ́ jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ, kí wọ́n sì jẹ́ kí o mọ irú ẹni tí àwọn jẹ́, kí o mọ àwọn ohun tí wọ́n gbà gbọ́, ètò àjọ wọn, àti irú ojú tí wọ́n fi ń wo àwọn èèyàn àti ayé tí gbogbo wa jọ ń gbé yìí. Kí èyí fi lè ṣeé ṣe ni wọ́n ṣe ṣe ìwé pẹlẹbẹ yìí fún ọ.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò kúkú fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ọmọ aráyé yòókù. Àwọn náà ní ìṣòro, ìṣòro àtijẹ-àtimu, ọ̀ràn ìlera àti ti ìmí ẹ̀dùn. Wọ́n ń ṣàṣìṣe nígbà mìíràn, nítorí wọn kì í ṣe ẹni pípé, Ọlọ́run kò dìídì mí sí wọn, wọn kì í sì í ṣe ẹni tí kò lè ṣàṣìṣe. Ṣùgbọ́n, wọ́n máa ń gbìyànjú láti fi ìrírí wọn ṣàríkọ́gbọ́n, wọn sì ń ṣakitiyan láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kí wọ́n bàa lè ṣàtúnṣe tó bá yẹ. Wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀, wọ́n sì ń sapá gidigidi láti rí i pé àwọn ń tẹ̀ lé gbogbo ohun tó wé mọ́ ìyàsímímọ́ yìí. Wọ́n máa ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe atọ́nà àwọn nínú gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe.
Ohun tó jẹ wọ́n lógún gidigidi ni pé ohun tí àwọn gbà gbọ́ ní láti jẹ́ èyí tí ó tinú Bíbélì wá, pé kò wá látinú èrò ọkàn tàbí ìlànà ìsìn kan tí ọmọ èèyàn gbé kalẹ̀. Èrò tiwọn rí gẹ́gẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, nígbà tó sọ̀rọ̀ lábẹ́ ìmísí, pé: “Jẹ́ kí a rí Ọlọ́run ní olóòótọ́, bí a tilẹ̀ rí olúkúlùkù ènìyàn ní òpùrọ́.” (Róòmù 3:4, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntuna) Bó bá di ti àwọn ẹ̀kọ́ tí a pè ní òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, ohun tí àwọn ará Bèróà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìwàásù àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù làwọn Ẹlẹ́rìí fara mọ́ délẹ̀délẹ̀, ìyẹn ni pé: “Wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 17:11) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé gbogbo ẹ̀kọ́ ìsìn ló yẹ ká fi Ìwé Mímọ́ dán wò bí ibí yìí ṣe wí, ìyẹn láti mọ̀ bóyá wọ́n bá Ìwé Mímọ́ tí Ọlọ́run mí sí mu tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ì báà jẹ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn fi ń kọ́ni ni o tàbí ẹ̀kọ́ ti àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n ké sí ọ, àní wọ́n rọ̀ ọ́, pé ìyẹn ni kí o máa ṣe bóo bá ń bá àwọn jíròrò pọ̀.
Èyí jẹ́ kó hàn kedere pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba Bíbélì gbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Wọ́n gbà pé Ọlọ́run mí sí ìwé mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] tó wà nínú rẹ̀, pé ìtàn inú rẹ̀ sì pé pérépéré. Apá tí ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun làwọn ń pè ní Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, wọ́n sì ń pe Májẹ̀mú Láéláé ní Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Àti Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì àti ti Hébérù ni wọ́n gbára lé, wọ́n sì gbà pé bí ọ̀rọ̀ inú wọn ṣe sọ gẹ́lẹ́ ni ká ṣe gbà á, àyàfi ibi tí àwọn gbólóhùn tàbí àyíká ọ̀rọ̀ rẹ̀ bá ti fi hàn kedere pé wọ́n jẹ́ àpèjúwe tàbí ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ. Òye wọn ni pé púpọ̀ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló ti ṣẹ, pé àwọn mìíràn ṣì ń ṣẹ lọ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ṣì kù tó máa ṣẹ́.
ORÚKỌ WỌN
Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àbí? Bẹ́ẹ̀ ni, orúkọ tí wọ́n ń pe ara wọn nìyẹn. Orúkọ aṣàpèjúwe ni, tó ń fi hàn pé wọ́n ń jẹ́rìí nípa Jèhófà, nípa jíjẹ́ tó jẹ́ Ọlọ́run, àti àwọn ète rẹ̀. “Ọlọ́run,” “Olúwa,” àti “Ẹlẹ́dàá,” dà bí “Ààrẹ,” “Ọba,” àti “Ọ̀gágun” ni, orúkọ oyè ni wọ́n, wọ́n sì lè tọ́ka sí onírúurú ẹni àyẹ́sí. Ṣùgbọ́n orúkọ ara ẹni ní pàtó ni “Jèhófà” jẹ́, Ọlọ́run Olódùmarè, Ẹlẹ́dàá àgbáálá ayé ló sì ń jẹ́ bẹ́ẹ̀. Èyí hàn nínú Orin Dáfídì 83:18, gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìtumọ̀ Bíbélì Mímọ́, pé: “Ki awọn enia ki o le mọ̀ pe iwọ, orukọ ẹni-kanṣoṣo ti ijẹ Jehofah, iwọ li Ọga-ogo lori aiye gbogbo.”
Orúkọ náà, Jèhófà, (tàbí Yahweh, ìyẹn èyí tí Jerusalem Bible ti ìjọ Kátólíìkì àti àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan yàn láàyò) fara hàn níye ìgbà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bíbélì tó pọ̀ jù lọ ni kò fi bẹ́ẹ̀ lò ó, ńṣe ni wọ́n fi “Ọlọ́run” tàbí “Olúwa” rọ́pò rẹ̀. Àmọ́, nínú Bíbélì wọ̀nyẹn pàápàá, èèyàn sábà máa ń lè sọ ibi tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti lo Jèhófà, nítorí pé, ní gbogbo ibi tó bá ti wà tẹ́lẹ̀, lẹ́tà gàdàgbà-gàdàgbà ni wọ́n máa fi ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n bá fi rọ́pò rẹ̀, wọ́n á kọ ọ́ báyìí: ỌLỌ́RUN tàbí OLÚWA. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní mélòó kan máa ń lo yálà orúkọ náà, Jèhófà tàbí orúkọ náà, Yahweh. Nípa bẹ́ẹ̀, nínú Aísáyà 42:8, Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun kà báyìí pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.”
Àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti mú orúkọ wọn ni Aísáyà orí kẹtàlélógójì. Ńṣe ni ibẹ̀ yẹn gbé ọ̀ràn ilé ayé kalẹ̀ bí ẹní ń wòran ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nínú kóòtù, ó lọ báyìí pé: Wọ́n pe àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè pé kí wọ́n kó àwọn ẹlẹ́rìí wọn wá, láti lè fi ẹ̀rí jíjẹ́ tí wọ́n ní àwọn jẹ́ olódodo múlẹ̀, tàbí kí wọ́n tẹ́tí gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn tó jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Jèhófà kí wọ́n sì gba èyí tó jẹ́ òtítọ́. Ibẹ̀ ni Jèhófà ti sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi, ni Jèhófà wí, àti ìránṣẹ́ mi tí mo ti yàn; kí ẹ̀yin lè mọ̀, kí ẹ sì gbà mí gbọ́, kí ó sì yé yín pé èmi ni: ṣáájú mi, kò sí Ọlọ́run kankan tí a ṣẹ̀dá, kì yóò sì sí ìkankan tí yóò wà lẹ́yìn mi. Èmi, àní èmi, ni Jèhófà; àti lẹ́yìn mi, kò sí olùgbàlà kankan.”—Aísáyà 43:10, 11, American Standard Version.
Jèhófà Ọlọ́run ní àwọn ẹlẹ́rìí lórí ilẹ̀ ayé ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù. Lẹ́yìn tí Hébérù orí kọkànlá ti mẹ́nu kan díẹ̀ lára àwọn tó jẹ́ ẹni ìgbàgbọ́, Hébérù 12:1 wá sọ pé: “Nípa báyìí, nítorí tí a ní àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yí wa ká, ẹ jẹ́ kí àwa pẹ̀lú mú gbogbo ẹrù wíwúwo kúrò àti ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn, ẹ sì jẹ́ kí a fi ìfaradà sá eré ìje tí a gbé ka iwájú wa.” Jésù sọ níwájú Pọ́ńtíù Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” Wọ́n pe Jésù ní, “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.” (Jòhánù 18:37; Ìṣípayá 3:14) Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣe 1:8.
Nípa bẹ́ẹ̀, lóde òní, ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ, nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà èèyàn tó ń sọ ìhìn rere Ìjọba Jèhófà tí Kristi Jésù ń ṣàkóso, gbà pé ó tọ́ bí àwọn ṣe ń pe ara àwọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Inú ìtumọ̀ Bíbélì yìí la ti fa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a lò nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí yọ, àyàfi bí a bá fi hàn pé ó jẹ́ látinú òmíràn.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]
Wọ́n gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Orúkọ yẹn bí wọ́n ṣe fi wé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú kóòtù
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà Ẹlẹ́rìí wà ní ilẹ̀ tó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]
Wọ́n ń wá ire rẹ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Orúkọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ní èdè Hébérù àtijọ́