Orí Karùn-ún
Ọlọ́run Tòótọ́ Sọ Àsọtẹ́lẹ̀ Ìdáǹdè
1, 2. (a) Àwọn ìbéèrè wo ni Jèhófà béèrè? (b) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe fi ẹ̀rí hàn pé òun nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run tòótọ́?
‘TA NI Ọlọ́run tòótọ́?’ Látayébáyé ni ìbéèrè yìí ti ń wáyé. Ìyàlẹ́nu gbáà ló wá jẹ́ pé Jèhófà alára béèrè ìbéèrè kan náà nínú ìwé Aísáyà! Ó ké sí aráyé pé kí wọ́n gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, ìyẹn ni pé: ‘Ṣé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́ ni? Tàbí Ọlọ́run mìíràn tún wà tó lè bá a figẹ̀ wọngẹ̀?’ Lẹ́yìn tí Jèhófà dá ìjíròrò yìí sílẹ̀ tán, ó gbé àwọn ìlànà tó bọ́gbọ́n mu kalẹ̀ kí àríyànjiyàn nípa ẹni tó tọ́ láti jẹ́ Ọlọ́run lè yanjú. Àlàyé tí ó ṣe kalẹ̀ ń jẹ́ kí àwọn olóòótọ́ ọkàn mọ ibi títọ́ kan ṣoṣo tí ọ̀ràn náà yóò yọrí sí.
2 Nígbà ayé Aísáyà, ìjọsìn ère wọ́pọ̀ gan-an ni. Ìjíròrò tí ó ṣe ṣàkó, láìfọ̀rọ̀ lọ́ko-lọ́jù, tó wà nínú ìwé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà orí kẹrìnlélógójì sì jẹ́ kó hàn gbangba pé asán gbáà ni ìjọsìn ère jẹ́! Àmọ́ o, àwọn èèyàn Ọlọ́run alára wá tọrùn bọ ìbọ̀rìṣà. Nípa bẹ́ẹ̀, ìbáwí lílekoko tọ́ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gẹ́gẹ́ bí a ti ṣe rí i nínú àwọn orí ìwé Aísáyà látẹ̀yìnwá. Ṣùgbọ́n, Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ fi orílẹ̀-èdè yẹn lọ́kàn balẹ̀ pé, lóòótọ́ lòun máa yọ̀ǹda kí àwọn ará Bábílónì kó àwọn èèyàn òun lọ sígbèkùn, àmọ́, òun yóò dá wọn nídè bó bá ti tó àkókò lójú òun. Ṣíṣẹ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìdáǹdè kúrò nígbèkùn àti ti ìmúbọ̀sípò ìsìn mímọ́ bá ṣẹ ni yóò fi ẹ̀rí hàn láìsí àní-àní pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́, yóò sì dójú ti gbogbo àwọn tó ń bọ àwọn òrìṣà aláìlẹ́mìí ti àwọn orílẹ̀-èdè.
3. Báwo ni ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe ń ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ lóde òní?
3 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní apá ibí yìí nínú Aísáyà àti bí wọ́n ṣe ṣẹ láyé àtijọ́, máa ń fún ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni lókun lóde òní. Ẹ̀wẹ̀, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tún ṣẹ lọ́jọ́ tiwa yìí, kódà yóò sì tún ṣẹ lọ́jọ́ iwájú pàápàá. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí sì kan olùdáǹdè àti ìdáǹdè kan tó tilẹ̀ tún ga ju àwọn tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò wáyé fún àwọn èèyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́ lọ.
Ìrètí Wà fún Àwọn Tó Jẹ́ ti Jèhófà
4. Báwo ni Jèhófà ṣe fún Ísírẹ́lì níṣìírí?
4 Ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára ni orí kẹrìnlélógójì fi bẹ̀rẹ̀, ní mímú un wá sí ìrántí pé Ọlọ́run ló yan Ísírẹ́lì, pé ó yà á sọ́tọ̀ kúrò láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká láti fi í ṣe ìránṣẹ́. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sọ pé: “Wàyí o, fetí sílẹ̀, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, àti ìwọ Ísírẹ́lì, ẹni tí mo ti yàn. Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùṣẹ̀dá rẹ àti Aṣẹ̀dá rẹ, ẹni tí ó ti ń ràn ọ́ lọ́wọ́ àní láti inú ikùn wá, ‘Má fòyà, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, àti ìwọ, Jéṣúrúnì, ẹni tí mo ti yàn.’” (Aísáyà 44:1, 2) Jèhófà ti ń ṣètọ́jú Ísírẹ́lì bọ̀ látinú ilé ọlẹ̀ ìyá rẹ̀ ni ká wí, ìyẹn láti ìgbà tí Ísírẹ́lì ti di orílẹ̀-èdè lẹ́yìn tó ti jáde kúrò ní Íjíbítì. “Jéṣúrúnì,” tó túmọ̀ sí “Adúróṣinṣin,” ló pe àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀, ìfẹ́ àti ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó fi mú wọn sì hàn látinú orúkọ yìí. Ìránnilétí sì tún ni orúkọ yìí jẹ́ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, pé gbogbo ìgbà ni wọ́n ní láti jẹ́ adúróṣinṣin, èyí tí wọ́n sì sábà máa ń kùnà láti jẹ́.
5, 6. Àwọn ohun tó ń tuni lára wo ni Jèhófà pèsè fún Ísírẹ́lì, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
5 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ tẹ̀ lé e dùn mọ́ni, ó sì tura gan-an ni o! Ó ní: “Èmi yóò da omi sára ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, àti àwọn odò kéékèèké tí ń ṣàn sórí ibi gbígbẹ. Èmi yóò da ẹ̀mí mi sára irú-ọmọ rẹ, àti ìbùkún mi sára àwọn ọmọ ìran rẹ. Ṣe ni wọn yóò sì rú yọ bí ẹni pé láàárín koríko tútù, bí àwọn igi pọ́pílà tí ń bẹ lẹ́bàá àwọn kòtò omi.” (Aísáyà 44:3, 4) Kódà ní àwọn ẹkùn ilẹ̀ gbígbẹ tó gbóná pàápàá, àwọn igbó igi ṣúúrú ṣì lè rú lẹ́bàá àwọn ìsun omi. Bí Jèhófà bá sì ti pèsè omi òtítọ́ tó ń fúnni ní ìyè, tí ó sì tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jáde, ńṣe ni Ísírẹ́lì yóò rú yọ gbẹ̀gẹ́gbẹ̀gẹ́ bí àwọn igi tó wà lẹ́bàá ipadò. (Sáàmù 1:3; Jeremáyà 17:7, 8) Jèhófà yóò wá fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní okun láti ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń jẹ́rìí sí jíjẹ́ tí ó jẹ́ Ọlọ́run.
6 Ọ̀kan lára ohun tí yóò jẹ́ àbájáde títú tí Jèhófà tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ jáde yìí ni pé ìmọrírì tí àwọn kan ní fún àjọṣe tí ń bẹ láàárín Ísírẹ́lì àti Jèhófà yóò sọjí. Ìyẹn la fi rí i kà pé: “Ẹni yìí yóò wí pé: ‘Ti Jèhófà ni èmi.’ Ẹni yẹn yóò sì fi orúkọ Jékọ́bù pe ara rẹ̀, ẹlòmíràn yóò sì kọ ọ́ sí ọwọ́ rẹ̀ pé: ‘Ti Jèhófà ni.’ Ènìyàn yóò sì fi orúkọ Ísírẹ́lì fún ara rẹ̀ ní orúkọ oyè.” (Aísáyà 44:5) Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun ẹ̀yẹ ni yóò jẹ́ láti máa gbé orúkọ Jèhófà kiri, nítorí wọn yóò rí i pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́.
Ìpèníjà sí Àwọn Òrìṣà
7, 8. Báwo ni Jèhófà ṣe pe àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè níjà?
7 Lábẹ́ Òfin Mósè, olùtúnnirà, ìyẹn ìbátan tímọ́tímọ́ kan tó jẹ́ ọkùnrin, lè rani kúrò nígbèkùn. (Léfítíkù 25:47-54; Rúùtù 2:20) Jèhófà wá sọ pé òun gan-an ni Olùtúnnirà Ísírẹ́lì, ìyẹn ẹni tí yóò ra orílẹ̀-èdè yẹn padà, lojú bá ti Bábílónì àtàwọn òrìṣà rẹ̀ gbogbo. (Jeremáyà 50:34) Jèhófà wá ko àwọn òrìṣà àtàwọn tó ń sìn wọ́n lójú, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Ọba Ísírẹ́lì àti Olùtúnnirà rẹ̀, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘Èmi ni ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn, yàtọ̀ sí mi, kò sí Ọlọ́run kankan. Ta sì ni ó dà bí èmi? Kí ó pè, kí ó lè sọ ọ́, kí ó sì gbé e kalẹ̀ fún mi. Láti ìgbà tí mo ti yan àwọn ènìyàn àtọjọ́mọ́jọ́ sípò, àwọn ohun tí ń bọ̀ àti àwọn ohun tí ó máa tó dé, kí wọ́n sọ níhà ọ̀dọ̀ wọn. Ẹ má ṣe ní ìbẹ̀rùbojo, ẹ má sì di ẹni tí a dà lọ́kàn rú. Láti ìgbà yẹn síwájú, èmi kò ha ti mú kí ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan gbọ́, tí mo sì sọ ọ́ jáde? Ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi. Ọlọ́run kan ha wà yàtọ̀ sí mi bí? Ó tì o, kò sí Àpáta kankan. Èmi kò mọ ìkankan.’”—Aísáyà 44:6-8.
8 Jèhófà pe àwọn òrìṣà níjà pé kí wọ́n wá ṣàlàyé ara wọn. Ṣé wọ́n lè pe ohun tí kò tíì wáyé rí rárá jáde bíi pé wọ́n ti wà rí, nípa sísọ àsọtẹ́lẹ̀ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú lọ́nà pípéye débi ti yóò fi dà bí pé wọ́n tilẹ̀ ti ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́? Àyàfi “ẹni àkọ́kọ́ àti ẹni ìkẹyìn,” tó ti wà ṣáájú kí ẹnikẹ́ni tó ronú kan òrìṣàkórìṣà, tí yóò sì tún wà bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn tí gbogbo òrìṣà bá di ìgbàgbé tán porogodo, ló lè ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Kò sídìí fún àwọn èèyàn Jèhófà láti bẹ̀rù láti jẹ́rìí sí òtítọ́ yìí, nítorí pé Jèhófà, òyígíyigì bí àpáta ràbàtà, ń bẹ lẹ́yìn wọn gbágbáágbá!—Diutarónómì 32:4; 2 Sámúẹ́lì 22:31, 32.
Bí Sísin Ère Ṣe Jẹ́ Òtúbáńtẹ́
9. Ǹjẹ́ ó lòdì pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe àwòrán ohun abẹ̀mí èyíkéyìí? Ṣàlàyé.
9 Pípè tí Jèhófà pe àwọn òrìṣà níjà ránni létí òfin kejì nínú Òfin Mẹ́wàá. Òfin yẹn sọ kedere pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n.” (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Àmọ́ ṣá o, ìkàléèwọ̀ yìí kò túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò gbọ́dọ̀ ṣe àwòrán àwọn nǹkan láti fi ṣe ọnà. Jèhófà alára pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe àwòrán ewéko, ti ẹranko, àti ti kérúbù sínú àgọ́ ìjọsìn. (Ẹ́kísódù 25:18; 26:31) Ṣùgbọ́n ṣá, wọn kò gbọ́dọ̀ júbà wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbọ́dọ̀ sìn wọ́n. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gbàdúrà sí àwòrán wọ̀nyẹn, wọn kò sì gbọ́dọ̀ rúbọ sí wọn. Òfin tí Ọlọ́run mí sí yìí ka ṣíṣe ère irú èyíkéyìí fún jíjọ́sìn léèwọ̀. Sísin àwọn ère tàbí títẹrí ba fún wọn lọ́nà ìjúbà jẹ́ ìbọ̀rìṣà.—1 Jòhánù 5:21.
10, 11. Kí ni ìdí tí Jèhófà fi ka àwọn ère sí ohun tó tini lójú?
10 Aísáyà wá ṣe àpèjúwe bí ère aláìlẹ́mìí ṣe jẹ́ òfútùfẹ́ẹ̀tẹ̀ àti ìtìjú tí ń bọ̀ wá bá àwọn tó ṣe wọn, ó ní: “Òtúbáńtẹ́ ni gbogbo àwọn tí ń gbẹ́ ère gbígbẹ́, àwọn olólùfẹ́ wọn pàápàá kì yóò ṣàǹfààní; àti gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí wọn, wọn kò rí nǹkan kan, wọn kò sì mọ nǹkan kan, kí ojú lè tì wọ́n. Ta ni ó ti ṣẹ̀dá ọlọ́run kan tàbí tí ó mọ ère dídà lásán-làsàn? Ó jẹ́ èyí tí kò ṣàǹfààní rárá. Wò ó! Ojú yóò ti gbogbo alájọṣe rẹ̀ pàápàá, láti inú àwọn ará ayé sì ni àwọn oníṣẹ́ ọnà náà ti wá. Gbogbo wọn yóò kó ara wọn jọpọ̀. Wọn yóò dúró bọrọgidi. Ìbẹ̀rùbojo yóò mú wọn. Ojú yóò tì wọ́n lẹ́ẹ̀kan náà.”—Aísáyà 44:9-11.
11 Kí ni ìdí tí Ọlọ́run fi ka àwọn ère wọ̀nyí sí ohun tó tini lójú bẹ́ẹ̀? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé kò ṣeé ṣe láti fi ohun èlò èyíkéyìí ṣe àpẹẹrẹ Olódùmarè, kó sì bá a mu rẹ́gí. (Ìṣe 17:29) Ẹ̀wẹ̀, àfojúdi gbáà ló jẹ́ sí ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run bí èèyàn bá lọ ń sin ohun tí ó dá dípò òun Ẹlẹ́dàá. Ǹjẹ́ ìfara-ẹni-wọ́lẹ̀ kọ́ nìyẹn tilẹ̀ jẹ́ fún èèyàn, tí a dá ní “àwòrán Ọlọ́run”?—Jẹ́nẹ́sísì 1:27; Róòmù 1:23, 25.
12, 13. Kí ni ìdí tí èèyàn ò fi lè ṣe ère tí ó tó ohun tó yẹ láti jọ́sìn?
12 Ṣé àwọn nǹkan bí igi, òkúta àti irin lásán ti wá para dà di mímọ́ nìyẹn kìkì nítorí pé èèyàn dárà sí i lára láti lè máa sìn ín? Aísáyà rán wa létí pé ère gbígbẹ́ kò ju iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ èèyàn lásán lọ. Àwọn ohun èlò àti ọgbọ́n kan náà tí àwọn oníṣọ̀nà yòókù ń lò náà ni ẹni tó ṣe ère lò, ìyẹn ni pé: “Ní ti agbẹ́rin tí ń lo ohun èlò tí a fi ń gbẹ́ nǹkan, ọwọ́ rẹ̀ dí bí ó ti ń ṣe é lórí ẹyín iná; ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi òòlù ṣe é, ọwọ́ rẹ̀ sì dí bí ó ti ń fi apá rẹ̀ lílágbára ṣe é. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ebi ń pa á, nítorí náà, kò ní agbára. Kò tíì mu omi; nítorí náà, ó rẹ̀ ẹ́. Ní ti agbẹ́gi, ó na okùn ìdiwọ̀n; ó fi ẹfun pupa sàmì sí i; ó fi ìfági fá a; ó sì ń fi kọ́ńpáàsì sàmì sí i, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó ṣe é bí àwòrán ènìyàn, bí ẹwà aráyé, láti jókòó nínú ilé.”—Aísáyà 44:12, 13.
13 Ọlọ́run tòótọ́ ló dá gbogbo ohun abẹ̀mí tí ń bẹ láyé yìí, títí kan ènìyàn. Wíwà tí ẹ̀dà abẹ̀mí wà láàyè jẹ́ ara ẹ̀rí pé Jèhófà tóbi lọ́ba gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run, àmọ́ ṣá, gbogbo ohun tí Jèhófà dá pátá ló rẹlẹ̀ sí i. Ṣé èèyàn wá lè ṣe ohun tó tún kira ju ti Jèhófà lọ ni? Ṣé ó lè ṣe ohun tó ju òun fúnra rẹ̀ lọ ni, tó jù ú lọ débi tí yóò fi tó ohun tó yẹ láti máa júbà? Bí èèyàn bá ń ṣe ère lọ́wọ́, a máa rẹ̀ ẹ́, ebi á pa á, òùngbẹ a sì gbẹ ẹ́. Ìwọ̀nyí ń fi hàn pé agbára èèyàn mọ níwọ̀n, àmọ́, ó ṣáà ń jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí ṣì ń bẹ lára onítọ̀hún. Ère tí ó ṣe lè jọ èèyàn lóòótọ́ o. Ó tilẹ̀ lè lẹ́wà. Ṣùgbọ́n kò lẹ́mìí rárá. Ère kì í ṣe ará ọ̀run lọ́nàkọnà. Ẹ̀wẹ̀, ère gbígbẹ́ kan ò “jábọ́ láti ọ̀run” wá rí, nítorí iṣẹ́ ọwọ́ ọmọ adáríhurun kúkú ni.—Ìṣe 19:35.
14. Báwo ló ṣe jẹ́ pé àwọn tí ń ṣe ère ò lè dá ohunkóhun ṣe láìsí ìpèsè ti Jèhófà?
14 Aísáyà wá tẹ̀ síwájú láti fi hàn pé àwọn tí ń ṣe ère kò gbára lé ohun mìíràn rárá, àyàfi àwọn tí ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ àti àwọn ohun tí Jèhófà ṣẹ̀dá, ó ní: “Ẹnì kan wà tí iṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ láti gé kédárì lulẹ̀; ó sì mú irú igi kan, àní igi ràgàjì kan, ó sì jẹ́ kí ó di líle fún ara rẹ̀ láàárín àwọn igi igbó. Ó gbin igi lọ̀rẹ́ẹ̀lì, àní ọ̀yamùúmùú òjò sì ń mú kí ó tóbi sí i. Ó sì ti di ohun kan fún ènìyàn láti fi mú kí iná máa jó. Nítorí náà, ó mú lára rẹ̀ kí ó lè yáná. Ní ti gidi, ó dá iná, ó sì yan búrẹ́dì ní tòótọ́. Bákan náà, ó ṣiṣẹ́ lórí ọlọ́run kan tí òun lè máa tẹrí ba fún. Ó ṣe é ní ère gbígbẹ́, ó sì ń wólẹ̀ fún un. Ìdajì rẹ̀ ni ó sun nínú iná. Orí ìdajì rẹ̀ ni ó ti yan àyangbẹ ẹran tí ó ń jẹ, ó sì yó. Ó tún yáná, ó sì wí pé: ‘Àháà! Mo ti yáná. Mo ti rí ìmọ́lẹ̀ iná.’ Ṣùgbọ́n ìyókù rẹ̀ ni ó fi ṣe ọlọ́run ní tòótọ́, ó fi ṣe ère gbígbẹ́. Ó ń wólẹ̀ fún un, ó sì ń tẹrí bá, ó sì ń gbàdúrà sí i, ó sì ń wí pé: ‘Dá mi nídè, nítorí pé ìwọ ni ọlọ́run mi.’”—Aísáyà 44:14-17.
15. Ìwà àìlo-làákàyè gbáà wo ni àwọn tó ń ṣe ère ń hù?
15 Ṣé àjókù igi wá lè gba ẹnikẹ́ni là ni? Rárá o. Ọlọ́run tòótọ́ nìkan ló lè pèsè ìdáǹdè. Kí ló lè wá mú kí àwọn èèyàn sọ ohun aláìlẹ́mìí di àkúnlẹ̀bọ? Aísáyà fi hàn pé inú ọkàn-àyà onítọ̀hún gan-an ni ìṣòro yẹn wà, ó ní: “Wọn kò mọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò lóye, nítorí tí nǹkan ti rá wọn lójú kí wọ́n má bàa ríran, nǹkan sì ti rá ọkàn-àyà wọn kí wọ́n má bàa ní ìjìnlẹ̀ òye. Kò sì sí ẹni tí ó mú un wá sí ìrántí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ tàbí tí ó ní ìmọ̀ tàbí òye, pé: ‘Ìdajì rẹ̀ ni mo ti sun nínú iná, orí ẹyín iná rẹ̀ pẹ̀lú sì ni mo ti yan búrẹ́dì; mo yan ẹran, mo sì jẹ ẹ́. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ó yẹ kí n fi ìyókù rẹ̀ ṣe ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí lásán-làsàn? Ǹjẹ́ ó yẹ kí n máa wólẹ̀ fún igi gbígbẹ?’ Ó ń fi eérú bọ́ ara rẹ̀. Ọkàn-àyà rẹ̀ tí a ti tàn jẹ ti mú un ṣáko lọ. Kò sì dá ọkàn rẹ̀ nídè, bẹ́ẹ̀ sì ni kò wí pé: ‘Kò ha sí èké ní ọwọ́ ọ̀tún mi?’” (Aísáyà 44:18-20) Ní tòdodo, ńṣe ni ẹni tó bá ń rò ó nínú ara rẹ̀ pé ìbọ̀rìṣà lè pèsè ohun dáadáa kan nípa tẹ̀mí dà bí ẹni tó ń jẹ eérú dípò oúnjẹ aṣaralóore.
16. Kí ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìbọ̀rìṣà, kí ló sì ń jẹ́ kó lè wáyé?
16 Ní ti gidi, ọ̀run ni ìbọ̀rìṣà ti bẹ̀rẹ̀ nígbà tí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára kan tó di Sátánì ṣojúkòkòrò sí ìjọsìn tó tọ́ sí Jèhófà nìkan ṣoṣo. Ojúkòkòrò Sátánì yìí pọ̀ débi pé ó mú kó kúkú kẹ̀yìn sí Ọlọ́run. Ohun tó pilẹ̀ ìbọ̀rìṣà gan-an nìyẹn, nítorí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ohun kan náà ni ojúkòkòrò àti ìbọ̀rìṣà jọ jẹ́. (Aísáyà 14:12-14; Ìsíkíẹ́lì 28:13-15, 17; Kólósè 3:5) Sátánì ló sún tọkọtaya àkọ́kọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí ro èrò onímọtara ẹni nìkan lọ́kàn. Éfà ṣe ojúkòkòrò nítorí ohun tí Sátánì fi lọ̀ ọ́, pé: “Ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.” Jésù wá sọ pé inú ọkàn-àyà ni ojúkòkòrò ti ń wá. (Jẹ́nẹ́sísì 3:5; Máàkù 7:20-23) Ìgbà tí ọkàn-àyà ẹni bá dìdàkudà ni ìbọ̀rìṣà tó máa ń wáyé. Ó mà ṣe pàtàkì gidigidi nígbà náà o pé kí gbogbo wa “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà” wa, kí á má ṣe gba ẹnikẹ́ni tàbí ohunkóhun láyè láti gba ipò tó tọ́ sí Jèhófà lọ́kàn wa!—Òwe 4:23; Jákọ́bù 1:14.
Jèhófà Ń Rọ̀ Wọ́n
17. Kí ló yẹ kí Ísírẹ́lì fi sọ́kàn?
17 Lẹ́yìn náà, Jèhófà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n rántí pé àǹfààní ló jẹ́ fún wọn, àti pé wọ́n ní ojúṣe láti ṣe, ní ipò pàtàkì tí wọ́n wà. Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni wọ́n o! Ó ní: “Rántí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jékọ́bù, àti ìwọ, Ísírẹ́lì, nítorí pé ìránṣẹ́ mi ni ọ́. Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ. Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ jẹ́. Ìwọ Ísírẹ́lì, a kì yóò gbàgbé rẹ níhà ọ̀dọ̀ mi. Ṣe ni èmi yóò nu àwọn ìrélànàkọjá rẹ kúrò gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú àwọsánmà, àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìwọ́jọpọ̀ àwọsánmà. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí pé èmi yóò tún ọ rà dájúdájú. Ẹ fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí pé Jèhófà ti gbé ìgbésẹ̀! Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun, ẹ̀yin apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé! Ẹ tújú ká, ẹ̀yin òkè ńláńlá, pẹ̀lú igbe ìdùnnú, ìwọ igbó àti gbogbo ẹ̀yin igi tí ń bẹ nínú rẹ̀! Nítorí pé Jèhófà ti tún Jékọ́bù rà, ó sì fi ẹwà rẹ̀ hàn lára Ísírẹ́lì.”—Aísáyà 44:21-23.
18. (a) Èé ṣe tí Ísírẹ́lì fi ní ìdí láti máa yọ̀? (b) Báwo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe lè ṣàfarawé àpẹẹrẹ àánú rẹ̀ lóde òní?
18 Ísírẹ́lì kọ́ ló ṣẹ̀dá Jèhófà. Jèhófà kì í ṣe òrìṣà àtọwọ́dá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà ló ṣẹ̀dá Ísírẹ́lì láti fi í ṣe àyànfẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀. Yóò sì tún fi ẹ̀rí hàn lẹ́ẹ̀kan sí i pé Ọlọ́run ni òun nígbà tó bá dá orílẹ̀-èdè yẹn nídè. Ó fi pẹ̀lẹ́tù bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó mú un dá wọn lójú pé bí wọ́n bá ronú pìwà dà, òun yóò bo ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́lẹ̀ pátá, tí òun yóò sì fi ìrélànàkọjá wọn pa mọ́ bí ẹní fi nǹkan pa mọ́ sẹ́yìn àwọsánmà líle. Èyí mà táyọ̀ fún Ísírẹ́lì o! Àpẹẹrẹ tí Jèhófà fi lélẹ̀ ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní ṣàfarawé àánú rẹ̀. Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa wíwá ọ̀nà láti ṣèrànlọ́wọ́ fún àwọn tó dẹ́ṣẹ̀, ìyẹn ni láti gbìyànjú láti mú wọn bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí bó bá ṣeé ṣe.—Gálátíà 6:1, 2.
Àṣekágbá Ìdánwò Láti fi Mọ Ẹni Tó Jẹ́ Ọlọ́run
19, 20. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà sọ àsọkágbá ọ̀rọ̀ ẹjọ́ rẹ̀? (b) Àwọn ohun amọ́kànyọ̀ wo ni Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn rẹ̀, ta sì ni ońṣẹ́ rẹ̀ tí yóò lò láti ṣe àwọn ohun náà?
19 Jèhófà wá fẹ́ sọ àgbà ọ̀rọ̀ àsọkágbá lórí ẹjọ́ rẹ̀ wàyí. Ó fẹ́ sọ ìdáhùn rẹ̀ lórí ìdánwò tó gbóná jù lọ nípa ẹni tó jẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́, ìyẹn agbára láti lè sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la láìsí pé ó yingin. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kan pe ẹsẹ márùn-ún tó tẹ̀ lé e nínú Aísáyà orí kẹrìnlélógójì ní “ewì tó fi Ọlọ́run Ísírẹ́lì hàn bí ẹni gíga jù lọ,” ọ̀kan ṣoṣo Ẹlẹ́dàá, Olùṣípayá ọjọ́ ọ̀la, ìrètí ìdáǹdè fún Ísírẹ́lì. Àyọkà yìí ń rinlẹ̀ síwájú sí i ni látorí àgbà ọ̀rọ̀ kan bọ́ sórí òmíràn títí ó fi dé paríparì rẹ̀ tó ti dárúkọ ẹni tí yóò dá orílẹ̀-èdè yẹn nídè kúrò ní Bábílónì.
20 Ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, Olùtúnnirà rẹ àti Aṣẹ̀dá rẹ láti inú ikùn wá: ‘Èmi, Jèhófà, ń ṣe ohun gbogbo, mo na ọ̀run ní èmi nìkan, mo tẹ́ ilẹ̀ ayé. Ta ni ó wà pẹ̀lú mi? Mo ń mú àwọn iṣẹ́ àmì àwọn olùsọ òfìfo ọ̀rọ̀ já sí pàbó, èmi sì ni Ẹni tí ń mú kí àwọn woṣẹ́woṣẹ́ pàápàá máa ṣe bí ayírí; Ẹni tí ń dá àwọn ọlọ́gbọ́n padà sẹ́yìn, àti Ẹni tí ń sọ ìmọ̀ wọn pàápàá di òmùgọ̀; Ẹni tí ń mú kí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ, àti Ẹni tí ń mú ìmọ̀ràn àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ pátápátá; Ẹni tí ń wí nípa Jerúsálẹ́mù pé, “A óò gbé inú rẹ̀,” àti nípa àwọn ìlú ńlá Júdà pé, “A óò tún wọn kọ́, èmi yóò sì gbé àwọn ibi ahoro rẹ̀ dìde”; Ẹni tí ń wí fún ibú omi pé, “Gbẹ; gbogbo odò rẹ sì ni èmi yóò mú gbẹ táútáú”; Ẹni tí ó wí nípa Kírúsì pé, “Òun ni olùṣọ́ àgùntàn mi, gbogbo ohun tí mo sì ní inú dídùn sí ni òun yóò mú ṣe pátápátá”; àní nínú àsọjáde mi nípa Jerúsálẹ́mù pé, “A óò tún un kọ́,” àti nípa tẹ́ńpìlì pé, “A ó fi ìpìlẹ̀ rẹ lélẹ̀.”’ ”—Aísáyà 44:24-28.
21. Ẹ̀rí ìdánilójú wo ni ọ̀rọ̀ Jèhófà pèsè?
21 Ní tòótọ́, yàtọ̀ sí pé Jèhófà lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ ọ̀la, ó tún lágbára láti mú ète rẹ̀ tó bá ti ṣí payá ṣẹ látòkèdélẹ̀. Orísun ìṣírí ni ìkéde yìí yóò jẹ́ fún Ísírẹ́lì. Ó jẹ́ ẹ̀rí ìdánilójú pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì yóò pa ilẹ̀ yẹn run, Jerúsálẹ́mù àti ìgbèríko rẹ̀ yóò tún padà bọ̀ sípò, a ó sì tún padà fìdí ìsìn mímọ́ múlẹ̀ níbẹ̀. Ṣùgbọ́n báwo ni ìyẹn yóò ṣe wáyé?
22. Ṣàpèjúwe bí Odò Yúfírétì ṣe gbẹ.
22 Àwọn woṣẹ́woṣẹ́ aláìní ìmísí kì í sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní ṣàkó torí ìbẹ̀rù pé ìgbà lè yí padà kó sì sọ wọ́n dèké. Láìdàbí tiwọn, Jèhófà gbẹnu Aísáyà dárúkọ ẹni tí òun yóò lò láti dá àwọn èèyàn òun nídè kúrò nígbèkùn, tí wọn yóò fi lè padà lọ sílé láti tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́. Kírúsì lorúkọ rẹ̀, ayé sì mọ̀ ọ́n sí Kírúsì Ńlá ti Páṣíà. Jèhófà tún sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọgbọ́n ogun tí Kírúsì yóò dá láti fi jágbọ́n onírúurú ààbò rẹpẹtẹ tó díjú tí Bábílónì gbé kalẹ̀. Àwọn odi tó ga àti àwọn ipadò tó ń ṣàn gba inú ìlú, tó sì tún yí ìlú po, ni Bábílónì yóò fi ṣe ààbò. Ohun tó gba iwájú jù lọ nínú ìgbékalẹ̀ ààbò yìí gan-an ni Kírúsì yóò sì kúkú wá lò láti fi ṣọṣẹ́, ìyẹn Odò Yúfírétì. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn ìgbàanì, Hẹrodótù àti Sẹ́nófọ̀n ṣe wí, ibì kan lápá òkè ibi tí odò yìí ti ń ṣàn wá sí Bábílónì ni Kírúsì ti darí omi odò Yúfírétì gba ibòmíràn lọ, tí omi odò yìí sì fi fà, débi pé àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lè wọ́dò kọjá. Nígbà tí odò yìí kò sì ti lè dáàbò bo Bábílónì, alagbalúgbú odò Yúfírétì gbẹ lọ́nà yẹn nìyẹn.
23. Àkọsílẹ̀ wo ló wà ní ti ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ náà pé Kírúsì yóò dá Ísírẹ́lì nídè?
23 Ìlérí pé Kírúsì yóò dá àwọn èèyàn Ọlọ́run nídè, pé yóò sì rí sí i pé wọ́n tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́ wá ńkọ́? Nínú ìkéde kan tí Kírúsì ọba fúnra rẹ̀ ṣe, tó ṣì wà nínú Bíbélì di báyìí, ó ní: “Èyí ni ohun tí Kírúsì ọba Páṣíà wí, ‘Gbogbo ìjọba ilẹ̀ ayé ni Jèhófà Ọlọ́run ọ̀run ti fi fún mi, òun fúnra rẹ̀ sì ti fàṣẹ yàn mí pé kí n kọ́ ilé fún òun ní Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà. Ẹnì yòówù tí ń bẹ láàárín yín nínú gbogbo ènìyàn rẹ̀, kí Ọlọ́run rẹ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀. Nítorí náà, kí ó gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, tí ó wà ní Júdà, kí ó sì tún ilé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì kọ́—òun ni Ọlọ́run tòótọ́—èyí tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù.’” (Ẹ́sírà 1:2, 3) Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ ṣẹ látòkèdélẹ̀!
Aísáyà, Kírúsì, àti Àwọn Kristẹni Lónìí
24. Ìsopọ̀ wo ló wà láàárín àṣẹ tí Atasásítà pa “láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́” pẹ̀lú dídé Mèsáyà?
24 Orí kẹrìnlélógójì ìwé Aísáyà gbé Jèhófà ga gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà àti Olùdáǹdè àwọn èèyàn rẹ̀ ayé àtijọ́. Ẹ̀wẹ̀, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ní ìtumọ̀ tó jinlẹ̀ fún gbogbo wa lóde òní pẹ̀lú. Àṣẹ tí Kírúsì pa lọ́dún 538 sí 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, pé kí wọ́n lọ tún Jerúsálẹ́mù kọ́, ló jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó yọrí sí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì mìíràn. Lẹ́yìn àṣẹ Kírúsì, ọba mìíràn tó jẹ lẹ́yìn náà, ìyẹn Atasásítà, tún pàṣẹ tẹ̀ lé tirẹ̀, pé kí wọ́n lọ tún ìlú Jerúsálẹ́mù kọ́. Ìwé Dáníẹ́lì ṣí i payá pé “láti ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà láti mú Jerúsálẹ́mù padà bọ̀ sípò àti láti tún un kọ́ [ní ọdún 455 ṣááju Sànmánì Tiwa] títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú,” àpapọ̀ “ọ̀sẹ̀” mọ́kàndínláàádọ́rin tí ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan rẹ̀ jẹ́ ọdún méje ni yóò wà. (Dáníẹ́lì 9:24, 25) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ bákan náà. Nígbà tí ó tó àkókò gẹ́lẹ́, lọ́dún 29 Sànmánì Tiwa, ní ọ̀rìnlénírínwó ó lé mẹ́ta [483] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní Ilẹ̀ Ìlérí bí àṣẹ Atasásítà ṣe wí, Jésù ṣe batisí, ó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.a
25. Kí ni ṣíṣubú tí Kírúsì mú kí Bábílónì ṣubú ń tọ́ka sí láyé òde òní?
25 Ìṣubú Bábílónì, tó mú kí títú tí wọ́n tú àwọn Júù olóòótọ́ sílẹ̀ nígbèkùn lè wáyé, jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣáájú fún ìtúsílẹ̀ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí lọ́dún 1919. Ìtúsílẹ̀ yẹn jẹ́ ẹ̀rí pé Bábílónì mìíràn, táa ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó kan, ìyẹn Bábílónì Ńlá, tó dúró fún gbogbo ẹ̀sìn èké àgbáyé lápapọ̀, rí ìṣubú kan nìyẹn. Àpọ́sítélì Jòhánù ti ríran pé yóò ṣubú tẹ́lẹ̀, bí ó ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Ìṣípayá. (Ìṣípayá 14:8) Ó sì tún rí àrítẹ́lẹ̀ nípa ìparun òjijì tí yóò bá a. Bí Jòhánù ṣe ṣàpèjúwe ìparun ilẹ̀ ọba àgbáyé tí òrìṣà kún fọ́fọ́ yẹn fi àwọn ọ̀nà kan jọ àpèjúwe tí Aísáyà ṣe nípa bí Kírúsì yóò ṣe ja àjàṣẹ́gun lórí ìlú Bábílónì àtijọ́. Gẹ́lẹ́ bí àwọn ipadò tó jẹ́ ààbò fún Bábílónì kò ṣe lè gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ Kírúsì, bẹ́ẹ̀ ni “àwọn omi” aráyé tó kọ́wọ́ ti Bábílónì Ńlá tó sì ń dáàbò bò ó yóò ṣe “gbẹ ráúráú” kí ìparun tó tọ́ sí i tó dé bá a.—Ìṣípayá 16:12.b
26. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà àti ìmúṣẹ rẹ̀ ṣe fún ìgbàgbọ́ wa lókun?
26 Tí a bá wò ó lóde òní, ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, a rí i pé ní tòótọ́ Ọlọ́run “mú ìmọ̀ràn àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ pátápátá.” (Aísáyà 44:26) Nítorí náà, ṣíṣẹ tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ jẹ́ àpẹẹrẹ kan tó ta yọ nípa bí ó ṣe jẹ́ pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ló ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo orí kọkànlá ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
b Wo orí karùndínlógójì àti ìkẹrìndínlógójì ìwé Ìṣípayá-Òtéńté Rẹ̀ Títóbi Lọ́lá Kù Sí Dẹ̀dẹ̀!, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 63]
Ṣé àjókù igi wá lè gba ẹnikẹ́ni là?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 73]
Orí ọ̀kan nínú Ọba ilẹ̀ Iran, òkúta mábìlì ni wọ́n fi gbẹ́ ẹ, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti Kírúsì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 75]
Kírúsì mú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ ní dídarí tó darí omi odò Yúfírétì gba ibòmíràn lọ