Dídá Àwọn Ońṣẹ́ Tòótọ́ Mọ̀ Yàtọ̀
“Ẹni tí . . . ó fi ìdí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì mú ìmọ̀ àwọn [ońṣẹ́, NW] rẹ̀ ṣẹ.”—AÍSÁYÀ 44:25, 26.
1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn ońṣẹ́ tòótọ́ hàn yàtọ̀, báwo sì ni ó ṣe ń táṣìírí àwọn èké ońṣẹ́?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ni Atóbilọ́lá ẹni tí ń fi àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́ hàn yàtọ̀. Ó ń fi wọ́n hàn yàtọ̀ nípa mímú kí ọ̀rọ̀ tí òun tipasẹ̀ wọn sọ ní ìmúṣẹ. Jèhófà tún ni Atóbilọ́lá Olùtáṣìírí àwọn èké ońṣẹ́. Báwo ni ó ṣe ń táṣìírí wọn? Ó ń mú kí àwọn àmì àti àsọtẹ́lẹ̀ wọn já sí òtúbáńtẹ́. Lọ́nà yí, ó ń fi hàn pé, alásọtẹ́lẹ̀ tí ó yan ara rẹ̀ sípò ni wọ́n jẹ́, tí ìhìn iṣẹ́ wọ́n wá láti inú èrò èké tiwọn fúnra wọn—bẹ́ẹ̀ ni, láti inú ìrònú òmùgọ̀ wọn, tí ó jẹ́ ti ẹran ara!
2. Ìforígbárí wo ni ó ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn ońṣẹ́ ní àkókò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
2 Aísáyà àti Ìsíkẹ́ẹ̀lì sọ pé àwọn jẹ́ ońṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run. Ṣé lóòótọ́ ni? Ẹ jẹ́ kí a wò ó ná. Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù láti nǹkan bí ọdún 778 ṣááju Sànmánì Tiwa, títí di nǹkan bí ẹ̀yìn ọdún 732 ṣááju Sànmánì Tiwa. A mú Ìsíkẹ́ẹ̀lì nígbèkùn lọ sí Bábílónì ní ọdún 617 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ó sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù arákùnrin rẹ̀ tí ó wà níbẹ̀. Àwọn wòlíì méjèèjì fìgboyà kéde pé, a óò pa Jerúsálẹ́mù run. Àwọn wòlíì míràn sọ pé Ọlọ́run kò ní yọ̀ǹda kí èyí ṣẹlẹ̀. Àwọn wo ni wọ́n fẹ̀rí hàn pé àwọn jẹ́ ońṣẹ́ tòótọ́?
Jèhófà Táṣìírí Àwọn Wòlíì Èké
3, 4. (a) Ìhìn iṣẹ́ méjì tí ó takora wo ni a fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Bábílónì, báwo sì ni Jèhófà ṣe táṣìírí èké ońṣẹ́ kan? (b) Kí ni Jèhófà sọ pé yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn wòlíì èké?
3 Nígbà tí Ìsíkẹ́ẹ̀lì wà ní Bábílónì, a fi ìran ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù hàn án. Àwọn ọkùnrin 25 dúró ní ẹnubodè apá ìlà oòrùn. Àwọn ọmọ aládé méjì, Jaasáyà àti Pẹlatáyà, ń bẹ láàárín wọn. Ojú wo ni Jèhófà fi wò wọ́n? Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:2, 3 (NW) dáhùn pé: “Ọmọkùnrin ènìyàn, àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọkùnrin tí ń pète ìṣenilọ́ṣẹ́, tí wọ́n sì ń fúnni ní ìmọ̀ràn búburú lòdì sí ìlú yìí; tí wọ́n ń sọ pé, ‘Kíkọ́ àwọn ilé kò ha sún mọ́lé bí?’” Àwọn aṣàyàgbàǹgbà ońṣẹ́ àlàáfíà wọ̀nyí ń sọ pé, ‘Kò sí ewu kankan tí ń bọ̀ sórí Jerúsálẹ́mù. Họ́wù, a óò kọ́ ilé púpọ̀ sí i sínú rẹ̀ láìpẹ́!’ Nítorí náà, Ọlọ́run sọ fún Ìsíkẹ́ẹ̀lì pé kí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ tí yóò ta ko àwọn ońṣẹ́ irọ́ wọ̀nyí. Ní ẹsẹ 13, orí 11, Ìsíkẹ́ẹ̀lì sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀kan lára wọn fún wa: “Ó sì ṣe, nígbà tí mo sọ tẹ́lẹ̀, Pẹlatáyà ọmọ Bẹnáyà kú.” Ó ṣeé ṣe kí èyí ṣẹlẹ̀ nítorí pé, Pẹlatáyà ni ó tayọ lọ́lá jù lọ, tí ó sì ní agbára ìdarí jù lọ láàárín àwọn ọmọ aládé, òun ni ó sì jẹ́ abọ̀rìṣà paraku jù lọ. Kíkú tí ó kú ikú òjijì fi hàn pé wòlíì èké ni!
4 Pípa tí Jèhófà pa Pẹlatáyà kò mú kí àwọn wòlíì èké yòó kù ṣíwọ́ píparọ́ lórúkọ Ọlọ́run. Àwọn ẹlẹ́tàn wọ̀nyí ń bá a nìṣó nínú ipa ọ̀nà òpònú wọn, ti sísọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí ìfẹ́ inú Ọlọ́run. Nítorí náà, Jèhófà Ọlọ́run sọ fún Ìsíkẹ́ẹ̀lì pé: “Ègbé ni fún àwọn aṣiwèrè wòlíì, tí wọ́n ń tẹ̀ lé ẹ̀mí ara wọn, tí wọn kò sì rí nǹkan!” Gẹ́gẹ́ bíi Pẹlatáyà, wọn ‘kò ní sí mọ́’ nítorí tí wọ́n gbójú gbóyà láti rí “ìran àlàáfíà” fún Jerúsálẹ́mù, “bẹ́ẹ̀ ni àlàáfíà kò sí.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 13:3, 15, 16.
5, 6. Láìka gbogbo àwọn èké ońṣẹ́ sí, báwo ni a ṣe dá Aísáyà láre gẹ́gẹ́ bíi wòlíì tòótọ́?
5 Ní ti Aísáyà, gbogbo ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ àtọ̀runwá nípa Jerúsálẹ́mù ni ó ṣẹ. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ará Bábílónì pa ìlú náà run, wọ́n sì kó àwọn Júù tí ó ṣẹ́ kù nígbèkùn lọ sí Bábílónì. (Kíróníkà Kejì 36:15-21; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 22:28; Dáníẹ́lì 9:2) Àwọn àjálù wọ̀nyí ha mú kí àwọn wòlíì èké ṣíwọ́ rírọ̀jò ọ̀rọ̀ òpònú lásán sórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run bí? Rárá o, àwọn ońṣẹ́ irọ́ wọ̀nyẹn kò jáwọ́ nínú àpọ̀n tí kò yọ̀!
6 Ní àfikún sí èyí, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n wà ní ìgbèkùn tún ń gbọ́ ìsọkúsọ tí àwọn aríran, àwọn woṣẹ́woṣẹ́, àti awòràwọ̀ tí ń fọ́nnu ń sọ. Ṣùgbọ́n, Jèhófà fi àwọn ońṣẹ́ èké wọ̀nyí hàn gẹ́gẹ́ bí òmùgọ̀ tí ìsapá wọn já sí òtúbáńtẹ́, tí wọ́n ń sọ òdì kejì ohun tí yóò ṣẹlẹ̀. Nígbà tí àkókò tó, ó fi hàn pé Ìsíkẹ́ẹ̀lì ni ońṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà pẹ̀lú ti jẹ́. Jèhófà mú gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ láti ẹnu wọn ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí, pé: “Ẹni tí ó sọ àmì àwọn èké di asán, tí ó sì ba àwọn aláfọ̀ṣẹ ní orí jẹ́, tí ó dá àwọn ọlọgbọ́n pa dà, tí ó sì sọ ìmọ̀ wọn di wèrè. Tí ó fi ìdí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì mú ìmọ̀ àwọn [ońṣẹ́, NW] rẹ̀ ṣẹ.”—Aísáyà 44:25, 26.
Ìhìn Iṣẹ́ Amúnitagìrì Nípa Bábílónì àti Jerúsálẹ́mù
7, 8. Ìhìn iṣẹ́ onímìísí wo ni Aísáyà ní fún Bábílónì, kí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ túmọ̀ sí?
7 A óò sọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù dahoro pátápátá, láìní olùgbé kankan, fún 70 ọdún. Ṣùgbọ́n, Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà àti Ìsíkẹ́ẹ̀lì polongo pé, a óò tún ìlú náà kọ́, a óò sì pa dà gbé ilẹ̀ náà, ní àkókò gan-an tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀! Àgbàyanu àsọtẹ́lẹ̀ ni èyí jẹ́. Èé ṣe? Nítorí pé, a mọ Bábílónì sí orílẹ̀-èdè tí kì í jẹ́ kí àwọn ẹlẹ́wọ̀n rẹ̀ kófìrí ilẹ̀ ìbílẹ̀ wọn mọ́ láé. (Aísáyà 14:4, 15-17) Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ta ní lè tú àwọn ìgbèkùn wọ̀nyí sílẹ̀? Ta ní lè bi Bábílónì alágbára ṣubú, tí àwọn ògiri gìrìwò àti odò rẹ̀ dáàbò bò? Jèhófà Olódùmarè lè ṣe bẹ́ẹ̀! Ó sì wí pé òun yóò ṣe bẹ́ẹ̀: “[Èmi ni ẹni] . . . tí ó wí fún ibú [ìyẹn ni, odò tí ó dáàbò bo ìlú náà] pé, Gbẹ, èmi óò sì mú gbogbo odò rẹ gbẹ. Tí ó wí ní ti Kírúsì pé, Olùṣọ́ àgùntàn mi ni, yóò sì mú gbogbo ìfẹ́ mi ṣẹ: tí ó wí ní ti Jerúsálẹ́mù pé, A óò kọ́ ọ: àti ní ti tẹ́ńpìlì pé, A óò fi ìpìlẹ̀ rẹ sọlẹ̀.”—Aísáyà 44:25, 27, 28.
8 Ro ìyẹn wò ná! Odò Yúfírétì, tí ó jẹ́ ìdínà apániláyà fún àwọn ènìyàn, jẹ́ ẹ̀kán omi lórí òkúta gbígbóná fẹlifẹli lójú Jèhófà! Kíá ni yóò gbẹ, táútáú! Bábílónì yóò ṣubú. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ nǹkan bí 150 ọdún ṣáájú kí a tó bí Kírúsì ará Páṣíà, Jèhófà mú kí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ọba yìí yóò ṣe ṣẹ́gun Bábílónì, tí yóò sì dá àwọn Júù tí ó wà nígbèkùn sílẹ̀, nípa fífún wọn láṣẹ láti pa dà lọ tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́.
9. Ta ni Jèhófà pè ní aṣojú rẹ̀ fún jíjẹ Bábílónì níyà?
9 A rí àsọtẹ́lẹ̀ yí nínú Aísáyà 45:1-3: “Báyìí ni Olúwa wí fún ẹni òróró rẹ̀, fún Kírúsì, ẹni tí mo di ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ mú, láti ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ̀; . . . láti ṣí ilẹ̀kùn méjèèjì níwájú rẹ̀, a kì yóò sì ti ààṣẹ̀ náà; Èmi óò lọ ṣáájú rẹ, èmi óò sì sọ ibi wíwọ́ wọnnì di títọ́: èmi óò fọ́ ilẹ̀kùn idẹ wọnnì túútúú, èmi óò sì ké ọ̀já irin sí méjì. Èmi óò sì fi ìṣúra òkùnkùn fún ọ, àti ọrọ̀ tí a pa mọ́ níbi ìkọ̀kọ̀, kí ìwọ lè mọ̀ pé, èmi Olúwa, tí ó pè ọ́ ní orúkọ rẹ, ni Ọlọ́run.”
10. Lọ́nà wo ni Kírúsì fi jẹ́ “ẹni àmì òróró,” báwo sì ni Jèhófà ṣe lè bá a sọ̀rọ̀ ni ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú kí a tó bí i?
10 Ṣàkíyèsí pé Jèhófà bá Kírúsì sọ̀rọ̀ bí ẹni pé ó wà láàyè. Èyí bá ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù mu, pé Jèhófà “pe àwọn ohun tí kò sí bí ẹni pé wọ́n wà.” (Róòmù 4:17) Bákan náà, Ọlọ́run pe Kírúsì ní ‘ẹni òróró òun.’ Èé ṣe tí ó fi sọ bẹ́ẹ̀? Ó ṣe tán, àlùfáà àgbà Jèhófà kò fìgbà kan rí da òróró mímọ́ sí Kírúsì lórí. Òtítọ́ ni, ṣùgbọ́n yíyàn alásọtẹ́lẹ̀ ni èyí. Ó túmọ̀ sí yíyanni sí ipò iṣẹ́ àkànṣe kan. Nítorí náà, Ọlọ́run lè pe yíyàn tí ó yan Kírúsì sípò ṣáájú àkókò ní ìfòróróyàn.—Fi wé Ọba Kìíní 19:15-17; Ọba Kejì 8:13.
Ọlọ́run Mú Ọ̀rọ̀ Àwọn Ońṣẹ́ Rẹ̀ Ṣẹ
11. Èé ṣe tí àwọn olùgbé Bábílónì fi rò pé kò séwu?
11 Nígbà tí Kírúsì kógun ti Bábílónì, àwọn olùgbé rẹ̀ ronú pé kò séwu, pé kò sí ẹni tí ó lè ṣẹ́gun ìlú wọn. Iyàrà jínjìn, tí ó fẹ̀, tí ó sì lè pèsè ààbò, tí Odò Yúfírétì gbẹ́ yíká rẹ̀, yí ìlú náà ká. Èbúté gígùn jàn-ànràn jan-anran kan wà ní ìhà ìlà oòrùn bèbè odò náà, tí ó ṣàn la ìlú náà já. Láti lè yà á sọ́tọ̀ kúrò lára ìlú, Nebukadinésárì kọ́ ohun tí ó pè ní “ògiri ńlá, tí ó dà bí òkè ńlá [tí kò ṣeé] ṣí nídìí . . . Òkè rẹ̀ ga bí òkè ńlá.”a Idẹ ni a fi ṣe àwọn ilẹ̀kùn gàgàrà ẹnubodè ògiri yìí. Ẹnì kan ní láti pọ́n gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ náà láti etí odò, kí ó tó lè wọ inú wọn. Abájọ tí àwọn ìgbèkùn Bábílónì fi sọ ìrètí nù pé a lè dá wọn sílẹ̀!
12, 13. Báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà ońṣẹ́ rẹ̀ sọ ṣe ní ìmúṣẹ nígbà tí Bábílónì ṣubú sọ́wọ́ Kírúsì?
12 Ṣùgbọ́n, ìrètí àwọn Júù tí a kó nígbèkùn, tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà, kò ṣákìí! Wọ́n ní ìrètí tí ó dájú. Nípasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀, Ọlọ́run ti ṣèlérí láti dá wọn sílẹ̀. Báwo ni Ọlọ́run ṣe mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Kírúsì pàṣẹ pé kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ darí Odò Yúfírétì sí ọ̀pọ̀ kìlómítà ní ìhà àríwá Bábílónì. Nípa báyìí, dé ìwọ̀n gíga, olórí ààbò ìlú náà ti di etí bèbè gbígbẹ táútáú. Ní alẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé yẹn, àwọn alárìíyá aláriwo ní Bábílónì, tí wọ́n ti mu ọtí yó kẹ́ri, fi ilẹ̀kùn aláwẹ́ méjì náà tí ó wà lórí etí bèbè Yúfírétì sílẹ̀ gbayawu ní ṣíṣí sílẹ̀, láìbìkítà. Jèhófà kò fọ́ àwọn ilẹ̀kùn idẹ náà sí wẹ́wẹ́ ní ti gidi; bẹ́ẹ̀ sì ni kò gé àwọn ọ̀já irin tí a fi ń ti àwọn ilẹ̀kùn ẹnubodè náà ní ti gidi, ṣùgbọ́n bí ó ṣe fọgbọ́n darí ọ̀ràn lọ́nà ìyanu, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n wà ní ṣíṣí sílẹ̀ gbayawu, tí a kò sì fi àgádágodo tì wọ́n ní àbájáde kan náà. Àwọn ògiri Bábílónì kò wúlò! Àwọn ọmọ ogun Kírúsì kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní láti gùn wọ́n kí wọ́n tó wọ inú ìlú. Jèhófà ti lọ ṣáájú Kírúsì, láti sọ “ibi wíwọ́” di títọ́, bẹ́ẹ̀ ni, láti mú gbogbo ìdènà kúrò lọ́nà. A fi hàn pé Aísáyà jẹ́ ońṣẹ́ tòótọ́ ti Ọlọ́run.
13 Nígbà tí ìṣàkóso gbogbo ìlú náà bọ́ sí Kírúsì lọ́wọ́, gbogbo ìṣúra rẹ̀, títí kan àwọn tí a fi pa mọ́ síbi òkùnkùn, nínú àwọn yàrá kọ́lọ́fín, bọ́ sí ìkáwọ́ rẹ̀. Èé ṣe tí Jèhófà Ọlọ́run fi ṣe gbogbo èyí fún Kírúsì? Kí ó baà lè mọ̀ pé Jèhófà, ‘Ẹni tí ó pè é ní orúkọ rẹ̀,’ ni Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́ àti Olúwa Ọba Aláṣẹ àgbáyé. Òun yóò mọ̀ pé Ọlọ́run ti ṣètò fún òun láti gba agbára láti dá àwọn ènìyàn Rẹ̀, Ísírẹ́lì, sílẹ̀.
14, 15. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ni ó yẹ kí ó gba gbogbo ògo ìṣẹ́gun Kírúsì lórí Bábílónì?
14 Tẹ́tí sí ohun tí Jèhófà sọ fún Kírúsì: “Nítorí Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, àti Ísírẹ́lì àyànfẹ́ mi, èmi ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ: mo fi àpèlé kan fún ọ, bí ìwọ kò tilẹ̀ tí ì mọ̀ mí. Èmi ní Olúwa, kò sí ẹlòmíràn, kò sí Ọlọ́run kan lẹ́yìn mi; mo dì ọ́ ní àmùrè, bí ìwọ kò tilẹ̀ tí ì mọ̀ mí. Kí wọ́n lè mọ̀ láti ìlà oòrùn, àti láti ìwọ̀ oòrùn wá pé, kò sí ẹnì kan lẹ́yìn mi; Èmi ni Olúwa, kò sí ẹlòmíràn. Mo dá ìmọ́lẹ̀, mo sì dá òkùnkùn: mo [sì tún] ṣe àlàáfíà [ìyẹn ni pé, fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó wà nígbèkùn], mo sì dá ibi [fún Bábílónì]: Èmi Olúwa ni ó ṣe gbogbo ìwọ̀nyí.”—Aísáyà 45:4-7.
15 Jèhófà ni ó yẹ kí ó gba gbogbo ògo ìṣẹ́gun Kírúsì lórí Bábílónì, nítorí Òun ni ó fún un lókun láti mú ìfẹ́ inú Rẹ̀ sí ìlú búburú yẹn ṣẹ, kí ó sì dá àwọn ènìyàn Rẹ̀ tí ó wà nígbèkùn sílẹ̀. Ní ṣíṣe èyí, Ọlọ́run ké sí àwọn ọ̀run rẹ̀ láti rọ agbára ìdarí tàbí ipá ìdarí òdodo sílẹ̀. Ó ké sí ilẹ̀ ayé rẹ̀ kí ó lanu, kí ó sì mú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ òdodo àti ìgbàlà jáde fún àwọn ènìyàn rẹ̀ tí ó wà nígbèkùn. Àwọn ọ̀run rẹ̀ àti ilẹ̀ ayé rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ dáhùn pa dà sí àṣẹ yìí. (Aísáyà 45:8) Ohun tí ó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ikú rẹ̀, a fi Aísáyà hàn gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ tòótọ́ ti Jèhófà!
Ìhìn Rere Ońṣẹ́ Náà fún Síónì!
16. Nígbà tí a ṣẹ́gun Bábílónì, ìhìn rere wo ni a lè polongo ní ìlú Jerúsálẹ́mù tí a ti sọ dahoro?
16 Ṣùgbọ́n ó kù ni ìbọn ń ró. Aísáyà 52:7 sọ nípa ìhìn rere fún Jerúsálẹ́mù pé: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìhìn rere wá ti dára tó lórí àwọn òkè, tí ń kéde àlàáfíà; tí ń mú ìhìn rere ohun rere wá, tí ń kéde ìgbàlà; tí ó wí fún Síónì pé, Ọlọ́run rẹ ń jọba!” Ẹ wo bí yóò ti múni lára yá gágá tó láti rí ońṣẹ́ kan, láti orí òkè, tí ń sún mọ́ Jerúsálẹ́mù! Ó gbọ́dọ̀ ní ìròyìn tí ó fẹ́ sọ. Kí ni ìròyìn náà? Ó jẹ́ ìròyìn amọ́kànyọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ fún Síónì. Ìròyìn àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni, ìròyìn ìfẹ́ rere Ọlọ́run. A óò tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ kọ́! Ońṣẹ́ náà sì pòkìkí, pẹ̀lú ìtara ayọ̀ ìṣẹ́gun pé: “Ọlọ́run rẹ ń jọba!”
17, 18. Báwo ni ìṣẹ́gun Kírúsì lórí Bábílónì ṣe nípa lórí orúkọ Jèhófà?
17 Nígbà tí Jèhófà yọ̀ǹda kí àwọn ará Bábílónì dojú ìtẹ́ rẹ̀ ìṣàpẹẹrẹ, lórí èyí tí àwọn ọba ìlà Dáfídì jókòó lé, dé, ó ti lè jọ bíi pé, Òun kì í ṣe ọba mọ́. Mádọ́ọ́kù, olórí ọlọ́run Bábílónì, ni ó wá dà bí ọba tí ó rọ́pò rẹ̀. Ṣùgbọ́n, nígbà tí Ọlọ́run Síónì bi Bábílónì ṣubú, ó fi ipò ọba aláṣẹ àgbáyé rẹ̀ hàn—pé òun ni Ọba títóbi lọ́lá jù lọ. Láti lè tẹnu mọ́ òtítọ́ yìí, Jerúsálẹ́mù, “ìlú ńlá ti Ọba ńlá,” ni a óò tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀, pẹ̀lú tẹ́ńpìlì rẹ̀. (Mátíù 5:35) Ni ti ońṣẹ́ tí ó mú irú ìhìn rere bẹ́ẹ̀ wá, bí ekuru tilẹ̀ kún ẹsẹ̀ rẹ̀, tí ó bu tátá, tí ó sì dáranjẹ̀, ní ojú àwọn olólùfẹ́ Síónì àti Ọlọ́run rẹ̀, ẹ wo bí wọ́n ti rí rèǹtè rente tó!
18 Ní èrò àsọtẹ́lẹ̀, ìṣubú Bábílónì túmọ̀ sí pé, a ti fìdí Ìjọba Ọlọ́run múlẹ̀, ẹni tí ó mú ìhìn rere náà wá sì jẹ́ olùpòkìkí òkodoro òtítọ́ yẹn. Síwájú sí i, òjíṣẹ́ ìgbàanì náà, tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀, ṣàpẹẹrẹ ońṣẹ́ ìhìn rere kíkọ yọyọ—ó kọ yọyọ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ gíga lọ́lá tí ó ní nínú àti ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ti Ìjọba, pẹ̀lú ìtumọ̀ àgbàyanu tí ó ní fún gbogbo ẹni ìgbàgbọ́.
19. Ìhìn iṣẹ́ wo nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni Jèhófà ti ẹnu Ìsíkẹ́ẹ̀lì sọ?
19 A fún Ìsíkẹ́ẹ̀lì pẹ̀lú ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀-sípò tí ń múni lọ́kàn yọ̀. Ó sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Báyìí ni Olúwa Ọlọ́run wí; . . . èmi óò mú kí a tún gbé ìlú, a óò sì kọ́ ibi ahoro wọnnì. Wọn óò sì wí pé, Ilẹ̀ yí tí ó ti di ahoro ti dà bí ọgbà Édẹ́nì.”—Ìsíkẹ́ẹ̀lì 36:33, 35.
20. Ọ̀rọ̀ ìyànjú ọlọ́yàyà wo ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ fún Jerúsálẹ́mù?
20 Ní ìgbèkùn Bábílónì, àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti ń ṣọ̀fọ̀ lórí Síónì. (Orin Dáfídì 137:1) Wàyí o, wọ́n lè hó fún ayọ̀. Aísáyà gbà wọ́n níyànjú pé: “Bú sí ayọ̀, ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù: nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù pa dà. Olúwa ti fi apá mímọ́ rẹ̀ hàn ni ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo ìpín ayé yóò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa.”—Aísáyà 52:9, 10.
21. Báwo ni a ṣe mú ọ̀rọ̀ Aísáyà 52:9, 10 ṣẹ lẹ́yìn ìṣẹ́gun Bábílónì?
21 Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn àyànfẹ́ Jèhófà ní ìdí ńláǹlà láti kún fún ayọ̀. Wọn yóò pa dà gbé àwọn ibi ahoro wọ̀nyẹn, wọn yóò sì mú kí wọ́n dà bí ọgbà Édẹ́nì. Jèhófà ti “fi apá mímọ́ rẹ̀ hàn” fún wọn. Ó ká apá aṣọ rẹ̀ sókè, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀, kí ó lè ṣiṣẹ́ lórí mímú wọn pa dà wá sí ìlú ìbílẹ̀ wọn ọ̀wọ́n. Kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ kékeré lásán kan, tí kò hàn sí aráyé ni èyí jẹ́ nínú ìtàn. Rárá o, gbogbo àwọn tí ó wà láàyè nígbà náà lọ́hùn-ún rí ‘apá rẹ̀ tí ó fi hàn’ tí ń lo agbára lórí àlámọ̀rí ẹ̀dá ènìyàn láti baà lè mú ìgbàlà yíyani lẹ́nu wá fún orílẹ̀-èdè kan. Wọn rí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Aísáyà àti Ìsíkẹ́ẹ̀lì jẹ́ ońṣẹ́ tòótọ́ fún Jèhófà. Kò sí ẹni tí ó lè ṣiyè méjì pé Ọlọ́run Síónì ni Ọlọ́run alààyè kan ṣoṣo àti Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ní gbogbo ayé. Ní Aísáyà 35:2, a kà pé: “Wọn óò rí ògo Olúwa, àti ẹwà Ọlọ́run wa.” Àwọn tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ẹ̀rí yìí nípa jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run, yí pa dà láti jọ́sìn rẹ̀.
22. (a) Kí ni a lè kún fún ọpẹ́ fún lónìí? (b) Èé ṣe tí a fi ní láti kún fún ọpẹ́ ní pàtàkì pé, Jèhófà ń táṣìírí àwọn èké ońṣẹ́?
22 Ẹ wo bí ó ṣe yẹ kí a kún fún ọpẹ́ tó pé, Jèhófà fi àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́ hàn! Ní tòótọ́, òun ni ‘ẹni tí ń fi ìdí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ múlẹ̀, tí ó sì ń mú ìmọ̀ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ.’ (Aísáyà 44:26) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ìmúpadàbọ̀-sípò tí ó fún Aísáyà àti Ìsíkẹ́ẹ̀lì gbé ìfẹ́ ńláǹlà rẹ̀, inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, àti àánú rẹ̀ sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ga. Dájúdájú, gbogbo ìyìn wa tọ́ sí Jèhófà fún ohun tí ó ṣe yìí! Ó sì yẹ kí àwa lónìí kún fún ọpẹ́ ní pàtàkì pé, ó ń táṣìírí àwọn èké ońṣẹ́. Èyí jẹ́ nítorí pé, wọn pọ̀ rẹpẹtẹ nísinsìnyí káàkiri ayé. Àwọn ìhìn iṣẹ́ kẹ̀ǹkẹ̀kẹ̀ǹkẹ̀ wọn ṣá àwọn ète Jèhófà tí ó kéde tì. Àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e yóò ràn wá lọ́wọ́ láti dá àwọn èké ońṣẹ́ wọnnì mọ̀ yàtọ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé náà, The Monuments and the Old Testament, láti ọwọ́ Ira Maurice Price, 1925.
Ìwọ Ha Lè Ṣàlàyé Bí?
◻ Báwo ni Jèhófà ṣe ń fi àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ tòótọ́ hàn yàtọ̀?
◻ Nípasẹ̀ Aísáyà, ta ni Jèhófà pè ní aṣojú rẹ̀ fún ṣíṣẹ́gun Bábílónì?
◻ Báwo ni a ṣe mú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tí ó ṣàpèjúwe ìṣẹ́gun Bábílónì ṣẹ?
◻ Àbájáde rere wo ni ìṣẹ́gun Bábílónì ní lórí orúkọ Jèhófà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Lójú àwọn orílẹ̀-èdè ọjọ́ Ìsíkẹ́ẹ̀lì, Bábílónì dà bí ìlú tí kò ṣeé ṣẹ́gun