Orí Keje
Ẹ Padà Sínú Ìjọsìn Jèhófà
1. Kí ni orúkọ méjì nínú àwọn òrìṣà pàtàkì ní Bábílónì, kí ni Jèhófà sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn?
ÀÁRÍN àwọn ẹlẹ́sìn èké ni Ísírẹ́lì yóò wà nígbà tó bá di ìgbèkùn ní Bábílónì. Ní ìgbà ayé Aísáyà, àwọn èèyàn Jèhófà ṣì wà ní ilẹ̀ wọn, tẹ́ńpìlì wà níbẹ̀, ètò àlùfáà sì ń báṣẹ́ lọ níbẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè tó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run yìí ṣì tọrùn bọ ìbọ̀rìṣà. Ìyẹn ló fi wá ṣe pàtàkì láti mú wọn gbára dì sílẹ̀ kí wọ́n má bàa bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀wọ̀ fún àwọn òrìṣà Bábílónì, tàbí kó má di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sìn wọ́n. Ìdí nìyẹn tí Aísáyà fi tipa àsọtẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa méjì nínú àwọn òrìṣà pàtàkì ní Bábílónì pé: “Bélì ti tẹ̀ ba, Nébò tẹ̀ ba síwájú; àwọn òrìṣà wọn ti wá wà fún àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti fún àwọn ẹran agbéléjẹ̀, ẹrù wọn, ẹrù àjò wọn lẹ́yọ-lẹ́yọ, jẹ́ ẹrù ìnira fún àwọn ẹranko tí ó ti rẹ̀.” (Aísáyà 46:1) Bélì ni olórí àwọn òrìṣà lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà. Wọ́n ń júbà Nébò pé ó jẹ́ òrìṣà tó ni ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́ kíkọ́. Bí ọ̀wọ̀ tí ọ̀pọ̀ ń fún òrìṣà méjèèjì yìí ṣe pọ̀ tó hàn látinú bí wọ́n ṣe ń fi orúkọ wọn kún ara orúkọ tí wọ́n ń jẹ́ ní Bábílónì, irú bíi Bẹliṣásárì, Nabopolásárí, Nebukadinésárì, àti Nebusárádánì, kí á kàn mẹ́nu kan mélòó kan péré.
2. Báwo ló ṣe túbọ̀ hàn pé àwọn òrìṣà àwọn ará Bábílónì kò lè gbé ohunkóhun ṣe?
2 Aísáyà sọ pé Bélì ti “tẹ̀ ba,” àti pé Nébò “tẹ̀ ba síwájú.” Ẹ̀tẹ́ máa tó bá àwọn òrìṣà wọ̀nyí. Nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà bá dé sórí Bábílónì, òrìṣà wọ̀nyí ò ní lè gbèjà àwọn tó ń bọ wọ́n rárá. Kódà, wọn ò ní lè gba ara wọn là pàápàá! Kò ní sí àwọn tó máa tún tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ gbé Bélì àti Nébò ní ìgbé ẹ̀yẹ nígbà ayẹyẹ mọ́, irú bíi lásìkò Ọjọ́ Ọdún Tuntun ní Bábílónì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn tó ń bọ wọ́n yóò gbé wọn rù bí ẹrù àjò kan lásán. Ẹ̀sín àti ìtẹ́ńbẹ́lú ni yóò bá wọn dípò ìyìn àti àyẹ́sí wọn àtẹ̀yìnwá.
3. (a) Kí ni yóò jẹ́ kàyéfì fún àwọn ará Bábílónì? (b) Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo la lè rí kọ́ lóde òní látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn òrìṣà Bábílónì?
3 Kàyéfì gbáà ni yóò jẹ́ fún àwọn ará Bábílónì láti gbọ́ pé ẹrù lásán, tí ẹranko tó ti rẹ̀ yóò rù lọ, ni òrìṣà tí wọ́n ń gbé gẹ̀gẹ̀ jẹ́! Lóde òní bákan náà, ohun ẹ̀tàn gbáà ni àwọn òrìṣà ayé yìí jẹ́, ìyẹn àwọn ohun tí àwọn èèyàn gbẹ́kẹ̀ lé, tí wọ́n ń lo agbára wọn fún, àní tí wọ́n tilẹ̀ ń kú lé lórí pàápàá. Ọrọ̀, ohun ìjà, fàájì, àwọn alákòóso, ilẹ̀ baba ẹni tàbí ohun ìṣàpẹẹrẹ tó dúró fún un, àti ọ̀pọ̀ ohun mìíràn ti di ohun tí àwọn èèyàn ń fún ní ìfọkànsìn. Bó bá ti tákòókò lójú Jèhófà, àṣírí jíjẹ́ tí irú àwọn òrìṣà bẹ́ẹ̀ jẹ́ òtúbáńtẹ́ yóò tú.—Dáníẹ́lì 11:38; Mátíù 6:24; Ìṣe 12:22; Fílípì 3:19; Kólósè 3:5; Ìṣípayá 13:14, 15.
4. Ọ̀nà wo ni àwọn òrìṣà Bábílónì gbà “tẹ̀ ba síwájú,” tí wọn yóò sì “tẹ̀ ba”?
4 Láti túbọ̀ ṣàlàyé síwájú sí i nípa kíkùnà tí àwọn òrìṣà Bábílónì kùnà pátápátá, àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá a lọ pé: “Wọn yóò tẹ̀ ba síwájú; olúkúlùkù wọn yóò tẹ̀ ba bákan náà; wọn kò tilẹ̀ lè pèsè àsálà fún ẹrù ìnira, ṣùgbọ́n oko òǹdè ni ọkàn wọn yóò lọ.” (Aísáyà 46:2) Ó jọ pé àwọn òrìṣà Bábílónì “tẹ̀ ba síwájú” wọ́n sì “tẹ̀ ba” bí ẹni tó fara gbọgbẹ́ lójú ìjà tàbí bí ẹni tó ti darúgbó kùjọ́kùjọ́. Àní wọn ò tilẹ̀ jẹ́ kí ẹrù àwọn ẹranko tó gbé wọ́n ó fúyẹ́ pàápàá, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò jẹ́ kí ó rí ọ̀nà àjàbọ́. Nítorí náà, ṣé ó wá yẹ kí àwọn èèyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú máa wá yẹ́ àwọn òrìṣà sí bó tilẹ̀ jẹ́ pé òǹdè ni wọ́n ní Bábílónì? Ó tì o! Lọ́nà kan náà, àní títí kan ìgbà tí àwọn ẹni àmì òróró ìránṣẹ́ Jèhófà fi wà nígbèkùn nípa tẹ̀mí pàápàá, wọn kò jẹ́ yẹ́ àwọn òrìṣà “Bábílónì Ńlá” sí, àwọn òrìṣà tó jẹ́ pé kò lè gbà á sílẹ̀ kó má ṣubú lọ́dún 1919, tí wọn kò sì ní lè gbà á lọ́wọ́ àjálù tí yóò já lù ú nígbà “ìpọ́njú ńlá.”—Ìṣípayá 18:2, 21; Mátíù 24:21.
5. Báwo ni àwọn Kristẹni òde òní ṣe ń yàgò fún ṣíṣe àṣìṣe tí àwọn ará Bábílónì abọ̀rìṣà ṣe?
5 Àwọn Kristẹni tòótọ́ òde òní kì í tẹrí ba fún òrìṣà kórìṣà. (1 Jòhánù 5:21) Lílo àgbélébùú, ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà, àti àwọn ère ẹni mímọ́ kì í mú kí Ẹlẹ́dàá túbọ̀ gbọ́ tẹni. Wọn kò lè ṣe alágbàwí wa lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dàá. Ní ọ̀rúndún kìíní, Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ọ̀nà tó tọ́ láti sin Ọlọ́run nígbà tó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. Bí ẹ bá béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, èmi yóò ṣe é dájúdájú.”—Jòhánù 14:6, 14.
‘Mo Gbé E Láti Inú Ilé Ọlẹ̀’
6. Báwo ni Jèhófà ṣe yàtọ̀ sí àwọn òrìṣà àwọn orílẹ̀-èdè?
6 Bí Jèhófà ṣe fi hàn pé asán ni bíbọ àwọn òrìṣà Bábílónì já sí, ó wá sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Fetí sí mi, ìwọ ilé Jékọ́bù, àti gbogbo ẹ̀yin tí ó ṣẹ́ kù lára ilé Ísírẹ́lì, ẹ̀yin tí mo gbé láti inú ikùn, ẹ̀yin tí mo gbé láti inú ilé ọlẹ̀.” (Aísáyà 46:3) Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ mà ni ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín Jèhófà àtàwọn ère gbígbẹ́ Bábílónì o! Kò sí ohunkóhun tí àwọn òrìṣà Bábílónì lè gbé ṣe fún àwọn tó ń bọ wọ́n. Bí wọn yóò bá kúrò níbi tí wọ́n wà, àfi kí ẹranko arẹrù gbé wọn lọ. Ní ìyàtọ̀ sí wọn, Jèhófà ló ti ń gbé àwọn èèyàn tirẹ̀. “Láti inú ikùn,” ìyẹn láti ìgbà ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè yẹn ló ti ń pèsè fún wọn. Ńṣe ló yẹ kí rírántí tí àwọn Júù bá rántí tìdùnnú-tìdùnnú pé Jèhófà ló ti ń gbé àwọn bọ̀, fún wọn níṣìírí láti kọ ìbọ̀rìṣà sílẹ̀, kí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jẹ́ Bàbá àti Ọ̀rẹ́ wọn.
7. Báwo ni ìtọ́jú tí Jèhófà ń fún àwọn tó ń sìn ín ṣe ju ìtọ́jú tí òbí lè fún àwọn ọmọ wọn lọ?
7 Ọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́tù tí Jèhófà fẹ́ bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ ṣì tún kù, ó ní: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú. Dájúdájú, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀, kí èmi fúnra mi lè gbé, kí èmi fúnra mi sì lè rù, kí n sì pèsè àsálà.” (Aísáyà 46:4) Gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ni ìtọ́jú tí Jèhófà ń fún àwọn èèyàn rẹ̀ fi ju ti òbí tó lè gbọ́ tọmọ jù lọ láyé yìí. Bí àwọn ọmọ bá ti ń dàgbà, àwọn òbí lè máa kà á sí pé bùkátà wọn ń dín kù lọ́rùn àwọn nìyẹn. Bí àwọn òbí bá sì ti darúgbó, àwọn ọmọ ló sábà máa ń tọ́jú wọn. Àmọ́ ti Jèhófà ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Kì í ṣíwọ́ ìtọ́jú lórí ọmọ rẹ̀ ẹ̀dá èèyàn, àní títí dọjọ́ ogbó wọn pàápàá. Àwọn tó sin Ọlọ́run lóde òní ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ẹlẹ́dàá wọn, wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí sì ń tù wọ́n nínú gidigidi. Kò sí ìdí fún wọn láti máa ṣàníyàn nípa àwọn ọjọ́ tàbí ọdún tó kù síwájú fún wọn láti lò nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Jèhófà ṣèlérí pé òun “yóò máa ru” àwọn tó ti darúgbó, pé òun yóò máa fún wọn lókun láti máa forí tì í kí wọ́n sì máa bá ìṣòtítọ́ wọn lọ. Yóò gbé wọn, yóò fún wọn lókun, yóò sì pèsè àsálà fún wọn.—Hébérù 6:10.
Ṣọ́ra fún Àwọn Òrìṣà Òde Ìwòyí
8. Ẹ̀ṣẹ̀ tí kò ṣeé gbójú fò wo ni àwọn kan tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà pẹ̀lú Aísáyà ṣẹ̀?
8 Ẹ ò rí i bí ìjákulẹ̀ tí ń bẹ́ níwájú fún àwọn ará Bábílónì tó lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé àwọn òrìṣà ṣe pọ̀ tó, àwọn ohun tí kò wúlò rárá! Ǹjẹ́ ó wá yẹ kí Ísírẹ́lì gbà gbọ́ pé ó yẹ láti fi àwọn òrìṣà wọ̀nyẹn wé Jèhófà? Rárá o. Ìyẹn ló fi tọ́ bí Jèhófà ṣe béèrè pé: “Ta ni ẹ ó fi mí wé, tàbí tí ẹ óò mú mi bá dọ́gba tàbí tí ẹ ó fi mí ṣe àkàwé kí a lè jọra?” (Aísáyà 46:5) Áà, ó mà kúkú burú o pé àwọn tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà pẹ̀lú Aísáyà wá bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn ère tí kò lè sọ̀rọ̀, tí kò lẹ́mìí, tí kò sì lè gbé ohunkóhun ṣe! Kí orílẹ̀-èdè tó mọ Jèhófà lọ máa gbára lé àwọn ère tí ọmọ ènìyàn gbẹ́, tí wọn kò lẹ́mìí, tí wọn kò sì lè gba ara wọn jẹ́ ìwà ẹ̀gọ̀ gbáà.
9. Ṣàpèjúwe ìrònú akúrí tí àwọn abọ̀rìṣà kan ń rò.
9 Wo ìrònú akúrí tí àwọn abọ̀rìṣà ń rò ná. Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tẹ̀ síwájú pé: “Àwọn kan wà tí ń da wúrà jáde yàlàyàlà láti inú àpò, wọ́n sì fi ọ̀pá àfiwọn-nǹkan wọn fàdákà. Wọ́n háyà oníṣẹ́ irin, ó sì fi í ṣe ọlọ́run kan. Wọ́n ń wólẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n ń tẹrí ba.” (Aísáyà 46:6) Kò sí iyekíye tí àwọn abọ̀rìṣà ò lè ná láti fi ṣe ohun àkúnlẹ̀bọ wọn, àfi bíi pé òrìṣà olówó gọbọi ń gbani là ju òrìṣà igi lọ ni. Síbẹ̀, gbogbo akitiyan yòówù kí wọ́n ṣe, tàbí bó ti wù kí ohun tí wọ́n fi ṣe é wọ́nwó tó, òrìṣà aláìlẹ́mìí lòrìṣà aláìlẹ́mìí ń jẹ́, kò jù bẹ́ẹ̀ lọ.
10. Báwo ni wọ́n ṣe ṣàpèjúwe jíjẹ́ tí òrìṣà jẹ́ òtúbáńtẹ́?
10 Láti túbọ̀ fi ìwà òmùgọ̀ àwọn abọ̀rìṣà hàn, àsọtẹ́lẹ̀ yẹn tẹ̀ síwájú pé: “Wọ́n gbé e sí èjìká, wọ́n rù ú, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sí àyè rẹ̀ kí ó lè dúró bọrọgidi. Kò ṣísẹ̀ kúrò ní ibi tí ó dúró sí. Ẹnì kan tilẹ̀ ń ké jáde sí i, ṣùgbọ́n kò dáhùn; kò gbani là kúrò nínú wàhálà ẹni.” (Aísáyà 46:7) Ìfara-ẹni ṣe ẹlẹ́yà gidi mà ló jẹ́ o láti lọ máa ké pe ère tí kò lè gbọ́, tí kò sì lè gbé ohunkóhun ṣe! Onísáàmù ṣàpèjúwe àìwúlò àwọn ohun àkúnlẹ̀bọ bẹ́ẹ̀ dáadáa, ó ní: “Àwọn òrìṣà wọn jẹ́ fàdákà àti wúrà, iṣẹ́ ọwọ́ ará ayé. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ̀rọ̀; wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò lè ríran; wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ràn. Wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbóòórùn. Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lè fọwọ́ ba nǹkan. Wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò lè rìn; wọn kì í mú ìró kankan jáde láti ọ̀fun wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n yóò dà bí àwọn gan-an, gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.”—Sáàmù 115:4-8.
“Máyàle”
11. Kí ni yóò ran àwọn tí ọkàn wọn kò dúró sọ́nà kan lọ́wọ́ láti “máyàle”?
11 Bí Jèhófà ṣe fi bí òrìṣà bíbọ ṣe jẹ́ asán tó hàn tán, ó wá sọ ìdí tí àwọn èèyàn rẹ̀ fi ní láti sìn ín, ó ní: “Ẹ rántí èyí, kí ẹ lè máyàle. Ẹ fi í sínú ọkàn-àyà, ẹ̀yin olùrélànàkọjá. Ẹ rántí àwọn nǹkan àkọ́kọ́ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, pé èmi ni Olú Ọ̀run, kò sì sí Ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dà bí èmi.” (Aísáyà 46:8, 9) Kí àwọn tí ọkàn wọn kò dúró sọ́nà kan láàárín ìsìn tòótọ́ àti ìbọ̀rìṣà yáa tètè rántí ìtàn àtẹ̀yìnwá o. Kí wọ́n rántí àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe. Èyí yóò mú kí wọ́n máyàle láti ṣe ohun tó tọ́. Ìyẹn yóò sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti padà sínú ìjọsìn Jèhófà.
12, 13. Ìjàkadì wo ni àwọn Kristẹni kó wọ̀, báwo ni wọ́n sì ṣe lè ja àjàṣẹ́gun?
12 A ṣì nílò ìṣírí yìí lóde òní pẹ̀lú. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ní láti gbéjà ko àwọn ìdẹwò àti àìpé àwọn fúnra wọn, bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ṣe. (Róòmù 7:21-24) Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn àti ọ̀tá alágbára gidigidi kan tó jẹ́ ẹni àìrí tún jọ wà á kò nínú ìjà ogun tẹ̀mí. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwa ní gídígbò kan, kì í ṣe lòdì sí ẹ̀jẹ̀ àti ẹran ara, bí kò ṣe lòdì sí àwọn alákòóso, lòdì sí àwọn aláṣẹ, lòdì sí àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.”—Éfésù 6:12.
13 Kò sí ohun tí Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kò ní ṣe tán láti sáà lè yí àwọn Kristẹni tòótọ́ kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́. Tí àwọn Kristẹni yóò bá wá ja àjàṣẹ́gun, wọ́n ní láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jèhófà kí wọ́n sì máyàle. Lọ́nà wo? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ gbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìhámọ́ra ogun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọ̀, kí ẹ bàa lè dúró gbọn-in gbọn-in lòdì sí àwọn ètekéte Èṣù.” Jèhófà kò jẹ́ rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sójú ogun láìdira fún wọn dáadáa. Lára ohun tí wọ́n fi há mọ́ra nípa tẹ̀mí ni “apata ńlá ti ìgbàgbọ́, èyí tí [wọn] ó lè fi paná gbogbo ohun ọṣẹ́ oníná ti ẹni burúkú náà.” (Éfésù 6:11, 16) Pípa tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pa àwọn ìpèsè tẹ̀mí tí Jèhófà fún wọn tì ni wọ́n fi di olùrélànàkọjá. Ká ní wọ́n ṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe léraléra nítorí tiwọn ni, láé, wọn kì bá jẹ́ yíjú sí ìbọ̀rìṣà, ohun ìríra. Ǹjẹ́ ká fi tiwọn ṣàríkọ́gbọ́n o, ká sì pinnu láti má ṣe yà bàrá kúrò nínú ìjà tí a ń jà láti ṣe ohun tó tọ́.—1 Kọ́ríńtì 10:11.
14. Agbára wo ni Jèhófà tọ́ka sí pé òun ní, láti fi hàn pé òun nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́?
14 Jèhófà ni “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe; Ẹni tí ń wí pé, ‘Ìpinnu tèmi ni yóò dúró, gbogbo nǹkan tí mo bá sì ní inú dídùn sí ni èmi yóò ṣe.’” (Aísáyà 46:10) Òrìṣà wo ló lè ṣe bí Jèhófà ti ṣe yìí ná? Agbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ iwájú jẹ́ ẹ̀rí títayọ tó fi jíjẹ́ tí Ẹlẹ́dàá jẹ́ Ọlọ́run hàn. Ṣùgbọ́n o, ọ̀tọ̀ ni kéèyàn mọ ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, rírí i dájú pé ohun táa sọ tẹ́lẹ̀ ṣẹ gan-an ni kókó. Kíkéde tí Ọlọ́run sì wá kéde pé “ìpinnu tèmi ni yóò dúró” túbọ̀ ń fi hàn pé ète tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀ kò ní yẹ̀ láé. Níwọ̀n bí agbára Jèhófà kò ti lópin, kò sí ohunkóhun láyé àti lọ́run tó lè ṣèdíwọ́ fún un láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. (Dáníẹ́lì 4:35) Nípa bẹ́ẹ̀, kí ó dá wa lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ èyíkéyìí tí kò bá tíì ṣẹ yóò ṣẹ dandan bí àsìkò rẹ̀ bá ti tó lójú Ọlọ́run.—Aísáyà 55:11.
15. Àpẹẹrẹ pàtàkì nípa bí Jèhófà ṣe lágbára láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ iwájú wo ni a pe àfiyèsí wa sí?
15 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tí ó kàn yìí pe àfiyèsí wa sí àpẹẹrẹ pàtàkì kan nípa agbára tí Jèhófà ní láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú, kí ó sì mú kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, ó ní: “Ẹni tí ń pe ẹyẹ aṣọdẹ láti yíyọ oòrùn wá, tí ń pe ọkùnrin tí yóò mú ìpinnu mi ṣẹ ní kíkún láti ilẹ̀ jíjìnnà wá. Àní mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú. Mo ti gbé e kalẹ̀, èmi yóò ṣe é pẹ̀lú.” (Aísáyà 46:11) Bí Jèhófà Ọlọ́run ti jẹ́ “Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin,” yóò darí bí àwọn nǹkan yóò ṣe lọ láàárín àwọn ọmọ èèyàn láti lè mú kí ìpinnu rẹ̀ ṣẹ. Yóò pe Kírúsì “láti yíyọ oòrùn wá,” tàbí láti Páṣíà níhà ìlà oòrùn, níbi tí Pasagádáè, olú ìlú tí Kírúsì yàn láàyò yóò wà. Bí “ẹyẹ aṣọdẹ” ni Kírúsì yóò ṣe ṣọṣẹ́ ní ti pé lójijì ni yóò kàn yọ lu Bábílónì.
16. Báwo ni Jèhófà ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ tí òun sọ nípa Bábílónì yóò ṣẹ?
16 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ pé, “Mo ti sọ ọ́; èmi yóò mú un wá pẹ̀lú,” jẹ́ ẹ̀rí tó mú un dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ Rẹ̀ nípa Bábílónì yóò ṣẹ dandan ni. Èèyàn aláìpé ló máa ń fi ìwàǹwára ṣe àwọn ìlérí, àmọ́ ní ti Ẹlẹ́dàá, awímáyẹhùn lòun. Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run “tí kò lè purọ́,” kí ó dá wa lójú pé bó bá ti “gbé e kalẹ̀” dájúdájú “yóò ṣe é pẹ̀lú.”—Títù 1:2.
Àwọn Ọkàn-Àyà Tí Kò Nígbàgbọ́
17, 18. Ta ni a lè ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí àwọn tó “jẹ́ alágbára ní ọkàn-àyà” (a) láyé àtijọ́? (b) lóde òní?
17 Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà yíjú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ sí àwọn ará Bábílónì, ó ní: “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ alágbára ní ọkàn-àyà, ẹ̀yin tí ẹ jìnnà réré sí òdodo.” (Aísáyà 46:12) Gbólóhùn náà, “ẹ̀yin . . . alágbára ní ọkàn-àyà” ń ṣàpèjúwe àwọn tó ti ya olóríkunkun tí wọ́n sì ti fi hàn pé àwọn kanlẹ̀ lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run ni. Kò sí àní-àní pé àwọn ará Bábílónì jìnnà sí Ọlọ́run gan-an ni. Kíkórìíra tí wọ́n kórìíra Jèhófà àti àwọn èèyàn rẹ̀ ló mú kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, kí wọ́n sì kó àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ sígbèkùn.
18 Lóde òní, àwọn oníyèméjì àti aláìní ìgbàgbọ́ ń forí kunkun kọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí ìwàásù rẹ̀ ń lọ lọ́wọ́ níbi gbogbo téèyàn ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 24:14) Wọn kò fẹ́ gbà pé Jèhófà ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ. (Sáàmù 83:18; Ìṣípayá 4:11) Nígbà tí ọkàn-àyà wọn sì ti “jìnnà réré sí òdodo,” wọ́n lòdì sí ìfẹ́ Jèhófà, wọ́n sì ń takò ó. (2 Tímótì 3:1-5) Bí àwọn ará Bábílónì làwọn náà ṣe ń ṣe, etí dídi ni wọ́n kọ sí Jèhófà.
Ìgbàlà Ọlọ́run Kò Ní Pẹ́
19. Ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà ṣe ohun òdodo fún Ísírẹ́lì?
19 Ọ̀rọ̀ tó parí Aísáyà orí kẹrìndínláàádọ́ta tẹnu mọ́ àwọn apá kan lára ànímọ́ Jèhófà, ó ní: “Mo ti mú òdodo mi sún mọ́ tòsí. Kò jìnnà réré, ìgbàlà mi kì yóò sì pẹ́. Dájúdájú, èmi yóò pèsè ìgbàlà ní Síónì, èmi yóò fún Ísírẹ́lì ní ẹwà mi.” (Aísáyà 46:13) Òdodo ṣíṣe ni yóò mú kí Ọlọ́run dá Ísírẹ́lì nídè. Kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ̀ pẹ́ jù nígbèkùn. Àsìkò tó yẹ gẹ́lẹ́ ni ìgbàlà Síónì yóò dé, “kì yóò sì pẹ́.” Ísírẹ́lì yóò di ohun àfiṣèranwò lójú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká, lẹ́yìn ìdáǹdè wọn kúrò nígbèkùn. Ẹ̀rí nípa bí Jèhófà ṣe lágbára láti gbani là ni ìdáǹdè orílẹ̀-èdè rẹ̀ yóò jẹ́. Àṣírí jíjẹ́ tí Bélì àti Nébò, àwọn òrìṣà Bábílónì, jẹ́ aláìwúlò yóò wá tú fún gbogbo èèyàn láti rí, àìlègbé ohunkóhun ṣe wọn yóò sì hàn kedere.—1 Àwọn Ọba 18:39, 40.
20. Báwo ló ṣe lè dá àwọn Kristẹni lójú pé ‘ìgbàlà Jèhófà kì yóò pẹ́’?
20 Lọ́dún 1919, Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò nígbèkùn tẹ̀mí. Kò jẹ́ kí ó pẹ́. Ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn àti àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́, nígbà tí Bábílónì fi ṣubú sí Kírúsì lọ́wọ́, máa ń fún wa níṣìírí lóde òní. Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò mú ètò àwọn nǹkan búburú yìí wá sópin, títí kan ẹ̀sìn èké rẹ̀. (Ìṣípayá 19:1, 2, 17-21) Àmọ́ bí àwọn Kristẹni kan bá wá ń fojú tènìyàn wò ó, wọ́n lè máa rò ó pé ìgbàlà àwọn ti ń pẹ́ o. Ṣùgbọ́n ní ti gidi, òdodo ṣíṣe ló mú kí Jèhófà máa fi sùúrù dúró de ìgbà tí àkókò rẹ̀ bá tó láti mú ìlérí yẹn ṣẹ. Ó ṣe tán, “[Jèhófà] kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Nítorí náà, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé, ‘ìgbàlà kì yóò pẹ́’ gẹ́lẹ́ bí kò ṣe pẹ́ nígbà ti Ísírẹ́lì ayé àtijọ́. Àní bí ọjọ́ ìgbàlà ṣe ń sún mọ́lé ni Jèhófà tún ń fi tìfẹ́tìfẹ́ pe ìpè báyìí pé: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí. Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:6, 7.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 94]
Àwọn òrìṣà Bábílónì kò dáàbò bò ó lọ́wọ́ ìparun
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 98]
Àwọn Kristẹni tòní gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà òde òní
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 101]
Máyàle láti ṣe ohun tó tọ́