Gbádùn Àwọn Àǹfààni̇́ Ẹ̀kọ́ Àtọ̀runwá
“Èmi, Jehofa, ni Ọlọrun rẹ, Ẹni náà tí ń kọ́ ọ láti ṣe ara rẹ ní àǹfààní.”—ISAIAH 48:17, NW.
1. Báwo ni nǹkan yóò ti rí fún wa bí a bá fi ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò nínú ìgbésí-ayé wa?
JEHOFA ỌLỌRUN ni ó mọ ohun tí ó dára jùlọ. Kò sí ẹni kankan tí ó tayọ rẹ̀ nínú èrò, ọ̀rọ̀, tàbí ìṣe. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa, ó mọ àwọn àìní wa ó sì ń pèsè wọn lọ́pọ̀ yanturu. Dájúdájú ó mọ̀ bí òun ṣe lè fún wa ní ìtọ́ni. Bí a bá sì fi ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò, àwa yóò ṣe araawa ní àǹfààní a óò sì gbádùn ayọ̀ tòótọ́.
2, 3. (a) Báwo ní àwọn ènìyàn Ọlọrun ìgbàanì ìbá ti ṣe araawọn ní àǹfààní kání wọ́n ti ṣègbọràn sí àwọn òfin-àṣẹ rẹ̀ ni? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá fi ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò nínú ìgbésí-ayé wa lónìí?
2 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣípayá ìfẹ́-ọkàn onítara tí Ọlọrun ní, pé kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ yẹra fún àjálù-ibi kí wọ́n sì gbádùn ìgbésí-ayé nípa ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin àti ìlànà rẹ̀. Bí àwọn ènìyàn Jehofa ní ìgbàanì ba ti fetísílẹ̀ sí i ni, wọn ìbá ti gbádùn àwọn ìbùkún dídọ́ṣọ̀, nítorí ó ti sọ fún wọn pé: “Èmi, Jehofa, ni Ọlọrun rẹ, Ẹni náà tí ń kọ́ ọ láti ṣe araarẹ ní àǹfààní, Ẹni náà tí ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹlẹ̀ lójú ọ̀nà náà nínú èyí tí ìwọ níláti rìn. Óò kìkì bí ìwọ yóò bá fiyèsílẹ̀ sí àwọn òfin-àṣẹ mi níti gidi! Nígbà náà ni àlàáfíà rẹ yóò dàbí ti odò gan-an, àti òdodo rẹ bí ìgbì òkun.”—Isaiah 48:17, 18, NW.
3 Àwọn ènìyàn Ọlọrun ní ìgbàanì ìbá ti ṣe araawọn ní àǹfààní kání wọ́n ti fetísílẹ̀ sí àwọn òfin-àṣẹ àti ìtọ́ni rẹ̀ ni. Dípò jíjìyà àjálù-ibi lọ́wọ́ àwọn ará Babiloni, wọn ìbá ti gbádùn àlàáfíà àti aásìkí bíi ti odò kan tí ó kún, tí ó jìn, tí ọ̀dá kìí dá. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn iṣẹ́ òdodo wọn kìbá tí lóǹkà bíi ti ìgbì òkun. Lọ́nà kan-náà, bí a bá fi àwọn ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò nínú ìgbésí-ayé wa, àwa lè gbádùn ọ̀pọ̀ àwọn àǹfààní rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára ìwọ̀nyí?
Ó Ń Yí Ìgbésí-Ayé Padà
4. Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe ń nípalórí ìgbésí-ayé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn?
4 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ti ń ṣàǹfààní fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn nípa yíyí ìgbésí-ayé wọn padà sí rere. Àwọn wọnnì tí wọ́n fi ìtọ́ni Jehofa sílò pa “àwọn iṣẹ́ ti ara,” bí ìwà-àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò, gbọ́nmisi-omi-òto, àti owú tì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi àwọn èso ẹ̀mí ti ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́, ìwàtútù, àti ìkóra-ẹni-níjàánu hàn. (Galatia 5:19-23) Wọ́n tún kọbiara sí ìmọ̀ràn Efesu 4:17-24 (NW), níbi tí Paulu ti rọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ láti máṣe rìn bí àwọn orílẹ̀-èdè ti ń rìn, nínú àìlérè èrò-inú wọn àti nínú òkùnkùn èrò-orí, tí a ti sọ di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọrun. Bí a kò ti darí wọn nípasẹ̀ ọkàn-àyà tí kò mòye, àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan tí wọ́n fìwà jọ Kristi ‘bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀-ìwà tí ó bá ipa-ọ̀nà ìwà wọn àtijọ́ ṣedéédéé sílẹ̀ a sì sọ wọ́n di titun nínú ipá tí ń mú èrò-inú wọn ṣiṣẹ́.’ Wọ́n ‘gbé àkópọ̀-ìwà titun tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-inú Ọlọrun nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin wọ̀.’
5. Báwo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ṣe nípalórí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn ń gbà rìn?
5 Àǹfààní dídára kan ti fífi ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò ni pé ó ń fihàn wá bí a ṣe lè bá Ọlọrun rìn. Bí a bá bá Jehofa rìn, gẹ́gẹ́ bí Noa ti ṣe, àwa ń tẹ̀lé ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé tí Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa lànà rẹ̀ sílẹ̀. (Genesisi 6:9; Isaiah 30:20, 21) Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè “ń rìn nínú àìlérè èrò-inú wọn,” gẹ́gẹ́ bí aposteli Paulu ti wí. Ẹ sì wo bí àwọn kan nínú àwọn ìkọ̀wé èrò-inú wọnnì ti lè jẹ́ aláìlérè tó! Ní ṣíṣàkíyèsí ìkọ̀wé àwọn mìíràn lára ògiri kan ní Pompeii, olùṣàkíyèsí kan fi ọwọ́ araarẹ̀ kọ̀wé pé: “Ìyanu ni ó jẹ́, óò ògiri, pé síbẹ̀ ìwọ kò tíì wó lulẹ̀ lábẹ́ ẹrù àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí ó pọ̀ tó báyìí.” Ṣùgbọ́n kò sí ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kankan nínú “ẹ̀kọ́ Jehofa” àti nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba tí ó mú kí ó ṣeéṣe. (Iṣe 13:12) Nípasẹ̀ iṣẹ́ yẹn, àwọn ènìyàn olùfẹ́ òtítọ́ ni a ti ràn lọ́wọ́ láti hùwà lọ́nà tí ó lọ́gbọ́n-nínú. A ń kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè dẹ́kun rírìn nínú ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, nínú àìmọ̀kan nípa àwọn ète Ọlọrun. Wọ́n kò sí nínú òkùnkùn mọ́ níti èrò-orí, bẹ́ẹ̀ sì ni ọkàn-àyà tí kò mòye tí ń wá àwọn góńgó tí kò lérè kò sún wọn ṣiṣẹ́ mọ́.
6. Ipò-ìbátan wo ni ó wà láàárín ìgbọ́ràn wa sí ẹ̀kọ́ Jehofa àti ayọ̀ wa?
6 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tún ń ṣàǹfààní fún wa níti pé ó sọ wá di ojúlùmọ̀ pẹ̀lú Jehofa àti àwọn ìbálò rẹ̀. Irúfẹ́ ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ń fà wá súnmọ́ Ọlọrun pẹ́kípẹ́kí síi, ó ń mú ìfẹ́ wa fún un pọ̀ síi, ó sì ń mú ìfẹ́-ọkàn wa láti ṣègbọràn sí i ga síi. 1 Johannu 5:3 sọ pé: “Èyí ni ìfẹ́ Ọlọrun, pé kí àwa kí ó pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira.” A tún ń ṣègbọràn sí àwọn òfinàṣẹ Jesu nítorí a mọ̀ pé ẹ̀kọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. (Johannu 7:16-18) Irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ ń pa wá mọ́ kúrò lọ́wọ́ ìpalára tẹ̀mí ó sì ń mú ayọ̀ wa ga síi.
Ète Tòótọ́ Nínú Ìgbésí-Ayé
7, 8. (a) Báwo ni ó ṣe yẹ kí a lóye Orin Dafidi 90:12? (b) Báwo ni a ṣe lè fi ọkàn-àyà wa sí ipa ọgbọ́n?
7 Ẹ̀kọ́ Jehofa ń ṣe wa láǹfààní nípa fífihàn wá bí a ṣe lè lo ìgbésí-ayé wa ní ọ̀nà tí ó ní ète nínú. Níti tòótọ́, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń fihàn wá bí a ṣe lè ka ọjọ́ wa ní ọ̀nà àkànṣe. Gígùn ìwàláàyè ti 70 ọdún fún wa ní ìrètí nǹkan bíi 25,550 ọjọ́. Ẹnìkan tí ó jẹ́ ẹni 50 ọdún ti lo 18,250 nínú wọn ní báyìí ná, tí 7,300 àwọn ọjọ́ tí ó ṣẹ́kù tí òun ń retí sì dàbí èyí tí ó kéré jọjọ. Ní pàtàkì nígbà náà ni òun lè mọrírì ní kíkún síi ìdí tí wòlíì Mose fi gbàdúrà sí Ọlọrun nínú Orín Dafidi 90:12 pé: “Kí ìwọ kí ó kọ́ wa láti máa ka iye ọjọ́ wa, kí àwa kí ó lè fí ọkàn wa sípa ọgbọ́n.” Ṣùgbọ́n kí ni ohun tí Mose ní lọ́kàn nípa ìyẹn?
8 Mose kò ní in lọ́kàn pé Ọlọrun yóò ṣí iye ọjọ́ pàtó tí yóò wà nínú àkókò ìgbésíayé ọmọ Israeli kọ̀ọ̀kan payá. Gẹ́gẹ́ bí Orin Dafidi 90, ẹsẹ 9 àti 10 ti sọ, wòlíì Heberu yẹn mọ̀ pé gígùn ìwàláàyè lè jẹ́ nǹkan bíi 70 tàbí 80 ọdún—ó kúrú nítòótọ́. Nítorí náà ó ṣe kedere pé àwọn ọ̀rọ̀ inú Orin Dafidi 90:12 ṣe àfihàn ìfẹ́-ọkàn tí Mose fi àdúrà sọ pé kí Jehofa fihan òun àti àwọn ènìyàn Rẹ̀, tàbí kí ó kọ́ wọn láti lo ọgbọ́n nínú ìṣèdíyelé ‘iye ọjọ́ àwọn ọdún wọn’ kí wọ́n sì lò wọ́n lọ́nà tí Ọlọrun fọwọ́sí. Ó dára, nígbà náà, àwa ń kọ́? Àwa ha mọrírì ọjọ́ oníyebíye kọ̀ọ̀kan bí? Àwa ha ń fi ọkàn-àyà wa sí ipa ọgbọ́n nípa wíwá ọ̀nà láti lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lọ́nà tí ó ṣàǹfààní sí ògo Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa, Jehofa Ọlọrun bí? Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.
9. Kí ni a lè retí bí a bá kọ́ láti ka àwọn ọjọ́ wa sí ògo ti Jehofa?
9 Bí a bá kọ́ láti ka iye ọjọ́ wa sí ògo Jehofa, ó lè ṣeéṣe fún wa láti máa ka iye ọjọ́ wa nìṣó, nítorí pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń fúnni ní ìmọ̀ fún ìyè ayérayé. Jesu wí pé: “Ìyè ànìnípẹ̀kun náà sì ni èyí, kí wọn kí ó lè mọ̀ ọ́, ìwọ nìkan Ọlọrun òtítọ́, àti Jesu Kristi, ẹni tí ìwọ rán.” (Johannu 17:3) Àmọ́ ṣáá o, bí a bá jèrè gbogbo ìmọ̀ ayé tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kì yóò fún wa ní ìyè ayérayé. Ṣùgbọ́n ìyè àìnípẹ̀kun lè jẹ́ tiwa bí a bá jèrè ìmọ̀ pípéye nípa àwọn ẹni méjì pàtàkì julọ lágbàáyé tí a sì fi í sílò tí a sì tún lo ìgbàgbọ́ níti gidi.
10. Kí ni ìwé agbédègbéyọ̀ kan sọ nípa ẹ̀kọ́-ìwé, báwo sì ni èyí ṣe yàtọ̀ sí àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá?
10 Láìka bí ó ti pẹ́ tó tí a ti wàláàyè sí, ẹ jẹ́ kí a rántí àǹfààní pàtàkì ti ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí: Ó ń fún àwọn wọnnì tí ń fi í sílò ni ète gidi kan nínú ìgbésí-ayé. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà The World Book Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Ẹ̀kọ́-ìwé gbọ́dọ̀ ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ láti di mẹ́ḿbà wíwúlò láwùjọ. Ó gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹ̀lú láti mú ìmọrírì dàgbà fún àṣà-ìṣẹ̀dálẹ̀ àjogúnbá wọn kí wọ́n sì gbé ìgbésí-ayé tí ń tẹ́nilọ́rùn lọ́nà púpọ̀ síi.” Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ṣàǹfààní ní ríràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbésí-ayé tí ń mú ìtẹ́lọ́rùn wá. Ó ń mú ìmọrírì mímúhánhán dàgbà nínú wa fún àjogúnbá tẹ̀mí wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn Ọlọrun. Dájúdájú ó sì mú kí a jẹ́ mẹ́ḿbà wíwúlò láwùjọ, nítorí ó mú kí ó ṣeéṣe fún wa láti kó ipa ṣíṣe kókó nínú kíkúnjú àìní àwọn ènìyàn kárí-ayé. Èéṣe tí a fi lè sọ bẹ́ẹ̀?
Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ẹ̀kọ́ Kárí-Ayé
11. Báwo ní Thomas Jefferson ṣe tẹnumọ́ àìní náà fún ẹ̀kọ́-ìwé tí ó tọ̀nà?
11 Láìdàbí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtọ́ni èyíkéyìí, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá kúnjú àìní àwọn ènìyàn fún ìmọ̀-ẹ̀kọ́. Àìní náà láti kọ́ àwọn ènìyàn ni Thomas Jefferson, tí ó di ààrẹ kẹta ní United States ṣàkíyèsí. Nínú lẹ́tà kan tí ó kọ sí George Wythe, ọ̀rẹ́ kan àti alájùmọ̀ fọwọ́sí Ìpolongo Òmìnira ní August 13, 1786, Jefferson kọ̀wé pé: “Mo ronú pé òfin pàtàkì jùlọ nínú odidi àkójọ òfin wa ni òfin fún ìpínkiri ìmọ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Kò sí ìpilẹ̀ dídájú mìíràn tí a lè fi lélẹ̀, fún ìtọ́jú òmìnira àti ayọ̀. . . . Ọ̀gbẹ́ni mi ọ̀wọ́n, wàásù ogun lòdìsí àìmọ̀kan; ṣe àgbékalẹ̀ kí o sì mú òfin fún dídá àwọn ènìyàn gbáàtúù lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n síi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn ìlú wa mọ̀ . . . pé owó-orí náà tí a ó san fún ète [ìmọ̀-ẹ̀kọ́] kò ju ìdá kan nínú ẹgbẹ̀rún ohun tí a ó san fún àwọn ọba, àlùfáà, àti àwọn ọ̀tọ̀kùlú tí yóò dìde láàárín wa bí a bá fi àwọn ènìyàn sílẹ̀ nínú àìmọ̀kan.”
12. Èéṣe tí a fi lè sọ pé ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ yíyọrísírere jùlọ tí ó sì ṣàǹfààní fún ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kárí ayé?
12 Dípò fífi àwọn ènìyàn tí ọkàn wọn tẹ̀ sí òdodo sílẹ̀ nínú àìmọ̀kan, ẹ̀kọ́ Jehofa ń pèsè ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan tí ó dára jùlọ fún ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kárí ayé fún àǹfààní wọn. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń jà ní 50 ọdún sẹ́yìn, Ìgbìmọ̀ Olùṣàtúnṣe Ẹ̀kọ́-Ìwé ti United States rí àìní kánjúkánjú náà fún “ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kárí ayé.” Àìní yẹn ṣì wà, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ yíyọrísírere kanṣoṣo tí ó wà fún ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kárí ayé. Òun ni ó tún ṣàǹfààní jùlọ nítorí pé ó ń gbé àwọn ènìyàn dìde kúrò nínú àìnírètí, ó ń gbé wọn ga níti ìwàrere àti tẹ̀mí, ó ń gbà wọ́n là kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ẹ̀tanú ayé, ó sì ń fún wọn ní ìmọ̀ fún ìyè ayérayé. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí ń ṣàǹfààní fún àwọn ènìyàn níbi gbogbo nípa kíkọ́ wọn láti ṣiṣẹ́sin Jehofa Ọlọrun.
13. Báwo ni a ṣe ń mú Isaiah 2:2-4 ṣẹ lónìí?
13 Àwọn ògìdìgbó tí wọ́n ń di ìránṣẹ́ Ọlọrun nísinsìnyí ti ń gbádùn àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Àìní wọn nípa tẹ̀mí ń jẹ wọ́n lọ́kàn wọ́n sì mọ̀ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pé ọjọ́ Jehofa ti súnmọ́lé. (Matteu 5:3; 1 Tessalonika 5:1-6) Nísinsìnyí gan-an, “ní ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn ènìyàn wọ̀nyí láti gbogbo orílẹ̀-èdè ń rọ́ lọ sórí òkè-ńlá Jehofa, ìjọsìn mímọ́gaara rẹ̀. A ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọnyingbọnyin a sì gbé e ga ju gbogbo ìjọsìn tí ó lòdìsí ìfẹ́-inú Ọlọrun. (Isaiah 2:2-4) Bí ìwọ bá jẹ́ Ẹlẹ́rìí tí ó ti ya araarẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa, inú rẹ kò ha dùn láti wà lára ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń pọ̀ síi ṣáá tí wọ́n ń sìn ín tí wọ́n sì ń jàǹfààní láti inú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá bí? Ẹ wo bí ó ti jẹ́ àgbàyanu tó láti wà lára àwọn wọnnì tí ń polongo pé: “Ẹ yin Jah, ẹ̀yin ènìyàn!”—Orin Dafidi 150:6, NW.
Ipa Ṣíṣàǹfààní Tí Ó Ní Lórí Ẹ̀mí Wa
14. Àǹfààní wo ni ó jẹ́ láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn Paulu ní 1 Korinti 14:20?
14 Lára ọ̀pọ̀ àwọn ìbùkún ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ni ipa rere tí ó lè ní lórí ìrònú àti ẹ̀mí wa. Ó ń ta wá jí láti ronú lórí àwọn ohun tí ó jẹ́ òdodo, mímọ́, fífẹ́, àti èyí tí ó ní ìròyìn rere. (Filippi 4:8) Ẹ̀kọ́ Jehofa ń ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀lé ìmọ̀ràn Paulu pé: “Ẹ jẹ́ ọmọdé ní àránkàn, ṣùgbọ́n ní òye kí ẹ jẹ́ àgbà.” (1 Korinti 14:20) Bí a bá fi ìṣílétí yìí sílò, àwa kì yóò fẹ́ láti wá ìmọ̀ nípa ìwà burúkú. Paulu tún kọ̀wé pé: “Gbogbo ìwà kíkorò, àti ìbínú àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí á mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àránkàn.” (Efesu 4:31) Kíkọbiara sí irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ìwàpálapàla àti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ búburú mìíràn. Nígbà tí èyí lè ṣàǹfààní nípa ti ara àti nípa ti èrò-orí, ní pàtàkì ni yóò mú ayọ̀ ti mímọ̀ pé a ń mú inú Ọlọrun dùn wá fún wa.
15. Kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa báa nìṣó láti ní ohun tí ó yẹ ní fífẹ́ nínú èrò-inú?
15 Bí a bá ń fẹ́ láti máa ní ohun tí ó yẹ ní fífẹ́ nìṣó nínú èrò-inú wa, ìrànlọ́wọ́ kan ni láti yẹra fún ‘ẹgbẹ́ búburú tí ń ba ìwàrere jẹ́.’ (1 Korinti 15:33) Gẹ́gẹ́ bíi Kristian, àwa kò ní máa kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn àgbèrè, panṣágà, àti àwọn oníwà-àìtọ́ mìíràn. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́nmu pé à kò gbọ́dọ̀ kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú irú àwọn ẹnìkọ̀ọ̀kan bẹ́ẹ̀ nípa kíkà nípa wọn fún adùn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara tàbí nípa wíwò wọ́n lórí tẹlifíṣọ̀n tàbí nínú àwòrán sinimá. Ọkàn-àyà kún fún àdàkàdekè, ó rọrùn fún un láti mú ìfẹ́-ọkàn dàgbà fún àwọn nǹkan búburú, a sì lè dẹ ẹ́ wò láti ṣe wọn. (Jeremiah 17:9) Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a yẹra fún irú àwọn ìdẹwò bẹ́ẹ̀ nípa títòròpinpin mọ́ ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá. Ó lè nípalórí ìrònú àwọn “tí ó fẹ́ Oluwa” dé ìwọ̀n àyè ṣíṣàǹfààní tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóò fi “kórìíra ibi.”—Orin Dafidi 97:10.
16. Báwo ni ẹ̀kọ́ Ọlọrun ṣe lè nípalórí ẹ̀mí tí a fihàn?
16 Paulu sọ fún Timoteu alábàáṣiṣẹ́pọ̀ rẹ̀ pé: “Kí Oluwa kí ó wà pẹ̀lú ẹ̀mí rẹ. Kí oore-ọ̀fẹ́ kí ó wà pẹ̀lú yín.” (2 Timoteu 4:22) Aposteli náà nífẹ̀ẹ́-ọkàn pé kí Ọlọrun fọwọ́sí ipá tí ń sún Timoteu àti àwọn Kristian mìíràn ṣiṣẹ́, nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa. Ẹ̀kọ́ Ọlọrun ń ràn wá lọ́wọ́ láti fi ẹ̀mí ìfẹ́, onínúure, àti ti ìwàtútù hàn. (Kolosse 3:9-14) Ẹ sì wo bí ó ti yàtọ̀ sí ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí! Wọ́n jẹ́ onírera, aláìlọ́pẹ́, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeébáṣàdéhùn èyíkéyìí, olùwarùnkì, olùfẹ́ adùn, àti aláìní ìfọkànsìn oníwà-bí-Ọlọrun tòótọ́. (2 Timoteu 3:1-5, NW) Bí ó ti wù kí ó rí, bí a ti ń báa lọ láti máa fi àwọn àǹfààní ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò nínú ìgbésí-ayé wa, a ń fi ẹ̀mí kan tí ó túbọ̀ ń mú wa jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún Ọlọrun àti àwọn ènìyàn ẹlẹgbẹ́ wa hàn.
Ó Ṣàǹfààní Nínú Àjọṣepọ̀ Ènìyàn
17. Èéṣe tí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn fi ṣe pàtàkì tóbẹ́ẹ̀?
17 Ẹ̀kọ́ Jehofa ń ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn àǹfààní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn ẹlẹgbẹ́ wa. (Orin Dafidi 138:6) Láìdàbí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lónìí, a kìí ṣẹ̀ sí àwọn ìlànà títọ́ ṣùgbọ́n a ṣeé bá ṣàdéhùn. Fún àpẹẹrẹ, rere púpọ̀ ń jẹyọ nítorí pé àwọn alábòójútó tí a yànsípò ṣeé bá ṣàdéhùn nígbà ìpàdé àwọn alàgbà. Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lè fi pẹ̀lẹ́tù sọ̀rọ̀ fún ire òtítọ́, nígbà tí wọn kì yóò yọ̀ǹda fún èrò-ìmọ̀lára láti ṣíji bo ọgbọ́n-ìrònú tàbí ṣokùnfà àìsí ìṣọ̀kan. Gbogbo mẹ́ḿbà nínú ìjọ yóò jàǹfààní láti inú ẹ̀mí ìṣọ̀kan tí a ń gbádùn bí gbogbo wa bá ń báa lọ láti máa fi ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá sílò.—Orin Dafidi 133:1-3.
18. Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye wo nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa?
18 Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tún ṣàǹfààní nínú ríràn wá lọ́wọ́ láti ní ojú-ìwòye tí ó tọ́ nípa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa. Jesu wí pé: “Kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, bíkòṣepé Baba tí ó rán mi fà á.” (Johannu 6:44) Láti 1919 ní pàtàkì, Jehofa ti mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ polongo àwọn ìdájọ́ rẹ̀, ètò-ìgbékalẹ̀ ayé Satani sì ni ìkìlọ̀ káàkiri ayé yìí ti mì tí ó sì ti gbọ̀n jìgìjìgì. Ní àkókò kan-náà, àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun—“àwọn ohun fífanilọ́kànmọ́ra”—ni Ọlọrun ti fà láti ya araawọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn orílẹ̀-èdè kí wọ́n sì ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró ní fífi ògo kún ilé ìjọsìn Jehofa. (Haggai 2:7, NW) Dájúdájú, a níláti fojú wo irú àwọn ẹni fífanilọ́kànmọ́ra tí Ọlọrun fà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùbákẹ́gbẹ́ ọ̀wọ́n.
19. Kí ni ẹ̀kọ́ Ọlọrun ṣípayá nípa yíyanjú àwọn aáwọ̀ ara-ẹni pẹ̀lú àwọn Kristian ẹlẹgbẹ́ wa?
19 Àmọ́ ṣáá o, nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, àwọn nǹkan kò ní máa lọ geere nígbà gbogbo. Nígbà tí ó kù díẹ̀ kí Paulu gbéra lọ fún ìrìn-àjò ìjíhìn-iṣẹ́-Ọlọ́run rẹ̀ kejì, Barnaba pinnu láti mú Marku lọ́wọ́ lọ. Paulu kọ̀ nítorí pé Marku “fi wọ́n sílẹ̀ ní Pamfilia, tí kò sì bá wọn lọ sí iṣẹ́ náà.” Nítorí ìyẹn, “ìbújáde ìbínú” (NW) ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà. Barnaba mú Marku dání lọ sí Kipru, nígbà tí Paulu yàn kí Sila bá òun rékọjá lọ sí Siria àti Kilikia. (Iṣe 15:36-41) Lẹ́yìn náà, ẹ̀rí fihàn pé àlàfo àjọṣepọ̀ yìí ni a dí, nítorí pé Marku wà pẹ̀lú Paulu ní Romu, aposteli náà sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere. (Kolosse 4:10) Àǹfààní kan tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ní ni pé ó ń fihàn wá bí a ṣe lè yanjú àwọn aáwọ̀ ara-ẹni láàárín àwọn Kristian nípa títẹ̀lé irú ìmọ̀ràn tí Jesu sọ ní Matteu 5:23, 24 àti Matteu 18:15-17.
Ó Ń Ṣàǹfààní Ó Sì Ń Ṣẹ́gun Nígbà Gbogbo
20, 21. Ìgbéyẹ̀wò tí a ti ṣe nípa ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yẹ kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe kí ni?
20 Kódà láti inú ìgbéyẹ̀wò ṣókí tí a ti ṣe nípa àwọn àǹfààní àti ìṣẹ́gun ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá, kò sí iyèméjì pé gbogbo wa lè rí àìní náà láti dúró gangan nínú fífi í sílò nínú ìgbésí-ayé wa. Nígbà náà, pẹ̀lú ẹ̀mí tí ó kún fún àdúrà, ẹ jẹ́ kí a máa báa lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ láti ọ̀dọ̀ Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa. Láìpẹ́, ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yóò ṣẹ́gun ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Yóò ṣẹ́gun nígbà tí àwọn ọlọ́gbọ́nlóye ayé yìí bá ti gbẹ́mìímì. (Fiwé 1 Korinti 1:19.) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, bí ọ̀pọ̀ million síi ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ìfẹ́-inú Ọlọrun tí wọ́n sì ń ṣe é, ìmọ̀ Jehofa yóò kún ilẹ̀-ayé bí omi tí ń bo òkun. (Isaiah 11:9) Ẹ wo bí èyí yóò ti ṣàǹfààní fún aráyé onígbọràn tí yóò sì dá Jehofa láre gẹ́gẹ́ bí Ọba-Aláṣẹ Àgbáyé lọ́nà títóbilọ́lá tó!
21 Ẹ̀kọ́ Jehofa yóò máa fìgbà gbogbo ṣàǹfààní yóò sì máa ṣẹ́gun. Ìwọ yóò ha máa jàǹfààní nìṣó láti inú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ tí ó ní ìtara-ọkàn fún Ìwé-Ẹ̀kọ́ ńlá Ọlọrun bí? Ìwọ ha ń gbé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Bibeli tí o sì ń ṣàjọpín àwọn òtítọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ lè máa wọ̀nà láti rí ìṣẹ́gun pátápátá tí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yóò ní, sí ògo Atóbilọ́lá Olùkọ́ni wa, Jehofa Oluwa Ọba-Aláṣẹ.
Kí Ni O Ti Rí Kọ́?
◻ Ipa wo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lè ní lórí ìgbésí-ayé wa?
◻ Báwo ni ẹ̀kọ́ Jehofa ṣe ń kúnjú àwọn àìní nípa ti ìmọ̀-ẹ̀kọ́?
◻ Ipa tí ó ṣàǹfààní wo ni ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá lè ní lórí ìrònú àti ìṣarasíhùwà wa?
◻ Báwo ni ẹ̀kọ́ Ọlọrun ṣe jásí èyí tí ó ṣàǹfààní níti àjọṣepọ̀ ènìyàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá ń fi hàn wá bí a ṣe lè bá Ọlọrun rìn, gẹ́gẹ́ bí Noa ti ṣe
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Àwọn ènìyàn láti gbogbo orílẹ̀-èdè ń rọ́ lọ sórí òkè-ńlá Jehofa