Orí Kẹjọ
Jèhófà Ọlọ́run Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Mímọ́ Rẹ̀
1, 2. (a) Ìgbà wo ni wòlíì Aísáyà rí ìran tó rí nípa tẹ́ńpìlì? (b) Kí ni kò jẹ́ kí Ùsáyà Ọba rí ojú rere Jèhófà mọ́?
“BÍ Ó ti wù kí ó rí, ní ọdún tí Ùsáyà Ọba kú, mo wá rí Jèhófà, tí ó jókòó lórí ìtẹ́ tí ó ga fíofío, tí a sì gbé sókè, ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ sì kún inú tẹ́ńpìlì.” (Aísáyà 6:1) Ọ̀rọ̀ wòlíì yìí ló bẹ̀rẹ̀ orí kẹfà ìwé Aísáyà. Ìyẹn jẹ́ lọ́dún 778 ṣááju Sànmánì Tiwa.
2 Geerege làwọn nǹkan ń lọ ní èyí tó pọ̀ jù nínú ọdún méjìléláàádọ́ta tí Ùsáyà fi jọba Júdà. Nítorí pé “ó ń bá a nìṣó ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà,” ṣe ni Ọlọ́run ń tì í lẹ́yìn lẹ́nu ogun jíjà, ilé kíkọ́, àti iṣẹ́ ọ̀gbìn tó dáwọ́ lé. Àmọ́, gàlègàlè tó ń ṣe nítorí àṣeyọrí wọ̀nyẹn náà ló fi tẹ́. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọkàn-àyà rẹ̀ di onírera “tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi ṣe àìṣòótọ́ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, tí ó sì wá sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà láti sun tùràrí lórí pẹpẹ tùràrí.” Nítorí ìwà ọ̀yájú yìí àti bíbínú tó bínú sí àwọn àlùfáà tó bá a wí, Ùsáyà ya adẹ́tẹ̀ títí dọjọ́ ikú rẹ̀. (2 Kíróníkà 26:3-22) Àsìkò ìgbà yẹn ni Aísáyà bẹ̀rẹ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ.
3. (a) Ṣé Aísáyà fojú rí Jèhófà ní ti gidi? Ṣàlàyé. (b) Ìran wo ni Aísáyà rí, kí sì ni ìdí tó fi rí i?
3 Wọn kò sọ ibi tí Aísáyà wà tó fi rí ìran yìí fún wa. Àmọ́, ó dájú pé ìran ni ohun tó fojú rí yìí jẹ́, kì í ṣe pé ó fojú gán-án-ní Olódùmarè, nítorí “kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18; Ẹ́kísódù 33:20) Síbẹ̀síbẹ̀, pé èèyàn tiẹ̀ rí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá, lójú ìran, àwòyanu gbáà ni. Alákòóso Àgbáyé, Ẹni tí gbogbo ìjọba títọ́ ń bẹ níkàáwọ́ rẹ̀, mà ló gúnwà sórí ìtẹ́ rẹ̀ gíga fíofío yẹn o, ìtẹ́ tó dúró fún ipa tó ń kó gẹ́gẹ́ bí Ọba àti Onídàájọ́ ayérayé! Ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ rẹ̀ gígùn, kún inú tẹ́ńpìlì. Ńṣe ni Aísáyà ń gba ìpè láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, èyí tí yóò gbé agbára àti ìdájọ́ òdodo gíga jù lọ ti Jèhófà lékè. Láti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún iṣẹ́ yìí, wọ́n fẹ́ fi ìran nípa jíjẹ́ tí Ọlọ́run jẹ́ mímọ́ hàn án.
4. (a) Èé ṣe tó fi ní láti jẹ́ pé àpẹẹrẹ lásán ni àwọn àpèjúwe ìrísí Jèhófà tí wọ́n máa ń rí lójú ìran, tí wọ́n sì kọ sínú Bíbélì? (b) Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ nípa Jèhófà látinú ìran Aísáyà?
4 Aísáyà kò ṣàlàyé kankan nípa ìrísí Jèhófà nínú ìran rẹ̀—kò dà bí ìran tí Ìsíkíẹ́lì, Dáníẹ́lì, àti Jòhánù rí. Gbogbo àkọsílẹ̀ wọ̀nyẹn ló sì yàtọ̀ síra ní ti ohun tí wọ́n rí ní ọ̀run. (Ìsíkíẹ́lì 1:26-28; Dáníẹ́lì 7:9, 10; Ìṣípayá 4:2, 3) Àmọ́ o, ẹ jẹ́ ká fi bí ìran wọ̀nyí ṣe jẹ́ àti ète tí wọ́n wà fún sọ́kàn. Wọn kì í ṣe àlàyé nípa bí àyíká Jèhófà ṣe rí ní ti gidi. Ojúyòójú kò lè rí ohun tó jẹ́ tẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni ọpọlọ béńbé tí ọmọ ènìyàn ní kò lè gbé òye bí òde ọ̀run ṣe rí. Nítorí náà, ńṣe làwọn ìran yìí wulẹ̀ lo ohun tí ènìyàn lè lóye láti fi ṣàlàyé ohun tí wọ́n fẹ́ sọ. (Fi wé Ìṣípayá 1:1.) Nínú ìran Aísáyà, kò sí ìdí fún àlàyé nípa ìrísí Ọlọ́run. Ìran yẹn fi yé Aísáyà pé Jèhófà wà nínú tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ̀, àti pé ẹni mímọ́ ni, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ kò sì lálèébù kankan.
Àwọn Séráfù
5. (a) Ta ni àwọn séráfù, kí sì ni gbólóhùn náà túmọ̀ sí? (b) Èé ṣe tí àwọn séráfù fi fi ojú àti ẹsẹ̀ wọn pa mọ́?
5 Ẹ fetí sílẹ̀! Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Àwọn séráfù dúró lókè rẹ̀. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ apá mẹ́fà. Méjì ni ó fi ń bo ojú rẹ̀, méjì sì ni ó fi ń bo ẹsẹ̀ rẹ̀, méjì sì ni ó fi ń fò káàkiri.” (Aísáyà 6:2) Aísáyà orí kẹfà nìkan la ti rí i pé Bíbélì mẹ́nu kan séráfù. Ó dájú pé àwọn áńgẹ́lì tó ní ipò ẹrù iṣẹ́ àti àǹfààní tó ga gidigidi nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ni àwọn ẹ̀dá wọ̀nyí, nítorí àyíká ìtẹ́ Jèhófà lọ́run làwọn máa ń wà. Wọn kò dà bí Ùsáyà, ọba onígbèéraga, nítorí tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ni wọ́n fi wà ní ipò wọn, wọ́n sì mọ̀wọ̀n ara wọn. Wíwà tí wọ́n wà nítòsí Ọba Aláṣẹ ọ̀run mú kí wọ́n fi ìyẹ́ méjì bojú; wọ́n sì tún fi méjì mìíràn bo ẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́. Bó ṣe jẹ́ pé itòsí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé làwọn séráfù yìí wà, ṣe ni wọ́n túbọ̀ fara wọn pa mọ́, kí wọ́n má bàa bu ògo Ọlọ́run kù. Gbólóhùn náà, “séráfù,” tó túmọ̀ sí “ẹni bí iná” tàbí “ajóbí-iná,” fi hàn pé ara wọn ń tànmọ́lẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀, wọ́n ṣì gbójú pa mọ́ nítorí kíkọ mànà Jèhófà àti ògo rẹ̀ tó ga ju tiwọn lọ.
6. Níbo ni àwọn séráfù wà sí Jèhófà?
6 Àwọn séráfù a máa fi ìyẹ́ méjì tó ṣìkẹta fò, ó sì dájú pé wọ́n tún fi ń rà bàbà, tàbí kí wọ́n fi “dúró,” sí ipò wọn. (Fi wé Diutarónómì 31:15.) Ọ̀jọ̀gbọ́n Franz Delitzsch sọ nípa ipò wọn pé: “Dájúdájú, àwọn séráfù kò ní ga gàgàrà sókè orí Ẹni tó jókòó sórí ìtẹ́ náà, ṣùgbọ́n wọn a máa rà bàbà lókè aṣọ Rẹ̀ tó kún inú gbọ̀ngàn náà.” (Commentary on the Old Testament) Ó jọ pé èyí bọ́gbọ́n mu. Wọ́n “dúró lókè,” kì í ṣe ti pé wọ́n ga lọ́lá ju Jèhófà lọ, bí kò ṣe ti pé wọ́n ń ṣèránṣẹ́ fún un, pé wọ́n jẹ́ onígbọràn, wọ́n sì ṣe tán láti jíṣẹ́ tó bá rán wọn.
7. (a) Iṣẹ́ wo ni àwọn séráfù ń gbé ṣe? (b) Èé ṣe tí àwọn séráfù fi polongo lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé mímọ́ ni Ọlọ́run?
7 Wàyí o, ẹ wá gbóhùn àwọn séráfù tó láǹfààní gíga yìí! “Ẹni tibí sì ń ké sí ẹni tọ̀hún pé: ‘Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ gbogbo ilẹ̀ ayé ni ògo rẹ̀.’” (Aísáyà 6:3) Iṣẹ́ tiwọn ni láti rí i pé ìpolongo ìjẹ́mímọ́ Jèhófà kò dáwọ́ dúró, àti pé gbogbo àgbáyé pátá, tí ayé jẹ́ apá kan rẹ̀, ń fògo fún un. Ògo rẹ̀ yọ lára gbogbo ohun tó dá, gbogbo olùgbé ayé ni yóò sì wá mọ̀ bẹ́ẹ̀ láìpẹ́. (Númérì 14:21; Sáàmù 19:1-3; Hábákúkù 2:14) Pípolongo tí wọ́n polongo “mímọ́, mímọ́, mímọ́,” lẹ́ẹ̀mẹ́ta kì í ṣe ẹ̀rí pé Mẹ́talọ́kan wà rárá. Dípò ìyẹn, ńṣe ló ń tẹnu mọ́ ọn gbọnmọgbọnmọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé mímọ́ ni Ọlọ́run. (Fi wé Ìṣípayá 4:8.) Jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ mímọ́ kò lẹ́gbẹ́.
8. Kí ló tẹ̀yìn ìpolongo àwọn séráfù yọ?
8 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò mẹ́nu kan iye tí àwọn séráfù náà jẹ́, ó ṣeé ṣe kí àwọn séráfù yìí wà ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́ yí ká ìtẹ́ náà. Ńṣe ni wọ́n ń fi orin adùnyùngbà polongo ìjẹ́mímọ́ àti ògo Ọlọ́run lọ́wọ̀ọ̀wọ́, tí wọ́n ń kọ ọ́ lákọgbà. Kí la rí pé ó tẹ̀yìn èyí yọ? Tún gbọ́ bí Aísáyà ṣe ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Àwọn ìkọ́ olóyìípo tí ń bẹ ní ibi àbáwọlé . . . bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nítorí ohùn ẹni tí ń pè, ilé náà sì kún fún èéfín ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀.” (Aísáyà 6:4) Nínú Bíbélì, èéfín tàbí àwọsánmà sábà máa ń jẹ́ àmì táwọn èèyàn máa fi ń mọ̀ pé Ọlọ́run ń bẹ nítòsí. (Ẹ́kísódù 19:18; 40:34, 35; 1 Àwọn Ọba 8:10, 11; Ìṣípayá 15:5-8) Ó dúró fún ògo tí àwa ẹ̀dá ènìyàn kò lè sún mọ́ rárá.
Kò Kúnjú Òṣùnwọ̀n, Síbẹ̀ Ó Rí Ìwẹ̀nùmọ́
9. (a) Ipa wo ni ìran yìí ní lórí Aísáyà? (b) Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín Aísáyà àti Ùsáyà Ọba?
9 Ipa tó ga gidigidi ni ìran ìtẹ́ Jèhófà ní lórí Aísáyà. Ó kọ̀wé pé: “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé: ‘Mo gbé! Nítorí, kí a sáà kúkú sọ pé a ti pa mí lẹ́nu mọ́, nítorí pé ọkùnrin aláìmọ́ ní ètè ni mí, àárín àwọn ènìyàn aláìmọ́ ní ètè sì ni mo ń gbé; nítorí pé ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tìkára rẹ̀!’” (Aísáyà 6:5) Aísáyà àti Ùsáyà Ọba mà kúkú yàtọ̀ síra o! Ùsáyà fi ìkùgbù bọ́ sí ipò àlùfáà, tó jẹ́ tàwọn ẹni àmì òróró nìkan, ó sì fi ìwà àìlọ́wọ̀ já wọnú ibi Mímọ́ inú tẹ́ńpìlì. Lóòótọ́, Ùsáyà rí ọ̀pá fìtílà wúrà, pẹpẹ wúrà tí wọ́n ń sun tùràrí lórí rẹ̀, àti àwọn tábìlì “búrẹ́dì tó fi hàn pé Jèhófà wà níbẹ̀,” àmọ́ kò rí ojú rere Jèhófà, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà kò yan àkànṣe iṣẹ́ fún un láti ṣe. (1 Àwọn Ọba 7:48-50; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Àmọ́, ní ti wòlíì Aísáyà, kò fojú tín-ínrín ipò àlùfáà, kò sì yọjúràn ní tẹ́ńpìlì. Síbẹ̀, lójú ìran, ó rí Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ mímọ́, Ọlọ́run sì dá a lọ́lá nípa fífúnra rẹ̀ gbé àkànṣe iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ láti ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn séráfù kò jẹ́ dá a láṣà láti ṣíjú wo Olúwa tẹ́ńpìlì náà lórí ìtẹ́ rẹ̀, a yọ̀ǹda fún Aísáyà láti tojú ìran wo “Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, tìkára rẹ̀!”
10. Èé ṣe tí ẹ̀rù fi ba Aísáyà nígbà tó rí ìran yìí?
10 Bí ẹlẹ́gbin ni Aísáyà rí lójú ara rẹ̀ nígbà tó ń wo bí Ọlọ́run ṣe jẹ́ mímọ́ tó ní ìyàtọ̀ sí òun ẹlẹ́ṣẹ̀. Bí ẹ̀rù ṣe bà á tó, ṣe ló rò pé òun yóò kú. (Ẹ́kísódù 33:20) Ó ń gbọ́ bí àwọn séráfù náà ṣe ń fi ètè mímọ́ yin Ọlọ́run, ètè tirẹ̀ sì rèé, aláìmọ́ ni, àìmọ́ ètè àwọn tí Aísáyà ń gbé láàárín wọn tó sì ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn sì túbọ̀ dá kún àìmọ́ tirẹ̀. Mímọ́ ni Jèhófà, ànímọ́ tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì gbọ́dọ̀ ní nìyẹn. (1 Pétérù 1:15, 16) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ti yan Aísáyà ṣe agbẹnusọ rẹ̀, jíjẹ́ tó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ wá hàn gbangba sí i, ó rí i pé ètè òun kò mọ́ tó tẹni tó lè jẹ́ agbẹnusọ fún Ọba mímọ́ ológo yẹn. Èsì wo ló máa wá gbà látọ̀run?
11. (a) Kí ni ọ̀kan lára àwọn séráfù ṣe, kí sì ni ìgbésẹ̀ yìí dúró fún? (b) Báwo ni ṣíṣàṣàrò lórí ohun tí séráfù sọ fún Aísáyà ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà tó bá ṣe wá bíi pé a ò tóótun gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Ọlọ́run?
11 Dípò kí àwọn séráfù taari Aísáyà tí kò já mọ́ nǹkan kan kúrò níwájú Jèhófà, ṣe ni wọ́n ràn án lọ́wọ́. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Látàrí ìyẹn, ọ̀kan lára àwọn séráfù náà fò wá sọ́dọ̀ mi, ẹyín iná pípọ́n yòò sì wà ní ọwọ́ rẹ̀, èyí tí ó fi ẹ̀múná mú láti orí pẹpẹ wá. Ó sì fi kan ẹnu mi, ó sì wí pé: ‘Wò ó! Èyí ti kan ètè rẹ, ìṣìnà rẹ sì ti kúrò, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ pàápàá ni a sì ti ṣètùtù fún.’” (Aísáyà 6:6, 7) Iná lè sọ nǹkan di mímọ́ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Nígbà tí séráfù náà ń fi ẹyín iná tó mú látinú iná mímọ́ tó wà lórí pẹpẹ kan Aísáyà létè, ó fi yé Aísáyà pé wọ́n ti ṣètùtù àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ dépò tí yóò fi lè rójú rere Ọlọ́run, kí Ọlọ́run sì gbé iṣẹ́ fún un láti ṣe. Èyí mà fi wá lọ́kàn balẹ̀ o! Ẹlẹ́ṣẹ̀ làwa náà, a kò sì tóótun láti tọ Ọlọ́run lọ. Àmọ́, ìtóye ẹbọ ìràpadà Jésù ti rà wá padà, a sì lè rójú rere Ọlọ́run kí a sì gbàdúrà sí i.—2 Kọ́ríńtì 5:18, 21; 1 Jòhánù 4:10.
12. Pẹpẹ wo ni Aísáyà rí, kí sì ni iná lè ṣe?
12 Dídá táa dárúkọ “pẹpẹ” ló tún rán wa létí pé ìran lèyí o. (Fi wé Ìṣípayá 8:3; 9:13.) Pẹpẹ méjì ló wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Pẹpẹ kékeré fún tùràrí sísun wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìkélé Ibi Mímọ́ Jù Lọ, pẹpẹ ńlá fún ẹbọ rírú sí wà ní ìta àbáwọlé ibùjọsìn, iná kì í sì í kú lórí ìyẹn rárá. (Léfítíkù 6:12, 13; 16:12, 13) Ṣùgbọ́n àwọn pẹpẹ orí ilẹ̀ ayé wọ̀nyí jẹ́ ohun ìṣàpẹẹrẹ, tó dúró fún àwọn nǹkan tó ga jù bẹ́ẹ̀ lọ. (Hébérù 8:5; 9:23; 10:5-10) Iná àtọ̀runwá ló jó ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ nígbà ayẹyẹ tí Sólómọ́nì Ọba fi ṣí tẹ́ńpìlì. (2 Kíróníkà 7:1-3) Lọ́tẹ̀ yìí, iná tó wá látorí pẹpẹ tòótọ́, tó wà lọ́run, ló mú àìmọ́ ètè Aísáyà kúrò.
13. Ìbéèrè wo ni Jèhófà béèrè, ta ló sì fi kún un nígbà tó lo “wa”?
13 Ẹ jẹ́ ká jọ fetí sílẹ̀ pẹ̀lú Aísáyà. “Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ́ ohùn Jèhófà tí ó wí pé: ‘Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?’ Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wí pé: ‘Èmi nìyí! Rán mi.’” (Aísáyà 6:8) Ó dájú pé ńṣe ni Jèhófà béèrè ìbéèrè rẹ̀ kí Aísáyà lè dáhùn, torí yàtọ̀ sí i kò tún sí ènìyàn mìíràn tó jẹ́ wòlíì nínú ìran yẹn. Dájúdájú, ńṣe ni Jèhófà ń ké sí Aísáyà láti di ońṣẹ́ òun. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tí Jèhófà fi béèrè pé, “Ta . . . ni yóò lọ fún wa?” Bí Jèhófà ṣe yí kúrò lórí lílo “èmi,” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ atọ́ka ẹnì kan ṣoṣo, tó sì lo “wa,” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ atọ́ka ẹlẹ́ni púpọ̀, fi hàn pé ó kéré tán, ó ti mú ẹnì kan mọ́ra. Ta ni? Òun ha kọ́ ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tó di ẹni tí ń jẹ́ Jésù Kristi? Bẹ́ẹ̀ ni, Ọmọ yìí kan náà ni Ọlọ́run sọ fún pé, “Jẹ́ kí a ṣe ènìyàn ní àwòrán wa.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:26; Òwe 8:30, 31) Bẹ́ẹ̀ ni, Ọmọ bíbí kan ṣoṣo tí Jèhófà ní wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ nínú ààfin ọ̀run náà.—Jòhánù 1:14.
14. Báwo ni Aísáyà ṣe dáhùn ìpè Jèhófà, àpẹẹrẹ wo ló sì fi lélẹ̀ fún wa?
14 Ojú ẹsẹ̀ mà ni Aísáyà fèsì o! Ohun yòówù kí iṣẹ́ náà jẹ́, ó fèsì kíákíá pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” Kò sì béèrè ohun tó máa jẹ́ ère tòun bóun bá tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yẹn. Àpẹẹrẹ àtàtà ni ẹ̀mí ìmúratán tó ní jẹ́ fún gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí, tí iṣẹ́ wọn jẹ́ láti wàásù “ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Bíi Aísáyà, wọn kò jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ wọn, wọ́n sì ṣàṣeparí iṣẹ́ jíjẹ́ “ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè,” bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọ etí dídi sí wọn. Tìgboyàtìgboyà ni wọ́n sì fi ń bá iṣẹ́ wọn lọ gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti ṣe, nítorí wọ́n mọ̀ pé, ẹni gíga jù lọ ló gbéṣẹ́ lé àwọn lọ́wọ́.
Iṣẹ́ Tí Ọlọ́run Yàn fún Aísáyà
15, 16. (a) Kí ni Aísáyà yóò sọ fún “àwọn ènìyàn yìí,” kí ni yóò sì jẹ́ ìṣarasíhùwà wọn sí i? (b) Ṣé Aísáyà ló fà á tí àwọn èèyàn yẹn fi hùwà lọ́nà yẹn? Ṣàlàyé.
15 Jèhófà wá ṣàlàyé ohun tí Aísáyà yóò sọ àti èsì tó máa rí gbà, pé: “Lọ, kí o sì sọ fún àwọn ènìyàn yìí pé, ‘Ẹ gbọ́ ní àgbọ́túngbọ́, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe lóye; kí ẹ sì rí ní àrítúnrí, ṣùgbọ́n kí ẹ má ṣe ní ìmọ̀ kankan.’ Mú kí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí sébọ́, sì mú kí etí wọn gan-an gíràn-án, sì lẹ ojú wọn gan-an pọ̀, kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí, kí wọ́n má sì fi etí wọn gbọ́, kí ọkàn-àyà wọn má sì lóye, kí wọ́n má sì yí padà ní tòótọ́, kí wọ́n má sì rí ìmúláradá gbà fún ara wọn.” (Aísáyà 6:9, 10) Ṣé pé kí Aísáyà kàn máa sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu àwọn Júù, kó sọ̀rọ̀ sí wọn ṣàkàṣàkà kí wọ́n sì yarí, kí wọ́n dọ̀tá Jèhófà? Rárá o! Ìbátan Aísáyà ni wọ́n, ojú mọ̀lẹ́bí ló fi ń wò wọ́n. Ńṣe ni ọ̀rọ̀ Jèhófà ń sọ ohun tí yóò jẹ́ ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn wọ̀nyẹn sí ọ̀rọ̀ òun, bó ti wù kí Aísáyà sapá tó lẹ́nu iṣẹ́ yẹn.
16 Àwọn èèyàn yẹn ló lẹ̀bi. “Àgbọ́túngbọ́” ni Aísáyà yóò mú kí wọ́n gbọ́, ṣùgbọ́n wọn kò ní gba iṣẹ́ rẹ̀, kò sì ní yé wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn yóò ya olóríkunkun àti elétí dídi àfi bí ẹni pé afọ́jú àti odi ni wọ́n. Lílọ tí Aísáyà ń lọ sọ́dọ̀ “àwọn ènìyàn yìí” lemọ́lemọ́ ni yóò fi jẹ́ kí wọ́n fi hàn pé ńṣe làwọn ò fẹ́ kí òye ohun tó ń sọ yé àwọn. Wọn yóò fúnra wọn fi hàn pé ńṣe làwọn kọ etí dídi sí iṣẹ́ tí Aísáyà ń jẹ́ fáwọn—iṣẹ́ Ọlọ́run. Báwọn èèyàn mà ṣe ń ṣe gẹ́lẹ́ lónìí nìyẹn o! Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló ń kọ̀ láti gbọ́rọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí wọ́n ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ń bọ̀.
17. Nígbà tí Aísáyà béèrè pé, “Yóò ti pẹ́ tó?” kí ló ń tọ́ka sí?
17 Ìyẹn ò fi Aísáyà lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Látàrí èyí, mo sọ pé: ‘Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà?’ Nígbà náà ni ó sọ pé: ‘Títí àwọn ìlú ńlá náà yóò fi fọ́ bàjẹ́ ní tòótọ́, tí wọn yóò fi wà láìsí olùgbé, tí àwọn ilé yóò fi wà láìsí ará ayé, tí a ó sì run ilẹ̀ pàápàá di ahoro; tí Jèhófà yóò sì ṣí àwọn ará ayé lọ sí ọ̀nà jíjìnréré ní ti gidi, tí ipò ìkọ̀tì náà yóò sì wá di gbígbòòrò gidigidi ní àárín ilẹ̀ náà.’” (Aísáyà 6:11, 12) Nígbà tí Aísáyà béèrè pé, “Yóò ti pẹ́ tó?” kì í ṣe pé ó ń béèrè ìwọ̀n àkókò tí òun yóò fi wàásù fún àwọn tó kọ etí dídi sí i yìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń ṣàníyàn nípa àwọn èèyàn yẹn, tó fi béèrè nípa bí yóò ṣe pẹ́ tó tí wọn yóò fi máa ṣàìgbọ́ ti Ọlọ́run, àti bí àìbọ̀wọ̀ fún orúkọ Jèhófà yóò ṣe máa bá a lọ pẹ́ tó ní ayé. (Wo Sáàmù 74:9-11.) Tóò, báwo wá ni ipò burúkú yìí yóò ti wà pẹ́ tó?
18. Títí dìgbà wo ni àwọn èèyàn yẹn yóò fi ṣàìgbọ́ tí Ọlọ́run, ṣé àsọtẹ́lẹ̀ yẹn yóò sì ṣẹ pátápátá níṣojú Aísáyà?
18 Ó mà ṣe o, èsì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà fi hàn pé àwọn èèyàn yìí yóò máa ṣàìgbọ́ tòun títí dìgbà tí gbogbo ìyà àìgbọràn sí Ọlọ́run, tí májẹ̀mú rẹ̀ tò lẹ́sẹẹsẹ, yóò fi jẹ wọ́n. (Léfítíkù 26:21-33; Diutarónómì 28:49-68) Orílẹ̀-èdè náà yóò pa run, àwọn èèyàn yẹn yóò dèrò ìgbèkùn, ilẹ̀ náà yóò sì dahoro. Pípa tí agbo ọmọ ogun Bábílónì yóò pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa kò ní ṣojú Aísáyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé yóò fi ohun tó ju ogójì ọdún sàsọtẹ́lẹ̀, ìyẹn títí dìgbà ìṣàkóso Hesekáyà, ọmọ ọmọ Ùsáyà Ọba. Síbẹ̀ náà, Aísáyà kò ní jáwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ títí dìgbà ikú rẹ̀ ní èyí tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ ṣáájú kí àjálù yẹn tó bá orílẹ̀-èdè náà.
19. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa gé orílẹ̀-èdè náà lulẹ̀ bí igi, ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ni Ọlọ́run fún Aísáyà?
19 Ó di dandan kí ìparun tí yóò “run” Júdà “di ahoro” dé, àmọ́ ṣíṣe ṣì kù. (2 Àwọn Ọba 25:1-26) Jèhófà fi Aísáyà lọ́kàn balẹ̀ pé: “Ìdá mẹ́wàá yóò ṣì wà nínú rẹ̀ síbẹ̀, yóò sì tún di ohun kan fún sísun kanlẹ̀, bí igi ńlá àti bí igi ràgàjì, tí ó jẹ́ pé, nígbà tí a gé wọn lulẹ̀, wọ́n ní kùkùté; irúgbìn mímọ́ ni yóò jẹ́ kùkùté rẹ̀.” (Aísáyà 6:13) Bẹ́ẹ̀ ni, “ìdá mẹ́wàá . . . irúgbìn mímọ́,” yóò ṣẹ́ kù, gẹ́gẹ́ bíi kùkùté igi ràgàjì tí wọ́n gé lulẹ̀. Ó dájú pé ọ̀rọ̀ yìí tu Aísáyà nínú—àṣẹ́kù mímọ́ yóò ṣì wà nínú àwọn èèyàn rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé léraléra ni orílẹ̀-èdè náà yóò jó, bí ẹní gé igi ńlá lulẹ̀ láti fi dáná, síbẹ̀síbẹ̀ kùkùté pàtàkì kan yóò ṣẹ́ kù lára igi tó ṣàpẹẹrẹ Ísírẹ́lì yìí. Yóò jẹ́ irúgbìn mímọ́, tàbí irú ọmọ, tó jẹ́ mímọ́ sí Jèhófà. Bó bá yá, yóò tún sọ, igi yìí a sì tún rúwé.—Fi wé Jóòbù 14:7-9; Dáníẹ́lì 4:26.
20. Báwo ni apá ìkẹyìn àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣe kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ?
20 Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ? Bẹ́ẹ̀ ni. Àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró olùbẹ̀rù Ọlọ́run padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì ní àádọ́rin ọdún lẹ́yìn tí ilẹ̀ Júdà ti dahoro. Wọ́n tún tẹ́ńpìlì àti ìlú yẹn kọ́, wọ́n sì mú ìjọsìn tòótọ́ bọ̀ sípò ní ilẹ̀ náà. Ìpadàbọ̀ àwọn Júù yìí sí ilẹ̀ tí Ọlọ́run fi fún wọn, ló jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà fi fún Aísáyà yìí ní ìmúṣẹ kejì. Kí ni ìyẹn wá jẹ́?—Ẹ́sírà 1:1-4.
Àwọn Ìmúṣẹ Mìíràn
21-23. (a) Ta ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ sí lára ní ọ̀rúndún kìíní, báwo sì ni? (b) Ta ni “irúgbìn mímọ́” ní ọ̀rúndún kìíní, báwo la sì ṣe pa á mọ́?
21 Iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ iṣẹ́ tí Jésù Kristi, Mèsáyà, yóò ṣe ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ọdún lẹ́yìn náà. (Aísáyà 8:18; 61:1, 2; Lúùkù 4:16-21; Hébérù 2:13, 14) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù tóbi ju Aísáyà, bíi tirẹ̀ gẹ́lẹ́ lòun náà ṣe wà ní sẹpẹ́ láti jẹ́ iṣẹ́ Baba rẹ̀ ọ̀run, ó ní: “Wò ó! Mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ.”—Hébérù 10:5-9; Sáàmù 40:6-8.
22 Bíi Aísáyà, Jésù pẹ̀lú kò jáwọ́ rárá lẹ́nu iṣẹ́ tó gbà, irú ìwà kan náà sì làwọn èèyàn hù sí i. Bí àwọn Júù tí wòlíì Aísáyà wàásù fún ṣe kọ etí dídi sí i náà làwọn Júù ọjọ́ Jésù ṣe kọ ọ́. (Aísáyà 1:4) A mọ Jésù mọ́ àpèjúwe lílò lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ìyẹn mú kí àwọn àpọ́sítélì bi í léèrè pé: “Èé ṣe tí o fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn àpèjúwe?” Jésù fèsì pé: “Ẹ̀yin ni a yọ̀ǹda fún láti lóye àwọn àṣírí ọlọ́wọ̀ ti ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọnnì ni a kò yọ̀ǹda fún. Ìdí nìyí tí mo fi ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa lílo àwọn àpèjúwe, nítorí pé, ní wíwò, wọ́n ń wò lásán, àti ní gbígbọ́, lásán ni wọ́n ń gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni òye rẹ̀ kò yé wọn; àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sì ń ní ìmúṣẹ sí wọn, èyí tí ó wí pé, ‘Ní gbígbọ́, ẹ óò gbọ́ ṣùgbọ́n òye rẹ̀ kì yóò yé yín lọ́nàkọnà; àti pé, ní wíwò, ẹ ó wò ṣùgbọ́n ẹ kì yóò rí lọ́nàkọnà. Nítorí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn yìí ti sébọ́, wọ́n sì ti fi etí wọn gbọ́ láìsí ìdáhùnpadà, wọ́n sì ti di ojú wọn; kí wọ́n má bàa fi ojú wọn rí láé, kí wọ́n sì fi etí wọn gbọ́, kí òye rẹ̀ sì yé wọn nínú ọkàn-àyà wọn, kí wọ́n má sì yí padà, kí n má sì mú wọn lára dá.’”—Mátíù 13:10, 11, 13-15; Máàkù 4:10-12; Lúùkù 8:9, 10.
23 Fífà tí Jésù fa ọ̀rọ̀ Aísáyà yọ, ńṣe ló ń fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ lọ́jọ́ tòun. Irú ìṣarasíhùwà tí àwọn Júù ayé Aísáyà ní làwọn èèyàn yìí ní gbogbo gbòò ní. Wọ́n di ojú, wọ́n tún di etí wọn sí iṣẹ́ tó ń jẹ́, àwọn náà sì pa run pẹ̀lú. (Mátíù 23:35-38; 24:1, 2) Èyí ṣẹlẹ̀ nígbà tí Ọ̀gágun Títù kó agbo ọmọ ogun Róòmù wá sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa, tí wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run. Àmọ́ ṣá, àwọn kan gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù, wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Jésù sọ pé “aláyọ̀” ni àwọn yẹn. (Mátíù 13:16-23, 51) Ó ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé nígbà tí wọ́n bá rí i tí “àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun adótini bá yí Jerúsálẹ́mù ká” kí wọ́n “bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ sí àwọn òkè ńlá.” (Lúùkù 21:20-22) Bí ìgbàlà ṣe dé fún “irúgbìn mímọ́” tó lo ìgbàgbọ́, táa sì sọ di orílẹ̀-èdè tẹ̀mí, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” nìyẹn.a—Gálátíà 6:16.
24. Àlàyé wo ni Pọ́ọ̀lù ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, kí ni èyí sì fi hàn?
24 Ní nǹkan bí ọdún 60 Sànmánì Tiwa, wọ́n sé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ́lé ní Róòmù. Ibẹ̀ ló ti bá “àwọn tí wọ́n jẹ́ sàràkí-sàràkí . . . lára àwọn Júù” àti àwọn mìíràn ṣèpàdé, ó sì “jẹ́rìí kúnnákúnná nípa ìjọba Ọlọ́run” fún wọn. Nígbà tí púpọ̀ nínú wọn ò gba ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó ṣàlàyé pé àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ló ń ṣẹ sí wọn lára. (Ìṣe 28:17-27; Aísáyà 6:9, 10) Nípa báyìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ṣe irú iṣẹ́ tó jọ ti Aísáyà.
25. Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Ọlọ́run lóde òní fòye mọ̀, kí sì ni ìṣarasíhùwà wọn sí i?
25 Lónìí bákan náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fòye mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wà nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ mímọ́. (Málákì 3:1) Wọ́n sọ bíi ti Aísáyà pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” Wọ́n ń fi ìtara kéde iṣẹ́ ìkìlọ̀ nípa òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí tó sún mọ́lé. Àmọ́, bí Jésù ṣe wí, ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ló la ojú wọn láti rí, tí wọ́n sì ṣí etí wọn láti gbọ́, kí wọ́n sì rí ìgbàlà. (Mátíù 7:13, 14) Ní tòótọ́, aláyọ̀ gbáà làwọn tó ṣí ọkàn wọn sílẹ̀ láti gbọ́ kí wọ́n sì “rí ìmúláradá gbà fún ara wọn”!—Aísáyà 6:8, 10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lọ́dún 66 Sànmánì Tiwa, nígbà tí Cestius Gallus kó agbo ọmọ ogun Róòmù lọ paná ọ̀tẹ̀ àwọn Júù, wọ́n yí Jerúsálẹ́mù ká, wọ́n sì wọ̀lú dé ibi ògiri tẹ́ńpìlì. Lẹ́yìn náà, wọ́n padà sẹ́yìn, tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ráyè sá lọ sórí òkè Perea kí àwọn ará Róòmù tó padà lọ́dún 70 Sànmánì Tiwa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 94]
“Èmi nìyí! Rán mi.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 97]
‘Títí àwọn ìlú ńlá náà yóò fi fọ́ bàjẹ́, tí wọn yóò fi wà láìsí olùgbé’