Orí Kọkànlá
“Ẹ Má Ṣe Gbẹ́kẹ̀ Yín Lé Àwọn Ọ̀tọ̀kùlú”
1, 2. (a) Ìmọ̀ràn onímìísí wo ni àwọn Júù kọ etí dídi sí, kí sì ni àbáyọrí rẹ̀? (b) Kí ni ìdí tí Jèhófà fi béèrè pé: ‘Ibo ni ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ wà?’
“Ẹ MÁ ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀. . . . Aláyọ̀ ni ẹni tí ó ní Ọlọ́run Jékọ́bù fún ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, ẹni tí ìrètí rẹ̀ ń bẹ nínú Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, Olùṣẹ̀dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 146:3-6) Áà, àwọn Júù tó wà nígbà ayé Aísáyà ì bá jẹ́ tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onísáàmù yìí! Wọn ì bá jẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé “Ọlọ́run Jékọ́bù” dípò gbígbẹ́kẹ̀ lé Íjíbítì tàbí orílẹ̀-èdè kèfèrí èyíkéyìí! Tí àwọn ọ̀tá Júdà bá sì wá gbógun dìde sí i, Jèhófà ì bá gbèjà rẹ̀. Àmọ́, Júdà kọ̀ láti yíjú sí Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́. Nítorí náà, Jèhófà yóò jẹ́ kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run kí wọ́n sì kó àwọn ará Júdà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì.
2 Ìyẹn kì í ṣe ẹ̀bi ẹnikẹ́ni o, àfọwọ́fà Júdà ló kó bá a. Kò ní àwíjàre kankan tí yóò fi lè sọ pé àdàkàdekè ni Jèhófà ṣe sí òun tàbí pé ńṣe ni ó kọ májẹ̀mú tó bá orílẹ̀-èdè òun dá sílẹ̀ tí ìparun fi bá òun. Ẹlẹ́dàá kì í da májẹ̀mú rárá. (Jeremáyà 31:32; Dáníẹ́lì 9:27; Ìṣípayá 15:4) Ohun tí Jèhófà ń gbé yọ nìyí tó fi bi àwọn Júù léèrè pé: “Ibo wá ni ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá yín wà, ẹni tí mo rán lọ?” (Aísáyà 50:1a) Lábẹ́ Òfin Mósè, ẹni tó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ ní láti fún un ní ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀. Obìnrin náà á wá lómìnira láti fẹ́ ẹlòmíràn. (Diutarónómì 24:1, 2) Jèhófà ti fún Ísírẹ́lì, tó jẹ́ ìjọba tó ṣìkejì ìjọba Júdà ní irú ìwé ẹ̀rí yẹn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, àmọ́ kò tíì fún Júdà.a Òun ṣì ni “ọkọ olówó orí” wọn. (Jeremáyà 3:8, 14) Dájúdájú, Júdà kò lómìnira láti lọ fẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè kèfèrí. Júdà àti Jèhófà kò ní kọra sílẹ̀ “títí Ṣílò [Mèsáyà] yóò fi dé.”—Jẹ́nẹ́sísì 49:10.
3. Kí ni ìdí tí Jèhófà fi ‘ta’ àwọn èèyàn rẹ̀?
3 Jèhófà sì tún bi Júdà pé: “Èwo lára àwọn tí mo jẹ ní gbèsè ni mo tà yín fún?” (Aísáyà 50:1b) Jèhófà kò ní rán àwọn Júù lọ sígbèkùn ní Bábílónì bí ìgbà táà bá sọ pé ó jẹ gbèsè tó sì fẹ́ lọ fi wọ́n dí i. Jèhófà kò rí bí akúùṣẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì kan tó di dandan fún pé kí ó ta àwọn ọmọ rẹ̀ láti fi dí gbèsè. (Ẹ́kísódù 21:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà sọ ìdí gan-an tí àwọn èèyàn rẹ̀ yóò fi lọ sìnrú, ó ní: “Wò ó! Nítorí àwọn ìṣìnà tiyín ni a fi tà yín, nítorí àwọn ìrélànàkọjá tiyín ni a sì fi rán ìyá yín lọ.” (Aísáyà 50:1d) Àwọn Júù ló kúkú kọ Jèhófà sílẹ̀; Jèhófà kọ́ ló kọ̀ wọ́n sílẹ̀.
4, 5. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun fẹ́ràn àwọn èèyàn òun, ṣùgbọ́n ìhà wo ni Júdà kọ sí i?
4 Ìbéèrè tí Jèhófà béèrè tẹ̀ lé e gbé ìfẹ́ tí ó fẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ yọ, ó ní: “Èé ṣe tí ó fi jẹ́ pé, nígbà tí mo wọlé wá, kò sí ẹnì kankan? Nígbà tí mo pè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó dáhùn?” (Aísáyà 50:2a) Jèhófà wọnú ilé àwọn èèyàn rẹ̀ ni ká wí, nípa bí ó ṣe lo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì láti rọ̀ wọ́n láti fi gbogbo ọkàn wọn yí padà sí òun. Ṣùgbọ́n wọ́n fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́. Àwọn Júù yàn láti yíjú sí ọmọ aráyé fún ìtìlẹyìn, kódà wọ́n tilẹ̀ ń yíjú sí Íjíbítì nígbà mìíràn.— Aísáyà 30:2; 31:1-3; Jeremáyà 37:5-7.
5 Ṣé Íjíbítì wá jẹ́ olùgbàlà tó ṣeé gbára lé ju Jèhófà lọ ni? Ńṣe ló jọ pé àwọn Júù aláìṣòótọ́ wọ̀nyẹn ti gbàgbé àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ kí orílẹ̀-èdè wọn tó wáyé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn. Jèhófà bi wọ́n léèrè pé: “Ṣé ọwọ́ mi ti wá kúrú tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò fi lè túnni rà padà ni, tàbí kẹ̀, ṣé kò sí agbára nínú mi láti dáni nídè ni? Wò ó! Ìbáwí mímúná mi ni mo fi mú òkun gbẹ táútáú; mo sọ àwọn odò di aginjù. Ẹja wọn ṣíyàn-án nítorí pé kò sí omi, wọ́n sì kú nítorí òùngbẹ. Mo fi òkùnkùn ṣíṣú bo ọ̀run, mo sì fi aṣọ àpò ìdọ̀họ ṣe ìbòjú wọn.”—Aísáyà 50:2b, 3.
6, 7. Báwo ni Jèhófà ṣe fi agbára rẹ̀ láti gbani là hàn nígbà tí Íjíbítì gbógun ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?
6 Lọ́dún 1513 ṣááju Sànmánì Tiwa, Íjíbítì kì í ṣe olùgbàlà tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń retí, kàkà bẹ́ẹ̀ òun gan-an ló ń pọ́n wọn lójú. Ẹrú ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ní orílẹ̀-èdè kèfèrí yẹn. Ṣùgbọ́n Jèhófà dá wọn nídè, ìdáǹdè yẹn mà sì wúni lórí o! Lákọ̀ọ́kọ́, ó mú Ìyọnu Mẹ́wàá bá orílẹ̀-èdè yẹn. Lẹ́yìn ìyọnu kẹwàá tó fojú wọn gbolẹ̀ tààrà, Fáráò ilẹ̀ Íjíbítì rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n kúrò ní orílẹ̀-èdè yẹn. (Ẹ́kísódù 7:14–12:31) Àmọ́, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ tàìṣe bẹ́ẹ̀ tán ni Fáráò bá tún yí ọkàn padà. Ló bá kó agbo ọmọ ogun rẹ̀ lẹ́yìn, ó wá gbéra láti lọ dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì padà sí Íjíbítì tipátipá. (Ẹ́kísódù 14:5-9) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dojú kọ Òkun Pupa níwájú ni agbo ọmọ ogun Íjíbítì bá yọ lẹ́yìn wọn, wọ́n ká wọn mọ́! Ṣùgbọ́n Jèhófà kò kúrò lẹ́yìn wọn, ó gbèjà wọn.
7 Jèhófà de àwọn ará Íjíbítì lọ́nà, ó gbé ọwọ̀n àwọsánmà dí àárín àwọn àti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọsánmà yìí mú ìhà ti àwọn ará Íjíbítì ṣú dùdù; ó sì tànmọ́lẹ̀ síhà ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (Ẹ́kísódù 14:20) Bí Jèhófà ṣe dínà mọ́ àwọn ará Íjíbítì tán, ó wá “bẹ̀rẹ̀ sí mú òkun náà padà sẹ́yìn nípa ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn líle láti òru mọ́jú tí ó sì yí ìsàlẹ̀ òkun padà di ilẹ̀ gbígbẹ.” (Ẹ́kísódù 14:21) Bí omi náà ṣe pínyà, ni gbogbo èèyàn, lọ́kùnrin, lóbìnrin àtàwọn ọmọdé bá rí ọ̀nà sọdá Okùn Pupa láti sálà. Nígbà tí àwọn èèyàn Jèhófà sì fẹ́rẹ̀ẹ́ sọdá sí etíkun lódì kejì tán, Jèhófà wá gbé àwọsánmà yẹn kúrò. Bẹ́ẹ̀ làwọn ará Íjíbítì bá rọ́ sorí ilẹ̀ gbígbẹ nísàlẹ̀ òkun láti lépa wọn kíkankíkan. Bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe sọdá sí etíkun tán báyìí, ó dá alagbalúgbú omi náà padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀, ni Fáráò àti agbo ọmọ ogun rẹ̀ bá kú sómi. Bí Jèhófà ṣe gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀ nìyẹn o. Ìṣírí ńlá lèyí jẹ́ fún àwa Kristẹni òde òní!—Ẹ́kísódù 14:23-28.
8. Àwọn ìkìlọ̀ wo ni àwọn ará Júdà kọ etí dídi sí tó mú kí wọ́n dèrò ìgbèkùn nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín?
8 Nígbà ayé Aísáyà, ọgọ́rùn-ún ọdún méje ti kọjá lẹ́yìn tí ìṣẹ́gun yìí látọwọ́ Ọlọ́run wáyé. Júdà sì ti wá di orílẹ̀-èdè kan láyè ara rẹ̀. Nígbà mìíràn, ó máa ń lọ bá àwọn ìjọba ilẹ̀ òkèèrè bí Ásíríà àti Íjíbítì pé kí ìjọba wọn wọ àjọṣe pẹ̀lú òun. Ṣùgbọ́n àwọn aṣáájú orílẹ̀-èdè kèfèrí wọ̀nyí kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé. Ire tara wọn ni wọ́n sábà ń fi ṣáájú májẹ̀mú èyíkéyìí tí wọ́n bá bá Júdà dá. Àwọn wòlíì wá sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà, wọ́n kìlọ̀ fún àwọn ará Júdà pé kí wọ́n má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n kọ etí dídi sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì yìí. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, àwọn Júù yóò dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì láti lọ fi àádọ́rin ọdún sìnrú níbẹ̀. (Jeremáyà 25:11) Àmọ́ ṣá, Jèhófà kò ní gbàgbé àwọn èèyàn rẹ̀, kò sì ní ta wọ́n nù títí gbére. Bí àsìkò bá ti tó, yóò rántí wọn, yóò sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn láti lọ mú ìsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Fún ète wo? Kí wọ́n fi lọ múra sílẹ̀ de dídé Ṣílò, ẹni tí àwọn ènìyàn yóò máa gbọ́ tirẹ̀ ni!
Ṣílò Dé
9. Ta ni Ṣílò, irú olùkọ́ wo ló sì jẹ́?
9 Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún kọjá lọ lẹ́yìn náà. “Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àkókò dé,” ni ẹni tí ń jẹ́ Ṣílò, Jésù Kristi Olúwa, bá wá sójú táyé. (Gálátíà 4:4; Hébérù 1:1, 2) Ohun tí Jèhófà fi lè gbé alájọṣepọ̀ tímọ́tímọ́ rẹ̀ jù lọ dìde pé kí ó lọ ṣe Agbọ̀rọ̀sọ òun lọ́dọ̀ àwọn Júù, fi hàn pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn èèyàn rẹ̀ gidigidi. Irú agbọ̀rọ̀sọ wo ni Jésù sì wá jẹ́? Kò mà sí ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ o! Jésù tilẹ̀ tún ju agbọ̀rọ̀sọ lọ, olùkọ́ni ló jẹ́, àní Àgbà Olùkọ́ pàápàá. Ìyẹn kò sì yani lẹ́nu, nítorí pé ọ̀dọ̀ àgbàyanu olùkọ́ ló ti gbẹ̀kọ́, ìyẹn lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀. (Jòhánù 5:30; 6:45; 7:15, 16, 46; 8:26) Ohun tí Jésù sì gbẹnu Aísáyà sọ nínú àsọtẹ́lẹ̀ jẹ́rìí sí èyí, ó ní: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti fún mi ní ahọ́n àwọn tí a kọ́, kí n lè mọ bí a ti ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn. Ó ń jí mi ní òròòwúrọ̀; ó ń jí etí mi láti gbọ́, bí àwọn tí a kọ́.”—Aísáyà 50:4.b
10. Báwo ni Jésù ṣe gbé ìfẹ́ tí Jèhófà fẹ́ àwọn èèyàn Rẹ̀ yọ, ìhà wo ni wọ́n sì kọ sí Jésù?
10 Kí Jésù tó wá sórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀gbẹ́ Baba rẹ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ lọ́run. Òwe 8:30 ṣàpèjúwe àjọṣe tímọ́tímọ́ tí ń bẹ láàárín Baba àti Ọmọ yìí lọ́nà ewì, ó ní: “Mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Jèhófà] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, . . . mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Ìdùnnú ńláǹlà ló jẹ́ fún Jésù láti máa gbọ́rọ̀ lẹ́nu Bàbá rẹ̀. Ìfẹ́ tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ “àwọn ọmọ ènìyàn” lòun náà sì fẹ́ wọn. (Òwe 8:31) Nígbà tí Jésù wá sáyé, ó “ń fi ọ̀rọ̀ dá ẹni tí ó ti rẹ̀ lóhùn.” Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni kíka àyọkà tó jẹ́ ọ̀rọ̀ ìtùnú látinú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó sọ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì, . . . láti rán àwọn tí a ni lára lọ pẹ̀lú ìtúsílẹ̀.” (Lúùkù 4:18; Aísáyà 61:1) Ìhìn rere fún àwọn òtòṣì! Ìtura fún àwọn tí ó ti rẹ̀! Ayọ̀ gbáà ni ìkéde yẹn máa mú wá fún àwọn èèyàn yìí o! Àwọn kan sì yọ̀ lóòótọ́ o, àmọ́ kì í ṣe gbogbo àwọn èèyàn yìí ló yọ̀. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, púpọ̀ nínú wọn kọ̀ láti gbà pé òótọ́ ni pé Jèhófà ló kọ́ Jésù lẹ́kọ̀ọ́.
11. Ta ní bá Jésù wọ àjàgà pọ̀, kí ni ìyẹn sì mú bá wọn?
11 Ṣùgbọ́n, àwọn kan ṣì fẹ́ gbọ́rọ̀ rẹ̀ sí i. Tìdùnnú tìdùnnú ni wọ́n fi jẹ́ ìpè ọlọ́yàyà tí Jésù pè wọ́n, pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín.” (Mátíù 11:28, 29) Àwọn tó di àpọ́sítélì Jésù jẹ́ ara àwọn tó fà mọ́ ọn. Wọ́n mọ̀ pé bí àwọn àti Jésù yóò bá jọ wọ àjàgà, àwọn yóò ní láti ṣe iṣẹ́ àṣekára. Ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run títí dé òpin ilẹ̀ ayé sì wà lára àwọn ohun tó para pọ̀ jẹ́ iṣẹ́ yìí. (Mátíù 24:14) Bí àwọn àpọ́sítélì àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù sì ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ yìí, wọ́n rí i pé ó ń mú ìtura bá ọkàn wọn lóòótọ́. Iṣẹ́ kan náà yìí làwọn Kristẹni olóòótọ́ ń ṣe lóde òní, irú ìdùnnú kan náà yìí làwọn náà sì ń rí níbẹ̀.
Kò Ya Ọlọ̀tẹ̀
12. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà ṣe ìgbọràn sí Baba rẹ̀ ọ̀run?
12 Jésù kò gbàgbé rárá pé ète tóun fi wá sí ayé jẹ́ láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àsọtẹ́lẹ̀ sọ irú ojú tó fi wo ọ̀ràn náà, ó ní: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ ti ṣí etí mi, èmi, ní tèmi, kò sì ya ọlọ̀tẹ̀. Èmi kò yí padà sí òdì-kejì.” (Aísáyà 50:5) Gbogbo ìgbà ni Jésù máa ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run. Kódà, ó tilẹ̀ kúkú sọ pé: “Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe.” (Jòhánù 5:19) Kó tó di pé Jésù wá sí ayé, ó ṣeé ṣe kí ó ti fi àràádọ́ta ọ̀kẹ́, àní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọ̀kẹ́ ọdún pàápàá, bá Baba rẹ̀ ṣiṣẹ́ pọ̀. Bí ó sì ṣe wá sí ayé, ó ń bá a lọ láti tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni Jèhófà. Ẹ ò ri pé ó yẹ kí àwa ọmọlẹ́yìn Kristi, táa tilẹ̀ tún jẹ́ aláìpé, tètè sa gbogbo ipá wa láti máa ṣe ohun tí Jèhófà ń darí wa pé ká ṣe!
13. Kí ní ń bẹ níwájú fún Jésù, síbẹ̀ báwo ló ṣe fi ìgboyà hàn?
13 Àwọn kan lára àwọn tí kò tẹ́wọ́ gba Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Jèhófà yìí ṣe inúnibíni sí i, àsọtẹ́lẹ̀ sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, pé: “Ẹ̀yìn mi ni mo fi fún àwọn akọluni, mo sì fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ mi fún àwọn tí ń fa irun tu. Ojú mi ni èmi kò fi pa mọ́ fún àwọn ohun tí ń tẹ́ni lógo àti itọ́.” (Aísáyà 50:6) Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe wí, Mèsáyà yóò jìyà lọ́wọ́ àwọn alátakò rẹ̀, wọ́n á sì tẹ́ ẹ. Jésù sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ó sì mọ bí inúnibíni yìí ṣe máa tó. Síbẹ̀, bí àsìkò tí ó máa lò láyé ṣe ń tán lọ, ẹ̀rù kò bà á rárá. Ó fi ìgboyà tó lágbára bí akọ òkúta gbéra lọ sí Jerúsálẹ́mù, níbi tí wọn yóò ti gbẹ̀mí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn. Bí wọ́n ṣe ń lọ lọ́nà ibẹ̀, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwa nìyí, tí a ń tẹ̀ síwájú gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, a ó sì fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá a lẹ́bi ikú, wọn yóò sì fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, wọn yóò sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọn yóò sì tutọ́ sí i lára, wọn yóò sì nà án lọ́rẹ́, wọn yóò sì pa á, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn náà, yóò dìde.” (Máàkù 10:33, 34) Àwọn èèyàn tó sì yẹ kí òye yé jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìyẹn àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, ni wọ́n máa wà nídìí ṣíṣe tí wọ́n yóò ṣe é ṣúkaṣùka yìí.
14, 15. Báwo ni ọ̀rọ̀ Aísáyà pé wọn yóò lu Jésù pé wọn yóò sì tẹ́ ẹ ṣe ṣẹ?
14 Ní òru Nísàn 14, ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mélòó kan wà nínú ọgbà Gẹtisémánì. Ó ń gbàdúrà. Lójijì, àwọn èèyànkéèyàn kan ya lù wọ́n, wọ́n sì mú un. Ṣùgbọ́n kò bẹ̀rù rárá. Ó mọ̀ pé Jèhófà ń bẹ lẹ́yìn òun. Jésù jẹ́ kó dá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ tí jìnnìjìnnì mú lójú pé ká ní pé òun fẹ́ ni, òun ì bá ké pe Baba òun pé kí ó rán àwọn áńgẹ́lì tó ju líjíónì méjìlá wá láti wá gba òun sílẹ̀, ó wá ní: “Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ni a ó ṣe mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ lọ́nà yìí?”—Mátíù 26:36, 47, 53, 54.
15 Gbogbo ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ sọ nípa àdánwò àti ikú Mèsáyà ló ṣẹ pátá. Lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ èrú kan tí àjọ Sànhẹ́dírìn ṣe, Pọ́ńtíù Pílátù ṣàyẹ̀wò ẹjọ́ Jésù, ó sì ní kí wọ́n lu Jésù. Àwọn ọmọ ogun Róòmù tún ‘fi ọ̀pá esùsú gbá a ní orí, wọ́n sì tutọ́ sí i lára.’ Bí ọ̀rọ̀ Aísáyà ṣe ṣẹ nìyẹn. (Máàkù 14:65; 15:19; Mátíù 26:67, 68) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò mẹ́nu kàn án pé wọ́n fà lára irùngbọ̀n Jésù tu, tó jẹ́ àmì pé wọ́n kórìíra rẹ̀ dé góńgó, ó dájú pé èyí ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀.c—Nehemáyà 13:25.
16. Ní gbogbo bí wọ́n ṣe fínná mọ́ Jésù tó yìí, kí ni ìhùwàsí rẹ̀, kí sì ni ìdí tí ìtìjú ò fi bá a?
16 Nígbà tí Jésù dúró níwájú Pílátù, kò bẹ̀bẹ̀ pé kí wọ́n dá ẹ̀mí òun sí, kò tilẹ̀ janpata rárá, nítorí ó mọ̀ pé dandan ni kí òun kú kí Ìwé Mímọ́ bàa lè ṣẹ. Nígbà tí gómìnà ará Róòmù yìí wá sọ pé òun lágbára láti ní kí wọ́n pa Jésù, òun sí lágbára láti dá a sílẹ̀, Jésù fèsì láìbẹ̀rù, ó ní: “Ìwọ kì bá ní ọlá àṣẹ kankan rárá lòdì sí mi láìjẹ́ pé a ti yọ̀ǹda rẹ̀ fún ọ láti òkè wá.” (Jòhánù 19:11) Àwọn ọmọ ogun Pílátù ṣe Jésù ṣúkaṣùka lóòótọ́ o, síbẹ̀ wọn kò mú un kárí sọ. Kí lojú ì bá tì í fún ná? Kì í kúkú ṣe pé ó ṣẹ̀ tí wọ́n sì ń fi ìyà tó tọ́ sí i jẹ ẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, torí òdodo ni wọ́n ṣe ń ṣenúnibíni sí i. Lọ́nà yìí, àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ síwájú sí i ló ṣẹ, ó ní: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò ràn mí lọ́wọ́. Ìdí nìyẹn tí a kì yóò fi tẹ́ mi lógo. Ìdí nìyẹn tí mo fi gbé ojú mi ró bí akọ òkúta, mo sì mọ̀ pé ojú kì yóò tì mí.”—Aísáyà 50:7.
17. Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà dúró ti Jésù ní gbogbo àsìkò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
17 Ìgbọ́kànlé kíkún tí Jésù ní nínú Jèhófà ló ń fún un nígboyà. Ìṣarasíhùwà rẹ̀ fi hàn pé pátápátá ló fara mọ́ ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ, pé: “Ẹni tí ń polongo mi ní olódodo ń bẹ nítòsí. Ta ni ó lè bá mi fà á? Jẹ́ kí a jọ dìde dúró. Ta ni ó dojú ìjà kọ mí nínú ọ̀ràn ìdájọ́? Kí ó sún mọ́ mi. Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ tìkára rẹ̀ yóò ràn mí lọ́wọ́. Ta ni ó lè pè mí ní ẹni burúkú? Wò ó! Gbogbo wọn, bí ẹ̀wù, yóò gbó. Òólá lásán-làsàn ni yóò jẹ wọ́n tán.” (Aísáyà 50:8, 9) Lọ́jọ́ tí Jésù ṣe batisí, Jèhófà polongo pé olódodo ni, ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Àní wọ́n gbọ́ ohùn Ọlọ́run lásìkò yẹn pàápàá, tó sọ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Nígbà tó kù fẹ́fẹ́ kí ìwàláàyè Jésù lórí ilẹ̀ ayé dópin, tí ó kúnlẹ̀ àdúrà nínú ọgbà Gẹtisémánì, “áńgẹ́lì kan láti ọ̀run fara hàn án, ó sì fún un lókun.” (Lúùkù 22:41-43) Nípa bẹ́ẹ̀, Jésù mọ̀ pé Baba òun fara mọ́ ìgbésí ayé tí òun gbé. Ẹni pípé, Ọmọ Ọlọ́run yìí kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan. (1 Pétérù 2:22) Àwọn ọ̀tá rẹ̀ fẹ̀sùn èké kàn án pé ó rú òfin Sábáàtì, pé ọ̀mùtí ni, pé ó tún jẹ́ ẹlẹ́mìí èṣù, ṣùgbọ́n àwọn irọ́ wọn kò kan Jésù lábùkù kankan. Ọlọ́run kúkú ń bẹ lẹ́yìn rẹ̀, nípa bẹ́ẹ̀, ta ni yóò gbéjà kò ó?—Lúùkù 7:34; Jòhánù 5:18; 7:20; Róòmù 8:31; Hébérù 12:3.
18, 19. Irú ìrírí tó jọ ti Jésù wo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní?
18 Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Jòhánù 15:20) Kò pẹ́ kò jìnnà tọ́rọ̀ yìí fi ṣẹ. Ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn olóòótọ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, bẹ́ẹ̀ ni ìjọ Kristẹni bẹ̀rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹsẹ̀kẹsẹ̀ làwọn aṣáájú ìsìn bẹ̀rẹ̀ akitiyan láti tẹ iṣẹ́ ìwàásù àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin tí wọ́n dara pọ̀ mọ́ Jésù gẹ́gẹ́ bí ara “irú-ọmọ Ábúráhámù” tí wọ́n sì ti dẹni tí Ọlọ́run gbà ṣọmọ nípa tẹ̀mí yìí rì. (Gálátíà 3:26, 29; 4:5, 6) Látọ̀rúndún kìíní títí di ìsinsìnyí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti ń fojú winá ìgbékèéyíde àti inúnibíni kíkorò látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀tá Jésù nítorí pé wọn kò yẹhùn rárá lórí òdodo tí wọ́n dúró lé.
19 Síbẹ̀ wọ́n rántí ọ̀rọ̀ ìṣírí Jésù pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:11, 12) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kì í kárí sọ rárá bí àwọn èèyàn bá tilẹ̀ gbógun tì wọ́n lọ́nà tó le koko jù lọ. Ohun yòówù kí àwọn alátakò wọn wí, wọ́n mọ̀ pé Ọlọ́run ti polongo àwọn pé àwọn jẹ́ olódodo. Lójú tirẹ̀, wọ́n wà ní “àìlábààwọ́n àti ní àìfi àyè sílẹ̀ fún ẹ̀sùn kankan.”—Kólósè 1:21, 22.
20. (a) Ta ló ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, kí ló sì ti ṣẹlẹ̀ sí wọn? (b) Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” ṣe wá dẹni tó ní ahọ́n àwọn tí a kọ́?
20 “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” ń ṣètìlẹyìn fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lóde òní. Orí òdodo làwọn náà dúró lé. Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọn náà jọ jìyà pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró, wọ́n sì ti “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Jèhófà ti polongo wọn pé wọ́n jẹ́ olódodo, tí èyí fi fún wọn ní ìrètí pé wọn yóò la “ìpọ́njú ńlá náà” já. (Ìṣípayá 7:9, 14, 15; Jòhánù 10:16; Jákọ́bù 2:23) Àní bí àwọn alátakò wọn bá tilẹ̀ ṣe bí ẹní lágbára nísinsìnyí, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ pé bó bá tó àkókò lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àwọn alátakò wọ̀nyẹn yóò dà bí ẹ̀wù tí òólá ti jẹ tán, tó jẹ́ pé kí á kàn sọ ọ́ sí ààtàn ló kù. Ní báyìí ná, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” ń fún ara wọn lókun nípa gbígbàdúrà, kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti lílọ sí ìpàdé ìjọsìn déédéé. Ọ̀nà yẹn ni wọ́n gbà ń di ẹni tí Jèhófà kọ́, tí wọ́n sì ń mọ bí a ti ń fi ahọ́n àwọn tí a kọ́ sọ̀rọ̀.
Gbẹ́kẹ̀ Lé Orúkọ Jèhófà
21. (a) Àwọn wo ló ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀, kí ni yóò sì jẹ́ àbáyọrí rẹ̀ fún wọn? (b) Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó bá ń rìn nínú òkùnkùn?
21 Wàyí o, ẹ wá wo òdìkejì èyí: “Ta ní ń bẹ̀rù Jèhófà lára yín, tí ń fetí sí ohùn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ń rìn nínú òkùnkùn ìgbà gbogbo àti ẹni tí ìtànyòò kò sí fún? Kí ó gbẹ́kẹ̀ lé orúkọ Jèhófà, kí ó sì gbé ara rẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.” (Aísáyà 50:10) Àwọn tó ń fetí sí ohùn Jésù Kristi, Ìránṣẹ́ Ọlọ́run, a máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀. (Jòhánù 3:21) Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń lo orúkọ Ọlọ́run tí í ṣe Jèhófà, wọ́n tún gbẹ́kẹ̀ lé ẹni tó ń jẹ́ orúkọ yẹn. Àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fìgbà kan rí rìn nínú òkùnkùn, nísinsìnyí wọn kò bẹ̀rù èèyàn mọ́. Ọlọ́run ni wọ́n gbára lé. Àmọ́, ní ti àwọn tó tẹra mọ́ rírìn nínú òkùnkùn, ìbẹ̀rù èèyàn a máa gbé wọn dè. Irú nǹkan tó ṣe Pọ́ńtíù Pílátù nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó mọ̀ pé Jésù ò mọwọ́ mẹsẹ̀ nínú àwọn ẹ̀sùn èké tí wọ́n fi kàn án, ìbẹ̀rù kò jẹ́ kí ará Róòmù olóyè gíga yẹn dá Jésù sílẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Róòmù pa Ọmọ Ọlọ́run lóòótọ́ o, ṣùgbọ́n Jèhófà jí i dìde, ó sì fi ògo àti ọlá dé e ládé. Pílátù wá ńkọ́ o? Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Júù, òpìtàn náà, Flavius Josephus ṣe wí, ọdún mẹ́rin péré lẹ́yìn ikú Jésù ni wọ́n fi ẹlòmíràn rọ́pò Pílátù gẹ́gẹ́ bíi gómìnà ará Róòmù, wọ́n sì pàṣẹ pé kó padà wá Róòmù láti wá jẹ́jọ́ àwọn àṣemáṣe tó burú jáì tó ṣe. Àwọn Júù tó wá ṣekú pa Jésù ńkọ́? Kò tó ogójì ọdún sí ìgbà náà tí àwọn ọmọ ogun Róòmù fi wá pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n ṣekú pa àwọn kan lára àwọn aráàlú yẹn, wọ́n sì kó àwọn mìíràn lẹ́rú. Dípò ìmọ́lẹ̀ ayọ̀, òkùnkùn birimù-birimù ni yóò máa bá àwọn tó fẹ́ràn òkùnkùn!—Jòhánù 3:19.
22. Kí ni ìdí tó fi jẹ́ ìwà òpònú láti yíjú sí ọmọ aráyé fún ìgbàlà?
22 Ìwà òpònú gbáà ni pé kéèyàn yíjú sí ọmọ aráyé fún ìgbàlà. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣàlàyé ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ní: “Wò ó! Gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ń mú kí iná ràn, tí ẹ ń mú kí ìtapàrà mọ́lẹ̀ kedere, ẹ máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yín, àti láàárín ìtapàrà tí ẹ ti mú kí ó jó. Dájúdájú, láti ọwọ́ mi ni ẹ ó ti wá ní èyí: Nínú ìroragógó ni ẹ ó dùbúlẹ̀.” (Aísáyà 50:11) Ìgbà àwọn aṣáájú ayé kì í lọ bí òréré o. Àwọn aṣáájú tó jẹ́ olóhùn ìyọ, àsọ̀rọ̀-sọ-dídùn, lè gbayì lójú àwọn èèyàn fún ìgbà díẹ̀. Ṣùgbọ́n, ó ní ibi tí agbára èyí tó tilẹ̀ jẹ́ olóòótọ́ inú pàápàá láàárín ọmọ èèyàn mọ. Dípò ohun tí àwọn aláyẹ̀ẹ́sí rẹ̀ yóò máa retí, pé kí ọwọ́ iná àṣeyọrí rẹ̀ máa jó ròkè lálá, ó lè máa ju ìwọ̀nba “ìtapàrà” díẹ̀ tí gbogbo ìsapá rẹ̀ máa lè mú jáde, ìtapàrà tó kàn máa ràn yòò díẹ̀, tí yóò sì kú. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Ṣílò, ìyẹn Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, kì yóò rí ìjákulẹ̀ láé.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú Aísáyà orí àádọ́ta, Jèhófà ṣàpèjúwe orílẹ̀-èdè Júdà lápapọ̀ gẹ́gẹ́ bí aya òun, ó sì pe àwọn ará Júdà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ọmọ rẹ̀.
b Láti ẹsẹ kẹrin títí dé òpin orí yẹn, ó jọ pé ọ̀rọ̀ nípa ara rẹ̀ ni òǹkọ̀wé yìí ń sọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Aísáyà fojú winá àwọn kan nínú àdánwò tí ó mẹ́nu kàn nínú àwọn ẹsẹ yìí. Àmọ́, ara Jésù Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ṣẹ.
c Ẹ sì wá wò o, Aísáyà 50:6 nínú ìtumọ̀ ti Septuagint kà pé: “Mo fi ẹ̀yìn mi gba bílálà oníkókó, mo sì fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ gba ẹ̀ṣẹ́.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 155]
Àwọn Júù yíjú sí àwọn alákòóso èèyàn dípò kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 156, 157]
Jèhófà dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ létí Òkun Pupa nípa gbígbé ọwọ̀n àwọsánmà kalẹ̀ sáàárín àwọn àti àwọn ará Íjíbítì