Èdè Mímọ́gaara fun Gbogbo Awọn Orilẹ-Ede
“Nigba naa ni emi yoo fi iyipada si èdè mímọ́gaara kan fun awọn eniyan, nitori ki gbogbo wọn baa le maa kepe orukọ Jehofa, lati lè maa ṣiṣẹsin in ni ifẹgbẹkẹgbẹ.”—SEFANAYA 3:9, NW.
1, 2. (a) Ni imuṣẹ Sefanaya 3:9, ki ni Jehofa nṣe ni ọjọ wa? (b) Lati loye bi asọtẹlẹ Sefanaya ti nipa lori wa, awọn ibeere wo ni wọn nilo idahun?
JEHOFA ỌLỌRUN nṣaṣepari iṣẹ kan ti o jẹ́ agbayanu nitootọ ni ọjọ wa. Oun nso awọn eniyan lati inu gbogbo orilẹ-ede pọ̀ ṣọkan. Gẹgẹ bi oun ti sọtẹlẹ tipẹtipẹ sẹhin ninu Ọrọ rẹ Mimọ, oun nṣe bẹẹ nipa kikọ wọn ni ede titun kan.—Sefanaya 3:9.
2 Ki ni ede yẹn? Eeṣe ti o fi pọndandan? Ki ni kikẹkọọ rẹ beere lọwọ wa gẹgẹ bi ẹnikọọkan?
Ẹbun Ọrọ Sisọ
3. (a) Ẹbun yiyanilẹnu wo ni a fijinki Adamu? (b) Ede wo ni Adamu sọ?
3 Agbara lati jumọsọrọpọ nipasẹ ọrọ sisọ jẹ́ ẹbun atọrunwa kan ti o ya ẹda eniyan sọtọ kuro lara gbogbo iṣẹda ẹranko. Ẹda eniyan akọkọ, Adamu, ni a da pẹlu ero-inu ti o lagbara ironu ọlọgbọn oye. A fi agbara ifọhun, ahọn, ati ètè ti oun le lo fun ọrọ sisọ jinki rẹ̀, pẹlu awọn ọrọ ede ati agbara lati ṣẹda awọn ọrọ titun. Adamu le loye nigba ti Jehofa bá sọrọ síi, Adamu, ni ifesipada, lè sọ awọn ironu rẹ̀ jade pẹlu awọn ọrọ. (Jẹnẹsisi 1:28-30; 2:16, 17, 19-23) Lọna ti o han gbangba ede ti a fifun Adamu jẹ́ eyi ti a wa mọ̀ lẹhin naa sí Heberu. Nitori o kere tan fun 1,757 ọdun akọkọ ti iwalaaye ẹda eniyan, o han kedere pe, gbogbo araye nbaa lọ lati maa sọ ede kanṣoṣo yẹn.—Jẹnẹsisi 11:1.
4. Bawo ni awọn iṣẹlẹ ni awọn ọjọ Nimrọdu ṣe nipa lori ede ẹda eniyan?
4 Lẹhin naa, ni awọn ọjọ Nimrọdu, lati le mu isapa awọn eniyan buruku jakulẹ, Jehofa da ede awọn wọnni ti wọn yọnda araawọn fun idari lọna lilekoko lati ṣajọpin ninu kikọ ile-iṣọ ti Babeli rú. (Jẹnẹsisi 11:3-9) O farahan pe Jehofa kọkọ nu gbogbo iranti ede ajọsọ wọn akọkọ nù ó sì mú awọn ede titun wọle sinu ero inu wọn. Kii ṣe kiki awọn ọrọ ede titun nikan ni eyi ni ninu bikoṣe girama titun ati ọna ironu titun. Lati inu awọn ede ti Jehofa pilẹṣẹ ni Babeli, awọn miiran jẹ jade ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ titi di oni, gẹgẹ bi awọn ọmọwe nipa ede ti wi, nǹkan bii ẹgbẹrun mẹta ede ni a nsọ jakejado aye.
5. Bawo ni a ṣe le pinnu ohun ti “iyipada sí èdè mímọ́gaara kan” ní ninu?
5 Fun awọn eniyan ti wọn nsọ gbogbo ede wọnyi, njẹ “iyipada sí ede mimọgaara kan” yoo ha beere pe kí wọn pa ede ibilẹ wọn tì kí wọn si kẹkọọ ede ipilẹṣẹ ti Ọlọrun fifun Adamu? Awọn ipo ti o yi fifunni ni asọtẹlẹ naa ka ṣeranwọ lati dahun ibeere yẹn.
Aini fun Èdè Mímọ́gaara Kan
6-8. (a) Ipo wo nipa isin ni o ti dide ni Juda ṣaaju fifunni ni asọtẹlẹ ti Sefanaya 3:9? (b) Ninu awọn orilẹ-ede ti o yi Juda ká, ẹmi ironu wo ni o gbodekan?
6 Manase ni o kọkọ ṣakoso le Ijọba Juda lori laipẹ sẹhin, ati lẹhin naa Amoni, ẹni ti o gbe pẹpẹ Baali kalẹ, ti o ṣàmúlò iṣẹ́ wíwò, ti o si gbe awọn aṣa ìbẹ́mìílò larugẹ. (2 Ọba 21:1-6; 2 Kironika 33:21-23) Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, laaarin igba iṣakoso ọmọkunrin Amoni, Josaya ti o gbapò rẹ, Jehofa fun wolii rẹ̀ Sefanaya ni iṣẹ lati kilọ pe idajọ atọrunwa ni a o múṣẹ lori ilẹ naa.—Sefanaya 1:1, 2.
7 Bi o tilẹ jẹ pe awọn ara Judia mọ̀ lati inu itan tiwọn funraawọn ati lati inu Iwe Mimọ ti a misi pe Jehofa jẹ́ Ọlọrun otitọ, wọn nlọwọ ninu awọn ààtò isin oniwa palapala ti ijọsin Baali. Wọn foribalẹ fun oorun ati oṣupa ati awọn idipọ irawọ ti ntọ ipa ọna zodiak, eyi ti ó tẹ ofin Ọlọrun loju ni taarata. (Deuteronomi 4:19; 2 Ọba 23:5) Lékè gbogbo eyi, wọn nlọwọ ninu oriṣi amulumala igbagbọ, ni hihuwa gẹgẹ bi pe gbogbo isin rí bakan naa, nipa ṣiṣe ibura sí Jehofa ati ni orukọ ọlọrun eke Malikamu. Ẹmi ironu wọn ni pe “Oluwa [“Jehofa,” NW] ki yoo ṣe rere bẹẹ ni ki yoo ṣe buburu.” (Sefanaya 1:4-6, 12) Niti awọn orilẹ-ede tí wọn yi Juda ká, gbogbo wọn ni akọsilẹ iṣodi sí Jehofa ati awọn eniyan rẹ̀, nitori naa awọn pẹlu wà ní ila fun idajọ ododo atọrunwa tí a muwa sori wọn.—Sefanaya 2:4-15.
8 Ni ilodisi irú isọfunni ipilẹ awọn iṣẹlẹ bẹẹ ni Jehofa fi sọtẹlẹ pe oun yoo “fi iyipada sí èdè mímọ́gaara fun awọn eniyan, kí gbogbo wọn baa le maa kepe orukọ Jehofa, kí wọn baa le maa ṣiṣẹsin-in ní ifẹgbẹkẹgbẹ.” (Sefanaya 3:9, NW) Nigba naa, ki ni èdè mímọ́gaara yẹn?
9. (a) Eeṣe ti èdè mímọ́gaara naa kò fi jẹ́ ede Heberu tabi kí o wulẹ jẹ Ọrọ Olọrun ti a kọ silẹ? (b) Ki ni èdè mímọ́gaara yẹn, bawo ni o si ṣe nipa lori igbesi-aye awọn wọnni tí wọn ńsọ ọ́?
9 Ede Heberu ha ni bi? Bẹẹkọ, awọn eniyan Juda ti ni iyẹn ṣaaju akoko naa, ṣugbọn awọn nǹkan tí wọn nsọ tí wọn si nṣe lọna ti o han gbangba kò mọgaara ko si duro ṣanṣan loju Jehofa. Bẹẹ si ni èdè mímọ́gaara naa kii wulẹ ṣe Ọrọ Ọlọrun ti a kọsilẹ. Wọn ni iyẹn pẹlu. Ṣugbọn ohun tí wọn nilo ni iloye titọna ti otitọ nipa Ọlọrun ati awọn ète rẹ̀, Jehofa nikanṣoṣo ni ó sì lè pese eyiini nipasẹ ẹ̀mí rẹ̀. Nigba ti wọn ba kẹkọọ lati sọ èdè mímọ́gaara yẹn, ironu wọn, ọrọ sisọ wọn, ati iwa wọn, yoo dalori mimọ otitọ naa daju pe Jehofa ni Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa. (Sefanaya 2:3) Wọn yoo fi igbẹkẹle wọn sinu rẹ̀ wọn yoo sì fun ipo ọba-alaṣẹ rẹ̀ ni ẹkunrẹrẹ itilẹhin. Eyi jẹ́ ohun ti a ni ifẹ ọkan akanṣe sí lonii. Eeṣe?
Awọn Wọnni Ti A Fi Èdè Mímọ́gaara Fun
10. Laaarin saa akoko wo ni asọtẹlẹ Sefanaya 3:9 ṣetan lati ni imuṣẹ?
10 Ni titọkasi imuṣẹ asọtẹlẹ naa ní saa akoko kan ni pataki, Sefanaya 3:9 (NW) sọ pe: “Nitori nigba naa ni emi yoo fi iyipada sí èdè mímọ́gaara kan fun awọn eniyan.” Nigba wo niyẹn? Ẹsẹ 8 dahun pe laaarin akoko naa tí Jehofa ‘nko awọn orilẹ-ede jọpọ’ ṣaaju kí oun tó ‘tú ibinu jíjófòfò rẹ̀ sori wọn,’ ni o fun awọn ọlọkan-tutu ilẹ aye ni iyipada sí èdè mímọ́gaara kan.
11. (a) Asọtẹlẹ alapa meji wo ni Sefanaya 3:9 ni ṣaaju akoko ode oni? (b) Bawo ni imuṣẹ rẹ̀ lonii ṣe yatọ?
11 Ni awọn ọjọ Ọba Josaya, ṣaaju kí Jehofa tó yọnda awọn ọmọ ogun Babiloni lati mú idajọ ṣẹ, ọpọlọpọ pa isin eke tì, wọn sì ṣiṣẹsin Jehofa dipo rẹ. (2 Kironika 34:3-33) Lẹẹkan sii, ni ọgọrun-un ọdun kìn-ínní C.E., ṣaaju kí a to pa Jerusalẹmu run lati ọwọ awọn ara Roomu, ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan kẹkọọ otitọ nipa Ọlọrun ati ète rẹ̀ wọn sì wá wà ni iṣọkan ninu iṣẹ-isin rẹ̀. Ni akoko yẹn ede otitọ naa ni a mu sunwọn lọna giga nipa awọn ohun ti Jesu Kristi ṣe ni imuṣẹ ète Jehofa. Ṣugbọn ni ọjọ tiwa ni asọtẹlẹ Sefanaya ni imuṣẹ ní iwọn kan tí ó kari aye. Gbogbo awọn orilẹ-ede ni a nko jọ nisinsinyi sí ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare ni Amagẹdọni. (Iṣipaya 16:14, 16) Ikojọ naa ti nbaa lọ lati igba ìbí Ijọba naa ní 1914. Laaarin saa akoko kan naa yii si ni Jehofa ti nfun awọn eniyan yika aye ni iyipada naa sí èdè mímọ́gaara kan ni imuṣẹ asọtẹlẹ yii. Kíkọ́ ede yẹn ṣe pataki gidigidi nitori pe awọn olùla ipọnju nla ti nbọ já yoo jẹ́ awọn eniyan tí wọn ti sọ èdè mímọ́gaara yẹn di ede wọn nitootọ.—Joẹli 2:32.
12. (a) Isopọ wo ni iran ti a ṣakọsilẹ ní Aisaya 6 ní lori asọtẹlẹ nipa èdè mímọ́gaara kan? (b) Eeṣe tí awọn àṣẹ́kù ẹni ami-ororo fi nilo iranlọwọ bí wọn bá nilati maa baa lọ lati jẹ́ ẹni ti a tẹwọgba fun iṣẹ-isin Jehofa?
12 Ni ibamu pẹlu eyi, ní kutukutu sanmani ti o tẹle Ogun Agbaye Kìn-ínní ni Jehofa bẹrẹ sii ṣí oju òye awọn iranṣẹ rẹ̀ ẹni ami-ororo sí iran yiyanilẹnu naa ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Aisaya ori 6. (Ẹsẹ 1-4) Iran yii tẹnumọ ijẹpataki pe ki a ni ètè mimọtonitoni ki a baa lè ṣiṣẹsin Jehofa lọna tí ó ṣetẹwọgba. O fihan pe, dé iwọn giga julọ, Jehofa jẹ́ mimọ. Awọn iranṣẹ rẹ̀ gbọdọ fi animọ yẹn han pẹlu. (1 Peteru 1:15, 16) Ṣugbọn àṣẹ́kù ẹni ami-ororo nilo iranlọwọ nipa eyi. Lakooko Ogun Agbaye Kìn-ínní, de iwọn aye kan wọn ti yọnda ki lilọwọ ninu awọn àlámọ̀rí aye kó abaawọn bá wọn. “Ibẹru Jehofa mọ́gaara,” tabi mọ́ tónítóní, ṣugbọn wọn jẹ́ kí ibẹru eniyan ati ibẹru awọn eto-ajọ ẹda eniyan nipa lori ètè wọn ti o si pa ẹnu wọn mọ́ dé iwọn aye ti o lọ jinna ninu pipokiki Ọrọ Ọlọrun. (Saamu 19:9, NW) Nipasẹ ibaṣepọ pẹlu Kristẹndọm, awọn àṣẹ́kù naa ni a ṣi fi èérí bajẹ nipasẹ diẹ lara awọn aṣa atọwọdọwọ ati iṣe rẹ̀.
13, 14. (a) Bawo ni awọn àsẹ́kù ṣe fi iwa ti o tọna han, igbesẹ wo si ni Jehofa gbé nitori wọn? (b) Ni ọna wo ni Jehofa gba fun awọn àṣẹ́kù ni èdè mímọ́gaara kan?
13 Ni mimọ ipo wọn, awọn àṣẹ́kù naa sọ, gẹgẹ bi wolii Aisaya ti sọ pe: “Egbe ni fun mi, nitori mo gbé, nitori ti mo jẹ́ ẹni alaimọ ètè, mo sì wà laaarin awọn eniyan alaimọ ètè, nitori ti oju mi ti ri Ọba, Oluwa [“Jehofa,” NW] awọn ọmọ ogun!” (Aisaya 6:5) Wọn mọ̀ daju pe ipo wọn kò ṣetẹwọgba. Wọn kò fi ailera tẹpẹlẹ mọ́ ipa ọna ti kò tọ́ tabi kí wọn fi agidi kọ̀ lati tẹwọgba ibawi Jehofa. Wọn kò darapọ mọ́ awujọ alufaa nigba ti awọn wọnyi nfi ẹnu lasan ṣe itilẹhin fun Ijọba Ọlọrun ti wọn si wá fọwọsi Ìmùlẹ̀ awọn Orilẹ-ede lẹhin naa bí ẹni pe ó jẹ́ Ijọba yẹn.
14 Nitori iwa onironupiwada ti awọn àṣẹ́kù onirẹlẹ yẹn, Jehofa ninu inurere ailẹtọọsi rẹ̀ tẹsiwaju lati sọ ètè wọn di mimọ tónítóní. Aisaya 6:6, 7 sọ fun wa pe: “Nigba naa ni ọ̀kan ninu awọn Serafu fò wá sọdọ mi, o ni ẹ̀ṣẹ́ iná ní ọwọ rẹ̀, ti o ti fi ẹ̀mú mú lati ori pẹpẹ wa. O si fi kan mi ni ẹnu, o si wipe, kiyesi i, eyi ti kan ètè rẹ, a mú aiṣedeede rẹ kuro, a si fọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ nù.” Ihin iṣẹ ti nsọni di mimọ tonitoni lati inú Ọrọ Ọlọrun ni ó pa awọn àṣà-atọwọdọwọ ati awọn ẹkọ eniyan run gẹgẹ bi iná. O lé ibẹru eniyan kuro ninu ọkan wọn o si rọpo rẹ̀ pẹlu itara ajó-bí-iná lati lo awọn ètè wọn lati bọla fun Jehofa. Nipa bayii Jehofa nmu ileri rẹ̀ lati “fi iyipada si èdè mímọ́gaara kan (ní itumọ olowuuru, ètè mimọtonitoni kan) fun awọn eniyan, kí gbogbo wọn baa lè maa kepe orukọ Jehofa.”—Sefanaya 3:9, NW.
15. Bawo ni idahunpada awọn àṣẹ́kù ṣe wa ní ibamu pẹlu ìdí ti Jehofa fi fun wọn ni èdè mímọ́gaara naa?
15 Nitori naa nigba ti ẹgbẹ Aisaya ode oni bẹrẹ sii gbọ́ ohùn Jehofa ti o nbeere, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ̀ ni Aisaya 6:8 (NW) pe: “Ta ni emi yoo ran, ati ta ni yoo si lọ fun wa?” Wọn fi ayọ dahunpada pe, “emi niyii ran mi.” Kò rọrun fun gbogbo wọn lati bẹrẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ, ṣugbọn wọn nfẹ kí Ọlọrun lò wọn gẹgẹ bi eniyan fun orukọ rẹ̀. Ẹmi rẹ̀ fun wọn lokun. Iye wọn pọ̀ sii.
16. (a) Iyọrisi ti a ko fojusọna fun wo ni iwaasu awọn àṣẹ́kù mú jade? (b) Bawo ni ogunlọgọ nla ṣe funni ní ẹri pe awọn pẹlu nsọ èdè mímọ́gaara naa nisinsinyi?
16 Bi akoko ti nlọ o ṣe kedere pe iwaasu wọn nmu iyọrisi tí wọn ko fojusọna fun jade. Nipasẹ wọn, Jehofa nran awujọ miiran lọwọ lati kẹkọọ èdè mímọ́gaara naa. (Aisaya 55:5) Awọn wọnyi kò ṣajọpin ireti iye ti ọrun, ṣugbọn wọn kà á si anfaani lati jẹ́ alabaakẹgbẹ awọn àṣẹ́kù ajogun Ijọba ati lati ṣiṣẹsin ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu wọn gẹgẹ bi olupokiki Ijọba Ọlọrun. Lọna ti ntẹsiwaju, awọn wọnyi ti jade wá lati inú “gbogbo orilẹ-ede ati ẹ̀yà ati eniyan ati ede” titi ti wọn fi parapọ jẹ́ “ogunlọgọ nla” nisinsinyi tí iye wọn to araadọta ọkẹ. Ọrọ ti njade lati ẹnu wọn kii ṣe iru eyi ti yoo fi wọn han gẹgẹ bi apakan lara awọn awujọ onipinya ninu aye. Wọn ko fi ireti wọn sinu eniyan eyikeyii tabi sinu eto ajọ ẹda eniyan eyikeyii. Kaka bẹẹ, “wọn. . .kigbe ní ohun rara, wipe, igbala ni ti Ọlọrun wa ti o jokoo lori itẹ, ati ti Ọdọ-agutan.”—Iṣipaya 7:9, 10.
Ohun Ti Kikẹkọọ Ede naa Beere Fun Lọwọ Wa
17. Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati kẹkọọ èdè mímọ́gaara naa daradara ki a si sunwọn sii ninu agbara wa lati lò ó?
17 Laika bi o ṣe pẹ́ tó ti a ti wa pẹlu eto-ajọ Jehofa sí, pupọ sii ni a le ṣe lati mu imọ wa nipa èdè mímọ́gaara naa ati agbara wa lati lò ó daradara sunwọn sii. O ṣe pataki lati lo isapa naa lati ṣe iyẹn. Eeṣe? Nitori eyi nfi ifẹ wa fun otitọ han.
18, 19. (a) Gan-an lati ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀, eeṣe ti o fi ṣe pataki lati mú ifẹ lilagbara fun otitọ dagba? (b) Eeṣe ti o fi ṣe pataki lati maa baa lọ lati maa mú ifẹ yẹn dagba?
18 Ní ibẹrẹ pẹ̀pẹ̀, iru ifẹ bẹẹ nṣeranlọwọ lati ṣi ero-inu ati ọkan-aya ẹnikan silẹ debi pe oun lè loye Iwe Mimọ ti a tọka jade fun un; o ńsún un lati fà sunmọ Jehofa ati lati mọriri eto-ajọ rẹ̀. Nipa bayii, ifẹ fun otitọ ni kọkọrọ sí bíbọ́ dominira kuro ninu ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ isin eke. Awọn eniyan kan fẹnu lasan sọ pe awọn ni ifẹ si ihin iṣẹ Bibeli ṣugbọn niti gidi wọn ko tí ì fi igba kankan jọ̀wọ́ gbogbo awọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ isin eke ati ọna igbesi aye onígbọ̀jẹ̀gẹ́ rẹ̀ lọwọ. Eeṣe tí wọn ko fi ṣe bẹẹ? Gẹgẹ bi 2 Tẹsalonika 2:10 (NW) ti ṣalaye, wọn kò “tẹwọgba ifẹ fun otitọ ki a le gba wọn la.” Bawo ni o ti ṣe pataki tó pe ki a ni ifẹ yẹn!
19 Gbara ti a ba ti tẹwọgba otitọ, gbigbe ti a ngbe ifẹ yẹn ró jẹ́ koko ṣiṣe pataki ninu idagbasoke wa nipa tẹmi. Fi í sọkan pe Jehofa tọka sí otitọ naa gẹgẹ bi “èdè” kan. Nigba ti ẹnikan ba kẹkọọ èdè titun kan, oun nilati ṣe isapa alaapọn lati maa mú ọ̀rọ̀ èdè rẹ̀ pọ sii, ki o maa pe awọn ọrọ bi o ti yẹ, ki o kẹkọọ kulẹkulẹ girama ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ifẹ fun ede titun naa ati awọn eniyan tí wọn ńsọ ọ́ yoo ràn án lọwọ lati maa ni itẹsiwaju niṣo. O le ṣeeṣe fun un lati maa sọ ede naa dé iwọn aye kan ní awọn oṣu diẹ, ṣugbọn o ngba ọpọlọpọ ọdun isapa àfitọkàntọkàn ṣe kí ó tó lè maa sọ ọ́ gẹgẹ bi ọmọ ibilẹ. Iru isapa kan naa yẹn ni a beere fun bi awa yoo ba mọ èdè mímọ́gaara naa delẹdelẹ.
20. (a) Ki ni o mu ki èdè mímọ́gaara naa mọgaara nitootọ? (b) Eeṣe ti iṣọra nlanla fi jẹ́ ọranyan ní iha ọdọ gbogbo wa lẹnikọọkan?
20 O yẹ fun afiyesi ni pataki pe ede ti Ọlọrun fifun awọn iranṣẹ rẹ̀ ni a sọ pe ó jẹ́ mimọgaara. Eyi jẹ́ otitọ, kii ṣe nitori bi a ti gbé e kalẹ niti ilana ede, ṣugbọn nitori o nfunni ní ẹri ijẹmimọ tonitoni nipa tẹmi ati niti ọna iwahihu. Ninu ede yii a kò fi aaye gba irọ pipa, ẹtan, tabi ahọn agalamaṣa. Gbogbo awọn wọnni tí wọn nsọ ede yii gbọdọ maa sọ otitọ nigba gbogbo. (Sefanaya 3:13; Efesu 4:25) Ọrọ sisọ wọn gbọdọ fi ọpa idiwọn giga ti Jehofa nipa iwarere takọtabo han bakan naa. (Efesu 5:3, 4) Iwe Mimọ tun mu wa kiyesi pe ohun gbogbo ti o sopọ mọ Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye, jẹ́ alaimọ. (Iṣipaya 18:2-4) Awọn ère ọlọrun rẹ̀ ni a pe ni “awọn oriṣa ẹlẹbọtọ.” (Jeramaya 50:2, NW) Ni ọna tí ó ba a mu, nigba naa, awọn wọnni tí wọn nkẹkọọ èdè mímọ́gaara gbọdọ mú awọn ohun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ aṣeefojuri ti isin eke kuro, wọn gbọdọ ṣá awọn ẹkọ rẹ̀ tì, kí wọn já araawọn gbà kuro lọwọ awọn ayẹyẹ rẹ̀, kí wọn si mú awọn ede tí nfi ironu aimọ rẹ̀ hàn kuro ninu ọ̀rọ̀ ti wọn nsọ jade. Yatọ sí eyi, ni Iṣipaya 16:13-16, a fi tó wa leti pe kùkùfẹ̀fẹ̀ ti nko awọn orilẹ-ede jọ ni ilodisi Ijọba Ọlọrun tun jẹ́ alaimọ, eyi ti a misi nipasẹ awọn ẹmi-eṣu. Nitori naa a nilati wa lojufo lati maṣe jẹ́ kí eyikeyii ninu awọn ohun alaimọ wọnyi kó èèràn bá ọrọ sisọ wa.
21. Ki ni o tun wa pẹlu èdè mímọ́gaara naa ni afikun sí awọn ọrọ ti a nsọ?
21 Ohun ti a nkẹkọọ rẹ̀ ni a npe ni ede, ti o si ba a mu bẹẹ gẹẹ, ṣugbọn iyẹn kò tumọsi pe awọn wọnni tí nsọ ọ kan wulẹ kẹkọọ bi a ṣe le lo awọn ọrọ ti o wọpọ laaarin awọn eniyan Jehofa ni ṣakala. Ìró ohùn, irisi oju, ati ifaraṣapejuwe ṣe pataki pẹlu. Iwọnyi lè gbé awọn ihin-iṣẹ yọ eyi tí ọrọ nikan ko lè ṣe. Lemọlemọ ni wọn maa nfi ohun ti awa jẹ́ ninu niti tootọ han. Wọn le fihan yala awa ti fa owú, asọ̀, ati inúfùfù, gbogbo eyi tí o jẹ́ iṣẹ ẹran ara ti o kun fun ẹṣẹ tu tegbotegbo. Nigba ti ẹmi Ọlọrun ba nṣiṣẹ falala ninu igbesi-aye wa, awọn eso rẹ̀ yoo wá han kedere ni ọna ti a ngba ni ijumọsọrọpọ pẹlu awọn ẹlomiran.—Galatia 5:19-23; Efesu 4:31, 32.
22. Nigba ti a ba kẹkọọ èdè mímọ́gaara naa daradara, bawo ni o ṣe nipa lori ṣiṣe awọn ipinnu wa?
22 Ẹnikẹni ti o ba ti kẹkọọ ede titun kan mọ pe oun ti dé ọgangan pataki gidi kan nigba ti o ba ri araarẹ ti o nronu niti tootọ pẹlu ede titun naa gan-an, dipo ṣiṣetumọ lati inu ede ibilẹ tirẹ. Bakan naa pẹlu, nigba ti a ba kẹkọọ otitọ, ti a si ṣe isapa onifọkansi lati fi silo ninu igbesi-aye tiwa funraawa, ti a si nṣajọpin rẹ̀ deedee pẹlu awọn ẹlomiran, ni kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ a o ri araawa ti a nronu ni ọna otitọ. Awa ko ni maa fi ogbologboo wé titun ki a si maa lakaka lati ṣe yiyan ni gbogbo igba. Àní ninu awọn nǹkan keekeeke paapaa, awọn ilana Bibeli yoo wá sọkan lati pese idarisọna ti a nilo.—Owe 4:1-12.
23. Laika ohun ti ede ibilẹ wọn lè jẹ́ sí, ki ni o fihan pe gbogbo awọn Ẹlẹrii Jehofa yika aye nsọ èdè mímọ́gaara naa?
23 Otitọ ni pe ẹgbẹẹgbẹrun awọn ede ni araye nlo, ṣugbọn a lè fi gbogbo iwọnyi sọ èdè mimọgaara naa. Ni isopọṣọkan, jakejado ilẹ aye, awọn Ẹlẹrii Jehofa nlo èdè mímọ́gaara naa lọna ti o dara gẹgẹ bi wọn ti nṣiṣẹsin ni ifẹgbẹkẹgbẹ ni fifunni ni ijẹrii ti o mú ọlá wá fun Jehofa, Ọlọrun wa onifẹẹ.
Ibeere fun Atunyẹwo
◻ Ki ni ẹbun ọrọ sisọ ni ninu?
◻ Ki ni èdè mímọ́gaara naa?
◻ Sí awọn ta ni Sefanaya 3:9 ti ni imuṣẹ?
◻ Bawo ni a ṣe le fi ẹri han pe a nifẹẹ èdè mímọ́gaara naa nitootọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn wọnni ti wọn mọ èdè mímọ́gaara naa nṣajọpin rẹ̀ pẹlu awọn ẹlomiran
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Ohun yoowu ki ó jẹ́ ede ibilẹ wọn, awọn Ẹlẹrii Jehofa yika aye nsọ èdè mímọ́gaara naa