Ìránṣẹ́ Jèhófà Tí Wọ́n ‘Gún Nítorí Ìrélànàkọjá Wa’
“A gún un nítorí ìrélànàkọjá wa; a ń tẹ̀ ẹ́ rẹ́ nítorí àwọn ìṣìnà wa. . . . Nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa.”—AÍSÁ. 53:5.
1. Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nígbà tá a bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, àsọtẹ́lẹ̀ wo ni yóò sì jẹ́ ká lè máa fi í sọ́kàn?
ÌDÍ tá a fi ń pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi ni láti lè máa rántí ikú àti àjíǹde rẹ̀ àtàwọn àǹfààní tí wọ́n ṣe fún wa. Ó tún máa ń rán wa létí ìdáláre Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, bí orúkọ Jèhófà ṣe máa dèyí tá a sọ di mímọ́ àti bó ṣe máa mú àwọn ìpinnu rẹ̀ ṣẹ, títí kan ìgbàlà ọmọ aráyé. Bóyá la tún lè rí àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì tó ṣàlàyé ìrúbọ Kristi àti àǹfààní rẹ̀ bíi ti àsọtẹ́lẹ̀ inú Aísáyà 53:3-12. Ìwé Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Kristi Ìránṣẹ́ Ọlọ́run ṣe máa jìyà, ó sì sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan nípa ikú rẹ̀, àtàwọn ìbùkún tí ikú rẹ̀ máa mú wá fáwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” rẹ̀.—Jòh. 10:16.
2. Kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi hàn nípa Jèhófà, ipa wo ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn sì máa ní lórí wa?
2 Ọgọ́rùn-ún ọdún méje ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù sáyé ni Jèhófà ti mí sí Aísáyà pé kó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé Ìránṣẹ́ òun tóun yàn yóò jẹ́ olóòótọ́, àní tí wọ́n bá tiẹ̀ dán an wò dé góńgó. Èyí fi hàn pé ó dá Jèhófà lójú ṣáká pé Ọmọ òun yìí yóò dúró ṣinṣin lábẹ́ ipòkípò. Bá a ṣe ń ṣàyẹ̀wò àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ńṣe la ó túbọ̀ máa ṣọpẹ́, tí ìgbàgbọ́ wa á sì máa lágbára sí i.
Wọ́n “Tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀” Wọ́n sì “Kà Á Sí Aláìjámọ́ Nǹkan Kan”
3. Kí nìdí tó fi yẹ káwọn Júù fi tayọ̀tayọ̀ gba Jésù, àmọ́ kí ni wọ́n wá ṣe sí i dípò ìyẹn?
3 Ka Aísáyà 53:3. Nǹkan ńláǹlà ni Ọmọ Ọlọ́run yááfì o, bó ṣe fi ẹ̀gbẹ́ Baba rẹ̀ tó ti ń fi ìdùnnú ṣiṣẹ́ lọ́run sílẹ̀, tó wá sáyé láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti lè gba aráyé là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú! (Fílí. 2:5-8) Ẹbọ tó fẹ̀mí rẹ̀ rú yìí ló jẹ́ kí aráyé lè rí ojúlówó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, èyí táwọn ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú lábẹ́ Òfin Mósè ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. (Héb. 10:1-4) Nígbà náà, ṣebí àwọn èèyàn ì bá máa jó kí wọ́n sì máa yọ̀ mọ́ ọn ni nígbà tó dé sáyé, pàápàá àwọn Júù tó jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń retí Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòh. 6:14) Àmọ́ kàkà káwọn Júù ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n “tẹ́ńbẹ́lú” Kristi, tí wọ́n sì “kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan,” bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ó wá sí ilé òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tirẹ̀ kò gbà á wọlé.” (Jòh. 1:11) Àpọ́sítélì Pétérù wá sọ fáwọn Júù pé: “Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Ìránṣẹ́ rẹ̀, Jésù lógo, ẹni tí ẹ̀yin, ní tiyín, fà léni lọ́wọ́ tí ẹ sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ojú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu láti tú u sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn.”—Ìṣe 3:13, 14.
4. Báwo ni Jésù ṣe dẹni tó dojúlùmọ̀ àìsàn?
4 Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù yóò ní láti ‘di ojúlùmọ̀ àìsàn.’ Òótọ́ ni pé nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, a rí ìgbà tó rẹ̀ ẹ́, àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ṣàìsàn. (Jòh. 4:6) Àmọ́ ṣá, ó mọ bí àìsàn ṣe máa ń rí lára àwọn tó wàásù fún. Àánú wọn ṣe é, ó sì wo àwọn púpọ̀ sàn. (Máàkù 1:32-34) Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Lóòótọ́, àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé; àti pé ní ti ìrora wa, ó rù wọ́n.”—Aísá. 53:4a; Mát. 8:16, 17.
Ó Dà Bí “Ẹni Tí Ọlọ́run Kọlù”
5. Kí lèrò ọ̀pọ̀ àwọn Júù nípa irú ikú tí Jésù kú, báwo ni èyí sì ṣe fi kún ìrora rẹ̀?
5 Ka Aísáyà 53:4b. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí àwọn àti Jésù jọ gbé láyé kò mọ ìdí tó fi ní láti jìyà kó sì kú. Wọ́n gbà pé ṣe ni Ọlọ́run jẹ Jésù níyà, bíi pé ó mú kí àrùn burúkú kan máa yọ ọ́ lẹ́nu. (Mát. 27:38-44) Ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì làwọn Júù fi kan Jésù. (Máàkù 14:61-64; Jòh. 10:33) Láìsí àní-àní, Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí asọ̀rọ̀-òdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù Ìránṣẹ́ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an débi pé, èrò pé ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ni wọ́n máa fi kan òun tí wọ́n á sì tìtorí ẹ̀ pa òun ti ní láti fi kún ìrora rẹ̀. Síbẹ̀, ó fínnúfíndọ̀ gbà pé kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe.—Mát. 26:39.
6, 7. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘tẹ’ Ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ “rẹ́,” kí sì nìdí tí Ọlọ́run fi “ní inú dídùn” sí èyí?
6 A tiẹ̀ gbọ́ ti àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó sọ pé àwọn èèyàn máa ka Kristi sí “ẹni tí Ọlọ́run kọlù,” àmọ́ èwo ni ti àsọtẹ́lẹ̀ tó tún wá sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́”? (Aísá. 53:10) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà ló sọ pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi, . . . àyànfẹ́ mi, ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà,” báwo ni Jèhófà ṣe tún máa wá “ní inú dídùn sí títẹ̀ ẹ́ rẹ́”? (Aísá. 42:1) Ọ̀nà wo ni “títẹ̀ ẹ́ rẹ́” yìí gbà dùn mọ́ Jèhófà nínú?
7 Ká tó lè lóye apá yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà, a ní láti rántí pé bí Sátánì ṣe fẹ̀sùn kan Jèhófà pé kò tọ̀nà bó ṣe jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, ó tún ń dọ́gbọ́n sọ pé ìdúróṣinṣin gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé àtọ̀run kò dénú wọn. (Jóòbù 1:9-11; 2:3-5) Jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú wá fi hàn pé irọ́ gbuu ni Sátánì pa. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà yọ̀ǹda kí àwọn ọ̀tá pa Kristi, ó dájú pé ó dun Jèhófà gan-an bó ṣe ń wo Ìránṣẹ́ tó yàn yìí nígbà tí wọ́n ń pa á. Ṣùgbọ́n bí Jésù Ọmọ rẹ̀ ṣe jẹ́ olóòótọ́ pátápátá, láìkù síbì kan, dùn mọ́ Jèhófà nínú gan-an. (Òwe 27:11) Yàtọ̀ síyẹn, inú Jèhófà tún dùn gan-an nítorí pé ó mọ àǹfààní tí ikú Ọmọ òun máa ṣe fáwọn tó bá ronú pìwà dà nínú àwọn ọmọ aráyé.—Lúùkù 15:7.
Wọ́n “Gún Un Nítorí Ìrélànàkọjá Wa”
8, 9. (a) Báwo ló ṣe jẹ́ pé wọ́n ‘gún Jésù nítorí ìrélànàkọjá wa’? (b) Báwo ni Pétérù ṣe jẹ́rìí sí èyí?
8 Ka Aísáyà 53:6. Bí àgùntàn tó sọ nù ni gbogbo ìran èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe ń rìn gbéregbère kiri, tí wọ́n ń wá ọ̀nà tí wọ́n á gbà bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí wọ́n ti jogún látọ̀dọ̀ Ádámù. (1 Pét. 2:25) Níwọ̀n bí gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù sì ti jẹ́ aláìpé, kò sí èyíkéyìí lára wọn tó lè tún ohun tí Ádámù pàdánù rà pa dà. (Sm. 49:7) Ṣùgbọ́n nítorí ìfẹ́ ńlá tí “Jèhófà alára” ní, ó “mú kí ìṣìnà gbogbo wa ṣalábàápàdé ẹni yẹn,” ìyẹn Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n tó jẹ́ Ìránṣẹ́ tó yàn. Bí Kristi sì ṣe fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda kí wọ́n ‘gún òun nítorí ìrélànàkọjá wa,’ kí wọ́n sì ‘tẹ òun rẹ́ nítorí àwọn ìṣìnà wa,’ ṣe ló tipa bẹ́ẹ̀ ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí òpó igi tó sì gba ikú wa kú.
9 Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Ní ti tòótọ́, ipa ọ̀nà yìí ni a pè yín sí, nítorí Kristi pàápàá jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí. Òun tìkára rẹ̀ fi ara rẹ̀ ru àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí òpó igi, kí a lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀, kí a sì wà láàyè sí òdodo.” Lẹ́yìn náà, Pétérù wá fa ọ̀rọ̀ yọ látinú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ó ní: “Àti pé ‘nípa ìnà rẹ̀ ni a mú yín lára dá.’” (1 Pét. 2:21, 24; Aísá. 53:5) Bí ọ̀nà láti tún pa dà bá Ọlọ́run rẹ́ ṣe ṣí sílẹ̀ fáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe fi hàn síwájú sí i. Ó ní: “Kristi pàápàá kú lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ láìtún kú mọ́ láé, olódodo fún àwọn aláìṣòdodo, kí ó lè ṣamọ̀nà yín dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”—1 Pét. 3:18.
“A Ń Mú Un Bọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Àgùntàn fún Ìfikúpa”
10. (a) Kí ni Jòhánù Olùbatisí pe Jésù? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ọ̀rọ̀ tí Jòhánù sọ yẹn tọ̀nà?
10 Ka Aísáyà 53:7, 8. Nígbà tí Jòhánù Olùbatisí rí Jésù tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán, ó ní: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòh. 1:29) Nígbà tí Jòhánù pe Jésù ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà tó sọ pé: “A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa.” (Aísá. 53:7) Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú.” (Aísá. 53:12) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù dá Ìrántí Ikú Kristi sílẹ̀, ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ ní ife wáìnì kan, ó sì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Mát. 26:28.
11, 12. (a) Kí ni gbígbà tí Ísákì gbà kí Ábúráhámù fòun rúbọ ṣàpẹẹrẹ nínú ọ̀ràn ẹbọ Kristi? (b) Kí ló yẹ ká máa fi sọ́kàn nípa Ábúráhámù Gíga Jù, ìyẹn Jèhófà, nígbà tá a bá ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi?
11 Jésù ṣe bíi ti Ísákì, ó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda ká fi òun rúbọ nítorí àtiṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Jẹ́n. 22:1, 2, 9-13; Héb. 10:5-10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ísákì fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda kí Ábúráhámù fi òun rúbọ, Ábúráhámù ló dìídì fẹ́ ṣe ìrúbọ ọ̀hún. (Héb. 11:17) Bákan náà ni Jésù ṣe fínnúfíndọ̀ gbà láti kú, ṣùgbọ́n Jèhófà ló dìídì ṣètò ẹbọ ìràpadà yẹn. Ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí aráyé ló jẹ́ kó fi Ọmọ rẹ̀ rúbọ.
12 Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Nítorí náà, bó tilẹ̀ pé à ń bọlá fún Jésù nípa ṣíṣe Ìrántí Ikú Kristi, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ẹni tó dìídì ṣètò ẹbọ ìràpadà náà ni Ábúráhámù Gíga Jù, ìyẹn Jèhófà. Òun là ń fi ṣíṣe Ìrántí Ikú Kristi gbé ga.
Ìránṣẹ́ Náà “Mú Ìdúró Òdodo Wá fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”
13, 14. Báwo ni Ìránṣẹ́ Jèhófà ṣe “mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn”?
13 Ka Aísáyà 53:11, 12. Jèhófà sọ nípa Ìránṣẹ́ tó yàn pé: “Ìránṣẹ́ mi, olódodo, yóò . . . mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Ọ̀nà wo ni yóò gbà ṣe èyí? A róye ọ̀nà tó gbà ṣe é ní ìparí ẹsẹ kejìlá. Ó sọ pé Ìránṣẹ́ náà “tẹ̀ síwájú láti ṣìpẹ̀ nítorí àwọn olùrélànàkọjá.” Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù la bí gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀, ìyẹn “olùrélànàkọjá.” Nítorí náà, gbogbo wọn pátá ló ń gba “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san,” ìyẹn ikú. (Róòmù 5:12; 6:23) Ó wá pọn dandan káwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ rí ọ̀nà láti pa dà bá Jèhófà rẹ́. Ọ̀nà tó fa kíki ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó wà ní orí kẹtàléláàádọ́ta gbà ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe “ṣìpẹ̀,” tàbí bẹ̀bẹ̀, fún ìran èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó ní: “Ìnàlẹ́gba tí a pète fún àlàáfíà wa ń bẹ lára rẹ̀, àti nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa.”—Aísá. 53:5.
14 Bí Kristi ṣe ru ẹ̀ṣẹ̀ wa, tó sì gba ikú wa kú, ṣe ló “mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run rí i pé ó dára pé kí ẹ̀kún gbogbo máa gbé inú [Kristi], àti láti tún tipasẹ̀ rẹ̀ mú gbogbo ohun mìíràn padà rẹ́ pẹ̀lú ara rẹ̀ nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ tí ó ta sílẹ̀ lórí òpó igi oró, yálà wọn ì báà ṣe àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Kól. 1:19, 20.
15. (a) Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run” tí Pọ́ọ̀lù ń sọ? (b) Kìkì àwọn wo ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ nínú búrẹ́dì, kí wọ́n sì mu nínú wáìnì pupa tá a fi ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?
15 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run pè sí ọ̀run láti lọ bá Kristi jọba ni “àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run,” tí ẹ̀jẹ̀ Kristi, tó ta sílẹ̀ mú kí wọ́n pa dà bá Jèhófà rẹ́. Ọlọ́run ti polongo àwọn Kristẹni tó jẹ́ “alábàápín ìpè ti ọ̀run” yìí ní “olódodo fún ìyè.” (Héb. 3:1; Róòmù 5:1, 18) Jèhófà sì wá sọ wọ́n dọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ẹ̀mí mímọ́ ló ń bá ẹ̀mí wọn jẹ́rìí pé wọ́n jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi,” àti pé Ọlọ́run pè wọ́n láti di ọba àti àlùfáà nínú Ìjọba Kristi lọ́run. (Róòmù 8:15-17; Ìṣí. 5:9, 10) Wọ́n di Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” wọ́n sì dẹni tá a mú wọnú “májẹ̀mú tuntun.” (Jer. 31:31-34; Gál. 6:16) Nígbà tí wọ́n sì ti wà nínú májẹ̀mú tuntun, wọ́n ní ẹ̀tọ́ láti jẹ nínú búrẹ́dì, kí wọ́n sì mu nínú wáìnì pupa, tá a fi ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Wáìnì pupa tó máa ń wà nínú ife yìí ni Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ife yìí túmọ̀ sí májẹ̀mú tuntun nípa agbára ìtóye ẹ̀jẹ̀ mi, tí a óò tú jáde nítorí yín.”—Lúùkù 22:20.
16. Àwọn wo ni “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé,” ọ̀nà wo sì ni wọ́n ń gbà dẹni tí Jèhófà kà sí olódodo?
16 Àwọn àgùntàn mìíràn ti Kristi, tí wọ́n ń retí àtiwàláàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ni “àwọn ohun tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé.” Ìránṣẹ́ tí Jèhófà yàn yìí mú kí àwọn náà lè jẹ́ olódodo lójú Jèhófà. Wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ “fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi polongo wọn ní olódodo, àmọ́ kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Ńṣe ló polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ̀, tó sì wá fún wọn ní ìrètí àgbàyanu ti líla “ìpọ́njú ńlá náà” já. (Ìṣí. 7:9, 10, 14; Ják. 2:23) Àwọn àgùntàn mìíràn yìí kò sí nínú májẹ̀mú tuntun, èyí tó fi hàn pé wọn kò ní ìrètí pé wọ́n á lọ sọ́run láti lọ máa gbé, nítorí náà wọn kì í jẹ nínú búrẹ́dì, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í mu nínú wáìnì tá a fi ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ńṣe ni wọ́n máa ń wà níbi Ìrántí Ikú Kristi náà tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọ́n á máa wo ohun tó ń lọ.
Ọpẹ́ Ńlá Ni fún Jèhófà àti Ìránṣẹ́ Tó Tẹ́wọ́ Gbà Yìí!
17. Báwo ni àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ìwé Aísáyà sọ nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí ṣe jẹ́ ká lè máa múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi nínú ọkàn wa?
17 Àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ìwé Aísáyà sọ nípa Ìránṣẹ́ Ọlọ́run yìí jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà máa múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi nínú ọkàn wa. Ó ń jẹ́ ká lè “tẹjú mọ́ Olórí Aṣojú àti Aláṣepé ìgbàgbọ́ wa.” (Héb. 12:2) A ti kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run kò ya ọlọ̀tẹ̀. Kò ṣe bíi ti Sátánì. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ní inú dídùn sí bí Jèhófà ṣe ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́, nítorí ó mọ̀ dájú pé Jèhófà ni Olúwa Ọba Aláṣẹ. A tún rí i pé nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ó ní ìyọ́nú sáwọn tó ń wàásù fún, ó wo ọ̀pọ̀ lára wọn sàn, ó sì mú kí wọ́n tún lè pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. Ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ ohun tóun máa ṣe gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba nínú ètò tuntun nígbà tó bá “gbé ìdájọ́ òdodo kalẹ̀ ní ilẹ̀ ayé.” (Aísá. 42:4) Ìtara tó fi wàásù Ìjọba Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” ń rán àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ létí pé ká máa fi ìtara wàásù ìhìn rere jákèjádò ayé.—Aísá. 42:6.
18. Kí nìdí tó fi yẹ kí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà mú ká máa dúpẹ́ látọkànwá lọ́wọ́ Jèhófà àti Ìránṣẹ́ rẹ̀ tó jẹ́ olóòótọ́?
18 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tún mú kí òye wa túbọ̀ jinlẹ̀ sí i nípa ohun ńlá tó ná Jèhófà láti rán Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sí ayé pé kó wá jìyà kó sì kú fún wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Jèhófà kò dùn láti rí i pé Ọmọ òun jìyà, àmọ́ inú rẹ̀ dún láti rí i pé Jésù jẹ́ olóòótọ́ láìkù síbì kan, àní títí dójú ikú. Ó yẹ kí inú àwa náà máa dùn bíi ti Jèhófà, ká mọrírì gbogbo ohun tí Jésù ṣe láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì, ká sì tún mọrírì ohun tó ṣe láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó hàn gbangba pé ó tọ́ bí Jèhófà ṣe jẹ́ Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Yàtọ̀ síyẹn, Kristi ru ẹ̀ṣẹ̀ wa ó sì gba ikú wa kú. Ó wá tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ṣeé ṣe fún agbo kékeré ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn láti dẹni tí Jèhófà lè kà sí olódodo. Nítorí náà, nígbà tá a bá pé jọ láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, ẹ jẹ́ ká máa dúpẹ́ látọkànwá lọ́wọ́ Jèhófà àti Ìránṣẹ́ rẹ̀ yìí tó jẹ́ olóòótọ́.
Àtúnyẹ̀wò
• Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘ní inú dídùn sí títẹ Ọmọ rẹ̀ rẹ́’?
• Báwo ló ṣe jẹ́ pé wọ́n ‘gún Jésù nítorí ìrélànàkọjá wa’?
• Báwo ni Ìránṣẹ́ náà ṣe “mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn”?
• Ọ̀nà wo ni àgbéyẹ̀wò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìránṣẹ́ náà gbà mú kó o máa múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi nínú ọkàn rẹ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Wọ́n “tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀, àwa sì kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
“Ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn “àgùntàn mìíràn” máa ń wà níbi Ìrántí Ikú Kristi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọ́n á máa wo ohun tó ń lọ