ORÍ 2
Mọyì Ipa Tí Kristi Ń Kó Nínú Ìṣètò Ọlọ́run
“NÍ ÌBẸ̀RẸ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé,” gbogbo nǹkan tó dá sì “dára gan-an.” (Jẹ́n. 1:1, 31) Jèhófà dá àwa èèyàn, ó sì fẹ́ ká máa gbádùn ara wa títí láé. Àmọ́ ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì ò jẹ́ kí ayọ̀ yẹn tọ́jọ́. Síbẹ̀, ohun tí Jèhófà fẹ́ fún àwa èèyàn àti ayé yìí kò yí pa dà. Ọlọ́run sọ pé òun máa dá àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù tó bá jẹ́ onígbọràn nídè. Ìyẹn nìkan kọ́, Ọlọ́run á tún mú ìjọsìn tòótọ́ pa dà bọ̀ sípò, á sì pa ẹni ibi náà àti gbogbo iṣẹ́ ibi rẹ̀ run. (Jẹ́n. 3:15) Ohun gbogbo á tún wá “dára gan-an.” Jèhófà máa lo Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, láti ṣe àwọn nǹkan yìí. (1 Jòh. 3:8) Torí náà, ó yẹ ká mọyì ipa tí Kristi ń kó nínú ìṣètò Ọlọ́run.—Ìṣe 4:12; Fílí. 2:9, 11.
IPA TÍ KRISTI Ń KÓ
2 Onírúurú ipa ni Kristi ń kó nínú ìṣètò Ọlọ́run. Òun ni Olùràpadà aráyé, Àlùfáà Àgbà àti Orí ìjọ Kristẹni, kódà ní báyìí, ó ti di Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ipa tí Kristi ń kó yìí, àá túbọ̀ mọyì ètò Ọlọ́run, ìfẹ́ tá a ní sí Kristi Jésù á sì jinlẹ̀ sí i. Bíbélì ṣàlàyé àwọn kan lára onírúurú ipa tí Jésù ń kó.
Jésù ni ẹni tí Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé ṣẹ
3 Nígbà tí Jésù Kristi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, ó ṣe kedere pé òun ni Ọlọ́run máa lò láti mú káwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn pa dà bá Ọlọ́run rẹ́. (Jòh. 14:6) Torí pé Jésù ni Olùràpadà aráyé, ó fi ara rẹ̀ ṣe ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn. (Mát. 20:28) Jésù fi àpẹẹrẹ tó dáa lẹ́lẹ̀ tó bá di pé ká hùwà tó bá ìlànà Ọlọ́run mu. Àmọ́ láfikún síyẹn, Jésù ni ẹni tí Jèhófà ń lò láti mú ìfẹ́ rẹ̀ fún aráyé ṣẹ. Kódà, ipasẹ̀ rẹ̀ nìkan ṣoṣo la fi lè pa dà rí ojúure Ọlọ́run. (Ìṣe 5:31; 2 Kọ́r. 5:18, 19) Ikú ìrúbọ Jésù àti àjíǹde rẹ̀ ti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láti gbádùn ìbùkún ayérayé nínú Ìjọba Ọlọ́run.
4 Torí pé Jésù ni Àlùfáà Àgbà, ó ṣeé ṣe fún un láti “bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa” kó sì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó ti yara wọn sí mímọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Àlùfáà àgbà tí a ní kì í ṣe ẹni tí kò lè bá wa kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa, àmọ́ ó jẹ́ ẹni tí a ti dán wò ní gbogbo ọ̀nà bíi tiwa, àmọ́ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀.” Lẹ́yìn náà ni Pọ́ọ̀lù wá gba gbogbo àwọn tó nígbàgbọ́ nínú Jésù Kristi níyànjú pé kí wọ́n rí i dájú pé àwọn tẹ̀ lé ètò tí Ọlọ́run ṣe ká lè pa dà bá a rẹ́, ó ní: “Torí náà, ẹ jẹ́ ká sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, ká sọ̀rọ̀ ní fàlàlà, ká lè rí àánú gbà, ká sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó máa ràn wá lọ́wọ́ ní àkókò tó tọ́.”—Héb. 4:14-16; 1 Jòh. 2:2.
5 Jésù tún ni Orí ìjọ Kristẹni. Bíi tàwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, àwa náà ò nílò aṣáájú tó jẹ́ èèyàn. Jésù ń lo ẹ̀mí mímọ́ àtàwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n wà lábẹ́ ìdarí rẹ̀ láti tọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sọ́nà, àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí sì máa jíhìn fún òun àti Bàbá rẹ̀ ọ̀run nípa bí wọ́n ṣe bójú tó agbo Ọlọ́run. (Héb. 13:17; 1 Pét. 5:2, 3) Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jésù pé: “Wò ó! Mo fi ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn orílẹ̀-èdè, aṣáájú àti aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè.” (Àìsá. 55:4) Jésù jẹ́rìí sí i pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ sí òun lára nígbà tó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Kí wọ́n má sì pè yín ní aṣáájú, torí Aṣáájú kan lẹ ní, Kristi.”—Mát. 23:10.
6 Jésù jẹ́ ká mọ bí òun ṣe ń ronú àti pé òun ṣe tán láti ràn wá lọ́wọ́ nígbà tó sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tó ń ṣe làálàá, tí a di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, màá sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, torí oníwà tútù àti ẹni tó rẹlẹ̀ ní ọkàn ni mí, ara sì máa tù yín. Torí àjàgà mi rọrùn, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Bí Jésù Kristi ṣe ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bójú tó ìjọ tó sì ń tù wá lára, ó fi hàn pé Jésù jẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà” bíi ti Bàbá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run.—Jòh. 10:11; Àìsá. 40:11.
7 Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó ṣàlàyé apá mìíràn nínú ipa tí Jésù Kristi ń kó, ó sọ pé: “Torí ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ọba tí á máa ṣàkóso títí Ọlọ́run á fi fi gbogbo àwọn ọ̀tá sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, ìgbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ á fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún kálukú.” (1 Kọ́r. 15:25, 28) Kí Jésù tó wá sáyé, òun ni “àgbà òṣìṣẹ́” Ọlọ́run torí pé òun ni Jèhófà kọ́kọ́ dá. (Òwe 8:22-31) Ìfẹ́ Ọlọ́run ni Jésù ṣe jálẹ̀ gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀. Ó fara da àdánwò tó ga jù lọ, ó sì jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ títí tó fi kú. (Jòh. 4:34; 15:10) Torí pé Jésù jẹ́ adúróṣinṣin títí tó fi kú, Ọlọ́run jí i dìde sókè ọ̀run, ó sì fún un ní ẹ̀tọ́ láti di Ọba Ìjọba ọ̀run. (Ìṣe 2:32-36) Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta lé Kristi Jésù lọ́wọ́ pé kó ṣáájú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn áńgẹ́lì alágbára láti mú àkóso ẹ̀dá èèyàn kúrò, kó sì mú gbogbo ìwà ibi kúrò láyé. (Òwe 2:21, 22; 2 Tẹs. 1:6-9; Ìfi. 19:11-21; 20:1-3) Lẹ́yìn náà, Ìjọba Ọlọ́run tí Kristi ń darí ni ìjọba kan ṣoṣo táá máa ṣàkóso gbogbo ayé pátá.—Ìfi. 11:15.
OHUN TÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MỌYÌ IPA TÍ KRISTI Ń KÓ
8 Ẹni pípé ni Jésù Kristi tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa. Ọlọ́run ti yàn án pé kó máa bójú tó wa. Ká tó lè jàǹfààní látọ̀dọ̀ Jésù tó ń fi ìfẹ́ bójú tó wa, a gbọ́dọ̀ jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà ká sì máa bá ètò rẹ̀ tó ń tẹ̀ síwájú rìn.
9 Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní mọyì ipa tí Kristi kó nínú ìṣètò Ọlọ́run. Wọ́n fi èyí hàn bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan lábẹ́ Kristi tó jẹ́ aṣáájú wọn, wọ́n ń tẹ̀ lé ìtọ́ni Kristi bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń darí wọn. (Ìṣe 15:12-21) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan tó wà láàárín ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nígbà tó kọ̀wé pé: “Nípa sísọ òótọ́, ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú ká dàgbà sókè nínú ohun gbogbo sínú ẹni tó jẹ́ orí, ìyẹn Kristi. Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ara ti para pọ̀ di ọ̀kan, tí a sì mú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tó ń pèsè ohun tí a nílò. Tí ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, èyí á mú kí ara máa dàgbà sí i bó ṣe ń gbé ara rẹ̀ ró nínú ìfẹ́.”—Éfé. 4:15, 16.
10 Tí àwọn tó wà nínú ìjọ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀, tí gbogbo wọn sì ń ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan lábẹ́ ìdarí Kristi, ìjọ á máa gbèrú, ìfẹ́ tó jẹ́ “ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé” á sì gbilẹ̀.—Jòh. 10:16; Kól. 3:14; 1 Kọ́r. 12:14-26.
11 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ń ṣẹ ti jẹ́ ká rí i kedere pé láti ọdún 1914 ni Ọlọ́run ti gbé Ìjọba lé Jésù Kristi lọ́wọ́. Ní báyìí, ó ń ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Sm. 2:1-12; 110:1, 2) Kí lèyí túmọ̀ sí fáwọn èèyàn tó ń gbé láyé báyìí? Ó túmọ̀ sí pé Jésù máa tó fi hàn pé òun ni Ọba àwọn ọba àti Olúwa àwọn olúwa nígbà tó bá mú ìdájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Ìfi. 11:15; 12:10; 19:16) Ìgbà yẹn ni ìlérí tí Jèhófà ṣe nígbà tí aráyé ṣọ̀tẹ̀ máa ṣẹ, ó máa dá àwon tó wà lọ́wọ́ ọ̀tún Kristi nídè, ìyẹn àwọn tó rí ojúure rẹ̀. (Mát. 25:34) Inú wa mà dùn o pé a mọyì ipa tí Kristi ń kó nínú ìṣètò Ọlọ́run! Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa wà ní ìṣọ̀kan ká lè ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà kárí ayé, bí Kristi ṣe ń darí wa láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.