Orí Kẹrìndínlógún
Ọ̀rọ̀ Ìrètí fún Àwọn Ìgbèkùn Tí Ìrẹ̀wẹ̀sì Ọkàn Bá
1. Ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe rí fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì.
ÌGBÀ tí à ń wí yìí jẹ́ ìgbà tí nǹkan dojú rú gbáà nínú ìtàn Júdà. Bábílónì kó àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú kúrò ní ìlú ìbílẹ̀ wọn tipátipá, wọ́n wá dẹni tó ń ráre nígbèkùn ní Bábílónì. Òótọ́ ni pé wọ́n fún wọn lómìnira dé ìwọ̀n àyè kan láti lo ìgbésí ayé wọn bó ṣe wù wọ́n. (Jeremáyà 29:4-7) Tí àwọn kan di oníṣẹ́ ọwọ́ pàtàkì, tí àwọn mìíràn sì di oníṣòwò.a (Nehemáyà 3:8, 31, 32) Síbẹ̀síbẹ̀, nǹkan ò fararọ fún àwọn Júù tó jẹ́ ìgbèkùn. Ńṣe ni wọ́n wà nígbèkùn nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Ẹ jẹ́ ká wo bí ọ̀ràn náà ṣe rí bẹ́ẹ̀.
2, 3. Ipa wo ni wíwà tí àwọn Júù wà nígbèkùn ní lórí ìjọsìn wọn sí Jèhófà?
2 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, jàǹbá tí wọ́n ṣe ta yọ wíwulẹ̀ pa ìlú kan run; wọ́n kọlu ìsìn tòótọ́ pẹ̀lú. Wọ́n kó gbogbo nǹkan inú tẹ́ńpìlì Jèhófà lọ, wọ́n sì wó tẹ́ńpìlì ọ̀hún, wọ́n mú kí ètò iṣẹ́ àlùfáà dẹnu kọlẹ̀ nípa kíkó tí wọ́n kó àwọn kan lára ìdílé Léfì lẹ́rú, wọ́n sì pa àwọn mìíràn. Nígbà tí kò sì ti sí ilé ìjọsìn, tí kò sí pẹpẹ, tí kò sì sí ètò iṣẹ́ àlùfáà, kò ṣeé ṣe fún àwọn Júù láti rúbọ sí Ọlọ́run tòótọ́ bí Òfin ṣe là á lẹ́sẹẹsẹ.
3 Àmọ́ o, àwọn Júù tó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ ṣì lè fi hàn pé àwọn kò jáwọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn nípa dídá adọ̀dọ́ wọn, kí wọ́n sì máa pa ohun tí Òfin wí mọ́ bó bá ti ṣeé ṣe tó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè yàgò fún àwọn oúnjẹ tí Òfin kà léèwọ̀, kí wọ́n sì máa pa Sábáàtì mọ́. Ṣùgbọ́n bí wọ́n ṣe ń ṣe ìyẹn, àwọn tó kó wọn nígbèkùn á máa fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, nítorí ìwà òmùgọ̀ làwọn ará Bábílónì ka àwọn ààtò ìsìn tí àwọn Júù ń tẹ̀ lé sí. Ìbànújẹ́ tó bá àwọn Júù hàn látinú ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà sọ, pé: “Lẹ́bàá àwọn odò Bábílónì—ibẹ̀ ni a jókòó. Àwa sì sunkún nígbà tí a rántí Síónì. Orí àwọn igi pọ́pílà tí ń bẹ ní àárín rẹ̀ ni a gbé àwọn háàpù wa kọ́. Nítorí pé níbẹ̀, àwọn tí ó mú wa ní òǹdè béèrè àwọn ọ̀rọ̀ orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ń fi wá ṣe ẹlẹ́yà—wọ́n béèrè fún ayọ̀ yíyọ̀ pé: ‘Ẹ kọ ọ̀kan lára àwọn orin Síónì fún wa.’”—Sáàmù 137:1-3.
4. Kí nìdí tí yóò fi já sí asán bí àwọn Júù bá yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù fún ìdáǹdè, àmọ́ ta ni wọ́n lè yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?
4 Ta wá ni kí àwọn Júù tó wà nígbèkùn yíjú sí fún ìtùnú? Ibo ni ìgbàlà yóò ti wá fún wọn? Ó dájú pé kò lè wá láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká láé! Apá èyíkéyìí nínú wọn kò ká agbo ọmọ ogun Bábílónì, àti pé ọ̀pọ̀ lára wọn kò fojúure wo àwọn Júù. Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn wọ́n bà ni, kò tíì bà jẹ́. Jèhófà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí nígbà tí wọ́n ṣì wà lómìnira ara wọn, fi oore ọ̀fẹ́ pè wọ́n mọ́ra, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì wà nígbèkùn.
“Ẹ Wá Síbi Omi”
5. Kí ni ìpè náà pé, “ẹ wá síbi omi” túmọ̀ sí?
5 Jèhófà gbẹnu Aísáyà bá àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì sọ̀rọ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Kére o, gbogbo ẹ̀yin tí òùngbẹ ń gbẹ! Ẹ wá síbi omi. Àti ẹ̀yin tí kò ní owó! Ẹ wá, ẹ rà, kí ẹ sì jẹ. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ wá, ẹ ra wáìnì àti wàrà, àní láìsí owó àti láìsí ìdíyelé.” (Aísáyà 55:1) Àkàwé pọ̀ nínú ọ̀rọ̀ yìí gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, wo ìpè náà pé: “Ẹ wá síbi omi.” Láìsí omi, kò sóhun tó lè wà láàyè. Láìsí omi tó ṣeyebíye yìí, àwa èèyàn ò lè wà láàyè ju nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan péré lọ. Nípa bẹ́ẹ̀, ó bá a mu gan-an bí Jèhófà ṣe lo omi lọ́nà àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ láti fi ṣàkàwé ipa tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ní lórí àwọn Júù tó wà nígbèkùn. Ńṣe ni iṣẹ́ tó rán sí wọn yóò tù wọ́n lára, bí ẹní mu omi tútù lọ́jọ́ tí oòrùn mú janjan. Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìpòrúùru ọkàn, á sì pa òùngbẹ òtítọ́ àti òdodo tó ń gbẹ wọ́n. Yóò sì jẹ́ kí wọ́n nírètí pé àwọn yóò bọ́ nígbèkùn. Àmọ́ o, àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní láti mu nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán sí wọn, kí wọ́n fiyè sí ohun tó wí, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ lé e lórí, kí ó tó lè ṣe wọ́n láǹfààní.
6. Báwo ni àwọn Júù yóò ṣe jàǹfààní bí wọ́n bá ra “wáìnì àti wàrà”?
6 Jèhófà tún pèsè “wáìnì àti wàrà.” Wàrà a máa mú ara ìkókó le pọ́nkí, ó sì ń mú kí ọmọdé dàgbà. Bákan náà, ọ̀rọ̀ Jèhófà yóò fún àwọn èèyàn rẹ̀ lókun nípa tẹ̀mí, yóò sì jẹ́ kí wọ́n lè mú kí àjọṣe àwọn àti Jèhófà túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ sí i. Wáìnì wá ńkọ́ o? Nígbà àjọyọ̀, wọ́n sábà máa ń lo wáìnì. Aásìkí àti ayọ̀ yíyọ̀ ni wọ́n so ó pọ̀ mọ́ nínú Bíbélì. (Sáàmù 104:15) Bí Jèhófà ṣe wá sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n “ra wáìnì” ńṣe ló ń mú un dá wọn lójú pé bí wọ́n bá fi gbogbo ọkàn padà sínú ìjọsìn tòótọ́, ìyẹn á mú kí wọ́n “kún fún ìdùnnú.”—Diutarónómì 16:15; Sáàmù 19:8; Òwe 10:22.
7. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìyọ́nú tó kàmàmà ni Jèhófà fi hàn sí àwọn ìgbèkùn wọ̀nyẹn, kí ni ìyẹn sì kọ́ wa nípa irú ẹni tó jẹ́?
7 Áà, Jèhófà mà ṣàánú àwọn Júù tó wà nígbèkùn o tó fi sọ ọ̀rọ̀ tó ń tuni lára nípa tẹ̀mí yìí fún wọn! Ìyọ́nú rẹ̀ tún wá kàmàmà bí a bá rántí ìtàn bí àwọn Júù ṣe ti hùwàkiwà tí wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀. Wọn kò yẹ lẹ́ni tí Jèhófà ń ṣojú rere sí rárá o. Àmọ́, onísáàmù náà Dáfídì ti kọ̀wé ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Òun kì yóò máa wá àléébù ṣáá nígbà gbogbo, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò máa fìbínú hàn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Sáàmù 103:8, 9) Jèhófà kò kẹ̀yìn sí àwọn èèyàn rẹ̀ rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀, òun ló kọ́kọ́ ṣe ohun tí yóò mú kí àwọn méjèèjì tún padà dọ̀rẹ́. Ọlọ́run tí “ó ní inú dídùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́” ni lóòótọ́.—Míkà 7:18.
Wọ́n Gbẹ́kẹ̀ Lé Ẹni Tí Kò Yẹ
8. Ta ni ọ̀pọ̀ àwọn Júù gbẹ́kẹ̀ lé, ìkìlọ̀ wo ni wọ́n sì ṣàìkà sí?
8 Títí dìgbà tí à ń wí yìí, àwọn Júù kò tíì fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún ìgbàlà. Bí àpẹẹrẹ, kí Jerúsálẹ́mù tó ṣubú, àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ni àwọn ọba rẹ̀ lọ ń yíjú sí fún ìtìlẹyìn, wọ́n kúkú lọ ń fi ara wọn ṣe iṣẹ́ kárùwà fún Íjíbítì àti fún Bábílónì ni ká wí. (Ìsíkíẹ́lì 16:26-29; 23:14) Ìyẹn ló fi tọ́ bí Jeremáyà ṣe kìlọ̀ fún wọn pé: “Ègún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ará ayé, tí ó sì wá fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀, tí ọkàn-àyà rẹ̀ sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” (Jeremáyà 17:5) Bẹ́ẹ̀, ìyẹn gan-an làwọn èèyàn Ọlọ́run sì ṣe o!
9. Báwo ló ṣe lè jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn Júù “ń san owó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ”?
9 Wọ́n di ẹrú ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé wàyí. Ṣé wọ́n sì fi ìyẹn ṣàríkọ́gbọ́n? Ó jọ pé ọ̀pọ̀ lára wọn kò fi kọ́gbọ́n, nítorí Jèhófà ṣì tún béèrè pé: “Èé ṣe tí ẹ fi ń san owó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ, èé sì ti ṣe tí làálàá yín jẹ́ fún ohun tí kì í yọrí sí ìtẹ́lọ́rùn?” (Aísáyà 55:2a) Bí àwọn Júù tó wà nígbèkùn bá lọ ń gbẹ́kẹ̀ lé ẹnì kan yàtọ̀ sí Jèhófà, a jẹ́ pé wọ́n “ń san owó fún ohun tí kì í ṣe oúnjẹ” nìyẹn. Ó dájú pé wọn kò ní lè rí ìdáǹdè gbà kúrò lọ́wọ́ Bábílónì, nítorí òfin wọn ni pé àwọn ìgbèkùn kì í padà sílé rárá. Ní tòdodo, Bábílónì, tòun tí ètò ìjọba rẹ̀, ètò ìṣòwò rẹ̀, àti ìsìn èké rẹ̀ kò lè ṣe àwọn Júù tó wà nígbèkùn láǹfààní kankan o.
10. (a) Báwo ni Jèhófà yóò ṣe san èrè fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn bí wọ́n bá fetí sí i? (b) Májẹ̀mú wo ni Jèhófà bá Dáfídì dá?
10 Jèhófà rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ẹ fetí sí mi dáadáa, kí ẹ sì máa jẹ ohun tí ó dára, kí ọkàn yín sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀rá. Ẹ dẹ etí sílẹ̀, kí ẹ sì wá sọ́dọ̀ mi. Ẹ fetí sílẹ̀, ọkàn yín yóò sì máa wà láàyè nìṣó, pẹ̀lú ìmúratán sì ni èmi yóò bá yín dá májẹ̀mú tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ti àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì, àwọn èyí tí ó ṣeé gbíyè lé.” (Aísáyà 55:2b, 3) Ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún àwọn tí kò rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ nípa tẹ̀mí yìí ni Jèhófà, òun ló sì ń gbẹnu Aísáyà bá wọn sọ̀rọ̀ lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀ nísinsìnyí. Àní ìwàláàyè wọn sinmi lórí fífetí sílẹ̀ sí ìsọfúnni Ọlọ́run, nítorí ó sọ pé bí wọ́n bá fetí sílẹ̀, ‘ọkàn wọn yóò máa wà láàyè nìṣó.’ Kí wá ni “májẹ̀mú tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” tí Jèhófà yóò bá àwọn tó bá fetí sí i dá? Májẹ̀mú yẹn jẹ́ “ní ti àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì.” Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú, Jèhófà ṣèlérí fún Dáfídì pé ìtẹ́ rẹ̀ yóò di èyí tí a “fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (2 Sámúẹ́lì 7:16) Nípa bẹ́ẹ̀, “májẹ̀mú tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin” tí ibí yìí ń mẹ́nu kàn jẹ mọ́ ọ̀ràn ìṣàkóso.
Ajogún Tí Ìjọba Àìnípẹ̀kun Yóò Jẹ́ Tirẹ̀ Títí Láé
11. Kí nìdí tí ìmúṣẹ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún Dáfídì fi lè máà wá sí ọkàn àwọn ìgbèkùn ní Bábílónì rárá?
11 Lóòótọ́ o, ọ̀ràn nípa ìṣàkóso láti ìlà ìdílé Dáfídì tilẹ̀ lè máà wá sí ọkàn àwọn Júù tó wà nígbèkùn rárá. Wọ́n ti pàdánù ilẹ̀ wọ́n, wọ́n sì tún pàdánù ẹ̀rí pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀-èdè kan pàápàá! Àmọ́ fúngbà díẹ̀ ni. Jèhófà kò gbàgbé májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá. Bó ti wù kó dà bí ohun tí kò lè ṣeé ṣe tó lójú ọmọ aráyé, ète Ọlọ́run nípa Ìjọba tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ìlà ìdílé Dáfídì yóò ṣàṣeyọrí. Ṣùgbọ́n báwo ní yóò ṣe wáyé, ìgbà wo sì ni? Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, Jèhófà dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì, ó sì dá wọn padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ǹjẹ́ èyí wá yọrí sí fífi ìdí ìjọba tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin múlẹ̀ bí? Rárá o, ńṣe ni wọ́n di ọmọ abẹ́ ìjọba kèfèrí mìíràn, ìyẹn ti Mídíà òun Páṣíà. Ìdí ni pé “àwọn àkókò tí a yàn kalẹ̀” fún àwọn orílẹ̀-èdè láti fi ṣèjọba wọn kò tíì dópin. (Lúùkù 21:24) Nígbà tí kò sì ti sí ọba ní Ísírẹ́lì, ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Dáfídì yóò ṣì wà láìṣẹ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sí i.
12. Ìgbésẹ̀ wo ni Jèhófà gbé láti mú májẹ̀mú Ìjọba tó bá Dáfídì dá ṣẹ?
12 Ní ohun tó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún lẹ́yìn tí Ísírẹ́lì gba ìdáǹdè kúrò nígbèkùn Bábílónì, Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì kan láti lè mú májẹ̀mú Ìjọba tí ó dá ṣẹ nígbà tó ta àtaré ìwàláàyè àkọ́bí Ọmọ rẹ̀, tí ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá rẹ̀, látinú ògo ti ọ̀run wá sínú ilé ọlẹ̀ Màríà wúńdíá, ọmọbìnrin Júù kan. (Kólósè 1:15-17) Nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà ń kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, ó sọ fún Màríà pé: “Ẹni yìí yóò jẹ́ ẹni ńlá, a ó sì máa pè é ní Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ; Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Nípa bẹ́ẹ̀, ìlà ìdílé Dáfídì Ọba ni wọ́n bí Jésù sí, ó sì jẹ́ ẹni tí ipò ọba tọ́ sí. Bí Jésù bá sì ti wá jọba wàyí, yóò máa ṣàkóso lọ ni “títí dé àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 9:7; Dáníẹ́lì 7:14) Báyìí ni ọ̀nà là fún ìmúṣẹ ìlérí tí Jèhófà ti ṣe láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá pé òun yóò fún Dáfídì Ọba ní ajogún kan tí yóò jogún ìtẹ́ rẹ̀ títí láé.
“Aláṣẹ fún Àwọn Àwùjọ Orílẹ̀-Èdè”
13. Báwo ni Jésù ṣe jẹ́ ‘ẹlẹ́rìí fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè’ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ àti lẹ́yìn tó gòkè re ọ̀run pàápàá?
13 Kí ni ọba ọjọ́ iwájú yìí yóò ṣe? Jèhófà sọ pé: “Wò ó! Mo ti fi í fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí, gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àti aláṣẹ fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 55:4) Nígbà tí Jésù dàgbà tán, ó jẹ́ aṣojú Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé, ẹlẹ́rìí Ọlọ́run fún àwọn orílẹ̀-èdè. Lásìkò tí Jésù fi wà ní ayé, “àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n sọnù” ló dárí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ sí. Àmọ́, kété ṣáájú kí Jésù tó gòkè re ọ̀run, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn . . . Wò ó! mo wà pẹ̀lú yín ní gbogbo àwọn ọjọ́ títí dé ìparí ètò àwọn nǹkan.” (Mátíù 10:5, 6; 15:24; 28:19, 20) Nípa báyìí, láìpẹ́, iṣẹ́ Ìjọba yìí di èyí tó dé ọ̀dọ̀ àwọn tí kì í ṣe Júù, àwọn kan lára wọn sì kópa nínú ìmúṣẹ májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. (Ìṣe 13:46) Lọ́nà yìí, Jésù ń bá a lọ láti jẹ́ ‘ẹlẹ́rìí Jèhófà fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè’ kódà lẹ́yìn ikú, àjíǹde, àti ìgòkè re ọ̀run rẹ̀.
14, 15. (a) Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé òun jẹ́ “aṣáájú àti aláṣẹ”? (b) Kí ni àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti ọ̀rúndún kìíní ń retí láti dà?
14 Jésù yóò sì tún jẹ́ “aṣáájú àti aláṣẹ.” Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe wí lóòótọ́, nígbà tí Jésù fi wà lórí ilẹ̀ ayé, ó gbà láti ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí délẹ̀délẹ̀, ó sì mú ipò iwájú ní gbogbo ọ̀nà, ó wá di ẹni tí àwùjọ ńlá ń wọ́ tọ̀, òun náà sì ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ òtítọ́, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n rí àǹfààní tí àwọn tó bá tẹ̀ lé òun gẹ́gẹ́ bí aṣáájú wọn yóò rí gbà. (Mátíù 4:24; 7:28, 29; 11:5) Ó dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó yé wọn, ó fi ìyẹn múra wọn sílẹ̀ fún iṣẹ́ ìwàásù káàkiri tí wọ́n máa tó dáwọ́ lé. (Lúùkù 10:1-12; Ìṣe 1:8; Kólósè 1:23) Láàárín ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀ péré, Jésù ti fìdí ìjọ oníṣọ̀kan lọ́lẹ̀, ìjọ tí yóò kárí ayé, tí yóò sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọmọ ìjọ látinú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀yà! Àfi “aṣáájú àti aláṣẹ” tòótọ́ nìkan ló lè gbé irú iṣẹ́ bàǹtàbanta yẹn ṣe.b
15 A fi ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run yan àwọn tí wọ́n kó jọ pọ̀ sínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n sì dẹni tó ń retí láti di alájùmọ̀ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní Ìjọba ọ̀run. (Ìṣípayá 14:1) Ṣùgbọ́n ìgbà tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń wí ré kọjá ìgbà àwọn Kristẹni ti àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù Kristi kò bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run títí di ọdún 1914. Láìpẹ́ sí ìgbà yẹn, àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn sì fi onírúurú ọ̀nà jọ irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Kódà, ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn tún jẹ́ ọ̀nà tí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà gbà ṣẹ lọ́nà ńlá.
Ìgbèkùn àti Ìdáǹdè Òde Òní
16. Wàhálà wo ló wáyé bí Jésù ṣe gorí ìtẹ́ lọ́dún 1914?
16 Wàhálà kárí ayé, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí, ló wáyé nígbà tí Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba lọ́dún 1914. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé, bí Jésù ṣe di Ọba, ńṣe ló lé Sátánì àti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú yòókù kúrò ní ọ̀run. Bó sì ṣe di pé Sátánì kò lè kúrò ní àyíká ayé yìí mọ́, ló bá dojú ogun kọ àwọn ẹni mímọ́ tí ó ṣẹ́ kù, ìyẹn àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró. (Ìṣípayá 12:7-12, 17) Ọ̀ràn náà dé ògógóró rẹ̀ lọ́dún 1918, nígbà tó di pé iṣẹ́ ìwàásù láwùjọ fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ dúró, tí wọ́n sì kó àwọn tó di ipò pàtàkì mú nínú àwọn òṣìṣẹ́ Watch Tower Society sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn èké pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba. Ìyẹn ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti òde òní fi dèrò ìgbèkùn nípa tẹ̀mí, èyí tó dà bí irú ìgbèkùn nípa ti ara tí àwọn Júù ayé àtijọ́ lọ. Ló bá di pé ẹ̀gàn ńláǹlà fẹ́ bá wọn.
17. Ọ̀nà wo ni àyípadà gbà dé bá ipò àwọn ẹni àmì òróró lọ́dún 1919, báwo sì ni wọ́n ṣe dẹni táa fún lókun nígbà náà lọ́hùn-ún?
17 Ṣùgbọ́n ipò ìgbèkùn àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò wà fún ìgbà pípẹ́. Ní March 26, 1919, wọ́n tú àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyẹn sílẹ̀, wọ́n sì wá fagi lé gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n. Ni Jèhófà wá tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí àwọn èèyàn rẹ̀ tó dá nídè, ó tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn lókun láti lè ṣe iṣẹ́ tí ń bẹ níwájú wọn. Àwọn náà sì fi ìdùnnú ṣe bí ìpè yìí ṣe wí, ìyẹn ni pé kí wọ́n wá “gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” (Ìṣípayá 22:17) Wọ́n ra “wáìnì àti wàrà, àní láìsí owó àti láìsí ìdíyelé,” wọ́n sì di ẹni tó lókun nípa tẹ̀mí láti lè mójú tó ìbísí ńláǹlà tó máa tó wáyé, ìbísí tí àwọn ẹni àmì òróró kò tilẹ̀ mọ̀ tẹ́lẹ̀.
Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Sáré Tọ Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run Wá
18. Ẹgbẹ́ méjì wo ló wà nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi, kí ni wọ́n sì pa pọ̀ jẹ́ lóde òní?
18 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń retí láti nípìn-ín nínú ọ̀kan nínú ìrètí méjì. Àkọ́kọ́, “agbo kékeré” tí iye wọ́n jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni a kó jọ pọ̀, ìyẹn àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹ̀yà Júù àtàwọn tó jẹ́ Kèfèrí, tí wọ́n pa pọ̀ jẹ́ “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tí wọ́n sì ń retí láti bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. (Lúùkù 12:32; Gálátíà 6:16; Ìṣípayá 14:1) Ìkejì, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” ti yọjú. Àwọn wọ̀nyí ń retí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ́ sílẹ̀, ògìdìgbó yìí, tí wọn kò ní iye kan pàtó, ń bá agbo kékeré ṣiṣẹ́ pọ̀, tí agbo méjèèjì sí para pọ̀ di “agbo kan” lábẹ́ “olùṣọ́ àgùntàn kan.”—Ìṣípayá 7:9, 10; Jòhánù 10:16.
19. Báwo ni “orílẹ̀-èdè” kan tí Ísírẹ́lì Ọlọ́run kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ ṣe jẹ́ ìpè tí orílẹ̀-èdè tẹ̀mí ń pè?
19 Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó tẹ̀ lé e yìí jẹ́ ká rí òye bí kíkó ogunlọ́gọ̀ yìí jọ ṣe máa lọ, ó ní: “Wò ó! Orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni ìwọ yóò pè, àwọn ará orílẹ̀-èdè tí kò sì mọ̀ ọ́ yóò sáré wá àní sọ́dọ̀ rẹ, nítorí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, àti nítorí Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì, nítorí pé òun yóò ti ṣe ọ́ lẹ́wà.” (Aísáyà 55:5) Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé ìgbà tí àwọn ẹni àmì òróró rí ìdáǹdè gbà kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí, kò kọ́kọ́ yé wọn pé kí Amágẹ́dọ́nì tó dé, wọn yóò jẹ́ ohun èlò fún pípe “orílẹ̀-èdè” ńlá wá sínú ìjọsìn Jèhófà. Àmọ́ bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ tí kò retí pé àwọn yóò lọ sí ọ̀run wá bẹ̀rẹ̀ sí dára pọ̀ mọ́ àwọn ẹni àmì òróró, wọ́n sì ń fi irú ìtara kan náà sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn ẹni àmì òróró. Ńṣe ni àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé yìí ṣàkíyèsí ipò alárinrin tí àwọn èèyàn Ọlọ́run wà, wọ́n sì rí i pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn. (Sekaráyà 8:23) Àárín ọdún 1930 sí 1939 ni àwọn ẹni àmì òróró wá lóye ẹni tí ẹgbẹ́ yìí jẹ́ ní ti gidi, ẹgbẹ́ tó jẹ́ pé iye rẹ̀ ń pọ̀ sí i láàárín wọn. Ó wá yé wọn pé iṣẹ́ ìkórè ńláǹlà ṣì ń bẹ níwájú. Wìtìwìtì ni ogunlọ́gọ̀ ńlá ń rọ́ wá láti dara pọ̀ mọ́ àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú yìí, ohun tó sì yẹ bẹ́ẹ̀ ni.
20. (a) Nígbà ayé wa yìí, kí nìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé kéèyàn “wá Jèhófà,” báwo lèèyàn sì ṣe lè wá a? (b) Ìhà wo ni Jèhófà yóò kọ sí àwọn tó bá wá a?
20 Nígbà ayé Aísáyà, ìpè kan jáde lọ pé: “Ẹ wá Jèhófà, nígbà tí ẹ lè rí i. Ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.” (Aísáyà 55:6) Nígbà ayé wa yìí, ọ̀rọ̀ yìí bá a mú gan-an ni fún àwọn tó para pọ̀ jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run àti fún ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń pọ̀ sí i yìí. Rírí ìbùkún Jèhófà gbà kò ṣàìsinmi lórí àwọn ipò kan, bẹ́ẹ̀ sì ni Jèhófà kò ní máa bá a lọ láti nawọ́ ìpè náà síni títí lọ gbére. Ìsinsìnyí gan-an ni àkókò láti wá ojú rere Ọlọ́run. Nígbà tí àkókò ìdájọ́ Jèhófà bá fi dé, yóò ti pẹ́ jù. Ìyẹn ni Aísáyà fi sọ pé: “Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀, kí apanilára sì fi ìrònú rẹ̀ sílẹ̀; kí ó sì padà sọ́dọ̀ Jèhófà, ẹni tí yóò ṣàánú fún un, àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, nítorí tí òun yóò dárí jì lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:7.
21. Báwo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe hùwà àìṣòótọ́ nípa ohun tí àwọn baba ńlá wọn sọ pé àwọn yóò ṣe?
21 Gbólóhùn náà, “kí ó . . . padà sọ́dọ̀ Jèhófà,” ń fi hàn pé àwọn tó nílò ìrònúpìwàdà ní àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run tẹ́lẹ̀ rí. Gbólóhùn yìí ń mú wa rántí pé ọ̀pọ̀ nínú ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí ló ti kọ́kọ́ ṣẹ sára àwọn Júù tó wà nígbèkùn ní Bábílónì. Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, àwọn baba ńlá àwọn tó dèrò ìgbèkùn yìí kéde ìpinnu wọn pé àwọn yóò ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà tí wọ́n sọ pé: “Kò ṣeé ronú kàn fún àwa, láti fi Jèhófà sílẹ̀ láti lè sin àwọn ọlọ́run mìíràn.” (Jóṣúà 24:16) Ìtàn fi hàn pé ohun tí wọ́n ní “kò ṣeé ronú kàn” yìí ṣẹlẹ̀ o, ó tilẹ̀ ṣẹlẹ̀ léraléra pàápàá! Àìnígbàgbọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run sọ wọ́n dèrò ìgbèkùn ní Bábílónì.
22. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ pé ìrònú àti ọ̀nà òun ga ju tí àwọn ọmọ aráyé lọ?
22 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí wọ́n bá ronú pìwà dà? Jèhófà gbẹnu Aísáyà ṣèlérí pé òun yóò “dárí jì lọ́nà títóbi.” Ó wá fi kún un pé: “‘Nítorí pé ìrònú yín kì í ṣe ìrònú mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi kì í ṣe ọ̀nà yín,’ ni àsọjáde Jèhófà. ‘Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.’” (Aísáyà 55:8, 9) Ẹni pípé ni Jèhófà, ìrònú rẹ̀ àti ọ̀nà rẹ̀ sì ga fíofío. Kódà àánú rẹ̀ pàápàá ga débi pé àwa ọmọ aráyé kò tilẹ̀ lè gbèrò pé a lè ní àánú tó o láéláé. Ẹ̀yin ẹ wò ó ná: Nígbà tí a bá dárí ji ọmọnìkejì wa, ṣebí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ló ṣì ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀. A mọ̀ pé ó pẹ́, ó yá, àwa náà yóò fẹ́ kí ọmọnìkejì wa mìíràn dárí jì wá. (Mátíù 6:12) Ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sígbà kankan tí yóò wáyé pé ẹnì kan ní láti dárí jì í, òun a máa dárí jini “lọ́nà títóbi”! Ní tòótọ́, Ọlọ́run onínú rere onífẹ̀ẹ́ ńláǹlà ni o. Àti pé nínú àánú Jèhófà, ó ṣí ibodè omi ọ̀run, yóò sì rọ̀jò ìbùkún sórí àwọn tó bá fi gbogbo ọkàn wọn padà sọ́dọ̀ rẹ̀.—Málákì 3:10.
Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Ńbẹ Fáwọn Tó Bá Padà Sọ́dọ̀ Jèhófà
23. Báwo ni Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe dídájú tó dájú pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yóò ṣẹ?
23 Jèhófà ṣèlérí fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀yamùúmùú òjò ti ń rọ̀, àti ìrì dídì, láti ọ̀run, tí kì í sì í padà sí ibẹ̀, bí kò ṣe pé kí ó rin ilẹ̀ ayé gbingbin ní tòótọ́, kí ó sì mú kí ó méso jáde, kí ó sì rú jáde, tí a sì fi irúgbìn fún afúnrúgbìn àti oúnjẹ fún olùjẹ ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò já sí. Kì yóò padà sọ́dọ̀ mi láìní ìyọrísí, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò ṣe èyí tí mo ní inú dídùn sí, yóò sì ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú nínú èyí tí mo tìtorí rẹ̀ rán an.” (Aísáyà 55:10, 11) Gbogbo ohun tí Jèhófà bá sọ ni yóò ṣẹ dájúdájú. Gẹ́lẹ́ bí òjò àti ìrì dídì tí ń rọ̀ láti ojú sánmà wá ṣe ń ṣàṣeyọrí ète rẹ̀ nípa fífi omi rin ilẹ̀ ayé, tí ó sì ń mú èso jáde, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde ti ṣeé gbára lé pátápátá. Ohun tó bá ti ṣèlérí, yóò mú un ṣẹ o, ìyẹn dájú hán-únhán-ún.—Númérì 23:19.
24, 25. Àwọn ìbùkún wo ní ń bẹ níwájú fún àwọn Júù tó wà nígbèkùn tí wọ́n ṣiṣẹ́ lórí ohun tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ?
24 Nítorí náà, bí àwọn Júù bá kọbi ara sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ fún wọn lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀, wọn yóò rí ìgbàlà tí Jèhófà ṣèlérí gbà láìkùnà. Wọn yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó ní ayọ̀ ńláǹlà. Jèhófà sọ pé: “Ayọ̀ yíyọ̀ ni ẹ ó fi jáde lọ, àlàáfíà sì ni a ó fi mú yín wọlé. Àwọn òkè ńláńlá àti àwọn òkè kéékèèké pàápàá yóò fi igbe ìdùnnú tújú ká níwájú yín, àní gbogbo àwọn igi pápá yóò pàtẹ́wọ́. Dípò ìgbòrò ẹlẹ́gùn-ún, igi júnípà ni yóò hù jáde. Dípò èsìsì ajónilára, igi mátílì ni yóò hù jáde. Yóò sì di ohun lílókìkí fún Jèhófà, àmì fún àkókò tí ó lọ kánrin tí a kì yóò ké kúrò.”—Aísáyà 55:12, 13.
25 Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn Júù tó wà nígbèkùn fi ayọ̀ jáde lọ kúrò ní Bábílónì lóòótọ́. (Sáàmù 126:1, 2) Nígbà tí wọ́n dé Jerúsálẹ́mù, wọ́n rí i pé ìgbòrò ẹlẹ́gùn-ún àti èsìsì ajónilára tí bo ilẹ̀ ibẹ̀ pítipìti, ẹ sáà rántí pé ọdún gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ni ibẹ̀ fi wà láhoro. Ṣùgbọ́n àwọn èèyàn Ọlọ́run tí ó dá padà wálé wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ nísinsìnyí láti rí sí i pé àyípadà wáyé, àyípadà tó wúni lórí! Àwọn igi ràbàtà-ràbàtà, bí igi júnípà àti mátílì wá dípò àwọn igi ẹ̀gún àti èsìsì. Ìbùkún Jèhófà wá hàn kedere bí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe ń fi “igbe ìdùnnú” jọ́sìn rẹ̀. Àfi bíi pé ilẹ̀ náà fúnra rẹ̀ kúkú ń yọ̀ ni.
26. Ipò ìbùkún wo ni àwọn èèyàn Ọlọ́run wà lónìí?
26 Lọ́dún 1919, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gba ìdáǹdè tiwọn kúrò nígbèkùn nípa tẹ̀mí. (Aísáyà 66:8) Àwọn pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn ló wá jọ ń sin Ọlọ́run tayọ̀tayọ̀ nísinsìnyí nínú párádísè tẹ̀mí. Nígbà tí kò sì ti sí ọ̀ràn pé àbààwọ́n kankan látinú Bábílónì ń wọnú ọ̀rọ̀ wọn, wọ́n di ẹni ìtẹ́wọ́gbà, tí ó wá di “ohun lílókìkí” fún Jèhófà. Aásìkí wọn nípa tẹ̀mí ń yin orúkọ rẹ̀ lógo, ó sì ń gbé e ga pé ó jẹ́ Ọlọ́run àsọtẹ́lẹ̀ tòótọ́. Ohun tí Jèhófà ṣe láṣeparí fún wọn ń fi í hàn pé ó jẹ́ Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ẹ̀rí pé kò yẹsẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti pé ó ń fi àánú hàn sí àwọn tó ronú pìwà dà. Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn tí ń bá a nìṣó láti “ra wáìnì àti wàrà, àní láìsí owó àti láìsí ìdíyelé” máa fi ìdùnnú jọ́sìn rẹ̀ títí láé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọ̀pọ̀ orúkọ àwọn Júù làwọn èèyàn ti bá pàdé nínú àwọn àkọsílẹ̀ ìṣòwò ti àwọn ará Bábílónì àtijọ́.
b Jésù ṣì ń bá a lọ láti bójú tó iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn yìí. (Ìṣípayá 14:14-16) Lóde òní, Jésù ni àwọn Kristẹni lọ́kùnrin lóbìnrin kà sí Orí ìjọ. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Bí ó bá sì tó àkókò lójú Ọlọ́run, Jésù yóò ṣe ojúṣe “aṣáájú àti aláṣẹ” ní ọ̀nà mìíràn, nígbà tó bá dojú ogun àjàṣẹ́gun kọ àwọn ọ̀tá Ọlọ́run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣípayá 19:19-21.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 234]
Àwọn Júù tí òùngbẹ tẹ̀mí ń gbẹ gba ìpè pé kí wọ́n “wá síbi omi” àti pé kí wọ́n “ra wáìnì àti wàrà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 239]
Jésù fi hàn pé òun ni “aṣáájú àti aláṣẹ” fún àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 245]
“Kí ènìyàn burúkú fi ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀”