-
A Kó Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè Jọ sí Ilé Àdúrà Ọlọ́runÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
Ìtùnú fún Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè àti Ìwẹ̀fà
6. Ẹgbẹ́ méjì wo ló gbàfiyèsí báyìí?
6 Jèhófà wá bá ẹgbẹ́ méjì tó ń fẹ́ sìn ín ṣùgbọ́n tí Òfin Mósè kò gbà wọ́n láàyè láti wá sínú ìjọ àwọn Júù, sọ̀rọ̀ wàyí. A kà á pé: “Kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà má sì sọ pé, ‘Láìsí àní-àní, Jèhófà yóò pín mi níyà sí àwọn ènìyàn rẹ̀.’ Kí ìwẹ̀fà má sì sọ pé, ‘Wò ó! Igi gbígbẹ ni mí.’” (Aísáyà 56:3) Ìbẹ̀rù ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ni pé wọ́n á ké òun kúrò lára Ísírẹ́lì. Ìdààmú ti ìwẹ̀fà ni pé òun kò lè bímọ tí yóò máa jẹ́ orúkọ òun. Kí ẹgbẹ́ méjèèjì lọ mọ́kàn le. Kí a tó rí ìdí tó fi jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí á ṣàgbéyẹ̀wò bí àwọn àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe wà síra wọn lábẹ́ Òfin.
7. Ààlà wo ni Òfin pa fún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ní Ísírẹ́lì?
7 Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè aláìdádọ̀dọ́ kò lè bá Ísírẹ́lì ṣe ìjọsìn pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọn kò lè bá wọn jẹ nínú Ìrékọjá. (Ẹ́kísódù 12:43) Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ máa tẹ àwọn òfin ilẹ̀ Ísírẹ́lì lójú yóò rí ẹ̀tọ́ tirẹ̀ àti aájò àlejò gbà, ṣùgbọ́n kò lè sí àjọṣe tó wà títí gbére láàárín àwọn àti orílẹ̀-èdè yẹn. Lóòótọ́ o, tọkàntara làwọn kan fi gba Òfin, àwọn ọkùnrin sì fi ẹ̀rí èyí hàn nípa dídá adọ̀dọ́. Wọn á wá di aláwọ̀ṣe, ẹni tó láǹfààní láti jọ́sìn nínú àgbàlá ilé Jèhófà, tí wọ́n sì kà sí ara ìjọ ní Ísírẹ́lì. (Léfítíkù 17:10-14; 20:2; 24:22) Àmọ́, àwọn aláwọ̀ṣe pàápàá kò lè kópa ní kíkún nínú májẹ̀mú tí Jèhófà bá Ísírẹ́lì dá, wọn kò sì ní ogún ilẹ̀ kankan nínú Ilẹ̀ Ìlérí. Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè yòókù lè yíjú sí tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ẹ̀rí sì fi hàn pé àwọn àlùfáà lè bá wọn rú ẹbọ wọn tí ó bá ṣáà ti bá Òfin mu. (Léfítíkù 22:25; 1 Àwọn Ọba 8:41-43) Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò ní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú wọn.
Àwọn Ìwẹ̀fà Gba Orúkọ Tí Yóò Wà fún Àkókò Tó Lọ Kánrin
8. (a) Lábẹ́ Òfin, ojú wo ni wọ́n fi ń wo àwọn ìwẹ̀fà? (b) Kí ni wọ́n ń lo àwọn ìwẹ̀fà fún ní àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí, kí sì ni a lè lo ọ̀rọ̀ náà “ìwẹ̀fà” fún nígbà mìíràn?
8 Òfin kò ka ìwẹ̀fà kankan sí ojúlówó ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, kódà bàbá àti ìyá rẹ̀ ì báà jẹ́ Júù.a (Diutarónómì 23:1) Àwọn ìwẹ̀fà ní ipò pàtàkì tiwọn láàárín àwọn orílẹ̀-èdè Kèfèrí kan láyé ìgbà tí wọ́n ṣì ń kọ Bíbélì, ó sì jẹ́ àṣà wọn láti tẹ àwọn kan lọ́dàá lára àwọn ọmọ tí wọ́n bá kó nígbèkùn nígbà ogun. Wọ́n máa ń yan àwọn ìwẹ̀fà ṣe òṣìṣẹ́ láàfin. Ìwẹ̀fà lè jẹ́ “olùṣètọ́jú àwọn obìnrin,” “olùṣètọ́jú àwọn wáhàrì,” tàbí kí ó jẹ́ ìránṣẹ́ ayaba. (Ẹ́sítérì 2:3, 12-15; 4:4-6, 9) Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀, tàbí pé wọ́n dìídì máa ń wá àwọn ìwẹ̀fà tí wọ́n yóò máa ṣiṣẹ́ fún àwọn ọba Ísírẹ́lì.b
9. Ọ̀rọ̀ ìtùnú wo ni Jèhófà sọ fún àwọn tó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ti ara ìyára?
9 Yàtọ̀ sí pé àwọn tó jẹ́ ìwẹ̀fà ní ti ara ìyára ní Ísírẹ́lì kò lè fi bẹ́ẹ̀ kópa nínú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́, ẹ̀tẹ́ ńlá tún máa ń bá wọn ní ti pé wọn kò lè bímọ tí yóò máa jẹ́ orúkọ ìdílé wọn nìṣó. Nígbà náà, ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó tẹ̀ lé e yìí á mà jẹ́ ìtùnú o! A kà á pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún àwọn ìwẹ̀fà tí ń pa àwọn sábáàtì mi mọ́, tí wọ́n sì ti yan ohun tí mo ní inú dídùn sí, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi: ‘Àní èmi yóò fún wọn ní ohun ìránnilétí àti orúkọ ní ilé mi àti nínú àwọn ògiri mi, ohun tí ó sàn ju àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin. Orúkọ tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fún wọn, ọ̀kan tí a kì yóò ké kúrò.’”—Aísáyà 56:4, 5.
-
-
A Kó Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè Jọ sí Ilé Àdúrà Ọlọ́runÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
a Ọ̀rọ̀ náà “ìwẹ̀fà” tún di èyí tí a ń lò fún ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin láìjẹ́ pé wọ́n tẹ̀ ẹ́ lọ́dàá. Nígbà tó sì ti jọ pé aláwọ̀ṣe ni ará Etiópíà tí Fílípì rì bọmi, tí wọ́n sì tún rì í bọmi ṣáájú kí ọ̀nà tó ṣí sílẹ̀ fún àwọn tí kì í ṣe Júù, a jẹ́ pé irú ìwẹ̀fà bí èyí ni tirẹ̀.—Ìṣe 8:27-39.
b Ìwẹ̀fà ni wọ́n pe Ebedi-mélékì tó ṣèrànwọ́ fún Jeremáyà, tó tún jẹ́ ẹni tó lè tọ Sedekáyà Ọba lọ fàlàlà. Ó jọ pé jíjẹ́ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ láàfin nìyẹn tọ́ka sí dípò ti pé ó jẹ́ ẹni tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá.—Jeremáyà 38:7-13.
-