Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kejì
WÒLÍÌ AÍSÁYÀ ń fi tọkàntọkàn bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Àgbákò tó kéde pé ó máa dé bá ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá Ísírẹ́lì ti nímùúṣẹ. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ṣì kù tó fẹ́ sọ nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù lọ́jọ́ ọ̀la.
Àwọn ọ̀tá yóò pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n á sì kó àwọn tó ń gbé níbẹ̀ lọ sígbèkùn. Àmọ́, ìlú náà ò ní dahoro títí ayé o. Tó bá yá, àwọn èèyàn náà máa padà wá kí wọ́n lè máa ṣe ìjọsìn tòótọ́ bíi ti tẹ́lẹ̀. Ìyẹn ni lájorí ohun tí ìwé Aísáyà 36:1-66:24a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Tá a bá gbé àwọn ohun tó wà nínú àwọn orí wọ̀nyí yẹ̀ wò, yóò ṣe wá láǹfààní púpọ̀ torí pé ọ̀pọ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ló ń ní ìmúṣẹ ìkẹyìn lákòókò wa yìí, nígbà táwọn míì yóò nímùúṣẹ láìpẹ́. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn tó ń wúni lórí nípa Mèsáyà tún wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
“WÒ Ó! ÀWỌN ỌJỌ́ Ń BỌ̀”
Lọ́dún kẹrìnlá ìṣàkóso Hesekáyà Ọba (ìyẹn lọ́dún 732 ṣááju Sànmánì Kristẹni), àwọn ará Ásíríà gbógun ja Júdà. Jèhófà ṣèlérí pé òun ò ní jẹ́ kí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run. Gbogbo ìhàlẹ̀ àwọn ará Ásíríà pé àwọn máa pa Jerúsálẹ́mù run dópin nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà kan ṣoṣo pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] nínú àwọn ọmọ ogun wọn.
Lákòókò kan Hesekáyà dùbúlẹ̀ àìsàn. Ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó mú òun lára dá, Jèhófà sì dáhùn àdúrà rẹ̀, ó tún fọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ̀. Ọba Bábílónì rán àwọn ońṣẹ́ kan pé kí wọ́n lọ bá òun kí Hesekáyà kú àlàjá, àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó hùwà kan tí kò bọ́gbọ́n mu, ó fi gbogbo ìṣúra rẹ̀ hàn wọ́n. Aísáyà wá lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún Hesekáyà, ó ní: “Wò ó! Àwọn ọjọ́ ń bọ̀, gbogbo ohun tí ó sì wà nínú ilé tìrẹ àti èyí tí àwọn baba ńlá rẹ ti tò jọ pa mọ́ títí di òní yìí ni a óò kó lọ sí Bábílónì ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 39:5, 6) Àsọtẹ́lẹ̀ yìí nímùúṣẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún ó lé díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
38:8—Kí ni “àwọn ìdásẹ̀lé” tí Ọlọ́run mú kí òjìji oòrùn sún padà sẹ́yìn lára rẹ̀? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Íjíbítì àtàwọn ará Bábílónì máa ń lo ibi tí òjìji oòrùn dé lára ìdásẹ̀lé ara irú àtẹ̀gùn kan láti fi mọ iye aago tó lù, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdásẹ̀lé irú àtẹ̀gùn yìí tó jọ pé ó jẹ́ ti Áhásì bàbá Hesekáyà ni ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ. Ó sì lè jẹ́ pé àtẹ̀gùn kan wà láàfin ọba. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé nígbà tóòrùn bá ràn sára òpó kan tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àtẹ̀gùn yìí, ńṣe ni òjìji òpó yìí máa hàn lára ìdásẹ̀lé àtẹ̀gùn náà, ìyẹn á sì jẹ́ kí wọ́n mọ iye aago tó lù.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
36:2, 3, 22. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbaṣẹ́ ìríjú lọ́wọ́ Ṣébínà, síbẹ̀ wọ́n jẹ́ kó máa ṣe akọ̀wé fún ẹni tí wọ́n fi rọ́pò rẹ̀ láàfin. (Aísáyà 22:15, 19) Tí wọ́n bá gba ẹrù iṣẹ́ lọ́wọ́ wa nínú ètò Jèhófà nítorí ìdí kan, ṣé kò yẹ ká máa sin Ọlọ́run nìṣó ní ipò yòówù tó bá fi wá sí?
37:1, 14, 15; 38:1, 2. Tá a bá wà nínú ìṣòro, ohun tó bọ́gbọ́n mu láti ṣe ni pé ká gbàdúrà sí Jèhófà ká sì fi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé e.
37:15-20; 38:2, 3. Nígbà táwọn ará Ásíríà fẹ́ wá gbógun ja Jerúsálẹ́mù, ohun tó ká Hesekáyà lára jù lọ ni bí wọn ò ṣe ní ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù nítorí pé ìyẹn máa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Hesekáyà gbọ́ pé àìsàn tó ń ṣe òun yóò la ikú lọ, ìyẹn kọ́ ló dùn ún jù. Ó wò ó pé tóun bá lọ kú láìní ọmọkùnrin kankan, ìyẹn á ṣàkóbá fún ìlà ọba ní ìdílé Dáfídì. Nǹkan mìíràn tí ò fi í lọ́kàn balẹ̀ ni ọ̀rọ̀ ẹni tó máa ṣáájú nínú ogun tí wọ́n fẹ́ bá àwọn ará Ásíríà jà. Bíi ti Hesekáyà, ohun tó jẹ àwa náà lógún jù ni bí orúkọ Jèhófà ṣe máa di mímọ́ àti bí àwọn ohun tó pinnu láti ṣe ṣe máa nímùúṣẹ, kì í ṣe bí àwa fúnra wa ṣe máa rí ìgbàlà.
38:9-20. Orin tí Hesekáyà kọ yìí kọ́ wa pé kò sóhun tó ṣe pàtàkì láyé yìí ju pé kéèyàn lè máa yin Jèhófà.
“A ÓÒ TÚN UN KỌ́”
Kété lẹ́yìn tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ará Bábílónì yóò pa Jerúsálẹ́mù run àti pé wọ́n á kó àwọn ará ibẹ̀ lọ sígbèkùn ní Bábílónì, ó tún sọ tẹ́lẹ̀ pé wọn yóò tún ìlú náà kọ́. (Aísáyà 40:1, 2) Aísáyà 44:28 sọ pé: “A óò tún [Jerúsálẹ́mù] kọ́.” Aísáyà tún sọ pé wọn yóò kó ère òrìṣà àwọn ará Bábílónì lọ bí ìgbà téèyàn kó ‘ẹrù àjò lẹ́yọ-lẹ́yọ.’ (Aísáyà 46:1) Ó ní wọ́n á pa Bábílónì run. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì nímùúṣẹ ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì lẹ́yìn ìgbà yẹn.
Jèhófà yóò rán ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 49:6) Àwọn tó dà bí “ọ̀run” ní Bábílónì, ìyẹn àwọn alákòóso ibẹ̀ yóò “fọ́n ká ní wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ gẹ́gẹ́ bí èéfín,” àwọn aráàlú yòókù “yóò sì kú bí kòkòrò kantíkantí lásán-làsàn”; ṣùgbọ́n ‘òǹdè ọmọbìnrin Síónì yóò tú ọ̀já ọrùn rẹ̀ fúnra rẹ̀.’ (Aísáyà 51:6; 52:2) Ní ti àwọn tí wọ́n wá sọ́dọ̀ Jèhófà tí wọ́n sì gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, Jèhófà sọ fún wọn pé: “Pẹ̀lú ìmúratán sì ni èmi yóò bá yín dá májẹ̀mú tí yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ní ti àwọn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí Dáfídì.” (Aísáyà 55:3) Gbígbé táwọn èèyàn náà gbé níbàámu pẹ̀lú ìlànà òdodo Ọlọ́run mú kí wọ́n rí “inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà.” (Aísáyà 58:14) Àmọ́ o, ẹ̀ṣẹ̀ táwọn kan lára wọn dá ‘fa ìpínyà láàárín àwọn àti Ọlọ́run wọn.’—Aísáyà 59:2.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
40:27, 28—Kí nìdí tí Ísírẹ́lì fi sọ pé: “Ọ̀nà mi pa mọ́ kúrò lójú Jèhófà, àti pé ìdájọ́ òdodo sí mi ń yọ́ bọ́rọ́ mọ́ Ọlọ́run mi . . . lọ́wọ́”? Àwọn Júù kan tó wà nígbèkùn ní Bábílónì lè máa rò pé Jèhófà ò rí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táwọn èèyàn ń hù sáwọn. Àmọ́ Aísáyà jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ojú Ẹlẹ́dàá ilẹ̀ ayé, ẹni tí àárẹ̀ kì í mú tí agara kì í sì í dá, tó gbogbo nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ ní Bábílónì.
43:18-21—Kí nìdí tí wọ́n fi sọ fáwọn Júù tó ti ìgbèkùn wá pé kí wọ́n ‘má ṣe rántí àwọn nǹkan àtijọ́’? Wọn ò ní kí wọ́n gbàgbé àwọn nǹkan ribiribi tí Jèhófà ṣe látijọ́ láti fi gbà wọ́n là o. Ńṣe ni Jèhófà fẹ́ kí wọ́n fojú ara wọn rí “ohun tuntun” táá mú kí wọ́n máa yin òun. Lára àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ni ààbò tó nípọn tí Jèhófà máa dá bò wọ́n nígbà ìrìn àjò wọn padà sí Jerúsálẹ́mù, bóyá ní ọ̀nà aṣálẹ̀ tó túbọ̀ ṣe tààrà tó máa mú wọn gbà. Bákan náà ni ẹnì kọ̀ọ̀kan tó jẹ́ ara “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tó máa jáde wá látinú “ìpọ́njú ńlá” yóò ṣe ní ìdí tuntun mìíràn táá mú kí wọ́n fẹ́ láti máa yin Jèhófà.—Ìṣípayá 7:9, 14.
49:6—Báwo ni Mèsáyà ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ló ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Jésù fi èyí hàn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 49:6 ṣẹ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lára. (Ìṣe 13:46, 47) Lóde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí ogunlọ́gọ̀ ńlá olùjọsìn Ọlọ́run ń ṣèrànlọ́wọ́ fún, jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” ní ti pé wọ́n ń la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé àwọn èèyàn “títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 24:14; 28:19,20.
53:10—Kí ló túmọ̀ sí nígbà tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé Jèhófà ní inú dídún sí títẹ ọmọ rẹ̀ rẹ́? Kò sọ́gbọ́n kó má dun Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú àti onípamọ́ra, gan-an bó ṣe ń wo ìyà táwọn èèyàn fi jẹ Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n. Síbẹ̀, inú rẹ̀ dùn sí jíjẹ́ tí Jésù jẹ́ onígbọràn, inú rẹ̀ tún dùn nítorí gbogbo nǹkan tí ìyà tí Jésù jẹ àti ikú tó kú máa mú kó ṣeé ṣe.—Òwe 27:11; Aísáyà 63:9.
53:11—Kí ni ìmọ̀ tí Mèsáyà “yóò fi mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn”? Ìmọ̀ tíbí yìí ń sọ ni ìmọ̀ tí Jésù ní nípa wíwá sórí ilẹ̀ ayé, nípa dídi èèyàn, àti nípa jíjẹ ìyà tí kò tọ́ sí i títí dójú ikú. (Hébérù 4:15) Ikú tó sì kú yìí ló fi pèsè ìràpadà, tó mú kó ṣeé ṣe fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá láti mú ìdúró òdodo níwájú Ọlọ́run, ìyẹn ni pé kí wọ́n ní ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run.—Róòmù 5:19; Jákọ́bù 2:23, 25.
56:6—Àwọn wo ni “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,” ọ̀nà wo ni wọ́n sì gbà ń “rọ̀ mọ́ májẹ̀mú [Jèhófà]”? “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” tí ibí yìí ń sọ ni “àwọn àgùntàn mìíràn” tó jẹ́ ti Jésù. (Jòhánù 10:16) Ọ̀nà tí wọ́n sì gbà ń rọ̀ mọ́ májẹ̀mú tuntun ni pé wọ́n ń pa àwọn òfin tó ní í ṣe pẹ̀lú májẹ̀mú náà mọ́, wọ́n fara mọ́ àwọn ètò tó jẹ mọ́ májẹ̀mú náà délẹ̀délẹ̀, oúnjẹ tẹ̀mí kan náà táwọn ẹni àmì òróró ń jẹ làwọn náà ń jẹ, wọ́n sì ń kọ́wọ́ ti iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni-dọmọ-ẹ̀yìn táwọn ẹni àmì òróró ń ṣe.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
40:10-14, 26, 28. Jèhófà lẹni tó lágbára jù lọ láyé lọ́run, síbẹ̀ ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́, òun ni ọba ọgbọ́n, òye rẹ̀ sì ju tàwa ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì.
40:17, 23; 41:29; 44:9; 59:4. “Òtúbáńtẹ́” ló jẹ́ téèyàn bá lọ ń bá àwọn olóṣèlú ayé wọ àjọṣepọ̀ tó sì ń lọ́wọ́ nínú ìjọsìn òrìṣà. Asán lórí asán ni ìgbẹ́kẹ̀lé nínú wọn jẹ́.
42:18, 19; 43:8. Téèyàn bá di ojú rẹ̀ sí Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn ni pé tí kò kà á sí, tó sì kọ etí ikún sí ìtọ́ni tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń fúnni, ojú onítọ̀hún á fọ́ nípa tẹ̀mí etí rẹ̀ á sì di nípa tẹ̀mí.—Mátíù 24:45.
43:25. Jèhófà ń nu ìrélànàkọjá tàbí ẹ̀ṣẹ̀ kúrò nítorí tirẹ̀. Kékeré ni ọ̀rọ̀ pé ká bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ òun ikú ká sì rí ìyè àìnípẹ̀kun, ọ̀rọ̀ ìsọdimímọ́ orúkọ Jèhófà ló ṣe pàtàkì jù.
44:8. Jèhófà tó jẹ́ òyígíyigì bí àpáta tí kò ṣeé mì ni aláfẹ̀yìntì wa. Torí náà, kò yẹ kẹ́rù máa bà wá rárá láti wàásù fáwọn èèyàn pé Jèhófà ni Ọlọ́run!—2 Sámúẹ́lì 22:31, 32.
44:18-20. Ẹni tí ọkàn rẹ̀ bá ti di eléèérí ló máa ń bọ̀rìṣà. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun gbapò Jèhófà nínú ọkàn wa.
46:10, 11. Agbára tí Jèhófà ní láti ‘mú ìpinnu rẹ̀ dúró,’ ìyẹn láti mú àwọn ohun tó pinnu láti ṣe ṣẹ, jẹ́ ẹ̀rí tó dájú pé òun ni Ọlọ́run.
48:17, 18; 57:19-21. Tó bá jẹ́ pé Jèhófà la gbójú lé pé kó gbà wá là, tá a sún mọ́ ọn, tá a sì ń pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, àlàáfíà wa yóò pọ̀ bí omi odò tó ń ṣàn, ìṣe òdodo wa yóò sì pọ̀ bí ìgbì omi òkun. Àmọ́ ńṣe làwọn tí ò kọbi ara sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí “òkun tí a ń bì síwá bì sẹ́yìn.” Wọn ò lálàáfíà.
52:5, 6. Èrò àwọn ará Bábílónì ni pé Ọlọ́run tòótọ́ náà ò lè ta pútú, àmọ́ àṣìṣe ńlá gbáà ni wọ́n ṣe yẹn. Wọn ò mọ̀ pé torí inú tó bí Jèhófà sáwọn èèyàn rẹ̀, ìyẹn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, làwọn fi lè kó wọn lẹ́rú. Tíṣòro bá dé bá ẹnì kan, kò yẹ ká máa yára sọ pé nǹkan tibí tàbí tọ̀hún ló fà á.
52:7-9; 55:12, 13. Ó kéré tán, ìdí mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló mú ká máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọni-dọmọ-ẹ̀yìn. Ìdí kan ni pé ẹsẹ̀ àwa tá à ń wàásù ìhìn rere dára rèǹtè-rente lójú àwọn onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tí wọ́n ń fẹ́ láti gbọ́rọ̀ Ọlọ́run. A tún ń rí Jèhófà ní “ojú ko ojú,” ìyẹn ni pé a ní àjọse tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. A sì tún ní aásìkí nípa tẹ̀mí.
52:11, 12. Ká tó lè yẹ lẹ́ni tó máa fọwọ́ kan “àwọn nǹkan èlò Jèhófà,” ìyẹn àwọn ohun tó pèsè fún ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́, a kò gbọ́dọ̀ ní èérí kankan nípa tẹ̀mí, ìwà wa sì gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.
58:1-14. Tẹ́nì kan bá ń ṣe bíi pé òun ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run tàbí pé òun jẹ́ olódodo, àmọ́ tó jẹ́ pé ojú ayé ló ń ṣe, asán ni gbogbo ìsapá rẹ̀ já sí. Ńṣe ló yẹ kí olùjọsìn tòótọ́ jẹ́ ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ará kó sì máa fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run.—Jòhánù 13:35; 2 Pétérù 3:11.
59:15b-19. Jèhófà ń wo gbogbo nǹkan tọ́mọ aráyé ń ṣe, ó sì máa ń dá sí i tó bá tákòókò lójú rẹ̀.
SÍÓNÌ ‘YÓÒ DI ADÉ ẸWÀ’
Aísáyà 60:1 sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìjọsìn tòótọ́ yóò ṣe padà bọ̀ sípò láyé ìgbàanì àti lákòókò tiwa yìí, ó ní: “Dìde, ìwọ obìnrin, tan ìmọ́lẹ̀ jáde, nítorí pé ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé, àní ògo Jèhófà sì ti tàn sára rẹ.” Síónì “yóò sì di adé ẹwà ní ọwọ́ Jèhófà.”—Aísáyà 62:3.
Aísáyà bá àwọn aráàlú ẹ̀, ìyẹn àwọn tó máa ronú pìwà dà nígbà tí wọ́n bá wà nígbèkùn ní Bábílónì, gbàdúrà sí Jèhófà. (Aísáyà 63:15–64:12) Lẹ́yìn tí wòlíì Aísáyà ti sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn àtàwọn tí ò sìn ín tọkàntọkàn, ó sọ bí Jèhófà ṣe máa bù kún àwọn tó ń sìn ín.—Aísáyà 65:1-66:24.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
61:8, 9—Kí ni “májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” àwọn wo sì ni “àwọn ọmọ”? Májẹ̀mú yìí ni májẹ̀mú tuntun tí Jèhófà bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dá. “Àwọn ọmọ” ni “àwọn àgùntàn mìíràn,” ìyẹn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí wọ́n ń tẹ̀ lé ohun táwọn ẹni àmì òróró ń sọ.—Jòhánù 10:16.
63:5—Báwo ni ìhónú Ọlọ́run ṣe ń tì í lẹ́yìn? Ọlọ́run kì í ṣẹni tó máa ń bínú sódì, ìyẹn túmọ̀ sí pé ìbínú òdodo ni ìbínú rẹ̀ máa ń jẹ́. Ìhónú rẹ̀ máa ń tì í lẹ́yìn láti mú ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ, ó sì máa ń jẹ́ kó gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
64:6. Àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé ò lè gbara wa là. Tó bá dọ̀rọ̀ ṣíṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo ìṣe òdodo wa ò jẹ́ nǹkan kan, kódà aṣọ ìdọ̀tí dáa jù ú lọ.—Róòmù 3:23, 24.
65:13, 14. Jèhófà ń bù kún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, ó sì máa ń pèsè ohun tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí lọ́pọ̀ yanturu.
66:3-5. Jèhófà kórìíra àgàbàgebè.
“Ẹ Yọ Ayọ̀ Ńláǹlà”
Ó dájú pé inú àwọn Júù olóòótọ́ tí wọ́n wà nígbèkùn ní Bábílónì dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé ìjọsìn tòótọ́ máa padà bọ̀ sípò! Jèhófà sọ pé: “Ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá. Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù ní ohun tí ń fa ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà.”—Aísáyà 65:18.
Àkókò tí òkùnkùn bó ayé táwọn èèyàn orílẹ̀-èdè sì wà nínú òkùnkùn biribiri làwa náà ń gbé. (Aísáyà 60:2) “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Nítorí náà, ìṣírí ńlá ni ọ̀rọ̀ Jèhófà tí í ṣe ọ̀rọ̀ ìgbàlà tó wà nínú ìwé Aísáyà jẹ́ fún wa.—Hébérù 4:12.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ ka àlàyé lórí Aísáyà 1:1–35:10, wo llé Ìṣọ́ December 1, 2006 lábẹ́ àkòrí náà “Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yé—Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Ǹjẹ́ o mọ olórí ìdí tí Hesekáyà fi gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kó dáàbò bo òun lọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
“Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o!”