Ògo Jèhófà Tàn Sára Àwọn Èèyàn Rẹ̀
“Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ.”—AÍSÁYÀ 60:20.
1. Báwo ni Jèhófà ṣe ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́?
“JÈHÓFÀ ní ìdùnnú sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Ó ń fi ìgbàlà ṣe àwọn ọlọ́kàn tútù lẹ́wà.” (Sáàmù 149:4) Onísáàmù ìgbàanì ló sọ̀rọ̀ yẹn. Ìtàn sì fi hàn pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tó wí. Nígbà táwọn èèyàn Jèhófà bá jẹ́ olóòótọ́, ó máa ń bójú tó wọn, ó máa ń mú kí wọ́n bí sí i, ó sì máa ń dáàbò bò wọ́n. Láyé àtijọ́, ó gbé wọn lékè àwọn ọ̀tá wọn. Lóde òní, ó ń fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Ó sì mú un dá wọn lójú pé wọn yóò rí ìgbàlà, lọ́lá ẹbọ Jésù. (Róòmù 5:9) Ó ń ṣe èyí nítorí pé wọ́n lẹ́wà lójú rẹ̀.
2. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run ń fojú winá àtakò, kí ló fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀?
2 Àmọ́ ṣá o, nínú ayé tí òkùnkùn biribiri bò yìí, àwọn tó bá ‘ń gbé ìgbé-ayé ìfọkànsin Ọlọ́run’ yóò dojú kọ àtakò. (2 Tímótì 3:12) Síbẹ̀síbẹ̀, Jèhófà rí gbogbo itú táwọn alátakò ń pa. Ó sì kìlọ̀ fún wọn pé: “Orílẹ̀-èdè èyíkéyìí àti ìjọba èyíkéyìí tí kò bá sìn ọ́ yóò ṣègbé; àwọn orílẹ̀-èdè náà alára yóò sì wá sínú ìparundahoro dájúdájú.” (Aísáyà 60:12) Oríṣiríṣi ọ̀nà ni àtakò ń gbà wá lónìí. Ní àwọn ilẹ̀ kan, àwọn alátakò lè gbìyànjú láti ká àwọn Kristẹni tòótọ́ lọ́wọ́ kò nítorí ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe fún Jèhófà tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fòfin de irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀. Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, àwọn agbawèrèmẹ́sìn máa ń dìídì dojúùjà kọ àwọn olùjọsìn Jèhófà, tí wọ́n á sì dáná sun ohun ìní wọn. Àmọ́ rántí o, pé Jèhófà ti pinnu ohun tó máa jẹ́ àbájáde àtakò èyíkéyìí táwọn èèyàn bá gbé dìde sí ìmúṣẹ ìfẹ́ rẹ̀. Ìmọ̀ràn ọ̀tá máa dòfo ṣáá ni. Ìyẹn ni pé gbogbo àwọn tó bá ń bá àwọn ọmọ Síónì tó wà lórí ilẹ̀ ayé jà kò lè borí láé. Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ tí Jèhófà, Ọlọ́run wa tó tóbi lọ́ba, sọ yìí kò fini lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀?
A Bù Kún Wọn Ré Kọjá Ohun Tí Wọ́n Retí
3. Báwo la ṣe ṣàpèjúwe ẹwà àti èso wọ̀ǹtìwọnti táwọn olùjọsìn Jèhófà ń so?
3 Ní tòótọ́, Jèhófà ti bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ ré kọjá ohun tí wọ́n retí ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan yìí. Ní pàtàkì, ó ti bu ẹwà kún ibùjọsìn rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, ó sì bu ẹwà kún àwọn tó wà nínú rẹ̀ tó ń jẹ́ orúkọ mọ́ orúkọ rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti wí, ó sọ fún Síónì pé: “Ọ̀dọ̀ rẹ ni ògo Lẹ́bánónì gan-an yóò wá, igi júnípà, igi áàṣì àti igi sípírẹ́sì lẹ́ẹ̀kan náà, láti lè ṣe ibùjọsìn mi lẹ́wà; èmi yóò sì ṣe àyè ẹsẹ̀ mi gan-an lógo.” (Aísáyà 60:13) Àwọn òkè tó kún fún igbó kìjikìji máa ń wuni láti wò. Ìdí nìyẹn tí àwọn igi tó gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ fi jẹ́ ohun tó bá a mu láti fi ṣàpẹẹrẹ ẹwà àti èso wọ̀ǹtìwọnti táwọn olùjọsìn Jèhófà ń so.—Aísáyà 41:19; 55:13.
4. Kí ni “ibùjọsìn” àti “àyè ẹsẹ̀” Jèhófà jẹ́, báwo lá sì ṣe bu ẹwà kún wọn?
4 Kí ni “ibùjọsìn” àti “àyè ẹsẹ̀” Jèhófà tá a mẹ́nu kàn ní Aísáyà 60:13 tọ́ka sí? Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tọ́ka sí àwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí, èyí tí í ṣe ìṣètò fún sísìn ín nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Hébérù 8:1-5; 9:2-10, 23) Jèhófà ti sọ ète rẹ̀ láti ṣe tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yẹn lógo nípa mímú kí àwọn èèyàn máa tinú orílẹ̀-èdè gbogbo wá jọ́sìn níbẹ̀. (Hágáì 2:7) Aísáyà alára ti kọ́kọ́ rí àwọn ogunlọ́gọ̀ látinú gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń wọ́ tìrítìrí lọ sórí òkè ìjọsìn gíga ti Jèhófà. (Aísáyà 2:1-4) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Jòhánù rí ìran “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Àwọn wọ̀nyí dúró “níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run . . . , wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìṣípayá 7:9, 15) Níwọ̀n bí àsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí ti ní ìmúṣẹ lákòókò tiwa, àwa fúnra wa ti rí i bí ilé Jèhófà ṣe di èyí tá a bu ẹwà kún.
5. Àyípadà sí rere wo ni yóò dé bá àwọn ọmọ Síónì?
5 Àyípadà sí rere mà ni gbogbo èyí jẹ́ fún Síónì o! Jèhófà sọ pé: “Dípò kí ìwọ já sí ẹni tí a fi sílẹ̀ pátápátá, tí a sì kórìíra, láìsí ẹnikẹ́ni tí ń gba inú rẹ kọjá, ṣe ni èmi yóò tilẹ̀ sọ ọ́ di ohun ìyangàn fún àkókò tí ó lọ kánrin, ayọ̀ ńláǹlà fún ìran dé ìran.” (Aísáyà 60:15) Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní ń parí lọ, “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” dahoro fún sáà kan lóòótọ́. (Gálátíà 6:16) Ó ṣe é bíi pé ó di “ẹni tí a fi sílẹ̀ pátápátá,” nítorí pé àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé kò mọ ohun náà gan-an tí Ọlọ́run ń fẹ́ kí wọ́n ṣe nígbà yẹn. Ṣùgbọ́n lọ́dún 1919, Jèhófà mú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró sọjí, látìgbà yẹn ló sì ti fi aásìkí tẹ̀mí tó ga lọ́lá bù kún wọn. Ní àfikún sí i, ìlérí tó wà nínú ẹsẹ yìí kò ha mórí yá gágá bí? Jèhófà yóò ka Síónì sí “ohun ìyangàn.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn ọmọ Síónì, àti Jèhófà alára, yóò máa fi Síónì yangàn. Yóò jẹ́ ohun “ayọ̀ ńláǹlà.” Ìyẹn ò sì ní jẹ́ fún sáà kúkúrú lásán. Ipò ojú rere tí Síónì wà, bó ṣe hàn lára àwọn ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, yóò wà “fún ìran dé ìran.” Títí láé fáàbàdà ni.
6. Báwo làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè?
6 Wàyí o, wá fetí sí ìlérí mìíràn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Jèhófà sọ fún Síónì pé: “Ní ti tòótọ́, ìwọ yóò sì fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu, ìwọ yóò sì mu ọmú àwọn ọba; dájúdájú, ìwọ yóò sì mọ̀ pé èmi, Jèhófà, ni Olùgbàlà rẹ, Ẹni Alágbára Jékọ́bù sì ni Olùtúnnirà rẹ.” (Aísáyà 60:16) Báwo ni Síónì ṣe ń “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu,” tó sì ń “mu ọmú àwọn ọba”? Ó jẹ́ ní ti pé àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” alábàákẹ́gbẹ́ wọn ń lo àwọn ohun àmúṣọrọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn tòótọ́. (Jòhánù 10:16) Àwọn ọrẹ àtinúwá tí wọ́n ń mú wá ń jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ ńlá, tó kárí ayé ṣeé ṣe. Lílo ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ òde òní lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu ti mú kó ṣeé ṣe láti tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún èdè. Lóde òní, iye àwọn tí òtítọ́ Bíbélì ń tẹ̀ lọ́wọ́ pọ̀ ju tí ìgbàkigbà rí lọ. Àwọn èèyàn látinú ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ń rí i pé Olùgbàlà gidi ni Jèhófà tó ra àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹni àmì òróró padà kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí.
Ìtẹ̀síwájú Nínú Ìṣètò
7. Ìtẹ̀síwájú títayọ wo ló ti dé bá àwọn ọmọ Síónì?
7 Jèhófà tún ti bu ẹwà kún àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́nà mìíràn. Ó ti mú kí wọ́n tẹ̀ síwájú nínú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣètò nǹkan. Aísáyà 60:17 kà pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” Bí a bá fi wúrà dípò bàbà, ìtẹ̀síwájú nìyẹn jẹ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni ti àwọn ohun èèlò yòókù tí ibí yìí mẹ́nu kàn. Bí ìtẹ̀síwájú nínú ìṣètò ṣe ń bá Ísírẹ́lì Ọlọ́run gẹ́lẹ́ nìyẹn ní gbogbo ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
8-10. Ṣàpèjúwe àwọn àtúnṣe kan tó ti wáyé nínú ìṣètò láti ọdún 1919 wá.
8 Kó tó di ọdún 1919, àwọn alàgbà àti díákónì tí ìjọ dìbò yàn ló ń bójú tó ìjọ àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Àmọ́ láti ọdún yẹn, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” bẹ̀rẹ̀ sí yan olùdarí iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan láti máa bójú tó iṣẹ́ ìsìn pápá. (Mátíù 24:45-47) Ṣùgbọ́n, nínú ọ̀pọ̀ ìjọ, ètò yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ kẹ́sẹ járí, nítorí pé àwọn alàgbà kan tí ìjọ dìbò yàn kò fi taratara kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìjíhìnrere náà. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lọ́dún 1932, àwọn ìjọ gba ìtọ́ni pé kí wọ́n ṣíwọ́ dídìbò yan àwọn alàgbà àti díákónì. Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n dìbò yan ìgbìmọ̀ iṣẹ́ ìsìn tí yóò máa bá olùdarí iṣẹ́ ìsìn ṣiṣẹ́ pọ̀. Èyí dà bí ìgbà tá a fi “bàbà” rọ́pò “igi”—tí í ṣe àyípadà ńláǹlà!
9 Nígbà tó di ọdún 1938, àwọn ìjọ yí ká ayé pinnu pé àwọn máa tẹ́wọ́ gba ìṣètò kan tó sàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ìṣètò kan tó túbọ̀ bá àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ mu. Àbójútó ìjọ di èyí tó wà níkàáwọ́ ẹni tá a mọ̀ sí ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ àtàwọn ìránṣẹ́ mìíràn. Ẹrú olóòótọ́ àti olóye ló sì ń rí sí yíyan gbogbo wọn. A ò dìbò yan ẹnikẹ́ni mọ́! Bó ṣe di pé ọ̀nà ìṣàkóso Ọlọ́run la gbà ń yan àwọn èèyàn sípò nínú ìjọ nìyẹn. Èyí wá dà bí ìgbà tá a fi “irin” rọ́pò “òkúta” tàbí tá a fi “wúrà” rọ́pò “bàbà.”
10 Ìtẹ̀síwájú ti ń bá a lọ láìsọsẹ̀ láti ìgbà yẹn wá. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1972 a rí i pé ẹgbẹ́ àwọn alàgbà tá a yàn lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ bí òṣùṣù ọwọ̀, ló máa dáa kó máa bójú tó ìjọ, láìsí pé alàgbà kan ṣoṣo ń lo ọlá àṣẹ lórí àwọn yòókù. A sì rí i pé èyí tún túbọ̀ sún mọ́ ọ̀nà tá a gbà bójú tó àwọn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Síwájú sí i, ìtẹ̀síwájú mìíràn tún wáyé ní nǹkan bí ọdún méjì sẹ́yìn. Àtúnṣe kan wáyé nípa àwọn tí yóò máa jẹ́ olùdarí àwọn àjọ kan tí à ń lò lábẹ́ òfin. Èyí á sì mú kí Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso lè túbọ̀ pọkàn pọ̀ sórí ire tẹ̀mí àwọn èèyàn Ọlọ́run, láìsí pé àwọn ọ̀ràn ojoojúmọ́ tó jẹ mọ́ òfin ń pín ọkàn wọn níyà.
11. Ta ló wà nídìí àwọn àyípadà tó ń wáyé nínú ìṣètò láàárín àwọn èèyàn Jèhófà, kí sì ni àyípadà wọ̀nyí ti yọrí sí?
11 Ta ní ń bẹ nídìí àyípadà dáadáa tó ń wáyé wọ̀nyí? Jèhófà Ọlọ́run ni o. Òun ló sọ pé: “Èmi yóò mú wúrà wá.” Òun ló tún sọ pé: “Èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ló ń darí àwọn èèyàn rẹ̀. Ìtẹ̀síwájú tá a sọ tẹ́lẹ̀ nínú ìṣètò àwọn nǹkan jẹ́ ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà ń gbà bu ẹwà kún àwọn èèyàn rẹ̀. Ìyẹn sì ti já sí ọ̀pọ̀ ìbùkún fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Aísáyà 60:18 kà pé: “A kì yóò gbọ́ ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ, a kì yóò gbọ́ ìfiṣèjẹ tàbí ìwópalẹ̀ ní ààlà rẹ. Dájúdájú, ìwọ yóò sì pe àwọn ògiri rẹ ní Ìgbàlà àti àwọn ẹnubodè rẹ ní Ìyìn.” Ìyẹn ti lọ wà jù! Àmọ́ báwo ló ṣe ń ní ìmúṣẹ?
12. Báwo ni àlàáfíà ṣe ń jọba láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́?
12 Ojú Jèhófà làwọn Kristẹni tòótọ́ ń wò nígbà gbogbo fún ìtọ́ni àti ìtọ́sọ́nà. Ó sì ti yọrí sí ohun tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀, pé: “Gbogbo ọmọ rẹ yóò sì jẹ́ àwọn tí a kọ́ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò sì pọ̀ yanturu.” (Aísáyà 54:13) Síwájú sí i, ẹ̀mí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ lára àwọn èèyàn rẹ̀, ara èso ẹ̀mí yẹn sì ni àlàáfíà. (Gálátíà 5:22, 23) Àlàáfíà tó jọba láàárín àwọn èèyàn Jèhófà mú kí wọ́n di ibi ìtura láàárín ayé oníwà ipá yìí. Ipò àlàáfíà tí wọ́n wà, èyí tá a gbé ka ìfẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ ní láàárín ara wọn, jẹ́ àpẹẹrẹ irú ìgbé-ayé tí yóò wà nínú ayé tuntun. (Jòhánù 15:17; Kólósè 3:14) Ó dájú pé olúkúlùkù wa yóò fẹ́ gidigidi láti gbádùn àlàáfíà yẹn, ká sì mú kí ó máa pọ̀ sí i, nítorí pé àlàáfíà yìí ń mú ìyìn àti ọlá wá fún Ọlọ́run wa, ó sì jẹ́ kòṣeémánìí nínú Párádísè wa tẹ̀mí!—Aísáyà 11:9.
Ìmọ́lẹ̀ Jèhófà Yóò Máa Tàn Nìṣó
13. Ìdánilójú wo la ní pé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà kò ní yéé tàn sára àwọn èèyàn rẹ̀?
13 Ǹjẹ́ ìmọ́lẹ̀ Jèhófà yóò máa tàn sára àwọn èèyàn rẹ̀ nìṣó? Bẹ́ẹ̀ ni o! Aísáyà 60:19, 20 kà pé: “Oòrùn kì yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ mọ́ ní ọ̀sán, òṣùpá pàápàá kì yóò sì fún ọ ní ìmọ́lẹ̀ mọ́ fún ìtànyòò. Jèhófà yóò sì di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ, Ọlọ́run rẹ yóò sì di ẹwà rẹ. Oòrùn rẹ kì yóò wọ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òṣùpá rẹ kì yóò wọ̀ọ̀kùn; nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò di ìmọ́lẹ̀ tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin fún ọ, àwọn ọjọ́ ọ̀fọ̀ rẹ yóò sì parí dájúdájú.” Gbàrà tí àkókò “ọ̀fọ̀” àwọn ìgbèkùn tẹ̀mí dópin lọ́dún 1919 ni ìmọ́lẹ̀ Jèhófà ti bẹ̀rẹ̀ sí í tàn sára wọn. Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọgọ́rin [80] ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n ṣì ń gbádùn ojú rere Jèhófà bí ìmọ́lẹ̀ ṣe ń tàn nìṣó. Kò sì ní yéé tàn. Ní ti àwọn olùjọsìn rẹ̀, Ọlọ́run wa kò ní “wọ̀” bí oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ní “wọ̀ọ̀kùn” bí òṣùpá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ yóò máa tàn sí wọn lára títí ayé. Ọ̀rọ̀ yìí mà fi wá lọ́kàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ o, bí a ṣe ń gbé ní àkókò òpin ayé tó ṣókùnkùn yìí!
14, 15. (a) Lọ́nà wo ni gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run gbà jẹ́ “olódodo”? (b) Gẹ́gẹ́ bí ìwé Aísáyà 60:21 ti wí, ìmúṣẹ pàtàkì wo làwọn àgùntàn mìíràn ń wọ̀nà fún?
14 Tún wá gbọ́ ìlérí mìíràn tí Jèhófà ṣe nípa Ísírẹ́lì Ọlọ́run tó jẹ́ aṣojú Síónì lórí ilẹ̀ ayé. Aísáyà 60:21 sọ pé: “Ní ti àwọn ènìyàn rẹ, gbogbo wọn yóò jẹ́ olódodo; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò fi ilẹ̀ náà ṣe ìní, èéhù tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, kí a lè ṣe mí lẹ́wà.” Lọ́dún 1919, nígbà táwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tún padà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu, wọ́n wá yàtọ̀ léèyàn. Nínú ayé ẹlẹ́ṣẹ̀ paraku yìí, a ti “polongo wọn ní olódodo” nítorí ìgbàgbọ́ tó dúró sán-ún tí wọ́n ní nínú ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù. (Róòmù 3:24; 5:1) Lẹ́yìn náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó dé láti ìgbèkùn Bábílónì, wọ́n dẹni tó ni “ilẹ̀” kan, ìyẹn ilẹ̀ tẹ̀mí, tàbí àgbègbè ìgbòkègbodò, níbi tí wọn yóò ti máa gbádùn párádísè tẹ̀mí. (Aísáyà 66:8) Ẹwà ilẹ̀ yẹn tí kò yàtọ̀ sí ti Párádísè kò ní ṣá láé, nítorí pé Ísírẹ́lì Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, kò ní di aláìṣòótọ́ rárá, bí Ísírẹ́lì àtijọ́. Ìgbàgbọ́ wọn, ìfaradà wọn àti ìtara wọn nínú mímú ọlá bá orúkọ Ọlọ́run kò ní jó rẹ̀yìn láé.
15 Gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí yẹn ló wà nínú májẹ̀mú tuntun. Gbogbo wọn ni a kọ òfin Jèhófà sí ọkàn wọn. Jèhófà sì ti dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n nítorí ẹbọ ìràpadà Jésù. (Jeremáyà 31:31-34) Ó polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí “ọmọ,” ó sì ń bá wọn lò bíi pé wọ́n ti di ẹni pípé. (Róòmù 8:15, 16, 29, 30) Àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn pẹ̀lú ti rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, lọ́lá ẹbọ Jésù. Bíi ti Ábúráhámù, a ti polongo àwọn náà ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run nípasẹ̀ ìgbàgbọ́. “Wọ́n . . . ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Àwọn àgùntàn mìíràn wọ̀nyí tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn tún ń fojú sọ́nà fún ìbùkún yàbùgà-yabuga mìíràn. Lẹ́yìn líla “ìpọ́njú ńlá” já tàbí lẹ́yìn tá a bá jí wọn dìde, Wọn yóò fi ojúyòójú wọn rí ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 60:21, nígbà tí gbogbo ilẹ̀ ayé bá di Párádísè. (Ìṣípayá 7:14; Róòmù 4:1-3) Nígbà yẹn, “àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11, 29.
Ìbísí Náà Ń Bá A Nìṣó
16. Ìlérí tó gbámúṣé wo ni Jèhófà ṣe, báwo ló sì ṣe ní ìmúṣẹ?
16 Ẹsẹ tó gbẹ̀yìn Aísáyà orí ọgọ́ta sọ nípa ìlérí ìkẹyìn tí Jèhófà ṣe. Ó sọ fún Síónì pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísáyà 60:22) Jèhófà ti mú ìlérí yìí ṣẹ ní ọjọ́ wa. Nígbà tá a mú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró padà sẹ́nu ìgbòkègbodò lọ́dún 1919, wọ́n kéré níye, wọ́n jẹ́ “ẹni tí ó kéré” lóòótọ́. Iye wọn bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ sí i bó ṣe di pé à ń kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí wọlé wá sí i, tí àwọn àgùntàn mìíràn sì bẹ̀rẹ̀ sí rọ́ wá sọ́dọ̀ wọn ní iye púpọ̀ sí i. Àlàáfíà àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyẹn párádísè tẹ̀mí tí ń bẹ ní “ilẹ̀” wọn, ti mú kí ọ̀pọ̀ olóòótọ́ ọkàn dara pọ̀ mọ́ wọn débi pé “ẹni kékeré” wá di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè” lóòótọ́. Ní báyìí, “orílẹ̀-èdè” náà—ìyẹn Ísírẹ́lì Ọlọ́run àti iye tó ju mílíọ̀nù mẹ́fà “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” tó ti yara wọn sí mímọ́—pọ̀ ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó dá wà láyè ara wọn. (Aísáyà 60:10) Gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ló ń kópa nínú gbígbé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà yọ, ìyẹn sì mú kí gbogbo wọ́n lẹ́wà lójú rẹ̀.
17. Ipa wo ni ìjíròrò lórí Aísáyà orí ọgọ́ta yìí ti ní lórí rẹ?
17 Láìsí àní-àní, bí a ṣe gbé àwọn kókó pàtàkì inú ìwé Aísáyà orí ọgọ́ta yẹ̀ wò ti fún ìgbàgbọ́ wa lókun. Ó ń tuni nínú láti rí i pé tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti mọ̀ pé àwọn èèyàn òun máa lọ sígbèkùn tẹ̀mí, tí wọ́n á sì padà bọ̀. Ó jẹ́ ohun àgbàyanu lójú wa láti mọ̀ pé tipẹ́tipẹ́ ni Jèhófà ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìbísí ńláǹlà nínú iye àwọn olùjọsìn tòótọ́ ní àkókò tiwa. Kò mọ síbẹ̀ o, ẹ wo bó ṣe ń tuni nínú tó láti rántí pé Jèhófà kò ní fi wá sílẹ̀! Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ ìdánilójú náà ti fìfẹ́ hàn tó, pé àwọn ẹnubodè “ìlú” náà yóò wà ní ṣíṣí sílẹ̀ kí “àwọn tí wọ́n . . . ní ìtẹ̀sí-ọkàn títọ́ fún ìyè àìnípẹ̀kun” lè gba ibẹ̀ wọlé wọ́ọ́rọ́wọ́. (Ìṣe 13:48) Jèhófà kò ní yéé tànmọ́lẹ̀ sára àwọn èèyàn rẹ̀. Síónì yóò máa bá a nìṣó ní jíjẹ́ ohun ìyangàn bí àwọn ọmọ rẹ̀ ti ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wọn túbọ̀ mọ́lẹ̀ yòò. (Mátíù 5:16) Láìsí àní-àní, ìpinnu àìyẹsẹ̀ wa ni pé a óò dúró gbágbáágbá ti Ísírẹ́lì Ọlọ́run, a ó sì máa fojú ribiribi wo àǹfààní tá a ní láti máa gbé ìmọ́lẹ̀ Jèhófà yọ!
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ìdánilójú wo la ní bá a bá dojú kọ àtakò?
• Báwo làwọn ọmọ Síónì ṣe “fa wàrà àwọn orílẹ̀-èdè mu”?
• Ní àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ‘mú bàbà wá dípò igi’?
• Àwọn ànímọ́ méjì wo la mẹ́nu kàn nínú Aísáyà 60:17, 21?
• Báwo ni “ẹni kékeré” ṣe di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè”?
[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
ÀSỌTẸ́LẸ̀ AÍSÁYÀ—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé
Inú àsọyé kan nígbà Àpéjọ Àgbègbè “Àwọn Olùkọ́ni Ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” tó wáyé lọ́dún 2001 sí 2002 la ti mú àwọn ìsọfúnni tó wà nínú àwọn àpilẹ̀kọ yìí jáde. Ní àwọn àpéjọ tó pọ̀ jù lọ, nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó mú ìwé tuntun kan jáde tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì. Ọdún tó ṣáájú la mú Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní jáde. Pẹ̀lú ìtẹ̀jáde tuntun yìí, a ti ní ìsọfúnni tó gún régé lọ́wọ́ báyìí, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ kárí gbogbo ẹsẹ tó wà nínú ìwé Aísáyà. Ìwé méjèèjì yìí ń ràn wá lọ́wọ́ gidigidi láti mú òye wa àti ìmọrírì wa jinlẹ̀ sí i fún ìwé Aísáyà tó kún fún àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ń gbé ìgbàgbọ́ ró.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
‘Jèhófà fi ìgbàlà bu ẹwà kún àwọn èèyàn rẹ̀’ lójú àtakò rírorò
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Àwọn èèyàn Ọlọ́run ń fi ohun àmúṣọrọ̀ láti inú àwọn orílẹ̀-èdè gbé ìjọsìn mímọ́ ga
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jèhófà ti fi ìtẹ̀síwájú nínú ìṣètò àti àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀