Títẹ̀síwájú Sí Ìṣẹ́gun Ìkẹyìn!
“Wò ó! ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ sì ní ọrun kan; a sì fún un ní adé, ó sì jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”—ÌṢÍPAYÁ 6:2.
1. Kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ iwájú tí Jòhánù rí nínú ìran?
NÍPASẸ̀ ìmísí Ọlọ́run, ó ṣeé ṣe fún àpọ́sítélì Jòhánù láti ríran dé nǹkan bí ẹgbẹ̀sán [1,800] ọdún sí ọjọ́ iwájú, ó sì ṣàpèjúwe gbígbé tí a gbé Kristi gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ọba. Jòhánù nílò ìgbàgbọ́ láti gbà pé ohun tí òun rí nínú ìran yóò nímùúṣẹ. Àwa táa wà láyé lóde òní rí ẹ̀rí ìdánilójú pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa gbígbé Jésù gorí ìtẹ́ yìí wáyé ní 1914. Pẹ̀lú ojú ìgbàgbọ́, a rí Jésù Kristi tó ń “jáde lọ ní ṣíṣẹ́gun àti láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”
2. Kí ni Èṣù ṣe nígbà ìbí Ìjọba náà, ẹ̀rí wo sì ni èyí jẹ́?
2 Lẹ́yìn ìbí Ìjọba náà, a lé Sátánì jáde ní ọ̀run, tó mú kó túbọ̀ jà fitafita pẹ̀lú ìbínú tó gbóná janjan, àmọ́ kò sí ọ̀nà fún un mọ́ láti kẹ́sẹ járí. (Ìṣípayá 12:7-12) Ìbínú rẹ̀ ti mú kí ipò nǹkan túbọ̀ burú sí i lórí ilẹ̀ ayé. Ó jọ pé àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ń pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Lójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Ọba wọn ń tẹ̀ síwájú “láti parí ìṣẹ́gun rẹ̀.”
Ọmọ Ẹgbẹ́ Ayé Tuntun Ń Kóra Jọ
3, 4. (a) Àwọn ìyípadà wo ló ti wáyé lórí báa ṣe ń ṣètò nǹkan nínú ìjọ Kristẹni láti ìgbà ìbí Ìjọba náà, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi pọndandan? (b) Kí làǹfààní àwọn ìyípadà wọ̀nyí, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀?
3 Gbàrà tí a bí Ìjọba náà, ó tó àkókò láti mú kí ìjọ Kristẹni tí a rà padà—tó ní àlékún ẹrù iṣẹ́ Ìjọba náà nísinsìnyí—jẹ́ èyí tó wà ní ìbámu tímọ́tímọ́ pẹ̀lú bí nǹkan ṣe rí nínú ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Nípa bẹ́ẹ̀, nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti June 1 àti 15, 1938 (Gẹ̀ẹ́sì), a ṣàyẹ̀wò bó ṣe yẹ kí ìjọ Kristẹni máa ṣiṣẹ́. Lẹ́yìn náà, ìtẹ̀jáde ti June 1, 1972, túbọ̀ ṣàlàyé Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti òde òní nínú àpilẹ̀kọ náà “Ẹgbẹ Alakoso kan ni Iyatọ si Ẹgbẹ Kan Ti A Gbekalẹ Lọna Ofin.” Ní 1972, a bẹ̀rẹ̀ sí yan ẹgbẹ́ àwọn alàgbà láti máa ṣèrànwọ́ kí wọ́n sì máa darí àwọn ìjọ àdúgbò.
4 Ṣíṣe àtúnṣe nínú báa ṣe ń ṣe àbójútó fún ìjọ Kristẹni lókun gan-an. Ohun mìíràn tó tún fún ìjọ lókun ni ètò tí Ẹgbẹ́ Alákòóso ṣe láti fún àwọn alàgbà nítọ̀ọ́ni lórí bí wọn ó ṣe máa ṣe àwọn ojúṣe wọn, títí kan dídá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́. Àwọn ìmúsunwọ̀n sí i tó ń wáyé nínú ètò Ọlọ́run ti orí ilẹ̀ ayé àti àwọn àbájáde rere tó ń tìdí rẹ̀ yọ, ni a sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nínú Aísáyà 60:17 pé: “Dípò bàbà, èmi yóò mú wúrà wá, àti dípò irin, èmi yóò mú fàdákà wá, àti dípò igi, bàbà, àti dípò àwọn òkúta, irin; dájúdájú, èmi yóò sì yan àlàáfíà ṣe àwọn alábòójútó rẹ àti òdodo ṣe àwọn tí ń pínṣẹ́ fún ọ.” Àwọn ìyípadà rere wọ̀nyí fi ìbùkún Ọlọ́run hàn, ó sì ń fi hàn pé Ọlọ́run tẹ́wọ́ gba àwọn tó wá fìtara ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba rẹ̀.
5. (a) Kí ni Sátánì ṣe nígbà tó rí ìbùkún Jèhófà lórí àwọn ènìyàn Rẹ̀? (b) Ní ìbámu pẹ̀lú Fílípì 1:7, kí làwọn èèyàn Jèhófà ṣe nípa ìbínú Sátánì?
5 Gbogbo àfiyèsí onífẹ̀ẹ́ àti ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́yìn ìbí Ìjọba náà ni Sátánì ń kíyè sí. Fún àpẹẹrẹ, ní 1931, ẹgbẹ́ kékeré ti àwọn Kristẹni yìí kéde ní gbangba pé àwọn kì í wulẹ̀ ṣe Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lásán. Ní ìbámu pẹ̀lú Aísáyà 43:10, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n! Yálà ó kàn bọ́ sí àsìkò yẹn ni o, tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣe ni Èṣù gbé inúnibíni tí a kò rí irú rẹ̀ rí dìde sí wọn jákèjádò ayé. Kódà láwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti lómìnira ìsìn, irú bí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Kánádà, àti Jámánì, ọ̀pọ̀ ìgbà ló di dandan fún àwọn Ẹlẹ́rìí láti jà fitafita nílé ẹjọ́ kí wọ́n má bàa pàdánù òmìnira tí wọ́n ní láti jọ́sìn. Nígbà tó fi máa di 1988, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ṣàgbéyẹ̀wò ẹjọ́ mọ́kànléláàádọ́rin tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tó jẹ́ pé ìdá méjì nínú ìdá mẹ́ta rẹ̀ la ti dá wọn láre. Lóde òní, jákèjádò ayé ni a ti ń gbé ẹjọ́ lọ sílé ẹjọ́ kí “gbígbèjà àti fífi ìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin” lè wà bíi ti ọ̀rúndún kìíní.—Fílípì 1:7.
6. Ǹjẹ́ ìfòfindè àti ìkálọ́wọ́kò dí ìtẹ̀síwájú àwọn ènìyàn Jèhófà lọ́wọ́? Ṣàpèjúwe.
6 Ní àwọn ọdún 1930, láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn ìjọba bóofẹ́-bóokọ̀ fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Jámánì, Sípéènì, àti Japan, ká mẹ́nu kan mẹ́ta péré nínú wọn. Àmọ́, ní ọdún 2000, àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́ta wọ̀nyí nìkan ní nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [500,000] àwọn tó ń pòkìkí Ìjọba Ọlọ́run déédéé. Ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ìlọ́po mẹ́wàá iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní gbogbo ayé ní 1936! Ó ṣe kedere pé ìfòfindè àti ìkálọ́wọ́kò kò lè ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú àwọn ènìyàn Jèhófà lábẹ́ Jésù Kristi, Aṣáájú wọn tó jẹ́ aṣẹ́gun.
7. Kí ni ohun àrà ọ̀tọ̀ tó ṣẹlẹ̀ ní 1958, kí sì ni ìyípadà pípabanbarì tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà yẹn?
7 Ẹ wo bí ẹ̀rí ìtẹ̀síwájú yìí ṣe hàn kedere nígbà tó di 1958, tí wọ́n ṣe àpéjọpọ̀ tó tóbi jù lọ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tíì ṣe rí ní New York City, ìyẹn ni Ìpàdé Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá, tí àwọn tó pésẹ̀ síbẹ̀ lọ́jọ́ térò pọ̀ jù lọ jẹ́ ẹgbàá mẹ́tàdínláàádóje dín méjìdínlọ́gọ́rin [253,922]. Nígbà tó fi máa di 1970, wọ́n ti fàyè gba iṣẹ́ wọn ní orílẹ̀-èdè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta táa mẹ́nu kàn lókè yìí, àyàfi ní ibi tí wọ́n ń pè ní Ìlà Oòrùn Jámánì nígbà yẹn. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí ṣì wà lábẹ́ ìfòfindè ní Soviet Union àti láwọn orílẹ̀-èdè alájọṣepọ̀ rẹ̀ nínú Àdéhùn Warsaw. Lóde òní, láwọn ibi tó jẹ́ orílẹ̀-èdè Kọ́múníìsì tẹ́lẹ̀ wọ̀nyí, àwọn tó lé ní ìdajì mílíọ̀nù Ẹlẹ́rìí tó ń ṣe déédéé ló wà níbẹ̀ báyìí.
8. Kí ló ti jẹ́ àbájáde ìbùkún Jèhófà lórí àwọn èèyàn rẹ̀, kí sì ni Ile-Iṣọ Na ti 1950 ní í sọ nípa èyí?
8 A ti fi ìbísí jíǹkí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí pé wọ́n ń bá a lọ “ní wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.” (Mátíù 6:33) Ní ti gidi, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ti nímùúṣẹ pé: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísáyà 60:22) Ìbísí náà kò sì tíì dópin. Ní ẹ̀wádún tó kọjá yìí nìkan ṣoṣo, iye àwọn alágbàwí Ìjọba náà fi ohun tó lé ní mílíọ̀nù kan, ọ̀kẹ́ mẹ́tàdínlógójì ó lé ẹgbàárùn-ún [1,750,000] ènìyàn pọ̀ sí i. Àwọn wọ̀nyí ti fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn láti di ara ẹgbẹ́ tí Ile-Iṣọ Na ti 1950 sọ ọ̀rọ̀ yìí nípa wọn pé: “Ọlọ́run ti ń kó àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ayé tuntun jọ báyìí. . . . Àwọn tó jẹ́ ìpìlẹ̀ yìí yóò la Amágẹ́dọ́nì já, . . . àwọn ni yóò jẹ́ àkọ́kọ́ nínú ‘ayé tuntun’ náà . . . , àwọn tí a ṣètò lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run, níwọ̀n bí wọ́n ti mọ̀ nípa àwọn ìlànà báa ṣe ń ṣètò nǹkan.” Àpilẹ̀kọ náà parí báyìí pé: “Nípa báyìí, kí gbogbo wa lápapọ̀ máa tẹ̀ síwájú láìyẹsẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ ayé tuntun!”
9. Báwo ni ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ bí ọdún ti ń gorí ọdún ṣe ṣàǹfààní?
9 Bí àkókò ti ń lọ, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ayé tuntun tó ń tẹ̀ síwájú yìí ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe ń ṣe nǹkan létòlétò àti lọ́nà tó gbéṣẹ́, èyí tó wúlò gidigidi lóde òní, tó sì ṣeé ṣe kó tún wúlò gan-an nígbà iṣẹ́ ìmúbọ̀sípò lẹ́yìn Amágẹ́dónì. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Ẹlẹ́rìí ti kọ́ bí a ṣe ń ṣètò àwọn àpéjọpọ̀ ńlá, bí a ṣe ń fi àwọn ohun àfiṣèrànwọ́ ránṣẹ́ ní pàjáwìrì, àti bí a ṣe ń yára kọ́lé. Ìgbòkègbodò yìí ti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kan sáárá sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ti mú kí wọ́n bọ̀wọ̀ fún wọn pẹ̀lú.
Títún Àwọn Èrò Òdì Ṣe
10, 11. Ṣàpèjúwe bí èrò òdì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe di èyí tí a tún ṣe.
10 Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan wà tí wọ́n ń fẹ̀sùn kan àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé wọn ò bẹ́gbẹ́ mu. Olórí ohun tó sì fà á ni ipò tó bá Bíbélì mu táwọn Ẹlẹ́rìí dì mú lórí àwọn ọ̀ràn bí ìfàjẹ̀sínilára, àìdásí-tọ̀túntòsì, sìgá mímu, àti ìwà rere. Àmọ́, àwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí gbà báyìí pé ojú ìwòye àwọn Ẹlẹ́rìí kò ṣeé fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn. Fún àpẹẹrẹ, dókítà kan ní Poland tẹ ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láago, ó sì sọ pé òun àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn náà ti ń jiyàn lórí ọ̀ràn nípa ìfàjẹ̀sínilára fún wákàtí bíi mélòó kan. Ohun tó fa ìjíròrò náà ni àpilẹ̀kọ kan tó jáde nínú ìwé ìròyìn Dziennik Zachodni ní èdè Polish lọ́jọ́ yẹn. Dókítà náà sọ pe: “Ó ń dun èmi gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan pé a ti ń lo ẹ̀jẹ̀ jù nínú ọ̀ràn ìṣègùn. Èyí gbọ́dọ̀ yí padà, inú mi sì dùn pé àwọn kan ti mú kókó yẹn wá sójútáyé. Inú mi yóò dùn láti gba ìsọfúnni sí i.”
11 Níbi àpérò kan tí wọ́n ṣe lọ́dún tó kọjá, àwọn lọ́gàálọ́gàá nínú iṣẹ́ ìṣègùn láti Ísírẹ́lì, Kánádà, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àti Yúróòpù jíròrò àwọn ìsọfúnni tí wọ́n ṣe láti fi ran àwọn dókítà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa tọ́jú àwọn aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀. Wọ́n tọ́ka sí i níbí ìpàdé yìí, tí wọ́n ṣe ní Switzerland pé, ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń rò, iye àwọn tó ń kú nínú àwọn aláìsàn tó gbẹ̀jẹ̀ sára pọ̀ gan-an ju iye àwọn tó ń kú nínú àwọn aláìsàn tí kò gbẹ̀jẹ̀ sára. Àwọn aláìsàn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí tètè máa ń kúrò ní ọsibítù ṣáájú àwọn tó gbẹ̀jẹ̀ sára, èyí sì máa ń dín iye owó tí wọ́n ń san fún ìtọ́jú kù.
12. Fúnni ní àpẹẹrẹ bí àwọn kan tó jẹ́ lóókọlóókọ ṣe gbóríyìn fún ìdúró tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú nítorí àìdásí-tọ̀túntòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú.
12 Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ rere làwọn èèyàn ti sọ nípa bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ṣe dá sí tọ̀túntòsì ṣáájú àti lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì nígbà tí wọ́n fara da ìwà ìkà ìjọba Násì. Fídíò náà, Jehovah’s Witnesses Stand Firm Against Nazi Assault, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, táa sì kọ́kọ́ gbé jáde lọ́nà tó bá a mu ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück tó wà ní Jámánì ní November 6, 1996, ti mú kí àwọn èèyàn sọ ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ìyìn. Nígbà tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ irú ètò yẹn ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan tó burú jáì ní Bergen-Belsen, ní April 18, 1998, Ọ̀mọ̀wé Wolfgang Scheel tó jẹ́ olùdarí Ibùdó fún Ẹ̀kọ́ Ìṣèlú ní Lower Saxony sọ pé: “Ọ̀kan nínú òtítọ́ tí ń tini lójú nínú ìtàn ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ta kété sí Ìjọba Násì pẹ̀lú ìpinnu tó lágbára ju bí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kristẹni ti ṣe. . . . Bó ti wù kí ẹ̀kọ́ àti ìtara ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí lára wa, síbẹ̀ ìdúróṣinṣin wọn nígbà ìjọba Násì tó ohun tó fi yẹ ká bọ̀wọ̀ fún wọn.”
13, 14. (a) Àkíyèsí rere wo nípa àwọn Kristẹni ìjímìjí ló wá láti orísun kan tí wọn kò retí? (b) Fúnni láwọn àpẹẹrẹ ọ̀rọ̀ rere táwọn èèyàn ti sọ nípa àwọn èèyàn Ọlọ́run lóde òní.
13 Nígbà táwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn tàbí ilé ẹjọ́ bá gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí àwọn ọ̀ràn tó ń fa àríyànjiyàn, ó lè jẹ́ kí ẹ̀tanú táwọn èèyàn ní sí wọn dín kù, kí wọ́n sì wá túbọ̀ máa fojú tó dára wo àwọn Ẹlẹ́rìí. Èyí sábà máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti bá àwọn kan tí kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ wọn rárá tẹ́lẹ̀ sọ̀rọ̀. Nítorí náà, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dùn sí irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì mọrírì rẹ̀ gidigidi. Èyí rán wa létí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní. Nígbà tí Sànhẹ́dírìn, ilé ẹjọ́ gíga ti àwọn Júù fẹ́ pa àwọn Kristẹni nítorí pé wọ́n ń fìtara wàásù, Gàmálíẹ́lì “olùkọ́ Òfin tí gbogbo ènìyàn kà sí,” kìlọ̀ fún wọn, ó ní “Ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì, ẹ kíyè sí ara yín ní ti ohun tí ẹ ń pète-pèrò láti ṣe nípa àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. . . . Ẹ má tojú bọ ọ̀ràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ wọn jẹ́ẹ́; (nítorí pé, bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni ìpètepèrò tàbí iṣẹ́ yìí ti wá, a ó bì í ṣubú; ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kì yóò lè bì wọ́n ṣubú;) bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a lè wá rí yín ní ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà ní ti gidi.”—Ìṣe 5:33-39.
14 Bíi ti Gàmálíẹ́lì, àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn ti fìgboyà sọ̀rọ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé kí wọ́n fi àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́rùn sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, alága fún Ilé Ẹ̀kọ́ Òmìnira àti Ìgbàgbọ́ Ìsìn Kárí Ayé tẹ́lẹ̀ sọ pé: “A ò gbọ́dọ̀ fi ẹ̀tọ́ ìsìn du ètò ẹ̀sìn kan kìkì nítorí pé àwọn èèyàn ka ìgbàgbọ́ irú ìsìn bẹ́ẹ̀ sí èyí tí kò bójú mu tàbí tí kò bá ìgbàgbọ́ àwọn tó kù mu.” Bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn lọ́nà tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu ní yunifásítì Leipzig gbé ìbéèrè pàtàkì kan dìde sí ìgbìmọ̀ kan tí ìjọba Jámánì gbé kalẹ̀ láti ṣèwádìí àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n pé ní ẹ̀ya ẹ̀sìn, pé: “Èé ṣe tó fi jẹ́ pé kìkì àwọn ẹ̀sìn tí kò fí bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ ni wọ́n ṣèwádìí rẹ̀ àmọ́ tí wọn ò wádìí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ńlá méjèèjì [Ṣọ́ọ̀ṣì Roman Kátólíìkì àti Ìjọ Lutheran]?” A lè rí ìdáhùn sí èyí nínú ọ̀rọ̀ aláṣẹ kan ní ilẹ̀ Jámánì tẹ́lẹ̀, tó kọ̀wé pé: “Kò sí àní-àní pé àwọn agbawèrèmẹ́sìn inú ṣọ́ọ̀ṣì ló pinnu ipa ọ̀nà ìṣèlú tí ìgbìmọ̀ tí ìjọba gbé kalẹ̀ náà ń tọ̀.”
Ta Là Ń Wò fún Ìrànwọ́?
15, 16. (a) Èé ṣe tí ìgbésẹ̀ Gàmálíẹ́lì kò fi yanjú gbogbo ìṣòro náà? (b) Èé ṣe tí ìrànlọ́wọ́ táwọn lóókọlóókọ mẹ́ta mìíràn ṣe fún Jésù fi ní ààlà?
15 Ohun tí Gàmálíẹ́lì sọ wulẹ̀ fi kókó pàtàkì náà hàn ni, pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run bá tì lẹ́yìn kò lè kùnà láé. Ó dájú pé àwọn Kristẹni ìjímìjí jàǹfààní nínú ọ̀rọ̀ tó bá Sànhẹ́dírìn sọ, àmọ́ wọn ò gbàgbé pé ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa bí a ó ṣe máa ṣe inúnibíni sí àwọn ọmọlẹ́yìn òun tún jẹ́ òtítọ́. Ìgbésẹ̀ tí Gàmálíẹ́lì gbé fòpin sí ìpètepèrò àwọn aṣáájú ìsìn láti pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn, àmọ́ ìyẹn ò wá fòpin sí gbogbo inúnibíni náà o, nítorí a kà á pé: “Wọ́n sì fi ọlá àṣẹ pe àwọn àpọ́sítélì, wọ́n nà wọ́n lẹ́gba, wọ́n sì pa àṣẹ fún wọn pé kí wọ́n dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa orúkọ Jésù, wọ́n sì jẹ́ kí wọ́n lọ.”—Ìṣe 5:40.
16 Nígbà tí wọ́n ń gbẹ́jọ́ Jésù, tí Pọ́ńtíù Pílátù kò rí ẹ̀bi kankan kà sí i lọ́rùn, ó gbìyànjú láti dá Jésù sílẹ̀. Àmọ́, kò rí i ṣe. (Jòhánù 18:38, 39; 19:4, 6, 12-16) Kódà ìwọ̀nba díẹ̀ ni ohun tí àwọn mẹ́ńbà méjì nínú Sànhẹ́dírìn náà, ìyẹn Nikodémù àti Jósẹ́fù Arimatíà, tí wọ́n fojú rere hàn sí Jésù, lè ṣe láti máà jẹ́ kí ilé ẹjọ́ náà gbé ìgbésẹ̀ kankan lòdì sí Jésù. (Lúùkù 23:50-52; Jòhánù 7:45-52; 19:38-40) Ohun yòówù kó jẹ́ ìdí táwọn èèyàn fi ń gbèjà àwọn èèyàn Jèhófà, ìwọ̀nba ni ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n lè ṣe. Ayé kò ní dẹ́kun àtimáa kórìíra àwọn tó jẹ ọmọlẹ́yìn tòótọ́ fún Kristi, àní bí wọ́n ṣe kórìíra òun fúnra rẹ̀. Ọ̀dọ̀ Jèhófà nìkan ṣoṣo ni ìrànlọ́wọ́ tó kún rẹ́rẹ́ ti lè wá.—Ìṣe 2:24.
17. Ojú tó bọ́gbọ́n mu wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wo ọ̀ràn náà, àmọ́ èé ṣe tí wọn ò fi juwọ́ sílẹ̀ nínú ìpinnu wọn láti máa bá wíwàásù ìhìn rere náà nìṣó?
17 Ká sọ̀rọ̀ síbi tí ọ̀rọ̀ wà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà retí pé kí inúnibíni máa bá a nìṣó. Kìkì ìgbà tí ètò Sátánì bá di èyí táa ṣẹ́gun pátápátá ni àtakò lè dópin. Síbẹ̀, inúnibíni yìí, bí kò tilẹ̀ múnú ẹni dùn, kò ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí jáwọ́ nínú mímú àṣẹ táa pa fún wọn láti wàásù Ìjọba náà ṣẹ. Báwo ló ṣe lè mú wọn jáwọ́, nígbà tí wọ́n ní ìtìlẹ́yìn Ọlọ́run? Wọ́n ń wo Aṣáájú wọn onígboyà nì, Jésù Kristi, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tó dára jù lọ.—Ìṣe 5:17-21, 27-32.
18. Ìṣòro wo ló ṣì wà níwájú fún àwọn ènìyàn Jèhófà, àmọ́ àbájáde wo ló dá wọn lójú?
18 Láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ni ìsìn tòótọ́ ti dojú kọ àtakò líle koko. Láìpẹ́, yóò jẹ́ olórí ohun tí Gọ́ọ̀gù, ìyẹn Sátánì táa ti rẹ̀ sílẹ̀ látìgbà táa ti lé e kúrò ní ọ̀run, yóò fi gbogbo agbára gbéjà kò. Àmọ́, ìsìn tòótọ́ yóò là á já. (Ìsíkíẹ́lì 38:14-16) “Àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” lábẹ́ ìdarí Sátánì, “yóò bá Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà jagun, ṣùgbọ́n, nítorí pé òun ni Olúwa àwọn olúwa àti Ọba àwọn ọba, Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà yóò ṣẹ́gun wọn.” (Ìṣípayá 16:14; 17:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, Ọba wa ti ń tẹ̀ síwájú lọ sí ìṣẹ́gun ìkẹyìn, yóò sì “parí ìṣẹ́gun rẹ̀” láìpẹ́. Ẹ wo àǹfààní ńlá tó jẹ́ láti máa bá a tẹ̀ síwájú, nígbà táa mọ̀ pé láìpẹ́ kò ní sí ẹnikẹ́ni tó tún máa tako àwọn olùjọsìn Jèhófà mọ́ nígbà tí wọ́n bá sọ pé: “Ọlọ́run . . . wà fún wa”!—Róòmù 8:31; Fílípì 1:27, 28.
Ṣé O Lè Ṣàlàyé?
• Kí ni Jèhófà ti ṣe láti fún ìjọ Kristẹni lókun látìgbà ìbí Ìjọba náà?
• Kí ni Sátánì ti ṣe láti dá Kristi dúró kí ó má lè parí ìṣẹ́gun rẹ̀, kí sì ni àbájáde rẹ̀?
• Kí ni ojú ìwòye tó wà déédéé tó yẹ ká ní nípa ìgbésẹ̀ rere tí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ń gbé?
• Kí ni Sátánì yóò ṣe láìpẹ́, kí ni yóò sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn àpéjọpọ̀ ń fi bí àwọn èèyàn Jèhófà ṣe ń tẹ̀ síwájú hàn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Àìdásí-tọ̀túntòsì àwọn Ẹlẹ́rìí nígbà Ogun Àgbáyé Kejì ṣì ń mú ìyìn bá Jèhófà