-
Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí AyéÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
29, 30. Báwo ni “ẹni tí ó kéré” ṣe ti di “ẹgbẹ̀rún”?
29 A rí ìlérí pàtàkì kan tí Jèhófà fi orúkọ ara rẹ̀ jẹ́rìí sí ní ìparí Aísáyà orí ọgọ́ta. Ó ní: “Ẹni tí ó kéré yóò di ẹgbẹ̀rún, ẹni kékeré yóò sì di alágbára ńlá orílẹ̀-èdè. Èmi tìkára mi, Jèhófà, yóò mú un yára kánkán ní àkókò rẹ̀.” (Aísáyà 60:22) Nígbà tí a dá àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n fọ́n ká padà sẹ́nu ìgbòkègbodò lọ́dún 1919, àwọn ni “ẹni tí ó kéré.”e Ṣùgbọ́n iye wọn wá di púpọ̀ sí i bí a ṣe ń kó ìyókù àwọn Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí wọlé wá. Ìbísí yẹn sì tún wá bùáyà bí kíkó àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá jọ ṣe bẹ̀rẹ̀.
30 Láìpẹ́ láìjìnnà, àlàáfíà àti òdodo tó wà láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọlọ́kàn mímọ́ mọ́ra débi pé “ẹni kékeré” wá di “alágbára ńlá orílẹ̀-èdè” ní ti gidi. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, iye wọ́n pọ̀ ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn orílẹ̀-èdè ayé tó dá wà láyè ara wọn lọ. Dájúdájú, Jèhófà ń lo Jésù Kristi láti fi darí iṣẹ́ Ìjọba náà, ó sì ti mú kó yára kánkán. Ó mà wúni lórí o láti rí i bí ìsìn tòótọ́ ṣe ń gbilẹ̀, tí a sì tún ń kópa níbẹ̀! Dájúdájú, ayọ̀ ló jẹ́ fúnni láti mọ̀ pé ìbísí yìí ń ṣe Jèhófà, ẹni tó ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nǹkan wọ̀nyí tipẹ́tipẹ́, lógo.
-
-
Ìsìn Tòótọ́ Gbilẹ̀ Kárí AyéÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
e Lọ́dún 1918, ìpíndọ́gba iye àwọn tó ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ọ̀rọ̀ náà lóṣooṣù kò tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin.
-