-
“Orúkọ Tuntun” KanÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
13, 14. (a) Láyé àtijọ́, báwo ni Jerúsálẹ́mù ṣe di ìlú tó jẹ́ ibi ààbò? (b) Lóde òní, báwo ni Síónì ṣe di “ìyìn ní ilẹ̀ ayé”?
13 Orúkọ ìṣàpẹẹrẹ tuntun tí Jèhófà sọ àwọn èèyàn rẹ̀ yìí ń mú kí wọ́n ní ìfọ̀kànbalẹ̀. Wọ́n mọ̀ pé ó tẹ́wọ́ gba àwọn, àti pé tirẹ̀ ni àwọn ń ṣe. Wàyí o, Jèhófà lo àpèjúwe mìíràn, ó bá àwọn èèyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ bíi pé wọ́n jẹ́ ìlú olódi, ó ní: “Èmi ti fàṣẹ yan àwọn olùṣọ́ sórí àwọn ògiri rẹ, ìwọ Jerúsálẹ́mù. Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ àti láti òru mọ́jú, nígbà gbogbo, kí wọ́n má ṣe dákẹ́ jẹ́ẹ́. Ẹ̀yin tí ń mẹ́nu kan Jèhófà, kí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ má ṣe sí níhà ọ̀dọ̀ yín, kí ẹ má sì fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ títí yóò fi fìdí Jerúsálẹ́mù sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, bẹ́ẹ̀ ni, títí yóò fi gbé e kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyìn ní ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 62:6, 7) Nígbà tó tákòókò lójú Jèhófà, lẹ́yìn tí àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ padà dé láti Bábílónì, Jerúsálẹ́mù di “ìyìn ní ilẹ̀ ayé” lóòótọ́, àní ìlú olódi tó jẹ́ ibi ààbò fún àwọn olùgbé ibẹ̀. Tọ̀sán tòru làwọn olùṣọ́ tó wà lórí àwọn ògiri rẹ̀ wà lójúfò láti rí i dájú pé ààbò wà fún ìlú yẹn àti láti lè ta àwọn aráàlú lólobó.—Nehemáyà 6:15; 7:3; Aísáyà 52:8.
14 Lóde òní, Jèhófà ti lo àwọn olùṣọ́ rẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró, láti fi tọ́ka ọ̀nà òmìnira kúrò nínú ìsìn èké fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Wọ́n sì ti ké sí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí wọ́n wá sínú ètò àjọ Jèhófà, níbi tí wọ́n ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn ohun tó ń sọni di àìmọ́ nípa tẹ̀mí, tí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ àkóràn àwọn àṣà tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, tí ìbínú Jèhófà kò sì sí lórí wọn. (Jeremáyà 33:9; Sefanáyà 3:19) Ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà, “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tó ń pèsè “oúnjẹ” nípa tẹ̀mí “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu,” ń kó ipa tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn ààbò yìí. (Mátíù 24:45-47) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí ń bá ẹgbẹ́ olùṣọ́ yìí ṣiṣẹ́ pọ̀ ń kó ipa pàtàkì pẹ̀lú ní mímú kí Síónì jẹ́ “ìyìn ní ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 7:9.
-
-
“Orúkọ Tuntun” KanÀsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kejì
-
-
16. Ọ̀nà wo ni àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò fi “fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́”?
16 A rọ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé kí wọ́n máa gbàdúrà láìdabọ̀, kí wọ́n máa bẹ Ọlọ́run pé kí ‘ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bíi ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’ (Mátíù 6:9, 10; 1 Tẹsalóníkà 5:17) A gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n: ‘Má ṣe fún Jèhófà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́’ títí tí yóò fi ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ àti ìrètí wọn, ìyẹn ni pé kí ìsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò. Jésù tẹnu mọ́ yíyẹ tó yẹ ká máa gbàdúrà lemọ́lemọ́, ó sì rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí “wọ́n ké jáde sí [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.”—Lúùkù 18:1-8.
-