Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Wa
NÍGBÀ tí àpọ́sítélì Pétérù ń sọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la ẹ̀dá èèyàn àti ti ayé, ó sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí [Ọlọ́run], nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Wòlíì Aísáyà ló kọ́kọ́ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun.” (Aísáyà 65:17; 66:22) Bí Pétérù ṣe sọ̀rọ̀ tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yìí fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ náà kò tíì ṣẹ tán pátápátá nígbà ayé rẹ̀.
Nígbà tó di nǹkan bí ọdún 96 Sànmánì Kristẹni, Ìṣípayá tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, fi hàn pé “ayé tuntun” jẹ́ ara àwọn ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run máa mú wá. (Ìṣípayá 21:1-4) Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àtèyí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ipò tí ayé máa wà ṣáájú kí Ìjọba Ọlọ́run tó dé ti ń ṣẹ báyìí. Fún ìdí yìí, a lè retí pé láìpẹ́ Ìjọba Ọlọ́run máa sọ ayé di tuntun. Báwo ni ayé tuntun yẹn ṣe máa rí? Ìwé Aísáyà inú Bíbélì sọ ọ́ fún wa.
Àwọn Ìbùkún Tá A Máa Gbádùn Nínú Ayé Tuntun
Àlááfíà Kárí Ayé àti Ìjọsìn Tó Ṣọ̀kan. “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:2-4.
Àlááfíà Láàárín Àwọn Èèyàn Àtàwọn Ẹranko. “Ìkookò yóò sì máa gbé ní ti tòótọ́ fún ìgbà díẹ̀ pẹ̀lú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, àmọ̀tẹ́kùn pàápàá yóò sì dùbúlẹ̀ ti ọmọ ewúrẹ́, àti ọmọ màlúù àti ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ẹran tí a bọ́ dáadáa, gbogbo wọn pa pọ̀; àní ọmọdékùnrin kékeré ni yóò sì máa dà wọ́n. Abo màlúù àti béárì pàápàá yóò máa jẹun; àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pa pọ̀. Kìnnìún pàápàá yóò jẹ èérún pòròpórò gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù. . . . Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:6-9.
Ọ̀pọ̀ Rẹpẹtẹ Oúnjẹ fún Gbogbo Èèyàn. “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun yóò sì se àkànṣe àsè tí ó jẹ́ oúnjẹ tí a fi òróró dùn fún gbogbo àwọn ènìyàn ní òkè ńlá yìí, àkànṣe àsè wáìnì tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, ti àwọn oúnjẹ tí a fi òróró dùn, èyí tí ó kún fún mùdùnmúdùn, ti wáìnì sísẹ́, èyí tí ń bẹ lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀.”—Aísáyà 25:6.
Kò Ní Sí Ikú Mọ́. “Ní ti tòótọ́, [Ọlọ́run] yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn. Ẹ̀gàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ni òun yóò sì mú kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀ ti sọ ọ́.”—Aísáyà 25:8.
Àwọn Òkú Máa Jíǹde. “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. . . . wọn yóò dìde. Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru! . . . Ilẹ̀ ayé pàápàá yóò sì jẹ́ kí àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú pàápàá jáde wá nínú ìbímọ.”—Aísáyà 26:19.
Onídàájọ́ Òdodo Ni Mèsáyà. “Kì yóò sì ṣe ìdájọ́ nípasẹ̀ ohun èyíkéyìí tí ó hàn lásán sí ojú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí etí rẹ̀ wulẹ̀ gbọ́. Yóò sì fi òdodo ṣe ìdájọ́ àwọn ẹni rírẹlẹ̀, yóò sì fi ìdúróṣánṣán fúnni ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà nítorí àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé.”—Aísáyà 11:3, 4.
Afọ́jú àti Adití Máa Rí Ìwòsàn. “Ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí.”—Aísáyà 35:5.
Aṣálẹ̀ Máa Di Ilẹ̀ Ọlọ́ràá. “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. Láìkùnà, yóò yọ ìtànná, ní ti tòótọ́ yóò fi tayọ̀tayọ̀ kún fún ìdùnnú àti fífi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.”—Aísáyà 35:1, 2.
Ayé Tuntun. “Èmi yóò dá ọ̀run tuntun [ìjọba tuntun ní ọ̀run] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ àwọn èèyàn tuntun tí wọ́n jẹ́ olódòdó]; àwọn ohun àtijọ́ ni a kì yóò sì mú wá sí ìrántí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò wá sí ọkàn-àyà. Ṣùgbọ́n ẹ yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá. . . . Dájúdájú, [àwọn tó máa gbénú ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí] yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. Nítorí pé bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Wọn kì yóò ṣe làálàá lásán, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò bímọ fún ìyọlẹ́nu; nítorí pé àwọn ni ọmọ tí ó para pọ̀ jẹ́ alábùkún lọ́dọ̀ Jèhófà, àti àwọn ọmọ ìran wọn pẹ̀lú wọn. Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ti tòótọ́ pé, kí wọ́n tó pè, èmi fúnra mi yóò dáhùn; bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi fúnra mi yóò gbọ́.” “‘Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí èmi yóò ṣe ti dúró níwájú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ yín àti orúkọ yín yóò dúró.’”—Aísáyà 65:17-25; 66:22.
Àsọtẹ́lẹ̀ Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Tó Kọ Yọyọ
Ìwé Aísáyà nìkan kọ́ ni ìwé inú Bíbélì tó sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ìbùkún ọjọ́ iwájú. Ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ nípa nǹkan àgbàyanu tí Ọlọ́run máa ṣe nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ tí Kristi máa jẹ́ alákòóso rẹ̀ kún inú Bíbélì.a Ṣé wàá fẹ́ gbé nínú Párádísè orílẹ̀ ayé tí Bíbélì sọ yìí? Ó kúkú ṣeé ṣe! Wádìí fúnra rẹ ohun tí Bíbélì kọ́ni gan-an nípa àwọn ohun rere tí Ọlọ́run ní lọ́kàn fún ọjọ́ iwájú, kó o sì mọ bó o ṣe lè jàǹfààní nínú àwọn ohun rere náà. Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àlàyé síwájú sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa gbé ṣe wà nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, ojú ìwé 76 sí 85. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àlàáfíà máa wà láàárín àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn òkú máa jíǹde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Gbogbo ayé máa di Párádísè