Orí Kẹtàdínlọ́gbọ̀n
Jèhófà Fi Ìbùkún sí Ìsìn Mímọ́
1. Àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ wo ni orí tó gbẹ̀yìn ìwé Aísáyà ṣàlàyé lé lórí, àwọn ìbéèrè wo ló sì dáhùn?
ORÍ tó gbẹ̀yìn nínú ìwé Aísáyà ṣe àṣeparí àlàyé tó fakíki nípa díẹ̀ lára àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ pàtàkì-pàtàkì inú ìwé àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ó sì dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè tó ṣe kókó. Lára àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ tó ṣàlàyé ni bí ọlá Jèhófà ti ga tó, bó ṣe kórìíra ìwà àgàbàgebè, bó ṣe pinnu láti jẹ àwọn ẹni burúkú níyà, bó ṣe fẹ́ràn àwọn olóòótọ́ tó àti ọwọ́ tó fi ń mú ọ̀ràn wọn. Ẹ̀wẹ̀, ó dáhùn àwọn ìbéèrè yìí: Kí ló ń fi ìsìn tòótọ́ hàn yàtọ̀ sí ìsìn èké? Báwo ló ṣe lè dá wa lójú pé ẹ̀san Jèhófà á ké lórí àwọn alágàbàgebè tó ń ṣe bíi pé àwọn jẹ́ ẹni mímọ́ àmọ́ tí wọ́n ń ni àwọn èèyàn Ọlọ́run lára? Báwo ni Jèhófà yóò sì ṣe bù kún àwọn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí i?
Ohun Tó Ṣe Kókó Nínú Ìjọsìn Mímọ́
2. Kí ni Jèhófà sọ nípa ọlá ńlá rẹ̀, kí ni ọ̀rọ̀ yẹn kò sì túmọ̀ sí?
2 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ tẹnu mọ́ ọlá ńlá Jèhófà ná, ó ní: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ilẹ̀ ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Ibo wá ni ilé tí ẹ lè kọ́ fún mi wà, ibo sì wá ni ibi tí ó jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún mi?’” (Aísáyà 66:1) Àwọn kan rò pé ṣe ni wòlíì yìí ń bu ìrẹ̀wẹ̀sì lu àwọn Júù, kí wọ́n máà tún tẹ́ńpìlì Jèhófà kọ́ nígbà tí orílẹ̀-èdè yẹn bá padà dé ìlú ìbílẹ̀ wọn. Ìyẹn kò rí bẹ́ẹ̀ rárá; nítorí Jèhófà alára ní yóò pàṣẹ pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì yẹn kọ́. (Ẹ́sírà 1:1-6; Aísáyà 60:13; Hágáì 1:7, 8) Kí wá ni àyọkà yìí túmọ̀ sí nígbà náà?
3. Kí nìdí tó fi bá a mu láti ṣàpèjúwe ilẹ̀ ayé pé ó jẹ́ “àpótí ìtìsẹ̀” Jèhófà?
3 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, a lè ṣàyẹ̀wò ìdí tí Jèhófà fi ṣàpèjúwe ayé pé ó jẹ́ “àpótí ìtìsẹ̀” òun. Kò fi ìyẹn tàbùkù ayé rárá. Ilẹ̀ ayé nìkan ni ó lo gbólóhùn àkànṣe yìí fún nínú gbogbo ọ̀kẹ́ àìmọye ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lójú ọ̀run. Títí láé ni ilé ayé wa yóò fi jẹ́ ibi àrà ọ̀tọ̀, nítorí pé ibí ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà ti san ìràpadà, ibí sì ni Jèhófà yóò ti tipasẹ̀ Ìjọba Mèsáyà dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre. Ó mà bá a mu gan-an o pé Jèhófà pe ilẹ̀ ayé ní àpótí ìtìsẹ̀ òun! Ọba lè fi irú àpótí ìtìsẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe àtẹ̀gùn ìtẹ́ rẹ̀ gíga, kí ó sì wá kẹ́sẹ̀ lé e gẹ́gẹ́ bí ibi ìsinmi fún ẹsẹ̀ rẹ̀ tó bá ti jókòó sórí ìtẹ́ tán.
4. (a) Kí nìdí tí ilé kankan láyé ò fi lè jẹ́ ibi ìsinmi fún Jèhófà Ọlọ́run? (b) Kí ni gbólóhùn náà, “gbogbo nǹkan wọ̀nyí,” túmọ̀ sí, èrò wo ló sì yẹ ká gbìn sọ́kàn nípa ìjọsìn Jèhófà?
4 A mọ̀ pé ọba ò ní máa gbé inú àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀, bí Jèhófà kò ṣe ní gbé inú ayé yìí pẹ̀lú. Kódà, ìsálú ọ̀run tó ṣeé fojú rí kò tiẹ̀ lè gbà á pàápàá! Áńbọ̀sì-bọ́sí pé kí ilé kan nínú ayé yìí wá gba Jèhófà débi pé a tiẹ̀ wá fi ṣe ibùgbé. (1 Àwọn Ọba 8:27) Ibi tí àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí ń gbé ni ìtẹ́ Jèhófà àti ibi ìsinmi rẹ̀ wà, ìyẹn sì ni ọ̀rọ̀ náà, “ọ̀run,” gẹ́gẹ́ bí a ṣe lò ó nínú Aísáyà 66:1 túmọ̀ sí. Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e mú kí kókó yìí túbọ̀ yéni sí i, ó ní: “‘Wàyí o, ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí, tí gbogbo ìwọ̀nyí fi wá wà,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Aísáyà 66:2a) Fojú inú wò ó pé o rí Jèhófà tó ń fọwọ́ ṣàpèjúwe yí ká bí ẹní ń tọ́ka nǹkan wọ̀nyẹn nígbà tó sọ pé “gbogbo nǹkan wọ̀nyí,” ìyẹn ni gbogbo ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ayé. (Aísáyà 40:26; Ìṣípayá 10:6) Gẹ́gẹ́ bí Atóbilọ́lá, Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, ohun tó tọ́ sí i ju ọ̀ràn pé à ń ya ilé sọ́tọ̀ fún un lọ. Ó ju ẹni tí a kàn ń fi kìkì ààtò ìsìn àti ohun tí a lè fojú rí lásán jọ́sìn lọ.
5. Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ “ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ó sì ní ìròbìnújẹ́ nínú ẹ̀mí”?
5 Irú ìjọsìn wo ló tọ́ sí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé? Òun fúnra rẹ̀ sọ ọ́ fún wa, ó ní: “Ẹni yìí, nígbà náà, ni èmi yóò wò, ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ó sì ní ìròbìnújẹ́ nínú ẹ̀mí, tí ó sì ń wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.” (Aísáyà 66:2b) Òótọ́ ni o, ohun tó ṣe kókó nínú ìsìn mímọ́ ni pé kí ẹni tí ń ṣèjọsìn fi ẹ̀mí tí ó tọ́ ṣe é. (Ìṣípayá 4:11) Ẹni tí ń sin Jèhófà ní láti jẹ́ “ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́, tí ó sì ní ìròbìnújẹ́ nínú ẹ̀mí.” Ṣé pé Jèhófà ò fẹ́ kí inú wa dùn? Bẹ́ẹ̀ kọ́, “Ọlọ́run aláyọ̀” ni, ó sì ń fẹ́ kí àwọn tó ń sìn ín láyọ̀ bákan náà. (1 Tímótì 1:11; Fílípì 4:4) Ṣùgbọ́n o, gbogbo wa ló máa ń dẹ́ṣẹ̀ lemọ́lemọ́, a ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa. Ó yẹ kí wọ́n ‘ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́,’ kí ó sì bà wá lọ́kàn jẹ́ pé a yà kúrò lójú ìlà àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. (Sáàmù 51:17) A ní láti fi hàn pé a “ní ìròbìnújẹ́ nínú ẹ̀mí” nípa ríronú pìwà dà, kí á gbógun ti fífẹ́ tí ara wá ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀, kí á sì máa gbàdúrà sí Jèhófà fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.—Lúùkù 11:4; 1 Jòhánù 1:8-10.
6. Ọ̀nà wo ni kí àwọn olùsìn tòótọ́ gbà “wárìrì sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”?
6 Bákan náà, Jèhófà tún ń kíyè sí àwọn tó “ń wárìrì sí ọ̀rọ̀” rẹ̀. Ṣé pé ó ń fẹ́ kí jìnnìjìnnì máa bò wá nígbàkigbà tí a bá ń ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni? Rárá, àmọ́, ó ń fẹ́ ká bọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ohun tí òun bá sọ. Kí á ṣàfẹ́rí ìmọ̀ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, kí á sì fi ṣe atọ́nà wa nínú gbogbo ohun táa bá ń ṣe ní ìgbésí ayé wa. (Sáàmù 119:105) A tún lè “wárìrì” ní ọ̀nà ti pé kí ẹ̀rù tiẹ̀ máa bà wá láti ronú nípa ṣíṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, kí á bẹ̀rù láti fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ èèyàn kó èérí bá òtítọ́ rẹ̀ àti láti fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. Irú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́, ṣùgbọ́n, ó bani nínú jẹ́ pé irú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n láyé òde òní.
Jèhófà Kórìíra Ìsìn Àgàbàgebè
7, 8. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ààtò ìsìn tí àwọn alágàbàgebè yìí ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà?
7 Bí Aísáyà ṣe ń ronú nípa àwọn tó wà láyé ìgbà tiẹ̀, ó mọ̀ dájú pé ìwọ̀nba kéréje nínú wọn ló ní irú ẹ̀mí tí Jèhófà ń fẹ́ kí àwọn tó ń sìn ín ní. Nítorí náà, ìparun tó ń bọ̀ yìí tọ́ sí Jerúsálẹ́mù apẹ̀yìndà. Kíyè sí ojú tí Jèhófà fi wo irú ìjọsìn tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀, ó ní: “Ẹni tí ń pa akọ màlúù dà bí ẹni tí ń ṣá ènìyàn balẹ̀. Ẹni tí ń fi àgùntàn rúbọ dà bí ẹni tí ń ṣẹ́ ọrùn ajá. Ẹni tí ń fi ẹ̀bùn rúbọ—bí ẹni tí ń fi ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ! Ẹni tí ń mú ohun ìrántí olóje igi tùràrí wá dà bí ẹni tí ń fi àwọn abàmì ọ̀rọ̀ súre. Àwọn pẹ̀lú jẹ́ àwọn ènìyàn tí ó ti yan ọ̀nà tiwọn, inú àwọn ohun ìríra wọn sì ni ọkàn wọn gan-an ní inú dídùn sí.”—Aísáyà 66:3.
8 Ọ̀rọ̀ yìí mú wa rántí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó wà nínú Aísáyà orí kìíní. Ibẹ̀ ni Jèhófà ti sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ oníwàkiwà pé yàtọ̀ sí pé ààtò ìsìn tí wọ́n ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà kò tẹ́ òun lọ́rùn rárá, ó túbọ̀ ń mú kí ìbínú òdodo òun ru, nítorí pé alágàbàgebè ni àwọn onísìn yẹn. (Aísáyà 1:11-17) Nísinsìnyí pẹ̀lú, Jèhófà fi ẹbọ tí wọ́n ń rú wé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì. Wọn kò lè fi ìpànìyàn tu Jèhófà lójú, bákan náà mà ni fífi tí wọ́n ń fi màlúù olówó gọbọi rúbọ kò lè tù ú lójú rárá o! Bíi pé wọ́n ń fi ajá tàbí ẹlẹ́dẹ̀ rúbọ lojú tó fi ń wo àwọn ẹbọ yòókù, bẹ́ẹ̀, ẹranko aláìmọ́ la ka ìwọ̀nyẹn sí lábẹ́ Òfin Mósè, ó sì dájú pé wọn kò yẹ lóhun tí à ń fi rúbọ rárá. (Léfítíkù 11:7, 27) Ṣé Jèhófà gbà pé kí irú ìsìn àgàbàgebè bẹ́ẹ̀ jẹ́ àṣegbé?
9. Ìhà wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù kọ sí àwọn ìránnilétí tí Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ fún wọn, kí ló sì ní láti yọrí sí fún wọn ní dandan?
9 Jèhófà wá sọ pé: “Èmi alára, ẹ̀wẹ̀, yóò yan àwọn ọ̀nà ṣíṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́; àwọn ohun tí ń da jìnnìjìnnì bò wọ́n ni èmi yóò sì mú wá bá wọn; nítorí ìdí náà pé mo pè, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó dáhùn; mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó fetí sílẹ̀; wọ́n sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi, ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni wọ́n yàn.” (Aísáyà 66:4) Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ yìí dá a lójú ṣáká. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé òun ni Jèhófà ń lò láti fi ‘pe’ àwọn èèyàn Rẹ̀ àti láti fi bá wọn “sọ̀rọ̀.” Ohun tí wòlíì yìí sì mọ̀ dájú ṣáká ni pé kò sí ẹnikẹ́ni nínú wọn tó fetí sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì ti ń bá a nìṣó láti ṣe búburú, ẹ̀san ní láti ké lórí wọn dandan ni. Ó dájú pé Jèhófà yóò yan ìyà tí yóò fi jẹ wọ́n, yóò sì mú kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń da jìnnìjìnnì boni já lu àwọn èèyàn rẹ̀ apẹ̀yìndà.
10. Kí ni ohun tí Jèhófà ṣe sí Júdà mú kí á mọ̀ nípa ojú tó fi ń wo Kirisẹ́ńdọ̀mù?
10 Kirisẹ́ńdọ̀mù òde òní ń ṣe àwọn ohun tí inú Jèhófà kò dùn sí bákan náà. Ìbọ̀rìṣà gbilẹ̀ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀, wọ́n ń gbé ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ lárugẹ láti orí àwọn àga ìwàásù rẹ̀, lílé tí ó ń lépa agbára ìṣèlú sì ti mú kí ó túbọ̀ rì wọnú àjọṣe onípanṣágà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè ayé. (Máàkù 7:13; Ìṣípayá 18:4, 5, 9) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù àtijọ́ náà ni yóò dé bá Kirisẹ́ńdọ̀mù, ẹ̀san tó tọ́ sí i, ìyẹn “ohun tí ń da jìnnìjìnnì boni,” ń bọ̀ wá ké lórí rẹ̀ dandan ni. Ara àwọn ìdí tó fi dájú pé ìyà ń bọ̀ wá sórí rẹ̀ ni ìwà tó ń hù sí àwọn èèyàn Ọlọ́run.
11. (a) Kí ló pa kún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn apẹ̀yìndà ti ìgbà ayé Aísáyà? (b) Ọ̀nà wo ni àwọn tó gbé láyé ìgbà Aísáyà fi ta àwọn olóòótọ́ nù ‘nítorí orúkọ Ọlọ́run’?
11 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin tí ń wárìrì sí ọ̀rọ̀ rẹ̀: ‘Àwọn arákùnrin yín tí ó kórìíra yín, tí ó ta yín nù láwùjọ nítorí orúkọ mi, wí pé, “Kí a yin Jèhófà lógo!” Òun yóò sì fara hàn pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀ níhà ọ̀dọ̀ yín, àwọn sì ni ìtìjú yóò bá.’” (Aísáyà 66:5) Ojúṣe tí Ọlọ́run yàn fún “àwọn arákùnrin” Aísáyà, ìyẹn àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè rẹ̀, ni láti ṣojú fún Jèhófà Ọlọ́run kí wọ́n sì máa tẹrí ba fún ipò ọba aláṣẹ rẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ ńlá gbáà ló jẹ́ fún wọn pé wọ́n kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ohun tó pa kún ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni pé wọ́n tún kórìíra ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ olóòótọ́ àti onírẹ̀lẹ̀, bíi ti Aísáyà. Àwọn apẹ̀yìndà yìí kórìíra àwọn olóòótọ́, wọ́n sì ń ta wọ́n nù nítorí pé wọ́n ń ṣojú fún Jèhófà Ọlọ́run lọ́nà tòótọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, títa tí wọ́n ń ta wọ́n nù jẹ́ ‘nítorí orúkọ Ọlọ́run.’ Lẹ́sẹ̀ kan náà, ńṣe làwọn èké ìránṣẹ́ Jèhófà yìí ṣì ń sọ pé àwọn ń ṣojú fún un, wọ́n a máa fi ìtara ìsìn lo àwọn gbólóhùn tó jẹ mọ́ ti ẹ̀sìn, bíi “Ògo ni fún Jèhófà!”a
12. Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nípa bí àwọn alágàbàgebè ẹlẹ́sìn ṣe ṣenúnibíni sí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà?
12 Kíkórìíra tí ìsìn èké kórìíra àwọn tí ń ṣe ìsìn mímọ́ kì í ṣe nǹkan tuntun. Ńṣe ló túbọ̀ ń mú àsọtẹ́lẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:15 ṣẹ, èyí tó sọ pé ìṣọ̀tá ọlọ́jọ́ pípẹ́ yóò wà láàárín irú-ọmọ Sátánì àti Irú-Ọmọ obìnrin Ọlọ́run. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ẹni àmì òróró ní ọ̀rúndún kìíní pé àwọn pẹ̀lú yóò jìyà lọ́wọ́ àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wọn, àní wọ́n á lé wọn kúrò nínú àwọn sínágọ́gù wọn, wọ́n á sì ṣe inúnibíni sí wọn títí kan pípa wọ́n pàápàá. (Jòhánù 16:2) Òde òní wá ńkọ́ o? Ní ìbẹ̀rẹ̀ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àwọn èèyàn Ọlọ́run rí i pé irú inúnibíni yẹn ń bẹ níwájú fáwọn pẹ̀lú. (2 Tímótì 3:1) Lọ́dún 1914 lọ́hùn-ún, Ilé Ìṣọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) fa ọ̀rọ̀ Aísáyà 66:5 yọ, ó wá ṣàlàyé pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ni gbogbo inúnibíni tó ti ń dé bá àwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń wá.” Àpilẹ̀kọ kan náà yìí tún sọ pé: “A kò mọ̀ bóyá wọ́n lè kúkú ṣe é láṣerégèé nígbà ayé tiwa, àní kí wọ́n ta wá nù láwùjọ, kí wọ́n bẹ́gi dínà ètò àjọ wa, bóyá kí wọ́n tiẹ̀ pa wá pàápàá.” Ọ̀rọ̀ yìí mà sì ṣẹ lóòótọ́ o! Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ yìí jáde ni inúnibíni tí àwọn àlùfáà ń súnná sí dé ògógóró rẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní. Àmọ́ ṣá, ojú ti Kirisẹ́ńdọ̀mù gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe sọ. Lọ́nà wo?
Ìmúbọ̀sípò Tó Yá Kíákíá Tó sì Jẹ́ Lójijì
13. Kí ni ‘ìró ìrọ́kẹ̀kẹ̀ tí ń bẹ nínú ìlú ńlá náà’ nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ?
13 Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ìró ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ń bẹ láti inú ìlú ńlá náà, ìró kan láti inú tẹ́ńpìlì! Ó jẹ́ ìró Jèhófà tí ń san ohun tí ó yẹ padà fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.” (Aísáyà 66:6) Nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ, Jerúsálẹ́mù níbi tí tẹ́ńpìlì Jèhófà wà, ni “ìlú ńlá náà.” “Ìró ìrọ́kẹ̀kẹ̀” dúró fún rúkèrúdò ogun, èyí tí wọ́n gbọ́ nínú ìlú náà nígbà tí àwọn ọmọ ogun Bábílónì wá gbógun jà wọ́n lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ìmúṣẹ tòde òní wá ńkọ́?
14. (a) Kí ni Málákì sọ tẹ́lẹ̀ nípa pé Jèhófà yóò wá sínú tẹ́ńpìlì Rẹ̀? (b) Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣe sọ, kí ni wíwá tí Jèhófà wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ yọrí sí? (d) Ìgbà wo ni Jèhófà àti Jésù bẹ tẹ́ńpìlì nípa tẹ̀mí wò, ipa wo sì ni ìyẹn ní lórí àwọn tó sọ pé àwọn ń ṣojú fún ìsìn mímọ́?
14 Ọ̀rọ̀ inú Aísáyà yìí bá àwọn àsọtẹ́lẹ̀ méjì mìíràn mu, ìyẹn èyí tó wà nínú Ìsíkíẹ́lì 43:4, 6-9 àti ti inú Málákì 3:1-5. Ìsíkíẹ́lì àti Málákì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àkókò kan tí Jèhófà Ọlọ́run yóò wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀. Àsọtẹ́lẹ̀ Málákì fi hàn pé Jèhófà wá bẹ ilé ìjọsìn mímọ́ rẹ̀ wò, ó ṣe iṣẹ́ Ẹni tí ń yọ́ nǹkan mọ́, ó sì kọ àwọn tí kò ṣojú fún un lọ́nà títọ́ sílẹ̀. Ìran Ìsíkíẹ́lì fi Jèhófà hàn pé ó wọ tẹ́ńpìlì rẹ̀, ó sì sọ pé kí wọ́n kó gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìṣekúṣe àti ìbọ̀rìṣà kúrò pátápátá.b Nígbà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lóde òní, nǹkan pàtàkì kan ṣẹlẹ̀ lọ́run nípa ọ̀ràn ìjọsìn Jèhófà lọ́dún 1918. Ó dájú pé Jèhófà àti Jésù bẹ gbogbo àwọn tó sọ pé àwọn ń ṣojú fún ìsìn mímọ́ wò. Àbáyọrí àbẹ̀wò yẹn ni pé Jèhófà kọ Kirisẹ́ńdọ̀mù oníwà ìbàjẹ́ sílẹ̀ pátápátá. Ní ti àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Kristi, ìbẹ̀wò yẹn yọrí sí ìyọ́mọ́ fún àkókò kúkúrú kan, tí ìmúbọ̀sípò nípa tẹ̀mí sì tẹ̀ lé e kíákíá lọ́dún 1919.—1 Pétérù 4:17.
15. Ọ̀rọ̀ nípa ìbímọ wo la sọ tẹ́lẹ̀, báwo sì ni èyí ṣe ṣẹ lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?
15 Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìwé Aísáyà ṣàpèjúwe ìmúbọ̀sípò yìí lọ́nà tó bá a mu gan-an ni, pé: “Kí ó tó wọnú ìrora ìrọbí, ó ti bímọ. Kí ìroragógó ìbímọ tó dé sí i lára, àní ó ti bí ọmọ kan tí ó jẹ́ akọ. Ta ni ó ti gbọ́ irú èyí rí? Ta ni ó ti rí irú nǹkan báwọ̀nyí rí? A ha lè bí ilẹ̀ kan pẹ̀lú ìrora ìrọbí ní ọjọ́ kan? Tàbí kẹ̀, a ha lè bí orílẹ̀-èdè kan ní ìgbà kan? Nítorí pé Síónì ti wọnú ìrora ìrọbí, ó sì ti bí àwọn ọmọ rẹ̀.” (Aísáyà 66:7, 8) Nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí kọ́kọ́ ṣẹ, ọ̀nà tó wúni lórí ló gbà ṣẹ sára àwọn Júù tó jẹ́ ìgbèkùn ní Bábílónì. Lẹ́ẹ̀kan sí i, a tún ṣàpèjúwe Síónì, tàbí Jerúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí obìnrin tó ń bímọ lọ́wọ́, àmọ́, ìbímọ àrà-ọ̀tọ̀ gbáà lèyí o! Ó yá kíákíá, ó sì jẹ́ òjijì tó bẹ́ẹ̀ tó fi jẹ́ pé, àní ó ti bímọ kó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí pàápàá! Àpèjúwe yìí bá a mu gan-an ni. Títún àwọn èèyàn Ọlọ́run bí gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè tó dá dúró, lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, yá kíákíá, ó sì jẹ́ òjijì tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jọ iṣẹ́ ìyanu. Àní, àsìkò tó wà láàárín ìgbà tí Kírúsì dá àwọn Júù sílẹ̀ nígbèkùn sí ìgbà tí àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ fi padà dé ìlú ìbílẹ̀ wọn kò gbà ju oṣù mélòó kan péré! Èyí mà kúkú yàtọ̀ o lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ kó tó di pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wáyé nígbà àkọ́kọ́! Lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, kò sídìí fún ẹnikẹ́ni láti lọ máa bẹ̀bẹ̀ òmìnira lọ́dọ̀ ọba kan tó ti fàáké kọ́rí, kò sídìí fún wọn láti máa sá kìjokìjo lọ nítorí àwọn ọmọ ogun ọ̀tá, kò sì sídìí fún wọn láti lọ ṣe àtìpó fún ogójì ọdún nínú aginjù.
16. Nígbà tí Aísáyà 66:7, 8 ṣẹ lóde òní, kí ni Síónì dúró fún, ọ̀nà wo ni a sì gbà tún irú ọmọ rẹ̀ bí?
16 Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lóde òní, Síónì dúró fún “obìnrin” Jèhófà lọ́run, ìyẹn ètò àjọ rẹ̀ lọ́run tó jẹ́ tàwọn ẹ̀dá ẹ̀mí. Lọ́dún 1919, inú “obìnrin” yìí dùn láti rí i pé a bí àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ọmọ òun lórí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn tí a ṣètò jọ, àní gẹ́gẹ́ bí “orílẹ̀-èdè kan.” Bíbí tí a tún wọn bí yìí yá kíákíá, ó sì jẹ́ òjijì.c Láàárín nǹkan bí oṣù mélòó kan péré, àwọn ẹni àmì òróró lápapọ̀ tinú ipò àìsí ìgbòkègbodò rárá, bíi pé wọ́n kú, dẹni tó ń báṣẹ́ lọ ní pẹrẹu nínú “ilẹ̀” wọn, ìyẹn gbogbo ẹ̀ka ìgbòkègbodò nípa tẹ̀mí tí Ọlọ́run fi fún wọn. (Ìṣípayá 11:8-12) Ní nǹkan bí ìgbà ìwọ́wé lọ́dún 1919, wọ́n tiẹ̀ kéde pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn tuntun tí yóò máa ṣàtìlẹ́yìn fún Ilé Ìṣọ́ jáde. Wọ́n pe ìwé ìròyìn náà ní The Golden Age (tó di Jí! nísinsìnyí), ìtẹ̀jáde tuntun yẹn sì fi ẹ̀rí hàn pé àwọn èèyàn Ọlọ́run tún ti sọ jí, wọ́n sì tún ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn tí a fètò sí.
17. Báwo ni Jèhófà ṣe mú un dá àwọn èèyàn rẹ̀ lójú pé ohunkóhun ò lè dí òun lọ́wọ́ láti mú ète òun nípa Ísírẹ́lì tẹ̀mí ṣẹ?
17 Kò sí ohunkóhun láyé àti lọ́run tó lè dènà ìbímọ nípa tẹ̀mí yìí. Ohun tí ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sì sọ gẹ́lẹ́ nìyẹn, ó ní: “‘Ní tèmi, èmi yóò ha fa yíya, kí n má sì fa bíbímọ?’ ni Jèhófà wí. ‘Tàbí kẹ̀, èmi yóò ha fa bíbímọ, kí n sì fa títìpa ní tòótọ́?’ ni Ọlọ́run rẹ wí.” (Aísáyà 66:9) Gẹ́lẹ́ bí ọmọ ò ti ṣeé dá dúró tó bá ti ń jáde bọ̀ nígbà ìbímọ, bẹ́ẹ̀ ni títún Ísírẹ́lì tẹ̀mí bí kò ti ṣeé dá dúró ní gbàrà tó ti bẹ̀rẹ̀. Òótọ́ ni pé àtakò wà, ó sì ṣeé ṣe kí àtakò púpọ̀ sí i wà lọ́jọ́ iwájú. Ṣùgbọ́n Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè dá ohun tóun fúnra rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ dúró, kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ rárá! Ọwọ́ wo ni Jèhófà wá fi mu àwọn èèyàn rẹ̀ tó mú sọ jí?
Ìkẹ́ Jèhófà
18, 19. (a) Àpèjúwe tó dùn mọ́ni wo ni Jèhófà lò, báwo ló sì ṣe kan àwọn èèyàn rẹ̀ tó wà nígbèkùn? (b) Báwo ni àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró lóde òní ṣe ti jàǹfààní láti inú ìpèsè àti àbójútó onífẹ̀ẹ́ yìí?
18 Ẹsẹ mẹ́rin tó tẹ̀ lé e ṣàpèjúwe ìkẹ́ Jèhófà lọ́nà tó dùn mọ́ni. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Aísáyà sọ pé: “Ẹ bá Jerúsálẹ́mù yọ̀, kí ẹ sì kún fún ìdùnnú pẹ̀lú rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin olùfẹ́ rẹ̀. Ẹ bá a yọ ayọ̀ ńláǹlà, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀; nítorí ìdí náà pé ẹ ó mu, ẹ ó sì yó dájúdájú láti inú ọmú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìtùnú nípasẹ̀ rẹ̀; nítorí ìdí náà pé ẹ óò sófèrè, ẹ ó sì ní inú dídùn kíkọyọyọ láti inú orí ọmú ògo rẹ̀.” (Aísáyà 66:10, 11) Àpẹẹrẹ abiyamọ tó ń fọ́mọ lọ́mú ni Jèhófà lò níhìn-ín. Bí ebi bá ti ń pa ọmọ, ńṣe ni yóò máa ké láìdabọ̀. Àmọ́, tó bá ti di pé ìyà rẹ̀ gbé e sún mọ́ ọmú rẹ̀ láti fún un lọ́yàn, ìbànújẹ́ ọmọ náà a di ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Bákan náà ni àṣẹ́kù àwọn Júù olóòótọ́ tó wà ní Bábílónì yóò ṣe tinú ipò ọ̀fọ̀ bọ́ sínú ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn kíákíá nígbà tí àsìkò ìdáǹdè àti ìmúbọ̀sípò bá dé. Ìdùnnú yóò bá wọn. Ògo Jerúsálẹ́mù yóò tún yọ lákọ̀tun bí wọ́n bá tún un kọ́ tán, tí wọ́n sì ń gbé ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ògo ìlú yẹn yóò ran àwọn olóòótọ́ tó ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, wọn yóò dẹni tí àwọn àlùfáà tó jáfáfá ń bọ́ yó nípa tẹ̀mí.—Ìsíkíẹ́lì 44:15, 23.
19 A fi ọ̀pọ̀ yanturu ìpèsè jíǹkí Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí pẹ̀lú lẹ́yìn tí wọ́n padà bọ̀ sípò lọ́dún 1919. Látìgbà náà wá ni oúnjẹ nípa tẹ̀mí táa ń tipasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” pèsè, ti ń wá déédéé. (Mátíù 24:45-47) Ní tòótọ́, àkókò ayọ̀ àti ìtùnú ni èyí jẹ́ fún àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró. Ṣùgbọ́n àwọn ìbùkún síwájú sí i tún ti wà pẹ̀lú.
20. Báwo la ṣe fi “àkúnya ọ̀gbàrá” jíǹkí Jerúsálẹ́mù láyé àtijọ́ àti lóde òní?
20 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń bá a lọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí: ‘Kíyè sí i, èmi yóò nawọ́ àlàáfíà sí i gẹ́gẹ́ bí odò àti ògo àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí àkúnya ọ̀gbàrá, ó sì dájú pé ẹ ó mu. Ìhà ni a óò gbé yín sí, orí eékún sì ni a ó ti máa ṣìkẹ́ yín.’” (Aísáyà 66:12) Níhìn-ín, Jèhófà lo àpẹẹrẹ ìtọ́jú abiyamọ pa pọ̀ mọ́ àpèjúwe nípa bí ìbùkún yàbùgà yabuga ṣe ń rọ́ wá, bíi ṣíṣàn “odò” àti bí “àkúnya ọ̀gbàrá” ló sì ṣe ń rọ́ wá. Yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà látọ̀dọ̀ Jèhófà, èyí táa ó fi jíǹkí Jerúsálẹ́mù, yóò tún gba “ògo àwọn orílẹ̀-èdè,” tó jẹ́ pé ó ń ṣàn wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn Ọlọ́run, tí ó sì ń bù kún wọn. Ìyẹn túmọ̀ sí pé, àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yóò rọ́ wìtìwìtì wá sọ́dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà. (Hágáì 2:7) Nígbà tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ láyé àtijọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn látinú onírúurú orílẹ̀-èdè dara pọ̀ mọ́ Ísírẹ́lì lóòótọ́, wọ́n sì di aláwọ̀ṣe Júù. Àmọ́, ó tún ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ tóbi gan-an jù bẹ́ẹ̀ lọ nígbà tiwa yìí, nígbà tí “ogunlọ́gọ̀ ńlá . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” tí í ṣe àkúnya ọ̀gbàrá ọmọ aráyé lóòótọ́, dara pọ̀ mọ́ àṣẹ́kù àwọn Júù nípa tẹ̀mí.—Ìṣípayá 7:9; Sekaráyà 8:23.
21. Irú ìtùnú wo ni a lo àpèjúwe tó dùn mọ́ni láti fi sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀?
21 Aísáyà 66:12 tún sọ nípa ìfẹ́ abiyamọ sọ́mọ rẹ̀ pẹ̀lú, ìyẹn ṣíṣìkẹ́ ọmọ lórí eékún àti gbígbé e sí ìhà. Èrò yìí kan náà ló wà ní ẹsẹ tó tẹ̀ lé e, àmọ́ ìhà mìíràn ló ti gbé àlàyé ọ̀rọ̀ náà. Ó ní: “Bí ènìyàn [ọkùnrin] tí ìyá rẹ̀ ń tù nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi fúnra mi yóò ṣe máa tù yín nínú; àti ní ti ọ̀ràn Jerúsálẹ́mù, a ó tù yín nínú.” (Aísáyà 66:13) Ọmọ náà ti di “ọkùnrin,” ó ti di géńdé wàyí. Síbẹ̀, kò sú ìyà rẹ̀ láti máa tù ú nínú nígbà ìpọ́njú.
22. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi bí ìfẹ́ rẹ̀ ṣe jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó àti bí ó ṣe lágbára tó hàn?
22 Ọ̀nà tó dùn mọ́ni yìí ni Jèhófà gbà ṣàpèjúwe bí ìfẹ́ tó fẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe lágbára tó àti bí ó ṣe jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tó. Ńṣe ni ìfẹ́ abiyamọ tó lágbára jù lọ wulẹ̀ jẹ́ àwòkọ́ṣe bíńtín lára irú ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà ní fún àwọn èèyàn rẹ̀. (Aísáyà 49:15) Ó mà ṣe pàtàkì pé kí gbogbo Kristẹni fi ànímọ́ tí Baba wọn ọ̀run ní yìí hàn o! Ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe nìyẹn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún àwọn alàgbà nínú ìjọ Kristẹni. (1 Tẹsalóníkà 2:7) Jésù sọ pé ìfẹ́ ará ni yóò jẹ́ nǹkan pàtàkì jù lọ táa ó fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn òun mọ̀.—Jòhánù 13:34, 35.
23. Ṣàpèjúwe ipò ayọ̀ tí àwọn èèyàn Jèhófà tó padà bọ̀ sípò bọ́ sí.
23 Inú ìṣe ni Jèhófà ti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn. Ìyẹn ló fi ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ẹ ó sì rí i, ọkàn-àyà yín yóò sì yọ ayọ̀ ńláǹlà dájúdájú, àní egungun yín yóò sì rú jáde gẹ́gẹ́ bí koríko tútù yọ̀yọ̀. Dájúdájú, a ó sì sọ ọwọ́ Jèhófà di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n òun yóò dá àwọn ọ̀tá rẹ̀ lẹ́bi ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 66:14) Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀hun gbólóhùn inú èdè Hébérù kan sọ nípa gbólóhùn náà, “ẹ ó sì rí i,” ó ní ó túmọ̀ sí pé ibikíbi tí àwọn ìgbèkùn tó padà wálé bá yíjú sí nínú ilẹ̀ wọn tó ti padà bọ̀ sípò, “ohun ayọ̀ ni wọn óò sáà máa rí.” Wọn yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀lú ìdùnnú tó kọyọyọ, pé wọ́n dẹni tó padà bọ̀ sípò nínú ìlú ìbílẹ̀ wọn. Yóò dà bí ẹni pé ṣe ni ara wọn padà sọ jí, bíi pé egungun wọn tún padà ń lé sí i, tó sì ní àlékún okun bíi koríko tó ń rú nígbà ìrúwé. Gbogbo èèyàn yóò wá rí i pé ìsapá èèyàn kọ́ ló mú kí ipò aásìkí yẹn ṣeé ṣe, bí kò ṣe nípa “ọwọ́ Jèhófà.”
24. (a) Èrò wo lo gbìn sọ́kàn nígbà tóo ń gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ní ipa lórí àwọn èèyàn Jèhófà lóde òní yẹ̀ wò? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìpinnu wa?
24 Ǹjẹ́ o ń rí ohun tí ọwọ́ Jèhófà ń gbé ṣe láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí bí? Kò sí ọmọ èèyàn tó lè mú kí ìsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò. Kò sí ọmọ aráyé tó lè pète pèrò kí ó sì mú kí ẹgbàágbèje àwọn èèyàn àtàtà látinú gbogbo orílẹ̀-èdè máa rọ́ wìtìwìtì wá láti dara pọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ́kù olóòótọ́ nínú ilẹ̀ wọn nípa tẹ̀mí. Àfi Jèhófà Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn yìí ń mú inú wa dùn gan-an ni. Ǹjẹ́ kí á má ṣe fojú yẹpẹrẹ wo ìfẹ́ rẹ̀ láé o. Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti “wárìrì sí ọ̀rọ̀” rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí á pinnu láti máa fi ìlànà Bíbélì ṣe amọ̀nà ìgbésí ayé wa, kí á sì máa fi ìdùnnú sin Jèhófà.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lóde òní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù ló kọ̀ láti lo orúkọ Jèhófà, àní wọ́n tiẹ̀ yọ ọ́ kúrò nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹ̀dà ìtumọ̀ Bíbélì. Àwọn kan ń fi àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣẹlẹ́yà nítorí pé wọ́n ń lo orúkọ Ọlọ́run. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn yìí ló ń fi ìtara ìsìn lo gbólóhùn náà, “Halelúyà,” tó túmọ̀ sí “Ẹ yin Jáà.”
b Àwọn òrìṣà ni gbólóhùn náà, “òkú àwọn ọba wọn,” tí Ìsíkíẹ́lì 43:7, 9 sọ ń tọ́ka sí. Àwọn ọlọ̀tẹ̀ aṣáájú àti àwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù fi ère sọ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run di ẹlẹ́gbin, nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n kúkú ka àwọn ère yẹn sí ọba.
c Ìbímọ tí ibí yìí ń sàsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ kì í ṣe ọ̀kan náà pẹ̀lú èyí tí Ìṣípayá 12:1, 2, 5 ṣàpèjúwe o. Ní orí yẹn nínú ìwé Ìṣípayá, “ọmọkùnrin kan, akọ,” dúró fún Ìjọba Mèsáyà, èyí tó bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 1914. Àmọ́ ṣáá, ẹnì kan náà ni “obìnrin” inú àsọtẹ́lẹ̀ méjèèjì jẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 395]
“Ọwọ́ mi ni ó ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 402]
Jèhófà yóò mú kí “ògo àwọn orílẹ̀-èdè” nasẹ̀ dé Síónì