Orí Kejìdínlọ́gbọ̀n
Ìmọ́lẹ̀ fún Àwọn Orílẹ̀-Èdè
1, 2. Kí nìdí tí ìmọ́lẹ̀ fi ṣe pàtàkì, irú òkùnkùn wo ló sì bo ayé òde òní?
JÈHÓFÀ ni Orísun ìmọ́lẹ̀, “Olùfúnni ní oòrùn fún ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ fún ìmọ́lẹ̀ ní òru.” (Jeremáyà 31:35) Fún ìdí kan ṣoṣo yìí, ó yẹ kí á gbà pé òun ni Orísun ìwàláàyè, nítorí ìmọ́lẹ̀ ló ń mú kí ìwàláàyè ṣeé ṣe. Ká ní oòrùn ò máa ta sí ilẹ̀ ayé yìí déédéé ni, ìwàláàyè gẹ́gẹ́ bí a ṣe mọ̀ ọ́n yìí kì bá má ti ṣeé ṣe rárá. Ilé ayé kò ní ṣeé gbé rárá o.
2 Ìyẹn ló fi dà wá láàmú gan-an pé ohun tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ nígbà tó wo ọjọ́ iwájú tó sì rí ìgbà ayé wa yìí ni pé dípò kí ìmọ́lẹ̀ wà, òkùnkùn ni yóò wà. Ọlọ́run mí sí Aísáyà láti kọ̀wé pé: “Wò ó! òkùnkùn pàápàá yóò bo ilẹ̀ ayé, ìṣúdùdù nínípọn yóò sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè.” (Aísáyà 60:2) Lóòótọ́, òkùnkùn nípa tẹ̀mí ni ibí yìí ń sọ, kì í ṣe òkùnkùn tí a lè fojú rí, ṣùgbọ́n a kò gbọ́dọ̀ fojú kékeré wo ohun pàtàkì tí ọ̀rọ̀ yìí ń sọ. Àwọn tí kò bá ní ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí kò ní wà láàyè mọ́ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gẹ́lẹ́ bí àwọn táa bá fi ìmọ́lẹ̀ oòrùn dù kò ṣe ní lè wà láàyè mọ́.
3. Ní àkókò òkùnkùn yìí, ibo la lè yíjú sí fún ìmọ́lẹ̀?
3 Lásìkò òkùnkùn tí a wà yìí, a kò gbọ́dọ̀ dán an wò rárá ni pé a ń ṣàìka ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí tí Jèhófà ń tàn sí wa sí. Ó ṣe pàtàkì pé kí á fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe atọ́nà tí yóò máa tànmọ́lẹ̀ sí ọ̀nà wa o, kí á máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ bó bá ṣeé ṣe. (Sáàmù 119:105) Àwọn ìpàdé Kristẹni ń fún wa láǹfààní láti fún ara wa níṣìírí kí á má yẹsẹ̀ nínú “ipa ọ̀nà àwọn olódodo.” (Òwe 4:18; Hébérù 10:23-25) Okun tí a ń rí gbà látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ Kristẹni tó gbámúṣé ń ràn wá lọ́wọ́ kí á má ṣe dẹni tí òkùnkùn “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, tí yóò jálẹ̀ sí “ọjọ́ ìbínú Jèhófà,” gbé mì. (2 Tímótì 3:1; Sefanáyà 2:3) Ọjọ́ yẹn sì ń bọ̀ wá kánkán! Bí irú ọjọ́ yẹn ṣe dé bá àwọn ará Jerúsálẹ́mù àtijọ́ náà ló ṣe dájú ṣáká pé ọjọ́ yìí yóò dé.
Jèhófà “Bẹ̀rẹ̀ Ìjà”
4, 5. (a) Ọ̀nà wo ni Jèhófà yóò gbà bá Jerúsálẹ́mù jà? (b) Kí nìdí tí a fi lè gbà pé ìwọ̀nba èèyàn díẹ̀ ni yóò la ìparun Jerúsálẹ́mù já lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)
4 Ní àwọn ẹsẹ tó kẹ́yìn nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà amóríyá gágá yìí, Jèhófà ṣe àpèjúwe tó ṣe kedere nípa àwọn ohun tí yóò kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọjọ́ ìbínú rẹ̀ bá fi máa dé. A kà á pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ rèé tí ń bọ̀ àní bí iná, àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ sì dà bí ẹ̀fúùfù oníjì, láti lè fi ìhónú tí ó bùáyà san ìbínú rẹ̀ padà, kí ó sì fi ọwọ́ iná san ìbáwí mímúná rẹ̀ padà. Nítorí pé bí iná ni Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ ìjà náà ní tòótọ́, bẹ́ẹ̀ ni, pẹ̀lú idà rẹ̀, lòdì sí gbogbo ẹran ara; dájúdájú, àwọn tí Jèhófà pa yóò di púpọ̀.”—Aísáyà 66:15, 16.
5 Ó yẹ kí àwọn ọ̀rọ̀ yìí mú kí àwọn tó ń gbé láyé ìgbà Aísáyà mọ̀ pé ọ̀ràn àwọn ti wá dé ògógóró rẹ̀ wàyí. Nítorí àkókò kù sí dẹ̀dẹ̀ tí àwọn ará Bábílónì, tí yóò mú ìdájọ́ Jèhófà ṣẹ, yóò ṣígun ti Jerúsálẹ́mù, tí kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn yóò máa ku eruku lálá bí ìgbà tí àfẹ́yíká ìjì ń jà. Ìpáyà ọjọ́ náà á pọ̀ jọjọ! Àwọn tó máa gbógun wá jà wọn yìí ni Jèhófà yóò lò láti fi mú ìdájọ́ rẹ̀ mímúná ṣẹ sára gbogbo “ẹran ara” àwọn Júù aláìṣòótọ́. Bíi pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ jà ni yóò rí. Kò ní yí ‘ìhónú rẹ̀ tí ó bùáyà’ padà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù ní yóò kú sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àwọn tí Jèhófà pa.” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ṣẹ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa.a
6. Àwọn ìṣe tí kò ṣètẹ́wọ́gbà wo ní wọ́n ń ṣe ní Júdà?
6 Ǹjẹ́ Jèhófà jàre bí ó ṣe “bẹ̀rẹ̀” sí bá àwọn èèyàn rẹ̀ ‘jà’? Ó jàre o! Nínú bí a ṣe ń jíròrò ìwé Aísáyà, a ti rí i lọ́pọ̀ ìgbà pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù sọ pé àwọn ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà, ńṣe ni wọ́n tara bọnú ìsìn èké, bẹ́ẹ̀, ohun tí wọ́n ń ṣe kò pa mọ́ fún Jèhófà rárá. A tún rí èyí nínú ọ̀rọ̀ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ tẹ̀ lé e pé: “‘Àwọn tí ń sọ ara wọn di mímọ́, tí wọ́n sì ń wẹ ara wọn mọ́ fún àwọn ọgbà lẹ́yìn èyí tí ó wà ní àárín, tí wọ́n ń jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti ohun ìkórìíra tẹ̀gbintẹ̀gbin, títí kan eku pàápàá, gbogbo wọn lápapọ̀ yóò dé òpin wọn,’ ni àsọjáde Jèhófà.” (Aísáyà 66:17) Ṣé ìsìn mímọ́ làwọn Júù ń múra sílẹ̀ fún ni, tí wọ́n fi “ń sọ ara wọn di mímọ́, tí wọ́n sì ń wẹ ara wọn mọ́”? Ìsìn mímọ́ kọ́ o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ààtò ìwẹ̀nùmọ́ àwọn abọ̀rìṣà ní wọ́n ń ṣe nínú àwọn àkànṣe ọgbà. Lẹ́yìn náà, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀mùwọ̀mù, àti ẹran àwọn ẹ̀dá yòókù tí Òfin Mósè kà sí aláìmọ́.—Léfítíkù 11:7, 21-23.
7. Báwo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe dà bíi Júdà abọ̀rìṣà?
7 Ipò tó ríni lára gbáà ni orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run òtítọ́ kan ṣoṣo bá dá májẹ̀mú yìí wà! Ṣùgbọ́n gba èyí yẹ̀ wò: Irú ipò ìríra tó jọ tiwọn yìí ń bẹ nínú àwọn ìsìn inú Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí. Àwọn náà sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run, púpọ̀ lára àwọn aṣáájú rẹ̀ a sì máa dọ́gbọ́n ṣe bí ẹni tó jẹ́ olùfọkànsìn. Síbẹ̀, wọ́n ń fi àwọn ẹ̀kọ́ ìbọ̀rìṣà àti ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ kó èérí bá ara wọn, èyí tó fi hàn pé inú òkùnkùn nípa tẹ̀mí ni wọ́n wà. Òkùnkùn yẹn mà pọ̀ jọjọ o!—Mátíù 6:23; Jòhánù 3:19, 20.
‘Dájúdájú, Wọn Yóò Rí Ògo Mi’
8. (a) Kí ni yóò dé bá Júdà àti Kirisẹ́ńdọ̀mù? (b) Ọ̀nà wo ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbà ‘rí ògo Jèhófà’?
8 Ǹjẹ́ Jèhófà ń rí àwọn ìwà tí kò ṣètẹ́wọ́gbà tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ń hù àti àwọn ẹ̀kọ́ èké tó fi ń kọ́ni? Ka ọ̀rọ̀ Jèhófà tó tẹ̀ lé e yìí, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe kọ ọ́, kí o sì wá wo èrò tó máa wá sí ọ lọ́kàn, ó ní: “Ní ti iṣẹ́ wọn àti ìrònú wọn, mo ń bọ̀ wá kó gbogbo orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọpọ̀; dájúdájú, wọn yóò sì wá, wọn yóò sì rí ògo mi.” (Aísáyà 66:18) Yàtọ̀ sí pé Jèhófà mọ iṣẹ́ ọwọ́ àwọn tó sọ pé àwọn jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀, àti pé ó ṣe tán láti ṣèdájọ́ wọn, ó tún mọ èrò inú wọn pẹ̀lú. Júdà sọ pé Jèhófà lòun gbà gbọ́, ṣùgbọ́n òrìṣà tó ń bọ àti ìṣe abọ̀rìṣà tó ń ṣe fi hàn pé irọ́ ló ń pa. Asán ni wíwẹ̀ tí wọ́n “ń wẹ ara wọn mọ́” ní ìlànà àwọn abọ̀rìṣà já sí. Píparun ni orílẹ̀-èdè yẹn yóò pa run, bẹ́ẹ̀, ìgbà tí ìyẹn yóò bá ṣẹlẹ̀, ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè abọ̀rìṣà tó yí wọn ká ni yóò ṣe. Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn yóò ‘rí ògo Jèhófà’ ní ti pé wọn yóò fojú rí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọn yóò sì gbà tipátipá pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣẹ lóòótọ́. Báwo ni gbogbo ìwọ̀nyí ṣe kan Kirisẹ́ńdọ̀mù? Nígbà tí òpin rẹ̀ bá dé, ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti àwọn tí wọ́n jọ da òwò pọ̀ tẹ́lẹ̀ rí kò ní lè ṣe ju pé kí wọ́n kàn dúró kí wọ́n máa wò ó bí ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ń ṣẹ sí i lára.—Jeremáyà 25:31-33; Ìṣípayá 17:15-18; 18:9-19.
9. Ìhìn rere wo ni Jèhófà kéde?
9 Ṣé ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa wá túmọ̀ sí pé Jèhófà ò tún ní ní àwọn ẹlẹ́rìí mọ́ lórí ilẹ̀ ayé ni? Rárá o. Àwọn olùpa ìwà títọ́ mọ́ tó ta yọ, bíi Dáníẹ́lì àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, yóò máa bá a lọ láti sin Jèhófà kódà bí wọ́n tiẹ̀ wà nígbèkùn ní Bábílónì. (Dáníẹ́lì 1:6, 7) Dájúdájú, kò ní ṣẹlẹ̀ rárá o pé àkókò kan á wà tí kò ní sí àwọn olóòótọ́ ẹlẹ́rìí Jèhófà láyé yìí, àti pé, nígbà tí àádọ́rin ọdún yóò bá fi pé, àwọn olóòótọ́ èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin yóò kúrò ní Bábílónì wọ́n yóò sì padà lọ sí Júdà láti lọ tún ìjọsìn mímọ́ bẹ̀rẹ̀ níbẹ̀. Ohun tí Jèhófà yán fẹ́rẹ́ nìyẹn nínú ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e pé: “Ṣe ni èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ sáàárín wọn, èmi yóò sì rán lára àwọn tí ó ti sá àsálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè, sí Táṣíṣì, Púlì, àti Lúdì, àwọn tí ń fa ọrun, Túbálì àti Jáfánì, àwọn erékùṣù jíjìnnàréré, àwọn tí kò tíì gbọ́ ìròyìn nípa mi tàbí kí wọ́n rí ògo mi; ó sì dájú pé wọn yóò sọ nípa ògo mi láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.”—Aísáyà 66:19.
10. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn Júù olóòótọ́ tó gba ìdáǹdè kúrò ní Bábílónì yóò gbà jẹ́ àmì? (b) Ta ní jẹ́ àmì lóde òní?
10 Ẹgbàágbèje àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin tó padà sí Jerúsálẹ́mù lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa ni yóò jẹ́ àmì tó yani lẹ́nu, ẹ̀rí pé Jèhófà ti dá àwọn èèyàn rẹ̀ nídè. Ta ni ì bá tiẹ̀ rò pé yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan pé àwọn Júù tó wà nígbèkùn á lómìnira láti lè máa bá ìjọsìn mímọ́ nìṣó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà? Lọ́nà tó jọ èyí, ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn tó “dà bí àmì àti bí iṣẹ́ ìyanu” ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, èyí tí àwọn ọlọ́kàn tútù tó ń fẹ́ sin Jèhófà rọ́ lọ bá. (Aísáyà 8:18; Hébérù 2:13) Lóde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tó ń láásìkí nínú ilẹ̀ wọn tó padà bọ̀ sípò, ló jẹ́ àmì tó yani lẹ́nu nínú ayé. (Aísáyà 66:8) Lára wọn ni ẹ̀rí agbára ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà ti ń hàn fáyé rí, ìyẹn sì ń fa àwọn ọlọ́kàn tútù tí ọkàn wọn ń sún láti sin Jèhófà mọ́ra.
11. (a) Lẹ́yìn ìmúbọ̀sípò, báwo ni yóò ṣe di pé àwọn èèyàn inú àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ nípa Jèhófà? (b) Báwo ni Sekaráyà 8:23 ṣe ní ìmúṣẹ àkọ́kọ́?
11 Àmọ́, lẹ́yìn ìmúbọ̀sípò ti ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, báwo ni àwọn èèyàn inú àwọn orílẹ̀-èdè tí kò tíì gbọ́ ìròyìn nípa Jèhófà yóò ṣe wá mọ̀ ọ́n? Tóò, kì í ṣe gbogbo àwọn Júù olóòótọ́ ni yóò padà sí Jerúsálẹ́mù ní òpin ìgbà ìgbèkùn wọn ní Bábílónì. Àwọn èèyàn bíi Dáníẹ́lì, yóò ṣì wà ní Bábílónì. Àwọn mìíràn yóò fọ́n ká sí orígun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún karùn-ún ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn Júù ti wà jákèjádò Ilẹ̀ Ọba Páṣíà, níbi tí wọ́n ń gbé. (Ẹ́sítérì 1:1; 3:8) Dájúdájú, àwọn kan lára wọn sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà fún àwọn aládùúgbò wọn tó jẹ́ abọ̀rìṣà, nítorí ọ̀pọ̀ nínú wọn ló di aláwọ̀ṣe Júù. Ó dájú pé irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ìwẹ̀fà ará Etiópíà, tí ọmọ ẹyìn náà Fílípì tó jẹ́ Kristẹni wàásù fún ní ọ̀rúndún kìíní nìyẹn. (Ìṣe 8:26-40) Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ wòlíì Sekaráyà ní, ìyẹn àsọtẹ́lẹ̀ tó sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Jèhófà mà tan ìmọ́lẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè ní tòótọ́ o!—Sáàmù 43:3.
Kíkó ‘Ẹ̀bùn Wá fún Jèhófà’
12, 13. Ọ̀nà wo ni “àwọn arákùnrin” wọ̀nyí yóò gbà dẹni táa mú wá sí Jerúsálẹ́mù bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa?
12 Nígbà tí wọ́n bá ti tún Jerúsálẹ́mù kọ́, àwọn Júù tó fọ́n káàkiri sí ọ̀nà jíjìn sí ìlú ìbílẹ̀ wọn yóò máa yíjú sí Jerúsálẹ́mù àti àwọn àlùfáà rẹ̀ tó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ padà gẹ́gẹ́ bí ibi tí ìsìn mímọ́ fìdí kalẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ nínú wọn yóò máa ti ọ̀nà jíjìn réré wá, láti wá ṣe àwọn àjọ̀dún níbẹ̀. Aísáyà kọ̀wé lábẹ́ ìmísí, ó ní: “‘Ní tòótọ́, wọn yóò sì kó gbogbo àwọn arákùnrin yín jáde láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Jèhófà, lórí ẹṣin àti nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti nínú kẹ̀kẹ́ tí a bò lórí àti lórí ìbaaka àti lórí abo ràkúnmí ayárakánkán, gòkè wá sórí òkè ńlá mímọ́ mi, Jerúsálẹ́mù,’ ni Jèhófà wí, ‘gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ohun èlò tí ó mọ́ gbé ẹ̀bùn wá sínú ilé Jèhófà. Nínú wọn pẹ̀lú ni èmi yóò sì ti mú àwọn kan ṣe àlùfáà, àní ṣe àwọn ọmọ Léfì.’”—Aísáyà 66:20, 21.
13 Díẹ̀ lára ‘àwọn arákùnrin láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’ yìí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, nígbà tí a tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Àkọsílẹ̀ náà kà báyìí pé: “Àwọn Júù wà tí ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, àwọn ènìyàn tí ó ní ìfọkànsìn, láti gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.” (Ìṣe 2:5) Ńṣe ni wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù láti wá jọ́sìn ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà àwọn Júù, àmọ́ nígbà tí wọ́n gbọ́ ìhìn rere nípa Jésù Kristi, ọ̀pọ̀ nínú wọn gbà á gbọ́ wọ́n sì ṣe ìrìbọmi.
14, 15. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe kó “àwọn arákùnrin” púpọ̀ sí i wọlé lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, báwo sì ni àwọn wọ̀nyí ṣe di “ẹ̀bùn” tí a “fi ohun èlò tí ó mọ́ gbé” wá fún Jèhófà? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “mú àwọn kan ṣe àlùfáà”? (d) Àwọn wo ni díẹ̀ lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó kópa nínú kíkó àwọn arákùnrin wọn nípa tẹ̀mí jọ pọ̀? (Wo àpótí tó wà lójú ewé yìí.)
14 Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lóde òní? Ó ṣẹ o. Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà róye rẹ̀ láti inú Ìwé Mímọ́ pé Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914. Nípa fífi ẹ̀sọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, òye yé wọn pé wọn yóò ṣì ní láti kó àwọn ajogún Ìjọba, tàbí “àwọn arákùnrin,” mìíràn wọlé sí i. Ni àwọn òjíṣẹ́ oníforítì bá bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò lọ sí “apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé,” tí wọ́n ń lo onírúurú ohun ìrìnnà láti fi wá àwọn tí yóò di ara àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró, lóòótọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ wọn sì jáde wá látinú àwọn ìjọ inú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Bí wọ́n ṣe ń wá wọn kàn ni wọ́n ń kó wọn wá fún Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn.—Ìṣe 1:8.
15 Àwọn ẹni àmì òróró táa kó jọ pọ̀ ní àwọn ọdún ìbẹ̀rẹ̀ yẹn, kò retí pé Jèhófà á kàn sáà gba àwọn gẹ́gẹ́ bí àwọn ṣe wà kí àwọn tó lóye òtítọ́ Bíbélì. Wọ́n múra, wọ́n sì wẹ gbogbo àìmọ́ tẹ̀mí àti ti ìwà híhù kúrò lára, kí wọ́n lè dẹni tó jẹ́ “ẹ̀bùn” tí a “fi ohun èlò tí ó mọ́ gbé wá,” tàbí gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́, kí wọ́n lè dẹni tí a “mú . . . wá fún Kristi gẹ́gẹ́ bí wúńdíá oníwà mímọ́.” (2 Kọ́ríńtì 11:2) Yàtọ̀ sí pé wọ́n kọ àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn tó lòdì sílẹ̀, àwọn ẹni àmì òróró tún kọ́ bí a ṣe ń wà láìdásí tọ̀tún tòsì rárá nínú ọ̀ràn ìṣèlú ayé yìí. Lọ́dún 1931, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti wá wẹ̀ tí wọ́n sì ti mọ́ dé ìwọ̀n tó yẹ, Jèhófà fi oore ọ̀fẹ́ fún wọn láǹfààní láti bá òun jẹ́ orúkọ pọ̀, ìyẹn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Aísáyà 43:10-12) Ṣùgbọ́n, ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “mú àwọn kan ṣe àlùfáà”? Òun ni pé lápapọ̀, àwọn ẹni àmì òróró yìí di ara “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé, orílẹ̀-èdè mímọ́,” tí ń rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run.—1 Pétérù 2:9; Aísáyà 54:1; Hébérù 13:15.
Ìkójọpọ̀ Ń Bá A Nìṣó
16, 17. Àwọn wo ni “àwọn ọmọ yín” lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní?
16 Ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye “ẹgbẹ́ àlùfáà aládé” yẹn, nígbà tó sì yá, a kó ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ iye wọn jọ pọ̀. (Ìṣípayá 7:1-8; 14:1) Ṣé ibi tí iṣẹ́ ìkójọpọ̀ máa wá parí sí nìyẹn? Ó tì o. Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń bá a lọ pé: “‘Nítorí pé gẹ́gẹ́ bí ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun tí èmi yóò ṣe ti dúró níwájú mi,” ni àsọjáde Jèhófà, “bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọmọ yín àti orúkọ yín yóò dúró.’” (Aísáyà 66:22) Nígbà tí ọ̀rọ̀ yẹn kọ́kọ́ ṣẹ, ńṣe làwọn Júù tó padà wálé láti ìgbèkùn Bábílónì bẹ̀rẹ̀ sí bímọ. Nípa bẹ́ẹ̀, àṣẹ́kù àwọn Júù tó padà wálé, ìyẹn “ilẹ̀ ayé tuntun,” tó wà lábẹ́ ìṣàkóso tuntun ti àwọn Júù, ìyẹn “ọ̀run tuntun,” di èyí tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in. Àmọ́ ṣá o, ọjọ́ wa ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́nà tó bùyààrì jù lọ.
17 “Ogunlọ́gọ̀ Ńlá” tó ń retí láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé ni “àwọn ọmọ” yìí tí orílẹ̀-èdè àwọn arákùnrin tẹ̀mí bí. “Inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” ni wọ́n ti wá, wọ́n sì “dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Àwọn wọ̀nyí “ti fọ aṣọ wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” (Ìṣípayá 7:9-14; 22:17) Lóde òní, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” yìí ń yí padà kúrò nínú òkùnkùn tẹ̀mí, wọ́n sì ń bọ́ sínú ìmọ́lẹ̀ ti Jèhófà pèsè. Wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi, wọ́n sì ń sapá láti wà ní mímọ́ nípa tẹ̀mí àti ní ti ìwà híhù, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn ẹni àmì òróró. Lápapọ̀, wọ́n ń bá a lọ láti sìn lábẹ́ ìdarí Kristi, wọn yóò sì “dúró,” àní títí láé!—Sáàmù 37:11, 29.
18. (a) Ọ̀nà wo ni àwọn tó jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá gbà ń ṣe bíi ti àwọn arákùnrin wọn ẹni àmì òróró? (b) Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe ń sin Jèhófà “láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì”?
18 Àwọn òṣìṣẹ́ kára lọ́kùnrin lóbìnrin yìí, tó ń retí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, mọ̀ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì gidigidi láti jẹ́ ẹni tó mọ́ níwà àti ẹni tó mọ́ nípa tẹ̀mí, ìyẹn nìkan ò tó bí èèyàn bá fẹ́ ṣe ohun tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn. Iṣẹ́ ìkójọpọ̀ náà ń lọ ní pẹrẹu, wọ́n sì ń fẹ́ láti kópa níbẹ̀. Ìwé Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn pé: “Wọ́n . . . wà níwájú ìtẹ́ Ọlọ́run; wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún un tọ̀sán-tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀.” (Ìṣípayá 7:15) Ọ̀rọ̀ yẹn mú wa rántí ẹsẹ tó ṣáájú ẹsẹ tó kẹ́yìn pátápátá nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ó sọ pé: “‘Dájúdájú, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì, gbogbo ẹran ara yóò wọlé wá tẹrí ba níwájú mi,’ ni Jèhófà wí.” (Aísáyà 66:23) Ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti ogunlọ́gọ̀ ńlá alábàákẹ́gbẹ́ wọn máa ń pàdé pọ̀ láti sin Jèhófà “láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì,” ìyẹn ni pé, wọ́n ń pàdé pọ̀ déédéé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ ní gbogbo oṣù. Wọ́n ń ṣe èyí nípa lílọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti lílọ sí òde ẹ̀rí, ìwọ̀nyí sì jẹ́ láfikún sí àwọn ọ̀nà mìíràn tí wọ́n tún ń gbà ṣe é. Ǹjẹ́ o wà lára àwọn tó ń ‘wọlé wá tẹrí ba níwájú Jèhófà’ déédéé? Ìdùnnú ńláǹlà ló ń jẹ́ fún àwọn èèyàn Jèhófà láti máa ṣe èyí, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá sì ń wọ̀nà fún ìgbà tí “gbogbo ẹran ara,” ìyẹn gbogbo ẹ̀dá ènìyàn tí ń bẹ láàyè, yóò máa sin Jèhófà “láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun àti láti sábáàtì dé sábáàtì” títí ayérayé.
Ìgbẹ̀yìn Àwọn Ọ̀tá Ọlọ́run
19, 20. Kí ni ohun tí wọ́n ń fi Gẹ̀hẹ́nà ṣe láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àpẹẹrẹ kí ló sì jẹ́?
19 Ó ṣì ku ẹsẹ kan táa fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ lé lórí nínú àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. Ọ̀rọ̀ tó parí ìwé náà lọ báyìí pé: “Wọn yóò sì jáde lọ ní tòótọ́, wọn yóò sì wo òkú àwọn ènìyàn tí ń rélànà mi kọjá; nítorí pé kòkòrò mùkúlú tí ó wà lára wọn kì yóò kú, iná wọn ni a kì yóò sì fẹ́ pa, wọn yóò sì di ohun tí ń kóni nírìíra fún gbogbo ẹran ara.” (Aísáyà 66:24) Ó jọ pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ni Jésù Kristi ní lọ́kàn nígbà tó ń rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n gbé ìgbésí ayé tó rọrùn kí wọ́n sì fi ire Ìjọba Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo. Ó ní: “Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, sọ ọ́ nù; ó sàn fún ọ láti wọ ìjọba Ọlọ́run ní olójú kan ju kí a gbé ọ pẹ̀lú ojú méjì sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà, níbi tí ìdin wọn kì í kú, tí a kì í sì í pa iná náà.”—Máàkù 9:47, 48; Mátíù 5:29, 30; 6:33.
20 Ibo ló ń jẹ́ Gẹ̀hẹ́nà yìí? Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ tó sì jẹ́ ọmọ Júù náà, David Kimhi, kọ̀wé pé: “Ibì kan tó wà . . . lẹ́bàá Jerúsálẹ́mù ni, ó jẹ́ ibi tó kóni nírìíra, wọ́n sì máa ń da ẹ̀gbin àti ohun tó bá kú síbẹ̀. Iná kì í kú níbẹ̀ pẹ̀lú, kí ó lè máa sun àwọn ohun ẹ̀gbin àti egungun òkú tó wà níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Gẹ́hínómù fi di ohun táa fi ń pòwe ìdájọ́ àwọn ẹni ibi.” Bó bá ṣe pé bí ọmọ Júù ọ̀mọ̀wé tó kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ yìí ṣe wí lọ́ràn rí, pé wọ́n fi Gẹ̀hẹ́nà ṣe ààtàn tí wọ́n ń da ìdọ̀tí sí àti ibi tí wọ́n ń ju òkú ẹni tí wọ́n bá kà sí ẹni tí kò yẹ fún sísin sí, iná ló máa dára láti máa fi sun irú pàǹtírí bẹ́ẹ̀ dànù. Ohun tí iná kò bá lè sun, ìdin á jẹ ẹ́. Àpèjúwe tó bá a mu gbáà nìyẹn láti lò fún ohun tó máa gbẹ̀yìn gbogbo ọ̀tá Ọlọ́run!b
21. Ta ni ọ̀nà tí ìwé Aísáyà gbà parí jẹ́ ìdùnnú fún, kí nìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀?
21 Ǹjẹ́ nǹkan ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ kọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó wúni lórí fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ lóòótọ́, nígbà tó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ òkú, iná, àti kòkòrò mùkúlú ló sọ kẹ́yìn? Dájúdájú, ohun tó máa jẹ́ èrò àwọn tó sọ ara wọn di abínúkú ọ̀tá Ọlọ́run nìyẹn. Ṣùgbọ́n, ohun ìdùnnú gbáà ni àpèjúwe tí Aísáyà ṣe nípa ìparun ayérayé tí yóò dé bá àwọn olubi jẹ́ fáwọn ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Àwọn èèyàn Jèhófà nílò ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí gan-an ni, pé àwọn ọ̀tá wọn kò tún ní lékè mọ́ láé. Àwọn ọ̀tá wọ̀nyẹn, tó ti pọ́n àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run lójú gan-an, tí wọ́n sì ti kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀ gidigidi yìí, yóò pa run láéláé. Lẹ́yìn náà, “wàhálà kì yóò dìde nígbà kejì.”—Náhúmù 1:9.
22, 23. (a) Ṣàlàyé díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tóo ti gbà jàǹfààní látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ ìwé Aísáyà. (b) Bí o ṣe ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Aísáyà, kí ni ìpinnu rẹ, kí sì lò ń retí?
22 Bí a ṣe ń parí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nípa ìwé Aísáyà, a rí i pé ìwé náà kì í ṣe òkú ìtàn rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìsọfúnni pàtàkì ń bẹ nínú rẹ̀ fún wa lóde òní. Nígbà tí a bá ronú lórí bí gbogbo nǹkan ṣe dojú rú nígbà ayé Aísáyà, a lè rí bí ìgbà ayé tirẹ̀ àti tiwa lónìí ṣe jọra wọn. Rògbòdìyàn òṣèlú, àgàbàgebè àwọn ẹlẹ́sìn, àìsí ìdájọ́ òdodo, àti níni àwọn olóòótọ́ àti aláìní lára ló gbòde kan nígbà ayé Aísáyà, ìyẹn ló sì gbilẹ̀ nígbà tiwa yìí pẹ̀lú. Àwọn Júù olóòótọ́ ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa ti ní láti dúpẹ́ gan-an ni fún àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, ó sì jẹ́ ìtùnú fún wa lóde òní bí a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ pẹ̀lú.
23 Ní ìgbà lílekoko yìí tí òkùnkùn bo ilẹ̀ ayé, tí òkùnkùn biribiri sì bo àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè, gbogbo wa mà dúpẹ́ gan-an o pé Jèhófà gbẹnu Aísáyà pèsè ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo aráyé! Ní tòótọ́, ìyè àìnípẹ̀kun ni ìmọ́lẹ̀ nípa tẹ̀mí yìí jẹ́ fún gbogbo àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á, láìka orílẹ̀-èdè tàbí ìran tí wọ́n ti wá sí. (Ìṣe 10:34, 35) Nígbà náà, ǹjẹ́ kí á máa bá a lọ láti rìn nínú ìmọ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kí á máa kà á lójoojúmọ́, kí á máa ṣe àṣàrò lé e lórí, kí á sì ka ìsọfúnni inú rẹ̀ sí ohun iyebíye. Ìbùkún ayérayé nìyẹn yóò yọrí sí fún wa, yóò sì mú ìyìn ayérayé bá orúkọ mímọ́ Jèhófà!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà tí Jeremáyà 52:15 ń sọ nípa bí nǹkan ṣe rí lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Bábílónì tán, ó mẹ́nu kan “àwọn kan lára àwọn ẹni rírẹlẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà àti ìyókù àwọn ènìyàn tí a fi sílẹ̀ sí ìlú ńlá náà.” Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, Apá kìíní, ojú ewé 415, sọ pé: “Gbólóhùn náà, ‘tí a fi sílẹ̀ sí ìlú ńlá náà’ ń fi hàn dájúdájú pé àwọn tó pọ̀ gan-an ló ti tipa ìyàn, àrùn, tàbí iná kú, tàbí kí wọ́n ti bá ogun lọ.”
b Nígbà tó ti jẹ́ pé òkú nìkan ni wọ́n ń finá sun ní Gẹ̀hẹ́nà, tí wọn kì í ju ààyè èèyàn síbẹ̀, ibẹ̀ kì í ṣe àpẹẹrẹ ìdálóró ayérayé rárá.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 409]
Kíkó Àwọn Ẹni Àmì Òróró Wá Gẹ́gẹ́ Bí Ẹ̀bùn fún Jèhófà Látinú Gbogbo Orílẹ̀-Èdè
Lọ́dún 1920, Juan Muñiz gbéra ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ó lọ sí ilẹ̀ Sípéènì, ó sì wá tibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ajẹntínà níbi tó ti kó ìjọ àwọn ẹni àmì òróró jọ. Láti ọdún 1923 síwájú, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí tàn sórí àwọn olódodo ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà nígbà tí William R. Brown (tí a sábà ń pè ní Bible Brown) gbéra láti lọ wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run ní àwọn ilẹ̀ bíi Sierra Leone, Gánà, Liberia, Gambia, àti Nàìjíríà. Lọ́dún kan náà, ará Kánádà náà, George Young, lọ sí ilẹ̀ Brazil, ó sì ti ibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ajẹntínà, Costa Rica, Panama, Venezuela, ó sì dé Soviet Union pàápàá. Ní nǹkan bí àsìkò yìí kan náà, Edwin Skinner wọ ọkọ̀ ojú omi láti ilẹ̀ England lọ sí Íńdíà, níbi tó ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣiṣẹ́ àṣekára lẹ́nu iṣẹ́ ìkórè yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 411]
Àwọn kan lára àwọn Júù tó wá sí Pẹ́ńtíkọ́sì jẹ́ ‘àwọn arákùnrin táa kó jáde láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 413]