Orí Kẹsàn-án
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Nígbà Ìpọ́njú
1. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni lónìí yóò fi jàǹfààní bí wọ́n bá ṣàyẹ̀wò Aísáyà orí keje àti ìkẹjọ?
ORÍ keje àti ìkẹjọ ìwé Aísáyà dá lórí ìṣe àwọn èèyàn méjì kan tó yàtọ̀ síra gédégédé. Aísáyà àti Áhásì jọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè táa yà sí mímọ́ fún Jèhófà; àwọn méjèèjì ló ní iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́, ọ̀kan jẹ́ wòlíì, ìkejì jẹ́ ọba Júdà; ewu kan náà làwọn méjèèjì dojú kọ, ìyẹn ni, ogun tí agbo ọmọ ogun ọ̀tá tó lágbára jù wọ́n lọ ń gbé bọ̀ wá ja Júdà. Aísáyà gbọ́kàn lé Jèhófà ní tirẹ̀ bó ṣe dojú kọ làásìgbò náà, ṣùgbọ́n inú ìpáyà ni Áhásì wà. Kí ló mú kí ìṣarasíhùwà wọn yàtọ̀ síra? Bó ti jẹ́ pé àárín àwọn ọ̀tá làwọn Kristẹni wà lónìí bákan náà, ó yẹ kí wọ́n gbé orí méjèèjì ìwé Aísáyà yìí yẹ̀ wò láti lè rí àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú wọn.
Ọ̀ràn Dórí Ìpinnu Ṣíṣe
2, 3. Àkópọ̀ wo ni Aísáyà ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀?
2 Bí ayàwòrán kan ṣe kọ́kọ́ máa ń fi ìlà hẹ́rẹ́hẹ́rẹ́ mélòó kan dá ojú àwòrán tuntun tó fẹ́ yà, ni Aísáyà ṣe kọ́kọ́ fi gbólóhùn mélòó kan ṣàkópọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ tó fẹ́ sọ nípa rẹ̀ àti òpin rẹ̀, ó ní: “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Áhásì ọmọkùnrin Jótámù ọmọkùnrin Ùsáyà, ọba Júdà, pé Résínì ọba Síríà àti Pékà ọmọkùnrin Remaláyà, ọba Ísírẹ́lì, gòkè wá sí Jerúsálẹ́mù láti bá a jagun, kò sì lè bá a jagun.”—Aísáyà 7:1.
3 Ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa ni. Áhásì ti jọba Júdà nípò Jótámù baba rẹ̀. Résínì ọba Síríà, àti Pékà ọba ìjọba àríwá Ísírẹ́lì, ṣígun wá Júdà, àwọn ọmọ ogun wọn sì fìjà pẹẹ́ta. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n wá sàga ti Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, pàbó ni ìsàgatì náà já sí. (2 Àwọn Ọba 16:5, 6; 2 Kíróníkà 28:5-8) Èé ṣe? A ó máa mọ ìyẹn bó bá yá.
4. Kí ló kó jìnnìjìnnì bá Áhásì àti àwọn ènìyàn rẹ̀?
4 Nígbà ìbẹ̀rẹ̀ ogun yẹn, a “ròyìn fún ilé Dáfídì, pé: ‘Síríà ti gbára lé Éfúráímù.’ Ọkàn-àyà rẹ̀ àti ọkàn-àyà àwọn ènìyàn rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n pẹ̀pẹ̀, bí ìgbọ̀npẹ̀pẹ̀ àwọn igi igbó nítorí ẹ̀fúùfù.” (Aísáyà 7:2) Dájúdájú, ẹ̀rù ba Áhásì àtàwọn èèyàn rẹ̀ láti gbọ́ pé àwọn ará Síríà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti lẹ̀dí àpò pọ̀, àti pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn tilẹ̀ ti pabùdó sí ilẹ̀ Éfúráímù (ilẹ̀ Ísírẹ́lì). Títí ọjọ́ méjì sí mẹ́ta péré, wọ́n á ti kàn wọ́n lára ní Jerúsálẹ́mù!
5. Ọ̀nà wo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí gbà dà bí Aísáyà?
5 Jèhófà sọ fún Aísáyà pé: “Jọ̀wọ́, jáde lọ pàdé Áhásì, ìwọ àti Ṣeari-jáṣúbù ọmọkùnrin rẹ, ní ìpẹ̀kun ọ̀nà omi adágún òkè, lẹ́gbẹ̀ẹ́ òpópó pápá alágbàfọ̀.” (Aísáyà 7:3) Ẹ sáà rò ó wò ná! Lákòókò tó yẹ kí ọba máa wá wòlíì Jèhófà láti béèrè fún ìtọ́ni, kó tún jẹ́ wòlíì yẹn ló máa jáde lọ wá ọba! Síbẹ̀ náà, Aísáyà kò janpata, ó ṣe bí Jèhófà ṣe wí. Lónìí bákan náà, tinútinú làwọn èèyàn Ọlọ́run fi ń jáde lọ wá àwọn tí ipò àìfararọ inú ayé yìí ń kó ìpáyà bá. (Mátíù 24:6, 14) Ó mà sì dùn mọ́ni gan-an o, pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún ló ń ṣègbọràn sí ìkésíni àwọn oníwàásù ìhìn rere wọ̀nyí lọ́dọọdún, tí wọ́n sì ń wá sábẹ́ ààbò Jèhófà!
6. (a) Iṣẹ́ tí ń múni lọ́kàn le wo ni wòlíì yìí lọ jẹ́ fún Áhásì Ọba? (b) Kí ni ipò nǹkan ti rí lóde òní?
6 Ẹ̀yìn odi Jerúsálẹ́mù ni Aísáyà ti rí Áhásì, níbi tí ọba yẹn ti ń ṣàyẹ̀wò orísun omi ìlú yẹn, ní ìmúrasílẹ̀ de ìsàgatì tí wọ́n ń retí. Ni Aísáyà bá sọ ohun tí Jèhófà wí fún un pé: “Ṣọ́ ara rẹ, kí o má sì yọ ara rẹ lẹ́nu. Má fòyà, má sì jẹ́ kí ojora mú ọkàn-àyà rẹ nítorí ibi orí méjèèjì ti àwọn ìtì igi wọ̀nyí tí ń rú èéfín, nítorí ìbínú gbígbóná Résínì àti Síríà àti ọmọkùnrin Remaláyà.” (Aísáyà 7:4) Nígbà tí àwọn agbóguntini han Júdà léèmọ̀ níṣàájú, bí iná ni ìbínú wọn ṣe gbóná janjan. Báyìí o, ‘ibi orí méjèèjì ti àwọn ìtì igi tí ń rú èéfín’ lásán ni wọ́n jẹ́. Kò sídìí fún Áhásì láti bẹ̀rù Résínì ọba Síríà tàbí Pékà ọba Ísírẹ́lì, ọmọ Remaláyà. Bẹ́ẹ̀ náà ló rí lónìí. Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá ni àwọn aṣáájú Kirisẹ́ńdọ̀mù ti ń ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sí àwọn Kristẹni tòótọ́. Àmọ́ o, bí ògúnná tó kù ṣín-ń-ṣín kó jó tán ni Kirisẹ́ńdọ̀mù rí báyìí. Òpin rẹ̀ ti dé tán.
7. Èé ṣe tí orúkọ Aísáyà àti ti ọmọ rẹ̀ fi jẹ́ orúkọ tó fúnni nírètí?
7 Nígbà ayé Áhásì, iṣẹ́ tí Aísáyà jẹ́ nìkan kọ́ ló fún àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ìrètí, ìtumọ̀ orúkọ Aísáyà àti ti ọmọ rẹ̀ náà tún fún wọn nírètí. Ewu rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Júdà lóòótọ́, àmọ́, orúkọ Aísáyà, tó túmọ̀ sí “Ìgbàlà Jèhófà,” jẹ́ àmì pé Jèhófà yóò dá wọn nídè. Jèhófà sọ fún Aísáyà pé kó mú Ṣeari-jáṣúbù ọmọ rẹ̀, tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Kìkì Àṣẹ́kù Ni Yóò Padà” dání. Àní nígbà tí ìjọba Júdà bá tilẹ̀ fọ́ pàápàá, Ọlọ́run yóò fi àánú mú àwọn àṣẹ́kù padà wá sí ilẹ̀ náà.
Kì Í Kàn Í Ṣe Ogun Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè
8. Èé ṣe ti ogun tó fẹ́ ja Jerúsálẹ́mù kì í kàn í ṣe ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè?
8 Jèhófà wá tipasẹ̀ Aísáyà táṣìírí ète àwọn ọ̀tá Júdà. Ohun tí wọ́n pète rèé: “Ẹ jẹ́ kí a gòkè lọ bá Júdà kí a sì ya á sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, kí a sì gbà á fún ara wa nípasẹ̀ ìyawọlé; kí a sì fi ọba mìíràn jẹ nínú rẹ̀, ọmọkùnrin Tábéélì.” (Aísáyà 7:5, 6) Àpapọ̀ ogun Síríà àti Ísírẹ́lì pète láti ṣẹ́gun Júdà, kí wọ́n sì fi ẹni tí wọ́n fẹ́ jọba dípò Áhásì ọmọ Dáfídì. Dájúdájú, ogun tó fẹ́ ja Jerúsálẹ́mù yìí kì í kàn í ṣe ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ó ti di ìjà láàárín Sátánì àti Jèhófà. Èé ṣe? Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run bá Dáfídì Ọba dá májẹ̀mú, tó tipa bẹ́ẹ̀ mú kó dá a lójú pé àwọn ọmọ rẹ̀ ni yóò máa ṣàkóso àwọn ènìyàn Jèhófà. (2 Sámúẹ́lì 7:11, 16) Àjàṣẹ́gun gbáà ni yóò jẹ́ fún Sátánì tó bá lè rọ́nà gbé ìlà ìdílé ọba mìíràn gorí itẹ́ ní Jerúsálẹ́mù! Kódà, ó tilẹ̀ lè dabarú ète Jèhófà pé kí ajogún kan tí yóò wà títí láé ti ìlà Dáfídì wá, ìyẹn “Ọmọ Aládé Àlàáfíà.”—Aísáyà 9:6, 7.
Ìfọ̀kànbalẹ̀ Tí Jèhófà Fi Tìfẹ́tìfẹ́ Fúnni
9. Ìfinilọ́kànbalẹ̀ wo ló yẹ kó fún Áhásì àti àwọn Kristẹni lóde òní nígboyà?
9 Ṣé ohun tí Síríà àti Ísírẹ́lì gbèrò yóò ṣẹ? Rárá o. Jèhófà sọ pé: “Kì yóò dúró, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ṣẹ.” (Aísáyà 7:7) Jèhófà lo Aísáyà láti sọ ọ́ pé, yàtọ̀ sí pé sísàga tí wọ́n sàga ti Jerúsálẹ́mù yóò já sí pàbó, “ní kìkì ọdún márùn-dín-láàádọ́rin, Éfúráímù ni a óò fọ́ túútúú kí ó má bàa jẹ́ àwọn ènìyàn kan.” (Aísáyà 7:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, nígbà tí yóò fi tó ọdún márùn-dín-láàádọ́rin sí i, Ísírẹ́lì kò ní wà gẹ́gẹ́ bí ènìyàn kan mọ́.a Ó yẹ kí ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí, tó tún lọ́jọ́ pàtó, fún Áhásì ní ìgboyà. Bákan náà, mímọ̀ tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run lóde òní mọ̀ pé àkókò kúkúrú ló kù fún ayé Sátánì ń fún wọn lókun.
10. (a) Báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí ṣe lè fara wé Jèhófà? (b) Kí ni Jèhófà sọ pé kí Áhásì béèrè?
10 Bóyá ó hàn lójú Áhásì pé kò gba èyí gbọ́, nítorí Jèhófà tipasẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Àyàfi bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kì yóò wà pẹ́.” Nínú sùúrù rẹ̀, Jèhófà “bá Áhásì sọ̀rọ̀ síwájú sí i.” (Aísáyà 7:9, 10) Àpẹẹrẹ rere gbáà lèyí! Lónìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ kì í tètè kọbi ara sí ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, ó yẹ kí a ṣe bíi Jèhófà nípa ‘sísọ̀rọ̀ síwájú sí i’ báa ṣe ń padà lọ sọ́dọ̀ wọn léraléra. Jèhófà tún sọ fún Áhásì pé: “Béèrè àmì kan lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ fún ara rẹ, ní mímú kí ó jìn bí Ṣìọ́ọ̀lù tàbí mímú kí ó ga bí àwọn ẹkùn ilẹ̀ ìhà òkè.” (Aísáyà 7:11) Áhásì lè béèrè àmì, Jèhófà yóò sì ṣe é láti fi ṣe ẹ̀rí pé òun yóò dáàbò bo ilé Dáfídì.
11. Ìfọ̀kànbalẹ̀ wo ló wà nínú sísọ tí Jèhófà sọ pé “Ọlọ́run rẹ”?
11 Ṣàkíyèsí pé Jèhófà ní: ‘Béèrè àmì kan lọ́wọ́ Ọlọ́run rẹ.’ Onínúure gidi ni Jèhófà. Wọ́n ní Áhásì ti bẹ̀rẹ̀ sí bọ̀rìṣà, pé ó ti ń ṣe àwọn ààtò ìbọ̀rìṣà tó ríni lára. (2 Àwọn Ọba 16:3, 4) Láìka ìyẹn sí, láìsì ka bíbẹ̀rù tí Áhásì ń bẹ̀rù sí, Jèhófà ṣì sọ pé òun jẹ́ Ọlọ́run Áhásì. Èyí fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà kì í dédé yán ọmọ aráyé dànù. Ó ń fẹ́ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tàbí àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn kò lágbára mọ́. Ṣé fífi tí Ọlọ́run fi Áhásì lọ́kàn balẹ̀ lórí ìfẹ́ tó ní sí i yóò mú kó gbà kí Jèhófà ṣèrànwọ́ fún òun bí?
Látorí Iyèméjì Dórí Àìgbọràn
12. (a) Ìwà ìgbéraga wo ni Áhásì hù? (b) Dípò tí Áhásì ì bá fi yíjú sí Jèhófà, ta ló tọ̀ lọ fún ìrànlọ́wọ́?
12 Ni Áhásì bá fọnmú, ó ní: “Èmi kì yóò béèrè, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dán Jèhófà wò.” (Aísáyà 7:12) Kì í ṣe ìgbọràn sófin ló sún Áhásì débẹ̀ o, ìyẹn òfin tó sọ pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run yín wò.” (Diutarónómì 6:16) Ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà, Jésù fa ọ̀rọ̀ òfin yìí kan náà yọ nígbà tí Sátánì dán an wò. (Mátíù 4:7) Àmọ́ ní ti Áhásì, ńṣe ni Jèhófà ń ké sí i láti padà sínú ẹ̀sìn tòótọ́, tó sì ń fẹ́ ṣe iṣẹ́ àmì kan láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun. Ṣùgbọ́n, ibòmíràn ni Áhásì fẹ́ wá ààbò lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yìí ni ọba gbé owó ńlá ránṣẹ́ sí Ásíríà láti wá ìrànlọ́wọ́ nítorí àwọn ọ̀tá rẹ̀ tó wà ní ìhà àríwá. (2 Àwọn Ọba 16:7, 8) Láàárín àkókò yìí, àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà àti Ísírẹ́lì ti yí Jerúsálẹ́mù ká, wọ́n sì ti sàga tì í.
13. Àyípadà wo ni a ṣàkíyèsí ní ẹsẹ kẹtàlá, tó túmọ̀ sí kí ni?
13 Ọ̀ràn àìnígbàgbọ́ ọba yìí ló mú kí Aísáyà sọ pé: “Jọ̀wọ́, fetí sílẹ̀ ìwọ ilé Dáfídì. Ohun kékeré bẹ́ẹ̀ ha ni fún yín láti kó àárẹ̀ bá àwọn ènìyàn, kí ẹ tún kó àárẹ̀ bá Ọlọ́run mi?” (Aísáyà 7:13) Híhùwà àìkanisí léraléra lè mú nǹkan sú Jèhófà. Tún ṣàkíyèsí pé “Ọlọ́run mi” ni wòlíì yìí lò báyìí, kì í ṣe “Ọlọ́run yín.” Àmì pé ìjàngbọ̀n fẹ́ bẹ́ ni àyípadà yìí o! Nígbà tí Áhásì kẹ̀yìn sí Jèhófà, tó sì yíjú sí Ásíríà, àǹfààní ńlá tí ì bá fi tún àárín òun àti Ọlọ́run ṣe ló gbé sọnù yẹn. Ká má rí i láé pé a tìtorí àtirí àǹfààní aláìtọ́jọ́ gbà yááfì àjọṣepọ̀ wa pẹ̀lú Ọlọ́run nípa gbígbà láti ṣe ohun tó lòdì sí ìgbàgbọ́ wa tí a gbé karí Ìwé Mímọ́.
Àmì Ìmánúẹ́lì
14. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé òun kò yẹhùn lórí májẹ̀mú tóun bá Dáfídì dá?
14 Jèhófà kò yẹhùn lórí májẹ̀mú tó bá Dáfídì dá. Ó ti ní kó béèrè àmì, àmì yóò dé dandan ni! Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò fún yín ní àmì kan: Wò ó! Omidan náà yóò lóyún ní tòótọ́, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, dájúdájú, yóò pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì. Bọ́tà àti oyin ni yóò máa jẹ nígbà tí ó bá fi máa mọ bí a ti ń kọ ohun búburú sílẹ̀, tí a sì ń yan ohun rere. Nítorí kí ọmọdékùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ohun búburú sílẹ̀, tí a sì ń yan ohun rere, ilẹ̀ ọba méjèèjì tí ìwọ ní ìbẹ̀rùbojo amúniṣàìsàn fún ni a ó fi sílẹ̀ pátápátá.”—Aísáyà 7:14-16.
15. Ìbéèrè méjì wo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa Ìmánúẹ́lì dáhùn?
15 Ìhìn ayọ̀ rèé fún ẹnikẹ́ni tó bá ń bẹ̀rù pé àwọn tó ṣígun wá yìí yóò fòpin sí ìlà ọba tí ń jẹ ní ìdílé Dáfídì. “Ìmánúẹ́lì” túmọ̀ sí “Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa.” Ọlọ́run wà pẹ̀lú Júdà, kò sì ní gbà kẹ́nikẹ́ni pa májẹ̀mú rẹ̀ pẹ̀lú Dáfídì rẹ́. Ẹ̀wẹ̀, yàtọ̀ sí pé Jèhófà sọ ohun tóun yóò ṣe fún Áhásì àtàwọn èèyàn rẹ̀, ó tún dá ìgbà tí yóò ṣe é. Kí ọmọ yìí, Ìmánúẹ́lì, tó dàgbà tó láti mọ̀yàtọ̀ láàárín rere àti búburú, ìparun yóò ti bá àwọn orílẹ̀-èdè tó jẹ́ ọ̀tá yìí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ mà ló ṣẹ o!
16. Kí ló lè jẹ́ ìdí tí Jèhófà fi ṣàìjẹ́ kí ẹni tí Ìmánúẹ́lì jẹ́ nígbà ayé Áhásì ṣe kedere?
16 Bíbélì kò sọ ọmọ ẹni tí Ìmánúẹ́lì jẹ́. Àmọ́, níwọ̀n bí ọmọ náà, Ìmánúẹ́lì, yóò ti jẹ́ àmì, tí Aísáyà sì wá sọ lẹ́yìn náà pé òun àti àwọn ọmọ òun “dà bí àmì,” ó ṣeé ṣe kí Ìmánúẹ́lì jẹ́ ọmọ wòlíì yìí. (Aísáyà 8:18) Bóyá Jèhófà ṣàìjẹ́ kí ẹni tí Ìmánúẹ́lì jẹ́ nígbà ayé Áhásì ṣe kedere kí àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn ìgbà náà lè pọkàn pọ̀ sọ́dọ̀ Ìmánúẹ́lì Ńlá náà. Ta sì ni?
17. (a) Ta ni Ìmánúẹ́lì Ńlá náà, kí ni ìbí rẹ̀ sì túmọ̀ sí? (b) Ìdí wo làwọn ènìyàn Ọlọ́run ní lónìí tí wọ́n fi lè polongo pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa”?
17 Lẹ́yìn ìwé Aísáyà, ibì kan péré la tún ti dárúkọ Ìmánúẹ́lì nínú Bíbélì, ìyẹn ní Mátíù 1:23. Jèhófà mí sí Mátíù láti lo àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìbí Ìmánúẹ́lì fún ìbí Jésù, Ajogún tí ìtẹ́ Dáfídì tọ́ sí. (Mátíù 1:18-23) Àmì pé Ọlọ́run kò kọ ilé Dáfídì sílẹ̀ ni ìbí Ìmánúẹ́lì tàkọ́kọ́ jẹ́. Bákan náà ni ìbí Jésù, Ìmánúẹ́lì Ńlá, jẹ́ àmì pé Ọlọ́run kò kọ aráyé tàbí májẹ̀mú Ìjọba tó bá ilé Dáfídì dá sílẹ̀. (Lúùkù 1:31-33) Bí olórí aṣojú Jèhófà ṣe wá wà láàárín aráyé, Mátíù lè sọ ní ti tòótọ́ pé, ‘Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.’ Lónìí, Ọba tí ń ṣàkóso ni Jésù jẹ́ ní ọ̀run, ó sì wà pẹ̀lú ìjọ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 28:20) Dájúdájú, àwọn ènìyàn Ọlọ́run tún ní ìdí púpọ̀ sí i láti fi ìgboyà polongo pé: “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!”
Àwọn Ohun Mìíràn Tí Àìṣòótọ́ Fà Bá Wọn
18. (a) Èé ṣe tí ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tẹ̀ lé e fi kó jìnnìjìnnì bá àwọn olùgbọ́ rẹ̀? (b) Àyípadà wo ló máa tó wáyé láìpẹ́?
18 Bí ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ tán yìí tilẹ̀ tuni nínú, ọ̀rọ̀ tó sọ tẹ̀ lé e kó jìnnìjìnnì bá àwọn olùgbọ́ rẹ̀, ó ní: “Jèhófà yóò mú wá sórí ìwọ àti sórí àwọn ènìyàn rẹ àti sórí ilé baba rẹ irúfẹ́ àwọn ọjọ́ tí kò tíì sí láti ọjọ́ tí Éfúráímù ti yí padà kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ Júdà, èyíinì ni, ọba Ásíríà.” (Aísáyà 7:17) Bẹ́ẹ̀ ni, àjálù ń bọ̀, yóò sì jẹ́ láti ọwọ́ ọba Ásíríà. Ìrònú pé àwọn ará Ásíríà táyé mọ̀ sí òǹrorò ẹ̀dá yóò jẹ gàba lé àwọn lórí ti ní láti kó àìsùn ọjọ́ púpọ̀ bá Áhásì àtàwọn èèyàn rẹ̀. Áhásì rò pé bóun bá bá Ásíríà ṣọ̀rẹ́, ìyẹn yóò yọ òun lọ́wọ́ Ísírẹ́lì àti Síríà. Lóòótọ́, ọba Ásíríà yóò ṣe ohun tí Áhásì bẹ̀ ẹ́, yóò sì gbéjà ko Ísírẹ́lì àti Síríà. (2 Àwọn Ọba 16:9) Ó ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ ohun tí yóò mú kí Pékà àti Résínì palẹ̀ ìsàgatì wọn mọ́ kúrò ní Jerúsálẹ́mù tipátipá. Bí àpapọ̀ ọmọ ogun Síríà àti Ísírẹ́lì kò ṣe ní lè gba Jerúsálẹ́mù nìyẹn. (Aísáyà 7:1) Àmọ́, Aísáyà wá ń sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ tí ìpáyà bá pé Ásíríà, tí wọ́n ń retí pé yóò jẹ́ aláàbò wọn, yóò padà tẹ̀ wọ́n lórí ba!—Fi wé Òwe 29:25.
19. Ìkìlọ̀ wo ló wà fáwọn Kristẹni lónìí látinú ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí?
19 Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ yìí jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí. Nígbà ìṣòro, ó lè ṣe wá bíi pé ká pa àwọn ìlànà Kristẹni tì, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ ààbò Jèhófà sílẹ̀. Irú ìyẹn kò láyọ̀lé o, bí ẹní fokùn ọ̀gẹ̀dẹ̀ gun ọ̀pẹ ni, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Aísáyà sọ síwájú sí i ṣe fi hàn. Wòlíì yìí wá ń bá a lọ láti ṣàpèjúwe ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ náà àtàwọn èèyàn ibẹ̀ nígbà tí Ásíríà bá gbógun wá jà á.
20. Ta ni “àwọn eṣinṣin” àti “àwọn oyin,” kí sì ni wọn yóò ṣe?
20 Aísáyà wá pín ìkéde rẹ̀ sí apá mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ ń sàsọtẹ́lẹ̀ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ “ní ọjọ́ yẹn,” ìyẹn, lọ́jọ́ tí Ásíríà yóò kọ lu Júdà. Ó ní: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé Jèhófà yóò súfèé sí àwọn eṣinṣin tí ó wà ní ìkángun àwọn ipa odò Náílì ti Íjíbítì àti sí àwọn oyin tí ó wà ní ilẹ̀ Ásíríà, dájúdájú, wọn yóò wọlé wá, wọn yóò sì bà, gbogbo wọn, sí àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá tí ó ní bèbè ọ̀gbun àti sí pàlàpálá àwọn àpáta gàǹgà àti sórí gbogbo ìgbòrò ẹlẹ́gùn-ún àti sórí gbogbo ibi olómi.” (Aísáyà 7:18, 19) Bí agbo eṣinṣin àti oyin ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Íjíbítì àti Ásíríà yóò ṣe dorí kọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ogun tí wọ́n ń bọ̀ wá jà, àjàkú-akátá ni, kì í ṣe ogun gìrìgìrì tó máa dá wáí. Ńṣe ni “àwọn eṣinṣin” àti “àwọn oyin” wọ̀nyí máa ṣùjọ tì wọ́n lọ́rùn, gbogbo kọ̀rọ̀ ilẹ̀ náà ni wọ́n máa ṣoro dé.
21. Ọ̀nà wo ni ọba Ásíríà yóò gbà dà bí abẹ fẹ́lẹ́?
21 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ní ọjọ́ yẹn, nípasẹ̀ abẹ fẹ́lẹ́ tí a háyà ní ẹkùn ilẹ̀ Odò, àní nípasẹ̀ ọba Ásíríà, Jèhófà yóò fá orí àti irun ẹsẹ̀, yóò sì gbá irùngbọ̀n pàápàá lọ.” (Aísáyà 7:20) Lọ́tẹ̀ yìí, Ásíríà, tó léwu jù lọ, nìkan ló mẹ́nu kàn. Ṣe ni Áhásì háyà ọba Ásíríà pé kó “fá orí” Síríà àti Ísírẹ́lì. Àmọ́, “abẹ fẹ́lẹ́ tí a háyà” láti ẹkùn ilẹ̀ Yúfírétì yìí yóò kọjú sí “orí” Júdà yóò sì fá a kodoro, àní yóò fá a nírùngbọ̀n pàápàá!
22. Kí ni Aísáyà fi ṣe àpèjúwe àbájáde ogun tí Ásíríà fẹ́ gbé jà wọ́n láìpẹ́?
22 Kí ni yóò yọrí sí? “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé ẹnì kan yóò pa ẹgbọrọ abo màlúù kan nínú ọ̀wọ́ ẹran àti àgùntàn méjì mọ́ láàyè. Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, nítorí ọ̀pọ̀ yanturu wàrà tí a ń mú jáde, òun yóò máa jẹ bọ́tà; nítorí pé bọ́tà àti oyin ni olúkúlùkù ẹni tí a ṣẹ́ kù sí àárín ilẹ̀ náà yóò máa jẹ.” (Aísáyà 7:21, 22) Nígbà tí Ásíríà fi máa “fá orí” ilẹ̀ náà tán, àwọn ènìyàn tó máa ṣẹ́ kù sí ilẹ̀ náà yóò kéré gan-an tó fi jẹ́ pé ìwọ̀nba ẹranko díẹ̀ yóò ti tó láti pèsè oúnjẹ wọn. “Bọ́tà àti oyin” ni wọn ó máa jẹ—kò sí nǹkan mìíràn, kò sí wáìnì, kò sí búrẹ́dì, kò sóúnjẹ gidi mìíràn mọ́. Bí ẹni pé Aísáyà fẹ́ tẹnu mọ́ bí ìsọdahoro yẹn ṣe máa tó, ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ló sọ ọ́ pé ilẹ̀ tó ti fìgbà kan rí jẹ́ ọlọ́ràá, tó ń méso wá, yóò di ilẹ̀ àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún àti èpò. Àwọn tó bá fẹ́ lọ sí eréko ibẹ̀ yóò ní láti kó “ọfà àti ọrun” dání láti dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ àwọn ẹranko ẹhànnà tó lúgọ sábẹ́ àwọn ìgbòrò. Oko tí wọ́n ṣán kalẹ̀ yóò di ibi tí akọ màlúù àti àgùntàn ti ń jẹ̀. (Aísáyà 7:23-25) Ìgbà ayé Áhásì gan-an ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ sí ní ìmúṣẹ.—2 Kíróníkà 28:20.
Àwọn Àsọtẹ́lẹ̀ Tó Ṣẹ Láìtàsé
23. (a) Àṣẹ wo ni Ọlọ́run wá pa fún Aísáyà báyìí? (b) Kí ló ṣẹ̀rí sí àmì wàláà yẹn?
23 Aísáyà tún wá padà sórí ọ̀ràn tó ń lọ lọ́wọ́. Nígbà tí Síríà àti Ísírẹ́lì ṣì pawọ́ pọ̀ sàga ti Jerúsálẹ́mù, Aísáyà sọ pé: “Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti sọ fún mi pé: ‘Mú wàláà ńlá kan fún ara rẹ, kí o sì fi kálàmù ẹni kíkú kọ “Maheri-ṣalali-háṣí-básì” sára rẹ̀. Sì jẹ́ kí n ní ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀ fún ara mi nípasẹ̀ àwọn ẹlẹ́rìí olùṣòtítọ́, Ùráyà àlùfáà àti Sekaráyà ọmọkùnrin Jeberekáyà.’” (Aísáyà 8:1, 2) Orúkọ yìí, Maheri-ṣalali-háṣí-básì túmọ̀ sí “Tètè, Ohun Ìfiṣèjẹ Rèé! Ó Sáré sí Ìkógun.” Aísáyà ní kí ọ̀tọ̀kùlú méjì ṣẹlẹ́rìí kíkọ tóun kọ orúkọ yìí sórí wàláà òkúta ńlá, kí wọ́n lè jẹ́rìí pé òótọ́ ni àkọsílẹ̀ yẹn tó bá yá. Àmọ́ ṣá, àmì tí yóò ṣìkejì ni yóò fẹ̀rí àmì yìí múlẹ̀.
24. Ipa wo ló yẹ kí àmì Maheri-ṣalali-hásí-básì ní lórí àwọn ènìyàn Júdà?
24 Aísáyà sọ pé: “Nígbà náà ni mo sún mọ́ wòlíì obìnrin náà, ó sì wá lóyún, nígbà tí ó ṣe, ó bí ọmọkùnrin kan. Jèhófà sọ fún mi wàyí pé: ‘Pe orúkọ rẹ̀ ní Maheri-ṣalali-háṣí-básì, nítorí pé kí ọmọdékùnrin náà tó mọ bí a ti ń pe, “Baba mi!” àti “Ìyá mi!” ẹnì kan yóò kó àwọn ohun àmúṣọrọ̀ Damásíkù àti ohun ìfiṣèjẹ Samáríà lọ níwájú ọba Ásíríà.’” (Aísáyà 8:3, 4) Wàláà ńlá yẹn àti ọmọ tuntun yìí ni yóò pa pọ̀ jẹ́ àmì pé láìpẹ́ Ásíríà yóò kó Síríà àti Ísírẹ́lì tó ń ni Júdà lára ní ìkógun. Báwo ni yóò ṣe yá tó? Kí ọmọ yẹn tó lè sọ ọ̀rọ̀ tí ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ọwọ́ kọ́kọ́ máa ń mọ̀ ọ́n sọ—“Bàbá” àti “Màmá.” Ó yẹ kí àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣe pàtó tó báyìí mú kí àwọn ènìyàn yẹn túbọ̀ fọkàn tán Jèhófà. Ó sì tún lè mú kí àwọn kan máa fi Aísáyà àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣẹlẹ́yà. Bó ti wù kó rí, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ṣẹ lóòótọ́.—2 Àwọn Ọba 17:1-6.
25. Àwọn nǹkan wo ni ìgbà ayé Aísáyà àti òde òní fi jọra?
25 Àwọn Kristẹni lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ látinú ìkìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ tí Aísáyà ṣe. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn wá pé Jésù Kristi ni Aísáyà dúró fún nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé yìí, àwọn ọmọ Aísáyà sì ṣàpẹẹrẹ àwọn ẹni àmì òróró, ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Hébérù 2:10-13) Ó ti pẹ́ tí Jésù ti ń lo àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti rán àwọn Kristẹni tòótọ́ létí nípa bó ti ṣe pàtàkì tó láti “wà lójúfò” ní àkókò lílekoko tí a wà yìí. (Lúùkù 21:34-36) Lẹ́sẹ̀ kan náà, ìkìlọ̀ ń dún sétí àwọn alátakò tí kò ronú pìwà dà pé ìparun wọn ń bọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀sín ni wọ́n ń fi irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀ ṣe. (2 Pétérù 3:3, 4) Ṣíṣẹ tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ táa dá àkókò fún ṣẹ nígbà ayé Aísáyà mú kó dáni lójú pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ọlọ́run ṣe fún ọjọ́ tiwa “yóò ṣẹ láìkùnà. Kì yóò pẹ́.”—Hábákúkù 2:3.
“Omi” Aṣèparun
26, 27. (a) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀? (b) Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà fi han àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà pé yóò ṣẹlẹ̀ lónìí?
26 Aísáyà ń bá ìkìlọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Nítorí ìdí náà pé àwọn ènìyàn yìí ti kọ omi Ṣílóà tí ó rọra ń ṣàn jẹ́ẹ́, tí ayọ̀ ńláǹlà sì wà nítorí Résínì àti ọmọkùnrin Remaláyà; àní nítorí náà, wò ó! Jèhófà yóò gbé omi tí ó ní agbára ńlá tí ó sì pọ̀, tí ó jẹ́ ti Odò náà dìde sí wọn, èyíinì ni ọba Ásíríà àti gbogbo ògo rẹ̀. Dájúdájú, òun yóò sì gòkè wá sórí gbogbo ojú ìṣàn omi rẹ̀, yóò sì gun orí gbogbo bèbè rẹ̀, yóò sì la Júdà já. Ní ti tòótọ́, òun yóò kún bò ó. Yóò kan ọrùn. Ìnàjáde ìyẹ́ apá rẹ̀ yóò sì ṣẹlẹ̀ láti lè kún ìbú ilẹ̀ rẹ, ìwọ Ìmánúẹ́lì!”—Aísáyà 8:5-8.
27 “Àwọn ènìyàn yìí,” ìyẹn ìjọba àríwá ti Ísírẹ́lì, kọ májẹ̀mú tí Jèhófà bá Dáfídì dá. (2 Àwọn Ọba 17:16-18) Lójú tiwọn, bí omi Ṣílóà, ìyẹn omi wọn ní Jerúsálẹ́mù, ṣe ń ṣàn pẹ́sẹ́pẹ́sẹ́ náà ni agbára májẹ̀mú yẹn ṣe rí. Ńṣe ni wọ́n ń yọ̀ ṣìnkìn pé àwọn fẹ́ bá Júdà jagun. Àmọ́ o, wọn ò ní ṣàìjìyà ìwà ìfojútín-ín-rín tí wọ́n hù yìí. Jèhófà yóò jẹ́ kí àwọn ará Ásíríà “kún bò,” tàbí ya bo Síríà àti Ísírẹ́lì mọ́lẹ̀, àní bí Jèhófà yóò ṣe jẹ́ kí ẹ̀ka ìṣèlú ayé yìí kún bo ilẹ̀ ọba ìsìn èké láìpẹ́. (Ìṣípayá 17:16; fi wé Dáníẹ́lì 9:26.) Aísáyà sọ pé, lẹ́yìn náà ni “omi” tó ń kún sí i náà yóò wá “la Júdà já,” tí yóò sì kún “kan ọrùn,” ìyẹn Jerúsálẹ́mù, níbi tí orí (ọba) Júdà ti ń ṣàkóso.b Nígbà tiwa, bẹ́ẹ̀ náà làwọn òṣèlú tí yóò pa ìsìn èké run yóò ṣe ṣùrù bo àwọn ènìyàn Jèhófà, tí wọn yóò mù wọ́n “kan ọrùn.” (Ìsíkíẹ́lì 38:2, 10-16) Kí ni yóò tẹ̀yìn rẹ̀ yọ? Tóò, kí ló ṣẹlẹ̀ láyé Aísáyà? Ǹjẹ́ àwọn ará Ásíríà ya kọjá odi ìlú láti gbá àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ bí? Rárá. Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn.
Ẹ Má Bẹ̀rù—“Ọlọ́run Wà Pẹ̀lú Wa!”
28. Láìka bí àwọn ọ̀tá Júdà ṣe lè sapá tó, kí ni Jèhófà mú kó dá Júdà lójú?
28 Aísáyà kìlọ̀ pé: “Ẹ jẹ́ aṣeniléṣe, ẹ̀yin ènìyàn [tó tako àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú], kí a sì fọ́ yín túútúú; ẹ sì fetí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ wà ní àwọn apá ibi jíjìnnà ilẹ̀ ayé! Ẹ di ara yín lámùrè, kí a sì fọ́ yín túútúú! Ẹ di ara yín lámùrè, kí a sì fọ́ yín túútúú! Ẹ wéwèé ìpètepèrò, a ó sì fọ́ ọ túútúú! Ẹ sọ ọ̀rọ̀ èyíkéyìí, kì yóò sì dúró, nítorí pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa!” (Aísáyà 8:9, 10) Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣẹ nígbà ìṣàkóso Hesekáyà olùṣòtítọ́, ọmọ Áhásì, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà. Nígbà tí àwọn ará Ásíríà fẹjú mọ́ Jerúsálẹ́mù, áńgẹ́lì Jèhófà pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] lára wọn. Dájúdájú, Ọlọ́run wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀ àti ìlà Dáfídì tí ń jọba. (Aísáyà 37:33-37) Bákan náà, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì tí ń bọ̀, yàtọ̀ sí pé Jèhófà yóò rán Ìmánúẹ́lì Ńlá náà láti fọ́ àwọn ọ̀tá Rẹ̀ túútúú, yóò tún gba gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ lé E là pẹ̀lú.—Sáàmù 2:2, 9, 12.
29. (a) Báwo ni àwọn Júù ìgbà ayé Áhásì ṣe yàtọ̀ sí àwọn Júù ti ìgbà ayé Hesekáyà? (b) Èé ṣe tí àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí fi yàgò fún bíbá àwọn ètò ẹ̀sìn àti ìṣèlú ní àjọṣe?
29 Àwọn Júù ìgbà ayé Áhásì kò gbà gbọ́ pé Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn, wọn kò ṣe bí àwọn Júù ti ìgbà ayé Hesekáyà. Wọ́n yàn láti bá Ásíríà wọ àjọṣe, tàbí láti bá wọn di “tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun” láti lè rí ààbò kúrò lọ́wọ́ àpapọ̀ ọmọ ogun Síríà àti Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n, “ọwọ́” Jèhófà mú kí Aísáyà bẹnu àtẹ́ lu “ọ̀nà àwọn ènìyàn yìí,” tàbí ohun tí ọ̀pọ̀ jù lọ ń fẹ́ láti ṣe. Ó kìlọ̀ fún wọn pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rù ohun ẹ̀rù wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́dọ̀ wárìrì nítorí rẹ̀. Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—òun ni Ẹni tí ó yẹ kí ẹ kà sí mímọ́, òun sì ni ó yẹ kí ó jẹ́ ohun ẹ̀rù yín, òun sì ni Ẹni tí ó yẹ kí ó máa mú yín wárìrì.” (Aísáyà 8:11-13) Èyí làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà rí tí wọ́n fi ń yàgò fún bíbá àwọn ètò ẹ̀sìn tàbí ìmùlẹ̀ àwọn òṣèlú di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í gbẹ́kẹ̀ lé wọn. Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ìdánilójú hán-únhán-ún pé Ọlọ́run lágbára láti dáàbò boni. Àbí, bí ‘Jèhófà bá ń bẹ ní ìhà ọ̀dọ̀ wa, kí ni ará ayé lè fi wá ṣe?’—Sáàmù 118:6.
30. Kí ni àtúbọ̀tán àwọn tí kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà?
30 Aísáyà tún wá tẹnu mọ́ ọn pé Jèhófà yóò jẹ́ “ibi ọlọ́wọ̀,” ìyẹn ibi ààbò, fáwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e. Àmọ́, ní ti àwọn tó bá kọ̀ ọ́, ‘ó dájú pé wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú, a ó sì ṣẹ́ wọn, a ó sì dẹkùn mú wọn’—ìwọ̀nyí jẹ́ ọ̀rọ̀ ìṣe kàǹkà-kàǹkà márùn-ún, tí èèyàn ò fi ní ṣiyèméjì nípa àtúbọ̀tán àwọn tí kò bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. (Aísáyà 8:14, 15) Ní ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tó kọ Jésù sílẹ̀ ṣe kọsẹ̀, tí wọ́n sì ṣubú. (Lúùkù 20:17, 18) Ohun kan náà ní ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn tòní tó bá kọ̀ láti túúbá fún Jésù, Ọba ọ̀run tó ti gorí àlééfà.—Sáàmù 2:5-9.
31. Báwo ni àwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Aísáyà àtàwọn tó kọbi ara sí ẹ̀kọ́ rẹ̀?
31 Gbogbo ènìyàn kọ́ ló kọsẹ̀ láyé Aísáyà. Aísáyà sọ pé: “Wíwé ni kí o wé ẹ̀rí tí ń fìdí ọ̀ràn múlẹ̀, fi èdìdì di òfin yí ká láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn mi! Ṣe ni èmi yóò máa bá a nìṣó ní fífojúsọ́nà fún Jèhófà, ẹni tí ń fi ojú rẹ̀ pa mọ́ fún ilé Jékọ́bù, èmi yóò sì ní ìrètí nínú rẹ̀.” (Aísáyà 8:16, 17) Aísáyà àti àwọn tó kọbi ara sí ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní kọ Òfin Ọlọ́run sílẹ̀. Ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jèhófà kò yẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn oníwàkiwà yòókù láyé ìgbà yẹn kọ̀ láti gbẹ́kẹ̀ lé e, tí ìyẹn sì mú kí Jèhófà fi ojú pa mọ́ fún wọn. Kí àwa náà mà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà o, kí ìpinnu tiwa náà sì jẹ́ láti dìrọ̀ mọ́ ìsìn mímọ́ gaara!—Dáníẹ́lì 12:4, 9; Mátíù 24:45; fi wé Hébérù 6:11, 12.
“Àmì” àti “Iṣẹ́ Ìyanu”
32. (a) Lónìí, àwọn wo ló jẹ́ “àmì àti iṣẹ́ ìyanu”? (b) Èé ṣe tí Kristẹni fi ní láti dá yàtọ̀ nínú ayé?
32 Aísáyà wá polongo pé: “Wò ó! Èmi àti àwọn ọmọ tí Jèhófà ti fi fún mi dà bí àmì àti bí iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ẹni tí ń gbé ní Òkè Ńlá Síónì.” (Aísáyà 8:18) Bẹ́ẹ̀ ni, Aísáyà, Ṣeari-jáṣúbù, àti Maheri-ṣalali-hásí-básì jẹ́ àmì ète Jèhófà fún Júdà. Lónìí, Jésù àti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ jẹ́ àmì bákan náà. (Hébérù 2:11-13) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” sì ti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú iṣẹ́ wọn. (Ìṣípayá 7:9, 14; Jòhánù 10:16) Àmọ́ o, àmì ò lè wúlò bí kò bá dá yàtọ̀ láàárín ibi tó wà. Bákan náà, àyàfi bí àwọn Kristẹni bá dá yàtọ̀ nínú ayé yìí, kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, kí wọ́n sì máa fi ìgboyà polongo ète rẹ̀, ni wọ́n fi lè ṣe ojúṣe wọn gẹ́gẹ́ bí àmì.
33. (a) Kí ni àwọn Kristẹni tòótọ́ pinnu láti ṣe? (b) Kí ni yóò jẹ́ kí àwọn Kristẹni tòótọ́ lè dúró gbọn-in gbọn-in?
33 Nígbà náà, ìlànà Ọlọ́run ni kí gbogbo wa máa tẹ̀ lé, kó máà jẹ́ ti ayé yìí. Kí a máa bá a lọ láti dá yàtọ̀ láìbẹ̀rù—bí àmì—ní títẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ tí Jésù Kristi, Aísáyà Ńlá náà, gbà, ìyẹn ni: “Láti pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà . . . àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa.” (Aísáyà 61:1, 2; Lúùkù 4:17-21) Ó dájú pé nígbà tí ìkún omi Ásíríà bá ya lu ilẹ̀ ayé—ì báà tiẹ̀ mù wá dé ọrùn—kò ní gbá Kristẹni tòótọ́ lọ. Gbọn-in gbọn-in la óò dúró nítorí pé “Ọlọ́run wà pẹ̀lú wa.”
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ewé 62 àti 758, Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ló tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Wọ́n tún fi Ásíríà wé ẹyẹ tí apá tó nà “kún ìbú ilẹ̀ rẹ.” Nípa bẹ́ẹ̀, kò síbi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà kò ní dé ní gbogbo ilẹ̀ náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 103]
Aísáyà mú Ṣeari-jáṣúbù dání nígbà tó lọ jíṣẹ́ Jèhófà fún Áhásì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 111]
Èé ṣe tí Aísáyà fi kọ “Maheri-ṣalali-hásí-básì” sára wàláà ńlá kan?