Orí Kẹta
“Ẹ Jẹ́ Kí A Mú Àwọn Ọ̀ràn Tọ́”
1, 2. Ta ni Jèhófà fi àwọn ọba àtàwọn èèyàn Jerúsálẹ́mù àti Júdà wé, èé sì ti ṣe tí èyí fi tọ́?
ÀWỌN olùgbé Jerúsálẹ́mù lè fẹ́ máa dá ara wọn láre lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìbáwí kíkankíkan tó wà nínú Aísáyà 1:1-9. Ó dájú pé wọ́n á fẹ́ máa fi gbogbo ẹbọ tí wọ́n ń rú sí Jèhófà yangàn. Àmọ́, ẹsẹ kẹwàá sí ìkẹẹ̀ẹ́dógún sọ èsì tí Jèhófà fi bẹnu àtẹ́ lu irú ìwà bẹ́ẹ̀. Ó lọ báyìí pé: “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin apàṣẹwàá Sódómù. Ẹ fi etí sí òfin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn Gòmórà.”—Aísáyà 1:10.
2 Kì í ṣe tìtorí ìṣekúṣe nìkan ni wọ́n fi pa Sódómù àti Gòmórà run, oríkunkun àti ìgbéraga pẹ̀lú ohun tó fà á. (Jẹ́nẹ́sísì 18:20, 21; 19:4, 5, 23-25; Ìsíkíẹ́lì 16:49, 50) Ó ní láti jẹ́ pé ńṣe làyà àwọn tó ń gbọ́rọ̀ Aísáyà kó sókè bí wọ́n ṣe gbọ́ tó ń fi wọ́n wé àwọn ènìyàn ìlú ègún wọ̀nyẹn.a Ṣùgbọ́n Jèhófà mọ irú ẹni tí àwọn èèyàn rẹ̀ yà, Aísáyà ò sì ní bomi la ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run láti lè “rìn wọ́n ní etí.”—2 Tímótì 4:3.
3. Kí ni Jèhófà ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ẹbọ àwọn èèyàn náà ‘ti tó òun gẹ́ẹ́,’ èé sì ti ṣe tọ́ràn fi rí bẹ́ẹ̀?
3 Kíyè sí ojú tí Jèhófà fi ń wo ìjọsìn àìfọkànṣe tí àwọn èèyàn rẹ̀ ń ṣe. Ó ní: “‘Àǹfààní kí ni ògìdìgbó àwọn ẹbọ yín jẹ́ fún mi?’ ni Jèhófà wí. ‘Odindi ọrẹ ẹbọ sísun ti àgbò àti ọ̀rá àwọn ẹran tí a bọ́ dáadáa ti tó mi gẹ́ẹ́; èmi kò sì ní inú dídùn sí ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn àti òbúkọ.’” (Aísáyà 1:11) Àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ti gbàgbé pé ẹbọ àwọn kọ́ ni Jèhófà gbára lé. (Sáàmù 50:8-13) Kò nílò ohunkóhun tí aráyé bá fi rúbọ sí i. Nítorí náà, bí àwọn èèyàn wọ̀nyẹn bá rò pé ṣe làwọn ń fi ẹbọ gbà-jẹ́-n-sinmi wọn ṣe Jèhófà lóore, àṣìṣe gbáà ni wọ́n ṣe. Àgbà àkànlò èdè ni Jèhófà lò. Gbólóhùn náà “[wọ́n] ti tó mi gẹ́ẹ́” tún lè túmọ̀ sí “wọ́n ti sú mi” tàbí “mo ti yó bètèkùn.” Ṣé o mọ bó ṣe máa ń rí téèyàn bá ti jẹun yó gan-an dépò pé yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa bì bó bá fojú kan oúnjẹ? Bí ẹbọ wọ̀nyẹn ṣe rí sí Jèhófà nìyẹn o—ó rí i lára gidi gan-an ni!
4. Báwo ni Aísáyà 1:12 ṣe táṣìírí bí wíwá tí àwọn èèyàn ń wá sí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ṣe jẹ́ asán?
4 Jèhófà ń bá a lọ pé: “Nígbà tí ẹ ń wọlé wá láti rí ojú mi, ta ni ó béèrè èyí lọ́wọ́ yín, láti máa tẹ àgbàlá mi?” (Aísáyà 1:12) Òfin Jèhófà fúnra rẹ̀ ha kọ́ ló sọ pé kí àwọn èèyàn yẹn ‘máa wọlé wá láti rí ojú òun,’ ìyẹn ni pé, kí wọ́n wá sínú tẹ́ńpìlì òun ní Jerúsálẹ́mù? (Ẹ́kísódù 34:23, 24) Bẹ́ẹ̀ ni, ṣùgbọ́n wíwá má-póò-rójúù-mi lásán ni wọ́n ń wá, wọ́n kàn ń ṣe ààtò tí ìjọsìn mímọ́ gaara ń béèrè gẹ́gẹ́ bí àṣà ni, ète tí wọ́n fi ń ṣe é kò mọ́ gaara rárá. Lójú Jèhófà, gbogbo wíwá tí wọ́n ń wá sínú àgbàlá rẹ̀ já sí ‘títẹ̀mọ́lẹ̀,’ tí kò ṣàǹfààní kankan ju pé ó kàn ń mú kí ilẹ̀ ibẹ̀ jẹ dànù lásán.
5. Kí ni díẹ̀ lára ohun tí àwọn Júù ń ṣe nínú ìjọsìn wọn, èé sì ti ṣe tí ìwọ̀nyí fi jẹ́ “ẹrù ìnira” fún Jèhófà?
5 Abájọ tí Jèhófà fi wá ń lo gbólóhùn tó túbọ̀ le wàyí! Ó ní: “Ẹ ṣíwọ́ mímú àwọn ọrẹ ẹbọ ọkà tí kò ní láárí wá. Tùràrí—ó jẹ́ ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí fún mi. Òṣùpá tuntun àti sábáàtì, pípe àpéjọpọ̀—èmi kò lè fara da lílo agbára abàmì pa pọ̀ pẹ̀lú àpéjọ ọ̀wọ̀. Ọkàn mi kórìíra àwọn òṣùpá tuntun yín àti àwọn àkókò àjọyọ̀ yín. Wọ́n ti di ẹrù ìnira fún mi; rírù wọ́n ti sú mi.” (Aísáyà 1:13, 14) Ọrẹ ẹbọ ọkà rírú, tùràrí, Sábáàtì ṣíṣe, àti pípe àpéjọpọ̀, gbogbo rẹ̀ ní ń bẹ lára Òfin tí Ọlọ́run fún Ísírẹ́lì. Ní ti “òṣùpá tuntun,” ohun tí Òfin kàn sọ ni pé kí wọ́n máa ṣe é, àmọ́, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn àṣà tó dára wá wọnú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń ṣe é. (Númérì 10:10; 28:11) Wọ́n wá sọ òṣùpá tuntun di sábáàtì oṣooṣù, nígbà tí àwọn èèyàn yóò ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́, wọn a tilẹ̀ kóra jọ láti gba ìtọ́ni látẹnu àwọn wòlíì àti àwọn àlùfáà. (2 Àwọn Ọba 4:23; Ìsíkíẹ́lì 46:3; Ámósì 8:5) Pípa irú àwọn ọjọ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ kò burú. Ṣíṣe wọn nítorí ṣekárími ló burú. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn Júù tún wá ń lo “agbára abàmì,” tó jẹ́ bíbá ẹ̀mí èṣù lò, pa pọ̀ mọ́ bí wọ́n ṣe ń pa Òfin Ọlọ́run mọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà.b Nípa bẹ́ẹ̀, jíjọ́sìn tí wọ́n láwọn ń jọ́sìn Jèhófà jẹ́ “ẹrù ìnira” fún un.
6. Ọ̀nà wo ni nǹkan fi “sú” Jèhófà?
6 Ṣùgbọ́n báwo ni nǹkan ṣe lè “sú” Jèhófà? Bẹ́ẹ̀, ó ní ‘ọ̀pọ̀ yanturu okun alágbára gíga . . . Àárẹ̀ kì í mú un, bẹ́ẹ̀ ni agara kì í dá a.’ (Aísáyà 40:26, 28) Àkànlò èdè ajúwe ni Jèhófà ń lò láti fi jẹ́ kí a mọ bọ́ràn náà ṣe rí lára òun. Ǹjẹ́ ó tíì ṣẹlẹ̀ sí ọ rí pé o ru ẹrù tó wúwo pẹ́, tó sì wọ̀ ọ́ lọ́rùn gan-an dépò pé ńṣe lo ṣáà ń wá bóo ṣe máa sọ̀ ọ́ kalẹ̀? Bí ìjọsìn alágàbàgebè tí àwọn ènìyàn yẹn ń ṣe ṣe rí lára Jèhófà nìyẹn.
7. Èé ṣe tí Jèhófà kò fetí sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́?
7 Jèhófà wá tẹnu bọ̀rọ̀ lórí ohun téèyàn fúnra rẹ̀ ń ṣe nínú ìjọsìn, tó sì ń tìsàlẹ̀ ọkàn wá. Ó ní: “Nígbà tí ẹ bá sì tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ yín, èmi yóò fi ojú mi pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ yín. Bí ẹ tilẹ̀ gba àdúrà púpọ̀, èmi kò ní fetí sílẹ̀; àní ọwọ́ yín kún fún ìtàjẹ̀sílẹ̀.” (Aísáyà 1:15) Títẹ́ àtẹ́lẹwọ́, ká tẹ́ ọwọ́ méjèèjì, jẹ́ àmì pé èèyàn ń bẹ̀bẹ̀ fún nǹkan. Àmọ́, lójú Jèhófà, ìṣe yẹn ti dasán nítorí pé ọwọ́ tó kún fún ẹ̀jẹ̀ ni ọwọ́ àwọn èèyàn yẹn. Ìwà ipá gbòde kan ní ilẹ̀ náà. Níni àwọn aláìlágbára lára wọ́pọ̀ gan-an ni. Ohun ìríra ló jẹ́ pé kí irú àwọn onímọtara-ẹni-nìkan tó ń hùwà àìdáa bẹ́ẹ̀ wá máa gbàdúrà sí Jèhófà pé kó bù kún àwọn. Abájọ tí Jèhófà fi sọ pé, “èmi kò ní fetí sílẹ̀”!
8. Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ń dá lónìí, báwo sì ni àwọn Kristẹni kan ṣe jìn sínú irú ọ̀fìn kan náà?
8 Lọ́jọ́ tiwa, bákan náà ni Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe kùnà láti tipasẹ̀ àdúrà asán tó ń gbà láìdabọ̀ àti àwọn “iṣẹ́” ìjọsìn rẹ̀ mìíràn rójú rere Ọlọ́run. (Mátíù 7:21-23) Ó ṣe pàtàkì gidigidi pé kí a má jìn sínú ọ̀fìn kan náà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí Kristẹni máa jìn sọ́fìn dídẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, kó sì wá ronú pé báṣìírí òun ò bá ṣá ti tú, tóun sì túbọ̀ fi kún ìgbòkègbodò òun nínú ìjọ Kristẹni, iṣẹ́ rere wọ̀nyẹn yóò máa dí ẹ̀ṣẹ̀ òun bákan ṣá. Irú ìgbòkègbodò tó jẹ́ ṣíṣojú ayé bẹ́ẹ̀ kò dùn mọ́ Jèhófà nínú. Oògùn kan ṣoṣo ló wà fún àìsàn tẹ̀mí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e nínú Aísáyà ṣe fi hàn.
Oògùn Àìsàn Tẹ̀mí
9, 10. Báwo ni ìmọ́tótó ti ṣe pàtàkì tó nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà?
9 Jèhófà, Ọlọ́run ìyọ́nú, wá bẹ̀rẹ̀ sí lo ohùn pẹ̀lẹ́ tó túbọ̀ fani mọ́ra wàyí. Ó ní: “Ẹ wẹ̀; ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́; ẹ mú búburú ìbánilò yín kúrò ní iwájú mi; ẹ ṣíwọ́ ṣíṣe búburú. Ẹ kọ́ ṣíṣe rere; ẹ wá ìdájọ́ òdodo; ẹ tún ojú ìwòye aninilára ṣe; ẹ ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba; ẹ gba ẹjọ́ opó rò.” (Aísáyà 1:16, 17) Oríṣi ohun àìgbọ́dọ̀máṣe, tàbí àṣẹ mẹ́sàn-án la rí níhìn-ín. Mẹ́rin àkọ́kọ́ jẹ́ ti ṣíṣe àtúnṣe nítorí wọ́n jẹ mọ́ yíyọwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá; márùn-ún tó kù jẹ mọ́ rere ṣíṣe, tó lè múni rí ìbùkún gbà lọ́dọ̀ Jèhófà.
10 Apá pàtàkì nínú ìjọsìn mímọ́ gaara ní ìwẹ̀ àti ìmọ́tótó jẹ́ nígbà gbogbo. (Ẹ́kísódù 19:10, 11; 30:20; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Àmọ́, ohun tí Jèhófà ń fẹ́ ni pé kí ìwẹ̀nùmọ́ yẹn dénú lọ́hùn-ún, àní kó wọnú ọkàn àwọn olùjọsìn rẹ̀ lọ. Mímọ́ tónítóní nípa tẹ̀mí àti nínú ìwà ló ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn sì ni ohun tí Jèhófà ń tọ́ka sí. Àṣẹ méjì àkọ́kọ́ ní Ais 1 ẹsẹ kẹrìndínlógún kì í ṣe àsọtúnsọ lásán. Ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìlò èdè Hébérù dá a lábàá pé, “ẹ wẹ̀,” tó ṣáájú tọ́ka sí ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ nínú ìmọ́tótó, nígbà tí ìkejì, “ẹ jẹ́ kí ara yín mọ́,” tọ́ka sí ìsapá tí a ń ṣe nìṣó kí ìmọ́tótó yẹn lè máa bá a lọ bẹ́ẹ̀.
11. Láti lè gbéjà ko ẹ̀ṣẹ̀, kí ló yẹ kí a ṣe, kí ni a kò sì gbọ́dọ̀ ṣe láé?
11 Kò sóhun tí a lè fi pa mọ́ fún Jèhófà. (Jóòbù 34:22; Òwe 15:3; Hébérù 4:13) Nítorí náà, ohun kan ni àṣẹ rẹ̀ tó sọ pé, “Ẹ mú búburú ìbánilò yín kúrò ní iwájú mi,” lè túmọ̀ sí, ìyẹn ni, láti ṣíwọ́ ibi ṣíṣe. Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká má gbìyànjú láti bo ẹ̀ṣẹ̀ ńlá mọ́lẹ̀, nítorí pé bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀ ńṣe là ń dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀. Òwe 28:13 kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.”
12. (a) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí a “kọ́ ṣíṣe rere”? (b) Báwo ni àwọn alàgbà ní pàtàkì ṣe lè fi ìtọ́ni tó sọ pé “ẹ wá ìdájọ́ òdodo,” àti “ẹ tún ojú ìwòye aninilára ṣe” sílò?
12 Ẹ̀kọ́ púpọ̀ ni a lè rí kọ́ látinú àwọn ohun dáadáa tí Jèhófà pa láṣẹ fúnni láti ṣe ní Aísáyà orí kìíní, ẹsẹ kẹtàdínlógún. Ṣàkíyèsí pé kò kàn sọ pé “ẹ ṣe rere” ṣùgbọ́n ó ní “ẹ kọ́ ṣíṣe rere.” Fífúnra ẹni kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló lè múni lóye ohun tó dára lójú Ọlọ́run kó sì wuni láti ṣe. Bákan náà, Jèhófà kò kàn sọ pé “ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo” ṣùgbọ́n ó ní “ẹ wá ìdájọ́ òdodo.” Àní àwọn alàgbà onírìírí pàápàá ní láti wá inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fínnífínní láti lè mọ ọ̀nà tó jẹ́ ti ìdájọ́ òdodo nígbà tí àwọn ọ̀ràn kan bá díjú. Ó sì tún jẹ́ ojúṣe wọn láti “tún ojú ìwòye aninilára ṣe,” gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Jèhófà tó tẹ̀ lé e ṣe wí. Ìtọ́ni wọ̀nyí ṣe pàtàkì fún àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn lónìí, nítorí pé wọ́n ń fẹ́ láti dáàbò bo agbo kúrò lọ́wọ́ “àwọn aninilára ìkookò.”—Ìṣe 20:28-30.
13. Báwo ni àwa lónìí ṣe lè fi àṣẹ tó kan ọ̀ràn ọmọdékùnrin aláìníbaba àti opó sílò?
13 Àṣẹ méjì tó gbẹ̀yìn jẹ mọ́ ọ̀ràn àwọn tí ìyà lè tètè jẹ nínú àwọn ènìyàn Ọlọ́run—àwọn aláìníbaba àti opó. Irú wọn làwọn èèyàn ayé yìí máa ń tètè rẹ́ jẹ; èyí kò gbọ́dọ̀ wáyé láàárín àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ a máa “ṣe ìdájọ́” nítorí àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin aláìníbaba tó wà nínú ìjọ, wọn a ṣèrànwọ́ láti rí i pé wọ́n rí ìdájọ́ òdodo gbà, pé wọ́n sì wà láàbò nínú ayé tó ń fẹ́ máa rẹ́ wọn jẹ tó sì ń fẹ́ máa kó ìwà ìbàjẹ́ ràn wọ́n. Àwọn alàgbà a máa “gba ẹjọ́” opó “rò” tàbí pé wọ́n a máa “gbèjà” àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Hébérù náà ṣe tún lè túmọ̀ sí. Ní tòdodo, gbogbo Kristẹni ní láti jẹ́ ibi ìsádi, ìtùnú, àti ìdájọ́ òdodo fún àwọn aláìní àárín wa nítorí pé wọ́n ṣeyebíye lójú Jèhófà.—Míkà 6:8; Jákọ́bù 1:27.
14. Ìhìn iṣẹ́ dáadáa wo ni Aísáyà 1:16, 17 gbé jáde?
14 Ìsọfúnni tí Jèhófà fi àwọn àṣẹ mẹ́sàn-án wọ̀nyí gbé jáde mà fẹsẹ̀ rinlẹ̀ o, ó mà dára o! Nígbà mìíràn àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ máa ń ro ara wọn pin pé àwọn ò kàn tiẹ̀ lè ṣe rere mọ́ ni. Irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ a máa múni rẹ̀wẹ̀sì. Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n tún lòdì. Jèhófà mọ̀—ó sì ń fẹ́ ká mọ̀—pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Òun, ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí lè ṣíwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ dídá, kó sì yí padà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe rere dípò ẹ̀ṣẹ̀ tó ń dá.
Ẹ̀bẹ̀ Oníyọ̀ọ́nú, Tó Tọ̀nà
15. Kí làwọn èèyàn sábà máa ń ṣi gbólóhùn náà “ẹ . . . jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa” lóye sí, kí ló sì túmọ̀ sí ní ti gidi?
15 Jèhófà wá túbọ̀ lo ohùn pẹ̀lẹ́tù tòun tìyọ́nú sí i. Ó sọ pé: “‘Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa,’ ni Jèhófà wí. ‘Bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín tilẹ̀ rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò, a ó sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì; bí wọ́n tilẹ̀ pupa bí aṣọ pípọ́ndòdò, wọn yóò dà bí irun àgùntàn gẹ́lẹ́.’” (Aísáyà 1:18) Àwọn èèyàn sábà máa ń ṣi ìkésíni tó wà ní ìbẹ̀rẹ̀ ẹsẹ tó gbámúṣé yìí lóye. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì The New English Bible sọ pé, “Jẹ́ kí a jọ la ọ̀ràn yé ara wa”—bíi pé ìhà méjèèjì ló ní láti jùmọ̀ gbà fúnra wọn kí wọ́n lè fìmọ̀ ṣọ̀kan. Kò rí bẹ́ẹ̀ o! Jèhófà kò lè jẹ̀bi rárá, áńbọ̀sìbọ́sí nínú bó ṣe bá àwọn ọlọ̀tẹ̀ alágàbàgebè wọ̀nyí lò. (Diutarónómì 32:4, 5) Ohun tí ẹsẹ yìí ń sọ kì í ṣe ti àpérò àjọgbà láàárín ojúgbà ẹni bí kò ṣe àpéjọ láti fìdí ìdájọ́ òdodo múlẹ̀. Bíi pé Jèhófà pe Ísírẹ́lì lẹ́jọ́ ni.
16, 17. Báwo ni a ṣe mọ̀ pé Jèhófà ń fẹ́ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá jini?
16 Ìyẹn lè ṣe bí ẹní kani láyà, àmọ́ o, Jèhófà ni Onídàájọ́ tó láàánú tó sì níyọ̀ọ́nú jù lọ. Bó ṣe máa ń dárí jini tó kò láfiwé rárá ni. (Sáàmù 86:5) Òun nìkan ló lè kó gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì tó “rí bí aṣọ rírẹ̀dòdò” kó sì fọ̀ wọ́n dànù, kó sì “sọ wọ́n di funfun gẹ́gẹ́ bí ìrì dídì.” Kò sí ìsapá ènìyàn, kò sọ́gbọ́n iṣẹ́ ìsìn téèyàn lè ta, kò sẹ́bọ, tàbí àdúrà tó lè mú àbààwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ kúrò. Ìdáríjì Jèhófà nìkan ló lè wẹ ẹ̀ṣẹ̀ nù. Ọlọ́run a máa darí irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ jini níbàámu pẹ̀lú ìlànà tó gbé kalẹ̀, lára rẹ̀ sì ni ìrònúpìwàdà tòótọ́ látọkànwá.
17 Òdodo ọ̀rọ̀ yìí ṣe pàtàkì gan-an tó bẹ́ẹ̀ tí Jèhófà fi fi ọ̀rọ̀ tó jọ ọ́ tún un sọ lọ́nà ewì pé, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó pupa bí “aṣọ pípọ́ndòdò,” yóò funfun bí irun àgùntàn tuntun, tí wọn kò tí ì pa láró. Ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí a mọ̀ ni pé òun ni Olùdárí-ẹ̀ṣẹ̀-jini lóòótọ́, títí kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì pàápàá, bó bá sáà ti rí i pé a ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Bí èyí bá ṣòro fún àwọn kan láti gbà gbọ́, tí wọ́n rò pé ọ̀ràn tiwọn ti tayọ ìyẹn, kí wọ́n wo àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mánásè. Ó ń dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì—fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Síbẹ̀, ó ronú pìwà dà, ó sì rí ìdáríjì gbà. (2 Kíróníkà 33:9-16) Jèhófà ń fẹ́ kí gbogbo wa mọ̀, títí kan àwọn tó ti dá àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì, pé kò tíì pẹ́ jù fún wa láti “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” láàárín àwa àti òun.
18. Yíyàn wo ni Jèhófà fi síwájú àwọn ènìyàn rẹ̀ ọlọ̀tẹ̀?
18 Jèhófà rán àwọn ènìyàn rẹ̀ létí pé wọ́n ní láti yan èyí tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Ó ní: “Bí ẹ bá fi ẹ̀mí ìmúratán hàn, tí ẹ sì fetí sílẹ̀, ẹ ó jẹ ohun rere ilẹ̀ náà. Ṣùgbọ́n bí ẹ bá kọ̀, tí ẹ sì jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní ti gidi, idà ni a ó fi jẹ yín run; nítorí pé ẹnu Jèhófà gan-an ti sọ ọ́.” (Aísáyà 1:19, 20) Ìwà híhù ni Jèhófà ń tẹnu mọ́ níhìn-ín, ó sì tún lo àkànlò èdè ajúwe mìíràn láti fi gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ. Yíyàn tó wà fún Júdà rèé: Jẹun tàbí kóo di ìjẹ. Bí wọ́n bá lẹ́mìí fífẹ́ láti gbọ́ kí wọ́n sì gbà sí Jèhófà lẹ́nu, wọn yóò jẹ èso rere ilẹ̀ náà. Àmọ́, bó bá jẹ́ ìwà ọlọ̀tẹ̀ wọn ni wọ́n tẹra mọ́, wọn yóò di ìjẹ—lẹ́nu idà àwọn ọ̀tá wọn! Kò tiẹ̀ ṣeé ronú kàn ni pé àwọn èèyàn kan yóò yan idà àwọn ọ̀tá wọn dípò àánú àti ìpèsè rẹpẹtẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tí ń dárí jini. Ṣùgbọ́n o, ohun tí Jerúsálẹ́mù ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹsẹ tí ọpọ́n sún kàn nínú Aísáyà ṣe fi hàn.
Kíkọrin Arò Sórí Ìlú Àyànfẹ́ Náà
19, 20. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe gbé ìmọ̀lára tó ní yọ látàrí dídà tí wọ́n dà á? (b) Ọ̀nà wo ni ‘òdodo gbà fi wọ̀ sí inú Jerúsálẹ́mù rí’?
19 Nínú Aísáyà 1:21-23, a wá rí bí ìwà ibi Jerúsálẹ́mù ṣe gàgáàrá tó wàyí. Aísáyà wá gbẹ́nu lé ewì onímìísí, orin tàbí ohùn arò ló lò, ó ní: “Ẹ wo bí ìlú ìṣòtítọ́ ti di kárùwà! Ó kún fún ìdájọ́ òdodo rí; òdodo ti máa ń wọ̀ sí inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí, ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó kún fún àwọn òṣìkàpànìyàn.”—Aísáyà 1:21.
20 Ìlú Jerúsálẹ́mù mà kúkú bara ẹ̀ jẹ́ o! Ìlú tó jẹ́ olóòótọ́ aya nígbà kan rí, ó ti di kárùwà báyìí. Kí ni ì bá tún gbé ìmọ̀lára tí Jèhófà ní látàrí dídà tí wọ́n dà á àti jíjá tí wọ́n já a kulẹ̀ yọ lọ́nà tó ṣe kedere tó báyìí? “Òdodo ti máa ń wọ̀ sí inú” ìlú yìí “tẹ́lẹ̀ rí.” Ìgbà wo nìyẹn? Tóò, kí Ísírẹ́lì tó wáyé pàápàá, láyé ìgbà Ábúráhámù lọ́hùn-ún, Sálẹ́mù ni wọ́n ń pe ìlú yìí. Ọkùnrin kan tó jẹ́ ọba àti àlùfáà ní ń ṣàkóso ibẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni Melikisédékì, tó túmọ̀ sí “Ọba Òdodo,” ó sì hàn gbangba pé orúkọ tó yẹ ẹ́ gan-an ni. (Hébérù 7:2; Jẹ́nẹ́sísì 14:18-20) Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn Melikisédékì, ògo Jerúsálẹ́mù yọ nígbà tí Dáfídì àti Sólómọ́nì jẹ́ ọba ibẹ̀. “Òdodo ti máa ń wọ̀ sí inú rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí,” pàápàá nígbà tí àwọn ọba rẹ̀ ń fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún àwọn èèyàn ibẹ̀ nípa rírìn ní ọ̀nà Jèhófà. Àmọ́ o, láyé Aísáyà, gbogbo ìwọ̀nyẹn ti dìtàn àtijọ́.
21, 22. Kí ni ìdàrọ́ àti àdàlù ọtí bíà dúró fún, èé ṣe tí irú àpèjúwe yẹn fi tọ́ sí àwọn aṣáájú Júdà?
21 Ó jọ pé àwọn aṣáájú àwọn èèyàn náà ń dá kún ìṣòro ibẹ̀. Aísáyà ń bá orin arò rẹ̀ lọ pé: “Fàdákà rẹ pàápàá ti di ìdàrọ́. A ti fi omi ṣe àdàlù ọtí bíà àlìkámà rẹ. Àwọn ọmọ aládé rẹ jẹ́ alágídí àti alájọṣe pẹ̀lú àwọn olè. Gbogbo wọn jẹ́ olùfẹ́ àbẹ̀tẹ́lẹ̀ àti olùlépa àwọn ẹ̀bùn. Wọn kì í ṣe ìdájọ́ ọmọdékùnrin aláìníbaba; ẹjọ́ opó pàápàá ni wọn kì í sì í gbà wọlé.” (Aísáyà 1:22, 23) Àpèjúwe méjì tó tẹ̀ léra, tó ṣe kedere, fojú ẹni sọ́nà fún ohun tí yóò tẹ̀ lé e. Alágbẹ̀dẹ kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ń ré ìdàrọ́ dànù kúrò lójú fàdákà tó ń dà. Bí ìdàrọ́ làwọn ọmọ aládé Ísírẹ́lì rí, wọn kò rí bíi fàdákà. Ààtàn ló yẹ wọ́n. Wọn ò wúlò mọ́, ńṣe ni wọ́n dà bí ọtí bíà tí wọ́n ti da omi lù tí gbogbo adùn rẹ̀ sì ti bàjẹ́. Irú ọtí bẹ́ẹ̀ kò wúlò fún nǹkan kan, ńṣe ló yẹ ká yí i dànù!
22 Ais 1 Ẹsẹ kẹtàlélógún jẹ́ ká rí ìdí tó fi tọ́ láti fi àwọn aṣáájú wọ̀nyẹn wé irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Òfin Mósè gbé àwọn èèyàn Ọlọ́run ga, ó yà wọ́n sọ́tọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣe bẹ́ẹ̀ nípa sísọ pé wọ́n gbọ́dọ̀ dáàbò bo àwọn aláìníbaba àti opó. (Ẹ́kísódù 22:22-24) Àmọ́, láyé ìgbà Aísáyà, àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba kò lè fi bẹ́ẹ̀ retí àtirí ìdájọ́ òdodo gbà. Ní ti opó, kò tilẹ̀ lè rẹ́ni tẹ́tí gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ ni ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé kó rẹ́ni gbèjà òun. Ó tì o, ọ̀ràn tara wọn ni àwọn onídàájọ́ àti aṣáájú wọ̀nyẹn kàn gbájú mọ́—wọ́n ń wá àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kiri, wọ́n ń lépa ọ̀nà àtirí ẹ̀bùn gbà, wọ́n sì di alájọṣe pẹ̀lú àwọn olè, ní ti pé wọ́n ń dáàbò bo àwọn ọ̀daràn tí wọ́n sì ń jẹ́ kí ìyà jẹ àwọn tí àwọn ọ̀daràn ṣe lọ́ṣẹ́. Lékè gbogbo èyí, wọ́n tún jẹ́ “alágídí,” tàbí olóríkunkun, nínú ìwà àìtọ́ tí wọ́n ń hù. Áà, ó mà ṣe o!
Jèhófà Yóò Yọ́ Àwọn Ènìyàn Rẹ̀ Mọ́
23. Kí ni Jèhófà sọ nípa bọ́ràn àwọn ọ̀tá rẹ̀ ṣe rí lára rẹ̀?
23 Jèhófà kò ní gbà kí irú àṣìlò agbára bẹ́ẹ̀ máa wà títí láé. Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Nítorí náà, àsọjáde Olúwa tòótọ́, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ẹni Alágbára Ísírẹ́lì, ni pé: ‘Àháà! Èmi yóò mú ìtura bá ara mi kúrò lọ́wọ́ àwọn elénìní mi, dájúdájú, èmi yóò gbẹ̀san ara mi lára àwọn ọ̀tá mi.’” (Aísáyà 1:24) Ohun mẹ́ta ni a fi pe Jèhófà níhìn-ín, tó ń tẹnu mọ́ ipò rẹ̀ títọ́ gẹ́gẹ́ Olúwa àti bí agbára rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Ó ṣeé ṣe kí kíké tí Jèhófà ké pé, “Àháà!” fi hàn pé àánú fẹ́ kúrò lọ́rọ̀ yìí, ó wá fẹ́ fìyà jẹ wọ́n nínú ìrunú rẹ̀ wàyí. Ó dájú pé ìdí wà fún èyí.
24. Irú ọ̀nà ìyọ́mọ́ wo ni Jèhófà pète láti lò sí ọ̀ràn àwọn ènìyàn rẹ̀?
24 Àwọn ènìyàn Jèhófà sọ ara wọn dọ̀tá rẹ̀. Ẹ̀san tọ́ sí wọn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Jèhófà yóò “mú ìtura” bá ara rẹ̀ tàbí pé yóò já wọn kúrò lọ́rùn ara rẹ̀. Èyí ha túmọ̀ sí pé ṣe ni àwọn ènìyàn tí ń jórúkọ mọ́ ọn yóò pa rẹ́ láéláé ni? Rárá o, nítorí pé Jèhófà ń bá a lọ láti sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò sì yí ọwọ́ mi padà sára rẹ, èmi yóò sì yọ́ ìdàrọ́ rẹ dànù bí ẹni pé pẹ̀lú ọṣẹ ìfọṣọ, èmi yóò sì mú gbogbo ohun ìdọ̀tí rẹ kúrò.” (Aísáyà 1:25) Jèhófà wá lo àpèjúwe bí wọ́n ṣe ń yọ́ nǹkan mọ́. Láyé àtijọ́, ayọ́hunmọ́ sábà máa ń fi ọṣẹ ìfọṣọ kún ohun èlò rẹ̀ láti lè yọ ìdàrọ́ kúrò lára irin iyebíye náà. Bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà, ẹni tí kò ka àwọn ènìyàn rẹ̀ sí èyí tó ti burú kanlẹ̀ porogodo, yóò ṣe ‘fi ìyà jẹ wọ́n dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.’ Kìkì “ohun ìdọ̀tí”—àwọn alágídí, tí kò wúlò, tó kọ̀ láti gbẹ̀kọ́ kí wọ́n sì ṣègbọràn—ni yóò mú kúrò láàárín wọn.c (Jeremáyà 46:28) Ní kíkọ tí Aísáyà kọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, ìtàn ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú ló láǹfààní láti kọ sílẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn.
25. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe yọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa? (b) Ìgbà wo ni Jèhófà yọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ láwọn àkókò òde òní?
25 Jèhófà sì yọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ lóòótọ́, ó sì mú ìdàrọ́, ìyẹn àwọn aṣáájú oníwàkiwà àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ yòókù kúrò. Lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ní ìgbà pípẹ́ lẹ́yìn ìgbà ayé Aísáyà, wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run, wọ́n sì kó àwọn olùgbé ibẹ̀ lọ sí ìgbèkùn fún àádọ́rin ọdún ní Bábílónì. Ní àwọn ọ̀nà kan, èyí bá ohun kan tí Ọlọ́run ṣe ní àkókò gígùn lẹ́yìn ìgbà náà mu. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Málákì 3:1-5, tí wọ́n kọ nígbà pípẹ́ lẹ́yìn ìgbèkùn ní Bábílónì, fi hàn pé Ọlọ́run yóò tún ṣe iṣẹ́ ìyọ́mọ́ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó tọ́ka sí àkókò kan tí Jèhófà Ọlọ́run yóò wá sínú tẹ́ńpìlì rẹ̀ tẹ̀mí, tí Jésù Kristi “ońṣẹ́ májẹ̀mú” rẹ̀ yóò sì bá a wá. Ó dájú pé ẹ̀yìn Ogun Àgbáyé Kìíní lèyí ṣẹlẹ̀. Jèhófà bẹ gbogbo àwọn tó láwọn jẹ́ Kristẹni wò, ó sì sẹ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ́ kúrò lára àwọn èké Kristẹni. Kí ni àbájáde rẹ̀?
26-28. (a) Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ wo ni Aísáyà 1:26 ní? (b) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ní ìmúṣẹ nígbà tiwa? (d) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe lè ṣàǹfààní fún àwọn alàgbà lónìí?
26 Jèhófà dáhùn pé: “Èmi yóò sì tún mú àwọn onídàájọ́ padà wá fún ọ gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà àkọ́kọ́, àti àwọn agbani-nímọ̀ràn wá fún ọ gẹ́gẹ́ bí ti ìbẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn èyí, a óò máa pè ọ́ ní Ìlú Ńlá Òdodo, Ìlú Ìṣòtítọ́. Ìdájọ́ òdodo ni a ó fi tún Síónì fúnra rẹ̀ rà padà, a ó sì fi òdodo ṣe ìràpadà àwọn tí ń padà bọ̀ lára àwọn tí ó jẹ́ tirẹ̀.” (Aísáyà 1:26, 27) Ìmúṣẹ àkọ́kọ́ tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí máa ní, orí Jerúsálẹ́mù ìgbàanì ló ṣẹ sí. Lẹ́yìn tí àwọn tó lọ sí ìgbèkùn padà dé sí ìlú wọn ọ̀wọ́n lọ́dún 537 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn olóòótọ́ onídàájọ́ àti agbani-nímọ̀ràn tún padà wà bíi tàwọn tó wà látijọ́. Wòlíì Hágáì àti Sekaráyà, Jóṣúà àlùfáà, Ẹ́sírà akọ̀wé, àti gómìnà Serubábélì, gbogbo wọn pátá ló tọ́ àwọn àṣẹ́kù olùṣòtítọ́ tó padà wálé sọ́nà, tí wọ́n sì darí wọn láti rìn ní ọ̀nà Ọlọ́run. Àmọ́ o, ìmúṣẹ tó tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì ju ìyẹn wáyé ní ọ̀rúndún ogún yìí.
27 Ní 1919, àwọn ènìyàn Jèhófà lóde òní bọ́ nínú sáà ìdánwò. Wọ́n gba ìdáǹdè kúrò lóko ẹrú Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ìyàtọ̀ tí ń bẹ láàárín àṣẹ́kù àwọn ẹni àmì òróró olùṣòtítọ́ yẹn àti àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù apẹ̀yìndà wá hàn kedere. Ọlọ́run wá bù kún àwọn ènìyàn rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i, ní ‘mímú àwọn onídàájọ́ àti àwọn agbani-nímọ̀ràn padà wá fún wọn,’ ìyẹn ni, àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ tí ń fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ìtọ́ni níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, kì í ṣe níbàámu pẹ̀lú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ló sì wà láàárín àwọn “agbo kékeré” tó ń dín kù sí i àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ “àwọn àgùntàn mìíràn” tó ń pọ̀ sí i lóde òní.—Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16; Aísáyà 32:1, 2; 60:17; 61:3, 4.
28 Àwọn alàgbà máa ń fi sọ́kàn pé àwọn máa ń ṣe iṣẹ́ “àwọn onídàájọ́” nínú ìjọ nígbà mìíràn, láti lè mú kí ìwà híhù àti ipò tẹ̀mí ibẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní àti láti tọ́ àwọn tó bá ṣe aṣemáṣe sọ́nà. Ṣíṣe àwọn nǹkan bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, ṣíṣàfarawé bó ṣe ń ṣèdájọ́ òdodo rẹ̀ lọ́nà àánú, láìfì sọ́tùn-ún tàbí fì sósì, ló jẹ wọ́n lógún jù. Àmọ́ o, nínú àwọn ọ̀ràn tó pọ̀ jù lọ, iṣẹ́ “agbani-nímọ̀ràn” ni wọ́n máa ń ṣe. Dájúdájú, èyí yàtọ̀ gédégédé sí ṣíṣe bí ọba tàbí bí òṣìkà agbonimọ́lẹ̀, wọ́n sì máa ń sapá gidigidi láti rí i pé ohun tó jẹ mọ́ ṣíṣe bí ẹní “ń jẹ olúwa lé àwọn tí í ṣe ogún Ọlọ́run lórí” kò tiẹ̀ wáyé rárá nínú ìṣesí àwọn.—1 Pétérù 5:3.
29, 30. (a) Kí ni Jèhófà kéde sórí àwọn tó kọ̀ láti jàǹfààní látinú ọ̀nà ìyọ́mọ́ yìí? (b) Ọ̀nà wo ni àwọn igi àti ọgbà àwọn èèyàn náà gbà di “ìtìjú” fún wọn?
29 “Ìdàrọ́” tí Aísáyà wá mẹ́nu kàn nínú àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ńkọ́? Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí àwọn tó kọ̀ láti jàǹfààní látinú ìyọ́mọ́ tí Ọlọ́run ń ṣe? Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ìfọ́yángá àwọn adìtẹ̀ àti ti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóò sì jẹ́ lẹ́ẹ̀kan náà, àwọn tí ó fi Jèhófà sílẹ̀ yóò sì wá sí òpin wọn. Nítorí ìtìjú yóò bá wọn ní ti àwọn igi ràbàtà tí ojú yín wọ̀, ẹ ó sì tẹ́ nítorí àwọn ọgbà tí ẹ ti yàn.” (Aísáyà 1:28, 29) Àwọn tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ tí wọ́n sì ṣẹ̀ sí Jèhófà, tí wọ́n kọ etí ikún sí iṣẹ́ ìkìlọ̀ tí àwọn wòlíì jẹ́ fún wọn títí tó fi pẹ́ jù, kúkú “fọ́ yángá” lóòótọ́, wọ́n sì “wá sí òpin wọn.” Èyí ṣẹlẹ̀ lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa. Ṣùgbọ́n kí wá ni àwọn igi àti ọgbà tó tọ́ka sí yìí túmọ̀ sí?
30 Ìṣòro ìbọ̀rìṣà ni àwọn ará Jùdíà sáà ń kó sí léraléra. Abẹ́ àwọn igi, inú ọgbà, àti igbó ṣúúrú ni wọ́n sábà máa ń lò tí wọ́n bá fẹ́ hùwà ìbàjẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn olùjọsìn Báálì àti Áṣítórétì àlè rẹ̀ gbà gbọ́ pé ńṣe ni àwọn òrìṣà méjèèjì máa ń kú tí wọ́n á sì wà nínú ibojì nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. Láti lè mú kí wọ́n ta jí, kí wọ́n sì bára wọn lò pọ̀, kí ilẹ̀ wọn bàa lè méso jáde, àwọn tí ń bọ òrìṣà wọ̀nyẹn a kóra jọ sábẹ́ àwọn igi “ọlọ́wọ̀” nínú àwọn igbó ṣúúrú tàbí nínú ọgbà láti máa ṣe ìṣekúṣe burúkú lónírúurú. Bí òjò bá sì ti rọ̀, tí ilẹ̀ sì méso jáde, òrìṣà wọ̀nyẹn ni wọ́n ń fọpẹ́ fún; àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn á wá fi ìyẹn ṣẹ̀rí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tí wọ́n ní. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jèhófà fọ́ àwọn ọlọ́tẹ̀ abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn yángá, òòṣà kankan kò dáàbò bò wọ́n. Àwọn igi àti ọ̀gbà tí kò lè ta pútú wọ̀nyẹn di “ìtìjú” fún àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn.
31. Kí ló ń bọ̀ wá sórí àwọn abọ̀rìṣà wọ̀nyẹn tó tún burú ju ìtìjú lọ?
31 Àmọ́ ṣá, ohun tó ń bọ̀ wá sórí àwọn èèyàn Júdà abọ̀rìṣà tún burú ju ìtìjú lọ. Jèhófà wá yí àpèjúwe yẹn padà, ó kúkú wá fi abọ̀rìṣà fúnra rẹ̀ wé igi. Ó sọ pé: “Nítorí ẹ ó dà bí igi ńlá tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé ti ń rọ, àti bí ọgbà tí kò ní omi.” (Aísáyà 1:30) Wẹ́kú ni àpèjúwe yìí ṣe lójú irú ipò ojú ọjọ́ olóoru, ọlọ́gbẹlẹ̀, tí ń bẹ ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Kò sí igi tàbí ọgbà tó lè wà pẹ́ títí tí kò bá ń rí omi déédéé. Bí irú irúgbìn bẹ́ẹ̀ bá sì ti gbẹ́, kì í pẹ́ gbiná. Nípa bẹ́ẹ̀, àpèjúwe tó wà ní Ais 1 ẹsẹ kọkànlélọ́gbọ̀n kàn bọ́ sí i wẹ́kú ni.
32. (a) Ta ni “ọkùnrin tí ó ní okun inú” tí ẹsẹ kọkànlélọ́gbọ̀n tọ́ka sí? (b) Ọ̀nà wo ni yóò gbà dà bí “èétú okùn,” “ìtapàrà” wo ni yóò mú kó gbiná, kí sì ni yóò yọrí sí?
32 “Dájúdájú, ọkùnrin tí ó ní okun inú yóò di èétú okùn, àmújáde ìgbòkègbodò rẹ̀ yóò sì di ìtapàrà kan; dájúdájú, àwọn méjèèjì yóò jóná lẹ́ẹ̀kan náà, láìsí ẹnì kankan tí yóò pa iná náà.” (Aísáyà 1:31) Ta ni “ọkùnrin tí ó ní okun inú” yìí? Ohun tó jẹ mọ́ agbára àti ọlà ni gbólóhùn yìí gbé yọ nínú èdè Hébérù. Ó ṣeé ṣe kó tọ́ka sí ẹni tó láásìkí, tó dára ẹ̀ lójú lára àwọn tí ń tọ òrìṣà lẹ́yìn. Ńṣe làwọn tó kọ Jèhófà àti ìsìn mímọ́ gaara rẹ̀ sílẹ̀ pọ̀ lọ súà nígbà ayé Aísáyà, àní bó ṣe rí nígbà tiwa yìí. Ó dà bí pé nǹkan tilẹ̀ tún ń dáa fún àwọn kan lára wọn. Síbẹ̀ Jèhófà kìlọ̀ pé ṣe ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ yóò rí bí “èétú okùn,” okùn ọ̀gbọ̀ fúlẹ́fúlẹ́, tó gbẹ gidi gan-an tó fi jẹ́ pé bí iná bá rà á lára lásán yóò já sí méjì. (Àwọn Onídàájọ́ 16:8, 9) Ohun tó bá tinú ìgbòkègbodò abọ̀rìṣà náà jáde—ì báà jẹ́ àwọn òrìṣà rẹ̀, ọlà rẹ̀, tàbí ohunkóhun tó bá sáà ń jọ́sìn dípò Jèhófà—yóò dà bí “ìtapàrà” iná. Àti ìtapàrà iná àti èétú okùn ni yóò jóná lúúlúú nínú iná tẹ́nikẹ́ni kò ní lè pa. Kò sí alágbára kankan lágbàálá ayé tó lè dojú ìdájọ́ pípé Jèhófà dé.
33. (a) Báwo ni àwọn ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run ṣe nípa ìdájọ́ tí ń bọ̀ ṣe tún fi àánú rẹ̀ hàn pẹ̀lú? (b) Àǹfààní wo ni Jèhófà ń nawọ́ rẹ̀ sí aráyé báyìí, báwo ni ìyẹn sì ṣe kan ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?
33 Ǹjẹ́ iṣẹ́ ìkẹyìn yìí wà ní ìbámu pẹ̀lú iṣẹ́ àánú àti ìdáríjì tó wà ní ẹsẹ kejìdínlógún? Wẹ́kú ló bá a mu! Jíjẹ́ tí Jèhófà jẹ́ aláàánú ló ṣe mú kí ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn wà lákọsílẹ̀ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì kéde wọn. Ó ṣe tán, “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.” (2 Pétérù 3:9) Àǹfààní ló jẹ́ fún gbogbo Kristẹni tòótọ́ láti polongo àwọn iṣẹ́ ìkìlọ̀ Ọlọ́run fáráyé gbọ́, kí àwọn tó ronú pìwà dà lè jàǹfààní ìdáríjì fàlàlà rẹ̀ kí wọ́n sì wà láàyè títí láé. Inúure Jèhófà mà pọ̀ o, tó fi fún aráyé láyè láti lè “mú àwọn ọ̀ràn tọ́” láàárín òun pẹ̀lú wọn kó tó pẹ́ jù!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Gẹ́gẹ́ bí ìtàn àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Júù àtijọ́ ṣe wí, ṣe ni Mánásè Ọba burúkú ní kí wọ́n pa Aísáyà, pé kí wọ́n fi ayùn rẹ́ ẹ sí méjì. (Fi wé Hébérù 11:37.) Ìwé ìtàn kan sọ pé, kí wọ́n bàa lè rí ìdájọ́ ikú yẹn dá fún Aísáyà, ẹ̀sùn tí wòlíì èké kan fi kàn án ni pé: “Ó pe Jerúsálẹ́mù ní Sódómù, ó sì sọ pé àwọn ọmọ aládé Júdà àti Jerúsálẹ́mù jẹ́ ará Gòmórà.”
b Ọ̀rọ̀ Hébérù tí a túmọ̀ sí “agbára abàmì” tún ní ìtumọ̀ “ohun aṣenilọ́ṣẹ́,” “ohun abàmì,” àti “ohun ìṣìnà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé Theological Dictionary of the Old Testament ṣe wí, ṣe ni àwọn wòlíì Hébérù ń lo ọ̀rọ̀ náà láti fi bẹnu àtẹ́ lu “aburú tí ṣíṣi agbára lò máa ń fà.”
c Gbólóhùn náà, “èmi yóò . . . yí ọwọ́ mi padà sára rẹ” túmọ̀ sí pé Jèhófà yóò yíwọ́ kúrò lẹ́nu ìtìlẹyìn ṣíṣe fún àwọn èèyàn rẹ̀, yóò wá bọ́ sórí jíjẹ wọ́n níyà.