Ẹyin Alagba, Ẹ Fi Ododo Ṣe Idajọ
“Ẹ maa gbọ́ ẹjọ́ laaarin awọn arakunrin yin, ki ẹ sì maa ṣe idajọ ododo.”—DEUTERONOMI 1:16.
1. Ninu ọran idajọ, ìyannisípò aṣẹ wo ni ó ti ṣẹlẹ, ki ni eyi sì dọgbọn tumọsi fun awọn eniyan onidaajọ?
GẸGẸ bi Onidaajọ onipo-ajulọ, Jehofa ti yan ọla-aṣẹ idajọ fun Ọmọkunrin rẹ̀. (Johannu 5:27) Ni ipa tirẹ, gẹgẹ bi Ori ijọ Kristian, Kristi ń lo ẹgbẹ́ ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn-inu ati Ẹgbẹ́ Oluṣakoso rẹ̀ lati yan awọn alagba sípò, awọn ti wọn ń ṣe bi onidaajọ nigba miiran. (Matteu 24:45-47, NW; 1 Korinti 5:12, 13; Titu 1:5, 9) Gẹgẹ bi awọn onidaajọ ti a yàndípò, awọn wọnyi wà labẹ aigbọdọmaṣe kan lati tẹle apẹẹrẹ awọn Onidaajọ ti ọ̀run, Jehofa ati Kristi Jesu timọtimọ.
Kristi—Onidaajọ Awofiṣapẹẹrẹ
2, 3. (a) Asọtẹlẹ ti Messia wo ni o fi awọn animọ Kristi gẹgẹ bi Onidaajọ hàn? (b) Awọn kókó wo ni wọn yẹ fun akiyesi ni pataki?
2 Nipa Kristi gẹgẹ bi Onidaajọ, ni a kọ ọ́ lọna asọtẹlẹ pe: “Ẹmi Oluwa [“Jehofa,” NW] yoo sì bà lé e, ẹmi ọgbọ́n ati òye, ẹmi igbimọ ati agbara, ẹmi imọran ati ibẹru Oluwa. Ibẹru Oluwa yoo jẹ́ didun inu rẹ̀; oun ki yoo fi ohun ti oju rẹ̀ rí tabi eyi ti eti rẹ̀ gbọ́ dajọ. Ṣugbọn yoo fi ododo ṣe idajọ talaka, yoo si fi otitọ ṣe idajọ fun awọn ọlọkan tutu ayé.”—Isaiah 11:2-4.
3 Ṣakiyesi awọn animọ ti ó mú ki o ṣeeṣe fun Kristi lati “ṣe idajọ ayé ni ododo” ninu asọtẹlẹ yẹn. (Iṣe 17:31) Ó ń dajọ ni ibamu pẹlu ẹmi Jehofa, ọgbọn atọrunwa, òye, imọran, ati ìmọ̀. Kiyesi i, pẹlu, pe ó ń ṣe idajọ ni ibẹru Jehofa. Nipa bayii, “ìtẹ́ idajọ Kristi” ni, “ijokoo idajọ Ọlọrun,” lọna iṣapẹẹrẹ. (2 Korinti 5:10; Romu 14:10, NW) Oun ń ṣọra lati ṣe idajọ awọn ọ̀ràn ni ọ̀nà ti Ọlọrun gbà ń ṣe idajọ wọn. (Johannu 8:16) Oun kò wulẹ ṣe idajọ nipa irisi tabi ohun ti o fetígbọ́ lasan. Oun ń fi ododo pọ́ńbélé ṣe idajọ nititori awọn ọlọkan tutu ati awọn ẹni rirẹlẹ. Iru Onidaajọ agbayanu wo ni ó jẹ́! Apẹẹrẹ agbayanu wo ni ó sì jẹ́ fun awọn eniyan alaipe ti a késí lati ṣiṣẹ ninu àyè ipo idajọ lonii!
Awọn Onidaajọ Ori Ilẹ̀-Ayé
4. (a) Ki ni yoo jẹ́ ọ̀kan lara ohun ti awọn 144,000 yoo bojuto ni ìgbà Iṣakoso Ẹgbẹrundun ti Kristi? (b) Asọtẹlẹ wo ni o fihan pe awọn Kristian ẹni-ami-ororo kan ni a o yàn sípò gẹgẹ bi onidaajọ nigba ti wọn ṣì wà lori ilẹ̀-ayé?
4 Iwe Mimọ fihan pe iye awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti wọn kere ni ifiwera, ti o bẹrẹ pẹlu awọn aposteli 12, yoo jẹ́ onidaajọ alabaakẹgbẹ pẹlu Kristi Jesu ni akoko Ẹgbẹrundun. (Luku 22:28-30; 1 Korinti 6:2; Ìfihàn 20:4) Aṣẹku awọn mẹmba ẹni-ami-ororo ti Israeli tẹmi lori ilẹ̀-ayé funraawọn ni a dá lẹjọ ti a sì mú padabọsipo ni 1918 si 1919. (Malaki 3:2-4) Nipa imupadabọsipo Israeli tẹmi yii, ni a sọtẹlẹ pe: “Emi yoo . . . mu awọn onidaajọ rẹ pada bi ìgbà iṣaaju, ati awọn igbimọ rẹ bi igba akọbẹrẹ.” (Isaiah 1:26) Nipa bayii, gan-an gẹgẹ bi ó ti ṣe ‘nígbà ibẹrẹ’ ti Israeli nipa ti ara, Jehofa ti fun awọn aṣẹku ti a mú padabọsipo ní awọn onidaajọ ati olugbaninimọran olododo.
5. (a) Awọn wo ni a “fi sibẹ bi onidaajọ” lẹhin imupadabọsipo Israeli tẹmi, bawo sì ni a ṣe ṣapejuwe wọn ninu iwe Ìfihàn? (b) Nipasẹ awọn wo ni a gbà ń ran awọn alaboojuto ẹni-ami-ororo lọwọ nisinsinyi ninu iṣẹ idajọ, bawo sì ni a ṣe ń dá awọn wọnyi lẹkọọ lati di onidaajọ ti o tubọ sàn sii?
5 Lakọọkọ ná, gbogbo ‘awọn ọlọgbọn ọkunrin’ ti a “fi sibẹ bi onidaajọ” jẹ́ awọn àgbà ọkunrin ẹni-ami-ororo, tabi alagba. (1 Korinti 6:4, 5) Awọn alaboojuto ẹni-ami-ororo oluṣotitọ, ti a gbeniyi ni a yaworan wọn ninu iwe Ìfihàn gẹgẹ bi awọn ti a mú dání ni ọwọ ọ̀tún Jesu, iyẹn ni, labẹ akoso ati idari rẹ̀. (Ìfihàn 1:16, 20; 2:1) Lati 1935 awọn ẹni-ami-ororo ti gba itilẹhin aduroṣinṣin ti “awọn ogunlọgọ nla” ti ń pọ sii ṣáá, awọn ẹni ti ireti wọn jẹ lati la “ipọnju nla” já ki wọn sì walaaye titilae lori paradise ilẹ̀-ayé kan. (Ìfihàn 7:9, 10, 14-17, NW) Bi “igbeyawo Ọdọ-Agutan” ti ń sunmọ tosi, pupọ pupọ sii ninu awọn wọnyi ni a ń yàn sípò lati ọwọ Ẹgbẹ Oluṣakoso ẹni-ami-ororo lati ṣiṣẹsin gẹgẹ bi alagba ati onidaajọ ninu ijọ Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti o ju 66,000 lọ jakejado ilẹ̀-ayé.a (Ìfihàn 19:7-9) Nipasẹ awọn ile-ẹkọ akanṣe, a ń dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lati bojuto ẹrù-iṣẹ́ ninu ẹgbẹ awujọ “ayé titun.” (2 Peteru 3:13) Ile-Ẹkọ Iṣẹ-Ojiṣẹ Ijọba, ti a dari ni opin ọdun 1991 ní ọpọlọpọ awọn orilẹ-ede, gbé itẹnumọ kari abojuto bibojumu nipa awọn ọ̀ràn idajọ. Awọn alagba ti wọn ń ṣiṣẹsin gẹgẹ bi onidaajọ ni a sọ ọ́ di dandan fun lati ṣafarawe Jehofa ati Kristi Jesu, awọn ti idajọ wọn jẹ́ otitọ ati ododo.—Johannu 5:30; 8:16; Ìfihàn 19:1, 2.
Awọn Onidaajọ Ti Wọn ‘Fi Ibẹru Dari Araawọn’
6. Eeṣe ti awọn alagba ti wọn ń ṣiṣẹsin ninu awọn igbimọ idajọ fi gbọdọ ‘fi ibẹru dari arawọn’?
6 Bí Kristi fúnraarẹ̀ bá ṣe idajọ ni ibẹru Jehofa ati pẹlu iranlọwọ ẹmi Rẹ̀, meloo meloo ni ó ti yẹ ki awọn alagba alaipe ṣe bẹẹ tó! Nigba ti a bá yàn wọn lati ṣiṣẹsin ninu igbimọ idajọ, wọn nilati ‘fi ibẹru dari araawọn,’ ni ‘kíké pe Baba ẹni ti ń fi àìṣègbè ṣe idajọ’ lati ràn wọn lọwọ lati fi ododo ṣe idajọ. (1 Peteru 1:17) Wọn nilati ranti pe ẹmi awọn eniyan, “ọkàn” wọn, ni awọn ń bojuto gẹgẹ bi awọn wọnni ti “yoo jíhìn.” (Heberu 13:17, NW) Ni oju iwoye eyi, dajudaju wọn yoo tun jíhìn niwaju Jehofa fun awọn aṣiṣe idajọ ti o ṣee yẹra fun eyikeyii ti wọn le ṣe. Ninu alaye rẹ̀ lori Heberu 13:17, J. H. A. Ebrard kọwe pe: “Ó jẹ́ ojuṣe oluṣọ agutan lati daabobo awọn ọkàn ti a fi sí abojuto rẹ̀, . . . oun sì gbọdọ jíhìn nipa gbogbo wọn, ati ti awọn wọnni ti wọn ti sọnu nipasẹ aṣiṣe rẹ̀. Eyi jẹ́ ọrọ afiyesi kan. Jẹ ki gbogbo ojiṣẹ ọrọ naa kà á si, pe oun ti fínnúfíndọ̀ dawọle abojuto ti o nilo iṣeefọkantan gan-an [lọna gigalọla] yii.—Fiwe Johannu 17:12; Jakọbu 3:1.
7. (a) Ki ni awọn onidaajọ ode-oni gbọdọ ranti, ki ni ó sì gbọdọ jẹ́ gongo wọn? (b) Awọn ẹkọ wo ni awọn alagba gbọdọ fayọ lati inu Matteu 18:18-20?
7 Awọn alagba tí ń ṣiṣẹsin ni ipo idajọ kan gbọdọ ranti pe awọn Onidaajọ gidi fun ọ̀ràn kọọkan ni Jehofa ati Kristi Jesu. Ranti ohun ti a sọ fun awọn onidaajọ ni Israeli: “Ẹyin kò dajọ fun eniyan bikoṣe fun Oluwa, ti o wà pẹlu yin ninu ọ̀ràn idajọ. Ǹjẹ́ nisinsinyi, jẹ ki ẹ̀rù Oluwa ki o wà lara yin; . . . ẹ ṣe bẹẹ gẹgẹ ẹyin ki yoo sì jẹ̀bi.” (2 Kronika 19:6-10) Pẹlu ibẹru ọlọ́wọ̀, awọn alagba ti ń ṣe idajọ ọ̀ràn kan nilati ṣe gbogbo ohun ti wọn lè ṣe lati rí i daju pe Jehofa wà ‘pẹlu wọn ninu ọ̀ràn idajọ’ niti gidi. Ipinnu wọn nilati ṣagbeyọ ọ̀nà ti Jehofa ati Kristi gbà wo ọ̀ràn naa lọna pipeye. Ohun ti wọn ‘dè’ (rí pé ó jẹ́ ẹ̀bi) lọna iṣapẹẹrẹ tabi ‘tú silẹ’ (rí ni alaimọwọmẹsẹ) lori ilẹ̀-ayé nilati jẹ́ ohun ti a ti dè tabi tú tẹlẹ ni ọ̀run—gẹgẹ bi a ti fihan nipasẹ ohun ti a ti kọ silẹ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun ti a mísí. Bi wọn bá gbadura si Jehofa ni orukọ Jesu, Jesu yoo wà “laaarin wọn” lati ràn wọn lọwọ. (Matteu 18:18-20, NW, akiyesi ẹsẹ-iwe; Ilé-Ìṣọ́nà, February 15, 1988, oju-iwe 9) Imọlara ayika ibi ìgbẹ́jọ́ kan gbọdọ fihan pe Kristi wà laaarin wọn nitootọ.
Awọn Oluṣọ-Agutan Alakooko-Kikun
8. Ki ni ẹrù-iṣẹ́ pataki ti awọn alagba ní siha agbo agutan, gẹgẹ bí Jehofa ati Jesu Kristi ti ṣapẹẹrẹ rẹ̀? (Isaiah 40:10, 11; Johannu 10:11, 27-29)
8 Awọn alagba kì í ṣe ẹni ti a gbà sẹnu iṣẹ idajọ alakooko-kikun. Wọn jẹ oluṣọ-agutan alakooko-kikun. Olùmúniláradá ni wọn, kì í ṣe olùfìyàjẹni. (Jakọbu 5:13-16) Èrò ipilẹ ti o wà lẹhin ọrọ Griki naa fun alaboojuto (e·piʹsko·pos) jẹ́ ti abojuto aláàbò. Iwe Theological Dictionary of the New Testament wi pe: “Ni fifi oluṣọ-agutan kún un [ni 1 Peteru 2:25], ede isọrọ naa [e·piʹsko·pos] damọran iṣẹ oluṣọ-agutan ti didaabobo tabi ṣíṣọ́.” Bẹẹni, iṣẹ wọn akọkọ ni didaabobo awọn agutan ati ṣíṣọ́ wọn, pipa wọn mọ́ ninu agbo.
9, 10. (a) Bawo ni Paulu ṣe tẹnumọ ojuṣe akọkọ ti awọn alagba, nitori naa ibeere wo ni ó bojumu pe ki a gbe dide? (b) Ki ni awọn ọrọ Paulu ni Iṣe 20:29 dọgbọn tumọsi, nitori naa bawo ni awọn alagba ṣe lè gbiyanju lati dín iye ọ̀ràn idajọ kù?
9 Ni bíbá awọn alagba ni ijọ Efesu sọrọ, aposteli Paulu fi itẹnumọ si ibi ti ó yẹ: “Ẹ kiyesi araayin, ati si gbogbo agbo ti ẹmi mimọ fi yin ṣe alaboojuto rẹ̀, lati maa tọju [“ṣe oluṣọ-agutan,” NW] ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ̀ . . . [“Ọmọkunrin,” NW] rẹ̀ rà.” (Iṣe 20:28) Paulu tẹnumọ ṣiṣe oluṣọ-agutan, kì í ṣe fifiyajẹni. Awọn alagba kan lè ṣe daradara lati sìnmẹ̀dọ̀ ronu lori ibeere ti o tẹle yii: ‘Awa ha lè tọju iye akoko ti o pọ̀ ti a nilo lati fi ṣayẹwo ati lati bojuto awọn ọ̀ràn idajọ bi a bá lo akoko ati isapa pupọ sii fun ṣiṣe oluṣọ-agutan bi?’
10 Loootọ, Paulu kilọ lodisi “ìkookò buburu.” Ṣugbọn oun kò ha kẹ́gàn awọn wọnyi fun ‘ṣiṣai fi jẹlẹnkẹ bá agbo lò bi’? (Iṣe 20:29) Nigba ti ọrọ rẹ̀ si dọgbọn tumọsi pe awọn alaboojuto oluṣotitọ nilati lé awọn “ikooko” wọnyi lọ, ǹjẹ́ wọn kò ha fihan pe awọn alagba nilati ‘fi jẹlẹnkẹ’ bá awọn mẹmba miiran ninu agbo lò bi? Nigba ti agutan kan bá di alailera nipa tẹmi ti o sì ṣubu lẹ́bàá ọ̀nà, ki ni oun lọkunrin tabi lobinrin nilo—lílù tabi imularada, fifiyajẹ tabi ṣiṣe oluṣọ-agutan rẹ̀? (Jakọbu 5:14, 15) Nitori naa, awọn alagba gbọdọ maa ṣeto akoko deedee fun iṣẹ oluṣọ-agutan. Eyi lè mú iyọrisi alayọ wá niti lilo akoko ti o dinku ninu ọ̀ràn idajọ ti ń jẹ akoko ti o wémọ́ awọn Kristian ti ẹṣẹ ti lébá. Dajudaju, idaniyan akọkọ ti awọn alagba gbọdọ jẹ́ lati pese orisun idẹra ati itura, ni titipa bayii gbé alaafia, iparọrọ, ati aabo laaarin awọn eniyan Jehofa larugẹ.—Isaiah 32:1, 2.
Ṣiṣẹsin Gẹgẹ bi Oluṣọ-Agutan ati Adajọ Oloore
11. Eeṣe ti awọn alagba ti ń ṣiṣẹsin ninu igbimọ idajọ fi nilo àìṣègbè ati “ọgbọn ti o ti oke wá”?
11 Ṣiṣe oluṣọ-agutan kárakára sii ṣaaju ki Kristian kan tó ṣi ẹsẹ gbé lè dín iye awọn ọ̀ràn idajọ laaarin awọn eniyan Jehofa kù daradara. (Fiwe Galatia 6:1.) Bi o tilẹ ri bẹẹ, nitori ẹṣẹ ati aipe eniyan, awọn Kristian alaboojuto lè nilati bojuto awọn ọ̀ràn ìwà àìtọ́ lati ìgbà dé ìgbà. Awọn ilana wo ni o nilati dari wọn? Iwọnyi kò tíì yipada lati akoko Mose tabi ti awọn Kristian ijimiji sibẹ. Awọn ọrọ Mose ti ó ba awọn onidaajọ ni Israeli sọ fẹsẹmulẹ: “Ẹ maa gbọ ẹjọ́ laaarin awọn arakunrin yin, ki ẹ si maa ṣe idajọ ododo . . . Ẹ kò gbọdọ ṣe ojuṣaaju ni idajọ.” (Deuteronomi 1:16, 17) Àìṣègbè jẹ́ animọ iwa “ọgbọ́n ti o ti oke wá,” ọgbọ́n ti o ṣe kókó tobẹẹ fun awọn alagba ti ń ṣiṣẹsin ninu awọn igbimọ idajọ. (Jakọbu 3:17; Owe 24:23) Iru ọgbọn bẹẹ yoo ràn wọn lọwọ lati foye mọ iyatọ laaarin ailera ati iwa buburu.
12. Ni èrò itumọ wo ni awọn onidaajọ kò fi nilati jẹ́ kìkì olododo nikan ṣugbọn awọn ọkunrin rere?
12 Awọn alagba gbọdọ “fi ododo ṣe idajọ,” ni ibamu pẹlu awọn ọ̀pá idiwọn Jehofa nipa ẹ̀tọ́ ati àìtọ́. (Orin Dafidi 19:9) Sibẹ, nigba ti wọn ń saakun lati jẹ́ ọkunrin olododo, wọn gbọdọ gbiyanju pẹlu lati jẹ ọkunrin rere, ni èrò itumọ ìdáyàtọ̀ ti Paulu ṣe ni Romu 5:7, 8. Ni sisọrọ lori awọn ẹsẹ wọnyi ninu ọrọ-ẹkọ rẹ lori “Ododo,” iwe naa Insight on the Scriptures sọ pe: “Ìlò ede isọrọ Griki naa fihan pe ẹni naa ti a mọ dunju fun, tabi ti a dámọ̀ ketekete nipasẹ, iwarere jẹ́ ẹnikan ti o jẹ́ ẹlẹmii iṣoore (ti o ni itẹsi lati ṣe ohun rere tabi mú anfaani wá fun awọn ẹlomiran) ati ẹlẹmii ọlawọ (tí ń fi akikanju fi iru iwarere bẹẹ han). Oun kò wulẹ daniyan fun ṣiṣe ohun ti idajọ ododo beere fun ṣugbọn ó ń lọ rekọja eyi, ní jíjẹ́ ẹni ti a sún nipasẹ igbatẹniro pipeye fun awọn ẹlomiran ati ifẹ ọkàn lati ṣanfaani fun ati lati ràn wọn lọwọ.” (Idipọ 2, oju-iwe 809) Awọn alagba ti wọn kì í ṣe olododo nikan ṣugbọn ti wọn tun dara yoo bá awọn oníwà àìtọ́ lò pẹlu igbatẹniro oninuure. (Romu 2:4) Wọn gbọdọ fẹ́ lati fi aanu ati ìyọ́nú hàn. Wọn gbọdọ ṣe ohun ti wọn lè ṣe lati ran oníwà àìtọ́ naa lọwọ lati ri aini naa fun ironupiwada, ani bi o tilẹ jẹ pe oun lè jọbi pe ko dahunpada si awọn isapa wọn lakọọkọ.
Iṣarasihuwa Titọna Nibi Ìgbẹ́jọ́
13. (a) Nigba ti alagba kan bá huwa gẹgẹ bi onidaajọ kan, ki ni oun kò dawọ duro lati jẹ́? (b) Imọran wo ti Paulu funni ni o ṣee fisilo pẹlu nibi ìgbẹ́jọ́ idajọ?
13 Nigba ti ipo kan bá beere fun ìgbẹ́jọ́ idajọ, awọn alaboojuto kò gbọdọ gbàgbé pe awọn ṣì jẹ́ oluṣọ-agutan, ti ń ba agutan Jehofa lò, labẹ “oluṣọ-agutan rere.” (Johannu 10:11) Imọran ti Paulu fifunni fun iranlọwọ deedee ti a fifun awọn agutan ti o wà ninu ipo lilekoko ṣee fisilo bakan naa ni ibi ìgbẹ́jọ́ idajọ. Ó kọwe pe: “Ẹyin ará, àní bi eniyan kan bá tilẹ ṣi ẹsẹ gbé ki o tó mọ̀ nipa rẹ̀, ẹyin ti ẹ ní ẹ̀rí títóótun ti ẹmi nilati gbiyanju lati tún iru eniyan bẹẹ ṣe bọsipo ninu ẹmi iwapẹlẹ, bi olukuluku yin ti ń kiyesi araarẹ̀, ni ibẹru pe a lè dẹ ẹyin naa wò pẹlu. Ẹ maa baa lọ ni riru ẹrù-ìnira araayin ẹnikinni ẹnikeji, ki ẹ sì fi bayii mu ofin Kristi ṣẹ.”—Galatia 6:1, 2, NW.b
14. Oju wo ni awọn alaboojuto fi gbọdọ wo ìgbẹ́jọ́ idajọ, ki ni o sì gbọdọ jẹ́ iṣarasihuwa wọn si oníwà àìtọ́ kan?
14 Dipo kika araawọn si onidaajọ onipo giga ti ń pade lati fi ìyà jẹni, awọn alagba ti ń ṣiṣẹsin ninu igbimọ idajọ nilati wo ìgbẹ́jọ́ naa gẹgẹ bi ìhà miiran ninu iṣẹ oluṣọ-agutan wọn. Ọ̀kan lara awọn agutan Jehofa wà ninu ijangbọn. Ki ni wọn lè ṣe lati gbà á lọkunrin tabi lobinrin silẹ? Ó ha ti pẹ́ jù lati ran agutan yii ti o ti rìn régberègbe kuro ninu agbo lọwọ bi? Awa yoo reti ki o má ri bẹẹ. Awọn alagba gbọdọ pa oju-iwoye onifojusọna si rere mọ́ siha fifi aanu hàn nibi ti eyi yoo bá ti bojumu. Kì í ṣe pe wọn nilati rẹ ọ̀pá idiwọn Jehofa silẹ bi a bá ti dá ẹṣẹ wiwuwo kan. Ṣugbọn jíjẹ́ ki awọn ipo amọ́rànfúyẹ́ eyikeyii jẹ wọn lọ́kàn yoo ràn wọn lọwọ lati nawọ aanu nibi ti o bá ti ṣeeṣe. (Orin Dafidi 103:8-10; 130:3) Ó bani ninu jẹ lati sọ, pe awọn oníwà àìtọ́ kan ni wọn jẹ́ olóríkunkun tobẹẹ ninu iṣarasihuwa wọn debi pe a sọ ọ́ di dandan fun awọn alagba lati fi iduro gbọnyingbọnyin hàn, bi o tilẹ jẹ pe kò gbọdọ jẹ́ lilekoko mọni lae.—1 Korinti 5:13.
Ète Ìgbẹ́jọ́ Idajọ
15. Nigba ti iṣoro wiwuwo kan bá dide laaarin awọn ẹnikọọkan, ki ni a gbọdọ kọ́kọ́ pinnu?
15 Nigba ti iṣoro wiwuwo kan bá dide laaarin awọn ẹnikọọkan, awọn alagba ọlọgbọn yoo kọ́kọ́ pinnu yala awọn wọnni ti ọ̀ràn kàn ti gbiyanju lati yanju ọ̀ràn naa laaarin araawọn, nipasẹ ilana asunniṣiṣẹ ti o wà ninu Matteu 5:23, 24 tabi Matteu 18:15. Bi eyi kò bá ràn án, boya imọran lati ẹnu alagba kan tabi meji yoo tó. Igbesẹ idajọ pọndandan kìkì bi a bá ti dá ọ̀ràn ẹṣẹ lílékenkà ti o lè ṣamọna si iyọlẹgbẹ. (Matteu 18:17; 1 Korinti 5:11) Ipilẹ yiyekooro ti o bá Iwe Mimọ mu gbọdọ wà fun dídá igbimọ idajọ silẹ. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1989, oju-iwe 18.) Nigba ti a bá dá ọ̀kan silẹ, awọn alagba ti wọn tootun julọ ni a gbọdọ yàn fun iru ọ̀ràn pàtó kan.
16. Ki ni awọn alagba ń gbiyanju lati rígbà nipasẹ ìgbẹ́jọ́ idajọ?
16 Ki ni awọn alagba ń rígbà nipasẹ ìgbẹ́jọ́ idajọ? Lakọọkọ, kò ṣeeṣe lati fi ododo ṣe idajọ ayafi bi a bá mọ otitọ. Gẹgẹ bi o ti ri ni Israeli, awọn ọ̀ràn wiwuwo ni a gbọdọ ‘wadii kúnnákúnná.’ (Deuteronomi 13:14; 17:4) Nitori naa gongo ìgbẹ́jọ́ kan ni lati ridii awọn otitọ ọ̀ràn naa. Ṣugbọn eyi ni a lè ṣe ti a sì gbọdọ ṣe pẹlu ifẹ. (1 Korinti 13:4, 6, 7) Gbàrà ti wọn bá ti mọ otitọ ohun ti ó ṣẹlẹ naa gan-an awọn alagba yoo ṣe ohun yoowu ti o pọndandan lati daabobo ijọ ki wọn sì pa awọn ọ̀pá idiwọn giga ti Jehofa ati iṣiṣẹ deedee ẹmi rẹ̀ mọ ninu ijọ. (1 Korinti 5:7, 8) Bi o ti wu ki o ri, ọ̀kan lara awọn ète ìgbẹ́jọ́ ni lati gba ẹlẹṣẹ ti a fi sinu ewu là, bi ó bá ṣeeṣe rara.—Fiwe Luku 15:8-10.
17. (a) Bawo ni a ṣe gbọdọ bá ẹnikan ti a fi ẹ̀sùn kàn lò ni akoko ìgbẹ́jọ́, ati fun ète wo? (b) Ki ni eyi yoo beere fun ni iha ọdọ awọn mẹmba igbimọ idajọ?
17 Ẹnikan ti a fẹsun kan ni a kò gbọdọ bá lò lọna miiran ju bi agutan Ọlọrun lọ. Oun lọkunrin tabi lobinrin ni a gbọdọ fi ọwọ́ jẹlẹnkẹ mú. Bi ó bá ti dá ẹṣẹ kan (tabi awọn ẹṣẹ), ète awọn onidaajọ ododo yoo jẹ́ lati ran ẹlẹṣẹ naa lọwọ lati ṣe atunṣebọsipo, lati loye aṣiṣe ọ̀nà rẹ̀, lati ronupiwada, ki a sì tipa bayii já a gbà kuro lọwọ “ìdẹkùn Eṣu.” Yoo beere fun “ọnà ikọnilẹkọọ,” ‘fifi iwapẹlẹ kọni.’ (2 Timoteu 2:24-26; 4:2, NW) Ki ni bi ẹlẹṣẹ naa bá wá mọ̀ pe oun ti dẹ́ṣẹ̀, ti a gún un dénú ọkan-aya nitootọ, ti o sì tọrọ idariji lọdọ Jehofa? (Fiwe Iṣe 2:37.) Bi ó bá dá igbimọ naa loju pe oun ń fẹ́ iranlọwọ nitootọ, ó sábà maa ń jasi pé ki yoo si idi lati yọ ọ́ lẹgbẹ.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, July 1, 1983, oju-iwe 31, ipinrọ 1.
18. (a) Nigba wo ni o yẹ ki igbimọ idajọ fi iduro gbọnyingbọnyin hàn ninu yiyọ oníwà àìtọ́ kan lẹgbẹ? (b) Loju-iwoye ipo abanilọkanjẹ wo ni awọn alagba gbọdọ lo araawọn tokunra tokunra nititori awọn agutan ti ń rìn régberègbe?
18 Ni ọwọ keji ẹ̀wẹ̀, nigba ti awọn mẹmba igbimọ idajọ kan bá dojukọ ọ̀ràn ipẹhinda ti a ko fi irobinujẹ hàn fun ti o si ṣe kedere, iṣọtẹ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe lodisi awọn ofin Jehofa, tabi iwa buburu pọ́ńbélé, ojuṣe wọn ni lati daabobo awọn mẹmba ijọ yooku nipa yiyọ olùṣeláìfí alaironupiwada naa lẹgbẹ. Igbimọ idajọ naa ni a kò sọ ọ́ di aigbọdọmaṣe fun lati pade leralera pẹlu oníwà àìtọ́ naa tabi sọ ọrọ sí i lẹnu, ni gbigbiyanju lati fipa mú un lati ronupiwada, bi o bá ṣe kedere pe o ṣaini ibanujẹ oniwa-bi-Ọlọrun.c Ni awọn ọdun aipẹ yii iyọlẹgbẹ yika ayé ti jẹ́ ohun ti o sunmọ ipin 1 ninu ọgọrun-un awọn akede. Iyẹn tumọsi pe ninu nǹkan bii ọgọrun-un agutan ti ó kù ninu agbo agutan, ọ̀kan sọnu—ó keretan fun akoko diẹ. Ni wiwo akoko ati isapa ti o gbà lati mu ẹnikan wọnu agbo agutan naa, kò ha banilọkan jẹ́ lati mọ̀ pe ẹgbẹẹgbẹrun lọna mẹwaa mẹwaa ni a ‘ń fi lé Satani lọwọ pada’ ni ọdun kọọkan?—1 Korinti 5:5.
19. Ki ni awọn alagba ti ń ṣiṣẹsin ninu igbimọ idajọ kò gbọdọ gbagbe lae, nitori naa ki ni yoo jẹ́ gongo wọn?
19 Awọn alagba ti wọn bẹrẹ ọ̀ràn idajọ kan gbọdọ ranti pe ọpọ julọ awọn ọ̀ràn ẹṣẹ ninu ijọ wémọ́ ailera, kì í ṣe animọ iwa buburu. Wọn kò gbọdọ gbagbe àkàwé Jesu nipa agutan ti o sọnu lae, eyi ti o pari rẹ̀ pẹlu awọn ọrọ naa: “Mo wí fun yin, gẹgẹ bẹẹ ni ayọ yoo wà ni ọ̀run lori ẹlẹṣẹ kan ti o ronupiwada, ju lori oloootọ mọkandinlọgọrun-un lọ, ti kò ṣe aini ironupiwada.” (Luku 15:7) Loootọ, “Oluwa [“Jehofa,” NW] . . . kò fẹ́ ki ẹnikẹni ki o ṣègbé, bikoṣe ki gbogbo eniyan ki o wá si ironupiwada.” (2 Peteru 3:9) Pẹlu iranlọwọ Jehofa, ǹjẹ́ ki awọn igbimọ idajọ jakejado ayé ṣe gbogbo ohun ti wọn lè ṣe lati ṣokunfa ayọ̀ ni ọ̀run nipa ríran awọn oníwà àìtọ́ lọwọ lati ri aini naa lati ronupiwada ki wọn sì pada fi ẹsẹ wọn mulẹ loju ọ̀nà tóóró ti ń sinni lọ si ìyè ainipẹkun.—Matteu 7:13, 14.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fun ipo awọn alagba lati inu awọn agutan miiran wá niti apa ọ̀tún Kristi, wo iwe naa Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., oju-iwe 136, akiyesi ẹsẹ-iwe.
b Wo Ilé-Ìṣọ́nà, September 15, 1989, oju-iwe 19.
c Wo Ilé-Ìṣọ́nà, January 1, 1982, oju-iwe 26, ipinrọ 24.
Awọn Ibeere Atunyẹwo
◻ Ni titẹle apẹẹrẹ Oluṣọ-Agutan Titobi ati Oluṣọ-Agutan Rere naa, ki ni o gbọdọ jẹ́ lajori ọkàn-ìfẹ́ awọn alagba?
◻ Ni ọ̀nà wo ni awọn alagba lè gbà saakun lati mú iye awọn ọ̀ràn idajọ dinku?
◻ Ni èrò itumọ wo ni awọn onidaajọ kò fi nilati jẹ́ olododo nikan ṣugbọn ẹni rere pẹlu?
◻ Bawo ni a ṣe gbọdọ bá oníwà àìtọ́ kan lò ni akoko ìgbẹ́jọ́, pẹlu ète wo sì ni?
◻ Eeṣe ti iyọlẹgbẹ fi jẹ́ igbesẹ ti o kẹhin?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Nibi ti a bá ti ṣe iṣẹ oluṣọ-agutan ṣaaju akoko, ọpọlọpọ awọn ọ̀ràn idajọ ni a lè yẹra fun
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Ani ni akoko ìgbẹ́jọ́ idajọ kan paapaa, awọn alagba gbọdọ gbiyanju lati tun oníwà àìtọ́ kan ṣe bọsipo ninu ẹmi iwapẹlẹ