Bíbá Olùṣọ́ náà Ṣiṣẹ́ Pọ̀
“Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, ibi ìṣọ́ mi sì ni mo dúró sí ní gbogbo òru.”—AÍSÁYÀ 21:8.
1. Ìlérí kíkọyọyọ wo ni Jèhófà fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí?
JÈHÓFÀ jẹ́ Atóbilọ́lá Olùpète. Kò sí ohun tí áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ nì tó di Sátánì Èṣù lè ṣe láti dojú ète Rẹ̀ kíkọyọyọ délẹ̀, ìyẹn ni láti sọ orúkọ ara Rẹ̀ di mímọ́, kí ó sì fìdí Ìjọba ológo kan múlẹ̀ èyí tí yóò ṣàkóso orí ilẹ̀ ayé tí yóò di párádísè. (Mátíù 6:9, 10) A óò bù kún ìran ènìyàn gidigidi lábẹ́ ìṣàkóso yẹn. Ọlọ́run “yóò gbé ikú mì títí láé, dájúdájú, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ yóò nu omijé kúrò ní ojú gbogbo ènìyàn.” Àwọn ènìyàn aláyọ̀, tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan yóò máa gbádùn àlàáfíà àti aásìkí títí láé. (Aísáyà 25:8; 65:17-25) Jèhófà ló fúnra rẹ̀ jẹ́rìí sí àwọn ìlérí kíkọyọyọ wọ̀nyí!
2. Àwọn wo làwọn ẹlẹ́rìí tí Jèhófà ti ní?
2 Àmọ́ ṣá o, Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá náà tún ní àwọn ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ènìyàn. Kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé, “àwọsánmà àwọn ẹlẹ́rìí” tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ébẹ́lì, fi ìfaradà sá eré ìje, lọ́pọ̀ ìgbà ló sábà máa ń jẹ́ lójú àwọn ipò tí kò bára dé rárá. Àwọn àpẹẹrẹ pípegedé tí wọ́n fi lélẹ̀ jẹ́ ìṣírí fún àwọn Kristẹni tó dúró ṣinṣin lóde òní. Tó bá jẹ́ ti ká fìgboyà wàásù, Jésù Kristi ló pegedé jù lọ. (Hébérù 11:1–12:2) Fún àpẹẹrẹ, rántí ẹ̀rí tí ó jẹ́ kẹ́yìn níwájú Pọ́ńtíù Pílátù. Jésù là á mọ́lẹ̀ pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Láti ọdún 33 Sànmánì Tiwa títí di ọdún 2000 Sànmánì Tiwa yìí, àwọn Kristẹni onítara ti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìjẹ́rìí wọn nìṣó, nípa fífi ìgboyà polongo “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run.”—Ìṣe 2:11.
Ẹ̀ya Ẹ̀sìn Àwọn Ará Bábílónì
3. Báwo ni Sátánì ṣe tako ẹ̀rí táwọn èèyàn ń jẹ́ nípa Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀?
3 Láti ọ̀pọ̀ ẹgbẹ̀rúndún wá ni olórí Elénìní nì, Sátánì Èṣù, ti ń fi ìwà ìkà rẹ̀ wá ọ̀nà láti sọ ẹ̀rí tí àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run ń jẹ́ di yẹpẹrẹ. Gẹ́gẹ́ bíi “baba irọ́,” “dírágónì ńlá” yìí, “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” ti “ń ṣi gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” Kò dẹ́kun ìjà tó ń bá àwọn tí “ń pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́” jà rárá, pàápàá ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí.—Jòhánù 8:4; Ìṣípayá 12:9, 17.
4. Báwo ni Bábílónì Ńlá ṣe bẹ̀rẹ̀?
4 Ní nǹkan bí ẹgbàajì ọdún sẹ́yìn, lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Sátánì gbé Nímírọ́dù dìde, ẹni tó jẹ́ “ọdẹ alágbára ńlá ní ìlòdì sí Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 10:9, 10) Bábílónì (Bábélì), tó jẹ́ ìlú ńlá jù lọ fún Nímírọ́dù di ibùdó ìjọsìn àwọn ẹ̀mí èṣù. Nígbà tí Jèhófà da èdè àwọn tó ń kọ́ ilé gogoro Bábélì rú, àwọn ènìyàn náà fọ́n káàkiri gbogbo ayé, bí wọ́n sì ti ń lọ láti ibì kan sí ibòmíràn ni ẹ̀sìn èké wọ́n ń bá wọn lọ. Bí Bábílónì ṣe di orísun ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé nìyẹn, èyí táa pè ní Bábílónì Ńlá nínú ìwé Ìṣípayá. Ìwé yẹn sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun ètò ìsìn ìgbàanì yìí.—Ìṣípayá 17:5; 18:21.
Orílẹ̀-Èdè Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí
5. Orílẹ̀-Èdè wo ni Jèhófà ṣètò pé kí ó jẹ́ ẹlẹ́rìí òun, ṣùgbọ́n kí ló fà á tó fi yọ̀ǹda kó lọ sí ìgbèkùn?
5 Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún lẹ́yìn àkókò Nímírọ́dù, Jèhófà ṣètò àwọn àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù olóòótọ́ láti di orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti sìn gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí Rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. (Aísáyà 43:10, 12) Ọ̀pọ̀ àwọn ará orílẹ̀-èdè yẹn ló fi ìdúróṣinṣin sin Jèhófà. Àmọ́, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, ìgbàgbọ́ èké àwọn orílẹ̀-èdè tó múlé gbè wọ́n sọ Ísírẹ́lì dìbàjẹ́, ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà bá dá májẹ̀mú bá kẹ̀yìn sí i, tí wọ́n sì lọ jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. Nípa bẹ́ẹ̀, ní ọdún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, àwọn ọmọ ogun Bábílónì, tí Nebukadinésárì Ọba darí, pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run, wọ́n sì kó àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ní ìgbèkùn lọ sí Bábílónì.
6. Ìhìn rere wo ni olùṣọ́ tí Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ kéde rẹ̀, ìgbà wo ló sì ní ìmúṣẹ?
6 Ẹ wo ayọ̀ ńlá tí èyí jẹ́ fún ìsìn èké! Àmọ́ ṣá o, ìjẹgàba Bábílónì kò wà fún ìgbà pípẹ́. Ní nǹkan bí igba ọdún ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn, Jèhófà pàṣẹ pé: “Lọ, yan alóre sẹ́nu iṣẹ́, kí ó lè sọ ohun tí òun ń rí.” Irú ìròyìn wo ní olùṣọ́ yìí ní tó fẹ́ kéde? “Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú, gbogbo ère fífín ti àwọn ọlọ́run rẹ̀ ni òun ti wó mọ́lẹ̀!” (Aísáyà 21:6, 9) Ó sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, àsọtẹ́lẹ̀ tí a polongo rẹ̀ yìí ní ìmúṣẹ. Bábílónì alágbára ṣubú, kò sì pẹ́ rárá tó fi ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú láti padà sí ilẹ̀ baba wọn.
7. (a) Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn Júù kọ́ látinú ìbáwí Jèhófà? (b) Pańpẹ́ wo ni àwọn Júù tún kó sí lẹ́yìn ìgbèkùn wọn, kí ló sì yọrí sí?
7 Ẹ̀kọ́ tí àwọn Júù tí ó padà sílé wọ̀nyí kọ́ tó fún wọn láti yàgò fún ìbọ̀rìṣà àti ìsìn to ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí àìrí. Síbẹ̀, bí ọdún ti ń gorí ọdún, wọ́n tún kó sínú pańpẹ́ mìíràn. Àwọn kan kó sínú pańpẹ́ ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì. Àwọn mìíràn jẹ́ kí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn borí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn mìíràn sì rèé, ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ló gbé wọn lọ. (Máàkù 7:13; Ìṣe 5:37) Nígbà tó fi máa di àkókò tí a bí Jésù, orílẹ̀-èdè náà tún ti kẹ̀yìn sí ìjọsìn mímọ́ gaara. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Júù kọ̀ọ̀kan tẹ́wọ́ gba ìhìn rere tí Jésù polongo rẹ̀, síbẹ̀ orílẹ̀-èdè náà lódindi kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Ọlọ́run sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ àwọn náà sílẹ̀ pẹ̀lú. (Jòhánù 1:9-12; Ìṣe 2:36) Bí Ísírẹ́lì kò ṣe jẹ́ ẹlẹ́rìí fún Ọlọ́run mọ́ nìyẹn, nígbà tó sì di ọdún 70 Sànmánì Tiwa, Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ di ahoro, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí o, àwọn ọmọ ogun Róòmù ló pa á run.—Mátíù 21:43.
8. Ta ló di ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, èé sì ti ṣe tí ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fún ẹlérìí yìí fi bọ́ sí àsìkò?
8 Àárín àkókò yìí la bí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ti ẹ̀sìn Kristẹni, èyí ló sì wá di ẹlẹ́rìí Ọlọ́run fún àwọn orílẹ̀-èdè nísinsìnyí. (Gálátíà 6:16) Kíámọ́sá ni Sátánì dọ́gbọ́n láti sọ orílẹ̀-èdè tẹ̀mí táa ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ yìí dìbàjẹ́. Nígbà tó fi máa di òpin ọ̀rúndún kìíní, wàhálà tí ìyapa ń dá sílẹ̀ ti wá hàn gbangba nínú ìjọ. (Ìṣípayá 2:6, 14, 20) Wẹ́kú ni ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣe nígbà tó wí pé: “Ẹ máa ṣọ́ra: bóyá ẹnì kan lè wà tí yóò gbé yín lọ gẹ́gẹ́ bí ẹran ọdẹ rẹ̀ nípasẹ̀ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo ní ìbámu pẹ̀lú òfin àtọwọ́dọ́wọ́ ènìyàn, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé, tí kò sì sí ní ìbámu pẹ̀lú Kristi.”—Kólósè 2:8.
9. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ rẹ̀ gẹ́ẹ́, kí ni àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ tó mú kí Kirisẹ́ńdọ̀mù di èyí tí ó wà?
9 Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì, èrò ẹ̀sìn àwọn ará Bábílónì, àti lẹ́yìn náà “ọgbọ́n orí” àwọn ènìyàn bí àbá-èrò-orí ẹfolúṣọ̀n àti ṣíṣe lámèyítọ́ ìtàn àti ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ wá kó ẹ̀gbin burúkú bá ẹ̀sìn ọ̀pọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ gẹ́ẹ́ ló rí pé: “Mo mọ̀ pé lẹ́yìn lílọ mi, àwọn aninilára ìkookò yóò wọlé wá sáàárín yín, wọn kì yóò sì fi ọwọ́ pẹ̀lẹ́tù mú agbo, àti pé láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyìdáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:29, 30) Ìpẹ̀yìndà táa sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ló wá bí Kirisẹ́ńdọ̀mù.
10. Kí ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó fi hàn gbangba pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló fara wọn fún ìsìn tó ti dómùkẹ̀ tí wọ́n ń ṣe ní Kirisẹ́ńdọ̀mù?
10 Àwọn tó dìídì fara wọn fún ìjọsìn mímọ́ gaara ní láti “ja ìjà líle fún ìgbàgbọ́ tí a fi lé àwọn ẹni mímọ́ lọ́wọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo.” (Júúdà 3) Ṣé jíjẹ́rìí sí ìjọsìn mímọ́ gaara àti sí Jèhófà yóò kásẹ̀ nílẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni? Rárá o. Bí àkókò tí a ó pa Sátánì ọlọ̀tẹ̀ nì àti gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ run ṣe ń sún mọ́lé, ó ti wá hàn gbangba pé kì í ṣe gbogbo ènìyàn ló fara mọ́ ìjọsìn àwọn apẹ̀yìndà tí wọ́n ń ṣe ní Kirisẹ́ńdọ̀mù. Nígbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń parí lọ, àwùjọ kan tó jẹ́ ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́-ọkàn kóra jọ ní Pittsburgh, Pennsylvania, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, wọ́n sì di ìpìlẹ̀ fún àwọn ẹlẹ́rìí Ọlọ́run tó wà lóde òní. Àwọn Kristẹni wọ̀nyí pe àfiyèsí àwọn ènìyàn sí àwọn ẹ̀rí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ pé, òpin ètò àwọn nǹkan ayé ìsinsìnyí ti sún mọ́lé. Ní ìbámu pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, “ìparí” ayé yìí ti bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1914 tí Ogun Àgbáyé Kìíní tó bẹ́ sílẹ̀ nígbà náà sàmì sí. (Mátíù 24:3, 7) Ẹ̀rí tó múná dóko fi hàn pé lẹ́yìn ọdún yẹn la lé Sátánì àti àwọn ogunlọ́gọ̀ ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò ní ọ̀run. Ọ̀rúndún ogún oníwàhálà yìí ti fún wa ní ẹ̀rí tó ṣe kedere nípa itú tí Sátánì ń pa àti ọ̀nà tí àmì wíwàníhìn-ín Jésù gẹ́gẹ́ bí ọba nínú agbára Ìjọba ọ̀run gbà nímùúṣẹ lọ́nà kíkàmàmà.—Mátíù, orí 24 àti 25; Máàkù, orí 13; Lúùkù, orí 21; Ìṣípayá 12:10, 12.
11. Kí ni Sátánì jà fitafita láti ṣe, àmọ́ báwo ni kìràkìtà rẹ̀ ṣe já sásán?
11 Ní June 1918, Sátánì jà fitafita láti pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ̀nyẹn run, àwọn tó jẹ́ pé wọ́n ti ń wàásù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè lákòókò yẹn. Ó tilẹ̀ tún wọ́nà láti pa ẹgbẹ́ wọn táa ti fi òfin gbé kalẹ̀ pàápàá run, ìyẹn ni Watch Tower Bible and Tract Society. Wọ́n fi àwọn tó dipò pàtàkì mú nínú àwọn òṣìṣẹ́ Society sẹ́wọ̀n, wọ́n fi ẹ̀sùn èké kàn wọ́n pé wọ́n lòdì sí ìjọba, bí wọ́n ṣe fi kan Jésù ní ọ̀rúndún kìíní. (Lúùkù 23:2) Àmọ́, nígbà tó di ọdún 1919, a dá àwọn òṣìṣẹ́ wọ̀nyí sílẹ̀, kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lọ. Níkẹyìn a dá wọn láre, a sì dá wọ́n sílẹ̀ pátápátá.
“Alóre” Tó Wà Lójúfò
12. Àwọn wo ló para pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ olùṣọ́ tí Jèhófà yàn, tàbí “alóre” lóde òní, irú ìṣarasíhùwà wo ni wọ́n sì ti ní?
12 Nígbà tí “àkókò òpin” bẹ̀rẹ̀, Jèhófà tún ní olùṣọ́ kan tó wá sójútáyé, tó ń ta àwọn ènìyàn lólobó nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ní í ṣe pẹ̀lú ìmúṣẹ àwọn ète Rẹ̀. (Dáníẹ́lì 12:4; 2 Tímótì 3:1) Títí di oní olónìí, ẹgbẹ́ olùṣọ́ yẹn—ìyẹn ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, Ísírẹ́lì Ọlọ́run—ti ń ṣiṣẹ́ tó bá àpèjúwe Aísáyà nípa olùṣọ́ inú asọtẹ́lẹ̀ náà mu, ó wí pé: “Ó sì fiyè sílẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú ìfiyèsílẹ̀ púpọ̀. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké bí kìnnìún pé: ‘Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, ibi ìṣọ́ mi sì ni mo dúró sí ní gbogbo òru.’” (Aísáyà 21:7, 8) Olùṣọ́ kan tó káràmásìkí iṣẹ́ rẹ̀ mà lèyí o!
13. (a) Ìhìn iṣẹ́ wo ni olùṣọ́ tí Jèhófà yàn yìí ti kéde rẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè sọ pé Bábílónì Ńlá ti ṣubú?
13 Kí ni olùṣọ́ yìí rí? Lẹ́ẹ̀kan sí i, olùṣọ́ tí Jèhófà yàn náà, ẹgbẹ́ àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀, tún kéde pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú, gbogbo ère fífín ti àwọn ọlọ́run rẹ̀ ni òun [Jèhófà] ti wó mọ́lẹ̀!” (Aísáyà 21:9) Lọ́tẹ̀ yìí, ìyẹn lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, Bábílónì Ńlá, ìyẹn ni ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé, la ré lulẹ̀ láti orí ipò àṣẹ rẹ̀ tó lé téńté sí. (Jeremáyà 50:1-3; Ìṣípayá 14:8) Abájọ! Inú Kirisẹ́ńdọ̀mù ni Ogun Ńlá náà, bí wọ́n ṣe pè é nígbà yẹn ti bẹ̀rẹ̀, níbi tí àwọn ẹgbẹ́ àlùfáà tó wà níhà méjèèjì tó ń bára wọn jagun ti ń bu epo síná ogun tó ń jó lala náà, wọ́n ṣe èyí nípa fífún àwọn tó taagun jù lọ nínú àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn níṣìírí láti lọ jagun. Nǹkan ìtìjú gbáà mà lèyí o! Ní ọdún 1919, Bábílónì Ńlá kò lè dí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bí a ti ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà náà, lọ́wọ́ pé kí wọ́n máà jí gìrì láti inú ipò àìṣiṣẹ́mọ́ tí wọ́n wà, kí wọ́n sì dáwọ́ lé iṣẹ́ ìjẹ́rìí jákèjádò ayé, iṣẹ́ tó ṣì ń lọ lọ́wọ́ báyìí. (Mátíù 24:14) Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn tani lólobó pé ìṣubú Bábílónì Ńlá ti dé, gẹ́gẹ́ bí ìdáǹdè Ísírẹ́lì ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa ṣe fi hàn pé ìṣubú Bábílónì ìgbàanì ti dé.
14. Ìwé ìròyìn wo ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ tí Jèhófà yàn ti lò lọ́nà to gbàfiyèsí, báwo sì ni Jèhófà ṣe bù kún ọ̀nà tí a gbà ń lò ó?
14 Ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà ti máa ń fìgbà gbogbo ṣe iṣẹ́ tí a yàn fún un pẹ̀lú ìtara àti ìfẹ́ tó lágbára láti ṣe ohun tó tọ́. Ní July 1879, àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde, ohun tí a mọ̀ ọ́n sí nígbà náà ni Zion’s Watch Tower and Herald of Christ’s Presence. Gbogbo ìtẹ̀jáde rẹ̀ láti ọdún 1879 yẹn títí di December 15, 1938, ló ń ní àkọlé náà níwájú pé “‘Olùṣọ́, òru ti rí?’—Aísáyà 21:11.”a Lọ́nà tó fi hàn pé ó ṣeé gbára lé, fún ọgọ́fà ọdún ni Ilé Ìṣọ́ ti ń kíyè sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń lọ lágbàáyé àti ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti wà nílẹ̀. (2 Tímótì 3:1-5, 13) Ẹgbẹ́ olùṣọ́ tí Ọlọ́run yàn yìí àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó jẹ́ “àgùntàn mìíràn” ti lo ìwé ìròyìn yìí láti fi gbogbo okun wọn kéde fáráyé pé ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà nípasẹ̀ Ìjọba Kristi ti sún mọ́lé. (Jòhánù 10:16) Ǹjẹ́ Jèhófà ti bù kún iṣẹ́ ìjẹ́rìí yìí? Ní gidi, láti orí ẹgbàata ẹ̀dà táa kọ́kọ́ tẹ̀ jáde lọ́dún 1879, Ilé Ìṣọ́ ti di èyí tí a ń pín jákèjádò ayé báyìí tí ìtẹ̀jáde rẹ̀ kọ̀ọ̀kan sì ti lé ní mílíọ̀nù méjìlélógún ẹ̀dà ní èdè méjìléláàádóje—nínú èyí tí mọ́kànlélọ́gọ́fà lára rẹ̀ ń jáde nígbà kan náà pẹ̀lú ti èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ wo bó ti dára tó pé ìwé ìròyìn ẹ̀sìn tí a pín káàkiri jù lọ lágbàáyé jẹ́ èyí tó gbé orúkọ Jèhófà, Ọlọ́run òtítọ́ náà ga!
Ìyọ́mọ́ Ní Ṣísẹ̀-N-Tẹ̀-Lé
15. Ìyọ́mọ́ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé wo ló ti bẹ̀rẹ̀ ṣáájú ọdún 1914 pàápàá?
15 Láàárín nǹkan bí ogójì ọdún títí di ìgbà tí ìṣàkóso Kristi bẹ̀rẹ̀ lókè ọ̀run ní 1914 ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti dòmìnira kúrò nínú ọ̀pọ̀ lára àwọn ìgbàgbọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù tí kò bá Bíbélì mu, àwọn bíi ṣíṣe ìbatisí fún ọmọ ọwọ́, àìleèkú ọkàn ènìyàn, pọ́gátórì, iná ọ̀run àpáàdì, àti Ọlọ́run Mẹ́talọ́kan. Àmọ́, ó túbọ̀ gba àkókò sí i láti kó gbogbo èrò òdì tí wọ́n ní da nù. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn ọdún 1920, ọ̀pọ̀ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló máa ń lẹ nǹkan ọ̀ṣọ́ tó ní àgbélébùú àti adé lára mọ́ àyà wọn, wọ́n sì tún máa ń ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì àti àwọn ọdún mìíràn tó jẹ́ ti ìbọ̀rìṣà. Àmọ́ ṣá o, kí ìjọsìn kan tó lè mọ́ gaara, gbogbo àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà la gbọ́dọ̀ mú kúrò pátápátá. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìyẹn Bíbélì Mímọ́, ló gbọ́dọ̀ jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì tí a gbé ìgbàgbọ́ àti ọ̀nà ìgbésí ayé Kristẹni kà. (Aísáyà 8:19, 20; Róòmù 15:4) Kò tọ̀nà láti fi kún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàbí ká yọ ohunkóhun kúrò nínú rẹ̀.—Diutarónómì 4:2; Ìṣípayá 22:18, 19.
16, 17. (a) Èrò tó lòdì wo ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà ti dì mú fún àwọn ẹ̀wádún díẹ̀? (b) Kí ni àlàyé tí ó tọ́ nípa “pẹpẹ” àti “ọwọ̀n” tó wà ní “Íjíbítì”?
16 Àpẹẹrẹ kan yóò fi bí ìlànà yìí ti ṣe pàtàkì tó hàn. Ní ọdún 1886, nígbà tí C. T. Russell ṣe ìwé kan tí a mọ̀ sí The Divine Plan of the Ages jáde, ìdìpọ̀ yìí ní ṣáàtì kan nínú, èyí tó ṣàlàyé ìsopọ̀ tó wà láàárín sànmánì tí ìran ènìyàn ti lò àti Òkè Ńlá Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ti àwọn ará Íjíbítì. Òye rẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni pé, ibojì Fáráò Khufu ni ọwọ̀n táa tọ́ka sí nínú Aísáyà 19:19, 20, tó kà pé: “Ní ọjọ́ yẹn, pẹpẹ kan yóò wà fún Jèhófà ní àárín ilẹ̀ Íjíbítì, àti ọwọ̀n kan fún Jèhófà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà rẹ̀. Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní ilẹ̀ Íjíbítì.” Kí ni òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ lè ní í ṣe pẹ̀lú Bíbélì? Toò, fún àpẹẹrẹ, òye tí wọ́n ní nígbà yẹn lọ́hùn-ún ni pé, bí àwọn ọ̀nà tó gba inú Òkè Ńlá Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ náà kọjá ti gùn tó ló ń fi àkókò tí “ìpọ́njú ńlá” tó wà nínú Mátíù 24:21 yóò bẹ̀rẹ̀ hàn. Àwọn kan lára àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wá jẹ́ kí wíwọn bí àwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ síra náà ti gùn tó wá gbà wọ́n lọ́kàn pátápátá, débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lò wọ́n láti pinnu àwọn ọ̀ràn bí ọjọ́ tí àwọn yóò lọ sí ọ̀run!
17 Ọ̀pọ̀ ẹ̀wádún ni wọ́n fi ń gbé ohun tí wọ́n pè ní Bíbélì inú Òkè Aboríṣóńṣó-Bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ yìí gẹ̀gẹ̀, títí di ìgbà tí àwọn ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ ti November 15 àti December 1, 1928, wá ṣàlàyé rẹ̀ ní kedere pé Jèhófà kò nílò àwọn ibojì tí àwọn Fáráò abọ̀rìṣà kọ́, tó sì ní àwọn àmì ẹ̀mí èṣù tí àwọn awòràwọ̀ ń lò láti fìdí àwọn ẹ̀rí tó wà nínú Bíbélì múlẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìtumọ̀ tẹ̀mí ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìṣípayá 11:8, “Íjíbítì” ń ṣàpẹẹrẹ ayé Sátánì. “Pẹpẹ Jèhófà” rán wa létí ẹbọ ìtẹ́wọ́gbà tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń rú ní àkókò díẹ̀ tí wọ́n gbé nínú ayé yìí. (Róòmù 12:1; Hébérù 13:15, 16) Ọwọ̀n “tó wà lẹ́yìn odi [Íjíbítì]” ń tọ́ka sí ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, èyí tó jẹ́ “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́” tó sì dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ní “Íjíbítì,” ìyẹn ayé tó kù díẹ̀ kí wọ́n kúrò nínú rẹ̀.—1 Tímótì 3:15.
18. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kí nǹkan túbọ̀ yé àwọn tí ń fi tọkàntọkàn kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (b) Bó bá ṣòro fún Kristẹni kan láti lóye àlàyé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, irú ẹ̀mí wo ló bọ́gbọ́n mu ki irú ẹni bẹ́ẹ̀ ní?
18 Bí ọdún ti ń gorí ọdún ni Jèhófà túbọ̀ ń mú kí òye òtítọ́ yé wa sí i, títí kan lílóye àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ní kíkún sí i. (Òwe 4:18) Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a tún ti gbà wá níyànjú láti túbọ̀ fi òye tó jinlẹ̀ wo—àwọn nǹkan bíi—ìran tí kò ní ré kọjá kí òpin náà tóó dé, àkàwé àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́, ohun ìríra náà àti ìgbà tí yóò dúró ni ibi mímọ́, májẹ̀mú tuntun náà, ìyípadà ológo, àti ìran tẹ́ńpìlì tó wà nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì. Nígbà mìíràn ó máa ń ṣòro láti lóye irú àwọn àlàyé tuntun bẹ́ẹ̀, àmọ́ bí àkókò ti ń lọ la ó wá lóye ìdí táa fi ṣe irú àwọn àlàyé tuntun bẹ́ẹ̀. Bí Kristẹni kan kò bá lóye àlàyé tuntun kan táa ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, yóò dára tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lè fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ tún àwọn ọ̀rọ̀ Wòlíì Míkà nì sọ pé: “Èmi yóò fi ẹ̀mí ìdúródeni hàn sí Ọlọ́run ìgbàlà mi.”—Míkà 7:7.
19. Báwo ni àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn ṣe fi ìgboyà bíi ti kìnnìún hàn ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí?
19 Rántí pé olùṣọ́ náà “bẹ̀rẹ̀ sí ké bí kìnnìún pé: ‘Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, ibi ìṣọ́ mi sì ni mo dúró sí ní gbogbo òru.’” (Aísáyà 21:8) Àwọn ẹni àmì òróró ti fi ìgboyà bíi ti kìnnìún hàn nípa títú ìsìn èké fó, tí wọ́n sì ń fi ọ̀nà tó sinni lọ sí òmìnira han àwọn ènìyàn. (Ìṣípayá 18:2-5) Gẹ́gẹ́ bí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” wọ́n ti pèsè ọ̀pọ̀ Bíbélì, ìwé ìròyìn, àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdè—ìwọ̀nyí ni “oúnjẹ . . . ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mátíù 24:45) Wọ́n ti mú ipò iwájú nínú kíkó “ogunlọ́gọ̀ ńlá, . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” jọ. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ni ẹ̀jẹ̀ Jésù tó lè rani padà ti wẹ̀ mọ́, wọ́n sì ń fi hàn pé àwọn láyà bíi kìnnìún ní ṣíṣe “iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀” fún Ọlọ́run “tọ̀sán-tòru.” (Ìṣípayá 7:9, 14, 15) Kí ni àbájáde iṣẹ́ ìwọ̀nba kéréje tó ṣẹ́ kù lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ẹni àmì òróró àti àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá, tó jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí? Àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé èyí yóò sọ ọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láti January 1, 1939 ni a ti yí i padà sí “‘Wọn yóò sì ní láti mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’—Ìsíkíẹ́lì 35:15.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Irú àwọn ẹlẹ́rìí wo ni Jèhófà ti ní láti àwọn ọdún wọ̀nyí wa?
• Ibo ni Bábílónì Ńlá ti bẹ̀rẹ̀?
• Èé ṣe ti Jèhófà fi yọ̀ǹda kí a pa Jerúsálẹ́mù, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ run ni ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa? àti ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa?
• Irú ẹ̀mí wo ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ tí Jèhófà yàn àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ti fi hàn?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
“Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹgbẹ́ olùṣọ́ tí Jèhófà yàn ń ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́