Orí Kẹrìndínlógún
Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà fún Ìtọ́sọ́nà àti Ààbò
1, 2. Ewu wo ló rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa, ibo sì lọ̀pọ̀ nínú wọn ń fẹ́ yíjú sí fún ààbò?
GẸ́GẸ́ bí a ṣe rí i nínú àwọn orí tó ṣáájú nínú ìwé yìí, ewu tó bani lẹ́rù rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí àwọn èèyàn Ọlọ́run ní ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa. Àwọn ará Ásíríà afẹ̀jẹ̀wẹ̀ kàn ń run àwọn orílẹ̀-èdè lọ ràì, wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kan ìjọba Júdà níhà gúúsù lára. Ibo làwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yẹn wá fẹ́ yíjú sí fún ààbò? Àwọn àti Jèhófà jọ dá májẹ̀mú, òun ló sì yẹ kí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé fún ìrànlọ́wọ́. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Ohun tí Dáfídì Ọba ṣe nìyẹn. Ó sọ pé: “Jèhófà ni àpáta gàǹgà mi àti odi agbára mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.” (2 Sámúẹ́lì 22:2) Àmọ́, ó dájú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ní ọ̀rúndún kẹjọ ni kò gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà gẹ́gẹ́ bí odi ààbò wọn. Íjíbítì àti Etiópíà ni wọ́n ń fẹ́ yíjú sí, nírètí pé àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì wọ̀nyí yóò dènà ogun tí Ásíríà fẹ́ gbé jà wọ́n. Àṣìṣe ni wọ́n ṣe yẹn.
2 Jèhófà gba ẹnu wòlíì rẹ̀ Aísáyà kìlọ̀ fún wọn pé wọn yóò ko àgbákò bí wọ́n bá wá ààbò lọ sọ́dọ̀ Íjíbítì tàbí Etiópíà. Ẹ̀kọ́ pàtàkì lọ̀rọ̀ onímìísí tí wòlíì yìí sọ kọ́ àwọn tó wà láyé ìgbà yẹn, ó sì kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ gidi nípa bí ó ti ṣe pàtàkì tó pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.
Orílẹ̀-Èdè Ìtàjẹ̀sílẹ̀
3. Ṣàpèjúwe bí Ásíríà ṣe fẹ́ràn agbára ogun tó.
3 Òkìkí àwọn ará Ásíríà kàn fún agbára ogun jíjà tí wọ́n ní. Ìwé Ancient Cities sọ pé: “Agbára ni wọ́n ń bọ, wọn kì í sì í gbàdúrà sóhun mìíràn ju àwọn ère olókùúta, ère kìnnìún àti ère akọ màlúù gìrìwò gìrìwò, tó jẹ́ pé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn tó tóbi ràpàtà, ìyẹ́ apá idì, àti orí èèyàn tí wọ́n ní, jẹ́ àmì agbára, ìgboyà, àti ìṣẹ́gun. Ogun jíjà ni iṣẹ́ orílẹ̀-èdè yẹn, àwọn àwòrò wọn ló sì máa ń dá ogun sílẹ̀.” Abájọ tí Náhúmù, wòlíì inú Bíbélì, fi pe Nínéfè, olú ìlú Ásíríà, ní “ìlú ńlá ìtàjẹ̀sílẹ̀.”—Náhúmù 3:1.
4. Báwo ni àwọn ará Ásíríà ṣe kó jìnnìjìnnì bá ọkàn àwọn orílẹ̀-èdè yòókù?
4 Ọ̀nà táwọn ará Ásíríà máa ń gbà jagun tiwọn níkà nínú púpọ̀. Àwọn àwòrán tí wọ́n gbẹ́ láyé ìgbà yẹn fi àwọn jagunjagun ará Ásíríà hàn bí wọ́n ṣe fi ìkọ́ kọ́ imú tàbí ètè àwọn òǹdè, wọ́n sì fi ń fà wọ́n lọ. Wọ́n a fi ọ̀kọ̀ fọ́ ojú àwọn òǹdè mìíràn. Àkọlé kan dá lórí ìṣẹ́gun kan nínú èyí tí àwọn ọmọ ogun Ásíríà ti gé ẹ̀yà ara àwọn òǹdè wọn, tí wọ́n sì kó wọn jọ sí òkìtì méjì sẹ́yìn ìlú—òkìtì kan jẹ́ kìkìdá orí, ìkejì jẹ́ ọwọ́ àti ẹsẹ̀. Wọ́n sì dáná sun ọmọ àwọn tí wọ́n ṣẹ́gun. Jìnnìjìnnì tí irú ìwà ìkà yẹn ń kó báni ṣe àwọn ará Ásíríà láǹfààní nínú ogun jíjà, ó ń jẹ́ kí ọwọ́ àwọn ọ̀tá tó bá fẹ́ gbéjà ko àwọn ọmọ ogun wọ́n rọ.
Ogun Tó Ja Áṣídódì
5. Ta ni ọba alágbára ní Ásíríà nígbà ayé Aísáyà, báwo ni ẹ̀rí ṣe ti àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa rẹ̀ lẹ́yìn?
5 Nígbà ayé Aísáyà, agbára Ilẹ̀ Ọba Ásíríà ga dé ìwọ̀n tó ju tàtẹ̀yìnwá lọ lábẹ́ Ságónì Ọba.a Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn aṣelámèyítọ́ kò fi gbogbo ara gbà pé ọba yìí wà rí, nítorí pé wọn ò rí ìwé ayé kankan tó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó yá, àwọn awalẹ̀pìtàn walẹ̀ kan ààfin Ságónì, bí ìyẹn ṣe jẹ́rìí ti àkọsílẹ̀ Bíbélì nìyẹn.
6, 7. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó jẹ́ ìdí tí Ságónì fi pàṣẹ pé kí wọ́n gbéjà ko Áṣídódì? (b) Ipa wo ni ìṣubú Áṣídódì ní lórí àwọn tó wà nítòsí Filísíà?
6 Aísáyà ṣe àlàyé ráńpẹ́ nípa ogun kan tí Ságónì jà, ó ní: “Tátánì wá sí Áṣídódì, nígbà tí Ságónì ọba Ásíríà rán an, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá Áṣídódì jagun, ó sì gbà á.” (Aísáyà 20:1)b Kí ló mú kí Ságónì sọ pé kí wọ́n gbéjà ko ìlú Áṣídódì ti Filísínì? Ìdí kan ni pé, alájọṣe ni Íjíbítì àti Filísíà, àti pé ojú ọ̀nà tó gba etíkun láti Íjíbítì lọ dé Palẹ́sínì ni Áṣídódì wà, níbi tí wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì Dágónì sí. Nípa bẹ́ẹ̀, ojútáyé nìlú yẹn wà. Bí wọ́n bá ti lè ṣẹ́gun rẹ̀ a jẹ́ pé ọwọ́ ń ba Íjíbítì bọ̀ díẹ̀díẹ̀ nìyẹn. Ẹ̀wẹ̀, àwọn àkọsílẹ̀ Ásíríà sọ pé Ásúrì ọba Áṣídódì ń di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí Ásíríà. Nípa bẹ́ẹ̀, Ságónì ní kí wọ́n rọ ọlọ̀tẹ̀ ọba yẹn lóyè, ó sì fi àbúrò rẹ̀, Áhímítì, jọba. Ṣùgbọ́n, ìyẹn kò yanjú ọ̀ràn náà. Ọ̀tẹ̀ mìíràn tún rú, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ságónì hàn wọ́n léèmọ̀. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n gbéjà ko Áṣídódì, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sàga tì í, wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀. Ó jọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ni Aísáyà 20:1 ń sọ nípa rẹ̀.
7 Ṣíṣubú tí Áṣídódì ṣubú jẹ́ ewu fún gbogbo àwọn tó wà nítòsí rẹ̀, pàápàá Júdà. Jèhófà mọ̀ pé “apá tí ó jẹ́ ẹran ara,” irú bíi Íjíbítì tàbí Etiópíà níhà gúúsù, làwọn èèyàn òun fẹ́ gbára lé. Nítorí náà, ó ní kí Aísáyà ṣe àṣefihàn kan láti fi ṣèkìlọ̀ pàtàkì fún wọn.—2 Kíróníkà 32:7, 8.
“Ní Ìhòòhò àti Láìwọ Bàtà”
8. Kí ni Aísáyà ṣe lábẹ́ ìmísí láti fi sàsọtẹ́lẹ̀?
8 Jèhófà sọ fún Aísáyà pé: “Lọ, kí o sì tú aṣọ àpò ìdọ̀họ kúrò ní ìgbáròkó rẹ; kí o sì bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Aísáyà ṣe bí Jèhófà ṣe pàṣẹ. “Ó sì tẹ̀ síwájú láti ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń rìn káàkiri ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà.” (Aísáyà 20:2) Aṣọ àpò ìdọ̀họ jẹ́ ẹ̀wù háráhárá tí àwọn wòlíì sábà máa ń wọ̀, bóyá tí wọ́n bá fẹ́ jíṣẹ́ ìkìlọ̀. Wọ́n tún máa ń wọ̀ ọ́ nígbà ìṣòro tàbí bí wọ́n bá gbọ́ ìròyìn burúkú kan. (2 Àwọn Ọba 19:2; Sáàmù 35:13; Dáníẹ́lì 9:3) Ṣé Aísáyà wá ń káàkiri ní ìhòòhò goloto ni? Kò fi dandan rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ èdè Hébérù táa túmọ̀ sí “ìhòòhò” tún lè tọ́ka sí pé ẹni náà wọ aṣọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ bo ara tàbí aṣọ jáńpé. (1 Sámúẹ́lì 19:24, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀wù àwọ̀lékè ni Aísáyà kàn bọ́ sílẹ̀, kó wá ku àwọ̀tẹ́lẹ̀ péńpé tí wọ́n sábà máa ń kọ́kọ́ wọ̀ sára. Báyìí làwọn ará Ásíríà ṣe máa ń gbẹ́ àwòrán àwọn òǹdè tó jẹ́ ọkùnrin.
9. Kí ni nǹkan alásọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà ṣe túmọ̀ sí?
9 Ìtumọ̀ ohun àrà ọ̀tọ̀ tí Aísáyà ṣe yìí kò fara sin rárá, nítorí pé: “Jèhófà . . . ń bá a lọ láti sọ pé: ‘Gan-an gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Aísáyà ti rìn káàkiri ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà fún ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí àmì àti àmì àgbàyanu lòdì sí Íjíbítì àti lòdì sí Etiópíà, bẹ́ẹ̀ ni ọba Ásíríà yóò ṣe kó ẹgbẹ́ àwọn òǹdè Íjíbítì àti àwọn ìgbèkùn Etiópíà lọ, ọmọdékùnrin àti àgbàlagbà, ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà, ti àwọn ti ekiti ìdí tí a kò fi aṣọ bò, ìhòòhò Íjíbítì.’” (Aísáyà 20:3, 4) Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ará Íjíbítì àti àwọn ará Etiópíà yóò dèrò ìgbèkùn láìpẹ́. Kò ní yọ ẹnikẹ́ni sílẹ̀. Àní àti “ọmọdékùnrin àti àgbàlagbà,” ìyẹn ni, tọmọdé tàgbà, ni wọ́n máa gba gbogbo ohun ìní wọn, wọn yóò sì kó wọn lọ sígbèkùn. Ohun tó páni láyà yìí ni Jèhófà lò láti fi kìlọ̀ fún àwọn olùgbé Júdà pé pàbó ni yóò já sí bí wọ́n bá gbẹ́kẹ̀ wọn lé Íjíbítì àti Etiópíà. Ńṣe ni ìṣubú orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn máa tú wọn sí “ìhòòhò”—yóò mú wọn tẹ́ gbáà!
Ìrètí Wọmi, Ẹwà Ṣá
10, 11. (a) Kí ni Júdà yóò ṣe bí wọ́n bá ti rí i pé Íjíbítì àti Etiópíà ò lè mí fín-ín níwájú Ásíríà? (b) Kí ló lè mú kí àwọn olùgbé Júdà fẹ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Íjíbítì àti Etiópíà?
10 Lẹ́yìn èyí, Jèhófà wá fi àsọtẹ́lẹ̀ ṣàpèjúwe ohun tí àwọn èèyàn òun máa ṣe bí wọ́n bá ti rí i pé Íjíbítì àti Etiópíà, tí wọ́n retí pé yóò jẹ́ ibi ìsádi fáwọn, kò lè mí fín-ín níwájú àwọn Ásíríà. Ó ní: “Dájúdájú, wọn yóò sì jáyà, ojú yóò sì tì wọ́n fún Etiópíà, ìrètí tí wọ́n ń wọ̀nà fún, àti fún Íjíbítì ẹwà wọn. Ó sì dájú pé àwọn olùgbé ilẹ̀ etí òkun yìí yóò wí ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Bí ìrètí tí a ń wọ̀nà fún ti rí nìyẹn, èyí tí a sá lọ bá fún ìrànwọ́, kí a lè dá wa nídè nítorí ọba Ásíríà! Báwo sì ni àwa alára yóò ṣe yèbọ́?’”—Aísáyà 20:5, 6.
11 Bí ilẹ̀ tẹ́ẹ́rẹ́ létíkun ni Júdà rí lẹ́gbẹ̀ẹ́ agbára tí Íjíbítì àti Etiópíà ní. Bóyá ẹwà Íjíbítì ti kó sí àwọn kan lára àwọn olùgbé “ilẹ̀ etíkun yìí” lórí, ìyẹn ni, àwọn ilé àrímáleèlọ aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ ibẹ̀, àwọn tẹ́ńpìlì rẹ̀ gàgàrà gàgàrà, àtàwọn ilé alágbàlá gbàràmù gbaramu ibẹ̀, tó ní àwọn ọgbà ìtura, ọgbà èso àti àwọn adágún omi. Ńṣe ló dà bíi pé àwọn ilé aláràbarà tí wọ́n fà kalẹ̀ sí Íjíbítì jẹ́ ẹ̀rí pé orílẹ̀-èdè yẹn tòrò, pé yóò sì máa wà lọ títí ni. Ilẹ̀ yẹn kò tiẹ̀ lè pa run o jàre! Ó ṣeé ṣe kí àwọn tafàtafà Etiópíà, àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àtàwọn ẹlẹ́ṣin rẹ̀ sì tún wú àwọn Júù lórí pẹ̀lú.
12. Ta ló yẹ kí Júdà gbẹ́kẹ̀ lé?
12 Lójú ìkìlọ̀ tí Aísáyà ṣe àṣefihàn rẹ̀ àti ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Jèhófà sọ, kí èyíkéyìí lára àwọn tó láwọn jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run tó bá fẹ́ gbẹ́kẹ̀ lé Íjíbítì àti Etiópíà yáa rò ó wò dáadáa. Ó mà sàn láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà o, dípò gbígbẹ́kẹ̀ lé ọmọ aráyé! (Sáàmù 25:2; 40:4) Ibi tí ọ̀ràn yẹn já sí ni pé ọba Ásíríà jẹ Júdà níyà gidigidi, lẹ́yìn náà, Bábílónì tún pa tẹ́ńpìlì àti olú ìlú rẹ̀ run. Síbẹ̀, ó ṣẹ́ ku “ìdá mẹ́wàá,” “irúgbìn mímọ́,” bíi kùkùté igi ràbàtà kan. (Aísáyà 6:13) Nígbà tó bá yá, okun ńláǹlà gbáà lọ̀rọ̀ Aísáyà yóò fún ìgbàgbọ́ àwùjọ kéréje yẹn, àwọn tí ìgbàgbọ́ wọn nínú Jèhófà kò yẹ̀!
Jèhófà Ni Kí O Gbẹ́kẹ̀ Lé
13. Lóde òní, àwọn pákáǹleke wo ló kan gbogbo èèyàn, àti onígbàgbọ́ àti aláìgbàgbọ́?
13 Ìkìlọ̀ Aísáyà nípa bó ṣe jẹ́ asán láti gbẹ́kẹ̀ lé Íjíbítì àti Etiópíà kì í wulẹ̀ í ṣe òkú ìtàn. Ó wúlò fún wa lóde òní. “Àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” là ń gbé. (2 Tímótì 3:1) Kì í ṣe kìkì àwọn tó kọ ìṣàkóso Ọlọ́run nìkan ni ọrọ̀ ajé tó dojú rú, ipò òṣì tó ń jà ràn-ìn, ọ̀rọ̀ òṣèlú tí kò níyanjú, rúkèrúdò aráàlú, àti ogun abẹ́lé tàbí ogun ńláńlá, ń kó ìbànújẹ́ bá, ó ń kó ìbànújẹ́ bá àwọn olùjọsìn Jèhófà pẹ̀lú. Ìbéèrè táa ó bi ara wa ni pé, ‘Ta ni mo fẹ́ yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́?’
14. Èé ṣe tó fi jẹ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ló yẹ kí a gbẹ́kẹ̀ lé?
14 Àwọn tó mọ àpadé-àludé ọrọ̀ ajé, àwọn òṣèlú, àtàwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní, tó máa ń sọ pé àwọn yóò lo ọgbọ́n ènìyàn àti òye iṣẹ́ ẹ̀rọ láti fi yanjú ìṣòro àwọn ènìyàn lè mú ìwúrí bá àwọn èèyàn kan. Àmọ́ Bíbélì sọ kedere pé: “Ó sàn láti sá di Jèhófà ju láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú.” (Sáàmù 118:9) Pàbó ni gbogbo àlàáfíà àti ààbò tí ènìyàn ń wéwèé yóò já sí, ohun tó fà á ni wòlíì Jeremáyà ti sọ lọ́nà tó ṣe wẹ́kú pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
15. Ọwọ́ ta ni ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún aráyé oníṣòro wà?
15 Nígbà náà, ó ṣe pàtàkì pé kí agbára tàbí ọgbọ́n yòówù tó lè dà bíi pé ayé yìí ní má ṣe wú àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lórí kọjá bó ṣe yẹ. (Sáàmù 33:10; 1 Kọ́ríńtì 3:19, 20) Ọwọ́ Jèhófà, Ẹlẹ́dàá ni ìrètí kan ṣoṣo tó wà fún aráyé oníṣòro wà. Àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e yóò rí ìgbàlà. Bí àpọ́sítélì Jòhánù táa mí sí ṣe kọ ọ́, “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn òpìtàn sọ pé ọba yìí ni Ságónì Kejì. Ọba kan tó ti wà ṣáájú rẹ̀ ni wọ́n pè ní “Ságónì Kìíní,” ọba Ásíríà kọ́ o, ọba Bábílónì ni.
b “Tátánì” kì í ṣe orúkọ, bí kò ṣe oyè ọ̀gágun àgbà fún Ásíríà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé agbára tirẹ̀ ló wà nípò kejì ní ilẹ̀ ọba yẹn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 209]
Àwọn ará Ásíríà máa ń fọ́ àwọn kan lójú lára àwọn òǹdè wọn
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 213]
Ohun tí àwọn ènìyàn ti gbé ṣe lè wú àwọn kan lórí, ṣùgbọ́n ohun tó ti dára jù ni pé ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà