Orí Kẹtàdínlógún
“Bábílónì Ti Ṣubú!”
1, 2. (a) Kí ni lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ tí Bíbélì ní, ṣùgbọ́n, ìsọ̀rí pàtàkì wo ló fara hàn nínú ìwé Aísáyà? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàlàyé ìṣubú Bábílónì?
A LÈ fi Bíbélì wé àgbà orin, tó ní lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan, tí wọ́n sì wá pín orin náà sí ìsọ̀rí-ìsọ̀rí láti túbọ̀ fi kún adùn rẹ̀ tó tayọ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, lájorí ẹṣin ọ̀rọ̀ kan ni Bíbélì ní, ìyẹn ni, lílo Ìjọba Mèsáyà láti fi dá ipò ọba aláṣẹ Jèhófà láre. Ó tún ní àwọn ìsọ̀rí mìíràn tó ṣe pàtàkì, tó ń hàn léraléra pẹ̀lú. Ọ̀kan lára wọn ni ìṣubú Bábílónì.
2 Ìsọ̀rí yìí ni Aísáyà orí kẹtàlá àti ìkẹrìnlá nasẹ̀ rẹ̀. Ó tún fara hàn ní orí kọkànlélógún, ó sì tún fara hàn ní orí kẹrìnlélógójì àti ìkarùndínláàádọ́ta pẹ̀lú. Ní ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, Jeremáyà fẹ ìsọ̀rí yìí kan náà lójú, ìwé Ìṣípayá wá parí rẹ̀ lọ́nà tó bùáyà. (Jeremáyà 51:60-64; Ìṣípayá 18:1–19:4) Ó yẹ kí ìsọ̀rí pàtàkì yìí, nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, jẹ gbogbo àwọn tó bá ń fi tọkàntara kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lógún. Aísáyà orí kọkànlélógún sì ṣèrànwọ́ nípa èyí, nítorí ó sọ àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó wúni lórí nípa àsọtẹ́lẹ̀ ìṣubú agbára ayé ńlá yẹn. Tó bá yá, a óò rí i pé Aísáyà orí kọkànlélógún tẹnu mọ́ ìsọ̀rí pàtàkì mìíràn nínú Bíbélì, èyí tó ń ran àwa táa jẹ́ Kristẹni lóde òní lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò nípa bí a ṣe wà lójúfò tó.
“Ìran Líle”
3. Èé ṣe tí wọ́n fi pe Bábílónì ní “aginjù òkun,” kí sì ni ohun tí wọ́n pè é yẹn ń fi hàn nípa ohun tí yóò dà lọ́jọ́ iwájú?
3 Ọ̀rọ̀ tó fi hàn pé kutupu fẹ́ hu ni Aísáyà orí kọkànlélógún fi bẹ̀rẹ̀, ó ní: “Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí aginjù òkun: Bí àwọn ẹ̀fúùfù oníjì ní gúúsù ti ń lọ síwájú, láti aginjù ni ó ti ń bọ̀, láti ilẹ̀ tí ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù.” (Aísáyà 21:1) Ńṣe ni Bábílónì tẹ́ rẹrẹ síhà méjèèjì Odò Yúfírétì, apá kan rẹ̀ tó wà níhà ìlà oòrùn jẹ́ ara ilẹ̀ tó wà láàárín odò ńlá méjì, odò Yúfírétì àti Tígírísì. Ó jìnnà díẹ̀ sí ibi tí òkun wà. Kí wá ni ìdí tí wọ́n fi pè é ní “aginjù òkun”? Nítorí pé ọdọọdún ni omi máa ń kún bo àgbègbè Bábílónì, a sì máa dá “òkun” tó jẹ́ àbàtà tó lọ salalu sílẹ̀. Àmọ́, àwọn ará Bábílónì wọ́gbọ́n dá sí aginjù tó kún fómi yìí, wọ́n la ipadò lóríṣiríṣi, wọ́n mọ ògiri sí wọn, wọ́n sì ṣe ìsédò sí wọn. Wọ́n tún dá ọgbọ́n, wọ́n lo omi wọ̀nyẹn gẹ́gẹ́ bí ara ètò ààbò ìlú. Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ìsapá kankan tí ènìyàn lè ṣe tó lè mú kí Bábílónì bọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run. Aginjù kúkú ni tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀—aginjù náà ni yóò tún dà. Àjálù ń já bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀, eruku rẹ̀ ń sọ lálá bí ọ̀kan nínú ìjì líle tó sábà máa ń rọ́ lu Ísírẹ́lì láti aginjù ẹlẹ́rù jẹ̀njẹ̀n tó wà níhà gúúsù.—Fi wé Sekaráyà 9:14.
4. Báwo ni ìran inú Ìṣípayá nípa “Bábílónì Ńlá” ṣe mú ọ̀ràn bí “omi” àti “aginjù” lọ́wọ́, kí sì ni “omi” yẹn túmọ̀ sí?
4 Gẹ́gẹ́ bí a ṣe kọ́ ọ ní Orí Kẹrìnlá ìwé yìí, Bábílónì àtijọ́ ní alábàádọ́gba lóde òní, ìyẹn ni, “Bábílónì Ńlá,” ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ìgbà tí ìwé Ìṣípayá sì máa sọ̀rọ̀ nípa Bábílónì Ńlá, àwọn ọ̀rọ̀ bí “aginjù” àti “omi” ló fi ṣàpèjúwe òun náà. Aginjù ni wọ́n gbé àpọ́sítélì Jòhánù lọ láti lọ fi Bábílónì Ńlá hàn án. Wọ́n sọ fún un pé “ó jókòó lórí omi púpọ̀,” tó dúró fún “àwọn ènìyàn àti ogunlọ́gọ̀ àti orílẹ̀-èdè àti ahọ́n.” (Ìṣípayá 17:1-3, 5, 15) Ìtìlẹyìn àwọn aráàlú ṣáà lẹ̀sìn èké ti fi ń gbéra sọ, àmọ́ o, “omi” wọ̀nyẹn kò ní gbà á sílẹ̀ nígbà tí òpin bá dé. Ńṣe ni yóò ṣófo, tí yóò di ìkọ̀tì, àti ahoro kẹ́yìn, gẹ́gẹ́ bí alábàádọ́gba rẹ̀ ayé àtijọ́.
5. Báwo ni Bábílónì ṣe wá di èyí tí wọ́n ń pè ní “olùṣe àdàkàdekè” àti “afiniṣèjẹ”?
5 Nígbà ayé Aísáyà, Bábílónì kò tíì di agbára ayé tó lékè, àmọ́, Jèhófà ti rí i pé nígbà tí àkókò rẹ̀ bá dé, yóò ṣi agbára rẹ̀ lò. Aísáyà wá ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Ìran líle kan wà tí a ti sọ fún mi: Olùṣe àdàkàdekè ń ṣe àdàkàdekè, afiniṣèjẹ sì ń fini ṣe ìjẹ.” (Aísáyà 21:2a) Ńṣe ni Bábílónì máa fi àwọn orílẹ̀-èdè tó bá ṣẹ́gun ṣe ìjẹ, yóò sì ṣe àdàkàdekè sí wọn, títí kan Júdà. Àwọn ará Bábílónì yóò kó Jerúsálẹ́mù lẹ́rù lọ, wọn yóò kó tẹ́ńpìlì ní ìkógun, wọn yóò sì di àwọn èèyàn rẹ̀ nígbèkùn lọ sí Bábílónì. Ibẹ̀ ni wọn yóò ti ṣe àdàkàdekè sí àwọn ìgbèkùn tí kò lágbára kankan wọ̀nyí, wọn yóò fi wọ́n ṣẹ̀sín lórí ìgbàgbọ́ wọn, wọn kò ní fún wọn nírètí pé wọ́n lè padà sí ìlú wọn.—2 Kíróníkà 36:17-21; Sáàmù 137:1-4.
6. (a) Ìmí ẹ̀dùn wo ni Jèhófà yóò mú kó dáwọ́ dúró? (b) Àwọn orílẹ̀-èdè wo ni àsọtẹ́lẹ̀ sọ pé yóò kọlu Bábílónì, báwo sì ni èyí ṣe ṣẹ?
6 Bẹ́ẹ̀ ni o, “ìran líle” yìí tọ́ sí Bábílónì gan-an ni, ó túmọ̀ sí pé yóò ko ìṣòro. Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Gòkè lọ, ìwọ Élámù! Sàga tì, ìwọ Mídíà! Gbogbo ìmí ẹ̀dùn nítorí rẹ̀ ni mo ti mú kí ó kásẹ̀ nílẹ̀.” (Aísáyà 21:2b) Ìtura yóò bá àwọn tí ilẹ̀ ọba tí ń ṣe àdàkàdekè yìí ti ń tẹ̀ lórí ba. Áà, ìmí ẹ̀dùn wọn wá dópin poo! (Sáàmù 79:11, 12) Ọ̀nà wo ni ìtura yìí yóò gbà dé? Aísáyà dárúkọ orílẹ̀-èdè méjì tí yóò kọlu Bábílónì, tí í ṣe: Élámù àti Mídíà. Ní ọ̀rúndún méjì lẹ́yìn náà, ìyẹn lọ́dún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa, Kírúsì ará Páṣíà yóò kó àpapọ̀ agbo ọmọ ogun àwọn ará Páṣíà àti ti Mídíà lọ gbéjà ko Bábílónì. Ní ti Élámù, àwọn ọba Páṣíà yóò gba díẹ̀, ó kéré tán, lára orílẹ̀-èdè yẹn kó tó di ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa.a Ìdí nìyẹn tí àwọn ará Élámù yóò fi wà lára agbo ọmọ ogun àwọn ará Páṣíà.
7. Ipa wo ni ìran Aísáyà ní lórí rẹ̀, ó sì dúró fún kí ni?
7 Ṣàkíyèsí ipa tí Aísáyà sọ pé ìran yìí ní lórí òun: “Ìdí nìyẹn tí ìgbáròkó mi fi kún fún ìrora mímúná. Àní ìsúnkì iṣan ti mú mi, bí ìsúnkì iṣan obìnrin tí ó fẹ́ bímọ. Mo ti di aláìbalẹ̀ ara tí n kò fi gbọ́ràn; ìyọlẹ́nu ti bá mi tí n kò fi ríran. Ọkàn-àyà mi ti rìn gbéregbère; àní ìgbọ̀njìnnìjìnnì ti kó ìpayà bá mi. Wíríwírí ọjọ́ tí ara mi fà mọ́ ni a ti sọ di ìwárìrì fún mi.” (Aísáyà 21:3, 4) Ó jọ pé wòlíì yìí fẹ́ràn wíríwírí ọjọ́, nígbà tí kì í sáriwo, tí àṣàrò máa ń dùn-ún ṣe. Àmọ́, ní báyìí, òru ò tura mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ó kún fún ìbẹ̀rù, ìrora, àti ìwárìrì. Ìsúnkì iṣan mú un, bí ìsúnkì iṣan ṣe ń mú obìnrin tí ó ń rọbí lọ́wọ́, ọkàn-àyà rẹ̀ sì “ti rìn gbéregbère.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan túmọ̀ gbólóhùn yìí sí “ọkàn-àyà mi ń lù kìkì lemọ́lemọ́,” ó ṣàlàyé pé gbólóhùn yẹn ń tọ́ka sí “ìlùkìkì ọkàn lódìlódì.” Kí ló fa irú ìdààmú yẹn? Ó jọ pé àsọtẹ́lẹ̀ ni Aísáyà fi ohun tó ṣe é yìí sọ. Irú jìnnìjìnnì yẹn ni yóò bá àwọn ará Bábílónì ní òru oṣù October, ọjọ́ karùn-ún mọ́jú ọjọ́ kẹfà, ní ọdún 539 ṣááju Sànmánì Tiwa.
8. Bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe fi hàn, kí ni àwọn ará Bábílónì ń ṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀tá wọn wà lẹ́yìn odi wọn?
8 Kò sóhun tó jẹ mọ́ jìnnìjìnnì lọ́kàn àwọn ará Bábílónì rárá bí ilẹ̀ ọjọ́ burúkú yẹn ṣe ń ṣú lọ. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún méjì ṣáájú ni Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Kí títẹ́ tábìlì, ṣíṣètò àyè ìjókòó, jíjẹ, mímu ṣẹlẹ̀!” (Aísáyà 21:5a) Bẹ́ẹ̀ ni, àsè rẹpẹtẹ ń lọ lọ́wọ́ lọ́dọ̀ Bẹliṣásárì Ọba agbéraga yẹn. Ẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn rẹ̀ jàǹkàn-jàǹkàn ló ṣètò àyè ìjókòó fún, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ aya àti wáhàrì rẹ̀. (Dáníẹ́lì 5:1, 2) Àwọn tó ń ṣàríyá aláriwo yìí sì mọ̀ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan ń bẹ lẹ́yìn odi àwọn o, ṣùgbọ́n, wọ́n gbà gbọ́ pé mìmì kan ò lè mi ìlú àwọn. Àwọn odi rẹ̀ kìǹbà kìǹbà àtàwọn òjìngbùn-jingbùn yàrà rẹ̀ dà bí èyí tí kò lè jẹ́ kí wọ́n ṣẹ́gun ìlú yẹn láéláé; kò tiẹ̀ ṣeé ronú kàn ni lójú àwọn òrìṣà rẹpẹtẹ tó wà níbẹ̀. Nítorí náà, kí “jíjẹ, mímu” máa lọ ní rabidun o jàre! Ni Bẹliṣásárì bá mutí yó, kò sì lè jẹ́ pé òun nìkan ló ti yó. Láti mọ bí àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga wọ̀nyẹn ṣe yó bìnàkò tó, ńṣe ni wọ́n ní láti máa ta wọ́n jí bí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ tẹ̀ lé e ṣe fi hàn.
9. Kí ló mú kó di dandan fún wọ́n láti “fòróró yan apata”?
9 Ó ní: “Ẹ dìde, ẹ̀yin ọmọ aládé, ẹ fòróró yan apata.” (Aísáyà 21:5b) Àsè yẹn dópin lójijì. Ńṣe làwọn ọmọ aládé ní láti gbọnra nù! Wọ́n ti pe wòlíì Dáníẹ́lì arúgbó wá síbẹ̀, ó sì rí bí Jèhófà ṣe da jìnnìjìnnì bo Bẹliṣásárì ọba Bábílónì lọ́nà tó jọ èyí tí Aísáyà ṣàpèjúwe rẹ̀. Ṣìbáṣìbo bá àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn ọba bí àpapọ̀ agbo ọmọ ogun àwọn ará Mídíà, Páṣíà àtàwọn ará Élámù ṣe fọ́ ètò ààbò ìlú yẹn. Kíá Bábílónì ti ṣubú! Ṣùgbọ́n, kí ni ìtumọ̀ “fòróró yan apata”? Nígbà mìíràn, Bíbélì máa ń pe ọba orílẹ̀-èdè kan ní apata orílẹ̀-èdè yẹn nítorí pé òun ló ń gbà á sílẹ̀ tó sì ń dáàbò bò ó.b (Sáàmù 89:18) Nítorí náà, ó jọ pé ẹsẹ Aísáyà yìí ń sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa nílò ọba tuntun. Èé ṣe? Nítorí pé “òru ọjọ́ yẹn gan-an” ni wọ́n pa Bẹliṣásárì. Nípa bẹ́ẹ̀, ó di dandan pé kí wọ́n “fòróró yan apata,” tàbí kí wọ́n yan ọba tuntun.—Dáníẹ́lì 5:1-9, 30.
10. Ìtùnú wo làwọn olùjọsìn Jèhófà lè rí látinú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa aládàkàdekè yẹn?
10 Gbogbo àwọn olùfẹ́ ìjọsìn tòótọ́ ni àkọsílẹ̀ yìí ń tù nínú. Bábílónì òde òní, ìyẹn Bábílónì Ńlá, jẹ́ aládàkàdekè àti afiniṣèjẹ gẹ́lẹ́ bí alábàádọ́gba rẹ̀ ayé àtijọ́ ṣe jẹ́. Di òní olónìí làwọn aṣáájú ìsìn ń dìtẹ̀ láti rí i pé wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé wọ́n ṣe inúnibíni sí wọn, tàbí kí wọ́n bu owó orí ńlá lé wọn gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìfìyàjẹni. Ṣùgbọ́n bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe rán wa létí, Jèhófà rí gbogbo àdàkàdekè wọ̀nyẹn, kò sì ní ṣàì gbẹ̀san wọn. Yóò run gbogbo ẹ̀sìn tó bá ń sọ ohun tó lòdì nípa rẹ̀, tó sì ń ṣàìdáa sí àwọn èèyàn rẹ̀. (Ìṣípayá 18:8) Ǹjẹ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè wáyé lóòótọ́? Ẹ jẹ́ ká wo bí àwọn ìkìlọ̀ nípa ìṣubú Bábílónì àtijọ́ àti ti alábàádọ́gba rẹ̀ òde òní ṣe nímùúṣẹ, ìyẹn gan-an ni ìgbàgbọ́ wa yóò fi lágbára sí i.
“Ó Ti Ṣubú!”
11. (a) Kí ni iṣẹ́ olùṣọ́, ta ló sì ti ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́ lóde òní? (b) Kí ni kẹ̀kẹ́ ogun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ti ràkúnmí dúró fún?
11 Jèhófà wá bá wòlíì náà sọ̀rọ̀. Aísáyà ròyìn pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: ‘Lọ, yan alóre sẹ́nu iṣẹ́, kí ó lè sọ ohun tí òun ń rí.’” (Aísáyà 21:6) Ọ̀rọ̀ yìí nasẹ̀ ìsọ̀rí pàtàkì mìíràn nínú orí yìí, ìyẹn ni, alóre, tàbí olùṣọ́. Èyí ṣe pàtàkì fún gbogbo Kristẹni tòótọ́ lónìí, nítorí Jésù rọ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” kò dákẹ́ rí láìsọ ohun tó ń rí nípa bí ọjọ́ ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe sún mọ́lé tó àti ewu inú ayé tó díbàjẹ́ yìí. (Mátíù 24:42, 45-47) Kí ni olùṣọ́ inú ìran Aísáyà wá rí o? “Ó . . . rí kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun tí ó ní àdìpọ̀ méjì-méjì ẹṣin ogun, kẹ̀kẹ́ ogun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kẹ̀kẹ́ ogun ràkúnmí. Ó sì fiyè sílẹ̀ gidigidi, pẹ̀lú ìfiyèsílẹ̀ púpọ̀.” (Aísáyà 21:7) Ó ṣeé ṣe kí kẹ̀kẹ́ ogun alápapọ̀ yìí dúró fún ọ̀wọ́ àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tó ń sáré bọ̀ lọ́nà ìtẹ́gun, tí eré ẹsẹ̀ wọn sì jọ tàwọn ẹṣin ogun tí kò kẹ̀rẹ̀. Wẹ́kú làwọn kẹ̀kẹ́ ogun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ti ràkúnmí bá agbára ayé méjèèjì náà mu, ìyẹn Mídíà àti Páṣíà, tí yóò pawọ́ pọ̀ gbé ogun yìí wá. Síwájú sí i, ìtàn jẹ́rìí sí i pé àwọn ará Páṣíà a máa lo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí fún ogun jíjà.
12. Àwọn ànímọ́ wo ni olùṣọ́ inú ìran Aísáyà fi hàn, àwọn wo ló sì nílò ànímọ́ wọ̀nyí lónìí?
12 Ó wá di dandan kí olùṣọ́ náà ròyìn ohun tó rí. “Ó . . . bẹ̀rẹ̀ sí ké bí kìnnìún pé: ‘Jèhófà, orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, ibi ìṣọ́ mi sì ni mo dúró sí ní gbogbo òru. Kíyè sí i, kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun ti àwọn ọkùnrin rèé tí ń bọ̀, pẹ̀lú àdìpọ̀ méjì-méjì ẹṣin ogun!’” (Aísáyà 21:8, 9a) Olùṣọ́ yìí fi ìgboyà ké “bí kìnnìún.” Ó gba ìgboyà láti kéde iṣẹ́ ìdájọ́ sórí àkòtagìrì orílẹ̀-èdè bíi Bábílónì. Ó tún gba nǹkan mìíràn pẹ̀lú, ìyẹn ni, ìfaradà. Olùṣọ́ yìí kò kúrò níbi ìṣọ́ rẹ̀ tọ̀sán tòru, kò sọra nù rárá. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ní ìkẹyìn ọjọ́ yìí, ìgboyà àti ìfaradà ni ẹgbẹ́ olùṣọ́ yìí nílò. (Ìṣípayá 14:12) Gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló nílò ànímọ́ wọ̀nyí.
13, 14. (a) Ibo ni ọ̀rọ̀ Bábílónì àtijọ́ já sí, ọ̀nà wo sì ni àwọn òrìṣà rẹ̀ gbà wó mọ́lẹ̀? (b) Báwo ni Bábílónì Ńlá ṣe ṣubú lọ́nà kan náà, ìgbà wo sì ni?
13 Olùṣọ́ inú ìran Aísáyà rí i pé kẹ̀kẹ́ ogun kan ń bọ̀. Ìròyìn wo ló mú wá? “Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sókè, ó sì wí pé: ‘Ó ti ṣubú! Bábílónì ti ṣubú, gbogbo ère fífín ti àwọn ọlọ́run rẹ̀ ni òun ti wó mọ́lẹ̀!’” (Aísáyà 21:9b) Ìròyìn yìí mà mórí yá gágá o! Áà, nígbẹ̀yìngbẹ́yín, aládàkàdekè tó ń fi àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣèjẹ ti ṣubú!c Àmọ́, ọ̀nà wo ni àwọn ère fífín àti òrìṣà Bábílónì gbà wó mọ́lẹ̀? Ṣé àwọn ará Mídíà àti Páṣíà tó ṣígun wá máa ya wọ àwọn tẹ́ńpìlì Bábílónì, tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye òrìṣà wọ̀nyẹn ni? Rárá o, kò béèrè ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá. Àwọn òrìṣà Bábílónì máa wó mọ́lẹ̀ ní ti pé, àṣírí wọn máa wá tú pé wọn kò lágbára kankan láti dáàbò bo ìlú yẹn. Bábílónì yóò sì ṣubú tó bá ti di pé kò tún lè máa bá a lọ láti tẹ àwọn ènìyàn Ọlọ́run lórí ba mọ́.
14 Bábílónì Ńlá wá ńkọ́? Nítorí pé òun ló wà nídìí títẹ̀ tí wọ́n tẹ àwọn èèyàn Ọlọ́run lórí ba nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ó rí wọn kó nígbèkùn fún àkókò kan. Iṣẹ́ ìwàásù wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ dáwọ́ dúró. Wọ́n gbé ààrẹ Watch Tower Society àtàwọn ògúnnágbòǹgbò yòókù jù sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn èké. Àmọ́, lọ́dún 1919, àyípadà tó bùáyà ṣẹlẹ̀. Wọ́n tú àwọn òléwájú wọ̀nyí sílẹ̀, wọ́n tún ṣí orílé iṣẹ́ padà, iṣẹ́ ìwàásù sì tún bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu. Bí Bábílónì Ńlá ṣe ṣubú nìyẹn, ìyẹn ni pé agbára tó ní lórí àwọn èèyàn Ọlọ́run dópin.d Nínú ìwé Ìṣípayá, ẹ̀ẹ̀mejì ni áńgẹ́lì kan kéde ìṣubú yìí, tó ń lo ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 21:9.— Ìṣípayá 14:8; 18:2.
15, 16. Ọ̀nà wo ni àwọn èèyàn Aísáyà gbà jẹ́ àwọn “tí a pa bí ọkà,” ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ látinú ìwà tí Aísáyà hù sí wọn?
15 Ọ̀rọ̀ àánú ni Aísáyà ń sọ sí àwọn èèyàn rẹ̀ níparí iṣẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yìí. Ó ní: “Ẹ̀yin ènìyàn mi tí a ti pa bí ọkà àti ọmọ ilẹ̀ ìpakà mi, ohun tí mo gbọ́ láti ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni mo ti ròyìn fún yín.” (Aísáyà 21:10) Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń fi ìpakà ṣàpẹẹrẹ ìbáwí àti ìyọ́mọ́ àwọn èèyàn Ọlọ́run. Ńṣe ni àwọn èèyàn tí Ọlọ́run bá dá májẹ̀mú yóò di “ọmọ ilẹ̀ ìpakà,” níbi tí wọ́n ti máa ń fi ọ̀pá lu àlìkámà já kúrò nínú ìyàngbò, tí yóò fi wá ku hóró ọkà tó mọ́ tí à ń fẹ́. Aísáyà kò yọ̀ wọ́n lórí ìbáwí yìí o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni àánú àwọn “ọmọ ilẹ̀ ìpakà” yìí ń ṣe é, àwọn tó jẹ́ pé òmíràn lára wọn yóò lo gbogbo ìgbésí ayé wọn nígbèkùn ilẹ̀ òkèèrè.
16 Èyí lè jẹ́ ìránnilétí tó wúlò gan-an fún gbogbo wa. Nínú ìjọ Kristẹni òde òní, àwọn kan lè fẹ́ máa kanra mọ́ àwọn tó bá ṣaṣemáṣe. Àwọn táa ń bá wí sì lè fẹ́ kọ ìbáwí. Ṣùgbọ́n táa bá fi sọ́kàn pé bí Jèhófà ṣe ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ wí, ṣe ló fi ń yọ́ wọn mọ́, a kò ní fojú tín-ínrín ìbáwí àtàwọn tó bá fìrẹ̀lẹ̀ gbà á, bẹ́ẹ̀ ni a ò sì ní kọ̀ ọ́ nígbà tó bá tọ́ sí wa. Ẹ jẹ́ ká tẹ́wọ́ gba ìbáwí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ hàn.—Hébérù 12:6.
Ṣíṣèwádìí Lọ́wọ́ Olùṣọ́
17. Èé ṣe tó fi bá a mu wẹ́kú pé wọ́n pe Édómù ní “Dúmà”?
17 Ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ kejì tí Aísáyà sọ ní orí kọkànlélógún gbé olùṣọ́ yẹn jáde sójú táyé. Ó bẹ̀rẹ̀ báyìí: “Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí Dúmà: Ẹnì kan ń ké jáde sí mi láti Séírì wá pé: ‘Olùṣọ́, òru ti rí? Olùṣọ́, òru ti rí?’” (Aísáyà 21:11) Ibo ni Dúmà yìí wà? Ó dájú pé ọ̀pọ̀ ìlú ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ ibí yìí kò tọ́ka sí èyíkéyìí lára wọn. Kò sí Dúmà ní Séírì, ìyẹn orúkọ mìíràn tí wọ́n ń pe Édómù. Àmọ́, “Dúmà” túmọ̀ sí “Ìdákẹ́jẹ́ẹ́.” Nítorí náà, ó jọ pé ńṣe ni wọ́n fún àgbègbè yẹn lórúkọ tó ń sọ ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí i lọ́jọ́ iwájú, gẹ́lẹ́ bí ìkéde tó ṣáájú èyí ṣe rí. Ńṣe ni Édómù, ọ̀tá tó ń wá ọ̀nà tipẹ́tipẹ́ láti gbẹ̀san lára àwọn èèyàn Ọlọ́run, yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́ níkẹyìn, ìyẹn ìdákẹ́rọ́rọ́ nínú ikú. Àmọ́ kí ìyẹn tó wáyé, àwọn kan yóò fi àìbalẹ̀ ọkàn máa béèrè nípa ọjọ́ iwájú.
18. Báwo ni ìkéde náà, “Òwúrọ̀ ní láti dé, àti òru pẹ̀lú,” ṣe ṣẹ sí Édómù àtijọ́ lára?
18 Lákòókò tí kíkọ àkọsílẹ̀ Aísáyà ń lọ lọ́wọ́, Édómù wà lára àwọn ibi tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ásíríà alágbára máa gbà kọjá. Àwọn kan ní Édómù wá ń hára gàgà láti mọ ìgbà tí òru ìtẹ̀lóríba yẹn máa dópin fún wọn. Èsì wo ni wọ́n rí gbà? “Olùṣọ́ wí pé: ‘Òwúrọ̀ ní láti dé, àti òru pẹ̀lú.’” (Aísáyà 21:12a) Nǹkan ò ní ṣẹnuure fún Édómù. Ó máa hàn láwọsánmà pé ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, ṣùgbọ́n kò ní pẹ́ pòórá. Kíá ni òru, ìyẹn, àkókò ìtẹ̀lóríba mìíràn, yóò ti tẹ̀ lé òwúrọ̀ yẹn. Àpèjúwe yìí mà bá ọjọ́ ọ̀la Édómù mu wẹ́kú o! Lóòótọ́, ìtẹ̀lóríba àwọn ará Ásíríà yóò dópin, ṣùgbọ́n Bábílónì yóò rọ́pò Ásíríà gẹ́gẹ́ bí agbára ayé, yóò sì pa apá tó pọ̀ jù run ní Édómù. (Jeremáyà 25:17, 21; 27:2-8) Irú ìtẹ̀lóríba bẹ́ẹ̀ yóò sì tún padà wá ṣẹlẹ̀. Lẹ́yìn ìtẹ̀lóríba látọwọ́ Bábílónì, Páṣíà yóò tẹ̀ ẹ́ lórí ba, tí ìtẹ̀lóríba látọwọ́ Gíríìkì yóò sì tẹ̀ lé e. Lẹ́yìn náà, “òwúrọ̀” ráńpẹ́ yóò wà nígbà tàwọn Róòmù, nígbà tí ọ̀pá àṣẹ yóò tẹ àwọn Hẹ́rọ́dù—tí wọ́n ṣẹ̀ wá láti ilẹ̀ Édómù—lọ́wọ́ ní Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n, “òwúrọ̀” yẹn kò ní pẹ́ lọ títí. Níkẹyìn, Édómù yóò di ibi dídákẹ́ rọ́rọ́ títí gbére, wọn ò ní gbúròó rẹ̀ mọ́ láé. Orúkọ náà, Dúmà, yóò rò ó nígbẹ̀yìngbẹ́yín.
19. Nígbà tí olùṣọ́ yẹn sọ pé, “Bí ẹ bá fẹ́ wádìí, ẹ wádìí. Ẹ tún padà wá!” kí ló ṣeé ṣe kó ní lọ́kàn?
19 Olùṣọ́ yẹn fi ìsọfúnni ráńpẹ́ yìí kásẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ nílẹ̀, ó ní: “Bí ẹ bá fẹ́ wádìí, ẹ wádìí. Ẹ tún padà wá!” (Aísáyà 21:12b) Ó ṣeé ṣe kí gbólóhùn náà, “Ẹ tún padà wá!” tọ́ka sí “òru” léraléra láìlópin tí ń bẹ níwájú fún Édómù. Tàbí, nítorí pé a tún lè túmọ̀ gbólóhùn náà sí “padà,” ó ṣeé ṣe kí wòlíì yẹn máa dábàá pé kí èyíkéyìí lára àwọn ará Édómù tó bá fẹ́ bọ́ lọ́wọ́ àgbákò orílẹ̀-èdè yẹn ronú pìwà dà, kó sì “padà” sọ́dọ̀ Jèhófà. Èyí tó wù kó jẹ́, ńṣe ni olùṣọ́ yẹn ń sọ fún wọn pé kí wọ́n túbọ̀ ṣèwádìí sí i.
20. Èé ṣe tí ìkéde tó wà nínú Aísáyà 21:11, 12 fi ṣe pàtàkì fáwọn èèyàn Jèhófà lónìí?
20 Ìkéde kúkúrú yìí ṣe pàtàkì gidigidi fáwọn èèyàn Jèhófà lóde òní.e Ó yé wa pé aráyé ti wà ní ààjìn òru ti ìfọ́jú nípa tẹ̀mí àti ti sísọ ara ẹni dọ̀tá Ọlọ́run, tí yóò yọrí sí ìparun ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí. (Róòmù 13:12; 2 Kọ́ríńtì 4:4) Ní àkókò òru yìí, ìrètí yòówù tó bá yọ fìrí, bí ẹni pé aráyé lè mú àlàáfíà àti ààbò wá, kò yàtọ̀ sí wíríwírí ìmọ́lẹ̀ wọ̀nyẹn tó jẹ́ káwọn èèyàn máa rò pé ojúmọ́ ń mọ́ bọ̀, àmọ́ tí àkókò tó túbọ̀ ṣókùnkùn wá tẹ̀ lé e. Àfẹ̀mọ́jú tòótọ́ kù sí dẹ̀dẹ̀, ìyẹn àfẹ̀mọ́jú ti Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún ti Kristi lórí ayé yìí. Àmọ́, níwọ̀n bí òru yìí bá ti wà, a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìdarí ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà nípa wíwà lójúfò nípa tẹ̀mí, kí a sì fi ìgboyà máa kéde sísún tí òpin ètò nǹkan tó díbàjẹ́ yìí sún mọ́lé.—1 Tẹsalóníkà 5:6.
Ilẹ̀ Ṣú Ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Aṣálẹ̀
21. (a) Kí ló ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi dárà nínú gbólóhùn náà, “ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀” túmọ̀ sí? (b) Kí ni ọ̀wọ́ èrò Dédánì?
21 Ìkéde tó kẹ́yìn nínú Aísáyà orí kọkànlélógún wá sórí “pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.” Ó bẹ̀rẹ̀ báyìí: “Ọ̀rọ̀ ìkéde lòdì sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀: Inú igbó ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ ni ẹ ó sùn mọ́jú, ẹ̀yin ọ̀wọ́ èrò Dédánì.” (Aísáyà 21:13) Ó dájú pé Arébíà ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ tó ń tọ́ka sí, nítorí pé ọ̀pọ̀ ẹ̀yà Árábù ló darí ìkéde yìí sí. Nígbà mìíràn, “alẹ́” ni wọ́n máa ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ táa túmọ̀ sí “pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀” sí, ọ̀rọ̀ méjèèjì sì jọra gan-an lédè Hébérù. Èrò tàwọn kan ni pé ńṣe ni wọ́n fi ọ̀rọ̀ dárà níhìn-ín, bí ẹni pé alẹ́, ìyẹn àkókò ìjàngbọ̀n, ń lẹ́ bọ̀ lórí àgbègbè yẹn. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lálẹ́ ni ìkéde yìí sì fi bẹ̀rẹ̀, ó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀wọ́ èrò Dédánì, tó jẹ́ ẹ̀yà pàtàkì lára ẹ̀yà Árábù. Irú ọ̀wọ́ èrò bẹ́ẹ̀ a máa gba ọ̀nà àwọn oníṣòwò tó lọ láti ibi ìsun omi inú aṣálẹ̀ kan sí òmíràn, wọ́n á sì ru nǹkan amóúnjẹ-tasánsán, péálì, àti àwọn ìṣúra mìíràn. Àmọ́, ní báyìí, a rí i pé ó di dandan pé kí wọ́n yà kúrò lójú ọ̀nà tí wọ́n mọ̀ dunjú, láti lọ forí pa mọ́ síbì kan mọ́jú. Èé ṣe?
22, 23. (a) Dùgbẹ̀dùgbẹ̀ wo ló fẹ́ já lu àwọn ẹ̀yà Árábù, ipa wo ni yóò sì ní lórí wọn? (b) Báwo ló ṣe máa pẹ́ tó kí àgbákò yìí tó dé, láti ọwọ́ ta sì ni?
22 Aísáyà ṣàlàyé pé: “Ẹ gbé omi wá pàdé ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ. Ẹ̀yin olùgbé ilẹ̀ Témà, ẹ fi oúnjẹ tí ẹni tí ń sá lọ yóò jẹ pàdé rẹ̀. Nítorí pé idà ni ó mú kí wọ́n sá lọ, nítorí idà tí a fà yọ, àti nítorí ọrun tí a fà àti nítorí kíkira ogun náà.” (Aísáyà 21:14, 15) Bẹ́ẹ̀ ni o, dùgbẹ̀dùgbẹ̀ ogun yóò já lu àwọn ẹ̀yà Árábù wọ̀nyí. Ó di dandan pé kí Témà, tó wà níbi ọ̀kan lára ìsun tó lómi jù lọ nínú aṣálẹ̀ tó wà lágbègbè náà, gbé omi àti oúnjẹ pàdé àwọn tí ogun ń lé sá kìjokìjo náà. Ìgbà wo làgbákò yìí yóò bá wọn?
23 Aísáyà ń bọ́rọ̀ lọ pé: “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà wí fún mi: ‘Láàárín ọdún kan sí i, ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọdún lébìrà tí a háyà, àní gbogbo ògo Kídárì yóò wá sí òpin rẹ̀. Àwọn tí ó sì ṣẹ́ kù lára iye àwọn tí ń lo ọrun, àwọn ọkùnrin alágbára ńlá nínú àwọn ọmọ Kídárì, yóò di èyí tí ó kéré níye, nítorí pé Jèhófà tìkára rẹ̀, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni ó sọ ọ́.’” (Aísáyà 21:16, 17) Kídárì gbajúmọ̀ gan-an dépò tí wọ́n fi ń lò ó láti dúró fún gbogbo Arébíà nígbà mìíràn. Jèhófà pinnu pé àwọn tí ń lo ọrun àti àwọn ọkùnrin alágbára nínú ẹ̀yà yìí yóò dín kù, ìwọ̀nba táṣẹ́rẹ́ ni yóò kù. Nígbà wo? “Láàárín ọdún kan sí i” ni, kò ní jù bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí lébìrà tí a háyà kò ṣe ní jẹ́ kí àkókò tóun yóò fi ṣiṣẹ́ lé sí iye owó tí wọ́n máa san fún òun. Bí gbogbo èyí ṣe ṣẹ ní pàtó kò dáni lójú. Ọba Ásíríà méjì, ìyẹn Ságónì Kejì àti Senakéríbù, sọ pé àwọn ló tẹ Arébíà lórí ba. Ó lè jẹ́ èyíkéyìí lára wọn ló pa àwọn agbéraga ẹ̀yà Árábù wọ̀nyí ku kéréje bí àsọtẹ́lẹ̀ ṣe sọ.
24. Báwo ló ṣe dá wa lójú pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Aísáyà sọ lórí Arébíà ṣẹ?
24 Àmọ́, ó dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ pátápátá. Kò sóhun tó lè jẹ́ kí kókó yẹn túbọ̀ dáni lójú tó ọ̀rọ̀ tó parí ìkéde yẹn pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ni ó sọ ọ́.” Lójú àwọn èèyàn ìgbà ayé Aísáyà, ó lè dà bí ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ pé Bábílónì yóò borí Ásíríà kí á má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti pé wọn yóò gbàjọba Bábílónì ní alẹ́ ọjọ́ kan ṣoṣo, nígbà àríyá oníwọ̀bìà. Ó tún lè jọ ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀ pé Édómù alágbára yóò dákẹ́ rọ́rọ́ nínú ikú, tàbí pé òru ìnira àti ti àìní yóò dé bá àwọn ẹ̀yà Árábù ọlọ́rọ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ pé yóò wáyé, bó sì ṣe ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Lónìí, Jèhófà sọ fún wa pé ètò ìsìn èké àgbáyé yóò dasán. Ohun tó dájú pé ó máa ṣẹlẹ̀ ni; àní-àní kankan ò sí ńbẹ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sọ ọ́!
25. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ olùṣọ́ yẹn?
25 Nígbà náà, ẹ jẹ́ ká dà bí olùṣọ́ yẹn. Ẹ jẹ́ kí á wà lójúfò, bíi pé ṣe ni wọ́n yàn wá sórí ilé ìṣọ́ gíga fíofío, tí a ń ṣọ́ àmì ewu èyíkéyìí tó lè yọ láti ọ̀kánkán. Ẹ jẹ́ kí á fara mọ́ olóòótọ́ ẹgbẹ́ olùṣọ́ náà tímọ́tímọ́, ìyẹn àṣẹ́kù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà lórí ilẹ̀ ayé lónìí. Kí á fi ìgboyà dara pọ̀ mọ́ wọn nínú kíkéde ohun tí a rí gẹ́lẹ́, ìyẹn ni, ẹ̀rí púpọ̀ jáǹrẹrẹ tó fi hàn pé Kristi ń ṣàkóso ní ọ̀run; pé láìpẹ́, yóò mú òru aráyé tó gùn, tó sì ṣókùnkùn, ìyẹn sísọ táráyé sọ ara wọn dọ̀tá Ọlọ́run, wá sópin; àti pé lẹ́yìn ìyẹn, yóò mú àfẹ̀mọ́jú tòótọ́ wá, tí í ṣe Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún lórí párádísè ilẹ̀ ayé!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nígbà mìíràn, wọ́n máa ń pe Kírúsì ọba Páṣíà ní “Ọba Áńṣánì,” àgbègbè tàbí ìlú kan ní Élámù sì ni Áńṣánì yìí. Nígbà ayé Aísáyà—ọ̀rúndún kẹjọ ṣááju Sànmánì Tiwa—ó ṣeé ṣe kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì má mọ̀ nípa Páṣíà, àmọ́ ṣá, wọ́n á mọ Élámù. Ìyẹn lè jẹ́ ìdí tí Aísáyà fi dárúkọ Élámù níhìn-ín dípò Páṣíà.
b Ọ̀pọ̀ àwọn alálàyé Bíbélì rò pé ọ̀rọ̀ náà, “fòróró yan apata,” ń tọ́ka sí ìṣe àwọn ológun ayé àtijọ́, tí wọ́n máa ń fi epo pa apata aláwọ ṣáájú ìjà, kí gbogbo ohun tó bá bà á lè máa yọ́ bọ́rọ́. Lóòótọ́, èyí lè jẹ́ ọ̀nà ìtumọ̀ kan, ṣùgbọ́n, ká ṣàkíyèsí pé, lóru ọjọ́ tí ìlú yẹn ṣubú, agbára káká làwọn ará Bábílónì fi ráyè jà, áńbọ̀sìbọ́sí pé wọ́n á ráyè fi epo pa apata wọn ṣáájú ìjà!
c Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà nípa ìṣubú Bábílónì ṣẹ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn kan tó ń ṣe lámèyítọ́ Bíbélì fi gbé èrò kan jáde pé ó ní láti jẹ́ pé ẹ̀yìn tó ṣẹlẹ̀ ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ọ́. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí F. Delitzsch, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú èdè Hébérù ṣe sọ, kò sídìí fún irú ìméfò yẹn báa bá gbà pé wọ́n lè mí sí wòlíì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún ṣáájú ìmúṣẹ wọn.
e Nínú ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́ta àkọ́kọ́ tí wọ́n fi ń tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́, Aísáyà 21:11 máa ń wà lára èèpo ẹ̀yìn rẹ̀. Inú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan náà ni àkòrí ìwàásù ìkẹyìn tí Charles T. Russell, ààrẹ àkọ́kọ́ fún Watch Tower Society kọ, ti wá. (Wo àwòrán tó wà lójú ewé tó ṣáájú èyí.)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 219]
“Kí . . . jíjẹ, mímu ṣẹlẹ̀!”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 220]
Olùṣọ́ “bẹ̀rẹ̀ sí ké bí kìnnìún”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 222]
‘Orí ilé ìṣọ́ ni mo dúró sí nígbà gbogbo ní ọ̀sán, àti . . . ní gbogbo òru’