-
Awọn Ọmutipara Nipa Tẹmi—Ta ni Wọn Íṣe?Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | June 1
-
-
20, 21. Ki ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa npokiki laidabọ, ṣugbọn ki ni awọn aṣaaju Kristẹndọm kọ̀ lati ṣe?
20 Asọtẹlẹ naa sọ nipa iru awọn ẹni bẹẹ pe: ‘Si ẹni ti oun wipe, eyi ni isinmi, ẹyin iba mu awọn alaaarẹ sinmi, eyi sì ni itura: sibẹ wọn ki yoo gbọ́. Nitori ọrọ Jehofa jẹ àṣẹ le àṣẹ, àṣẹ le àṣẹ fun wọn: okun iwọn lé okun iwọn, okun iwọn lé okun iwọn; diẹ nihin-in diẹ lọhun-un: ki wọn baa le lọ, ki wọn sì ṣubu sẹhin, ki wọn sì ṣẹ́, ki a sì dẹ wọn, ki a sì mu wọn.’—Aisaya 28:12, 13.
-
-
Awọn Ọmutipara Nipa Tẹmi—Ta ni Wọn Íṣe?Ilé-Ìṣọ́nà—1991 | June 1
-
-
22. Ki ni Jehofa fi si afiyesi awọn aṣaaju Kristẹndọm?
22 Fun idi yii, awọn ọrọ alasọtẹlẹ Aisaya fi tó awujọ alufaa leti pe Jehofa ki yoo maa fi igbagbogbo sọrọ nipasẹ awọn Ẹlẹrii Rẹ̀ alaile panilara. Laipẹ, Jehofa yoo jẹ ki “àṣẹ le àṣẹ, okun iwọn lé okun iwọn” wa si imuṣẹ, iyọrisi naa yoo sì jẹ àjálù ibi fun Kristẹndọm. Awọn aṣaaju isin rẹ̀ ati awọn agbo rẹ̀ ni a o “ṣẹ́, ki a sì dẹ wọn, ki a sì mu wọn.” Bẹẹni, bii Jerusalẹmu atijọ, awọn eto isin Kristẹndọm ni a o parun raurau. Ẹ wo idagbasoke amunigbọnriri ti a kò reti ti iyẹn yoo jẹ! Ẹ sì wo abajade abanilẹru ti o jẹ fun awujọ alufaa ti wọn yàn imutipara tẹmi si awọn irannileti Jehofa!
-