Orí Kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n
Ọba àti Àwọn Ọmọ Aládé Rẹ̀
1, 2. Kí la lè sọ nípa ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà tó wà lára Àkájọ Ìwé Òkun Òkú?
NÍ APÁ ìparí àwọn ọdún 1940, àwọn kan rí àkójọ àwọn ìwé kíká tó kàmàmà nínú àwọn ihò inú àpáta tó wà lẹ́bàá Òkun Òkú ní ilẹ̀ Palẹ́sìnì. Àwọn ìwé kíká yẹn ni wọ́n wá ń pè ní Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, wọ́n sì gbá gbọ́ pé àárín nǹkan bí ọdún 200 ṣááju Sànmánì Tiwa sí ọdún 70 Sànmánì Tiwa ni wọ́n kọ ọ́. Èyí tó gbajúmọ̀ jù lára wọn ni àkájọ ìwé Aísáyà, èyí tí wọ́n fi èdè Hébérù kọ sára awọ, tí kò lè tètè bàjẹ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí èyí tó dín lára àkájọ yẹn, díẹ̀ ṣíún lọ̀rọ̀ rẹ̀ sì fi yàtọ̀ sí èyí tó wà nínú ìwé àdàkọ tí àwọn Másórétì kọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún sí ìgbà tí wọ́n ṣe àkájọ ìwé yẹn. Nípa báyìí, àkájọ ìwé yìí jẹ́ kó hàn pé ọ̀nà tó péye ni wọ́n gbà ń ṣe àdàkọ ọ̀rọ̀ Bíbélì látẹ̀yìnwá.
2 Lára àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ pàtàkì tó jẹ mọ́ ìwé Aísáyà tó wà lára Àkájọ Ìwé Òkun Òkú ni pé, akọ̀wé kan fa ìlà méjì tó kọjá lórí ara wọn báyìí “X” sí etí ẹ̀ka tí a mọ̀ sí Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n lóde òní. A ò mọ ìdí tí akọ̀wé yìí fi ṣe irú àmì bẹ́ẹ̀ sí i, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé lọ́nà kan ṣá ẹ̀ka yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú Bíbélì Mímọ́.
Ṣíṣàkóso Nínú Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
3. Iṣẹ́ àbójútó wo ni ìwé Aísáyà àti Ìṣípayá sọ tẹ́lẹ̀?
3 Àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wúni lórí, tó ń ṣẹ nígbà tiwa, ló bẹ̀rẹ̀ orí kejìlélọ́gbọ̀n ìwé Aísáyà, ìyẹn ni: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo; àti ní ti àwọn ọmọ aládé, wọn yóò ṣàkóso bí ọmọ aládé fún ìdájọ́ òdodo.” (Aísáyà 32:1) Bẹ́ẹ̀ ni, “Wò ó!” Ọ̀rọ̀ ìyanu yìí múni rántí irú ọ̀rọ̀ kan náà tó wà nínú ìwé àsọtẹ́lẹ̀ tó kẹ́yìn nínú Bíbélì, ó ní: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ sì wí pé: ‘Wò ó! Mo ń sọ ohun gbogbo di tuntun.’” (Ìṣípayá 21:5) Àti ìwé Aísáyà àti ìwé Ìṣípayá, tó jẹ́ pé wọ́n kọ ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún síra wọn, ló ṣe àkàwé tó pinminrin nípa iṣẹ́ àbójútó tuntun kan, ìyẹn “ọ̀run tuntun kan,” àwọn tó sì para pọ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni Kristi Jésù, Ọba tó gorí ìtẹ́ ní ọ̀run lọ́dún 1914, àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tí wọ́n jùmọ̀ ń ṣàkóso, tí a “rà lára aráyé,” wọ́n sì tún ṣe àkàwé nípa “ayé tuntun kan,” ìyẹn àwùjọ kárí ayé tó wà níṣọ̀kan.a (Ìṣípayá 14:1-4; 21:1-4; Aísáyà 65:17-25) Ẹbọ ìràpadà Kristi ló sì mú kí gbogbo ìṣètò yìí ṣeé ṣe.
4. Ìpìlẹ̀ ayé tuntun wo ló ti wà nísinsìnyí?
4 Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù ti rí ìran nípa bí wọ́n ṣe fi èdìdì di ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì náà níkẹyìn, ìyẹn àwọn tí yóò bá Jésù ṣàkóso, ó wá ròyìn pé: “Mo rí, sì wò ó! ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ àti níwájú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà.” Àwọn wọ̀nyí ni ìpìlẹ̀ ayé tuntun, ìyẹn ogunlọ́gọ̀ ńlá tí iye wọn ti wọ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ báyìí, tó ti kó jọ pọ̀ síhà ọ̀dọ̀ àṣẹ́kù kéréje ti ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọ́n ti darúgbó. Ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí yóò la ìpọ́njú ńlá tí ń bọ̀ kánkán náà já, wọn yóò sì máa gbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé níbi tí àwọn tí yóò jíǹde yóò ti dara pọ̀ mọ́ wọn, ìyẹn àwọn olóòótọ́ àti ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù mìíràn ti wọ́n máa fún láǹfààní láti fi ìgbàgbọ́ wọn hàn. Gbogbo àwọn tó bá sì fi ìgbàgbọ́ hàn yóò gba ìbùkún ìyè ayérayé.—Ìṣípayá 7:4, 9-17.
5-7. Ipa wo ni “àwọn ọmọ aládé” táa sọ tẹ́lẹ̀ ń kó láàárín agbo Ọlọ́run?
5 Àmọ́ ṣá, níwọ̀n ìgbà tí ayé tó kún fún ìwà ìkórìíra yìí bá ṣì wà, àwọn tó para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ yìí ń fẹ́ ààbò. “Àwọn ọmọ aládé” tó ń “ṣàkóso . . . fún ìdájọ́ òdodo” ló sì ń pèsè ààbò yìí ní pàtàkì. Áà, ìṣètò yìí mà ga lọ́lá o! Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà fi àwọn ọ̀rọ̀ tó gbámúṣé ṣàpèjúwe “àwọn ọmọ aládé” wọ̀nyí síwájú sí i pé: “Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.”—Aísáyà 32:2.
6 Ní àsìkò yìí gan-an tí ìpọ́njú kárí ayé, a nílò “àwọn ọmọ aládé,” bẹ́ẹ̀ ni o, àní àwọn alàgbà tí yóò “kíyè sí . . . gbogbo agbo,” nípa bíbójútó àwọn àgùntàn Jèhófà, kí wọ́n sì máa ṣe ìdájọ́ òdodo níbàámu pẹ̀lú àwọn ìlànà òdodo Jèhófà. (Ìṣe 20:28) Irú “àwọn ọmọ aládé” bẹ́ẹ̀ ní láti dójú ìlà àwọn ẹ̀rí ìtóótun tó wà nínú Tímótì kìíní, orí kẹta, ẹsẹ kejì sí keje àti Títù orí kìíní, ẹsẹ kẹfà sí ìkẹsàn-án.
7 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ ńlá tí Jésù fi ń ṣàpèjúwe “ìparí ètò àwọn nǹkan” tí yóò kún fún ìpọ́njú, ó sọ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò jáyà.” (Mátíù 24:3-8) Èé ṣe tí ipò inú ayé eléwu òde òní kò fi já àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù láyà? Ìdí kan ni pé, ńṣe ni “àwọn ọmọ aládé,” yálà ẹni àmì òróró tàbí “àgùntàn mìíràn,” ń fi ìdúróṣinṣin dáàbò bo agbo. (Jòhánù 10:16) Láìbẹ̀rù, wọ́n ń bójú tó àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn, kódà lójú ìwà ìkà bí ogun láàárín ẹ̀yà kan àti òmíràn, àti ìpẹ̀yàrun. Nínú ayé tí ohun tẹ̀mí ti ṣọ̀wọ́n yìí, wọ́n ń rí i dájú pé àwọn tó ní ìdààmú ọkàn ń rí òtítọ́ tó ń gbéni ró gbà látinú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí sì ń tù wọ́n lára.
8. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dá “àwọn ọmọ aládé” tó jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn lẹ́kọ̀ọ́?
8 Láti àádọ́ta ọdún síhìn-ín ni “àwọn ọmọ aládé” ti túbọ̀ hàn kedere sójú táyé. “Àwọn ọmọ aládé” tó jẹ́ ara àwọn àgùntàn mìíràn sì ń gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí ara ẹgbẹ́ “ìjòyè” tó ń yọjú bọ̀, kí ó lè jẹ́ pé, lẹ́yìn ìpọ́njú ńlá, àwọn tó tóótun lára wọn yóò wà ní sẹpẹ́ láti gba ẹrù iṣẹ́ àbójútó nínú “ayé tuntun.” (Ìsíkíẹ́lì 44:2, 3; 2 Pétérù 3:13) Wọ́n ń fi hàn pé àwọn dà “bí òjìji àpáta gàǹgà” nípa pípèsè tí wọ́n ń pèsè ìtọ́sọ́nà àti ìtura bí wọ́n ṣe ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìsìn Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì ń tipa báyìí mú ìtura bá agbo nínú gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìjọsìn wọn.b
9. Àwọn ipò wo ló fi hàn pé a nílò “àwọn ọmọ aládé” lóde òní?
9 Nínú àwọn ọjọ́ ìkẹyìn eléwu ti ayé búburú, ayé Sátánì yìí, àwọn Kristẹni tó ṣe ìyàsímímọ́ ń fẹ́ ààbò yìí gidigidi. (2 Tímótì 3:1-5, 13) Ẹ̀fúùfù líle ti ẹ̀kọ́ èké àti ìgbékèéyíde ń fẹ́. Ìjì ogun ń jà lọ ràì, àní ogun láàárín orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè àti ogun abẹ́lé, ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn èèyàn tún ń dojú ìjà kọ àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà Ọlọ́run. Inú ayé tó gbẹ táútáú nítorí ọ̀dá ohun tẹ̀mí yìí sì làwọn Kristẹni wà, nítorí náà, wọ́n nílò ìṣàn omi òtítọ́ gan-an ni, omi tó mọ́ tónítóní, tí kò lábùlà, láti lè fi pòùngbẹ wọn nípa tẹ̀mí. Ó sì dùn mọ́ni pé Jèhófà ṣèlérí pé Ọba tóun fi jẹ yìí yóò lo àwọn arákùnrin rẹ̀ ẹni àmì òróró, àti “àwọn ọmọ aládé” látinú àwọn àgùntàn mìíràn tó ń tì wọ́n lẹ́yìn, láti fi pèsè ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà fún àwọn tí ìdààmú ọkàn àti ìrẹ̀wẹ̀sì bá lákòókò ìnira yìí. Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà yóò rí sí i pé ohun tó tọ́, tó sì bá ìdájọ́ òdodo mu ni yóò gbilẹ̀.
Fífi Ojú Ṣàkíyèsí, Títẹ́ Etí Sílẹ̀, àti Fífi Ọkàn Gbọ́rọ̀
10. Ìṣètò wo ni Jèhófà ti ṣe kí àwọn èèyàn rẹ̀ lè ‘rí’ àwọn nǹkan tẹ̀mí, kí wọ́n sì ‘gbọ́’ àwọn nǹkan tẹ̀mí?
10 Ìhà wo làwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá wá kọ sí ìṣètò lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run tí Jèhófà ṣe? Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ń bá a lọ pé: “Ojú àwọn tí ń ríran kì yóò sì lẹ̀ pọ̀, àní etí àwọn tí ń gbọ́ràn yóò sì tẹ́ sílẹ̀.” (Aísáyà 32:3) Láti àwọn ọdún àtẹ̀yìnwá, Jèhófà a máa ṣètò bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ọ̀wọ́n yóò ṣe rí ìtọ́ni gbà àti ọ̀nà tí wọn yóò gbà dàgbà dénú nípa tẹ̀mí. Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti àwọn ìpàdé yòókù tó ń wáyé nínú àwọn ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé; àpéjọ àgbègbè, ti orílẹ̀-èdè, àti ti àgbáyé; àtàwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àkànṣe tí “àwọn ọmọ aládé” ń gbà nípa bí wọn ó ṣe fi ìfẹ́ bójú tó agbo, ló pa pọ̀ mú kó ṣeé ṣe kí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé, tó jẹ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́, lè wáyé. Ibikíbi tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn wọ̀nyí ì báà wà lórí ilẹ̀ ayé, ńṣe ni wọ́n máa ń tẹ́tí bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí àtúnṣe tó bá bá òye tí a ti ní tẹ́lẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ń tẹ̀ síwájú yìí. Bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rí ọkàn wọn tí Bíbélì ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, wọ́n máa ń múra tán nígbà gbogbo láti gbọ́ àti láti ṣègbọràn.—Sáàmù 25:10.
11. Ìdí wo làwọn èèyàn Ọlọ́run fi ń fi ìdánilójú sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nísinsìnyí, láìmáa sọ kábakàba nítorí àìní ìdánilójú?
11 Àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Àní ọkàn-àyà àwọn tí ń kánjú jù yóò sì ronú nípa ìmọ̀, àní ahọ́n àwọn akólòlò yóò ṣe kíá ní sísọ àwọn ohun ṣíṣe kedere.” (Aísáyà 32:4) Kẹ́nikẹ́ni má ṣe lọ kánjú jù o, láti máa fi ìwàǹwára dórí ìpinnu pé èyí ló tọ́, èyí ni kò tọ́. Bíbélì sọ pé: “Ìwọ ha ti rí ènìyàn tí ń fi ìkánjú sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀? Ìrètí ń bẹ fún arìndìn jù fún un lọ.” (Òwe 29:20; Oníwàásù 5:2) Ṣáájú ọdún 1919, èrò Bábílónì kó àbààwọ́n bá àwọn èèyàn Jèhófà pàápàá. Àmọ́ láti ọdún yẹn síwájú ni Jèhófà ti fún wọn ní òye tó ṣe kedere sí i nípa àwọn ète rẹ̀. Wọ́n rí i pé àròjinlẹ̀ tí máa ń wà ṣáájú lórí òtítọ́ tó ń ṣí payá fáwọn, kò sì sí ọ̀ràn pé ó ń kánjú jù níbẹ̀, ìyẹn ni wọ́n fi ń fi ìdánilójú sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nísinsìnyí, láìmáa sọ kábakàba nítorí àìní ìdánilójú.
“Òpònú”
12. Àwọn wo ni “òpònú” lóde òní, ọ̀nà wo ló sì fi jẹ́ pé wọn kò ní ìwà ọ̀làwọ́?
12 Lẹ́yìn náà, àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà wá mẹ́nu kan ohun tó jẹ́ òdì kejì èyí, ó ní: “A kì yóò tún pe òpònú ní ọ̀làwọ́ mọ́; àti ní ti oníwàkíwà, a kì yóò sọ pé ó jẹ́ ọ̀tọ̀kùlú; nítorí pé òpònú alára yóò máa sọ ọ̀rọ̀ òpònú lásán-làsàn.” (Aísáyà 32:5, 6a) Ta ni “òpònú” yìí? Ẹ̀ẹ̀mejì ni Dáfídì Ọba dáhùn rẹ̀, àfi bíi pé ó ń sọ àsọtúnsọ fún ìtẹnumọ́, ó ní: “Òpònú sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé: ‘Jèhófà kò sí.’ Wọ́n ti gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun, wọ́n ti hùwà lọ́nà ìṣe-họ́ọ̀-sí nínú ìbálò wọn. Kò sí ẹni tí ń ṣe rere.” (Sáàmù 14:1; 53:1) Lóòótọ́, àwọn tó jẹ́ ògidì aláìgbà-pọ́lọ́run-wà ti sọ pé kò sí Jèhófà. Ohun kan náà sì ni “àwọn ọ̀mọ̀wé” máa ń sọ àti àwọn mìíràn tí wọ́n ń ṣe bíi pé Ọlọ́run ò sí, tí wọ́n ń hùwà ta-ni-yóò-mú-mi. Òótọ́ kọ́bọ̀ ò sí nínú wọn. Ìwà ọ̀làwọ́ kankan kò sì sí lọ́kàn wọn. Ẹnu wọ́n kọ ìhìn rere tó dá lórí ìfẹ́. Bó bá ti di pé ká ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní tí wàhálà dé bá, bí ìgbín ni wọ́n ṣe máa ń fà tàbí kí wọ́n má tiẹ̀ yọjú síbẹ̀ rárá, wọn ò jẹ́ ṣe bíi tàwọn ojúlówó Kristẹni.
13, 14. (a) Báwo ni àwọn apẹ̀yìndà òde òní ṣe ń ṣiṣẹ́ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́? (b) Ọ̀nà kí ni àwọn apẹ̀yìndà fẹ́ dí mọ́ àwọn tí ebi ń pa tí òùngbẹ sì ń gbẹ, ṣùgbọ́n kí ni yóò jẹ́ àbáyọrí rẹ̀?
13 Ọ̀pọ̀ irú àwọn òpònú bẹ́ẹ̀ ló ń dẹni tó kórìíra àwọn tó jẹ́ akọgun nídìí òtítọ́ Ọlọ́run. “Àní ọkàn-àyà rẹ̀ yóò sì máa ṣiṣẹ́ ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, láti máa ṣiṣẹ́ ìpẹ̀yìndà àti láti máa sọ ọ̀rọ̀kọrọ̀ sí Jèhófà.” (Aísáyà 32:6b) Ẹ wo bí èyí ṣe bá àwọn apẹ̀yìndà òde òní mu wẹ́kú tó! Ní àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan ní Yúróòpù àti Éṣíà, ṣe ni àwọn apẹ̀yìndà lẹ̀dí àpò pọ̀ mọ́ àwọn alátakò òtítọ́ mìíràn, wọn a wá irọ́ burúkú pa fáwọn aláṣẹ, kí wọ́n lè fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí kí wọ́n ká wa lọ́wọ́ kò. Ẹ̀mí “ẹrú búburú” tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ ni wọ́n ní, ó ní: “Bí ẹrú búburú yẹn bá lọ sọ nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pẹ́nrẹ́n pé, ‘Ọ̀gá mi ń pẹ́,’ tí ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí lu àwọn ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ó sì ń jẹ, tí ó sì ń mu pẹ̀lú àwọn ọ̀mùtí paraku, ọ̀gá ẹrú yẹn yóò dé ní ọjọ́ tí kò fojú sọ́nà fún àti ní wákàtí tí kò mọ̀, yóò sì fi ìyà mímúná jù lọ jẹ ẹ́, yóò sì yan ipa tirẹ̀ fún un pẹ̀lú àwọn alágàbàgebè. Níbẹ̀ ni ẹkún rẹ̀ àti ìpayínkeke rẹ̀ yóò wà.”—Mátíù 24:48-51.
14 Ní báyìí ná, ńṣe ni apẹ̀yìndà ń mú kí “ọkàn àwọn tí ebi ń pa ṣófo, ó sì ń mú kí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ pàápàá ṣe aláìní ohun mímu.” (Aísáyà 32:6d) Àwọn ọ̀tá òtítọ́ ń sapá láti dínà oúnjẹ tẹ̀mí mọ́ àwọn tí ebi òtítọ́ ń pa, wọ́n sì ń sapá láti rí i pé àwọn tí òùngbẹ ń gbẹ kò rí omi ìsọfúnni nípa Ìjọba Ọlọ́run, tó ń tuni lára, mu. Àmọ́ ohun tí yóò jẹ́ àbáyọrí rẹ̀ ni Jèhófà ti gbẹnu wòlíì rẹ̀ mìíràn kéde fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Ó sì dájú pé wọn yóò bá ọ jà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò borí rẹ, nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘láti dá ọ nídè.’”—Jeremáyà 1:19; Aísáyà 54:17.
15. Lóde òní, àwọn wo ni àwọn “oníwàkíwà” ní pàtàkì, “àwọn àsọjáde èké” wo ni wọ́n sì ń gbé lárugẹ, kí ló sì yọrí sí?
15 Láti àwọn ọdún agbedeméjì ọ̀rúndún ogún ni ìṣekúṣe ti kúkú gbòde kan nínú àwọn ilẹ̀ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Èé ṣe? Àsọtẹ́lẹ̀ yìí sọ ìdí kan, ó ní: “Ní ti oníwàkíwà, àwọn ohun èlò rẹ̀ burú; òun fúnra rẹ̀ ti fúnni ní ìmọ̀ràn fún ìwà àìníjàánu, láti fi àwọn àsọjáde èké fọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ bàjẹ́, àní nígbà tí òtòṣì ń sọ ohun tí ó tọ́.” (Aísáyà 32:7) Lóòótọ́, bí ọ̀rọ̀ yìí ṣe sọ, ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ní pàtàkì, ti gba ìgbàkugbà lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ṣáájú ìgbéyàwó, àti kí ọkùnrin àti obìnrin gbà láti kàn jọ máa gbé pọ̀ láìjẹ́ tọkọtaya, àti lórí ọ̀ràn ìbẹ́yàkannáà-lòpọ̀, àní ká kúkú sọ pé wọ́n gbọ̀jẹ̀gẹ́ fún “àgbèrè àti ìwà àìmọ́ onírúurú gbogbo.” (Éfésù 5:3) Nípa báyìí, wọ́n ti fi àwọn àsọjáde èké wọn “fọ́” agbo wọn.
16. Kí ló ń fún àwọn ojúlówó Kristẹni láyọ̀?
16 Ní ìyàtọ̀ sí èyí, ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí wòlíì náà sọ tẹ̀ lé e mà tuni lára o! Ó ní: “Ní ti ẹni tí ó jẹ́ ọ̀làwọ́, ohun ọ̀làwọ́ ni ó fúnni ní ìmọ̀ràn lé lórí; òun fúnra rẹ̀ yóò sì dìde láti fara mọ́ àwọn ohun ọ̀làwọ́.” (Aísáyà 32:8) Jésù alára gbani níyànjú láti jẹ́ ọ̀làwọ́ nígbà tó sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín. Nítorí òṣùwọ̀n tí ẹ fi ń díwọ̀n fúnni, ni wọn yóò fi díwọ̀n padà fún yín.” (Lúùkù 6:38) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú sọ nípa àwọn ìbùkún tó máa ń bá àwọn ọ̀làwọ́ nígbà tó sọ pé: “Ẹ . . . fi àwọn ọ̀rọ̀ Jésù Olúwa sọ́kàn, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ wí pé, ‘Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.’” (Ìṣe 20:35) Jíjẹ́ ọ̀làwọ́, àní gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn Jèhófà ṣe jẹ́ ọ̀làwọ́ gẹ́lẹ́, ló máa ń fún àwọn ojúlówó Kristẹni láyọ̀, kì í ṣe jíjẹ́ ọlọ́là tàbí dídi gbajúmọ̀ láwùjọ. (Mátíù 5:44, 45) Ohun tó sì ń fún wọn láyọ̀ jù lọ ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, lílo ara wọn tọkàn tara láti lè rí i pé àwọn ẹlòmíràn mọ nípa “ìhìnrere ológo ti Ọlọ́run aláyọ̀.”—1 Tímótì 1:11.
17. Lóde òní, àwọn wo ló dà bí àwọn “ọmọbìnrin tí kò bìkítà” tí Aísáyà ń sọ?
17 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń bá a lọ pé: “Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ wà ní ìdẹ̀rùn, ẹ dìde, ẹ fetí sí ohùn mi! Ẹ̀yin ọmọbìnrin tí kò bìkítà, ẹ fi etí sí àsọjáde mi! Láàárín ọdún kan àti ọjọ́ mélòó kan, ṣìbáṣìbo yóò bá ẹ̀yin aláìbìkítà, nítorí pé kíká èso àjàrà yóò ti wá sí òpin, ṣùgbọ́n kò sí àkójọ èso tí yóò wọlé wá. Ẹ wárìrì, ẹ̀yin obìnrin tí ó wà ní ìdẹ̀rùn! Kí ṣìbáṣìbo bá yín, ẹ̀yin aláìbìkítà!” (Aísáyà 32:9-11a) Ìwà àwọn obìnrin wọ̀nyí lè mú wa rántí àwọn tó sọ pé àwọn ń sin Ọlọ́run lóde òní, ṣùgbọ́n tí wọn kò ní ìtara lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Irú wọn ló wà nínú àwọn ẹ̀sìn “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 17:5) Bí àpẹẹrẹ, bí Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe àwọn “obìnrin” wọ̀nyí gẹ́lẹ́ ni àwọn ọmọ ìjọ inú Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ń ṣe. “Ìdẹ̀rùn” ni wọ́n wà, wọn kò kọbi ara sí ìdájọ́ àti ṣìbáṣìbo tí yóò dé bá wọn láìpẹ́.
18. Ta ni wọ́n sọ fún pé kó “sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ abẹ́nú” rẹ̀, kí ló sì fà á?
18 Ìyẹn ni ẹ̀sìn èké fi gba ìpè yìí pé: “Ẹ bọ́ṣọ, kí ẹ sì tú ara yín sí ìhòòhò, kí ẹ sì sán aṣọ àpò ìdọ̀họ mọ́ abẹ́nú. Ẹ lu ara yín ní ọmú nínú ìdárò nítorí àwọn pápá fífani-lọ́kàn-mọ́ra, nítorí àjàrà tí ń so èso. Lórí ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi, ẹ̀gún lásán-làsàn àti àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún ọ̀gàn ni ó ń hù jáde, nítorí tí wọ́n wà lórí gbogbo ilé ayọ̀ ńláǹlà, bẹ́ẹ̀ ni, ìlú tí ayọ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́.” (Aísáyà 32:11b-13) Kò jọ pé gbólóhùn náà, “Ẹ bọ́ṣọ, kí ẹ sì tú ara yín sí ìhòòhò,” túmọ̀ sí pé wọ́n kúkú bọ́ sí ìhòòhò goloto. Ó jẹ́ àṣà wọn nígbà láéláé láti máa wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè sórí àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn. Ẹ̀wù àwọ̀lékè yẹn sábà máa ń jẹ́ ohun tí wọ́n fi ń dáni mọ̀. (2 Àwọn Ọba 10:22, 23; Ìṣípayá 7:13, 14) Nípa bẹ́ẹ̀, ńṣe ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí ń pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ ìjọ inú ẹ̀sìn èké bọ́ ẹ̀wù àwọ̀lékè wọn, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń díbọ́n pé àwọn jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, kí wọ́n wá wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ, tó jẹ́ àmì pé wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ nítorí ìdájọ́ tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dé sórí wọn. (Ìṣípayá 17:16) Àwọn ètò ẹ̀sìn inú Kirisẹ́ńdọ̀mù tó sọ pé òun jẹ́ “ìlú” Ọlọ́run “tí ayọ̀ kún inú rẹ̀ fọ́fọ́,” àtàwọn èèyàn yòókù látinú ilẹ̀ ọba ẹ̀sìn èké àgbáyé, kò mú èso tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu jáde rárá ni. “Ẹ̀gún lásán-làsàn àti àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún ọ̀gàn,” ìyẹn ìpatì àti ìkọ̀sílẹ̀, ló ń hù jáde ṣáá látinú gbogbo ibi tó wà níkàáwọ́ rẹ̀.
19. Ipò wo ni Aísáyà tú àṣírí rẹ̀ pé “Jerúsálẹ́mù” apẹ̀yìndà wà?
19 Ibi gbogbo nínú “Jerúsálẹ́mù” apẹ̀yìndà ni ọ̀ràn àgbákò yìí kàn, ó ní: “Ilé gogoro ibùgbé pàápàá ni a ti ṣá tì, àní riworiwo ìlú ńlá ni a ti pa tì; Ófélì àti ilé ìṣọ́ pàápàá ti di èkìdá àwọn pápá, fún àkókò tí ó lọ kánrin ni yóò jẹ́ ayọ̀ ńláǹlà àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ abilà, pápá ìjẹko agbo ẹran ọ̀sìn.” (Aísáyà 32:14) Àní ó tilẹ̀ kan Ófélì pàápàá. Ófélì jẹ́ apá ibi gíga ní Jerúsálẹ́mù, èyí tó ṣeé dúró sí láti gbéjà ko àwọn ọ̀tá. Láti sọ pé Ófélì di èkìdá àwọn pápá, túmọ̀ sí pé ìlú yẹn ti dahoro pátápátá nìyẹn. Ọ̀rọ̀ Aísáyà fi hàn pé “Jerúsálẹ́mù” apẹ̀yìndà, ìyẹn Kirisẹ́ńdọ̀mù, kò wà lójú fò láti rí i pé òun ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Aṣálẹ̀ ló jẹ́ nípa tẹ̀mí, ó jìnnà sí òtítọ́ àti ìdájọ́ òdodo pátápátá, ìwà ẹranko gbáà ló ń hù.
Ìyàtọ̀ Ológo!
20. Kí ni àbáyọrí títú tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde sórí àwọn èèyàn rẹ̀?
20 Lẹ́yìn èyí, Aísáyà sọ ìrètí àmọ́kànyọ̀ tó wà fún àwọn tó bá ṣe ìfẹ́ Jèhófà. Ahoro yòówù kó bá àwa èèyàn Ọlọ́run, yóò wulẹ̀ jẹ́ “títí di ìgbà tí a óò tú ẹ̀mí jáde sórí wa láti ibi gíga lókè, tí aginjù yóò sì di ọgbà igi eléso, tí a ó sì ka ọgbà igi eléso náà sí igbó gidi.” (Aísáyà 32:15) Ó dùn mọ́ni pé láti ọdún 1919 ni Jèhófà ti tú ẹ̀mí rẹ̀ jáde sórí àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́pọ̀ yanturu, tó fi wá mú kí ohun tí a lè pè ní ọgbà igi eléso ti àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ẹni àmì òróró, padà bọ̀ sípò, tí igbó ti àwọn àgùntàn mìíràn, tó túbọ̀ ń fẹ̀ sí i, wá tẹ̀ lé e. Aásìkí àti ìbísí ni a kàn ń rí ṣáá nínú ètò àjọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé lónìí. Nínú Párádísè tẹ̀mí tó ti padà bọ̀ sípò, ńṣe làwọn èèyàn Ọlọ́run ń gbé “ògo Jèhófà, ọlá ńlá Ọlọ́run wa” yọ bí wọ́n ṣe ń polongo Ìjọba rẹ̀ tó ń bọ̀ káàkiri ayé.—Aísáyà 35:1, 2.
21. Ibo la ti lè rí òdodo, ìdákẹ́jẹ́ẹ́, àti ààbò lóde òní?
21 Wá gbọ́ ìlérí ológo tí Jèhófà ṣe wàyí, ó ní: “Dájúdájú, ìdájọ́ òdodo yóò sì máa gbé aginjù, àní òdodo yóò sì máa gbé inú ọgbà igi eléso. Iṣẹ́ òdodo tòótọ́ yóò sì di àlàáfíà; iṣẹ́ ìsìn òdodo tòótọ́ yóò sì di ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Aísáyà 32:16, 17) Àpèjúwe yìí mà kúkú bá ipò tẹ̀mí tí àwọn èèyàn Jèhófà wà lónìí mu gan-an o! Àwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú aráyé, tó jẹ́ pé ìkórìíra, ìwà ipá, àti ipò òṣì paraku nípa tẹ̀mí ti pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ, ńṣe ni wọ́n wà ní ìṣọ̀kan ní tiwọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n.” Wọ́n ń gbé ìgbé ayé wọn, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ wọn, àti iṣẹ́ ìsìn wọn ní ìbámu pẹ̀lú òdodo Ọlọ́run, wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pé níkẹyìn, àwọn yóò gbádùn àlàáfíà àti ààbò tòótọ́ títí láé.—Ìṣípayá 7:9, 17.
22. Ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín ipò àwọn èèyàn Ọlọ́run àti ti àwọn tó wà nínú ẹ̀sìn èké?
22 Aísáyà 32:18 ti ń ṣẹ nísinsìnyí nínú Párádísè tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.” Àmọ́ o, ní ti àwọn àdàmọ̀di Kristẹni, ó ní: “Dájúdájú, yóò sì rọ yìnyín nígbà tí igbó bá lọ sílẹ̀, tí ìlú ńlá náà sì di rírẹ̀sílẹ̀ ní ipò ìrẹ̀wálẹ̀.” (Aísáyà 32:19) Bẹ́ẹ̀ ni o, bí ìjì líle tó ń rọ yìnyín, bẹ́ẹ̀ ni ìdájọ́ Jèhófà ṣe ń bọ̀ kánkán sórí ayédèrú ìlú ẹ̀sìn èké, tí yóò fi sọ “igbó” àwọn alátìlẹyìn rẹ̀ di rírẹ̀sílẹ̀, tí yóò sì pa wọ́n rẹ́ láéláé!
23. Iṣẹ́ kárí ayé wo ló ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, kí ni àwọn tó ń kópa níbẹ̀ yóò sì jẹ́?
23 Ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ yìí wá parí báyìí pé: “Aláyọ̀ ni ẹ̀yin tí ń fún irúgbìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo omi, tí ń rán ẹsẹ̀ akọ màlúù àti ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jáde.” (Aísáyà 32:20) Akọ màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ́ ẹranko arẹrù, èyí tí àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń lò látijọ́ láti fi túlẹ̀ àti láti fi fúnrúgbìn. Lóde òní, ohun èlò ìtẹ̀wé, àwọn irinṣẹ́ abánáṣiṣẹ́, àwọn ilé àti ohun ìrìnnà ìgbàlódé, àti lékè gbogbo rẹ̀ ètò àjọ tó ṣọ̀kan, táa ṣètò lọ́nà ìṣàkóso Ọlọ́run, ni àwọn èèyàn Jèhófà ń lò láti fi tẹ ọ̀kẹ́ àìmọye ìwé tó dá lórí Bíbélì, òun náà sì ni wọ́n ń lò láti fi pín wọn kiri. Àwọn tó fi tinútinú yọ̀ǹda láti ṣiṣẹ́ wá ń lo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí láti fi fúnrúgbìn òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run jákèjádò ilẹ̀ ayé, àní “lẹ́gbẹ̀ẹ́ gbogbo omi” ní ti gidi. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run, lọ́kùnrin lóbìnrin la sì ti kórè wọlé, tí ògìdìgbó àwọn mìíràn sì ń dára pọ̀ mọ́ wọn. (Ìṣípayá 14:15, 16) “Aláyọ̀” mà ni gbogbo wọn yóò jẹ́ ní tòótọ́ o!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí “ọba” tí Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n, ẹsẹ kìíní sọ kọ́kọ́ tọ́ka sí Hesekáyà Ọba. Àmọ́, ní ti ìmúṣẹ pàtàkì tí Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n ní, Kristi Jésù Ọba ló jẹ mọ́.
b Wo Ilé Ìṣọ́, March 1, 1999, ojú ìwé kẹtàlá sí ìkejìdínlógún, èyí tí Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania tẹ̀ jáde.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 331]
Nínú Àkájọ Ìwé Òkun Òkú, wọ́n fa ìlà méjì tó kọjá lórí ara wọn báyìí “X” sétí Aísáyà orí kejìlélọ́gbọ̀n
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 333]
Olúkúlùkù “ọmọ aládé” dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ òjò, bí omi ní ilẹ̀ aláìlómi, àti bí òjìji kúrò lọ́wọ́ oòrùn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 338]
Ìdùnnú ńlá ló máa ń jẹ́ fáwọn Kristẹni láti mú ìhìn rere tọ àwọn ẹlòmíràn lọ