Orí Kẹtàdínlọ́gbọ̀n
Jèhófà Tú Ìbínú Rẹ̀ Sórí Àwọn Orílẹ̀-Èdè
1, 2. (a) Kí ló dá wa lójú nípa ẹ̀san látọ̀dọ̀ Jèhófà? (b) Kí ni Ọlọ́run máa ń jẹ́ kó hàn nígbà tó bá gbẹ̀san?
JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN máa ń mú sùúrù fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, àmọ́ ó tún máa ń mú sùúrù fáwọn ọ̀tá rẹ̀ pẹ̀lú nígbà tó bá wé mọ́ mímú ète rẹ̀ ṣẹ. (1 Pétérù 3:19, 20; 2 Pétérù 3:15) Àwọn ọ̀tá Jèhófà lè má mọyì sùúrù rẹ̀, lójú tiwọn, ó lè dà bíi pé ńṣe ni kò lágbára láti gbégbèésẹ̀ tàbí pé ó ń lọ́ tìkọ̀. Àmọ́ ṣá o, gẹ́gẹ́ bí Aísáyà orí kẹrìnlélọ́gbọ̀n ti fi hàn, Jèhófà máa ń rí sí i pé wọ́n jíhìn iṣẹ́ ọwọ́ wọn, bó pẹ́ bó yá. (Sefanáyà 3:8) Fún sáà kan, Ọlọ́run yọ̀ǹda kí Édómù àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn kọjúùjà sáwọn ènìyàn rẹ̀ láìdásí wọn. Ṣùgbọ́n ẹ̀san ń bọ̀ wá ké nígbà tí àkókò rẹ̀ bá tó lójú Jèhófà. (Diutarónómì 32:35) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ní àkókò tí Jèhófà yàn, òun yóò gbẹ̀san lára gbogbo ẹ̀ka àwọn ètò tó wà nínú ayé burúkú yìí, tó ń tàpá sí ipò ọba aláṣẹ rẹ̀.
2 Olórí ète tí Ọlọ́run fi ń gbẹ̀san ni láti fi hàn pé òun ni ọba aláṣẹ, kí ó sì tún ṣe orúkọ ara rẹ̀ lógo. (Sáàmù 83:13-18) Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbígbẹ̀san tó bá gbẹ̀san yóò jẹ́ ẹ̀rí pé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni aṣojú rẹ̀ tòótọ́, yóò sì gbà wọ́n lọ́wọ́ ipò burúkú gbogbo. Kò mọ síbẹ̀ o, gbogbo ìgbà tí Jèhófà bá gbẹ̀san ni ẹ̀san rẹ̀ máa ń bá ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu rẹ́gírẹ́gí.—Sáàmù 58:10, 11.
Ẹ Gbọ́ O, Ẹ̀yin Orílẹ̀-Èdè
3. Kí ni Jèhófà gbẹnu Aísáyà ké sí àwọn orílẹ̀-èdè láti ṣe?
3 Kí Jèhófà tó dẹ́nu lé bó ṣe fẹ́ gbẹ̀san lára Édómù, ó kọ́kọ́ gbẹnu Aísáyà ké atótó-arére sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ó ní: “Ẹ sún mọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, láti gbọ́; àti ẹ̀yin àwùjọ orílẹ̀-èdè, ẹ fetí sílẹ̀. Kí ilẹ̀ ayé àti ohun tí ó kún inú rẹ̀ fetí sílẹ̀, ilẹ̀ eléso àti gbogbo èso rẹ̀.” (Aísáyà 34:1) Léraléra ni wòlíì yìí ti fọ̀rọ̀ bá àwọn orílẹ̀-èdè tí kò náání Ọlọ́run wí. Ó wá tó àkókò wàyí láti ṣàkópọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi bá wọn wí. Ǹjẹ́ ìkìlọ̀ wọ̀nyí túmọ̀ sí ohunkóhun nígbà ayé tiwa yìí?
4. (a) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Aísáyà 34:1, kí ni a ké sí àwọn orílẹ̀-èdè láti ṣe? (b) Ìdájọ́ tí Jèhófà ṣe fáwọn orílẹ̀-èdè ha sọ ọ́ di Ọlọ́run òǹrorò bí? (Wo àpótí ojú ìwé 363.)
4 Ó kàn wá o. Gbogbo ẹ̀ka ètò àwọn nǹkan tí kò náání Ọlọ́run yìí máa tó rí pupa ojú Ọba Aláṣẹ àgbáyé. Ìdí nìyẹn tó fi ké sáwọn “àwùjọ orílẹ̀-èdè” àti “ilẹ̀ ayé” pé kí wọ́n gbọ́ ìsọfúnni tó wá látinú Bíbélì, èyí tí Jèhófà ti mú ká polongo kárí ayé. Aísáyà lo àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ ti inú Sáàmù 24:1, ó ní ìsọfúnni yìí yóò kárí gbogbo ilẹ̀ ayé, àsọtẹ́lẹ̀ yìí sì ti ṣẹ nígbà tiwa yìí, bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù “títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Àmọ́, àwọn orílẹ̀-èdè ti fi gbígbọ́ ṣaláìgbọ́. Wọn ò kọbi ara sí ìkìlọ̀ nípa ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ lé wọn lórí. Àmọ́ o, ìyẹn ò ní kí Jèhófà máà mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ.
5, 6. (a) Kí lẹ̀ṣẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọ́run fi pè wọ́n wá jíhìn? (b) Báwo ni “àwọn òkè ńláńlá yóò [ṣe] yọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn”?
5 Àsọtẹ́lẹ̀ náà wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣàpèjúwe dùgbẹ̀dùgbẹ̀ tó ń fì lórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò náání Ọlọ́run, èyí tó yàtọ̀ pátápátá sí ìrètí ológo ti àwọn èèyàn Ọlọ́run táa ṣàpèjúwe lẹ́yìn náà. (Aísáyà 35:1-10) Wòlíì náà sọ pé: “Jèhófà ní ìkannú sí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ìhónú sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn. Òun yóò yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun; yóò fi wọ́n fún ìfikúpa. A ó sì sọ àwọn tí a pa nínú wọn síta; àti ní ti òkú wọn, àyán wọn yóò gòkè; àwọn òkè ńláńlá yóò sì yọ́ nítorí ẹ̀jẹ̀ wọn.”—Aísáyà 34:2, 3.
6 A pe àfiyèsí sí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè. Lóde òní, àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ló jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ jù lọ. Nínú ogun àgbáyé méjèèjì àtàwọn ogun pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ mìíràn tí wọ́n ti jà, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ ọmọ aráyé rin ilẹ̀ ayé gbingbin. Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gbẹ̀san gbogbo ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ yìí? Ẹlẹ́dàá, atóbilọ́lá Olùfúnni ní Ìyè kúkú ni. (Sáàmù 36:9) Òfin Jèhófà ti fi ìlànà náà lélẹ̀, pé: “Kí ìwọ fi ọkàn fún ọkàn.” (Ẹ́kísódù 21:23-25; Jẹ́nẹ́sísì 9:4-6) Ní ìbámu pẹ̀lú òfin yìí, òun yóò jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ṣàn, ìyẹn ni pé ẹ̀mí wọn á lọ sí i. Ṣe ni òkú wọn, tó máa wà láìsin, yóò máa ṣíyàn-án, tí òórùn rẹ̀ yóò sì gba afẹ́fẹ́ kan, áà, ikú ẹ̀sín gbáà ni! (Jeremáyà 25:33) Ẹ̀jẹ̀ tí a ó fi gbẹ̀san yóò tó láti yọ́ ohun táa lè pè ní àwọn òkè ńláńlá. (Sefanáyà 1:17) Nígbà tí ìparun yán-ányán-án bá dé bá ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè ayé, ìṣojú àwọn orílẹ̀-èdè yìí làwọn ìjọba wọn, tí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì máa ń fi wé òkè nígbà mìíràn, yóò fọ́ túútúú.—Dáníẹ́lì 2:35, 44, 45; Ìṣípayá 17:9.
7. Kí ni “ọ̀run,” kí sì ni “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run”?
7 Aísáyà tún ń bá a lọ ní lílo àpèjúwe tó fakíki, ó ní: “Gbogbo àwọn tí í ṣe ara ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run yóò sì jẹrà dànù. A ó sì ká ọ̀run jọ, gẹ́gẹ́ bí ìwé àkájọ; gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn yóò sì kíweje, gan-an gẹ́gẹ́ bí ewé ti ń kíweje kúrò lára àjàrà àti gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kíweje kúrò lára igi ọ̀pọ̀tọ́.” (Aísáyà 34:4) Gbólóhùn náà “gbogbo àwọn tí í ṣe ara ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” kò tọ́ka sí àwọn ìràwọ̀ àtàwọn pílánẹ́ẹ̀tì gidi. Ẹsẹ ìkarùn-ún àti ìkẹfà sọ̀rọ̀ nípa idà ìdájọ́ tí ẹ̀jẹ̀ yóò rin gbingbin nínú “ọ̀run” tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí. Ìyẹn ló jẹ́ ká mọ̀ pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ ohun kan láyé ńbí. (1 Kọ́ríńtì 15:50) Nítorí gíga fíofío àwọn ìjọba aráyé táa mọ̀ sí aláṣẹ onípò gíga, a fi wọ́n wé àwọn ọ̀run tí ń ṣàkóso àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn orí ilẹ̀ ayé. (Róòmù 13:1-4) Fún ìdí yìí, “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run” dúró fún àpapọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ìjọba aráyé wọ̀nyí.
8. Báwo ni àwọn ọ̀run ìṣàpẹẹrẹ ṣe dà “bí ìwé àkájọ,” kí sì ni yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” wọn?
8 “Ẹgbẹ́ ọmọ ogun” yìí yóò “jẹrà dànù,” ìyẹn ni pé yóò fọ́ túútúú, bí nǹkan tí kì í pẹ́ bà jẹ́. (Sáàmù 102:26; Aísáyà 51:6) Téèyàn bá fi ojúyòójú wo òkè ọ̀run, ńṣe ló máa dà bíi pé ó ká, bí àkájọ ìwé ìgbàanì, tó jẹ́ pé inú rẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń kọ nǹkan sí. Nígbà tẹ́ni tó ń kàwé bá ti ka ohun táa kọ sínú àkájọ ìwé tán, ńṣe ló máa ká ìwé tó ti kà tán náà, yóò sì wá ibì kan fi sí. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, “a ó . . . ká ọ̀run jọ, gẹ́gẹ́ bí ìwé àkájọ,” ní ti pé àwọn ìjọba ènìyàn á dópin. Níwọ̀n bí wọ́n ti gun igi dórí ewé, kí wọ́n rún wómúwómú nígbà Amágẹ́dọ́nì ló kù o. Ńṣe ni àwọn “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” wọn tó jọ wọ́n lójú yóò ṣubú túẹ́ bí ìgbà tí ewé gbígbẹ bá bọ́ lára igi àjàrà tàbí bí ìgbà tí èso “ọ̀pọ̀tọ́ tí ó kíweje” bá bọ́ lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Wọ́n á di ohun àmúpìtàn.—Fi wé Ìṣípayá 6:12-14.
Ọjọ́ Ẹ̀san
9. (a) Kí ni orírun Édómù, báwo sì ni àárín Ísírẹ́lì àti Édómù ṣe rí? (b) Ìpinnu wo ni Jèhófà ṣe nípa Édómù?
9 Wàyí o, àsọtẹ́lẹ̀ náà wá dá orílẹ̀-èdè kan tó wà nígbà ayé Aísáyà yà sọ́tọ̀, ìyẹn Édómù. Àwọn ọmọ Édómù jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ísọ̀ (Édómù), tó ta ogún ìbí rẹ̀ fún Jékọ́bù, tí wọ́n jọ jẹ́ ìbejì, nítorí búrẹ́dì àti ọbẹ̀ ẹ̀wà lẹ́ńtìlì. (Jẹ́nẹ́sísì 25:24-34) Nítorí pé ogún ìbí rẹ̀ ti di ti Jékọ́bù, Ísọ̀ wá kórìíra arákùnrin rẹ̀ burúkú-burúkú. Lẹ́yìn ìgbà náà, orílẹ̀-èdè Édómù àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wá dọ̀tá ara wọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbejì ni àwọn baba ńlá wọn. Jèhófà bínú sí Édómù gan-an nítorí bó ṣe ń bá àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣọ̀tá, ó sì sọ pé: “Ó dájú pé a ó rin idà mi gbingbin ní ọ̀run. Wò ó! Yóò sọ̀ kalẹ̀ wá sórí Édómù, àti sórí àwọn ènìyàn tí mo ti yà sọ́tọ̀ fún ìparun nínú ìdájọ́ òdodo. Jèhófà ní idà kan; a óò mú un kún fún ẹ̀jẹ̀; a óò mú un rin ṣìnkìn fún ọ̀rá, fún ẹ̀jẹ̀ àwọn ẹgbọrọ àgbò àti òbúkọ, fún ọ̀rá kíndìnrín àwọn àgbò. Nítorí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà, àti ìfikúpa ńlá ní ilẹ̀ Édómù.”—Aísáyà 34:5, 6.
10. (a) Ta ni Jèhófà rẹ̀ wálẹ̀ nígbà tó lo idà rẹ̀ “ní ọ̀run”? (b) Ìwà wo ni Édómù hù nígbà tí Bábílónì kógun wá ja Júdà?
10 Ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ni Édómù tẹ̀ dó sí. (Jeremáyà 49:16; Ọbadáyà 8, 9, 19, 21) Síbẹ̀síbẹ̀, àní àwọn odi agbára tí kì í ṣe àtọwọ́dá wọ̀nyí kò ní pèsè ààbò nígbà tí Jèhófà bá ń lo idà ìdájọ́ “ní ọ̀run,” nígbà tó bá rẹ àwọn alákòóso Édómù wálẹ̀ láti ibi gíga tí wọ́n lé téńté sí. Ńṣe ni Édómù dira ogun gádígádí, tí àwọn ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ a sì máa kilẹ̀ wì-wì-wì káàkiri àwọn òkè ńláńlá láti dáàbò bo orílẹ̀-èdè wọn. Ṣùgbọ́n Édómù abìjàwàrà kò wá ran Júdà lọ́wọ́ nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì kógun wá jà á. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Édómù ń yọ̀ ṣìnkìn nígbà tó rí i pé ìjọba Júdà dojú dé, tó tún ń sa àwọn tó wá ṣẹ́gun Júdà. (Sáàmù 137:7) Àní àwọn Júù tó tún ń sá lọ fún ẹ̀mí wọn, Édómù bẹ̀rẹ̀ sí lé wọn mú, ó ń fà wọ́n lé àwọn ará Bábílónì lọ́wọ́. (Ọbadáyà 11-14) Ète àwọn ọmọ Édómù ni láti gba ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lẹ́yìn tó bá dahoro, lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n tún ń fọ́nnu sí Jèhófà.—Ìsíkíẹ́lì 35:10-15.
11. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe gbẹ̀san ìwà ọ̀dàlẹ̀ àwọn ọmọ Édómù?
11 Ǹjẹ́ Jèhófà gbójú fo ìwà amọniṣeni táwọn ọmọ Édómù hù yìí? Ó tì o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa Édómù pé: “Àwọn akọ màlúù ìgbẹ́ yóò sì sọ̀ kalẹ̀ pẹ̀lú wọn, àti àwọn ẹgbọrọ akọ màlúù pẹ̀lú àwọn alágbára; ilẹ̀ wọn yóò sì rin gbingbin fún ẹ̀jẹ̀, a ó sì mú ekuru wọn gan-an rin ṣìnkìn fún ọ̀rá.” (Aísáyà 34:7) Jèhófà fi àwọn ẹni ńlá àtàwọn ẹni rírẹlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè náà wé akọ màlúù ìgbẹ́ àti ẹgbọrọ akọ màlúù, ó fi wọ́n wé ẹgbọrọ àgbò àti òbúkọ. “Idà” ìdájọ́ Jèhófà gbọ́dọ̀ mú kí ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn náà alára rin ilẹ̀ orílẹ̀-èdè ẹlẹ́bi ẹ̀jẹ̀ yìí gbingbin.
12. (a) Ta ni Jèhófà lò láti fìyà jẹ Édómù? (b) Kí ni Ọbadáyà wòlíì sọ tẹ́lẹ̀ nípa Édómù?
12 Ọlọ́run pète láti fìyà jẹ Édómù nítorí ìwà òṣónú tí wọ́n hù sí ètò àjọ Rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé, èyíinì ni Síónì. Àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ pé: “Jèhófà ní ọjọ́ ẹ̀san, ọdún àwọn ẹ̀san iṣẹ́ fún ẹjọ́ lórí Síónì.” (Aísáyà 34:8) Láìpẹ́ lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣááju Sànmánì Tiwa, ni Jèhófà lo Nebukadinésárì, ọba Bábílónì láti fi bẹ̀rẹ̀ sí gbẹ̀san tó tọ́ lára àwọn ọmọ Édómù. (Jeremáyà 25:15-17, 21) Nígbà tí ẹgbẹ́ ọmọ ogun Bábílónì wá ṣe Édómù bí ọṣẹ́ ṣe ń ṣojú, ó ku ẹni tó máa gba àwọn ọmọ Édómù sílẹ̀! “Ọdún àwọn ẹ̀san iṣẹ́” ni èyí jẹ́ fún ilẹ̀ olókè ńláńlá yẹn. Jèhófà gba ẹnu wòlíì Ọbadáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Nítorí ìwà ipá sí Jékọ́bù arákùnrin rẹ, ìtìjú yóò bò ọ́, dájúdájú, a ó ké ọ kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin. . . . Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ọ. Ọ̀nà-ìgbà-bánilò rẹ yóò padà sórí rẹ.”—Ọbadáyà 10, 15; Ìsíkíẹ́lì 25:12-14.
Ọjọ́ Iwájú Kirisẹ́ńdọ̀mù Pòkúdu
13. Ta ló dà bí Édómù lónìí, èé sì ti ṣe?
13 Lóde òní, ètò àjọ kan wà tí ìtàn rẹ̀ ò yàtọ̀ sí ti Édómù. Ètò àjọ wo nìyẹn o? Kò burú, ta ló jọ̀gá àwọn tó ń pẹ̀gàn, tó ń ṣe inúnibíni sáwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lóde òní? Kì í ha ṣe Kirisẹ́ńdọ̀mù, nípasẹ̀ ẹgbẹ́ àlùfáà rẹ̀, ni bí? Òun kúkú ni! Kirisẹ́ńdọ̀mù gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹni tó lé téńté sórí òkè, nínú àwọn ọ̀ràn ayé yìí. Ó fi ara rẹ̀ sí ipò gíga fíofío nínú ètò àwọn nǹkan ti ọmọ aráyé, àwọn ẹ̀sìn rẹ̀ ló sì kó apá tó pọ̀ jù lọ nínú Bábílónì Ńlá. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti pinnu “ọdún àwọn ẹ̀san iṣẹ́,” nígbà tí òun yóò gbẹ̀san lára Édómù òde òní yìí, nítorí ó han àwọn èèyàn Rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Rẹ̀, léèmọ̀.
14, 15. (a) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí ilẹ̀ Édómù àti sí Kirisẹ́ńdọ̀mù? (b) Kí ni ọ̀rọ̀ tí àsọtẹ́lẹ̀ náà sọ nípa ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tí ń jó àti èéfín tí ń rú fún àkókò tó lọ kánrin túmọ̀ sí, kí sì ni wọn ò túmọ̀ sí?
14 Nítorí náà, báa ṣe ń gbé ìyókù apá yìí lára àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà yẹ̀ wò, a ò kàn ronú nípa Édómù ayé ọjọ́un nìkan, ṣùgbọ́n a tún ronú nípa Kirisẹ́ńdọ̀mù pẹ̀lú. Àsọtẹ́lẹ̀ náà lọ báyìí pé: “Àwọn ọ̀gbàrá rẹ̀ ni a ó sì sọ di ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀, ekuru rẹ̀ ni a ó sì sọ di imí ọjọ́; ilẹ̀ rẹ̀ yóò sì dà bí ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ tí ń jó. Ní òru tàbí ní ọ̀sán, a kì yóò pa á; fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èéfín rẹ̀ yóò máa gòkè.” (Aísáyà 34:9, 10a) Ilẹ̀ Édómù gbẹ fúrúfúrú débi pé ńṣe ló dà bíi pé imí ọjọ́ ni ekuru rẹ̀, ní ti àwọn àfonífojì olójú ọ̀gbàrá rẹ̀, kì í ṣe omi ló kún inú wọn, bí kò ṣe ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀. A tún wá tanná ran nǹkan wọ̀nyí tí kò gbọ́dọ̀ ríná sójú!—Fi wé Ìṣípayá 17:16.
15 Àwọn kan ń sọ pé iná àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ àti imí ọjọ́ tí ibí yìí sọ̀rọ̀ rẹ̀, jẹ́ ẹ̀rí pé ọ̀run àpáàdì wà. Àmọ́ a kò sọ Édómù sínú ọ̀run àpáàdì ẹ̀tàn, láti lọ máa jó níbẹ̀ títí ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n pa á run, tọ́mọ aráyé ò gbúròó ẹ̀ mọ́ rárá, àfi bíi pé iná àti imí ọjọ́ la fi sun ún kanlẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ náà sì ṣe wá fi hàn, àtúbọ̀tán rẹ̀ kì í ṣe ìdálóró ayérayé, bí kò ṣe “òfìfo . . . òfò . . . aláìjámọ́ nǹkan kan.” (Aísáyà 34:11, 12) Èéfín ‘tí ń gòkè fún àkókò tí ó lọ kánrin’ ló fi èyí hàn kedere. Tí ilé kan bá jó kanlẹ̀, èéfín ṣì máa ń rú túú látinú eérú iná náà fún sáà kan lẹ́yìn tí iná náà ti jó tán, èéfín yẹn ni yóò sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé iná ti pitú níbẹ̀. Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni òde òní ti ń kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n nínú ìparun Édómù, bí a bá bá ibí yìí wò ó, èéfín tó ń rú túú látinú iná tó sun Édómù kanlẹ̀ ṣì ń gòkè síbẹ̀.
16, 17. Kí ni Édómù yóò dà, yóò sì ti pẹ́ tó tí yóò fi wà bẹ́ẹ̀?
16 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tẹ̀ síwájú, ó sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ẹranko ló máa wá rọ́pò àwọn èèyàn tí ń gbé ilẹ̀ Édómù, tí í ṣe àmì ahoro tí ń bọ̀, ó ní: “Láti ìran dé ìran ni yóò gbẹ hán-ún hán-ún; títí láé àti láéláé, kò sí ẹni tí yóò gbà á kọjá. Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀ yóò sì gbà á, àwọn òwìwí elétí gígùn àti ẹyẹ ìwò pàápàá yóò sì máa gbé inú rẹ̀; òun yóò sì na okùn ìdiwọ̀n òfìfo àti àwọn òkúta òfò sórí rẹ̀. Àwọn ọ̀tọ̀kùlú rẹ—kò sí ìkankan níbẹ̀ tí wọn yóò pè wá sí ipò ọba, àní gbogbo ọmọ aládé rẹ̀ yóò sì di aláìjámọ́ nǹkan kan. Ẹ̀gún yóò hù sórí àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀, èsìsì àti èpò ẹlẹ́gùn-ún yóò hù sí àwọn ibi olódi rẹ̀; yóò sì di ibi gbígbé fún àwọn akátá, àgbàlá fún àwọn ògòǹgò. Àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò sì bá àwọn ẹranko tí ń hu pàdé, ẹ̀mí èṣù onírìísí ewúrẹ́ pàápàá yóò sì pe alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé ibẹ̀ ni ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́ yóò fara balẹ̀ pẹ̀sẹ̀ sí, tí yóò sì ti rí ibi ìsinmi fún ara rẹ̀. Ibẹ̀ ni ejò ọlọ́fà kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí, tí ó sì yé ẹyin sí.”—Aísáyà 34:10b-15.a
17 Àní sẹ́, Édómù yóò dahoro. Yóò dá páropáro, tó fi jẹ́ pé àwọn ẹranko ẹhànnà, àti ẹyẹ, àti ejò nìkan ló máa kù síbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ kẹwàá ti wí, ilẹ̀ gbígbẹ ni yóò jẹ́ “títí láé àti láéláé.” Kò ní padà bọ̀ sípò.—Ọbadáyà 18.
Ìmúṣẹ Ọ̀rọ̀ Jèhófà Dájú
18, 19. Kí ni “ìwé Jèhófà,” kí sì ni ìwé yìí fi hàn pé ó ń dúró de Kirisẹ́ńdọ̀mù?
18 Ọjọ́ iwájú tó pòkúdu mà rèé o fún Kirisẹ́ńdọ̀mù, tí í ṣe Édómù òde òní! Ó ti sọ ara rẹ̀ di abínúkú ọ̀tá Jèhófà Ọlọ́run, ó sì ń ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sáwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ó sì dájú pé Jèhófà yóò mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Téèyàn bá wo àsọtẹ́lẹ̀ náà, tó tún wo ìmúṣẹ rẹ̀, á rí i pé méjèèjì ṣe rẹ́gí, àní gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ẹ̀dá tí ń gbé inú ahoro Édómù ti ṣe “ní ẹnì kejì rẹ̀.” Aísáyà wá ń bá àwọn tí yóò kẹ́kọ̀ọ́ àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì lọ́jọ́ ọ̀la sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ wá a fún ara yín nínú ìwé Jèhófà, kí ẹ sì kà á sókè: kò sí ọ̀kan tí ó dàwáàrí nínú wọn; ní ti tòótọ́, olúkúlùkù wọn kò kùnà láti ní ẹnì kejì rẹ̀, nítorí pé ẹnu Jèhófà ni ó pa àṣẹ náà, ẹ̀mí rẹ̀ sì ni ó kó wọn jọpọ̀. Àti pé, Òun ni ó ṣẹ́ kèké fún wọn, ọwọ́ rẹ̀ sì ni ó fi fi okùn ìdiwọ̀n pín ibẹ̀ fún wọn. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni wọn yóò gbà á; ìran dé ìran ni wọn yóò máa gbé inú rẹ̀.”—Aísáyà 34:16, 17.
19 “Ìwé Jèhófà” ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí Kirisẹ́ńdọ̀mù. “Ìwé Jèhófà” yìí ló sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹjọ́ tí Jèhófà yóò dá àwọn abínúkú ọ̀tá rẹ̀, àwọn tí kò yéé ni àwọn èèyàn rẹ̀ lára. Ohun tó wà lákọọ́lẹ̀ nípa Édómù ayé ọjọ́un ní ìmúṣẹ, ìyẹn làwa náà sì fi lè fọwọ́ sọ̀yà pé àsọtẹ́lẹ̀ tó dá lórí Kirisẹ́ńdọ̀mù, tí í ṣe Édómù tòde òní, kò ní ṣàì ṣẹ. “Okùn ìdiwọ̀n” náà, ìyẹn, ọ̀pá ìdiwọ̀n Jèhófà, mú un dá wa lójú pé ètò àjọ tó ń kú lọ nípa tẹ̀mí yìí yóò di ahoro tó dá páropáro.
20. Gẹ́gẹ́ bí ti Édómù ayé àtijọ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Kirisẹ́ńdọ̀mù?
20 Kirisẹ́ńdọ̀mù ń jà raburabu kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ olóṣèlú má bàa kẹ̀yìn sí i, àmọ́ asán lórí asán ni! Gẹ́gẹ́ bí ìwé Ìṣípayá orí kẹtàdínlógún àti ìkejìdínlógún ti wí, Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè, yóò fi í sọ́kàn wọn pé kí wọ́n gbégbèésẹ̀ lòdì sí gbogbo Bábílónì Ńlá, títí kan Kirisẹ́ńdọ̀mù. Bí ayédèrú ẹ̀sìn Kristẹni yóò ṣe lọ tèfètèfè kúrò ní gbogbo ilẹ̀ ayé pátá nìyẹn. Ipò Kirisẹ́ńdọ̀mù kò ní yàtọ̀ rárá sí ipò ahoro tí Aísáyà orí kẹrìnlélọ́gbọ̀n ṣàpèjúwe. Á tiẹ̀ ti lọ kó tó dìgbà “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” ogun tó máa kẹ́yìn gbogbo ogun! (Ìṣípayá 16:14) Gẹ́gẹ́ bí Édómù ayé àtijọ́ ni Kirisẹ́ńdọ̀mù yóò ṣe pa rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀ ayé, “títí láé àti láéláé.”
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àsọtẹ́lẹ̀ yìí ti ní ìmúṣẹ nígbà tó fi máa di ìgbà ayé Málákì. (Málákì 1:3) Málákì ròyìn pé àwọn ọmọ Édómù retí àtitún ilẹ̀ wọn tó ti dahoro kọ́. (Málákì 1:4) Àmọ́ o, ìfẹ́ Jèhófà kọ́ nìyẹn, nígbà tó sì ṣe, àwọn ará ibòmíràn, ìyẹn àwọn Nábátíà, wá ń gbé ibi tó jẹ́ ilẹ̀ Édómù tẹ́lẹ̀ rí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 363]
Ọlọ́run Oníbìínú Kẹ̀?
Irú àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Aísáyà 34:2-7, ti mú kí àwọn kan máa sọ pé Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù fi Jèhófà hàn bí Ọlọ́run oníkà àti onínú fùfù. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn rí?
Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ o. Òótọ́ ni pé Ọlọ́run máa ń fi ìbínú rẹ̀ hàn nígbà mìíràn, ṣùgbọ́n ìbínú tó bẹ́tọ̀ọ́mu ni gbogbo rẹ̀ máa ń jẹ́. Ìgbà gbogbo ló máa ń bá ìlànà mu, kì í sì í ṣe pé ó ń fara ya. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìgbà gbogbo ló máa ń ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀tọ́ tí Ẹlẹ́dàá ní láti gba ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe àti gbígbé òtítọ́ lárugẹ láìyẹsẹ̀. Ìfẹ́ Ọlọ́run fún òdodo àti ìfẹ́ rẹ̀ fáwọn tó ń ṣòdodo ló ń ṣàkóso ìbínú Ọlọ́run. Jèhófà jẹ́ arínúróde, tó mọ ohun gbogbo tó wé mọ́ ọ̀ràn kan látòkèdélẹ̀. (Hébérù 4:13) Olùmọ ọkàn ni; ó mọ ìgbà tó bá jẹ́ pé àìmọ̀kan tàbí àìka-nǹkan-sí ló ń yọ wá lẹ́nu, ó sì mọ ìgbà tó bá jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá ni; kì í sì í ṣe ojúsàájú.—Diutarónómì 10:17, 18; 1 Sámúẹ́lì 16:7; Ìṣe 10:34, 35.
Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run máa “ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Àwọn tó bá bẹ̀rù rẹ̀, tó sì ń làkàkà láti ṣiṣẹ́ òdodo yóò rí ojú àánú rẹ̀, nítorí pé Olódùmarè mọ̀ pé èèyàn ti jogún àìpé, ó sì máa ń ṣojú àánú sí i nítorí èyí. Lónìí, ẹbọ Jésù ló ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àánú Ọlọ́run yìí. (Sáàmù 103:13, 14) Ní àkókò yíyẹ, ìbínú Jèhófà máa ń rọlẹ̀, ó sì máa ń yọ́nú sáwọn tó bá jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tó ronú pìwà dà, tó sì wá ń fòótọ́ ọkàn sìn ín. (Aísáyà 12:1) Ní ti gidi, Jèhófà kì í ṣe Ọlọ́run onínú fùfù bí kò ṣe Ọlọ́run aláyọ̀, kì í ṣe oníkanra, bí kò ṣe elétíi gbáròyé, ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti oníyọ̀ọ́nú sáwọn tó bá tọ̀ ọ́ wá lọ́nà yíyẹ. (1 Tímótì 1:11) Èyí yàtọ̀ pátápátá sí ìwà àìlójú àánú, ìwà òǹrorò tí wọ́n máa ń sọ pé àwọn òrìṣà àwọn kèfèrí ń hù, tó sì máa ń hàn ní ìrísí àwọn òrìṣà wọ̀nyẹn.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 362]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Òkun Ńlá
Damásíkù
Sídónì
Tírè
ÍSÍRẸ́LÌ
Dánì
Òkun Gálílì
Odò Jọ́dánì
Mẹ́gídò
Ramoti-gílíádì
Samáríà
FILÍSÍÀ
JÚDÀ
Jerúsálẹ́mù
Líbínà
Lákíṣì
Bíá-ṣébà
Kadeṣi-báníà
Òkun Iyọ̀
ÁMÓNÌ
Rábà
MÓÁBÙ
Kiri-hárésétì
ÉDÓMÙ
Bósírà
Téménì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 359]
Kirisẹ́ńdọ̀mù ti fi ẹ̀jẹ̀ rin ilẹ̀ ayé gbingbin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 360]
“A ó sì ká ọ̀run jọ, gẹ́gẹ́ bí ìwé àkájọ”