Ori 15
Amápẹẹrẹ Edomu Ṣẹ, ti Òde-Òní Ni A O Mú Kúrò
1, 2. Oju wo ni Ẹlẹ́dàá fi ń wo awọn orilẹ-ede ti wọn dihamọra gádígádí lọna gigadabu, ki si ni ipinnu Jehofa, ní ibamu pẹlu asọtẹlẹ Isaiah?
LONII ayé tubọ ń dihamọra gádígádí lọna gigadabu sii ju ti ìgbàkígbà ri lọ. Awọn ohun ija alagbara atọmiki tí awọn orilẹ-ede ní ti wa di idayafoni ẹlẹrujẹjẹ gidi si iwalaaye iran eniyan. Oju wo, nigba naa, ni Ẹlẹ́dàá idile iran eniyan, Jehofa Ọlọrun, fi ń wo ipo ọran naa? Eyi ni a sọ kedere ninu ori 34 ti asọtẹlẹ Isaiah, eyi ti ó bẹrẹ pẹlu awọn ọ̀rọ̀ wọnyi:
2 “Sunmọtosi, ẹyin orilẹ-ede lati gbọ́, tẹtisilẹ ẹyin eniyan, jẹ́ ki ayé gbọ́, ati ẹkun rẹ̀; ayé ati ohun gbogbo ti ó ti inu rẹ̀ jade. Nitori ibinu Oluwa ń bẹ lara gbogbo orilẹ-ede, ati irunu rẹ̀ lori gbogbo ogun wọn: o ti pa wọn run patapata, o si ti fi wọn fun pipa. Awọn ti a pa ninu wọn ni a o si ju sode, òórùn wọn yoo ti inu oku wọn jade, awọn oke nla yoo sì yọ́ nipa ẹjẹ wọn. Gbogbo awọn ogun ọ̀run ni yoo di yíyọ́, a o si ká awọn ọ̀run [awọn ijọba eniyan alaigbeṣẹ] jọ bii takada, gbogbo ogun wọn yoo si ṣubu lulẹ, bi ewe ti í bọ kuro lara ajara, ati bi bibọ eso lara igi ọpọtọ.” (Isaiah 34:1-4) Asọtẹlẹ bibanilẹru kan niti gidi!
3. (a) Ki ni a kesi awọn orilẹ-ede lati fetisilẹ si, eesitiṣe ti Jehofa fi pẹlu ẹtọ paṣẹ fun wọn lọna bẹẹ? (b) Ki ni fihan pe awọn orilẹ-ede ko tii fetisilẹ?
3 Ẹlẹ́dàá agbaye ní ariyanjiyan kan pẹlu awọn orilẹ-ede lonii. Idi niyẹn ti a fi kesi awọn orilẹ-ede lati fetisilẹ si ihin-iṣẹ ti a gbeka Bibeli ti oun ti ń mu ki a polongo rẹ̀ kárí-ayé lati 1919 wá. Wọn gbọdọ fetisilẹ si ohun ti oun nilati sọ nipasẹ awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Ṣugbọn iṣàn awọn iṣẹlẹ inu ayé fihan pe wọn ko tii ṣe bẹẹ, awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ni awọn orilẹ-ede kò ka si, awọn ti wọn yan Iparapọ Awọn Orilẹ-Ede dipo Ijọba ti ọ̀run naa ní ọwọ́ Ọmọkunrin rẹ̀, “Ọmọ Alade Alaafia,” naa ti a ti gbeka ori itẹ.
Asọtẹlẹ Isaiah Lodisi Edomu
4, 5. (a) Awọn wo ni awọn ọmọ Edomu, iṣarasihuwa wo ni wọn si fihan si orilẹ-ede arakunrin ibeji wọn, Israeli? (b) Aṣẹ wo ni Jehofa wá tipa bẹẹ pa niti Edomu?
4 Okunfa ipilẹ pato kan ni o ti ń ṣiṣẹ laaarin ẹgbẹ awọn orilẹ-ede lonii. Ohun ipilẹ naa ni a fi orilẹ-ede Edomu ṣe apẹẹrẹ rẹ̀, eyi ti a mẹnuba ní pato ninu asọtẹlẹ yii. Awọn ọmọ Edomu jẹ́ atọmọdọmọ Esau, ẹni ti ó ta ogun ibi rẹ̀ fun arakunrin rẹ̀ ibeji, Jakọbu, fun “akara ati ipẹtẹ lentile.” Nigba iṣẹlẹ yẹn ni a bẹrẹsii pe Esau ni Edomu, eyi ti ó tumọsi “Pupa.” (Genesisi 25:24-34) Nitori pe Jakọbu fi èrú gba ogun ibi oniyebiye rẹ̀, Esau wá kun fun ikoriira si arakunrin rẹ̀ ibeji. Edomu wá di ọta aláìṣeé-tù-lójú fun orilẹ-ede Israeli igbaani, tabi Jakọbu, bi o tilẹ jẹ pe awọn orilẹ-ede arakunrin ibeji ni wọn. Nitori ikoguntini yii lodisi awọn eniyan Ọlọrun, Edomu fa irunu ti ó tọ si i lati ọdọ Jehofa, Ọlọrun Israeli sori araarẹ̀, Oun si paṣẹ ikekuro ayeraye fun Edomu. Ipinnu atọrunwa yii ni a tò lẹsẹẹsẹ ninu awọn ọ̀rọ̀ wolii Isaiah:
5 “Nitori ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kiyesi i, yoo sọkalẹ wá sori Idumea [“Edomu,” NW], ati sori awọn eniyan ègún mi, fun idajọ. Idà Oluwa kun fun ẹ̀jẹ̀, a mú un sanra fun ọ̀rá, ati fun ẹ̀jẹ̀ ọdọ-agutan ati ewurẹ, fun ọ̀rá eree agbo, nitori Oluwa ní irubọ kan ní Bosra [ilu-nla Edomu ti ó lokiki julọ], ati ipakupa nla kan ní ilẹ Idumea.”—Isaiah 34:5, 6.
6. (a) Eeṣe ti Jehofa fi lè sọrọ nipa gbigbe “idà” rẹ̀ lodisi Edomu “ni ọ̀run”? (b) Nigba ti Babiloni kọlu ijọba Juda, iṣarasihuwa alainifẹẹ ẹni wo ni Edomu fihan si awọn eniyan Jehofa?
6 Ilẹ orilẹ-ede Edomu oniwa apaniyan ni a gbọdọ rin gbingbin pẹlu ẹ̀jẹ̀ araawọn funraawọn nipasẹ “idà” Jehofa. Edomu ni a tẹ̀dó sori agbegbe oloke okuta giga kan. (Jeremiah 49:16) Nitori naa nipa mimu ki ipakupa kan ṣẹlẹ ní ilẹ yẹn, Jehofa lè sọ ọ lọna alaworan pe oun ń gbé idà idajọ oun “ni ọ̀run.” Edomu jẹ́ alagbara nla ninu iṣẹ ologun, ẹgbẹ ogun rẹ̀ a sì maa pòyì yika awọn oke olokuta rẹ̀ giga fiofio lati daabobo orilẹ-ede naa lodisi awọn agboguntini. Nitori naa o ṣe deedee lati pe ẹgbẹ ogun Edomu ní “ogun ọ̀run.” Ṣugbọn Edomu alagbara kò pese iranlọwọ kankan fun orilẹ-ede ibeji rẹ̀, Israeli, nigba ti awọn ẹgbẹ ogun Babiloni kọlu u. Kaka bẹẹ, Edomu yọ ayọ̀ lati ri ibilulẹ ijọba Juda ti ó tilẹ tun fun awọn oluparun rẹ̀ ní iṣiri paapaa. (Orin Dafidi 137:7) Iwa ọ̀dàlẹ̀ Edomu tilẹ rìn jinna debi lilepa awọn ẹnikọọkan ti ń sa asala fun ẹmi wọn ti ó si ń fa wọn lé ọta lọwọ. (Obadiah 10-14) Awọn ọmọ Edomu pete lati jogun orilẹ-ede ti awọn ọmọ Israeli ti sa fi silẹ, ní sisọrọ iyangan lodisi Jehofa.—Esekieli 35:10-15.
7. Oju wo ni Ọlọrun Israeli fi wo iwa ọ̀dàlẹ̀ orilẹ-ede Edomu?
7 Njẹ Jehofa, Ọlọrun Israeli igbaani, ha gbojufo ihuwa alainifẹ-ẹni tí awọn ọmọ Edomu hu si awọn eniyan ayanfẹ rẹ̀ bi? Bẹẹkọ. Idi niyẹn ti ọkan-aya Ọlọrun fi pète “ọjọ ẹsan” ati “ọdun isanpada” kan lati lè sẹsan ohun ti a ti fi irira arankan ṣe si ètò-àjọ rẹ̀ ori ilẹ̀-ayé, ti a ń pè ní Sioni. Asọtẹlẹ naa wi pe: “Nitori ọjọ ẹsan Oluwa [“Jehofa,” NW] ni, ati ọdun isanpada, nitori ọran [niwaju Ile-Ẹjọ Agbaye] Sioni.”—Isaiah 34:8; Esekieli 25:12-14.
8. (a) Ta ni Jehofa lò lati mú ijiya wá sori Edomu? (b) Ki ni wolii Obadiah sọtẹlẹ nipa Edomu?
8 Ko pẹ pupọ lẹhin iparun Jerusalemu, ti Jehofa bẹrẹsii fi igbẹsan ododo rẹ̀ hàn lori awọn ọmọ Edomu nipasẹ Nebukadnessari, ọba Babiloni. (Jeremiah 25:8, 15, 17, 21) Nigba ti ẹgbẹ ogun Babiloni gbé igbesẹ lodisi Edomu, ko si ohun ti ó lè gba awọn ọmọ Edomu silẹ! Ẹgbẹ ogun Babiloni ta awọn ọmọ Edomu lokiti lati awọn ibi giga oke olokuta wọn. O jẹ́ “ọdun isanpada” kan lori Edomu. Bi Jehofa ti sọ tẹ̀lẹ́ nipasẹ wolii miiran pe: “Nitori iwa ipa si Jakọbu arakunrin rẹ itiju yoo bò ọ́, a o si ke ọ kuro titilae. . . . Bi iwọ ti ṣe, bẹẹ ni a o si ṣe si ọ: ẹsan rẹ yoo si yipada sori araarẹ.”—Obadiah 10, 15.
9. Ta ni amápẹẹrẹ Edomu ṣẹ ti ode-oni, eesitiṣe?
9 Eyi pẹlu ṣe ifihan iṣarasihuwa Jehofa si amápẹẹrẹ Edomu ṣẹ ti ode-oni. Ta ni yẹn? O dara, ní ọrundun ogun tiwa yii, ta ni ó ti jẹ́ òléwájú ninu pipẹgan ati ṣiṣe inunibini si awọn iranṣẹ Jehofa? Kii ha ṣe Kristẹndọm apẹhinda nipasẹ ẹgbẹ alufaa onigberaga rẹ̀ ni bi? Bẹẹni! Kristẹndọm, ilẹ-ọba eke isin Kristian, ti gbé araarẹ̀ ga sori awọn ibi giga oke olokuta ninu awọn alamọri ayé yii. Oun jẹ́ apa giga fiofio kan ninu iṣetojọ awọn nǹkan ti iran eniyan, ti eto isin rẹ̀ si jẹ́ apa titobi julọ ninu Babiloni Nla. Ṣugbọn Jehofa ti paṣẹ “ọdun isanpada” kan lodisi amápẹẹrẹ Edomu ṣẹ ti ode-oni, fun iṣiwahu biburu lékenkà lodisi awọn eniyan rẹ̀, awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀.
Ìgbẹ̀hìn kan Bii Ti Edomu
10. Bawo ni Isaiah 34:9, 10 ṣe ṣapejuwe ìgbẹ̀hìn Edomu, ṣugbọn ta ni asọtẹlẹ naa kàn lonii?
10 Bi a ti ń kiyesi apa yooku asọtẹlẹ Isaiah yii, a lè ní Kristẹndọm ti òní lọ́kàn: ‘Odò rẹ̀ ni a o si sọ di ọ̀dà, ati ekuru rẹ̀ di imi ọjọ; ilẹ rẹ̀ yoo si di ọ̀dà ti ń jona. A ki yoo pa a ní oru tabi ní ọsan; èéfín rẹ̀ yoo goke laelae.’ (Isaiah 34:9, 10) Ilẹ Edomu ni a wá fihan bayii bi eyi ti ó ń di yiyangbẹ debi pe awọn afonifoji olomi rẹ̀ dabi ẹni pe ọ̀dà ń ṣàn ninu rẹ̀ ati bi ẹni pe imi ọjọ ni awọn ekuru rẹ̀, ati lẹhin naa ti a wa tinabọ awọn eroja amunajo wọnyi.—Fiwe Ìfihàn 17:16.
11, 12. Lati inu apejuwe alasọtẹlẹ ti a funni ninu Isaiah 34:10-15, ki ni yoo ṣẹlẹ si ilẹ Edomu, yoo si ti pẹ tó ti ilẹ naa yoo fi maa wà ninu iru ipo bẹẹ?
11 Asọtẹlẹ Isaiah ń baa lọ pe: “Yoo dahoro lati iran de iran; ko si ẹnikan ti yoo la a kọja lae ati laelae. Ṣugbọn ẹyẹ ofú ati akala ni yoo ni in; ati owiwi ati ìwò ni yoo maa gbe inu rẹ̀: oun o si na okun iparun sori rẹ̀, ati okuta òfo. Niti awọn ijoye rẹ̀ ẹnikan ki yoo si nibẹ ti wọn o pe wá si ijọba, gbogbo awọn olori rẹ̀ yoo si di asan. Ẹgun yoo si hu jade ninu afin rẹ̀ wọnni, ẹgun ọgan ninu ilu olodi rẹ̀: yoo jẹ́ ibugbe awọn dragoni, ati agbala fun awọn owiwi. Awọn ẹran iju ati awọn ọwawa ni yoo pade, ati satire [“ẹ̀mí-èṣù onírìísí ewúrẹ́,” NW] kan yoo maa kọ si ekeji rẹ̀; iwin [“ẹyẹ aáṣẹ̀rẹ́,” NW] yoo maa gbé ibẹ pẹlu, yoo si ri ibi isinmi fun araarẹ̀. Owiwi yoo tẹ́ itẹ rẹ̀ sibẹ, yoo yín.”—Isaiah 34:10-15.
12 Edomu yoo di ilẹ “òfo” bi a ba sọrọ nipa ti awọn eniyan. Yoo di ahoro pẹlu kiki awọn ẹranko ẹhanna, ẹyẹ, ati ejo ninu rẹ̀. Ipo yiyangbẹ ilẹ yii yoo maa baa lọ, bi Isa 34 ẹsẹ 10 ti wi, “lae ati laelae.” Ki yoo si mimu awọn olugbe rẹ̀ atijọ padabọ.—Obadiah 18.
13. Ki ni ohun ti a sọ tẹ́lẹ̀ fun Kristẹndọm ninu “iwe Jehofa,” ati ki ni, ní pato, ni iwe yii jẹ́?
13 Ẹ wo iru ipo ikaanu bibanilẹru ti eyi yaworan fun ẹlẹgbẹ Edomu ode-oni—Kristẹndọm! O ti fi araarẹ̀ hàn bi ọta kikoro fun Jehofa Ọlọrun, awọn Ẹlẹ́rìí ẹni ti oun ti ṣe inunibini kikankikan si. Nitori naa iparun rẹ̀ yii ti ó rọdẹdẹ ṣaaju Armageddoni ni a ti sọ tẹ́lẹ̀ ninu “iwe Jehofa.” (Isaiah 34:16, NW) Niti pato, “iwe Jehofa” yii ni iwe ijihin rẹ̀, ti ń ṣe itolẹsẹẹsẹ iṣiro ijihin ti oun yoo yanju pẹlu awọn wọnni ti wọn jẹ́ ọta rẹ̀ ati olutẹ awọn eniyan rẹ̀ loriba. Ohun ti a kọ sinu “iwe Jehofa” niti Edomu igbaani ṣẹ, eyi si funni ní idaniloju pe asọtẹlẹ naa bi ó ti kan Kristẹndọm, Edomu ode-oni, yoo ní imuṣẹ bakan naa.
14. Ki ni amápẹẹrẹ awọn ọmọ Edomu ṣẹ ti ode-oni kò tẹwọgba, apẹẹrẹ awọn eniyan Jehofa wo si ni wọn kuna lati tẹ̀lé?
14 Amápẹẹrẹ awọn ọmọ Edomu ṣẹ ti ode-oni kò tii tẹwọgba Jehofa Ọlọrun bi Ọba nigba “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan” isinsinyi. Siwaju sii, niwọn ìgbà ti Kristẹndọm ti jẹ́ apa ti ó tayọjulọ kan bẹẹ ninu Babiloni Nla, a ti ṣedajọ fun un lati ṣajọpin ninu awọn arun rẹ̀. Oun kò tii ṣegbọran si aṣẹ Jehofa naa lati “ti inu” Babiloni Nla “jade.” (Ìfihàn 18:4) Oun kò tii ṣe afarawe apẹẹrẹ ti àṣẹ́kú awọn ọmọ Israeli tẹmi tabi ti “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran.”
15, 16. Ki ni ọjọ-ọla Kristẹndọm ti kò jinna mọ́, bi a ti sọ tẹ́lẹ̀ ninu Ìfihàn 17 ati 18 ati Isaiah 34?
15 Ọjọ-ọla Kristẹndọm ti kò jinna mọ́ pòkúdu niti tootọ. O ń sa gbogbo ipa rẹ̀ lati tu awọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ oloṣelu loju ati lati dí wọn lọwọ ki wọn maṣe korajọ lati gbe igbesẹ onijagidijagan lodisi i, si iparun patapata rẹ̀, ṣugbọn si òtúbáńtẹ́ ni!
16 Ní ibamu pẹlu Ìfihàn ori 17 ati 18, Ọlọrun Olodumare, Jehofa, yoo fi sinu ọkan-aya wọn lati lo agbara oṣelu ati ologun wọn ninu igbegbeesẹ oniwa ẹranko ẹhanna lodisi Babiloni Nla ati gbogbo apa ẹka isin rẹ̀, titikan Kristẹndọm. Eyi yoo fọ àdàmọ̀dì ijọsin Kristian mọ́ kuro ninu gbogbo ilẹ̀-ayé. Ipo Kristẹndọm yoo dabi ipo alainireti ti a ṣapejuwe rẹ̀ ninu Isaiah 34. Kò ní wà larọwọto lati ní iriri àjàkágbá “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare” lodisi awọn orilẹ-ede, awọn ti yoo ti piyẹ́ Babiloni Nla nì. Kristẹndọm, amápẹẹrẹ Edomu ṣẹ, ni a o parẹ patapata kuro lori ilẹ̀-ayé, “lae ati laelae.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 122]
Kristẹndọm yoo gba idajọ ti o farajọ ti awọn ọmọ Edomu, awọn atọmọdọmọ Esau, ti ó ta ogun ibi rẹ̀ fun ounjẹ ẹẹkanṣoṣo pere