-
Párádísè Ti Padà Bọ̀ Sípò!Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
Orílẹ̀-Èdè Tuntun Kan Wáyé
19. Èé ṣe táa fi ní láti sọ pé kìkì ìmúṣẹ tó mọ níwọ̀nba ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa?
19 Lóòótọ́ o, ìmúṣẹ tó mọ níwọ̀nba ni Aísáyà orí karùndínlógójì ní ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Ìgbà kúkúrú làwọn Júù tí wọ́n dá padà wálé fi gbádùn ipò tó dà bíi ti Párádísè. Kò pẹ́ tí àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn èké àti ẹ̀mí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni fi ta àbààwọ́n sí ìsìn tòótọ́. Ni ẹ̀dùn ọkàn àti ìmí ẹ̀dùn nípa tẹ̀mí bá tún bo àwọn Júù. Àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, Jèhófà kọ̀ wọ́n pé wọn kì í ṣe ènìyàn òun mọ́. (Mátíù 21:43) Nítorí pé wọ́n tún gbé ẹ̀mí àìgbọ́ràn wọ̀, ayọ̀ wọn ò wà lọ títí. Gbogbo èyí wá ń fi hàn pé Aísáyà orí karùndínlógójì yóò ṣì tún ṣẹ lọ́nà tó túbọ̀ ga sí i.
20. Ísírẹ́lì tuntun wo ló wáyé ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa?
20 Nígbà tó tákòókò lójú Jèhófà, Ísírẹ́lì mìíràn, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, wáyé. (Gálátíà 6:16) Ìgbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé ló ti palẹ̀ ọ̀nà mọ́ fún dídé Ísírẹ́lì tuntun yìí. Jésù mú ìsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò, ẹ̀kọ́ tó sì ń kọ́ni mú kí omi òtítọ́ tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣàn lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó mú àwọn aláìsàn lára dá nípa ti ara àti nípa tẹ̀mí. Ni igbe ayọ̀ bá tún ta bí pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń bá a lọ. Ọ̀sẹ̀ méje lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù táa ti ṣe lógo, ó dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, àwọn tó sì para pọ̀ jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀ ni àwọn Júù àtàwọn yòókù tí ẹ̀jẹ̀ Jésù tí wọ́n ta sílẹ̀ rà padà, Ọlọ́run sì sọ wọ́n dọmọ rẹ̀ nípa tẹ̀mí, tí wọ́n fi di àbúrò Jésù, táa sì fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n.—Ìṣe 2:1-4; Róòmù 8:16, 17; 1 Pétérù 1:18, 19.
-
-
Párádísè Ti Padà Bọ̀ Sípò!Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
-
-
21. Ní ti ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo la lè kà sí ìmúṣẹ àwọn kan lára ẹ̀ka àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà?
21 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ Aísáyà orí karùndínlógójì, ẹsẹ kẹta nígbà tó ń kọ̀wé sí àwọn tó jẹ́ ara Ísírẹ́lì tẹ̀mí, ó ní: “Ẹ mú àwọn ọwọ́ rírọ̀ jọwọrọ àti àwọn eékún tí ó ti di ahẹrẹpẹ nà ró ṣánṣán.” (Hébérù 12:12) A jẹ́ pé, ó dájú pé ọ̀rọ̀ Aísáyà orí karùndínlógójì ṣẹ lọ́nà kan ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa. Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ fi iṣẹ́ ìyanu lajú àwọn afọ́jú, wọ́n sì ṣí etí àwọn adití ní ti gidi. Wọ́n mú kí “àwọn arọ” rìn, wọ́n sì mú kí àwọn odi máa sọ̀rọ̀. (Mátíù 9:32; 11:5; Lúùkù 10:9) Ní pàtàkì jù lọ, àwọn olódodo bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀sìn èké, wọ́n sì wá ń gbádùn párádísè tẹ̀mí nínú ìjọ Kristẹni. (Aísáyà 52:11; 2 Kọ́ríńtì 6:17) Ọ̀ràn àwọn tó ń rí ọ̀nà àjàbọ́ yìí wá dà bíi tàwọn Júù tó padà wálé láti Bábílónì, wọ́n rí i pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn ní ẹ̀mí àìyẹhùn, ẹ̀mí ìgboyà.—Róòmù 12:11.
22. Báwo ni àwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn tí ń wá òtítọ́ kiri lóde òní ṣe di òǹdè Bábílónì?
22 Ìgbà tiwa yìí wá ńkọ́? Ǹjẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ní ìmúṣẹ mìíràn, tó túbọ̀ kún rẹ́rẹ́, tó sì kan ìjọ Kristẹni òde òní bí? Bẹ́ẹ̀ ni o. Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, iye àwọn tó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tòótọ́ dín kù gan-an ni, tí àwọn èké Kristẹni, ìyẹn “àwọn èpò,” sì gbilẹ̀ láyé. (Mátíù 13:36-43; Ìṣe 20:30; 2 Pétérù 2:1-3) Kódà nígbà tí àwọn olóòótọ́ ọkàn bẹ̀rẹ̀ sí ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára Kirisẹ́ńdọ̀mù ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wá ìsìn mímọ́ gaara, àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ṣì nípa lórí bí wọ́n ṣe lóye Ìwé Mímọ́ sí. Lọ́dún 1914, Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba, ṣùgbọ́n kò pẹ́ sí ìgbà yẹn tí ipò nǹkan fi di ráuràu fún àwọn olóòótọ́ ọkàn tí ń wá òtítọ́ kiri wọ̀nyí. Àsọtẹ́lẹ̀ wá ṣẹ ní ti pé, àwọn orílẹ̀-èdè ‘bá wọn jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn,’ gbogbo ìsapá táwọn Kristẹni olóòótọ́ ọkàn yìí sì ṣe láti wàásù ìhìn rere ni wọ́n tẹ̀ rì. Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n di òǹdè Bábílónì.—Ìṣípayá 11:7, 8.
23, 24. Àwọn ọ̀nà wo lọ̀rọ̀ Aísáyà ti gbà ṣẹ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run látọdún 1919?
23 Àmọ́, àwọn nǹkan yí padà lọ́dún 1919. Jèhófà kó àwọn èèyàn rẹ̀ kúrò nígbèkùn. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí kọ àwọn ẹ̀kọ́ èké tó ti jẹ́ àbààwọ́n nínú ìsìn wọn látẹ̀yìnwá sílẹ̀. Nítorí náà, wọ́n rí ìwòsàn gbà. Wọ́n dẹni tó wà nínú párádísè tẹ̀mí, tó ń bá a lọ láti gbilẹ̀ kárí ayé títí di òní pàápàá. Ni àwọn afọ́jú bá ń kọ́ láti ríran, táwọn adití sì ń kọ́ láti gbọ́ràn nípa tẹ̀mí, ìyẹn ni pé, wọ́n dẹni tó wà lójúfò dáadáa sí ọ̀nà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà ń ṣiṣẹ́, wọ́n ń fìgbà gbogbo rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́. (1 Tẹsalóníkà 5:6; 2 Tímótì 4:5) Níwọ̀n bí àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ti yadi mọ́, wọ́n ń hára gàgà láti “ké jáde,” láti polongo òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn. (Róòmù 1:15) Àwọn tó ti jẹ́ aláìlera, tàbí “arọ” nípa tẹ̀mí, wá di onítara àti aláyọ̀ wàyí. Lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, wọ́n dẹni tó lè “gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe.”
-