-
Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Ilẹ̀ ÌléríIlé-Ìṣọ́nà—1996 | August 15
-
-
Àwọn Òke Kámélì
Orúkọ náà, Kámélì túmọ̀ sí “Ọgbà Igi Eléso.” A fi ọgbà àjàrà, igi ólífì, àti igi eléso ṣe ẹkùn ilẹ̀ ọlọ́ràá tí ó wà ní àríwá yìí, nǹkan bí 50 kìlómítà lóòró, lọ́ṣọ̀ọ́. Mánigbàgbé ni ògo àti ẹwà ṣóńṣó ọ̀wọ́ ilẹ̀ olókè yìí jẹ́. Aísáyà 35:2 sọ̀rọ̀ nípa “ẹwà Kámélì” gẹ́gẹ́ bí àmì ìṣàpẹẹrẹ ògo ìmésojáde ti ilẹ̀ Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀ sípò.
-
-
Àwọn Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Láti Ilẹ̀ ÌléríIlé-Ìṣọ́nà—1996 | August 15
-
-
Àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Kámélì ṣì ní ọgbà igi eléso, igi ólífì, àti àjàrà síbẹ̀. Nígbà ìrúwé, àwọn òdòdó títẹ́ rẹrẹ lọ́nà gíga lọ́lá máa ń bo àwọn gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ wọ̀nyí. Sólómọ́nì sọ fún omidan Ṣúlámáítì pé: “Orí rẹ dà bíi Kámélì lára rẹ,” bóyá tí ó ń dọ́gbọ́n tọ́ka sí bí irun rẹ̀ ti jà yọ̀yọ̀ tó tàbí sí bí orí rẹ̀ tí ó gún régé ti ṣe rèǹtèrente lórí ọrùn rẹ̀.—Orin Sólómọ́nì 7:6.
Ògo ẹwà tí a fi ń dá àwọn òke Kámélì mọ̀, ń rán wa létí ẹwà tẹ̀mí tí Jèhófà ti fi jíǹkí ètò àjọ àwọn olùjọsìn rẹ̀ lónìí. (Aísáyà 35:1, 2) Ní tòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé nínú párádísè tẹ̀mí kan, wọ́n sì gbà pẹ̀lú ojú ìwòye Ọba Dáfídì, tí ó kọ̀wé pé: “Okùn títa bọ́ sọ́dọ̀ mi ní ibi dáradára; lóòótọ́, èmí ní ogún rere.”—Orin Dáfídì 16:6.
-