Ori 16
“Ogunlọgọ Nla” naa Ń Gba “Òpópó” naa Wá Sinu Ètò-Àjọ Ọlọrun Nisinsinyi
1, 2. Nigba wo ni Isaiah ori 35 ní imuṣẹ nipa tẹmi, apejuwe wo si ni awọn ẹsẹ meji akọkọ fun wa?
LAAARIN Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun ti “Ọmọ-Aládé Alaafia,” ọpọ apa pataki ọ̀rọ̀ inu Isaiah ori 35, ti ń ni imuṣẹ nisinsinyi ṣaaju iparun Babiloni Nla, yoo ní iyọrisi niti gidi gan-an lori iran eniyan. Nitori ohun ti a ba ti ṣe aṣeyọri rẹ̀ lọna tẹmi ni a o ṣe aṣeyọri rẹ̀ lọna ti ara dajudaju. Olori imuṣẹ asọtẹlẹ yii nipa tẹmi ti ń ṣẹlẹ lọwọlọwọ nisinsinyi, pẹlu imupadabọsipo awọn iranṣẹ Ọlọrun lati inu igbekun Babiloni Nla. Wolii Isaiah ṣapejuwe rẹ̀ ninu ìlò awọn aṣayan ọ̀rọ̀ wiwuni wọnyi:
2 “Aginju ati ilẹ gbigbẹ yoo yọ̀ fun wọn; iju yoo yọ̀, yoo si tanna bii lili. Ní titanna yoo tanna; yoo si yọ̀ ani pẹlu ayọ̀ ati orin: ogo Lebanoni ni a o fi fun un, ẹwà Karmeli oun Ṣaroni; wọn o ri ogo Oluwa, ati ẹwà Ọlọrun wa.”—Isaiah 35:1, 2.
3. Padasẹhin si ọrundun kẹfa B.C.E., nibo ni ilẹ ti kò ní eso naa wà, bawo ni o si ṣe le yọ̀?
3 Nibo ni awọn aginju ati ilẹ gbigbẹ ati iju aṣalẹ wọnni wa? Ní ọrundun kẹfa B.C.E., wọn wà ni agbegbe ilẹ ijọba Juda. Nigba ti ó maa fi di 537 B.C.E., ilẹ yẹn ni a ti parun di ahoro ti kò si ní awọn olugbe fun 70 ọdun. Ṣugbọn bawo ni aginju kan ṣe le yọ̀? Yoo pọndandan pe ki awọn olugbe inu rẹ̀ tẹlẹri di ẹni ti a ṣinipo pada sinu rẹ̀. A o gbe e ga kuro ninu ipo irẹsilẹ rẹ̀ ki a si fun un ní iyì awọn oke giga ti Lebanoni ti ó dùn ún wò.
Pipese Ọgba Edeni Iṣapẹẹrẹ Kan
4, 5. (a) Nigba wo, ní awọn akoko ode-oni, ni iru iyipada jijọra bẹẹ ti ilẹ kan ti o dahoro ṣẹlẹ, eesitiṣe? (b) Ki ni awọn igbokegbodo imupadabọsipo àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa yọrisi? (c) Bawo ni Isaiah 35:5-7 ṣe ṣapejuwe isọdọtun ipo tẹmi wọn?
4 Ibaradọgba ti ode-oni, lọna tẹmi, ti iyipada ilẹ kan lati inu idahoro ni irisi si ipo kan ti ń fi ẹri imupadabọ si ojurere Jehofa hàn bẹrẹsii ṣẹlẹ ní 1919. Awọn eniyan Jehofa ti a mupadabọ naa ti wá pinnu lati lo anfaani akoko alaafia ti o ṣisilẹ nigba naa de ẹkunrẹrẹ. Kirusi Titobiju naa, Jesu Kristi, ati Baba rẹ̀, Jehofa Ọlọrun, pin iṣẹ titobi bantabanta kan, ti ó ṣe deedee pẹlu atunkọ tẹmpili Jehofa lati ọwọ́ àṣẹ́kù Israeli igbaani ti a mupadabọ si ilẹ̀ wọn lẹhin 537 B.C.E., fun àṣẹ́kù awọn ọmọ Israeli tẹmi ti a dasilẹ lominira. Awọn igbokegbodo imupadabọsipo naa lẹhin 1919 yọrisi pipese ọgba Edeni iṣapẹẹrẹ kan.
5 A ti sọ asọtẹlẹ eyi ninu awọn ọ̀rọ̀ Isaiah ori 35 wọnyi pe: “Nigba naa ni oju awọn afọju yoo là, eti awọn aditi yoo sì ṣí. Nigba naa ni awọn arọ yoo fò bi agbọnrin, ati ahọn odi yoo kọrin: nitori omi yoo tú jade ní aginju, ati iṣàn omi ní iju. Ilẹ yiyan yoo si di abata, ati ilẹ oungbẹ yoo di isun omi; ní ibugbe awọn dragoni, nibi ti olukuluku dubulẹ, ni o jẹ́ ọgba fun eesu oun iyè.”—Isaiah 35:5-7.
6. Ki ni ohun ti wíwànìṣó amápẹẹrẹ Edomu ṣẹ, ti ode-oni kò ṣe ìdènà rẹ̀, awọn wo lonii ni wọn ń fi ayọ̀ kigbe soke papọ pẹlu àṣẹ́kù naa ti a ti mupadabọsipo?
6 Wíwà amápẹẹrẹ Edomu ṣẹ, ti ode-oni kò ṣe ìdènà imupadabọsipo Israeli tẹmi sinu ipo paradise ní imuṣẹ asọtẹlẹ Isaiah ori 35. Nitori naa awọn ọmọ Edomu ode-oni kò ni idi kankan lati yọ ayọ̀ bi àṣẹ́kù Israeli tẹmi ti a mupadabọ ti ń ṣe, ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu awọn “ogunlọgọ nla” ti wọn tubọ ń pọ sii. “Ogunlọgọ nla” naa ní apa titobi kan ní pipa paradise tẹmi ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ode-oni mọ́.
7. Ki ni ohun ti oju imoye àṣẹ́kù naa kò tii fi ìgbà kan rí ríran rẹ̀ ṣaaju 1914, ṣugbọn njẹ a ha la oju wọn ti ó ‘fọ’ bi?
7 Kò si ìgbà kankan ri ṣaaju opin Akoko Awọn Keferi ti oju imoye awọn ọmọ Israeli nipa tẹmi tii ṣí sii lati rii pe ijọngbọn ayé ti yoo bẹsilẹ ní 1914 yoo wá sí ipari pẹlu àṣẹ́kù ninu wọn ti yoo ṣì walaaye nihin-in lori ilẹ̀-ayé sibẹ. Tabi ki wọn rii pe awọn ati “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ni a o ṣojurere si pẹlu anfaani pipese ijẹrii kárí-ayé si igbekalẹ Ijọba Ọlọrun ti Messia naa. Nitori naa o wa ṣẹlẹ pe ní 1919 awọn oju ti o fọ́ nipa tẹmi ti àṣẹ́kù naa ni a là, ẹ si wo iran ọjọ iwaju ti ó sunmọle tan ti awọn oju ti o là wọnyẹn wá loye rẹ̀!
8. Iyọrisi wo ni awọn apejọpọ meji ti a ṣe ní Cedar Point, Ohio, ní lori awọn eti ati ahọn tẹmi ti àṣẹ́kù naa ti a ti mupadabọsipo?
8 Ní awọn apejọpọ wọn ní Cedar Point, Ohio, ní 1919 ati ní 1922, wọn ri awọn isọfunni diẹ nipa iṣẹ naa ti ó wà niwaju wọn gbà. Wọn muratan lati gba ẹru iṣẹ ti ó wà ni iwaju wọn. Eti wọn tẹmi ni a ṣí si gbigbọ ihin-iṣẹ ti ń dún gbọnmọn-gbọnmọn naa nipa Ijọba Ọlọrun ati aini naa lati polongo rẹ̀. Gẹgẹ bi agbọnrin, wọn fò fẹ̀rẹ̀ lati ṣiṣẹsin bi olujẹrii fun Ijọba naa ti a ti ń gbadura fun tipẹ. Ahọn wọn, ti ó ti yadi titi di igba naa, kigbe jade pẹlu ayọ̀ idunnu nipa Ijọba Messia naa ti ó wà ninu agbara ninu awọn ọ̀run.—Ìfihàn 14:1-6.
9. Lọna tẹmi, bawo ni o ṣe ṣẹlẹ pe omi tú jade ninu aginju?
9 Bẹẹni, ń ṣe ni o dabi ẹni pe omi ti tú jade lati inu agbala ilẹ tẹmi kan ti ó ti fi igba kan ri gbẹ táútáú ti ó si dahoro, ti ó fi wa jẹ́ pe nisinsinyi gbogbo rẹ̀ wá dudu minimini pẹlu itutuyọyọ ti ó pọ̀ yanturu—ti o ṣetan lati mu ipese giga julọ wá. Abajọ ti awọn eniyan Jehofa ti a ti mupadabọsipo fi ń yọ̀ ṣìnkìn ti wọn si ń nimọlara ifunnilokun bii ti agbọnrin ti ń ta pọun pọun goke lọ sori oke! Nitootọ, omi otitọ nipa Ijọba Ọlọrun, ti a ti fidi rẹ̀ mulẹ sọ́wọ́ Jesu Kristi ní 1914, tú yàyà jade pẹlu agbara ti ń bisii, ti ó si ń yọrisi ìtura ńláǹlà.—Isaiah 44:1-4.
“Òpópó” Ìwàmímọ́
10, 11. (a) Ki ni iyipada atunilara yii tumọsi? (b) Oju ọna wo ni àṣẹ́kù naa gbà fi dé paradise tẹmi wọn, bawo si ni Isaiah 35:8, 9 ṣe ṣapejuwe rẹ̀?
10 Ki ni awọn ohun ti a ti mẹnuba wọnyi tumọsi? Eyi: Lakọọkọ àṣẹ́kù naa ati lẹhin naa “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti jade kuro ninu Babiloni Nla ti a si ti sọ wọn di Ẹlẹ́rìí Ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn oju ọna wo ni wọn yoo tọ̀ pada sinu ojurere atọrunwa ki a si kí wọn kaabọ sinu paradise tẹmi? Ń ṣe ni o dabi ẹni pe a ti ṣi oju ọna gbigbooro, ti ó fẹ̀ kan fun wọn lati fi àyè gba ogidigbo awọn ọmọ Israeli ẹlẹmi aṣaaju-ọna lati yan papọ ní iṣọkan lọ si ilẹ ibilẹ wọn ti Ọlọrun fifun wọn. Asọtẹlẹ Isaiah onidunnu fi eyi hàn pe:
11 “Òpópó kan yoo si wà nibẹ, ati ọna kan, a o si maa pe e ní, Ọna ìwàmímọ́; alaimọ ki yoo kọja nibẹ; nitori oun yoo wà pẹlu wọn: awọn èrò ọna naa, bi wọn tilẹ jẹ́ òpè, wọn ki yoo ṣì í. Kinniun ki yoo si nibẹ, bẹẹ ni ẹranko buburu kì yoo gùn ún.”—Isaiah 35:8, 9.
12. Opin Ogun Agbaye I ha wulẹ ṣi “òpópó” silẹ fun àṣẹ́kù naa ní taarata, ki ni o si ṣẹlẹ ní ọjọ kẹrin ọdun 1919?
12 Opin Ogun Agbaye I kò wulẹ ṣi “òpópó” ti ode-oni kan silẹ ní taarata. Mẹjọ ninu awọn oṣiṣẹ orile-iṣẹ Watch Tower Society ṣì wà ní ọgba ẹwọn sibẹ ti iṣẹ ijẹrii naa si falẹ̀ niti gidi gan-an. Ní January 4, 1919, ní ipade ọdọọdun ti Watch Tower Society ní Pittsburgh, Pennsylvania, a dibo yan J. F. Rutherford, aarẹ Society, pada si ipo iṣẹ rẹ̀, laika ifisẹwọn rẹ̀ si, ní idaniloju naa pe oun jẹ́ iranṣẹ alailẹṣẹ fun Ọlọrun Ọga Ogo Julọ.
13, 14. Awọn iṣẹlẹ wo ní 1919 ni o fihan pe òpópó iṣapẹẹrẹ kan ti ṣisilẹ fun àṣẹ́kù naa, awọn wo ni o si ń rìn ní “òpópó” yẹn?
13 Ní March 25, 1919, oun ati awọn ẹlẹwọn ẹlẹgbẹ rẹ̀ meje ni a tusilẹ ti a si dá wọn lare patapata lẹhin naa. Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) ti September 15, 1919, oju-iwe 283, ní irohin oniṣiri naa ninu pe awọn ọfiisi Society ni a o gbe lati Pittsburgh pada si Beteli ti Brooklyn ní 124 Columbia Heights, bẹrẹ lati October 1, 1919. Lẹhin naa, pẹlu ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà (Gẹẹsi) December 15, 1919, itẹjade ẹlẹẹmeji loṣu yii ni a kede pe a tun ń tẹjade ní Brooklyn, New York, lẹẹkan sii.
14 Bayii ni o ṣe jẹ́ pe ní 1919 a ṣi òpópó iṣapẹẹrẹ kan silẹ fun awọn iranṣẹ Ọlọrun onidunnu. Awọn wọnni ti wọn fẹ jẹ́ mímọ́ niwaju Jehofa ni awọn ti wọn ń rìn lori “òpópó” yẹn, “Ọna ìwàmímọ́.” Ẹnikẹni ti kò ba ní gongo ilepa titọ, ero isunniṣe mímọ́, kò jẹ́ gbé ẹsẹ lè ati rin “Ọna ìwàmímọ́” ki o si rí imubọsipo ojurere atọrunwa gbà.
15. Ki ni fi ẹri ti a le fojuri hàn wi pe “ogunlọgọ nla” ti rìn wọ òpópó iṣapẹẹẹrẹ naa?
15 Ní June 1, 1935, ní apejọpọ ní Washington, D.C., 840 ninu awọn “ogunlọgọ nla” ni a baptisi ninu omi, ti wọn si fi ẹri ti a le fojuri hàn pe wọn ti bẹrẹsii ń rìn wọ “òpópó” naa. Nisinsinyi, araadọta ọkẹ wọn ti ń pọ̀ sii ti wọ òpópó naa, ni dídarapọ̀ mọ́ àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo naa ti ń dinku sii niye. Ninu ijumọkẹgbẹpọ alalaafia ti ó gbadunmọni, wọn ń rin papọ nisinsinyi lori “òpópó” naa pẹlu ipinnu naa pe, pẹlu iranlọwọ Ọlọrun Olodumare ninu ọ̀run, ohunkohun ki yoo já iṣọkan wọn.
16. Ni sisọrọ lọna apejuwe, bawo ni o ṣe jẹ́ pe kò si kinniun tabi ẹranko apanijẹ miiran loju òpópó yii?
16 Ni sisọrọ lọna apejuwe, ko si kinniun tabi ẹranko apanijẹ eyikeyii ti a o rí loju òpópó yii. Iyẹn ni pe, kò si ohunkohun ti yoo jẹ gẹgẹ bi ìdènà tabi ti yoo dayafo àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo ati “ogunlọgọ nla” naa. Wọn fi igboya jumọ kẹsẹ sọna naa ti Oludasilẹ wọn, Kirusi Titobiju naa, ṣisilẹ fun wọn nisinsinyi, pẹlu Sioni gẹgẹ bi ibi ti wọn ń rìnrìn-àjò lọ.
17. (a) Bi o tilẹ jẹ pe a ti rìn jinna wọnú “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,” “òpópó” naa ha ṣi wa ní ṣiṣisilẹ bi? (b) Awọn wo ni wọn ń gba “Ọna ìwàmímọ́” naa wọle, bawo ni wọn si ṣe ṣe bẹẹ?
17 Lonii, bi a ti rìn jinna wọnú “ipari eto-igbekalẹ awọn nǹkan,” “òpópó” ti a pese lati ọ̀run wá naa ṣì wà ní ṣiṣisilẹ. Ogidigbo awọn eniyan olumọriri ń gbe ìgbésẹ̀ lori isọfunni naa pe Babiloni Nla ti ṣubu ṣaaju ikọluni Kirusi Titobiju naa, Jesu Kristi. Wọn si ń sá jade kuro ninu rẹ̀, ti wọn si ń gba ọna paradise tẹmi naa, “Ọna ìwàmímọ́” wọle.—Jeremiah 50:8.
18. Bawo ni ẹsẹ ti ó kẹhin ninu Isaiah 35 ṣe ṣapejuwe ipo awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa oluṣotitọ ti isinsinyi, ta ni ọpẹ imuṣẹ asọtẹlẹ yii si lọ sọdọ rẹ̀?
18 Ọwọ́ wọn ń tẹ́ idunnu nla ati ayọ̀ ti kò ṣee ṣapejuwe, gẹgẹ bi ẹsẹ ti o pari Isaiah ori 35 ti sọ ọ pe: “Awọn ẹni irapada Oluwa yoo pada, wọn o wá si Sioni ti awọn ti orin, ayọ̀ ainipẹkun yoo si wà ní ori wọn: wọn o rí ayọ̀ ati inudidun gbà, ikaanu oun imi-ẹdun yoo si fò lọ.” Ikaanu ati imi-ẹdun wọn lori fifi ìgbà kan ri ṣàìwà ní ifohunṣọkan pẹlu Jehofa Ọlọrun ti fò lọ lati 1919. Ikaanu ati imi-ẹdun kò sì tii pada sọdọ awọn Ẹlẹ́rìí oluṣotitọ, onidunnu ti Jehofa. Ọpẹ ni fun Ọlọrun ti ń sọ otitọ naa, Jehofa, ẹni ti ó ti mu asọtẹlẹ didanyinrin ti Isaiah ori 35 ṣẹ lọna ti ó fi yẹ fun iyin!