A Lè Padà Ní Ìgbọ́kànlé!
BÍ ÀÌNÍ ìgbọ́kànlé tí ń gbilẹ̀ lóde òní tilẹ̀ jẹ́ àmì “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” àìní ìgbọ́kànlé tún wà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rúndún sẹ́yìn. (2 Tímótì 3:1) Ó kọ́kọ́ yọjú níbi tí a kò lè retí rẹ̀—ní párádísè. Bíbélì sọ nípa ibẹ̀ pé: “Ọlọ́run gbin ọgbà kan ní Édẹ́nì, síhà ìlà-oòrùn, ibẹ̀ ni ó sì fi ọkùnrin tí ó ti ṣẹ̀dá sí. Nípa báyìí, Jèhófà Ọlọ́run mú kí olúkúlùkù igi tí ó fani mọ́ra ní wíwò, tí ó sì dára fún oúnjẹ hù láti inú ilẹ̀ àti igi ìyè pẹ̀lú ní àárín ọgbà náà àti igi ìmọ rere àti búburú.”—Jẹ́nẹ́sísì 2:8, 9.
Àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e jẹ́ kí a mọ bí èyí ṣe kan àìní ìgbọ́kànlé tí ń gbilẹ̀ lóde òní. A kà pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì gbé àṣẹ yìí kalẹ̀ fún ọkùnrin náà pé: ‘Nínú gbogbo igi ọgbà ni kí ìwọ ti máa jẹ àjẹtẹ́rùn. Ṣùgbọ́n ní ti igi ìmọ̀ rere àti búburú, ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.’” (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17) Ǹjẹ́ Ádámù ní ìdí kankan láti ṣiyèméjì nípa ohun tí Jèhófà sọ?
A kà síwájú pé: “Wàyí o, ejò jẹ́ oníṣọ̀ọ́ra jù lọ nínú gbogbo ẹranko inú pápá tí Jèhófà Ọlọ́run dá. Nítorí náà, ó sọ fún obìnrin náà pé: ‘Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ní tòótọ́, pé Ọlọ́run sọ pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú gbogbo igi ọgbà?’ Látàrí èyí, obìnrin náà sọ fún ejò pé: ‘Àwa lè jẹ nínú àwọn èso igi ọgbà. Ṣùgbọ́n ní ti jíjẹ èso igi tí ó wà ní àárín ọgbà, Ọlọ́run ti sọ pé, “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, rárá, ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn án, kí ẹ má bàa kú.”’ Látàrí èyí, ejò náà sọ fún obìnrin náà pé: ‘Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú. Nítorí Ọlọ́run mọ̀ pé ọjọ́ náà gan-an tí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀ ni ó dájú pé ojú yín yóò là, ó sì dájú pé ẹ̀yin yóò dà bí Ọlọ́run, ní mímọ rere àti búburú.’ Nítorí náà, obìnrin náà rí i pé igi náà dára fún oúnjẹ àti pé ohun kan tí ojú ń yánhànhàn fún ni, bẹ́ẹ̀ ni, igi náà fani lọ́kàn mọ́ra láti wò. Nítorí náà, ó mú nínú èso rẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Lẹ́yìn náà, ó fún ọkọ rẹ̀ ní díẹ̀ pẹ̀lú nígbà tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6.
Nípa ṣíṣàìka ìkìlọ̀ tó ṣe kedere tí Ọlọ́run fún wọn sí, Ádámù àti Éfà fi àìgbọ́kànlé Jèhófà hàn. Wọ́n fara wé ọ̀tá Ọlọ́run, Sátánì, tí ó ti bá Éfà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ejò gidi náà. Sátánì kò ní ìgbọ́kànlé nínú bí Jèhófà ṣe ń ṣàkóso. Nítorí èyí, àti nítorí ọkàn àyà onígbèéraga àti onílèépa ipò títayọ tó ní, ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, ó sì ṣi àwọn ènìyàn lọ́nà láti ṣe bákan náà. Ó mú kí wọ́n ronú pé Ọlọ́run kò ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé.
Kí Ló Yọrí Sí? Ìbátan Tí Kò Dán Mọ́rán
O lè ti kíyè sí i pé, ó máa ń ṣòro fún àwọn tí kì í gbẹ́kẹ̀ lé ẹlòmíràn láti máa báni ṣe ọ̀rẹ́ títí lọ. Publilius Syrus, òǹkọ̀wé ará Látìn ní ọ̀rúndún kìíní ṣááju Sànmánì Tiwa, kọ̀wé pé: “Ìgbọ́kànlé ni ìdè kan ṣoṣo tí ń so ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pọ̀.” Nípa ìṣọ̀tẹ̀ wọn, Ádámù àti Éfà fi hàn pé àwọn kò gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run. Nípa bẹ́ẹ̀, ó dájú pé kò sí ìdí kankan fún Ọlọ́run láti fọkàn tán wọn. Nítorí ìpàdánù ìgbẹ́kẹ̀lé, tàbí ìgbọ́kànlé, àwọn ẹ̀dá ènìyàn kìíní pàdánù ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn pẹ̀lú Ọlọ́run. Kò sí ẹ̀rí kankan pé Jèhófà tún bá wọn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí ó dá wọn lẹ́jọ́ nítorí ìṣọ̀tẹ̀ wọn.
Ìbátan àárín Ádámù àti Éfà pẹ̀lú tún fara gbá a. Jèhófà kìlọ̀ fún Éfà pé: “Inú ìroragógó ìbímọ ni ìwọ yóò ti máa bí àwọn ọmọ, ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ sì ni ìfàsí-ọkàn rẹ yóò máa wà, òun yóò sì jọba lé ọ lórí.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:16) The Jerusalem Bible sọ pé: “Òun yóò máa jẹ gàba lé ọ lórí.” Kàkà kí Ádámù máa fi ìfẹ́ ṣolórí aya rẹ̀, bí Ọlọ́run ti fẹ́, ó wá di ọ̀gá rẹ̀, ó ń jẹ gàba lé e lórí.
Lẹ́yìn tí wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, Ádámù gbìyànjú láti di ẹ̀bi náà ru aya rẹ̀. Èrò tirẹ̀ ni pé, ohun tí obìnrin náà ṣe ló mú kí a lé wọn kúrò nínú ọgbà pípé kan sí ilẹ̀ ayé kan tí a kò ì dá parí, kí wọ́n lè máa ṣẹrú lábẹ́ àwọn ipò tí kò dára, kí wọ́n tó padà sí inú ilẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19) A lè finú wòye pé èyí yóò ti jẹ́ ìdí kan fún ìforígbárí láàárín àwọn méjèèjì. Ó ṣeé ṣe kí Ádámù ti fara ya, ní sísọ pé òun kò ní tẹ́tí sí Éfà mọ́ láé. Ó ṣeé ṣe kí ó ti rò pé ẹjọ́ òun tọ́ láti torí bẹ́ẹ̀ sọ fún Éfà pé, ‘Láti wákàtí ọ̀wọ̀ yìí lọ, èmi lọ̀gá!’ Ní ìhà kejì, Éfà lè ti wò ó pé Ádámù kò kúnjú ìwọ̀n rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, kí ìyẹn sì mú kí ó má lè gbọ́kàn lé e mọ́. Èyí tó wù kó jẹ́, nípa fífi hàn pé àwọn kò gbọ́kàn lé Ọlọ́run, àwọn ẹ̀dá ènìyàn pàdánù ipò ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wọn lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ba ìbátan àárín àwọn fúnra wọn jẹ́.
Ta Ni A Lè Gbẹ́kẹ̀ Lé?
Gbogbo ènìyàn kọ́ ló yẹ ká gbọ́kàn lé, bí àpẹẹrẹ Ádámù àti Éfà ṣe fi hàn. Báwo la ṣe lè mọ ẹni tó yẹ ká gbọ́kàn lé àti ẹni tí kò yẹ yàtọ̀?
Sáàmù 146:3 gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” A sì tún kà ní Jeremáyà 17:5-7 pé: “Ègún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ará ayé, tí ó sì wá fi ẹlẹ́ran ara ṣe apá rẹ̀, tí ọkàn-àyà rẹ̀ sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.” Ní ìhà kejì, “ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí Jèhófà di ìgbọ́kànlé rẹ̀.”
Òtítọ́ ni pé gbígbọ́kànlé ènìyàn kì í fìgbà gbogbo burú. Àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn wulẹ̀ ń sọ kókó náà pé kò sí ìgbà kankan tí gbígbọ́kànlé Ọlọ́run jẹ́ àṣìṣe, ṣùgbọ́n gbígbọ́kànlé àwọn ènìyàn aláìpé lè yọrí sí ìjàǹbá lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tí ń gbẹ́kẹ̀ lé ènìyàn láti ṣe ohun tó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló lè ṣe é—láti gbani là àti láti mú àlàáfíà kíkún àti ààbò wá—yóò ní ìjákulẹ̀.—Sáàmù 46:9; 1 Tẹsalóníkà 5:3.
Ní gidi, bí àwọn ènìyàn àti àwọn àjọ tí wọ́n gbé kalẹ̀ bá ṣe ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ète Ọlọ́run tó, tí wọ́n sì ń lo àwọn ìlànà Ọlọ́run tó, ni ó ṣe yẹ kí a gbọ́kàn lé wọn tó. Nípa bẹ́ẹ̀, bí a bá ní láti sún àwọn ẹlòmíràn láti gbọ́kàn lé wa, a gbọ́dọ̀ máa sọ òtítọ́, kí a má ṣàbòsí, kí a sì ṣeé fọkàn tẹ̀. (Òwe 12:19; Éfésù 4:25; Hébérù 13:18) Bí a bá ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì nìkan ni ìgbẹ́kẹ̀lé tí àwọn ènìyàn ní nínú wa yóò lè bẹ́tọ̀ọ́ mu, tí yóò sì máa fún tọ̀túntòsì ní okun òun ìṣírí.
Pípadà Ní Ìgbọ́kànlé
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìdí fífẹsẹ̀múlẹ̀ láti gbọ́kàn lé Ọlọ́run kí wọ́n sì máa rọ àwọn ẹlòmíràn láti ṣe bákan náà. Jèhófà jẹ́ olóòótọ́ àti adúróṣinṣin, ẹni tí a lè máa fọkàn tẹ̀ nígbà gbogbo pé yóò ṣe ohun tí ó ti sọ, nítorí pé “kò ṣeé ṣe fún Ọlọ́run láti purọ́.” Ìgbọ́kànlé tí a bá ní nínú Ọlọ́run ìfẹ́ kò lè yọrí sí ìjákulẹ̀ láéláé.—Hébérù 6:18; Sáàmù 94:14; Aísáyà 46:9-11; 1 Jòhánù 4:8.
Àwọn ènìyàn tó wà ní ìṣọ̀kan ní gbígbọ́kànlé Jèhófà, tí wọ́n sì ń gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀ ní ìsúnniṣe lílágbára láti ní ìgbọ́kànlé nínú ẹnì kìíní kejì. Ẹ wo bí ó ti múni láyọ̀ tó láti rí àwọn ènìyàn tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nínú ayé kan tí àìní ìgbọ́kànlé ti gbilẹ̀! Ẹ fojú inú wo bí ayé ì bá ti yàtọ̀ tó ká ní a lè gbọ́kàn lé ohun tí ẹlòmíràn bá sọ tàbí tí ó ṣe pátápátá! Bí ipò nǹkan yóò ṣe rí nínú ayé tuntun tí ń bọ̀, tí Ọlọ́run ti ṣèlérí, nìyí. Kò tún ní sí àìní ìgbọ́kànlé mọ́ láéláé!
Ǹjẹ́ ìwọ yóò fẹ́ láti wà láàyè nígbà náà? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pè ọ́ pé kí o fún ìgbọ́kànlé rẹ nínú Ọlọ́run àti àwọn ìlérí rẹ̀ lókun nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa àwọn ohun tí òun fẹ́ kí a ṣe láti wà láàyè. Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń fúnni ní ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń bẹ, pé ire aráyé ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, àti pé yóò ṣe nǹkan láìpẹ́ láti ṣàtúnṣe sí àwọn ìṣòro aráyé, nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti kọ́ láti gbọ́kàn lé Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì. Inú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti fi bí wọ́n ṣe ń kọ́ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ hàn ọ́. O sì lè kọ̀wé sí àwọn tí ń tẹ ìwé ìròyìn yìí jáde láti gba ìsọfúnni síwájú sí i.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Àìgbọ́kànlé Ọlọ́run ń yọrí sí bíba ìbátan àárín àwọn ènìyàn jẹ́
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Bí àwọn ènìyàn bá ṣe ń hùwà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ọlọ́run tó, ni ó ṣe yẹ kí a gbọ́kàn lé wọn tó