MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Kí Lo Máa Ṣe Ní Ọdún Ọ̀gbẹlẹ̀?
Ó ṣe pàtàkì kéèyàn nígbàgbọ́ kó tó lè gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, ìgbàgbọ́ tó lágbára máa jẹ́ ká gbà pé Jèhófà máa dáàbò bò wá, á sì bójú tó wa. (Sm 23:1, 4; 78:22) Bá a ṣe ń sún mọ́ òpin ayé yìí, a mọ̀ pé àwọn àdánwò Sátánì á túbọ̀ máa le sí i. (Ifi 12:12) Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́?
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ KÍ LO MÁA ṢE NÍ ỌDÚN Ọ̀GBẸLẸ̀? KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo la ṣe dà bí “igi” tá a mẹ́nu kàn nínú Jeremáyà 17:8?
Kí ni ọ̀kan lára ohun tó lè dà bí “ooru”?
Kí ló lè ṣẹlẹ̀ sí “igi” náà, kí sì nìdí?
Kí ni Sátánì fẹ́ bà jẹ́?
Báwo la ṣe dà bí àwọn tó ti ń wọkọ̀ òfúrufú tipẹ́?
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fọkàn tán ẹrú olóòótọ́ àti olóye, àmọ́ kí ló lè dán wa wò?
Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán àwọn ìlànà Bíbélì láìka ohun táwọn èèyàn lè máa sọ?