Ìdájọ́ Jehofa Lòdìsí Àwọn Olùkọ́ni Èké
“Èmi ti rí ìríra lára àwọn wòlíì Jerusalemu, wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì rìn nínú èké . . . Gbogbo wọn dàbíi Sodomu níwájú mi, àti àwọn olùgbé rẹ̀ bíi Gomorra.”—JEREMIAH 23:14.
1. Èéṣe tí ẹnìkan tí ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá fi tẹ́wọ́gba ẹ̀rù-iṣẹ́ wíwúwo gidigidi kan?
ẸNIKẸ́NI tí ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá tẹ́wọ́gba ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo gidigidi kan. Jakọbu 3:1 (NW) kìlọ̀ pé: “Kìí ṣe púpọ̀ nínú yín ni ó níláti di olùkọ́, ẹ̀yin arákùnrin mi, ní mímọ̀ pé àwa yóò gba ìdájọ́ tí ó wúwo jù.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọrun wà lábẹ́ ẹrù-iṣẹ́ tí ó túbọ̀ wúwo láti ṣe ìjíhìn tí ó ní ìtẹ́wọ́gbà ju ti àwọn Kristian ní gbogbogbòò lọ. Kí ni èyí yóò túmọ̀sí fún àwọn tí wọ́n fi ẹ̀rí jíjẹ́ olùkọ́ni èké hàn? Ẹ jẹ́ kí a wo bí ipò-ọ̀ràn ti rí ní ọjọ́ Jeremiah. A óò rí bí ó ti ṣàpẹẹrẹ ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lónìí.
2, 3. Ìdájọ́ wo ni Jehofa tipasẹ̀ Jeremiah múwá níti àwọn olùkọ́ni èke Jerusalemu?
2 Ní 647 B.C.E., ọdún kẹtàlá ìjọba Ọba Josiah, a yan Jeremiah sípò gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Jehofa. Jehofa ní ẹ̀sùn kan lòdìsí Juda, nítorí náà ó rán Jeremiah láti kéde rẹ̀. Àwọn wòlíì, tàbí olùkọ́ni èké ní Jerusalemu, ń ṣe “ìríra” ní ojú Ọlọrun. Ìwà-ibi wọn peléke tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí Ọlọrun fi Jerusalemu àti Juda wé Sodomu àti Gomorra. Jeremiah orí 23 sọ fún wa nípa èyí. Ẹsẹ 14 sọ pé:
3 “Èmi ti rí ìríra lára àwọn wòlíì Jerusalemu, wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì rìn nínú èké, wọ́n mú ọwọ́ olùṣé búburú le tóbẹ́ẹ̀, tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀; gbogbo wọn dàbíi Sodomu níwájú mi, àti àwọn olùgbé rẹ̀ bíi Gomorra.”
4. Báwo ni àpẹẹrẹ ìwà búburú àwọn olùkọ́ni Jerusalemu ṣe bá ti Kristẹndọm ṣerẹ́gí lónìí?
4 Bẹ́ẹ̀ni, àwọn wòlíì, tàbí olùkọ́ni wọ̀nyí, ni àwọn fúnraawọn fi àpẹẹrẹ ìwà búburú jáì lélẹ̀ tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fún àwọn ènìyàn náà ní ìṣírí láti ṣe ohun kan náà. Ẹ wo bí àwọn ipò-ọ̀ràn ti rí nínú Kristẹndọm lónìí! Wọ́n kò ha rí gẹ́lẹ́ bíi ti ọjọ́ Jeremiah bí? Lónìí ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà gba àwọn panṣágà àti àwọn abẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ láyè láti wà láàárín wọn àní tí wọ́n tilẹ̀ ń jẹ́ kí wọ́n bójútó àwọn ètò-ìsìn nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Ó ha yanilẹnu nígbà náà pé ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn tí wọ́n forúkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà ṣọ́ọ̀ṣì pẹ̀lú jẹ́ oníwà-pálapàla bí?
5. Èéṣe tí ipò-ọ̀ràn ìwà-pálapàla Kristẹndọm fi búru ju ti Sodomu àti Gomorra lọ?
5 Jehofa fi àwọn olùgbé Jerusalemu wé àwọn ti Sodomu àti Gomorra. Ṣùgbọ́n ipò-ọ̀ràn ìwà-pálapàla Kristẹndọm burú ju ti Sodomu àti Gomorra lọ. Bẹ́ẹ̀ni, ó tilẹ̀ yẹ fún ìbáwí jù ní ojú Jehofa. Àwọn olùkọ́ni rẹ̀ ń tàpá sí òfin ìwàrere ti Kristian. Èyí sì ti ṣokùnfà ipò ìlànà ìwàrere lílọsílẹ̀ nínú èyí tí àwọn ìdẹwò ayọ́kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́ wà lónírúurú láti ṣe ohun tí ó burú. Ipò ìwàhíhù yìí gbalẹ̀kan tóbẹ́ẹ̀ tí a fi ń wo ìwà-ibi gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu lónìí.
‘Rírìn Nínú Ẹ̀kọ́ Èké’
6. Kí ni Jeremiah sọ nípa ìwà búburú àwọn wòlíì Jerusalemu?
6 Nísinsìnyí ẹ jẹ́ kí a kíyèsí ohun tí ẹsẹ 14 sọ nípa àwọn wòlíì Jerusalemu. Wọ́n ń “rìn nínú èké.” Apá tí ó gbẹ̀yìn ẹsẹ 15 sì sọ pé: “Láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalemu ni [ìpẹ̀yìndà, NW] ti jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ náà.” Lẹ́yìn naa, ẹsẹ 16 fikún un pé: “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí: Ẹ máṣe fetí sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún yín: wọ́n sọ yín di asán, wọ́n sọ̀rọ̀ ìran inú araawọn, kìí ṣe láti ẹnu Oluwa.”
7, 8. Èéṣe tí ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà Kristẹndọm fi dàbí àwọn wòlíì èké Jerusalemu, báwo ni èyí sì ti ṣe nípa lórí àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì?
7 Bíi ti àwọn wòlíì èké Jerusalemu, ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà Kristẹndọm pẹ̀lú ń rìn nínú èké, wọ́n ń tan àwọn ẹ̀kọ́ ìpẹ̀yìndà kálẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ tí a kò rí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ èké wọ̀nyí? Àìlèkú ọkàn, Mẹtalọkan, pọ́gátórì, àti iná ọ̀run àpáàdì láti dá àwọn ènìyàn lóró títí ayérayé. Wọ́n tún ń rin etí àwọn olùgbọ́ wọn nípa wíwàásù ohun tí àwọn ènìyàn fẹ́ láti gbọ́. Wọ́n ń sọ ní àsọtúnsọ pé àjálù ibi kankan kò dojúkọ Kristẹndọm nítorí pé ó ní àlàáfíà Ọlọrun. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ń sọ “ìran inú araawọn.” Èké ni. Àwọn wọnnì tí wọ́n gba irú àwọn èké bẹ́ẹ̀ gbọ́ ni a ń fún ní májèlé jẹ́ nípa tẹ̀mí. A ń ṣì wọ́n lọ́nà lọ sí ìparun wọn!
8 Ronú lórí ohun tí Jehofa sọ nípa àwọn olùkọ́ni èké wọ̀nyí ní ẹsẹ 21: “Èmi kò rán àwọn wòlíì wọ̀nyí, ṣùgbọ́n wọ́n sáré: èmi kò bá wọn sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó rí lónìí, Ọlọrun kò rán ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kò fi òtítọ́ rẹ̀ kọ́ni. Kí ni àbájáde rẹ̀? Àìmọ̀kan nípa Bibeli lọ́nà tí ń múni gbọ̀nrìrì wà láàárín àwọn olùreṣọ́ọ̀ṣì nítorí pé àwọn òjíṣẹ́ wọn ń fi ọgbọ́n èrò-orí ayé bọ́ wọn.
9, 10. (a) Irú àwọn àlá wo ni àwọn olùkọ́ni èké Jerusalemu lá? (b) Báwo ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà Kristẹndọm ṣe kọ́ni ní irú “àlá èké” kan náà?
9 Síwájú síi, ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà tòní ń tan ìrètí èké kálẹ̀. Ṣàkíyèsí ẹsẹ 25: “Èmi ti gbọ́ èyí tí àwọn wòlíì sọ, tí wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ mi pé, Mo lá àlá! mo lá àlá!” Irú àlá wo ni? Ẹsẹ 32 sọ fún wa pé: “Èmi dojúkọ àwọn tí ó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ àlá èké, ni Oluwa wí, tí wọ́n sì ń rọ́ wọn, tí wọ́n sì mú ènìyàn mi ṣìnà nípa èké wọn, àti nípa ìran wọn: ṣùgbọ́n èmi kò rán wọn, èmi kò sì pàṣẹ fún wọn: nítorí náà, wọn kì yóò ran àwọn ènìyàn yìí lọ́wọ́ rárá, ni Oluwa wi.”
10 Àwọn àlá, tàbí ìrètí èké wo ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti fi kọ́ni? Họ́wù, pé Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ni ìrètí kanṣoṣo tí ènìyàn ní fún àlàáfíà àti àìléwu lónìí. Ní àwọn ọdún ẹnu àìpẹ́ yìí, wọ́n ti pe Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ní “ìrètí ìkẹyìn fún ìṣọ̀kan àti àlàáfíà,” “ojúkò gíga jùlọ fún àlàáfíà àti ìdájọ́ òdodo,” “olórí ìrètí ti lọ́ọ́lọ́ọ́ fún àlàáfíà ayé.” Ẹ̀tàn yìí mà ga o! Ìjọba Ọlọrun ni ìrètí kanṣoṣo fún aráyé. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà kò wàásù bẹ́ẹ̀ni wọn kò sì kọ́ni ní òtítọ́ nípa ìjọba ọ̀run yẹn, èyí tí ó jẹ́ olórí ẹṣin-ọ̀rọ̀ ìwàásù Jesu.
11. (a) Ipa búburú wo ni àwọn olùkọ́ni èké ní Jerusalemu ní lórí orúkọ Ọlọrun fúnraarẹ̀? (b) Ní ìyàtọ̀ sí ẹgbẹ́ Jeremiah, kí ni àwọn olùkọ́ni ìsìn èké òde-òní ti ṣe nípa orúkọ Ọlọrun fúnraarẹ̀?
11 Ẹsẹ 27 sọ pupọ síi fún wa. “Wọ́n ń rò láti mú kí ènìyàn mi kí ó gbàgbé orúkọ mi nípa àlá wọn tí wọ́n ń rọ́, ẹnìkínní fún ẹnìkejì rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn ti gbàgbé orúkọ mi nítorí Báálì.” Àwọn wòlíì èké Jerusalemu mú kí àwọn ènìyàn náà gbàgbé orúkọ Ọlọrun. Àwọn olùkọ́ni ìsìn èké lónìí kò ha ti ṣe ohun kan náà bí? Èyí tí ó tilẹ̀ burú jù, wọ́n fi Jehofa, orúkọ Ọlọrun, pamọ́. Wọ́n kọ́ni pé kò pọndandan láti lò ó, wọ́n sì yọ ọ́ kúrò nínú àwọn ìtumọ̀ Bibeli wọn. Wọ́n ń fi tagbáratagbára tako ẹnikẹ́ni tí ó bá ń kọ́ àwọn ènìyàn pé Jehofa ni orúkọ Ọlọrun. Ṣùgbọ́n ẹgbẹ́ Jeremiah, àṣẹ́kù àwọn Kristian ẹni-àmì-òróró, papọ̀ pẹ̀lú àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ti ṣe gan-an gẹ́gẹ́ bí Jesu ti ṣe. Wọ́n ti kọ́ àràádọ́ta-ọ̀kẹ́ ènìyàn nípa orúkọ Ọlọrun.—Johannu 17:6.
Títú Ìwà Ìbàjẹ́ Wọn Fó
12. (a) Èéṣe ti ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ fi wà lórí àwọn olùkọ́ni ìsìn èké? (b) Ipa wo ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti kó nínú àwọn ogun àgbáyé méjì?
12 Ẹgbẹ́ Jeremiah ti tú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà fó léraléra pé wọ́n jẹ́ àwọn olùkọ́ni èké tí ń da àwọn agbo wọn gba ojú ọ̀nà gbòòrò tí ó lọ sí ìparun. Bẹ́ẹ̀ni, àwọn àṣẹ́kù náà ti mú kí ìdí tí àwọn alálàá wọnnì fi yẹ fún ìdájọ́ mímúná Jehofa ṣe kedere. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìránṣẹ́ Jehofa ti fìgbà gbogbo tọ́kasí Ìfihàn 18:24, tí ó sọ pé nínú Babiloni Ńlá ni a gbé rí ẹ̀jẹ̀ “gbogbo àwọn tí a pa lórí ilẹ̀-ayé.” Ronú nípa gbogbo ogun tí a ti jà nítorí àwọn aáwọ̀ ìsìn. Ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lọ́rùn àwọn olùkọ́ni ìsìn èké mà pọ̀ o! Àwọn ẹ̀kọ́ wọn ti fa ìyapa, wọ́n sì ti mú kí ìkórìíra àwọn wọnnì tí ìgbàgbọ́ àti orílẹ̀-èdè wọn yàtọ̀síra pọ̀ síi. Nípa Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní ìwé náà Preachers Present Arms sọ pé: “Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ni wọ́n fún ogun náà ní ìjẹ́pàtàkì tẹ̀mí àti ìsúnniṣe alágbára rẹ̀ lọ́nà gbígbóná janjan. . . . Ṣọ́ọ̀ṣì tipa báyìí ri araarẹ̀ bọ inú ètò ogun náà pátápátá.” Ohun kan náà ni ó ṣẹlẹ̀ nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ṣètìlẹ́yìn ní kíkún fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ń jagun wọ́n sì gbàdúrà fún àwọn ọmọ-ogun wọn. Àwọn ogun àgbáyé méjèèjì bẹ̀rẹ̀ ní Kristẹndọm nínú èyí tí àwọn mẹ́ḿbà ìsìn kan náà ti ń pa araawọn lẹ́nìkínní kejì ní ìpakúpa. Àwọn ẹgbẹ́-ìyapa ti ayé ati ti ìsìn láàárín Kristẹndọm ń báa lọ láti fa ìtàjẹ̀sílẹ̀ títí di ìsinsìnyí. Àbájáde ẹlẹ́rùjẹ̀jẹ̀ yìí láti inú ẹ̀kọ́ èké wọn mà ga o!
13. Báwo ni Jeremiah 23:22 ṣe fi ẹ̀rí hàn pé ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà Kristẹndọm kò ni ipò-ìbátan kankan pẹ̀lú Jehofa?
13 Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí Jeremiah orí 23, ẹsẹ 22: “Ìbáṣepé wọ́n dúró [nínú awujọ oníbàátan tímọ́tímọ́, NW] mi, wọn ìbá jẹ́ kí ènìyàn mi kí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, nígbà náà ni wọn ìbá yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn, àti kúrò nínú búburú ìṣe wọn.” Kání àwọn wòlíì ìsìn Kristẹndọm dúró nínú àwùjọ oníbàátan tímọ́tímọ́ ti Jehofa ni, nínú ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀ bí ẹni pé wọ́n jẹ́ olùṣòtítọ́ àti ọlọ́gbọ́n-inú ìránṣẹ́, nígbà náà, àwọn pẹ̀lú ìbá máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n Ọlọrun. Àwọn pẹ̀lú ìbá ti mu kí àwọn ènìyàn Kristẹndọm gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun fúnraarẹ̀. Dípò èyí, àwọn olùkọ́ni èké òde-òní ti sọ àwọn ọmọlẹ́yìn wọn di afọ́jú ìránṣẹ́ Elénìní Ọlọrun, Satani Eṣu.
14. Títú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà Kristẹndọm fó lọ́nà lílágbára wo ni a tẹ̀jáde ní 1958?
14 Títú ti ẹgbẹ́ Jeremiah tú ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà fó lágbára púpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, ní Àpéjọpọ̀ Àgbáyé Ìfẹ́ Àtọ̀runwá ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti 1958 ní New York City, igbákejì ààrẹ Watch Tower Society sọ ọ̀rọ̀ kan tí apákan rẹ̀ wí pé: “Láìsí àní-àní tàbí iyèméjì kankan àwa sọ gbangba pé gbòǹgbò tí ó wà nídìí ọ̀ràn náà tí ń fa gbogbo ìwà ìrúfin, ìwà ìbàjẹ́, ìkórìíra, ìjà, ìlara, . . . àti ìdàrúdàpọ̀ tí kò ṣeé kápá ni ìsìn tí kò tọ̀nà, ìsìn èké; èyí ti Satani Èṣù, ọ̀tá ènìyàn ti a kò fojúrí wà lẹ́yìn rẹ̀. Àwọn ènìyàn tí wọ́n ni ẹrù-iṣẹ́ púpọ̀ jùlọ láti dáhùn fún ipò ti ayé wà ni àwọn olùkọ́ni àti àwọn aṣáájú ìsìn; àwọn tí ó sì yẹ ní bíbáwí púpọ̀ jùlọ láàárín wọn ni àwọn àlùfáà ìsìn Kristẹndọm. . . . Lẹ́yìn gbogbo ọdún wọ̀nyí láti ìgbà Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, Kristẹndọm ti wà nínú ipò ìbátan pẹ̀lú Ọlọrun gẹ́gẹ́ bíi ti Israeli ní ọjọ́ Jeremiah. Bẹ́ẹ̀ni, arabaríbí ìparun àfọ́bàjẹ́ tí ó banilẹ́rù èyí tí ó tóbi ju irú èyí tí Jeremiah rí tí ó ṣẹlẹ̀ ní Jerusalemu àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀ ni ó dúró de Kristẹndọm nísinsìnyí.”
Ìdájọ́ Àwọn Olùkọ́ni Èké
15. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà wo ni ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti sọ? Wọn yóò ha ní ìmúṣẹ bí?
15 Láìka ìkìlọ̀ yìí sí, báwo ni ìwà ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti rí láti ìgbà náà wá? Bí ẹsẹ̀ 17 ti ròyìn gẹ́lẹ́ ni ó rí: “Wọ́n wí síbẹ̀ fún àwọn tí ó ń gàn mí pé, Oluwa ti wí pé, Àlàáfíà yóò wà fún yín; wọ́n sì wí fún olúkúlùkù tí ó ń rìn nípa agídí ọkàn rẹ̀: pé, kò sí ibi kan tí yóò wá sórí yín.” Òtítọ́ ha ni èyí bí? Bẹ́ẹ̀kọ́! Jehofa yóò tú èké àwọn àsọtẹ́lẹ̀ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà wọ̀nyí fó. Òun kì yóò mú ohun tí wọ́n ń sọ ní orúkọ rẹ̀ ṣẹ. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹ̀tàn gbáà ni ìmúdánilójú èké ti níní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọrun tí ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà sọ!
16. (a) Kí ni ipò ìwàhíhù ayé yìí, àwọn wo ni wọ́n sì ni ẹ̀bi rẹ̀? (b) Kí ni ẹgbẹ́ Jeremiah ń ṣe nípa ojú-ìwòye ìwàhíhù jíjẹrà ti ayé yìí?
16 Ìwọ ha ń ronú pé, ‘Kínla, pé a ti fi ẹ̀kọ́ èké láti ọwọ́ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà tàn mí jẹ kẹ̀? Kí a má ri!’ Ó dára, máṣe dá araàrẹ lójú ju bí ó ti yẹ lọ! Rántí pé ẹ̀kọ́ èké láti ọwọ́ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà ti gbé àwọn ipò eléwu níti ìwàhíhù, ayọ́kẹ́lẹ́-ṣọṣẹ́ lárugẹ. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ohun gbogbo pátá ni àwọn ẹ̀kọ́ onígbọ̀jẹ̀gẹ́ wọ́n dáláre, bí ó ti wù kí ó jẹ́ oníwà àìmọ́ tó. Ipò jíjẹrà yìí níti ìwàhíhù sì gbodekan nínú gbogbo pápá àwọn eré-ìnàjú, àwòrán sinimá, tẹlifíṣọ̀n, àwọn ìwé ìròyìn, àti orin. Nígbà náà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra gidi gan-an, kí a má baà ṣubú sábẹ́ agbára ìdarí ipò ìwàhíhù jíjẹrà tí ó rọra ń dọ́gbọ́n fanimọ́ra yìí. A lè dẹkùn mú àwọn ọ̀dọ́ nínú àwọn fídíò àti orin tí ń sọnidìbàjẹ́. Rántí pé ẹ̀mí ìgbàgbàkugbà yìí tí àwọn ènìyàn ní lónìí jẹ́ àbájáde tààràtà láti inú ẹ̀kọ́ èké ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà àti ìkùnà wọn láti gbé àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n òdodo Ọlọrun lárugẹ. Ẹgbẹ́ Jeremiah ń gbógunti àwọn ojú-ìwòye oníwà pálapàla wọ̀nyí ó sì ń ran àwọn ìránṣẹ́ Jehofa lọ́wọ́ láti ṣá ìwà búburú tí Kristẹndọm ń rì sí nínú tì.
17. (a) Gẹ́gẹ́ bí Jeremiah ti sọ, irú ìdájọ́ wo ni yóò wá sórí Jerusalemu búburú? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Kristẹndọm láìpẹ́?
17 Irú ìdájọ́ wo ni àwọn olùkọ́ni èké Kristẹndọm yóò rí gbà lọ́dọ̀ Jehofa, Onídàájọ́ ńlá náà? Ẹsẹ 19, 20, 39, àti 40 dáhùn pé: “Sá wò ó, afẹ́fẹ́-ìjì Oluwa! ìbínú ti jáde! àfẹ́yíká ìjì yóò ṣubú ní ìkanra sí orí àwọn olùṣe búburú: Ìbínú Oluwa kì yóò padà, títí yóò fi ṣe é, títí yóò sì fi mú ìrò inú rẹ̀ ṣẹ. . . . Èmi ó gbàgbé yín pátápátá, èmi ó sì kọ̀ yín sílẹ̀, èmi ó sì tì yín jáde, àti ìlú tí mo fi fún yín àti fún àwọn baba yín, kúrò níwájú mi. Èmi ó sì mú ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun wá sórí yín, àti ìtìjú láéláé, tí a kì yóò gbàgbé.” Gbogbo ìyẹn ṣẹlẹ̀ sí Jerusalemu oníwà burúkú àti tẹ́ḿpìlì rẹ̀, irú àjálù kan náà kò ní pẹ́ jálu Kristẹndọm oníwà burúkú nísinsìnyí!
Kíkéde “Ẹrù-Ìnira Jehofa”
18, 19. Kí ni “ẹrù-ìnira Jehofa” tí Jeremiah kéde fún Juda, pẹ̀lú àwọn ìtumọ̀ wo sì ni?
18 Nítorí náà, kí ni ẹrù-iṣẹ́ ẹgbẹ́ Jeremiah àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́pọ̀ wọn? Ẹsẹ 33 (NW) sọ fún wa: “Nígbà tí àwọn ènìyàn tàbí wòlíì tàbí àlùfáà yìí bá bi ọ́ léèrè, ní wíwí pé, ‘Kí ni ẹrù-ìnira Jehofa?’ ìwọ pẹ̀lú gbọ́dọ̀ sọ fún wọn pé, ‘“Ẹ̀yin ènìyàn yìí—óò ẹ ti jẹ́ ẹrù-ìnira tó! Dájúdájú èmi yóò sì pa yín tì,” ni àsọjáde ọ̀rọ̀ Jehofa.’”
19 Ọ̀rọ̀ Heberu náà fún “ẹrù-ìnira” ní ìtumọ̀ alápá méjì. Ó lè tọ́kasí ìkéde àtọ̀runwá títẹ̀wọ̀n tàbí sí ohun kan tí ó rin ẹnìkan mọ́lẹ̀ tí ó sì mú kí ó rẹ̀ ẹ́ pátápátá. Níhìn-ín gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà “ẹrù-ìnira Jehofa” tọ́kasí àsọtẹ́lẹ̀ títẹ̀wọ̀n—ìkéde náà pé a ti dẹ́bi ìparun fún Jerusalemu. Àwọn ènìyàn náà ha fẹ́ láti máa gbọ́ irú àwọn àsọjáde alásọtẹ́lẹ̀ gbankọgbì bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jehofa èyí tí Jeremiah sọ fún wọn léraléra bí? Bẹ́ẹ̀kọ́, àwọn ènìyàn náà fi Jeremiah ṣẹlẹ́yà: ‘Irú àsọtẹ́lẹ̀ (ẹrù-ìnira) wo ni ìwọ ní nísinsìnyí? A mọ̀ dájú pé àsọtẹ́lẹ̀ rẹ yóò jẹ́ ẹrù-ìníra mìíràn tí ń kó àárẹ̀ báni!’ Ṣùgbọ́n kí ni Jehofa sọ fún wọn? Èyí ni ohun tí ó sọ: “Ẹ̀yin ènìyàn yìí—óò ẹ ti jẹ́ ẹrù-ìnira tó! Dájúdájú èmi yóò sì pa yin tì.” Bẹ́ẹ̀ni, àwọn ènìyàn wọ̀nyí jẹ́ ẹrù-ìnira fún Jehofa, òun yóò sì mú wọn kúrò kí wọ́n máṣe tún ni ín lára mọ́.
20. Kí ni “ẹrù-ìnira Jehofa” lónìí?
20 Kí ni “ẹrù-ìnira Jehofa” lónìí? Ó jẹ́ ìhìn-iṣẹ́ alásọtẹ́lẹ̀ wíwúwo láti inú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ó kún fọ́fọ́ fún ègbé, tí ń kéde ìparun Kristẹndọm tí ó rọ̀dẹ̀dẹ̀. Níti àwa ènìyàn Jehofa, a ni ẹrù-iṣẹ́ wíwúwo náà láti kéde “ẹrù-ìnira Jehofa” yìí. Bí òpin ti ń súnmọ́lé, a gbọ́dọ̀ sọ fún gbogbo ènìyàn pé àwọn ènìyàn Kristẹndọm oníwà wíwọ́ jẹ́ “ẹrù-ìnira,” bẹ́ẹ̀ni, “óò wọ́n ti jẹ́ ẹrù-ìnira tó!” fún Jehofa Ọlọrun, àti pé òun yóò gba araarẹ̀ lọ́wọ́ “ẹrù-ìnira” yìí láìpẹ́ nípa kíkọ Kristẹndọm sílẹ̀ fún àjálù ibi.
21. (a) Èéṣe tí a fi pa Jerusalemu run ní 607 B.C.E.? (b) Lẹ́yìn ìparun Jerusalemu, kí ni o ṣẹlẹ̀ sí àwọn wòlíì èké àti àwọn wòlíì tòótọ́ ti Jehofa, ní fífún wa ni ìdánilójú wo lónìí?
21 A mú ìdájọ́ Jehofa ṣẹ ní ọjọ́ Jeremiah nígbà tí awọn ará Babiloni pa Jerusalemu run ní 607 B.C.E. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀, ìyẹn jẹ́ ‘ẹ̀gàn àti ìtìjú’ fún àwọn ọmọ Israeli alágídí, aláìgbàgbọ́ wọnnì. (Jeremiah 23:39, 40) Ó fihàn wọ́n pé Jehofa, tí wọ́n ti kẹ́gàn bá léraléra, ti kọ̀ wọ́n tì fún àwọn àbájáde ìwà ibi wọn nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Àwọn ọ̀yájú wòlíì èké wọn ni a palẹ́numọ́ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Síbẹ̀, ẹnu Jeremiah ń sọtẹ́lẹ̀ nìṣó. Jehofa kò kọ̀ ọ́ tì. Ní títẹ̀lé àwòkọ́ṣe yìí, Jehofa kì yóò pa ẹgbẹ́ Jeremiah tì nígbà tí ìpinnu wíwúwo rẹ̀ bá yọrísí gbígbẹ̀mí àwọn àlùfáà Kristẹndọm àti àwọn wọnnì tí wọ́n gba èké wọn gbọ́.
22. Irú ipò wo ni ìdájọ́ Jehofa yóò mú kí Kristẹndọm wà?
22 Bẹ́ẹ̀ni, irú ipò ahoro, aláìṣeégbé tí Jerusalemu wà lẹ́yìn 607 B.C.E. ni irú ipò náà gẹ́lẹ́ ti Kristẹndọm onísìnkusìn yóò wà lẹ́yìn tí a bá ti gba ọrọ̀ rẹ̀ kúrò ti a sì tú u fó lọ́nà tí ó mútìjúdání. Èyí ni ìdájọ́ títọ́ tí Jehofa ti paláṣẹ lòdìsí àwọn olùkọ́ni èké. Ìdájọ́ yẹn kì yóò kùnà. Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo àwọn ìhìn-iṣẹ́ ìkìlọ̀ onímìísí Jeremiah ti ní ìmúṣẹ ní ìgbà tí ó ti kọjá, bẹ́ẹ̀ náà ni wọn yóò rí nínú ìmúṣẹ wọn ti òde-ìwòyí. Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí a dàbí Jeremiah. Ẹ jẹ́ kí a fi ìgboyà polongo ẹrù-ìnira àsọtẹ́lẹ̀ ti Jehofa fún àwọn ènìyàn, kí wọ́n baà lè mọ ìdí rẹ̀ tí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n ìdájọ́ òdodo rẹ̀ fi ń bọ̀ wá sórí gbogbo àwọn olùkọ́ni ìsìn èké!
Àwọn Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Báwo ni Jerusalemu ìgbàanì ṣe burú tó lójú-ìwòye Jehofa?
◻ Ní àwọn ọ̀nà wo ni Kristẹndọm ti gbà “rìn nínú èké”?
◻ Báwo ni a ti ṣe tú ìwà ìbàjẹ́ ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà òde-òní fó?
◻ Kí ni “ẹrù-ìnira Jehofa” náà tí a ń polongo rẹ̀ nísinsìnyí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwọn wòlíì Jerusalemu ṣe ‘àwọn ohun ìríra’
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
“Wọ́n sọ̀rọ̀ ìran inú araawọn”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Jerusalemu lẹ́yìn tí a pa á run ṣàkàwé ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí Kristẹndọm níkẹyín