Ìṣùpọ̀-Èso—Dídára Àti Búburú
“Sì wò ó, Oluwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mi, . . . Agbọ̀n ìkínní ní èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára jù, gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó tètèkọ́ pọ́n: agbọ̀n èkejì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú jù, tí a kò lè jẹ, bí wọ́n ti burú tó.”—JEREMIAH 24:1, 2.
1. Báwo ni Jehofa ṣe fi ìyọ́nú hàn sí àwọn ènìyàn rẹ̀, Israeli, ṣùgbọ́n báwo ni wọ́n ṣe hùwàpadà?
ỌDÚN náà jẹ́ 617 B.C.E. Ó jẹ́ ọdún mẹ́wàá péré ṣáájú kí a tó mú ìdájọ́ yíyẹ ti Jehofa ṣẹ lòdìsí Jerusalemu àti àwọn ènìyàn rẹ̀. Jeremiah ti ń fi tokunratokunra wàásù fún 30 ọdún. Ṣàkíyèsí àpèjúwe ṣíṣekedere tí Esra ṣe nípa ipò náà gẹ́gẹ́ bí a ti ríi ní 2 Kronika 36:15: “[Jehofa] Ọlọrun àwọn baba wọn sì ránṣẹ́ sí wọn láti ọwọ́ àwọn ońṣẹ́ rẹ̀, ó ń dìde ní kùtùkùtù ó sì ń ránṣẹ́, nítorí tí ó ní ìyọ́nú sí àwọn ènìyàn rẹ̀, àti sí ibùgbé rẹ̀.” Kí sì ni ìyọrísí gbogbo ìsapá yìí? Lọ́nà tí ó baninínújẹ́, Esra ń báa lọ láti ròyìn ní ẹsẹ 16 pé: “Ṣùgbọ́n wọ́n fi àwọn ońṣẹ́ Ọlọrun ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì kẹ́gàn ọ̀rọ̀ rẹ̀, wọ́n sì fi àwọn wòlíì rẹ̀ ṣẹ̀sín, títí ìbínú Oluwa fi ru sí àwọn ènìyàn rẹ̀, tí kò fi sí àtúnṣe.”
2, 3. Ṣàpèjúwe ìran agbaniláfiyèsí tí Jehofa fihan Jeremiah.
2 Èyí ha túmọ̀sí pé orílẹ̀-èdè Juda ni a ó parẹ́ ráúráú bí? Láti rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ kí a gbé ìran ṣíṣe pàtàkì kan, tí a fi han Jeremiah nísinsìnyí tí ó sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí orí 24 nínú ìwé náà tí ń jẹ́ orúkọ rẹ̀ yẹ̀wò. Ọlọrun lo àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì nínú ìran yìí láti ṣàpẹẹrẹ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn májẹ̀mú rẹ̀. Ìwọ̀nyí ni ìṣùpọ̀ èso méjì, dídára àti búburú tí wọ́n yàtọ̀síra gédégédé yóò ṣojú fún.
3 Jeremiah orí 24, ẹsẹ 1 àti 2, ṣàpèjúwe ohun tí wòlíì Ọlọrun rí: “Sì wò ó, Oluwa fi agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì hàn mí, tí a gbé kalẹ̀ níwájú ilé Oluwa, lẹ́yìn ìgbà tí Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mú Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ní ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn olórí Juda, pẹ̀lú àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, àti àwọn alágbẹ̀dẹ, láti Jerusalemu, tí ó sì mú wọn wá sí Babeli. Agbọ̀n ìkínní ní èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára jù, gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó tètèkọ́ pọ́n: agbọ̀n èkejì ní èso ọ̀pọ̀tọ́ tí ó burú jù, tí a kò lè jẹ, bí wọ́n ti burú tó.”
Àwọn Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Dídára Inú Ìran Náà
4. Ìhìn-iṣẹ́ ìtùnú wo ni ìran àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ náà ní fún àwọn ọmọ Israeli olùṣòtítọ́?
4 Lẹ́yìn bíbèèrè lọ́wọ́ Jeremiah nípa ohun tí ó rí, Jehofa ń báa lọ ní sísọ ní ẹṣẹ 5 sí 7 pé: “Gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ dáradára wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó fi ojúrere wo àwọn ìgbèkùn Juda, tí èmi rán jáde kúrò ni ibí yìí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea. Èmi ó sì kọjú mi sí wọn fún rere, èmi ó sì mú wọn padà wá sí ilẹ̀ yìí, èmi óò gbé wọn ró ní àìtún wó wọn lulẹ̀, èmi ó gbìn wọ́n, ní àìtún fà wọ́n tu. Èmi ó sì fún wọn ní ọkàn láti mọ̀ mí, pé, Èmi ni [Jehofa], wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọrun wọn, nítorí pé wọn ó fi gbogbo ọkàn wọn yípadà sí mi.”
5, 6. (a) Báwo ni a ṣe ‘rán’ àwọn ọmọ Israeli díẹ̀ ‘jáde lọ́nà rere’ sí ilẹ̀ Kaldea? (b) Báwo ni Jehofa ṣe ‘kọjú sí’ àwọn ọmọ Israeli olùṣòtítọ́ tí wọ́n wà ní ìgbèkùn ‘fún rere’?
5 Nítorí náà, láti inú ohun ti Jehofa sọ níhìn-ín, o jọ pé àkókò dídára jù ṣì wà níwájú, pé gbogbo orílẹ̀-èdè Juda ni a kì yóò parẹ́ ráúráú. Ṣùgbọ́n kí ni ìjẹ́pàtàkì àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ dídára yìí?
6 Jekoniah, tàbí Jehoiakimu, ti jẹ́ ọba lórí Juda fún kìkì oṣù mẹ́ta àti ọjọ́ mẹ́wàá péré ṣáájú kí ó tó fínnúfíndọ̀ yọ̀ǹda Jerusalemu fún Ọba Nebukadnessari. Danieli àti àwọn Heberu alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́ta Hananiah, Miṣaeli, àti Asariah, àti Esekieli pẹ̀lú wà lára àwọn tí a kó lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú rẹ̀. Ọba Babiloni pa ìwàláàyè àwọn òǹdè wọ̀nyí mọ́, nítorí náà, a lè sọ pé Jehofa wo gbogbo àwọn tí a kólẹ́rú wọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán jáde sí ilẹ̀ àwọn ará Kaldea lọ́nà rere. Ìwọ ha ṣàkíyèsí pé Jehofa tún ṣèlérí láti ‘kọjú sí wọn fún rere’? Báwo ni a ṣe mú èyí ṣẹ? Ní 537 B.C.E., 80 ọdún lẹ́yìn náà, Jehofa mú kí Ọba Kirusi pa àṣẹ kan tí ó yọ̀ọ̀da fún àṣẹ́kù kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ wọn láti padà sí ilẹ̀ Juda. Àwọn Ju olùṣòtítọ́ wọ̀nyí tún ìlú-ńlá Jerusalemu kọ́; wọ́n gbé tẹ́ḿpìlì titun ró fún ìjọsìn Jehofa, Ọlọrun wọn; wọ́n sì padà sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn. Nítorí náà, nínú gbogbo èyí, lójú Jehofa, àwọn òǹdè wọ̀nyí àti àwọn àtọmọdọ́mọ ìran wọn dàbí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ àkọ́pọ́n dídára gan-an.
7. Nígbà wo àti báwo ni ojú Jehofa ṣe wà lára ẹgbẹ́ Jeremiah òde-òní “lọ́nà rere”?
7 O lè rántí pé nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú nípa àwọn ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jeremiah, a kẹ́kọ̀ọ́ pé wọ́n ní ìtumọ̀ fún ọ̀rúndún ogun wa. Orí 24 kò yàtọ̀ rárá. Lákòókò ọdún onídàágùdẹ̀ ti Ogun Àgbáyé Kìn-ín-ní, ọ̀pọ̀ lára àwọn olùṣèyàsímímọ́ ìránṣẹ́ Jehofa wá sábẹ́ agbára ìdarí Babiloni Ńlá ní ọ̀nà kan tàbí òmíràn. Ṣùgbọ́n ‘ojú’ Jehofa tí ń ṣàkíyèsí nǹkan ‘wà lára wọn fún rere.’ Nítorí náà ni ó fi jẹ́ pé nípasẹ̀ Kirusi Titobiju náà, Kristi Jesu, Jehofa fọ́ agbára Babiloni Ńlá kúrò lórí wọn tí ó sì mú wọn wá sínú paradise tẹ̀mí ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Àwọn Israeli tẹ̀mí wọ̀nyí dáhùnpadà wọ́n sì padà sọ́dọ̀ Jehofa pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà wọn. Lẹ́yìn náà, ní 1931, inú wọn dùn láti gba orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jehofa. Nítòótọ́, a lè sọ nísinsìnyí pé wọ́n dàbí agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ kan tí wọ́n dára gan-an ní ojú Jehofa.
8. Ní ọ̀nà wo ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa gbà fọnrere adùn ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba náà tí ó dàbí ti èso ọ̀pọ̀tọ́?
8 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kò sì tíì tàsé ète inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun níti títú tí ó tú wọn sílẹ̀ kúrò nínú Babiloni Ńlá. Wọn kò pa adùn ìhìn-iṣẹ́ ìhìnrere Ìjọba náà tí ó dàbí ti èso ọ̀pọ̀tọ́ mọ́ sọ́dọ̀ araawọn, ṣùgbọ́n wọ́n ti fọnrere rẹ̀ jákèjádò ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Jesu tí ó wà nínú Matteu 24:14: “A ó sì wàásù ìhìnrere ìjọba yìí ní gbogbo ayé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè.” Kí sì ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀? Iye tí ó ju 4,700,000 àwọn ẹni-bí-àgùtàn tí wọn kìí ṣe Israeli nípa tẹ̀mí ti já araawọn gbà kúrò lọ́wọ́ Babiloni Ńlá!
Àwọn Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Búburú Inú Ìran Náà
9. Àwọn wo ni àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú inú ìran Jeremiah ṣàpẹẹrẹ, kí ni ó sì níláti ṣẹlẹ̀ sí wọn?
9 Ṣùgbọ́n kí ni nípa ti agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú ti inú ìran Jeremiah yẹn? Jeremiah nísinsìnyí pa àfiyèsí rẹ̀ pọ̀ sórí ọ̀rọ̀ Jehofa tí ó wà ni Jeremiah orí 24, ẹsẹ 8 sí 10: “Gẹ́gẹ́ bí èso ọ̀pọ̀tọ́ bíburú jù tí a kò lè jẹ, nítorí tí wọ́n burú jù, báyìí ni Oluwa wi, Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi ó fi Sedekiah, ọba Juda, àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti àwọn tí ó kù ní Jerusalemu, àti àwọn ìyókù ní ilẹ̀ yìí àti àwọn tí ń gbé ilẹ̀ Egipti—Èmi ó fi wọ́n fún ìwọ̀sí àti fún ibi nínú gbogbo ìjọba ayé, láti di ìtìjú, òwe, ẹ̀sín, àti ẹ̀gàn ní ibi gbogbo, tí èmi óò lè wọn sí. Èmi ó sì rán idà, ìyàn, àti àjàkálẹ̀ àrùn, sí àárín wọn, títí wọn ó fi parun kúrò ní ilẹ̀ èyí tí èmi fifún wọn àti fún àwọn baba wọn.”
10. Èéṣe tí Jehofa fi ka Sedekiah sí ‘èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú’?
10 Nítorí náà, nítòótọ́ ni Sedekiah di ‘èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú’ ní ojú Jehofa. Kìí ṣe kìkì pé ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọba Nebukadnessari nípa dída ẹ̀jẹ́ ìdúróṣinṣin tí ó ti jẹ́ fún ọba yẹn ní orúkọ Jehofa nìkan ni ṣùgbọ́n ó tún kọ ìyọ́nú Jehofa tí a tipasẹ̀ Jeremiah nawọ́ rẹ̀ sí i. Níti tòótọ́, àní ó lọ jìnnà débi pé ó mú kí a fi Jeremiah sí àhámọ́! Abájọ ti Esra fi ṣàkópọ̀ ìwà ọba náà gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ọ́ ní 2 Kronika 36:12 pé: “Ó sì ṣe èyí tí ó burú ní ojú Oluwa Ọlọrun rẹ̀, kò sì rẹ araarẹ̀ sílẹ̀.” Ní ojú Jehofa Sedekiah àti àwọn wọnnì tí wọ́n ṣẹ́kù sí Jerusalemu dàbí agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú, jíjẹrà kan!
Àwọn Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Jíjẹrà Ìṣàpẹẹrẹ ní Ọjọ́ Wa
11, 12. Àwọn wo ni wọ́n jẹ́ àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú lónìí, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí wọn?
11 Nísinsìnyí wo ayé yíká lónìí. Ìwọ ha rò pé a lè rí agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú ìṣàpẹẹrẹ kan bí? Ẹ jẹ́ kí a gbé òtítọ́ náà yẹ̀wò nípa fífi ọjọ́ wa wé ti Jeremiah. Ní ọ̀rúndún ogún yìí, Jehofa ti lo ẹgbẹ́ Jeremiah, àṣẹ́kù àwọn ẹni-àmì-òróró, láti kìlọ̀ gbọnmọgbọnmọ fún àwọn orílẹ̀-èdè nípa ìbínú rẹ̀ tí ń bọ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá. Ó ti rọ àwùjọ àwọn orílẹ̀-èdè láti fún òun ní ògo tí ó tọ́ sí orúkọ òun, láti sin òun ní ẹ̀mí àti òtítọ́, kí wọ́n sì tẹ́wọ́gba Ọmọkùnrin òun tí ń jọba, Kristi Jesu, bí Alákòóso títọ́ fún ilẹ̀-ayé. Kí ni ó ti jẹ ìhùwàpadà wọn? Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ́ Jeremiah. Àwọn orílẹ̀-èdè ń báa lọ ni ṣíṣe ohun tí ó burú ní ojú Jehofa.
12 Àwọn wo ni wọ́n ń ru ìwà ìṣọ̀tẹ̀ yìí sókè? Àwọn wo ni wọ́n ń fi àwọn òjíṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n dàbí Jeremiah wọ̀nyí ṣe yẹ̀yẹ́ nípa gbígbé ìbéèrè dìde sí ọlá-àṣẹ tí wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọrun? Àwọn wo ni wọ́n ń báa lọ ní títẹ́ḿbẹ́lú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun? Àwọn wo lónìí ni wọ́n ti wà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ jùlọ nínú inúnibíni tí a ń ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa? Ìdáhùn náà ṣe kedere sí gbogbo ènìyàn láti rí—Kristẹndọm ni, ní pàtàkì ẹgbẹ́ àwọn àlùfáà! Sáà sì kíyèsí gbogbo ìṣùpọ̀ èso búburú, jíjẹrà ti Kristẹndọm tí a ti jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú náà. Óò, bẹ́ẹ̀ni, dájúdájú agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú ìṣàpẹẹrẹ kan wà lórí ilẹ̀-ayé lónìí. Nítòótọ́, Jehofa sọ pé wọn ‘kò ṣeé jẹ, bí wọ́n ti burú tó.’ Ọ̀rọ̀ Jehofa nípasẹ̀ Jeremiah ń dún títí di àkókò wa: ‘Wọn yóò parun kúrò ní ilẹ̀’! Ìbínú Jehofa sí Kristẹndọm kì yóò rí ìdènà kankan.
Ẹ̀kọ́ Akininílọ̀ fún Wa
13. Lójú ìwòye ọ̀rọ̀ Paulu tí a rí nínú 1 Korinti 10:11, báwo ni a ṣe níláti lóye ìran àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì náà?
13 Bí a ti ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí ìhìn-iṣẹ́ ìkìlọ̀ onímìísí ti Jeremiah túmọ̀sí, àwọn ọ̀rọ̀ aposteli Paulu ní 1 Korinti 10:11 dún ní etí wa pé: “Nǹkan wọ̀nyí sì ṣe sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa: a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá.” Àwa fúnraawa ha ti fi ìkìlọ̀ tí a fi fún wa nípasẹ̀ ìran àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì yìí sọ́kàn bí? Ohun tí a ti ń jíròrò jẹ́ apá pàtàkì kan lára àwọn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Israeli gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ akininílọ̀ fún wa.
14. Báwo ni Israeli ṣe hùwàpadà sí àbójútó oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ Jehofa?
14 Lákòótán, ẹ jẹ́ kí a rántí àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa sí Ọba Dafidi nípa Israeli, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú 2 Samueli 7:10 pé: “Èmi ó sì yan ibìkan fún àwọn ènìyàn mi, àní Israeli, èmi ó sì gbìn wọ́n.” Jehofa fi jẹ̀lẹ́nkẹ́ bójútó àwọn ènìyàn rẹ̀, Israeli, ní gbogbo ọ̀nà. Gbogbo ìdí ni ó wà fún àwọn ọmọ Israeli láti mú ìṣùpọ̀ èso dídára jáde nínú ìgbésí-ayé wọn. Wọ́n wulẹ̀ níláti fetísí ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá láti ọ̀dọ̀ Jehofa kí wọ́n sì pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Síbẹ̀, ìwọ̀nba díẹ̀ lára wọn ni ó ṣe bẹ́ẹ̀. Èyí tí ó pọ̀ jùlọ ya olóríkunkun àti oníwà wíwọ́ tí ó fi jẹ́ pé wọ́n mú ìṣùpọ̀ èso búburú, jíjẹrà jáde.
15. Báwo ni Israeli tẹ̀mí lónìí àti àwọn ẹni-bí-àgùtàn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ti ṣe dáhùnpadà sí ìyọ́nú Jehofa?
15 Ó dára, nígbà náà, kí ni nípa ti ọjọ́ wa? Jehofa ti fi ìyọ́nú púpọ̀ hàn sí àwọn àṣẹ́kù ẹni-àmì-òróró Israeli tẹ̀mí rẹ̀ àti àwọn ẹni-bí-àgùtàn alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Ojú rẹ̀ ti wà lára wọn nígbà gbogbo láti ìgbà ìdáǹdè wọn nípa tẹ̀mí ní 1919. Gẹ́gẹ́ bí ó ti sọtẹ́lẹ̀ nípasẹ̀ Isaiah, lójoojúmọ́ ni wọ́n ń gba ìtọ́ni àtọ̀runwá láti ọwọ́ Olùkọ́ni títóbilọ́lá jùlọ ní àgbáyé, Jehofa Ọlọrun. (Isaiah 54:13) Ẹ̀kọ́ àtọ̀runwá yìí, tí òun ń darí nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n, Jesu Kristi, ti yọrísí àlàáfíà yanturu láàárín wọn ó sì ti fi kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ mú wọn wá sínú ipò-ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jehofa. Ẹ wo irú àyíká àgbàyanu tẹ̀mí tí èyí pèsè fún gbogbo wa láti mọ Jehofa, láti fetísílẹ̀ sí i, àti láti máa báa lọ ní mímú ìṣùpọ̀ èso dídára jáde nínú ìgbésí-ayé wa—ìṣùpọ̀ èso tí ń mú ìyìn wá fún Jehofa! Ìwàláàyè wa gan-an ni ó túmọ̀sí!
16. Ọ̀nà wo ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wa lè gbà fi ìran àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì náà sílò fún araawa gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan?
16 Ṣùgbọ́n láìka gbogbo inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun sí, àwọn kan ṣì wà tí wọ́n di ọlọ̀tẹ̀ àti ọlọ́kàn líle, bí ọ̀pọ̀ ti ṣe ní Juda ìgbàanì, tí wọ́n sì mú ìṣùpọ̀ èso búburú, jíjẹrà jáde nínú ìgbésí-ayé wọn. Ẹ wo bí èyí ti baninínújẹ́ tó! Ǹjẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wa máṣe gbàgbé ẹ̀kọ́ akininílọ̀ tí a mú wá sí àfiyèsí wa ní kedere nípasẹ̀ àwọn agbọ̀n èso ọ̀pọ̀tọ́ méjì wọ̀nyí pẹ̀lú ìṣùpọ̀ èso wọn—dídára àti búburú. Bí ìdájọ́ yíyẹ láti ọ̀dọ̀ Jehofa sórí Kristẹndọm apẹ̀yìndà ti ń súnmọ́lé ju ti ìgbàkigbà rí lọ, ǹjẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ ìṣílétí aposteli Paulu sọ́kàn: “Kí ẹ baà lè máa rìn ní ọ̀nà yíyẹ Jehofa fún ète wíwù ú ní kíkún bí ẹ ti ń bá a lọ ní síso èso nínú isẹ́ dáradára gbogbo.”—Kolosse 1:10, NW.
Ṣíṣàtúnyẹ̀wò “Ìṣùpọ̀-Èso—Dídára àti Búburú” àti ìpínrọ̀ 1 sí 4 lábẹ́ “Àríyànjiyàn Jehofa Pẹ̀lú Àwọn Orílẹ̀-Èdè”
◻ Kí ni agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dídára náà ṣàpẹẹrẹ?
◻ Báwo ni agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú inú ìran náà ti ṣe farahàn kedere?
◻ Ẹ̀kọ́ akininílọ̀ wo ni ìhìn-iṣẹ́ Jeremiah pèsè fún wa?
◻ Kí ni o ṣe pàtàkì nípa ọdún 607 B.C.E.? àti 1914 C.E.?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Gẹ́gẹ́ bí àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ dídára, àwọn ènìyàn Ọlọrun ti mú ìṣùpọ̀ èso Ìjọba dídùn jáde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀rí ti fihàn pé Kristẹndọm dàbí agbọ̀n àwọn èso ọ̀pọ̀tọ́ búburú kan