Àríyànjiyàn Jehofa Pẹ̀lú Àwọn Orílẹ̀-Èdè
“Dájúdájú igbe kan yóò wà títí lọ dé ibi jíjìnnà jùlọ ní ilẹ̀-ayé, nítorí pé Jehofa ní àríyànjiyàn kan pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè.”—JEREMIAH 25:31, NW.
1, 2. (a) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ ní Juda lẹ́yìn ikú Ọba Josiah? (b) Ta ní ọba tí o jẹ kẹ́yìn ní Juda, báwo ni òun sì ṣe jìyà nítorí àìṣòdodo rẹ̀?
ÌGBÀ lílekoko tí ó ṣòro láti bálò dojúkọ ilẹ̀ Juda. Ọba rere kan, Josiah, ti fa ọwọ́ ìbínú kíkan Jehofa sẹ́yìn fún ìgbà díẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ni ó tẹ̀lé e nígbà tí a ṣekúpa Josiah ní 629 B.C.E.? Àwọn ọba tí wọn jẹ tẹ̀lé e tàbùkù sí Jehofa.
2 Ọba tí ó jẹ kẹ́yìn ní Juda, Sedekiah, ọmọkùnrin kẹrin Josiah, ń báa lọ, gẹgẹ bí 2 Ọba 24:19 ti sọ, ‘láti ṣe èyí tí ó burú ní ojú Oluwa, gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Jehoiakimu [ẹ̀gbọ́n rẹ̀] ti ṣe.’ Kí ni àbájáde rẹ̀? Nebukadnessari gbéjàko Jerusalemu, ó mú Sedekiah lẹ́rú, ó pa àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ lójú rẹ̀, ó fọ́ ọ ní ojú, ó sì mú un lọ sí Babiloni. Síwájú síi, àwọn ará Babiloni kó àwọn ohun-èlò tí a ń lò nínú ìjọsìn Jehofa gẹ́gẹ́ bí ìkógun, wọ́n sì tinábọ tẹ́ḿpìlì àti ìlú-ńlá náà. Àwọn olùlàájá di ìgbèkùn ní Babiloni.
3. Sáà wo ni ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun Jerusalemu ní 607 B.C.E., kí ni ó sì tó àkókò fún láti ṣẹlẹ̀ ní òpin sáà náà?
3 Kìí ṣe kìkì ìparun Jerusalemu tí ó kẹ́yìn nìkan bíkòṣe ìbẹ̀rẹ̀ “àwọn àkókò tí a yànkalẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè” pẹ̀lú, èyí tí a tọ́kasí nínú Luku 21:24 (NW), ni ọdún yẹn, 607 B.C.E., sàmì sí. Sáà 2,520 ọdún yìí parí ní ọ̀rúndún tiwa, ní ọdún 1914. Àkókò ti tó fún Jehofa nígbà náà láti tipasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀ tí a ti gbégorí ìtẹ́, Jesu Kristi, ẹni tí ó tóbilọ́lá ju Nebukadnessari lọ, kéde kí ó sì mú ìdájọ́ ṣẹ sórí ayé tí ó ti díbàjẹ́ náà. Ìdájọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú alábàádọ́gba Juda òde-òní, alábàádọ́gba kan tí ó ń sọ pe òun ń ṣojú fún Ọlọrun àti Kristi lórí ilẹ̀-ayé.
4. Àwọn ìbéèrè wo ni a gbé dìde nísinsìnyí ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ Jeremiah?
4 Àwa ha rí ìbáradọ́gba kan láàárín àwọn rògbòdìyàn tí ó wáyé ní àwọn ọdun tí Juda lò kẹ́yìn lábẹ́ àwọn ọba rẹ̀—pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ aṣèparun tí ń ran àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀—àti rògbòdìyàn nínú Kristẹndọm lónìí bí? Dájúdájú a rí i! Nígbà náà, kí ni àsọtẹ́lẹ̀ Jeremiah fihàn níti ọwọ́ tí Jehofa yóò fi mú àwọn ọ̀ràn lónìí? Ẹ jẹ́ kí a wò ó.
5, 6. (a) Láti 1914 wá, báwo ni ipò nǹkan ni Kristẹndọm ti ṣe dàbí ti Juda ní kété ṣáájú ìparun rẹ̀? (b) Ìhìn-isẹ́ wo ni Jeremiah òde-òní ti mú tọ Kristẹndọm lọ?
5 Bertrand Russell ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí ó jẹ́ onímọ̀ ìṣirò àti ẹlẹ́kọ̀ọ́ ọgbọ́n-ìmọ̀-ọ̀ràn ṣàlàyé ní nǹkan bí 40 ọdún sẹ́yìn pé: “Láti 1914 wá, gbogbo ẹni tí ọ̀nà tí ayé darí sí ń jẹ lọ́kàn ni a ti kó ìdààmú bá lọ́nà jíjinlẹ̀ nípasẹ̀ ohun tí ó dàbí ìgbésẹ̀ kánmọ́kánmọ́ kan tí a ti kádàrá tí a sì ti pinnu tẹ́lẹ̀ síhà ìjábá tí ó túbọ̀ ń tóbi síi.” Òṣèlú ọmọ ilẹ̀ Germany náà Konrad Adenauer sì sọ pé: “Àìléwu àti ìparọ́rọ́ ti pòórá nínú ìgbésí-ayé àwọn ènìyàn láti 1914 wá.”
6 Lónìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí ní ọjọ Jeremiah, ìsúnmọ́lé òpin ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan ni a sàmì sí nípasẹ̀ ìtasílẹ̀ alagbalúgbú ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀, ní pàtàkì nínú àwọn ogun àgbáyé méjèèjì ti ọ̀rúndún yìí. Ní apá tí ó pọ̀ jùlọ, àwọn orílẹ̀-èdè Kristẹndọm tí wọ́n sọ pé àwọn ń jọ́sìn Ọlọrun Bibeli, ni wọ́n ja àwọn ogun wọ̀nyí. Àgàbàgebè yìí mà ga o! Abájọ tí Jehofa fi rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ sí wọn, ní fífi àwọn ọ̀rọ̀ Jeremiah 25:5, 6 bá wọn sọ̀rọ̀ pé: “Ẹ ṣáà yípadà, olúkúlùkù kúrò ní ọ̀nà búburú rẹ̀, àti kúrò ní búburú ìṣe yín . . . Kí ẹ má sì tọ ọlọrun mìíràn lẹ́yìn láti máa sìn wọ́n, àti láti máa foríbalẹ̀ fún wọn, kí ẹ má sì ṣe fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, èmi kì yóò sì ṣe yín ní ibi.”
7. Ẹ̀rí wo ni ó wà pe Kristẹndọm ti kọ àwọn ìkìlọ̀ Jehofa?
7 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn orílẹ̀-èdè Kristẹndọm ti kùnà láti yípadà. Wọ́n ti fi èyí hàn nípa ìrúbọ wọn síwájú síi sí ọlọrun ogun ní Korea àti Vietnam. Wọ́n sì ń báa lọ láti fi owó ṣètìlẹ́yìn fún àwọn oníṣòwò ikú, àwọn olùṣe ohun ìjà ogun. Àwọn ilẹ̀ Kristẹndọm ni wọ́n ń pèsè apá púpọ̀ jùlọ nínú iye tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó trillion kan dọ́là tí a ná sórí àwọn ohun ìjà ogun lọ́dọọdún ní àwọn ọdún 1980. Láti 1951 sí 1991, ìnáwó ètò ogun United States nìkan tayọ èrè tí ń wọlé fún àwọn àjọ ilẹ̀ America lápapọ̀. Láti ìgbà tí a ti kéde fáyégbọ́ pé Ogun Tútù ti parí, wọ́n ti dín àwọn ohun ìjà átọ́míìkì tí kò bá ìgbà mu mọ́ kù, ṣùgbọ́n àkójọ tìrìgàngàn àwọn ohun ìjà tí agbára ìṣekúpani wọ́n tilẹ̀ tún lékenkà ṣì ṣẹ́kù wọ́n sì ń báa lọ ní mímú wọn gbèrú. Lọ́jọ́kanjọ́kan wọ́n lè lo ìwọ̀nyí.
Ìdájọ́ Lòdìsí Ilẹ̀-Àkóso Kristẹndọm Onígbọ̀jẹ̀gẹ́
8. Báwo ni àwọn ọ̀rọ̀ Jeremiah 25:8, 9 yóò ṣe ní ìmúṣẹ lórí Kristẹndọm?
8 Àwọn ọ̀rọ̀ Jehofa síwájú síi ní Jeremiah 25:8, 9, nísinsìnyí bá Kristẹndọm, tí ó ti kùnà láti gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ọ̀pá-ìdiwọ̀n òdodo Kristian wí ní pàtàkì: “Nítorí náà, báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí: nítori tí ẹ̀yin kò gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. Sá wò ó, èmi ó ránṣẹ́, èmi ó sì mú gbogbo ìdílé orílẹ̀-èdè àríwá wá, ní Oluwa wí, èmi ó sì ránṣẹ́ sí Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọ̀dọ̀ mí, èmi ó sì mú wọn wá sí ilẹ̀ yìí, àti olùgbé rẹ̀, àti sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíkáàkiri, èmi ó sì pa wọ́n pátápátá, èmi ó sì sọ wọ́n di ìyanu àti ìyọṣùtì sí, àti ahoro àìnípẹ̀kun.” Nípa bẹ́ẹ̀, ìpọ́njú ńlá náà yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Kristẹndọm, tí wọ́n polongo araawọn ní ènìyàn Ọlọrun, tí yóò sì gbòòrò dé gbogbo ayé níkẹyìn, dé “gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yíkáàkiri.”
9. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ipò tẹ̀mí Kristẹndọm gbà di èyí tí ó burú jù ní ọjọ́ wa?
9 Ìgbà kan wà tí a bọ̀wọ̀ fún Bibeli nínú Kristẹndọm, nígbà tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé jákèjádò ayé ni àwọn ènìyàn ń wo ìgbéyàwó àti ìgbésí-ayé ìdílé gẹ́gẹ́ bí orísun ayọ̀, nígbà tí àwọn ènìyàn ń jí ní kùtùkùtù tí wọ́n sì ń rí ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ ojúmọ́ wọn. Ọ̀pọ̀ ń tu araawọn lára nípa kíkà àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ àtùpà ní alẹ́. Ṣùgbọ́n lónìí, ìwà ìṣekúṣe ìbálòpọ̀ takọtabo, ìkọ̀sílẹ̀, ìjòògùnyó àti ìmutípara, ìyapòkíì, ìwọra, ìwà ọ̀lẹ lẹ́nu iṣẹ́, sísọ tẹlifíṣọ̀n wíwò di bárakú, àti àwọn ìwà abèṣe mìíràn ti ba ìgbésí-ayé jẹ́ dé ìwọ̀n tí ń múnigbọ̀nrìrì. Èyí ni yóò ṣáájú ìparun tí Jehofa Ọlọrun máa tó múṣẹ sórí ilẹ̀-àkóso onígbọ̀jẹ̀gẹ́ Kristẹndọm.
10. Ṣàpèjúwe ipò Kristẹndọm lẹ́yìn mímú àwọn ìdájọ́ Jehofa ṣẹ.
10 Jehofa polongo, gẹ́gẹ́ bí a ti kà ní Jeremiah orí 25, ẹsẹ 10 sí 11 pé: “Èmi óò mú ohùn inúdídùn, àti ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ ìyàwó, àti ohùn ìyàwó, ìró òkúta ọlọ, àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà kúrò lọ́dọ̀ wọn. Gbogbo ilẹ̀ yìí yóò sì di ìparun àti ahoro.” Kàyéfì ni yóò jẹ́ níti gidi nígbà tí àwọn tẹ́ḿpìlì ràgàjì àti àwọn ààfin olówó iyebíye Kristẹndọm bá wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ sí ìparun wọn. Báwo ni ìparun yìí yóò ṣe gbòòrò tó? Ní ọjọ́ Jeremiah, ìparun Juda àti àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká rẹ̀ gba 70 ọdún, èyí tí Orin Dafidi 90:10 ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí odindi ìgbà ìwàláàyè. Ìmúdàájọ́ṣẹ Jehofa lónìí yóò jẹ́ pátápátá, títíláé.
Ìdájọ́ Lòdìsí Babiloni Ńlá
11. Ta ni yóò jẹ́ ohun-èlò ní pípa Kristẹndọm run? Èéṣe?
11 Gẹ́gẹ́ bí a ti sọtẹ́lẹ̀ nínú Ìfihàn 17:12-17, àkókò náà yóò dé nígbà tí Jehofa yóò bẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ àràmàndà rẹ̀ nípa fífi sí ọkàn “ìwo mẹ́wàá” náà—àwọn mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ológun nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè—“láti mú ìfẹ́ rẹ̀” ti pípa ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé run “ṣẹ.” Báwo ni èyí yóò ṣe ṣẹlẹ̀? Onírúurú ọ̀nà ni “ìwo mẹ́wàá” inú Ìfihàn orí 17 náà lè gbà “kórìíra àgbèrè náà . . . [kí] ó sì fi iná sun ún pátápátá,” gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 16 ti sọ ọ́. Níti tòótọ́, àwọn ohun ìjà ogun átọ́míìkì ti gbèrú wọ́n sì ń báa lọ láti máa gbèrú síi ní ọ̀pọ̀ ibi eléwu lórí ilẹ̀-ayé. Ṣùgbọ́n a gbọ́dọ̀ dúró kí a sì rí bí Jehofa yóò ṣe fi í sọ́kàn àwọn alákòóso òṣèlú láti mú ẹ̀san rẹ̀ ṣẹ́.
12. (a) Kí ni ó ṣẹlẹ̀ sí Babiloni lẹ́yìn tí ó pa Jerusalemu run? (b) Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́yìn ìparun Kristẹndọm?
12 Ní àwọn ìgbà àtijọ́ ọpọ́n sún kan Babiloni láti fojúwiná ìbínú kíkan Jehofa. Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Jeremiah orí 25, ẹsẹ 12, àsọtẹ́lẹ̀ náà wo àwọn ọ̀ràn láti ipò ìdúró kan tí ó yípadà lẹ́yìn náà. Níwọ̀n bí kò ti ṣiṣẹ́ mọ́ gẹ́gẹ́ bí Amúdàájọ́ṣẹ fún Jehofa, Nebukadnessari àti Babiloni nísinsìnyí wà lára gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ayé. Èyí bá bí ipò ọ̀ràn náà ti rí lónìí mu. Àwọn “ìwo mẹ́wàá” ti Ìfihàn orí 17 yóò sọ ìsìn èké di ahoro, ṣùgbọ́n lẹ́yìn náà àwọn fúnraawọn yóò jìyà ìparun papọ̀ pẹ̀lú “àwọn ọba ayé” mìíràn, gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú Ìfihàn orí 19. Jeremiah 25:13, 14 ṣàpèjúwe bí Babiloni, papọ̀ pẹ̀lú “gbogbo orílẹ̀-èdè” tí wọ́n ti kó àwọn ènìyàn Jehofa nífà, ṣe gba ìdájọ́. Jehofa ti lo Nebukadnessari gẹ́gẹ́ bí amúdàájọ́ṣẹ ní fífi ìyà jẹ Juda. Síbẹ̀ òun àti àwọn ọba Babiloni tí wọ́n jẹ lẹ́yìn rẹ̀ fi pẹ̀lú ìgbéraga gbé araawọn ga lòdìsí Jehofa fúnraarẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn, fún àpẹẹrẹ, nípa sísọ àwọn ohun-èlò tẹ́ḿpìlì Jehofa di aláìmọ́. (Danieli 5:22, 23) Nígbà tí àwọn ará Babiloni sì pa Jerusalemu run, àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n wà ní àyíká Juda—Moabu, Ammoni, Tire, Edomu, àti àwọn mìíràn—yọ̀, wọ́n sì fi àwọn ènìyàn Ọlọrun ṣẹ̀sín. Àwọn pẹ̀lú gbọ́dọ̀ gba ẹ̀san tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Jehofa.
Ìdájọ́ Lòdìsí “Gbogbo Orílẹ̀-Èdè”
13. Kí ni “ago ọtí wáìnì ìbínú” túmọ̀sí, kí ni yóò sì ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí wọ́n bá mu ago náà?
13 Nítorí náà, Jeremiah polongo, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sílẹ̀ ní orí 25, ẹsẹ̀ 15 àti 16 pé: “Báyìí ni Oluwa Ọlọrun Israeli wí fún mi: Gba ago ọtí wáìnì ìbínú mi yìí kúrò lọ́wọ́ mi, kí o sì jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí èmi ó ran ọ sí, mu ún. Kí wọ́n mu, kí wọ́n sì máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n, kí wọ́n sì di aṣiwèrè, nítorí idà tí èmi óò rán sí àárín wọn.” Èéṣe tí ó fi jẹ́ ‘ago ọtí wáìnì ìbínú Jehofa’? Nínú Matteu 26:39, 42 àti Johannu 18:11, Jesu sọ nípa “ago” kan gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́-inú Ọlọrun fún òun. Bákan náà, ago kan ni a lò láti ṣàpẹẹrẹ ìfẹ́-inú Jehofa fún àwọn orílẹ̀-èdè láti mu nínú ẹ̀san àtọ̀runwá rẹ̀. Jeremiah 25:17-26 dárúkọ àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí wọ́n ṣàpẹẹrẹ àwọn orílẹ̀-èdè lónìí.
14. Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Jeremiah ti sọ, ta ni ó mu nínú ago ọtí wáìnì ìbínú Jehofa, kí ni èyí sì ṣàpẹẹrẹ fún ọjọ́ wa?
14 Bíi ti Juda, lẹ́yìn tí Kristẹndọm bá ti di “ìyanu àti ìyọṣùtì sí, àti ahoro àìnípẹ̀kun,” ìparun ń dúró de gbogbo ìyókù ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé lápapọ̀. Lẹ́yìn náà gbogbo ayé pátá, gẹ́gẹ́ bí Egipti ti ṣàpẹẹrẹ rẹ̀, gbọ́dọ̀ mu nínú ago ìbínú Jehofa! Bẹ́ẹ̀ni, “gbogbo àwọn ọba àríwá, ti itòsí àti ti ọ̀nà jíjìn, ẹnìkínní pẹ̀lú ẹnìkejì rẹ̀, àti gbogbo ìjọba ayé, tí ń bẹ ní ojú ayé,” gbọ́dọ̀ mu. Níkẹyìn, “ọba Ṣeṣaki yóò si mu lẹ́yìn wọn.” Ta sì ni “ọba Ṣeṣaki” yìí? Ṣeṣaki jẹ́ orúkọ ìṣàpẹẹrẹ, àdàpè, tàbí ẹnà, fún Babiloni. Gan-an gẹ́gẹ́ bí Satani ti jẹ́ ọba aláìṣeéfojúrí lórí Babiloni, bẹ́ẹ̀ náà ni òun jẹ́ “aládé ayé” títí di òní-olónìí, gẹ́gẹ́ bí Jesu ti fihàn. (Johannu 14:30) Nípa báyìí, Jeremiah 25:17-26 bá Ìfihàn orí 18 sí 20 mu ní mímú kí ìtòtẹ̀léra àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ṣe kedere bí ago ìbínú Jehofa ti ń lọ yíká. Lákọ̀ọ́kọ́, ilẹ̀-ọba ìsìn èké àgbáyé gbọ́dọ̀ parun, tẹ̀lé e ni àwọn agbára òṣèlú, àti lẹ́yìn náà Satani fúnraarẹ̀ ni a ó jù sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.—Ìfihàn 18:8; 19:19-21; 20:1-3.
15. Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí a bá gbọ ìgbe “àlàáfíà àti àìléwu”?
15 Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni a ti sọ nípa àlàáfíà àti àìléwu láti ìgbà tí a ti rò pé Ogun Tútù náà ti parí, tí ó sì ṣẹ́ku kìkì alágbára ògbóǹtarìgì kanṣoṣo. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ nínú Ìfihàn 17:10, alágbára ògbóǹtarìgì yẹn, ìkeje nínú orí ẹranko ẹhànnà náà, gbọ́dọ̀ “dúró fún ìgbà kúkúrú.” Ṣùgbọ́n “ìgbà kúkúrú” yẹn ń súnmọ́ òpin rẹ̀. Láìpẹ́, gbogbo igbe “àlàáfíà àti àìléwu” òṣèlú yóò fàyè sílẹ̀ fún “ìparun òjijì [tí yóò] dé sórí wọn.” Bẹ́ẹ̀ ni aposteli Paulu sọ.—1 Tessalonika 5:2, 3.
16, 17. (a) Bí ẹnikẹ́ni bá gbìyànjú láti yèbọ́ lọ́wọ́ ìdájọ́ Jehofa, kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí rẹ̀? (b) Ní ọ̀nà aṣèparun wo ni ìfẹ́-inú Jehofa yóò fi di ṣíṣe lórí ilẹ̀-ayé?
16 Gbogbo ètò-ìgbékalẹ̀ ayé Satani pátá, bẹ̀rẹ̀ láti orí Kristẹndọm, gbọ́dọ̀ mu nínú ago ìbínú Jehofa. Àṣẹ rẹ̀ síwájú síi tí ó pa fún Jeremiah, tí a kọ sílẹ̀ ní orí 25, ẹsẹ 27 sí 29, jẹ́rìí sí èyí: “Ìwọ ó sì wí fún wọn pé: Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wí; Ẹ mu, kí ẹ sì mu àmuyó, kí ẹ bì, kí ẹ sì ṣubú, kí ẹ má sì lè dìde mọ́, nítorí idà tí èmi óò rán sáàárín yín. Yóò sì ṣe, bí wọ́n bá kọ̀ láti gba ago lọ́wọ́ rẹ láti mu, ni ìwọ ó sì wí fún wọn pé: Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí; ní mímu ẹ̀yin ó mu! Sá wò ó, nítorí tí èmi bẹ̀rẹ̀ síí mú ibi wá sórí ìlú náà tí a pè ní orúkọ mi, ẹ̀yin fẹ́ jẹ́ aláìjìyà? ẹ̀yin kì yóò ṣe aláìjìyà: nítorí èmi ó pè fún idà sórí gbogbo olùgbé ayé, ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí.”
17 Ọ̀rọ̀ líle ni ìwọ̀nyẹn—níti gidi, àwọn ọ̀rọ̀ amúni kún fún ìbẹ̀rù, nítorí pé Oluwa Ọba Aláṣẹ gbogbo àgbáyé, Jehofa Ọlọrun ni ó sọ wọ́n. La ọ̀pọ̀ sáà ẹgbẹ̀rúndún já, òun ti fi sùúrù farada àwọn ọ̀rọ̀ òdì, ẹ̀gàn, àti ìkórìíra tí a ti wọ́jọ gègèrè sórí orúkọ mímọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àkókò náà ti dé níkẹyìn fún un láti dáhùn àdúrà tí Jesu Kristi, Ọmọkùnrin rẹ̀ àyànfẹ́ kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tí ó wà níhìn-ín lórí ilẹ̀-ayé: “Nítorí náà báyìí ni kí ẹ̀yin máa gbàdúrà: Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run; [kí a ya orúkọ rẹ sí mímọ́, NW]. Kí ìjọba rẹ dé; Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe, bíi ti ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni ní ayé.” (Matteu 6:9, 10) Ìfẹ́-inú Jehofa ni pé kí Jesu ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí idà Rẹ̀ ní mímú ẹ̀san ṣẹ.
18, 19. (a) Ta ni ó ń gẹṣin lọ láti ṣẹ́gun ní orúkọ Jehofa, kí ni òun sì ń dúró dè ṣáájú píparí ìṣẹ́gun rẹ̀? (b) Nígbà tí àwọn angẹli náà bá tú afẹ́fẹ́ ìjì ìbínú Jehofa sílẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ bíbanilẹ́rù wo ni yóò ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀-ayé?
18 Nínú Ìfihàn orí 6, a kọ́kọ́ kà nípa gígùn tí Jesu ń gun ẹṣin funfun kan lọ “láti ìṣẹ́gun dé ìṣẹ́gun.” (Ẹsẹ 2) Èyí bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìgbégorí ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba ọ̀run ní ọdún 1914. Àwọn ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin mìíràn tẹ̀lé e, ní ṣíṣàpẹẹrẹ ogun ọ̀gbálẹ̀-gbáràwé, ìyàn, àti àjàkálẹ̀-àrùn tí ó ti ń pọ́n ilẹ̀-ayé wa lójú láti ìgbà yìí wá. Ṣùgbọ́n nígbà wo ni gbogbo rògbòdìyàn yìí yóò dópin? Ìfihàn orí 7 fi tó wa létí pé àwọn angẹli mẹ́rin ń di “afẹ́fẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé mú” títí di ìgbà tí a ó fi kó Israeli tẹ̀mí àti ogunlọ́gọ̀ ńlá kan láti inú àwọn orílẹ̀-èdè gbogbo jọ fún ìgbàlà. (Ẹsẹ 1) Nígbà náà kí ni yóò tẹ̀lé e?
19 Jeremiah orí 25, ń báa lọ ní ẹsẹ 30 àti 31 pé: “Oluwa yóò kọ láti òkè wá, yóò sì fọ ohùn rẹ̀ láti ibùgbé rẹ̀ mímọ́, ní kíkọ, yóò kọ sórí ibùgbé rẹ̀, yóò pariwo sórí gbogbo olùgbé ayé, bí àwọn tí ń tẹ ìfúntí. Igbe kan yóò wá títí dé òpin ilẹ̀-ayé; nítorí Oluwa ní [àríyànjiyàn pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè NW], yóò ba gbogbo ẹran-ara wíjọ́, yóò fi àwọn olùṣe búburú fún idà, ni Oluwa wí.” Kò sí orílẹ̀-èdè kankan tí yóò yèbọ́ lọ́wọ́ mímu nínú ago ìbínú Jehofa lọ́nà yìí. Ó jẹ́ kánjúkánjú, nígbà náà, pé kí gbogbo àwọn ọlọ́kàn-àyà títọ́ ya araawọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ìwà búburú àwọn orílẹ̀-èdè ṣáájú kí àwọn angẹli mẹ́rin náà tó tú afẹ́fẹ́ ẹlẹ́fùúùfù-líle ti ìbínú Jehofa jáde. Ẹlẹ́fùúùfù-líle ni níti gidi, nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ Jeremiah ń báa lọ ní ẹsẹ 32 àti 33 pé:
20. Ìran àrídíjì wo ní ó fi bí ìdájọ́ Jehofa yóò ṣe múná tó hàn, ṣùgbọ́n èéṣe tí ìgbésẹ̀ yìí fi pọndandan?
20 “Báyìí ni Oluwa àwọn ọmọ-ogun wí, sá wò ó, ibi yóò jáde láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè, ìjì ńláǹlà yóò ru sókè láti agbègbè ayé. Àwọn tí Oluwa pa yóò wà ní ọjọ́ náà láti ìpẹ̀kun kìn-ín-ní ayé títí dé ìpẹ̀kun kejì ayé, a kì yóò ṣọ̀fọ̀ wọn, a kì yóò kó wọn jọpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò sin wọ́n, wọn óò di ààtàn lórí ilẹ̀.” Níti tòótọ́ ìran àrídíjì kan ni èyí jẹ́, ṣùgbọ́n ìgbésẹ̀ yìí pọndandan kí á baà lè fọ ilẹ̀-ayé mọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìwà búburú ṣáájú mímú Paradise tí Ọlọrun ṣèlérí wá.
Àwọn Olùsọ́-Àgùtàn Yóò Ké Wọn Yóò Sì Sọkún
21, 22. (a) Ní Jeremiah 25:34-36, àwọn wo ni “olùṣọ́-àgùtàn” Israeli, èésìtiṣe ti a fi fipá mú wọn láti ké? (b) Àwọn olùṣọ́-àgùtàn òde-òní wo ni ìbínú Jehofa tọ́ sí, èéṣìtiṣe tí ó fi yẹ wọ́n bẹ́ẹ̀?
21 Ẹsẹ 34 sí 36 sọ síwájú síi nípa ìdájọ́ Jehofa, ní wíwí pé: “Ké! ẹ̀yin olùṣọ́-àgùtàn! kí ẹ sì sọkún! ẹ fi ara yín yílẹ̀ nínú eérú, ẹ̀yin ọlọ́lá agbo-ẹran! nítorí ọjọ́ atipa yín àti láti tú yín ká pé, ẹ̀yin ó sì ṣubú bí ohun-èlò iyebíye. Sísá kì yóò sí fún àwọn olùṣọ́-àgùtàn, bẹ́ẹ̀ni àsálà kì yóò sí fún àwọn ọlọ́lá agbo-ẹran. Ohùn ẹkún àwọn olùṣọ́-àgùtàn, àti igbe àwọn ọlọ́lá agbo-ẹran ni a óò gbọ́: nítorí Oluwa ba pápá oko tútù wọn jẹ́.”
22 Àwọn wo ni olùṣọ́-àgùtàn wọ̀nyí? Wọn kìí ṣe àwọn aṣáájú ìsìn, tí wọ́n ti kọ́kọ́ mu nínú ago ìbínú Jehofa. Wọ́n jẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùtàn ológun, tí a tún ṣàpèjúwe ní Jeremiah 6:3, tí wọ́n kó àwọn ọmọ-ogun wọn jọ bí ọ̀wọ́ agbo-ẹran ní ìṣàyàgbàǹgbà sí Jehofa. Wọ́n jẹ́ àwọn alákòóso òṣèlú, tí wọ́n ti di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ lílu àwọn tí wọ́n ń ṣàkóso lé lórí ní jìbìtì. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn wọ̀nyí jẹ́ àwọn ọlọ́gbọ́n bérébéré, ọ̀jáfáfá nínú ìwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti lọ́ra láti pẹ̀rọ̀ sí àwọn ìyàn tí ó ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àwọn ilẹ̀ òtòṣì. Wọ́n sọ àwọn “ọlọ́lá agbo-ẹran” di ọlọ́rọ̀, irú bí àwọn oníṣòwò ohun ìjà ogun àti àwọn afìwọra ba àyíká jẹ́, nígbà tí wọ́n ń kọ̀ láti pèsè ìrànlọ́wọ́ ìṣègùn àti oúnjẹ aṣaralóore, èyí tí ó jẹ́ pé láìná wọn ní owó púpọ̀ rárá, ti lè gba àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà mẹ́wàá àwọn ọmọ tí ń kú là.
23. Ṣàpèjúwe ipò pápá-àkóso Satani lẹ́yìn tí Jehofa ti gbé àwọn ìgbésẹ̀ láti pa á run.
23 Abájọ nígbà náà ti Jeremiah orí 25 fi parí ọ̀rọ̀, ní ẹsẹ 37 àti 38, nípa sísọ nípa àwọn wọ̀nyí tí wọ́n jẹ́ olùfìmọ-tara-ẹni-nìkan wá àlàáfíà fún kìkìdá araawọn pé: “Ibùgbé àlàáfíà ni ó di ahoro, níwájú ìbínú kíkan Oluwa. Ó ti fi pàǹtírí rẹ̀ sílẹ̀ bíi kìnnìún nítorí tí ilẹ̀ wọn di ahoro, níwájú ìbínú idà aninilára, àti níwájú ìbínú kíkan rẹ̀.” Kàyéfì níti gidi! Síbẹ̀, ìbínú kíkan Jehofa ni a o fihàn pẹ̀lú ìdánilójú nípasẹ̀ Ẹni náà tí a ṣàpèjúwe nínú Ìfihàn 19:15, 16 gẹ́gẹ́ bí “Ọba àwọn ọba, àti Oluwa àwọn oluwa,” tí ń fi ọ̀pá irin ṣàkóso àwọn orílẹ̀-èdè. Kí ni yóò sì tẹ̀lé e?
24. Àwọn ìbùkún wo ni ìparun ìsìn èké àti ìyókù ayé Satani yóò mú wá fún aráyé olódodo?
24 Ìwọ ha ti la ìjì líle já rí bí? Ó lè jẹ́ ìrírí bíbanilẹ́rù. Ṣùgbọ́n ní òwúrọ̀ ọjọ́ tí ó bá tẹ̀lé e, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ lè rí àwókù káàkiri ilẹ̀, ojú ọjọ́ sábà máa ń mọ́ kedere tí ìparọ́rọ́ náà sì máa ń tunilára tóbẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí o fi lè dúpẹ́ lọ́wọ́ Jehofa fún ọjọ́ kan tí ó gbádùnmọ́ni lọ́nà àrà-ọ̀tọ̀. Bákan náà, bí ìjì ìpọ́njú ńlá náà bá ti ń rọlẹ̀, ìwọ lè bojúwo orí ilẹ̀-ayé pẹ̀lú ìdúpẹ́ pé o wà láàyè tí o sì ṣetán láti kópa nínú iṣẹ́ Jehofa síwájú síi láti sọ ilẹ̀-ayé tí a ti fọ̀ mọ́ di paradise ológo kan. Àríyànjiyàn Jehofa pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó ti mú wá sí òpin títóbilọ́lá rẹ̀, ní yíya orúkọ rẹ̀ sí mímọ́ àti pípa ọ̀nà mọ́ fún ìfẹ́-inú rẹ̀ láti di ṣíṣe lórí ilẹ̀-ayé lábẹ́ Ìṣàkóso Ẹlẹ́gbẹ̀rún Ọdún ti Ìjọba Messia náà. Ǹjẹ́ kí Ijọba yẹn dé láìpẹ́!
Ṣíṣàtúnyẹ̀wò ìpínrọ̀ 5 sí 24 nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ yìí
◻ Àwọn ọ̀nà àgàbàgebè Kristẹndọm wo ni ó ti wá sínú ìdájọ́ nísinsìnyí?
◻ Ojú-ìwòye gbígbòòrò wo nípa ìdájọ́ náà ni a fàyọ láti inú Jeremiah 25:12-38?
◻ Ago ẹ̀san wo ni a fifún gbogbo orílẹ̀-èdè?
◻ Àwọn wo ni olùṣọ́-àgùtàn tí wọn ké tí wọ́n sì sọkún, èésìtiṣe tí wọ́n fi dààmú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jehofa ti yan ohun-èlo fún pípa Kristẹndọm run
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Lẹ́yìn afẹ́fẹ́ ìjì ìpọ́njú ńlá náà, ilẹ̀-ayé kan tí a fọ̀ mọ́ yóò farahàn