Orí Kẹwàá
Ǹjẹ́ o Máa Ń béèrè Lójoojúmọ́ Pé, “Jèhófà Dà?”
1, 2. (a) Ọwọ́ wo làwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà fi mú àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run? (b) Kí ló yẹ kí àwọn Júù ṣe nípa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run?
OMIJÉ ń dà lójú Jeremáyà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. Kí ló fà á? Ipò táwọn Júù èèyàn rẹ̀ wà nígbà yẹn àtohun tí Ọlọ́run ní kó sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn lọ́jọ́ ọ̀la ló ń pa á lẹ́kún. Jeremáyà ní agbárí òun ì bá jẹ́ orísun omi, kí ojú òun sì jẹ́ ìsun omi, kóun bàa lè máa wa ẹkún mu. Ipò tí orílẹ̀-èdè náà wà sì tó ohun tó ń mú Jeremáyà máa kẹ́dùn lóòótọ́. (Jer. 9:1-3; ka Jeremáyà 8:20, 21.) Ńṣe làwọn Júù fàáké kọ́rí wọn kò tẹ̀ lé òfin Ọlọ́run, wọn ò sì gbọ́ràn sí Jèhófà lẹ́nu. Nítorí náà àjálù máa tó dé bá wọn.—Jer. 6:19; 9:13.
2 Àmọ́ àwọn ará Júdà yẹn ò kàn tiẹ̀ kọbi ara sí ohun tí Jèhófà ń sọ nípa ìwà wọn. Ohun tí wọ́n fẹ́ máa gbọ́ ni ‘kò séwu, kò séwu,’ táwọn aṣáájú ìsìn wọn sábà máa ń sọ fún wọn. (Jer. 5:31; 6:14) Wọ́n dà bí aláàárẹ̀ tó ń wá oníṣègùn táá máa sọ̀rọ̀ dídùn-dídùn sí wọn létí láìsọ ojú abẹ níkòó nípa àrùn burúkú tó ń ṣe wọ́n. Tí àìsàn ńlá bá ń ṣe ọ́, ǹjẹ́ o kò ní fẹ́ kí oníwòsàn ṣàyẹ̀wò rẹ kó sì sọ ohun tó ń ṣe ọ́ gan-an kó o lè tètè gba ìtọ́jú tó yẹ? Ohun tó yẹ kí àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà ṣe náà nìyẹn nípa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n wọ́nà láti mọ ipò táwọn wà gan-an lójú Ọlọ́run. Ṣe ló yẹ kí wọ́n béèrè pé: “Jèhófà dà?”—Jer. 2:6, 8.
3. (a) Kí làwọn Júù ì bá ṣe, táá jẹ́ kí wọ́n rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, “Jèhófà dà?” (b) Kí lọ̀nà kan táwọn Júù lè gbà wá Jèhófà?
3 Ká ní àwọn Júù ìgbà yẹn ń béèrè pé “Jèhófà dà?” ni, wọ́n á máa wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tí wọ́n bá fẹ́ ṣe ìpinnu, ì báà jẹ́ nínú ohun ńlá tàbí kékeré. Àwọn Júù yẹn kò ṣe èyí. Àmọ́ nígbà tí wọ́n bá fi máa dé láti ìgbèkùn Bábílónì lẹ́yìn tí Jerúsálẹ́mù bá ti dahoro, wọ́n á bẹ̀rẹ̀ sí í ‘wá Jèhófà.’ Wọ́n á lè tipa bẹ́ẹ̀ rí i, wọ́n á sì mọ àwọn ọ̀nà rẹ̀. (Ka Jeremáyà 29:13, 14.) Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà wá a? Ọ̀nà kan ni pé kí wọ́n gbàdúrà sí Ọlọ́run tọkàntọkàn, kí wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó máa tọ́ àwọn sọ́nà. Bí Dáfídì Ọba ṣe ń ṣe nìyẹn nígbà tirẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó bẹ Ọlọ́run pé: “Mú mi mọ àwọn ọ̀nà rẹ, Jèhófà; kọ́ mi ní àwọn ipa ọ̀nà rẹ.” (Sm. 25:4) Sì wo ohun tí Olùgbọ́ Àdúrà gbẹnu Jeremáyà sọ fún àwọn Júù ní ọdún kẹwàá ìjọba Sedekáyà pé kí wọ́n ṣe. Ó ní: “Ké pè mí, èmi yóò sì dá ọ lóhùn, pẹ̀lú ìmúratán sì ni èmi yóò fi sọ fún ọ nípa àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé finú mòye, àwọn tí ìwọ kò tíì mọ̀.” (Jer. 33:3) Ká ní ọba yìí àti ọ̀dàlẹ̀ orílẹ̀-èdè yẹn ké pe Ọlọ́run ni, ì bá jẹ́ kí wọ́n mọ àwọn ohun “tí kò ṣeé finú mòye,” ìyẹn bí Jerúsálẹ́mù ṣe máa dahoro àti bó ṣe máa pa dà bọ̀ sípò lẹ́yìn àádọ́rin ọdún.
4, 5. Àwọn ọ̀nà míì wo làwọn Júù ì bá ti gbà wá Jèhófà?
4 Ọ̀nà míì táwọn Júù ì bá tún gbà wá Jèhófà ni pé kí wọ́n lọ ṣèwádìí nínú ìtàn ìran wọn, kí wọ́n wo bí Ọlọ́run ṣe bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò. Ìyẹn ì bá jẹ́ kí wọ́n mọ ohun táwọn kan lára wọn ṣe tí wọ́n fi rójú rere Ọlọ́run àtohun táwọn míì ṣe tí wọ́n fi rí ìbínú rẹ̀. Wọ́n lè ṣèwádìí nínú àwọn ìwé tí Mósè kọ àtàwọn ìwé ìtàn míì tí Ọlọ́run mí sí, títí kan àwọn ìwé ìtàn àwọn ọba Ísírẹ́lì àti ti Júdà. Ká ní àwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà ṣàṣàrò lórí àwọn ìwé wọ̀nyẹn ni, tí wọ́n sì fetí sí àwọn wòlíì tòótọ́ tí Ọlọ́run rán, wọn ì bá mọ ìdáhùn sí ìbéèrè náà, “Jèhófà dà?”
5 Ọ̀nà kẹta táwọn Júù wọ̀nyẹn ì bá tún gbà wá Jèhófà ni pé kí wọ́n fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn gan-an alára àtèyí tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn míì ṣàríkọ́gbọ́n. Kì í ṣe pé kí wọ́n máa fọgbọ́n orí tara wọn ṣàyẹ̀wò nǹkan wọ̀nyẹn lọ́nà èyí-jẹ-èyí-ò-jẹ o. Àmọ́ ká ní wọ́n ronú lórí àwọn nǹkan táwọn fúnra wọn ti ṣe sẹ́yìn ni àti bí nǹkan wọ̀nyẹn ṣe rí lójú Jèhófà, ìyẹn ì bá ti ṣe wọ́n láǹfààní. Tí wọ́n bá jẹ́ni tó ń kíyè sára ni, wọn ì bá ti mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ìwà wọn.—Òwe 17:10.
6. Ìṣírí wo lo lè rí gbà látinú àpẹẹrẹ Jóòbù?
6 Ẹ jẹ́ ká wá wo bó ṣe kàn wá lónìí. Ǹjẹ́ o sábà máa ń béèrè pé, “Jèhófà dà?” tó o bá ń ṣe àwọn ìpinnu, àti nígbà tó o bá fẹ́ yan ohun tó o máa ṣe? Àwọn kan lè rí i pé àwọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ tó bó ṣe yẹ. Tó bá jọ pé bọ́rọ̀ tìẹ náà ṣe rí nìyẹn, má ṣe bọkàn jẹ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù baba ńlá ìgbàanì pàápàá. Nígbà tí nǹkan ò fara rọ fún un, ọ̀rọ̀ tara rẹ̀ nìkan ló gbà á lọ́kàn. Élíhù ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rán an létí ìwà ọmọ èèyàn, ó ní: “Kò sí ẹnì kankan tí ó sọ pé, ‘Ọlọ́run Olùṣẹ̀dá mi Atóbilọ́lá dà?’” (Jóòbù 35:10) Élíhù gba Jóòbù níyànjú pé: “Fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.” (Jóòbù 37:14) Ní tòdodo, ó yẹ kí Jóòbù kíyè sí àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà lára àwọn ìṣẹ̀dá tó wà láyìíká rẹ̀, kó sì tún wo bí Ọlọ́run ṣe ń bá àwọn èèyàn lò. Ìrírí tí Jóòbù fúnra rẹ̀ ní wá mú kó dẹni tó mọ àwọn ọ̀nà Jèhófà. Lẹ́yìn tó forí ti ìṣòro rẹ̀ dópin, tó sì wá rí bí Jèhófà ṣe bójú tó ọ̀ràn náà, ó ní: “Mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò lóye àwọn ohun tí ó jẹ́ àgbàyanu gidigidi fún mi, èyí tí èmi kò mọ̀. Àgbọ́sọ ni mo gbọ́ nípa rẹ, ṣùgbọ́n nísinsìnyí, ojú mi ti rí ọ.”—Jóòbù 42:3, 5.
7. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe rí i lójú ìwé 116, kí la fẹ́ máa jíròrò báyìí?
7 Ní ti Jeremáyà wòlíì, ó ń bá a nìṣó láti máa wá Jèhófà, ó sì rí i. Jeremáyà kò ṣe bíi tàwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀ ní gbogbo ọdún tó fi ṣe wòlíì. Ṣe lòun máa ń béèrè pé: “Jèhófà dà?” Wàyí o, àwọn ohun tá a fẹ́ máa jíròrò báyìí nínú àkòrí yìí á jẹ́ ká lè tinú àpẹẹrẹ Jeremáyà rí bá a ṣe lè tipasẹ̀ àdúrà gbígbà, ìkẹ́kọ̀ọ́ àti ìrírí wá Jèhófà ká sì rí i.—1 Kíró. 28:9.
Kí lẹni tó bá ń béèrè pé, “Jèhófà dà?” á máa ṣe? Àwọn ọ̀nà wo làwọn Júù ìgbà ayé Jeremáyà ì bá ti gbà béèrè bẹ́ẹ̀?
JEREMÁYÀ KÉ PE JÈHÓFÀ
8. Àwọn ipò wo ló mú kí Jeremáyà ké pe Ọlọ́run?
8 Ní gbogbo ọdún tí Ọlọ́run fi gbẹnu Jeremáyà bá orílẹ̀-èdè Júdà sọ̀rọ̀, ṣe ni Jeremáyà ń gbàdúrà àtọkànwá láti fi wá Jèhófà. Ó ké pe Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tó máa kéde iṣẹ́ Ọlọ́run fáwọn Júù tí kò fẹ́ gbọ́rọ̀ Ọlọ́run sétí rárá, ó tún ké pè é nígbà tó rò pé ẹ̀mí òun ò lè gbé e mọ́ àti nígbà tó fẹ́ mọ ìdí táwọn nǹkan kan fi ń ṣẹlẹ̀. Ọlọ́run dá a lóhùn, ó sì jẹ́ kó mọ ọ̀nà tó lè máa gbà bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ. Wo àpẹẹrẹ mélòó kan.
9. (a) Kí ni Jeremáyà sọ nípa ara rẹ̀ nínú Jeremáyà 15:15, 16, báwo ni Jèhófà sì ṣe dá a lóhùn? (b) Kí nìdí tó o fi lè gbà pé ó ṣe pàtàkì pé kó o máa sọ gbogbo bọ́ràn ṣe rí lára rẹ tó o bá ń gbàdúrà?
9 Nígbà kan tí Ọlọ́run ní kí Jeremáyà kéde ìdájọ́ lé àwọn èèyàn kan lórí, Jeremáyà ń rò ó pé gbogbo èèyàn ń fòun gégùn-ún. Ó wá ké pe Ọlọ́run pé kó rántí òun. Wo àdúrà rẹ̀ nínú Jeremáyà 15:15, 16, níbi tó ti sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tí Ọlọ́run dáhùn àdúrà rẹ̀. (Kà á.) Nígbà tó ń gbàdúrà náà, ó sọ ohun tó jẹ́ ìdààmú ọkàn rẹ̀. Bó ṣe wá rí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó sì jẹ ẹ́, ìyẹn lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ, ńṣe ni ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀! Jèhófà mú kí Jeremáyà túbọ̀ mọyì àǹfààní ńlá tó ní láti máa jẹ́ orúkọ mọ́ òun, àti láti máa kéde iṣẹ́ òun. Bí ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀rọ̀ náà ṣe wá hàn kedere sí Jeremáyà nìyẹn. Ẹ̀kọ́ wo ni èyí kọ́ wa?
10. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà dá Jeremáyà wòlíì lóhùn nígbà tó lóun ò tiẹ̀ ní sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà mọ́?
10 Tún wo ìgbà kan tí Páṣúrì àlùfáà, ọmọ Ímérì, lu Jeremáyà, Jeremáyà lóun ò tiẹ̀ ní sọ̀rọ̀ lórúkọ Jèhófà mọ́ rárá. Báwo ni Jèhófà ṣe dáhùn ohun tí Jeremáyà sọ nínú àdúrà rẹ̀? (Ka Jeremáyà 20:8, 9.) Bíbélì kò sọ pé Ọlọ́run sọ̀rọ̀ látọ̀run wá láti fi dá Jeremáyà lóhùn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí iná tí ń jó nínú egungun rẹ̀, kò sì lè pa á mọ́ra, àfi kó máa kéde rẹ̀ nìṣó. Sísọ tó sọ gbogbo ọkàn rẹ̀ fún Ọlọ́run, àti jíjẹ́ tó jẹ́ kí ohun tóun mọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ òun lọ́kàn, mú kó dẹni tó káràmáásìkí iṣẹ́ Ọlọ́run.
11, 12. Báwo ni Jeremáyà ṣe rí ìdáhùn sí ọ̀rọ̀ nípa bó ṣe jọ pé nǹkan ń lọ dáadáa fáwọn ẹni ibi?
11 Jeremáyà rí i pé nǹkan ń lọ dáadáa fáwọn ẹni ibi, ìyẹn sì rú u lójú. (Ka Jeremáyà 12:1, 3.) Ó gbà pé onídàájọ́ òdodo ni Jèhófà o, àmọ́ ó fẹ́ kó ṣe nǹkan kan nípa “ẹjọ́” tóun mú tọ̀ ọ́ wá. Bó ṣe sọ gbogbo èrò ọkàn rẹ̀ jáde jẹ́ kó hàn pé òun àti Ọlọ́run sún mọ́ra tímọ́tímọ́, àfi bí ọmọ àti baba tó fẹ́ràn ara wọn. Ohun tí Jeremáyà fẹ́ mọ̀ ni ìdí tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù tó jẹ́ èèyàn burúkú fi ń rọ́wọ́ mú. Ǹjẹ́ Jeremáyà wá rí ìdáhùn tó tẹ́ ẹ lọ́rùn gbà? Bẹ́ẹ̀ ni o. Jèhófà fi dá a lójú pé gbogbo àwọn ẹni ibi lòun máa fà tu. (Jer. 12:14) Nígbà tí Jeremáyà rí bí Jèhófà ṣe ń gbégbèésẹ̀ lórí àdúrà tó gbà, ó dájú pé ọkàn rẹ̀ á túbọ̀ balẹ̀ pé onídàájọ́ òdodo ni Ọlọ́run lóòótọ́. Èyí sì máa jẹ́ kí Jeremáyà tẹra mọ́ àdúrà gbígbà, kó túbọ̀ máa sọ èrò ọkàn rẹ̀ fún Baba rẹ̀ ọ̀run.
12 Lápá ìgbẹ̀yìn ìjọba Sedekáyà, nígbà táwọn ará Bábílónì sàga ti Jerúsálẹ́mù, Jeremáyà sọ pé Jèhófà jẹ́ “ẹni tí ojú rẹ ṣí sí gbogbo ọ̀nà àwọn ọmọ ènìyàn, láti fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso ìbálò rẹ̀.” (Jer. 32:19) Jeremáyà rí i pé Jèhófà jẹ́ onídàájọ́ òdodo, ó sì rí i pé Ọlọ́run ń kíyè sí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń ṣe àti pé ó ń gbọ́ àdúrà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá gbà tọkàntọkàn. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ náà yóò túbọ̀ máa rí ẹ̀rí síwájú sí i, pé Ọlọ́run máa ń “fi fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti gẹ́gẹ́ bí èso ìbálò rẹ̀.”
13. Kí ló fi ọ́ lọ́kàn balẹ̀ nípa àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ?
13 A lè rò pé àwa ò ṣiyèméjì nípa pé Ọlọ́run jẹ́ onídàájọ́ òdodo tàbí nípa ọgbọ́n tó wà nínú àwọn ọ̀nà tó gbà ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ báyìí àti bó ṣe máa mú un ṣẹ lọ́jọ́ ọ̀la. Síbẹ̀, a ó jàǹfààní tá a bá ronú lórí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jeremáyà, káwa náà sì máa sọ gbogbo bí nǹkan ṣe rí lọ́kàn wa fún Ọlọ́run nínú àdúrà. Tá a bá ń gbàdúrà lọ́nà bẹ́ẹ̀, a ó túbọ̀ máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, pé yóò mú ète rẹ̀ ṣẹ dájúdájú. Tá ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ mọ ìdí táwọn nǹkan fi ń lọ bó ṣe ń lọ báyìí, tàbí ìdí tó fi dà bíi pé ìgbésẹ̀ Ọlọ́run ń falẹ̀ jù tàbí ó ń yá jù, a lè gbàdúrà ká sọ fún Ọlọ́run pé ó dá wa lójú pé ohun gbogbo ń bẹ níkàáwọ́ rẹ̀. Ọ̀nà tí Jèhófà mọ̀ pé ó dára jù ló máa gbà mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ, yóò sì jẹ́ lásìkò tó dára jù. Ọlọ́run ti fi dá wa lójú bẹ́ẹ̀, kò sì sídìí tó fi yẹ ká ṣiyèméjì nípa rẹ̀. Ṣe ni ká máa bá a nìṣó láti máa béèrè pé “Jèhófà dà?” nípa gbígbàdúrà pé kó jẹ́ ká lè lóye ìfẹ́ rẹ̀ ká sì máa rí ọ̀nà tó gbà ń mú un ṣẹ.—Jóòbù 36:5-7, 26.
Ìdánilójú wo làwọn ìrírí Jeremáyà bó ṣe ń gbàdúrà láti fi wá Jèhófà mú kó o ní?
JEREMÁYÀ ṢÈWÁDÌÍ KÓ LÈ NÍ ÌMỌ̀ JÈHÓFÀ
14. Báwo la ṣe mọ̀ pé Jeremáyà ṣèwádìí nípa ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run?
14 Jeremáyà mọ̀ pé kóun tó lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, “Jèhófà dà?” òun gbọ́dọ̀ ní ‘ìmọ̀ Jèhófà.’ (Jer. 9:24) Ó dájú pé nígbà tó ń kọ ìwé Àwọn Ọba Kìíní àti Ìkejì yóò ti ṣèwádìí nípa ìtàn àwọn èèyàn Ọlọ́run dáadáa. Nítorí ó dìídì mẹ́nu kan “ìwé àwọn àlámọ̀rí Sólómọ́nì,” “ìwé àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Ísírẹ́lì” àti “ìwé àwọn àlámọ̀rí ọjọ́ àwọn ọba Júdà.” (1 Ọba 11:41; 14:19; 15:7) Ìwádìí tó ṣe á jẹ́ kó ti mọ bí Jèhófà ṣe bójú tó onírúurú ipò tó yọjú. Ó lè wá tipa bẹ́ẹ̀ mọ ohun tí inú Jèhófà ń dùn sí àti ojú tó fi ń wo ìpinnu àwọn èèyàn. Ó tún lè kàn sí àwọn ìwé tí Ọlọ́run mí sí tó wà láyé ìgbà yẹn, irú bí àwọn èyí tí Mósè, Jóṣúà, Sámúẹ́lì, Dáfídì àti Sólómọ́nì kọ. Ó sì dájú pé, ó mọ̀ nípa àwọn wòlíì tó wà ṣáájú rẹ̀ àtàwọn tó wà nígbà ayé rẹ̀ dáadáa. Báwo ni ìdákẹ́kọ̀ọ́ tí Jeremáyà ṣe yìí ṣe ràn án lọ́wọ́?
15. Àǹfààní wo ni Jeremáyà á ti jẹ látinú ìwádìí tó ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ Èlíjà?
15 Jeremáyà ṣàkọsílẹ̀ ìtàn Jésíbẹ́lì, aya búburú tí Áhábù Ọba tó wà ní Samáríà fẹ́. Ara ohun tó kọ sílẹ̀ ni ọ̀rọ̀ tí Èlíjà sọ, pé ajá ni yóò jẹ Jésíbẹ́lì ní abá ilẹ̀ Jésíréélì. (1 Ọba 21:23) Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jeremáyà sì kọ sílẹ̀ yẹn, wàá rántí pé ní nǹkan bí ọdún mẹ́rìnlá lẹ́yìn náà, wọ́n ré Jésíbẹ́lì bọ́ láti ojú fèrèsé, tí ẹṣin Jéhù tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, táwọn ajá sì jẹ òkú rẹ̀. (2 Ọba 9:31-37) Ó dájú pé ìwádìí tí Jeremáyà ṣe nípa àsọtẹ́lẹ̀ Èlíjà àti bó ṣe nímùúṣẹ, títí kan gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀, máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ gan-an ni. Láìsí àní-àní, ìgbàgbọ́ tó ní látinú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe sẹ́yìn ló mú kó lè fi ìfaradà ṣe iṣẹ́ wòlíì.
16, 17. Kí lo rò pé kò jẹ́ kó sú Jeremáyà láti máa kìlọ̀ fáwọn ọba burúkú ìgbà ayé rẹ̀?
16 Jẹ́ ká tún wo àpẹẹrẹ míì. Kí lo rò pé kò jẹ́ kó sú Jeremáyà láti máa kìlọ̀ fáwọn ọba búburú bíi Jèhóákímù àti Sedekáyà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ń ṣenúnibíni sí i? Ìdí kan pàtàkì ni pé Jèhófà mú kí Jeremáyà dà bí “ìlú ńlá olódi àti ọwọ̀n irin àti ògiri bàbà” sí àwọn ọba Júdà. (Jer. 1:18, 19) Àmọ́ ṣá o, ká má gbàgbé pé Jeremáyà pàápàá ti ṣèwádìí gan-an nípa àwọn ọba tó ti ṣàkóso sẹ́yìn ní Júdà àti Ísírẹ́lì. Òun ló ṣáà kọ ìtàn náà pé Mánásè mọ “àwọn pẹpẹ fún gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run sí àgbàlá méjì nínú ilé Jèhófà” àti pé ó finá sun ọmọ rẹ̀ láti fi rúbọ, ó sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ sílẹ̀ ní ìwọ̀n púpọ̀ gidigidi. (2 Ọba 21:1-7, 16; ka Jeremáyà 15:4.) Síbẹ̀, ó dájú pé Jeremáyà á ti mọ̀ pé nígbà tí Mánásè rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, tó ń rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà ṣáá, Jèhófà “jẹ́ kí ó pàrọwà sí òun,” ó sì dá ọba náà pa dà sórí ìtẹ́ rẹ̀.—Ka 2 Kíróníkà 33:12, 13.
17 Lóòótọ́ Jeremáyà kò mẹ́nu kan bí Jèhófà ṣe ṣàánú Mánásè nínú àwọn ìwé tó kọ. Àmọ́ nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún péré lẹ́yìn tí Mánásè kú ni Jeremáyà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wòlíì. Torí náà, yóò ti gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọba náà ronú pìwà dà àwọn ìwà búburú tó ti hù sẹ́yìn. Ó ní láti jẹ́ pé ìwádìí tí Jeremáyà ṣe nípa ìwà tó burú jáì tí Mánásè hù àti ohun tó jẹ́ àbájáde rẹ̀ ló jẹ́ kó rí bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa rọ àwọn ọba bíi Sedekáyà, pé kó bẹ̀bẹ̀ fún àánú àti inú rere onífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Ó ṣe tán, ọba tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí abọ̀rìṣà àti apààyàn yí pa dà, tí Ọlọ́run sì dárí jì í. Ká ní ìwọ lo wà nípò Jeremáyà, ǹjẹ́ ọ̀ràn Mánásè yìí kò ní jẹ́ ìṣírí fún ọ, kó jẹ́ kó o rí ìdí láti máa fi ìfaradà bá iṣẹ́ Ọlọ́run nìṣó nígbà ìjọba àwọn ọba búburú yòókù?
JEREMÁYÀ KẸ́KỌ̀Ọ́ LÁTINÚ ÌRÍRÍ
18. Ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n wo ni Jeremáyà á ti kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úríjà, kí sì nìdí tó o fi sọ bẹ́ẹ̀?
18 Ó dájú pé nígbà tí Jeremáyà ń ṣe iṣẹ́ wòlíì, ó fi ohun táwọn wòlíì ìgbà ayé rẹ̀ ṣe lábẹ́ àwọn ipò kan kọ́gbọ́n. Ọ̀kan ni ti wòlíì Úríjà, ẹni tó sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí ìlú Jerúsálẹ́mù àti Júdà nígbà ìjọba Jèhóákímù. Lẹ́yìn tí Úríjà sọ tẹ́lẹ̀ tán, ó bẹ̀rù Jèhóákímù Ọba, ó sì sá lọ sí Íjíbítì. Àmọ́ ọba yìí rán àwọn èèyàn lọ mú un pa dà wá láti Íjíbítì, ó sì ní kí wọ́n pa á. (Jer. 26:20-23) Ǹjẹ́ o rò pé Jeremáyà kò ní fi ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úríjà yìí ṣàríkọ́gbọ́n? Ó fi ṣàríkọ́gbọ́n o, níwọ̀n bí ó tí ń bá a nìṣó ní kíkìlọ̀ fáwọn Júù nípa àjálù tó ń bọ̀ lórí wọn, kódà tó tún lọ sọ ọ́ ní tẹ́ńpìlì. Jeremáyà ò fìgbà kankan ṣojo rárá, Jèhófà náà ò sì fi í sílẹ̀. Nítorí, ó ní láti jẹ́ pé Ọlọ́run ló lo Áhíkámù ọmọ Ṣáfánì láti dáàbò bo ẹ̀mí Jeremáyà onígboyà.—Jer. 26:24.
19. Kí ni Jeremáyà máa mọ̀ látinú bí Jèhófà ṣe ń rán àwọn wòlíì sáwọn èèyàn Rẹ̀?
19 Jeremáyà tún kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìrírí ara rẹ̀, ìyẹn bí Jèhófà ṣe lò ó láti kìlọ̀ fáwọn èèyàn Ọlọ́run. Lọ́dún kẹrin ìjọba Jèhóákímù, Jèhófà ní kí Jeremáyà ṣàkọsílẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ tóun ti ń sọ látìgbà ayé Jòsáyà títí dìgbà ayé Jeremáyà. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ní kó kọ ọ́ sílẹ̀? Ṣe ni Ọlọ́run fẹ́ lò ó láti fi gba olúkúlùkù àwọn Júù níyànjú pé kí wọ́n yí pa dà kúrò nínú ìwà burúkú wọn kóun lè dárí jì wọ́n. (Ka Jeremáyà 36:1-3.) Àní Jeremáyà, tó ń dìde ní kùtùkùtù láti jíṣẹ́ ìkìlọ̀ Ọlọ́run fáwọn Júù, tiẹ̀ ń bẹ̀ wọ́n pé kí wọ́n jáwọ́ nínú gbogbo ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí wọn. (Jer. 44:4) Ẹ ẹ̀ rí i pé Jeremáyà á ti mọ̀ látinú ìrírí tara rẹ̀ pé torí ìyọ́nú tí Ọlọ́run ní sáwọn èèyàn Rẹ̀ ló ṣe ń rán àwọn wòlíì sí wọn. Ǹjẹ́ èyí ò ní mú kí Jeremáyà náà ní ẹ̀mí ìyọ́nú sáwọn èèyàn náà? (2 Kíró. 36:15) Abájọ tí Jeremáyà fi wá sọ lẹ́yìn tó yè bọ́ nínú ìparun Jerúsálẹ́mù, pé: “Àwọn ìṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni kò jẹ́ kí a wá sí òpin wa, nítorí ó dájú pé àánú rẹ̀ kì yóò wá sí òpin. Tuntun ni wọ́n ní òròòwúrọ̀.”—Ìdárò 3:22, 23.
Ìwádìí tí Jeremáyà ṣe nípa ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń bá àwọn èèyàn rẹ̀ lò látẹ̀yìn wá àti àṣàrò tó ń ṣe lórí ìrírí ara rẹ̀ àti tàwọn míì, yóò ti ní ipa wo lórí rẹ̀? Ẹ̀kọ́ wo ni èyí sì kọ́ wa?
ǸJẸ́ ÌWỌ NÁÀ Ń BÉÈRÈ LÓJOOJÚMỌ́ PÉ, “JÈHÓFÀ DÀ?”
20. Báwo lo ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jeremáyà, kí ìwọ náà máa wá Jèhófà?
20 Ǹjẹ́ o máa ń rí i dájú pé o kọ́kọ́ wádìí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run lórí àwọn ìpinnu tó ò ń ṣe lójoojúmọ́, kó o máa béèrè pé, “Jèhófà dà?” (Jer. 2:6-8) Ní ti Jeremáyà, kò ṣe bí àwọn Júù ìgbà ayé rẹ̀. Ìgbà gbogbo ló máa ń wá ìtọ́sọ́nà Olódùmarè láti lè mọ ọ̀nà tó yẹ kó tọ̀. Láìsì àní-àní, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí olúkúlùkù wa náà máa ṣe bíi ti Jeremáyà, ká máa wádìí ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà lórí àwọn ìpinnu tá à ń ṣe lójoojúmọ́.
21. Irú àdúrà wo ló máa ṣèrànwọ́ fún ọ tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ìwàásù, bóyá títí kan ìgbà tẹ́nì kan bá kanra mọ́ ọ?
21 Kì í ṣe kìkì ìgbà téèyàn bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì nígbèésí ayé nìkan tàbí ìgbà téèyàn fẹ́ ṣe àwọn àyípadà pàtàkì kan ló yẹ kéèyàn tó wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kéèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá Jèhófà tó bá dọ̀rọ̀ lílọ sóde ìwàásù lọ́jọ́ téèyàn ti ní lọ́kàn pé òun fẹ́ jáde? Jẹ́ ká sọ pé o jí láàárọ̀ ọjọ́ náà tó o wá rí i pé ojú ọjọ́ dágùdẹ̀, èyí tó lè mú kí òde má wuni láti lọ. Bóyá ẹ tiẹ̀ ti wàásù léraléra ní ìpínlẹ̀ tẹ́ ẹ ti fẹ́ lọ ṣe ìwàásù àtilé-délé lọ́jọ́ náà. O tún wá rántí pé, nígbà yẹn, ṣe làwọn kan níbẹ̀ dọ́gbọ́n lé ọ kúrò lọ́dọ̀ wọn tàbí tí wọ́n tiẹ̀ fìwọ̀sí lọ̀ ọ́. Ǹjẹ́ o lè gbàdúrà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láàárọ̀ yẹn láti fi béèrè pé “Jèhófà dà?” Ìyẹn lè mú kó o ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù tó o fẹ́ lọ ṣe yẹn ti ṣe pàtàkì tó, kó sì tún máa wá sí ọ lọ́kàn pé Ọlọ́run ló fẹ́ kó o lọ jẹ́ iṣẹ́ yẹn. Èyí lè wá jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọ́ bíi ti Jeremáyà, ìyẹn ni pé kí ọ̀rọ̀ Jèhófà tó o fẹ́ lọ wàásù wá di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà rẹ. (Jer. 15:16, 20) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé bó o ṣe wà lóde ẹ̀rí ọ̀hún, ẹnì kan kanra mọ́ ọ tàbí ó tilẹ̀ halẹ̀ mọ́ ọ, o tún lè gbàdúrà kó o sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ fún Ọlọ́run. Ṣé wàá ṣe bẹ́ẹ̀? Má gbàgbé pé Ọlọ́run lè fi ẹ̀mí mímọ́ ràn ọ́ lọ́wọ́ tí wàá fi mọ ohun tó yẹ kó o ṣe, tó fi jẹ́ pé ẹ̀mí rere tó o ní tó o fi ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ.—Lúùkù 12:11, 12.
22. Kí ló lè jẹ́ kí àwọn àdúrà kan rí ìdènà?
22 Á dáa ká mọ̀ pé àwọn nǹkan kan lè dènà àdúrà tàbí kó mú kí àdúrà ẹni má gbà o. (Ka Ìdárò 3:44.) Jèhófà kò gbọ́ àdúrà àwọn Júù tó ya ọlọ̀tẹ̀ nítorí pé wọ́n ‘yí etí wọn kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,’ wọn ò sì jáwọ́ nínú ìwàkiwà. (Òwe 28:9) Jeremáyà á ti kọ́ ẹ̀kọ́ gidi nínú èyí, àní bó ṣe yẹ kó jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwa náà, pé: Téèyàn bá ń ṣe ohun tó lòdì sí àdúrà tó gbà, inú Ọlọ́run ò ní dùn, ìyẹn sì lè mú kí Ọlọ́run máà gbọ́ àdúrà onítọ̀hún. Nítorí náà, á dáa pé ká sa gbogbo ipá wa láti yàgò fún irú nǹkan bẹ́ẹ̀.
23, 24. (a) Ká tó lè mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà, kí ló ṣe pàtàkì pé ká máa ṣe? (b) Kí lo lè ṣe tí wàá fi túbọ̀ máa jàǹfààní nínú ìdákẹ́kọ̀ọ́ rẹ?
23 Yàtọ̀ sí àdúrà àtọkànwá tá a máa ń gbà láti fi wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ó yẹ ká máa ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́ déédéé, torí ìyẹn ni ọ̀nà pàtàkì kan tá a fi lè mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà. Ní ti ìdákẹ́kọ̀ọ́ yìí, a ní àǹfààní kan tí Jeremáyà kò ní. Àwa ní Bíbélì lódindi. Ìwọ náà lè ṣe bíi ti Jeremáyà tó ṣèwádìí jinlẹ̀ nígbà tó ń kọ àwọn ìwé ìtàn tí Ọlọ́run mí sí, ìyẹn ni pé kó o máa ṣèwádìí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti fi wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa béèrè pé, “Jèhófà dà?” Tó o bá ń sapá láti mọ ìfẹ́ rẹ̀, ìyẹn máa fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e, wàá sì “dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá omi, tí ó na gbòǹgbò rẹ̀ tààrà lọ sẹ́bàá ipadò.”—Ka Jeremáyà 17:5-8.
24 Bó o ṣe ń ka Ìwé Mímọ́ tó o sì ń ṣàṣàrò lórí rẹ̀, máa gbìyànjú láti fòye mọ ohun tí Jèhófà fẹ́ kó o ṣe nínú onírúurú ipò. Máa wá àwọn ìlànà tó yẹ kó o rántí kó o sì máa fi sílò nínú gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe. Tó o bá ń ka àwọn ìtàn inú Bíbélì, àwọn òfin Ọlọ́run, ìlànà Ọlọ́run àtàwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, máa ronú lórí ipa tó yẹ kí nǹkan wọ̀nyẹn máa ní lórí àwọn ìpinnu rẹ ojoojúmọ́. Ní ìdáhùn sí ìbéèrè rẹ pé, “Jèhófà dà?” Jèhófà lè tipasẹ̀ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè máa bójú tó onírúurú ipò tó bá yọjú, àní títí kan àwọn èyí tó le koko pàápàá. Kódà, o tiẹ̀ lè wá ṣàwárí, “àwọn ohun ńlá tí kò ṣeé finú mòye, àwọn tí ìwọ kò tíì mọ̀,” tàbí tí òye rẹ̀ kò yé ọ bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀, nínú Bíbélì!—Jer. 33:3.
25, 26. Àǹfààní wo la máa jẹ tá a bá ń ronú nípa àwọn ìrírí tara wa àti tàwọn ẹlòmíì?
25 Bákan náà, o tún lè máa ronú nípa àwọn ìrírí tìrẹ àti tàwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, o lè rí i pé àwọn díẹ̀ kan ṣe bíi ti Úríjà, wọn kò gbára lé Jèhófà mọ́. (2 Tím. 4:10) O lè fọ̀rọ̀ tiwọn kọ́gbọ́n, kó o sì yẹra fún irú ọ̀fìn tí wọ́n jìn sí. Rántí pé Jeremáyà mọyì àánú àti ìyọ́nú Ọlọ́run, torí náà, látìgbà dé ìgbà, máa rántí bí Jèhófà ṣe ń fi inú rere onífẹ̀ẹ́ bá ọ lò. Bó ṣe wù kí ipò rẹ le koko tó, má ṣe rò pé Ọ̀gá Ògo kò bìkítà nípa rẹ. Ó bìkítà o, àní bó ṣe bìkítà nípa Jeremáyà.
26 Tó o bá ń ṣàṣàrò nípa ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń dá sí ọ̀rọ̀ ẹnì kọ̀ọ̀kan lónìí, wàá máa rí i pé ojoojúmọ́ ló ń pèsè ìtọ́sọ́nà fún wa lóríṣiríṣi ọ̀nà. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Aki nílẹ̀ Japan rò pé irú òun kọ́ lèèyàn lè kà sí Kristẹni gidi. Lọ́jọ́ kan tí Aki àti ìyàwó alábòójútó àyíká wọn jọ wà lóde ẹ̀rí, Aki gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀, ó ní: “Ó ń ṣe mí bíi pé Jèhófà máa tó tu mí dà nù bí omi tí kò gbóná tí kò tutù, èmi ni mo kàn ṣì dìrọ̀ mọ́ ọn pé kó ṣàánú mi.” Ni ìyàwó alábòójútó àyíká yẹn bá sọ̀rọ̀ tó tù ú nínú, ó ní: “Látìgbà témi ti mọ̀ ọ́, mi ò rí nǹkan kan tó o fi jọ Kristẹni tí kò gbóná tí kò tutù o!” Aki wá ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ yẹn lẹ́yìn ìgbà náà. Ká sòótọ́, kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé Jèhófà tiẹ̀ fìgbà kankan rí kà á sí kò-gbóná-kò tutù. Lẹ́yìn náà, Aki gbàdúrà sí Jèhófà pé: “Jọ̀wọ́ rán mi lọ síbikíbi tó o bá fẹ́. Màá ṣe ohunkóhun tó o bá fẹ́ kí n ṣe.” Láàárín àkókò yẹn ló rìnrìn àjò lọ sí ilẹ̀ òkèèrè kan táwùjọ àwọn ará kéréje kan tí wọ́n ń sọ èdè ilẹ̀ Japan wà. Wọ́n ti ń wá ará kan tó gbọ́ èdè náà tó máa lè ṣí wá sọ́dọ̀ àwọn. Ó sì wá ṣẹlẹ̀ pé orílẹ̀-èdè yẹn gan-an ni wọ́n bí Aki sí, èyí tó jẹ́ kó rọrùn fún un láti ṣí lọ síbẹ̀ láti lọ ṣèrànwọ́ fún wọn. Àmọ́ kò wá síbi tó máa gbé. Arábìnrin kan tí ọmọ rẹ̀ kúrò nílé láìpẹ́ sígbà yẹn sì ní kó máa wá gbé yàrá kan nílé òun. Aki ní: “Bí gbogbo rẹ̀ kàn ṣe ń bọ́ síra láìtàsé dà bí àlá lójú mi; ṣe ni Jèhófà dìídì ń ṣínà fún mi.”
27. Kí nìdí tó fi yẹ kó o máa béèrè pé, “Jèhófà dà?” nínú gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe?
27 Ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àti arábìnrin ló ti ní àwọn ìgbà táwọn fúnra wọn rí i pé Ọlọ́run dìídì tọ́ wọn sọ́nà, bóyá nígbà tí wọ́n ń ka Bíbélì tàbí nígbà tí wọ́n ń ṣe ìdákẹ́kọ̀ọ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ti ṣẹlẹ̀ sí ìwọ náà. Ó sì yẹ kí irú ìrírí bẹ́ẹ̀ mú kí àjọṣe ìwọ àti Jèhófà túbọ̀ ṣe tímọ́tímọ́ sí i débi pé wàá túbọ̀ máa fi tọkàntọkàn gbàdúrà sí i déédéé. Kí ó dá wa lójú o, pé tá a bá ń béèrè lójoojúmọ́ pé, “Jèhófà dà?” yóò fi wá mọ ọ̀nà rẹ̀.—Aísá. 30:21.
Kí lo máa ṣe tí wàá fi lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè náà, “Jèhófà dà?” Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run?