Ọrọ-Afikun si Ori 14
Awọn opitan gbagbọ pe Babiloni ṣubu sọ́wọ́ ẹgbẹ ọmọ-ogun Kirusi ní October 539 B.C.E. Nabonidus ni ọba nigba naa, ṣugbọn ọmọkunrin rẹ̀ Belteṣassari jẹ́ alajumọṣakoso Babiloni. Awọn ọmọwe kan ti ṣakọsilẹ itolẹsẹẹsẹ awọn ọba tí wọn jẹ ní Babiloni Titun ati gígùn igba ijọba wọn, lati ọdun ikẹhin Nabonidus pada sẹhin sọdọ baba Nebukadnessari tí orukọ rẹ̀ ń jẹ́ Nabopolassar.
Gẹgẹ bi itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ awọn ọba Babiloni Titun yẹn ti wi, Alade Ọmọ-ọba Nebukadnessari ṣẹgun awọn ara Egipti ninu ìjà-ogun Carchemish ní 605 B.C.E. (Jeremiah 46:1, 2) Lẹhin tí Nabopolassar kú Nebukadnessari pada si Babiloni lati gorí ìtẹ́. Ọdun akọkọ rẹ̀ lori ìtẹ́ pé ní igba iruwe tí ó tẹle e (604 B.C.E.).
Bibeli rohin pe awọn ara Babiloni labẹ Nebukadnessari pa Jerusalemu run ni ọdun 18 igba ijọba rẹ̀ (19 bi a bá kà ọdun tí ó gorí ìtẹ́ mọ́ ọn). (Jeremiah 52:5, 12, 13, 29) Nipa bayii bi ẹnikan bá tẹwọgba itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ awọn ọba Babiloni Titun tí ó wà lókè yii, isọdahoro Jerusalemu yoo jẹ́ ní ọdun 587 si 586 B.C.E. Ṣugbọn ki ni a gbé itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ awọn ọba ti ayé yii kà, bawo ni ó sì ṣe rí ní ifiwera pẹlu itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ ti Bibeli?
Pataki awọn ẹri itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn ọba tí ayé yii gbarale ni iwọnyi:
Itolẹṣẹẹsẹ Akọsilẹ ti Ptolemy: Claudius Ptolemy jẹ́ awòràwọ̀ ara Griki kan tí ó gbé ní ọ̀rúndún keji C.E. Itolẹṣẹẹsẹ Akọsilẹ rẹ̀, tabi itolẹsẹẹsẹ awọn ọba, ní isopọ pẹlu iṣẹ kan lori ìwòràwọ̀ tí ó ṣe. Pupọ julọ awọn opitan ode-oni tẹwọgba isọfunni Ptolemy nipa awọn ọba Babiloni Titun ati gígùn igba ijọba wọn (bi ó tilẹ jẹ́ pe Ptolemy fò igba ijọba Labashi-Marduk dá). Laisi aniani Ptolemy gbé isọfunni ọlọ́rọ̀ ìtàn rẹ̀ ka awọn orisun tí ó lọ jinna dé sáà Seleucid, eyi tí ó bẹrẹ ní eyi tí ó jù 250 ọdun lẹhin tí Kirusi kó Babiloni lẹ́rú. Nipa bayii kò yanilẹnu pe awọn iye nọmba Ptolemy fohunṣọkan pẹlu awọn ti Berossus, alufaa ara Babiloni kan tí ó gbé ní sáà Seleucid.
Okuta-iranti ti Nabonidus Harran (NABON H 1, B): Okuta-iranti tabi ọwọ̀n yii tí ó jẹ́ ti akoko kan-naa pẹlu Nabonidus, tí ó ní àkọlé kan, ni a ṣawari rẹ̀ ní 1956. Ó mẹnukan igba ijọba awọn ọba Babiloni Titun bii Nebukadnessari, Efil-Merodaki, Neriglissar. Awọn iye ọdun fun awọn mẹtẹẹta wọnyi fohunṣọkan pẹlu awọn ti Itolẹṣẹẹsẹ Akọsilẹ ti Ptolemy.
VAT 4956: Eyi jẹ́ wàláà kan tí ó ní irisi cuneiform tí ó pese isọfunni tí ó gùn jàn-àn-ràn eyi tí a lè tọpasẹ rẹ̀ pada sẹhin sí 568 B.C.E. Ó sọ pe awọn akíyèsí naa wá jẹ ti ọdun 37 Nebukadnessari. Eyi yoo wà ní ibamu pẹlu itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ tí ó sọ pe 587 si 586 B.C.E. ni ọdun 18 rẹ̀ lori itẹ. Àmọ́ ṣáá o, wálàá yii ni a gbà pe ó jẹ́ àdàkọ kan tí a ṣe ní ọ̀rúndún kẹta B.C.E. nitori naa ó ṣeeṣe ki ó jẹ́ pe isọfunni ọlọ́rọ̀-ìtàn rẹ̀ wulẹ jẹ́ eyi tí a tẹwọgba ní sáà Seleucid.
Awọn wàláà iṣẹ́-ajé: Ẹgbẹẹgbẹrun awọn wálàá tí wọn ní irisi cuneiform tí wọn jẹ́ ti akoko kan-naa pẹlu igba Babiloni Titun ni a ti ṣàwárí tí wọn ṣe akọsilẹ awọn káràkátà iṣẹ́-ajé rirọrun, tí wọn ṣakọsilẹ ní pàtó ọba naa tí ó jẹ ní Babiloni nigba tí káràkátà naa wáyé. Iru awọn wàláà wọnyi ni a ti ṣawari fun gbogbo ọdun igba ijọba awọn ọba Babiloni Titun tí a mọ̀ ninu itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ sáà naa.
Lati oju-iwoye ti ayé, irú ìtògẹ̀n-ẹ̀n-rẹ̀n awọn ẹri bẹẹ lè dabi eyi tí ó fidii rẹ̀ mulẹ pe itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ awọn ọba Babiloni Titun tí ó sọ pe ọdun 18 Nebukadnessari (ati iparun Jerusalemu) jẹ́ ní 587 si 586 B.C.E. Bi ó ti wù ki ó rí, kò si opitan kankan tí ó lè sẹ́ ṣiṣeeṣe naa pe aworan isinsinyi ti itan Babiloni le ṣinilọ́nà tabi ki ó kún fun aṣiṣe. Fun apẹẹrẹ, ó jẹ́ ohun tí a mọ̀ dunjú pe awọn alufaa ati awọn ọba igbaani nigba miiran maa ń yi awọn akọsilẹ pada fun awọn ete tiwọn funraawọn. Tabi kẹ̀, àní bi ẹri tí a ṣawari naa bá tilẹ péye, awọn ọmọwe ode-oni lè ṣì í tumọ tabi ki ó ṣàìpéye lọna tí yoo fi jẹ́ pe awọn akojọpọ-ọrọ tí a kò tíì ṣawari sibẹ lè yi itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ sáà naa pada lọna tí ó bùáyà.
Dajudaju ní mímọ irú awọn otitọ bẹẹ lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Edward F. Campbell, Jr., mú ṣáàtì kan jade, tí ó ni itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ Babiloni Titun ninu, pẹlu ikilọ yii: “Láì ṣẹ̀ṣẹ̀ maa sọ, awọn itolẹsẹẹsẹ wọnyi ni a lè yipada. Bi ẹnikan bá ṣe tubọ n kẹkọọ awọn apá dídíjú ninu awọn iṣoro itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ ni apá Itòsí Ila-oorun ti igbaani, bẹẹ gẹ́lẹ́ ni oun yoo ti tubọ maa ní ìtẹ̀sí lati maṣe ronu nipa ohun kan tí oun gbekalẹ gẹgẹ bi eyi tí abẹ gé. Nitori idi eyi, ọ̀rọ̀ èdè naa circa [nǹkan bii] ni a lè lò kódà lọna tí ó gbòòrò jù itumọ rẹ̀ lọ.”—The Bible and the Ancient Near East (itẹjade ti 1965), oju-iwe 281.
Awọn Kristian tí wọn ní igbagbọ ninu Bibeli ti ṣawari leralera pe awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ yege ìdánwò ọpọlọpọ ariwisi a sì ti fi ẹ̀rí hàn pe ó péye ati pe ó ṣeéfọkàntẹ̀. Wọn mọyì pe gẹgẹ bi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a mísí a lè lò ó gẹgẹ bi ọ̀pá ìwọ̀n kan ní didiwọn itan ati awọn oju-iwoye ti ayé. (2 Timoteu 3:16, 17) Fun apẹẹrẹ, bi ó tilẹ jẹ́ pe Bibeli sọrọ nipa Belteṣassari gẹgẹ bi oluṣakoso Babiloni, fun ọpọ ọ̀rúndún ni awọn ọmọwe ti ní idarudapọ nipa rẹ̀ nitori pe kò si awọn akọsilẹ ti ayé tí ó wà larọwọto tí ó sọ nipa wíwà rẹ̀, ẹni ti o jẹ tabi ipò rẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, lẹhin-ọ-rẹhin ni awọn awalẹpitan ṣawari awọn akọsilẹ ayé tí wọn jẹrii si Bibeli. Bẹẹni, iṣọkan Bibeli ninu gbogbo apá rẹ̀ ati iṣọra tí awọn onkọwe rẹ̀ lò, kódà ninu awọn ọran itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ, fi tagbaratagbara damọran rẹ̀ pe ki Kristian kan gbé aṣẹ Bibeli ga ju awọn ipinnu aláìdúrósójúkan ti awọn opitan ayé.
Ṣugbọn bawo ni Bibeli ṣe ràn wa lọwọ lati pinnu igba tí a pa Jerusalemu run, bawo ni eyi sì ṣe rí ní ifiwera pẹlu itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ ti ayé?
Wolii Jeremiah sọtẹlẹ pe awọn ara Babiloni yoo pa Jerusalemu run, wọn yoo sì sọ ilu-nla naa ati ilẹ rẹ̀ dahoro. (Jeremiah 25:8, 9) O fikun un pe: “Gbogbo ilẹ yii yoo sì di iparun ati ahoro: orilẹ-ede wọnyi yoo sì sin ọba Babiloni ní aadọrin ọdun.” (Jeremiah 25:11) Ọdun 70 naa dopin nigba tí Kirusi Nla, ní ọdun akọkọ rẹ̀, tú awọn Ju silẹ tí wọn sì pada si ilẹ ibilẹ wọn. (2 Kronika 36:17-23) Awa gbagbọ pe kíkà tí ó ṣe taarata julọ ti Jeremiah 25:11 ati awọn ẹsẹ iwe mimọ yooku ni pe 70 ọdun naa yoo bẹrẹ lati igba tí awọn ara Babiloni pa Jerusalemu run tí wọn sì fi ilẹ Juda silẹ ní ahoro.—Jeremiah 52:12-15, 24-27; 36:29-31.
Sibẹ awọn wọnni tí wọn gbíyèlé isọfunni ti ayé ní pataki fun itolẹsẹẹsẹ ọjọ awọn iṣẹlẹ sáà yẹn mọ̀lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ pe bi ó bá jẹ́ pe 587 si 586 B.C.E. ni a pa Jerusalemu run, dajudaju a kò ṣẹgun Babiloni ṣaaju 70 ọdun lẹhin eyi tí Kirusi sì jẹ́ ki awọn Ju pada si ilẹ ibilẹ wọn. Ninu igbiyanju lati mú awọn nǹkan baramu, wọn sọ pe asọtẹlẹ Jeremiah bẹrẹsi ní imuṣẹ ní 605 B.C.E. Lẹhin naa awọn onkọwe fà ọ̀rọ̀ Berossus yọ ní sisọ pe lẹhin ìjà-ogun Carchemish, Nebukadnessari nasẹ̀ agbara idari Babiloni sori gbogbo Siria ti Palestine ati, nigba tí ó ń padabọ si Babiloni (ní ọdun tí ó gorí ìtẹ́, 605 B.C.E.), oun mú awọn òǹdè Ju lọ si ìgbèkùn. Nipa bayii wọn wò 70 ọdun naa gẹgẹ bi sáà ìsìnrú si Babiloni tí ó bẹrẹ ní 605 B.C.E. Eyi yoo tumọsi pe sáà 70 ọdun naa yoo dopin ní 535 B.C.E.
Ṣugbọn ọpọ ọran iṣoro pataki ni ó wà pẹlu itumọ yii:
Bi ó tilẹ jẹ́ pe Berossus sọ pe Nebukadnessari kó awọn òǹdé Ju ní ọdun tí ó gorí ìtẹ́, kò si awọn akọsilẹ ara okuta cuneiform tí ó tì eyi lẹhin. Eyi tí ó tún ṣe pàtàkì jù, Jeremiah 52:28-30 fi tiṣọratiṣọra rohin pe Nebukadnessari kó awọn Ju ni òǹdè ní ọdun keje rẹ̀, ọdun 18 ati ọdun 23 rẹ̀, kii ṣe ọdun tí ó gorí ìtẹ́. Pẹlupẹlu, Josephus opitan Ju naa là á lẹsẹẹsẹ pe ní ọdun ìjà-ogun Carchemish, Nebukadnessari ṣẹgun gbogbo Siria ati Palestine “ayafi Judea,” nipa bayii tí ó forigbari pẹlu Berossus tí ó sì kọlura pẹlu ijẹwọsọ naa pe 70 ọdun ìsìnrú bẹrẹ ní ọdun tí Nebukadnessari gorí ìtẹ́.—Antiquities of the Jews X, vi, 1.
Siwaju sii, nibomiran Josephus ṣalaye iparun Jerusalemu lati ọwọ́ awọn ara Babiloni lẹhin naa tí ó sì wipe “gbogbo Judea ati Jerusalemu, ati tẹmpili, ń báa lọ lati jẹ́ aginju fun aadọrin ọdun.” (Antiquities of the Jews X, ix, 7) O sọ ní pàtó pe “ilu-nla wa ni a sọdahoro lakooko alafo aadọrin ọdun, titi di awọn ọjọ Kirusi.” (Against Apion I, 19) Eyi fohunṣọkan pẹlu 2 Kronika 36:21 ati Danieli 9:2 pe 70 ọdun tí a sọtẹlẹ naa jẹ́ 70 ọdun isọdahoro tí ó kúnrẹ́rẹ́ fun ilẹ naa. Onkọwe ọ̀rúndún keji (C.E.) naa Theophilus ti Antioku pẹlu fihan pe 70 ọdun naa bẹrẹ pẹlu iparun tẹmpili lẹhin tí Sedekiah ti ṣakoso fun ọdun 11.—Pẹlupẹlu wò 2 Ọba 24:18–25:21.
Ṣugbọn Bibeli fúnraarẹ̀ pese ẹri tí ó tún pegede paapaa lodisi ijẹwọsọ naa pe 70 ọdun naa bẹrẹ ní 605 B.C.E. ati pe Jerusalemu ni a parun ní 587 si 586 B.C.E. Gẹgẹ bi a ti mẹnukan an, bi awa yoo bá kà á lati 605 B.C.E., 70 ọdun naa yoo nasẹ̀ wá si isalẹ dé 535 B.C.E. Bi ó ti wù ki ó rí, onkọwe Bibeli tí a misi naa Esra rohin pe 70 ọdun naa ń báa lọ titi di “ọdun èkínní Kirusi, ọba Persia,” ẹni tí ó mú aṣẹ kan jade, eyi tí ó gbà awọn Ju láayè lati pada si ilẹ ibilẹ wọn. (Esra 1:1-4; 2 Kronika 36:21-23) Awọn opitan tẹwọgba á pe Kirusi ṣẹgun Babiloni ní October 539 B.C.E. ati pe ọdun iṣakoso akọkọ ti Kirusi bẹrẹ ní igba iruwe 538 B.C.E. Bi aṣẹ Kirusi bá jade ní apá ipari ọdun iṣakoso rẹ̀ akọkọ, awọn Ju lè fi pẹlu irọrun pada dé si ilẹ ibilẹ wọn nigba tí o fi di oṣu keje (Tiṣiri) gẹgẹ bi Esra 3:1 ti wi; eyi yoo jẹ́ October 537 B.C.E.
Àmọ́ ṣáá o, kò si ọna kankan tí ó lọ́gbọ́n-nínú fun nínasẹ̀ ọdun akọkọ Kirusi gùn lati 538 si 535 B.C.E. Awọn kan ti wọn ti gbiyanju lati fi pẹlu àlàyé yanju iṣoro naa ti fi pẹlu àbùmọ́ sọ pe ní sisọrọ nipa “ọdun èkínní Kirusi” Esra ati Danieli lò oju-iwòye awọn Ju tí ó ṣajeji eyi tí ó yatọ si ọna tí gbogbogboo tẹwọgba fun kíka igba ijọba Kirusi. Ṣugbọn eyiini ni a kò lè dìmú, nitori pe gomina kan tí kii ṣe Ju ati akọsilẹ kan lati inu ibi ipamọ awọn isọfunni itan ti Persia fohunṣọkan pe aṣẹ naa wáyé ní ọdun akọkọ Kirusi, àní bi awọn onkọwe Bibeli ti rohin pẹlu iṣọra ati lọna tí ó ṣe pàtó.—Esra 5:6, 13; 6:1-3; Danieli 1:21; 9:1-3.
“Ọ̀rọ̀ rere” Jehofa wà ní isopọ timọtimọ pẹlu sáà 70 ọdun naa tí a sọtẹlẹ, nitori Ọlọrun wi pe:
“Bayii ni Oluwa wi pe, Lẹhin tí aadọrin ọdun bá pari ní Babeli, ni emi yoo bẹ̀ yin wò, emi yoo sì mú ọ̀rọ̀ rere mi ṣẹ si yin, ní mímú yin pada si ibi yii.” (Jeremiah 29:10)
Danieli gbíyèlé ọ̀rọ̀ yẹn, pẹlu igbẹkẹle pe 70 ọdun naa kii ṣe ‘nọmba aláìṣepàtó’ kan ṣugbọn iye géérégé kan tí a lè ṣírò. (Danieli 9:1, 2) Bẹẹ ni ó sì rí.
Lọna kan-naa, a ní ifẹ-inu lati jẹ́ ki Ọ̀rọ̀ Ọlọrun tọ́ wa sọna lakọọkọ dipo ki o jẹ nipasẹ itolẹsẹẹsẹ ọjọ iṣẹlẹ kan tí a gbeka ẹri ti ayé ní pataki tabi tí ó tako Ìwé Mímọ́. Ó dabi ẹni pe eyi ti o rọrun tí ó si ṣee loye taarata julọ ninu awọn gbolohun-ọ̀rọ̀ Bibeli ni pe 70 ọdun naa bẹrẹ pẹlu isọdahoro patapata ti Juda lẹhin tí a pa Jerusalemu run. (Jeremiah 25:8-11; 2 Kronika 36:20-23; Danieli 9:2) Nitori bẹẹ, ní kíka 70 ọdun pada sẹhin lati igba tí awọn Ju pada si ilẹ-ibilẹ ní 537 B.C.E., a gúnlẹ̀ si 607 B.C.E. fun déètì naa tí Nebukadnessari, ní ọdun 18 iṣakoso rẹ̀, pa Jerusalemu run, tí ó mú Sedekiah kuro lori ìtẹ́ tí ó sì mú opin débá ìlà awọn ọba Juda tí wọn jokoo sori ìtẹ́ ní Jerusalemu ti ilẹ̀-ayé.—Esekieli 21:19-27.