Àlàáfíà Kò Sí fún Àwọn Èké Ońṣẹ́!
“A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”—ORIN DÁFÍDÌ 37:9, 11.
1. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a retí láti rí àwọn ońṣẹ́, ti òtítọ́ àti ti èké, ní “ìgbà ìkẹyìn”?
ÀWỌN ońṣẹ́—ti èké tàbí ti òtítọ́? Oríṣi méjèèjì ni ó wà ní àkókò tí a kọ Bíbélì. Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ wa ńkọ́? Ní Dáníẹ́lì 12:9, 10, a kà pé, ońṣẹ́ ti ọ̀run kan sọ fún wòlíì Ọlọ́run pé: “A ti sé ọ̀rọ̀ náà mọ́ sọ́hùn-ún, a sì fi èdìdì dì í títí fi di ìgbà ìkẹyìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a óò wẹ̀ mọ́, wọn óò sì di funfun, a óò sì dán wọn wò; ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú: gbogbo àwọn ènìyàn búburú kì yóò kíyè sí i; ṣùgbọ́n [àwọn oníjìnlẹ̀ òye, NW] ni yóò kíyè sí i.” “Ìgbà ìkẹyìn” yẹn gan-an ni a ń gbé yìí. A ha rí ìyàtọ̀ gédégédé láàárín “àwọn ẹni búburú” àti “àwọn oníjìnlẹ̀ òye” bí? Dájúdájú, a rí i!
2. Báwo ni a ṣe ń mú Aísáyà 57:20, 21 ṣẹ lónìí?
2 Ní orí 57, ẹsẹ 20 àti 21, a ka àwọn ọ̀rọ̀ Aísáyà, ońṣẹ́ Ọlọ́run, tí ó sọ pé: “Àwọn ènìyàn búburú dà bí òkun ríru, nígbà tí kò lè sinmi, èyí tí omi rẹ̀ ń sọ ẹrẹ̀ àti èérí sókè. Àlàáfíà kò sí fún àwọn ènìyàn búburú, ni Ọlọ́run mi wí.” Ẹ wo bí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti ṣàpèjúwe ayé yìí lọ́nà ṣíṣe wẹ́kú tó, bí ó ti ń sún mọ́ ọ̀rúndún kọkànlélógún! Àwọn kan tilẹ̀ ń béèrè pé, ‘A óò ha lè dé ọ̀rúndún yẹn bí?’ Kí ni àwọn ońṣẹ́ tí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye ní í sọ fún wa?
3. (a) Ìfiwéra wo ni a ṣe nínú Jòhánù Kíní 5:19? (b) Báwo ni a ṣe ṣàpèjúwe àwọn “oníjìnlẹ̀ òye” nínú Ìṣípayá orí 7?
3 Àpọ́sítélì Jòhánù ní ìjìnlẹ̀ òye tí a mí sí látọ̀runwá. Nínú Jòhánù Kíní 5:19, ó sọ pé: “Àwa mọ̀ pé a pilẹ̀ ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ṣùgbọ́n gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ayé yìí ni a rí àwọn 144,000, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tẹ̀mí, tí àṣẹ́kù wọn tí wọ́n ń darúgbó sí i ṣì wà pẹ̀lú wa. “Ogunlọ́gọ̀ ńlá kan . . . láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” tí wọ́n ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún nísinsìnyí, tí àwọn pẹ̀lú ní ìjìnlẹ̀ òye, ń dara pọ̀ mọ́ àwọn àṣẹ́kù náà lónìí. “Àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí wọ́n jáde wá láti inú ìpọ́njú ńlá náà.” Èé sì ti ṣe tí a fi san èrè fún wọn? Ó jẹ́ nítorí pé, àwọn pẹ̀lú “ti fọ aṣọ ìgúnwà wọn, wọ́n sì ti sọ wọ́n di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Gẹ́gẹ́ bí ońṣẹ́ ìmọ́lẹ̀, àwọn pẹ̀lú “ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ ọlọ́wọ̀ fún [Ọlọ́run] tọ̀sán tòru nínú tẹ́ḿpìlì rẹ̀.”—Ìṣípayá 7:4, 9, 14, 15.
Àwọn Tí A Fẹnu Lásán Pè Ní Ońṣẹ́ Àlàáfíà
4. (a) Èé ṣe tí a fi kádàrá pé àwọn tí a fẹnu lásán pè ní ońṣẹ́ àlàáfíà nínú ayé Sátánì kò ní lè kẹ́sẹ járí? (b) Báwo ni Éfésù 4:18, 19 ṣe ṣeé mú lò lónìí?
4 Ṣùgbọ́n, kí ni ti àwọn tí a fẹnu lásán pè ní ońṣẹ́ àlàáfíà nínú ètò ìgbékalẹ̀ ayé Sátánì? A kà ní Aísáyà orí 33, ẹsẹ 7, pé: “Kíyè sí i, àwọn akọni kígbe lóde, àwọn [ońṣẹ́, NW] àlàáfíà sọkún kíkorò.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ òtítọ́ tó nípa àwọn tí ń sá kíjokíjo kiri lọ láti olú ìlú àgbáyé kan sí èkejì, nínú ìgbìyànjú láti mú àlàáfíà wá! Òtúbáńtẹ́ ni gbogbo rẹ̀! Èé ṣe tí ó fi rí bẹ́ẹ̀? Ó jẹ́ nítorí pé, wọ́n fi ẹ̀tẹ̀ tí ń da ayé láàmú sílẹ̀, wọ́n ń lọ pa làpálàpá. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọn kò gbà gbọ́ pé Sátánì wà, ẹni tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “ọlọ́run ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí.” (Kọ́ríńtì Kejì 4:4) Sátánì ti gbin ìwà ibi sáàárín ìran ènìyàn, ìyọrísí rẹ̀ sì ni pé, ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso, bá àpèjúwe inú Éfésù 4:18, 19 mu nísinsìnyí, pé: “Wọ́n . . . wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí, tí a sì sọ wọ́n di àjèjì sí ìyè tí ó jẹ́ ti Ọlọ́run, nítorí àìmọ̀kan tí ń bẹ nínú wọn, nítorí yíyigbì ọkàn àyà wọn. Níwọ̀n bí wọ́n ti wá ré kọjá gbogbo agbára òye ìwà rere, wọ́n fi ara wọn fún ìwà àìníjàánu láti máa fi ìwà ìwọra hu onírúurú ìwà àìmọ́ gbogbo.”
5. (a) Èé ṣe tí àwọn àjọ ẹ̀dá ènìyàn fi kùnà gẹ́gẹ́ bí olùmú-àlàáfíà-wá? (b) Ìhìn iṣẹ́ atuninínú wo ni Orin Dáfídì 37 mú jáde?
5 Kò sí àjọ ẹ̀dá ènìyàn aláìpé kankan tí ó lè fa ìwọra, ìmọtara-ẹni-nìkan, àti ìkórìíra tí ó gbalé gbòde lónìí tu kúrò nínú ọkàn àyà ẹ̀dá ènìyàn. Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, nìkan ṣoṣo ni ó lè ṣe ìyẹn! Síwájú sí i, kìkì ìwọ̀nba ènìyàn kéréje, tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn tútù láàárín aráyé, ni ó ṣe tán láti jọ̀wọ́ ara wọn fún ìtọ́sọ́nà rẹ̀. A fi àbájáde rẹ̀ fún àwọn wọ̀nyí àti fún àwọn olubi inú ayé wéra nínú Orin Dáfídì 37:9-11 pé: “A óò ké àwọn olùṣe búburú kúrò: ṣùgbọ́n àwọn tí ó dúró de Olúwa ni yóò jogún ayé. Nítorí pé nígbà díẹ̀, àwọn ènìyàn búburú kì yóò sí: . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò jogún ayé; wọn óò sì máa ṣe inú dídùn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà.”
6, 7. Àkọsílẹ̀ wo nípa àwọn ìsìn ayé ni ó fi hàn pé wọ́n ti kùnà láti jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà?
6 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a ha lè rí àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà láàárín àwọn ìsìn ayé tí àìsàn ti kọlù yí bí? Tóò, àkọsílẹ̀ wo ni ìsìn ní títí di ọjọ́ òní? Ìtàn fi hàn pé, ìsìn ti lọ́wọ́ nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ tí ó ti wáyé jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, àní, òun pàápàá ni ó súnná sí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú wọn. Fún àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn náà, Christian Century, ti ọ̀sẹ̀ August 30, 1995, nígbà tí ó ń ròyìn nípa rúkèrúdò ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí, sọ pé: “Ní Bosnia tí ó wà lábẹ́ àwọn Serb, àwọn àlùfáà jókòó ní ìlà iwájú nínú ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tí wọ́n fúnra wọn gbé kalẹ̀, àwọn ni wọ́n sì tún wà ní ìlà iwájú, níbi tí a ti ń gbàdúrà fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti àwọn ohun ìjà, kí ogun tó bẹ̀rẹ̀.”
7 Iṣẹ́ tí àwọn míṣọ́nnárì Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣe ní Áfíríkà fún ọ̀rúndún kan kò mú ìyọrísí tí ó sàn ju èyí wá, gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn kedere ní Rwanda, ilẹ̀ kan tí a gbà gbọ́ pé ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn olùgbé rẹ̀ jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì. Ìwé agbéròyìnjáde náà, The New York Times, ti July 7, 1995, ròyìn pé: “Golias, ìwé ìròyìn Kátólíìkì, tí a gbé karí ìmọ̀ gbígbòòrò, tí a tẹ̀ jáde ní Lyons [ilẹ̀ Faransé], wéwèé láti dárúkọ àwọn àlùfáà Rwanda 27 àti àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé mẹ́rin mìíràn, tí ó sọ pé wọ́n pànìyàn tàbí tí wọ́n fún ìpànìyàn níṣìírí ní Rwanda ní èṣí.” Àjọ Ẹ̀tọ́ Ọmọ Ilẹ̀ Áfíríkà, ètò àjọ kan ni London tí ń rí sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, ní èyí láti sọ: “Yàtọ̀ sí pé ó panu mọ́, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì gbọ́dọ̀ dáhùn fún ọ̀nà tí àwọn àlùfáà rẹ̀, àwọn pásítọ̀ rẹ̀ àti àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé rẹ̀, fi fi taratara lọ́wọ́ nínú ìpalápatán ẹ̀yà náà.” Èyí bá bí ipò nǹkan ti rí ní Ísírẹ́lì mu, nígbà tí Jeremáyà, ońṣẹ́ tòótọ́ ti Jèhófà, ṣàpèjúwe ‘bí ojú ṣe ti’ Ísírẹ́lì, àti àwọn alákòóso rẹ̀, àwọn àlùfáà rẹ̀, àti àwọn wòlíì rẹ̀, ní fífi kún un pé: “Ẹ̀jẹ̀ ẹ̀mí àwọn tálákà àti aláìṣẹ̀ ń bẹ lára aṣọ rẹ.”—Jeremáyà 2:26, 34.
8. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé Jeremáyà jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà?
8 A ti máa ń fìgbà gbogbo pe Jeremáyà ní wòlíì ègbé, ṣùgbọ́n lọ́nà yíyẹ wẹ́kú, a tún lè pè é ní ońṣẹ́ àlàáfíà Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó tọ́ka sí àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti ṣe ṣáájú rẹ̀. Jèhófà lo Jeremáyà láti kéde ìdájọ́ sórí Jerúsálẹ́mù, ní sísọ pé: “Nítorí ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìrunú fún mi láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ wá títí di òní yìí; tó bẹ́ẹ̀ tí èmi óò mú un kúrò níwájú mi. Nítorí gbogbo ibi àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Júdà, tí wọ́n ti ṣe láti mú mi bínú, àwọn, àwọn ọba wọn, ìjòyè wọn, àlùfáà wọn, àti wòlíì wọn, àti àwọn ọkùnrin Júdà, àti àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù.” (Jeremáyà 32:31, 32) Èyí ṣàpẹẹrẹ ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn alákòóso àti àwùjọ àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù lónìí. Kí àlàáfíà tòótọ́ baà lè jọba, a gbọ́dọ̀ mú àwọn tí ń súnná sí ìwà ibi àti ìwà ipá wọ̀nyí kúrò! Wọn kì í ṣe ońṣẹ́ àlàáfíà rárá.
Àjọ UN Ha Jẹ́ Olùmú-Àlàáfíà-Wá Bí?
9. Báwo ni àjọ UN ti ṣe sọ pé òun jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà?
9 Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè kò ha lè di ońṣẹ́ àlàáfíà tòótọ́ bí? Ó ṣe tán, ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú àkọsílẹ̀ ète rẹ̀, tí a gbé kalẹ̀ ní June 1945, ọjọ́ 41 péré ṣáájú kí bọ́ǹbù átọ́míìkì tó run Hiroshima, sọ ète rẹ̀: “láti gba àwọn ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn lọ́wọ́ ìyà ogun.” Àwọn 50 orílẹ̀-èdè tí ó ṣeé ṣe kí wọ́n di mẹ́ńbà Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nígbà náà lọ́hùn-ún, ní láti “pa okun [wọn] pọ̀ láti mú kí àlàáfíà àti ààbò jọba káàkiri àgbáyé.” Lónìí, àjọ UN ní orílẹ̀-èdè 185 tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀, tí a gbà gbọ́ pé gbogbo wọn pátá fara jìn fún ìgbésẹ̀ kan náà.
10, 11. (a) Báwo ni àwọn aṣáájú ìsìn ti ṣe sọ ìtìlẹ́yìn wọn fún àjọ UN jáde? (b) Ní ọ̀nà wo ni àwọn póòpù ti gbà gbé “Ìhìn Rere Ìjọba Ọlọ́run” kalẹ̀ lọ́nà òdì?
10 Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, a ti kan sáárá sí àjọ UN, pàápàá jù lọ láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣáájú ìsìn. Ní April 11, 1963, Póòpù John Kẹtàlélógún fọwọ́ sí lẹ́tà rẹ̀ sí gbogbo àwọn bíṣọ́ọ̀bù, tí ó pe àkọlé rẹ̀ ní “Pacem in Terris” (Àlàáfíà Lórí Ilẹ̀ Ayé) nínú èyí tí ó sọ pé: “Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn wa jíjinlẹ̀ pé kí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè—nínú ìgbékalẹ̀ rẹ̀ àti nínú dúkìá rẹ̀—lè túbọ̀ lágbára sí i láti bójú tó ìtóbi àti iyì iṣẹ́ rẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ní June 1965, ní San Francisco, àwọn aṣáájú ìsìn, tí wọ́n sọ pé àwọn ṣojú fún ìlàjì iye àwọn olùgbé ayé, ṣayẹyẹ àjọ̀dún ogún ọdún tí a dá àjọ UN sílẹ̀. Bákan náà ní 1965, Póòpù Paul Kẹfà, nígbà ìbẹ̀wò kan tí ó ṣe sí àjọ UN, ṣàpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìrètí tí ó kẹ́yìn fún ìṣọ̀kan àti àlàáfíà.” Ní 1986, Póòpù John Paul Kejì fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú ṣíṣonígbọ̀wọ́ Ọdún Àlàáfíà Àgbáyé ti Àjọ UN.
11 Ní àfikún sí i, nígbà ìbẹ̀wò rẹ̀ ní October 1995, póòpù náà polongo pé: “A ń ṣayẹyẹ Ìhìn Rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí.” Ṣùgbọ́n, òun ha jẹ́ ońṣẹ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní tòótọ́ bí? Ní sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣòro ayé, ó ń bá a lọ ní sísọ pé: “Bí a ti ń dojú kọ àwọn ìpèníjà ńláǹlà wọ̀nyí, báwo ni a ṣe lè kùnà láti mọ ipa tí Àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ń kó?” Póòpù yan àjọ UN, dípò Ìjọba Ọlọ́run.
Ìdí fún ‘Sísọkún Kíkorò’
12, 13. (a) Báwo ni àjọ UN ṣe hùwà lọ́nà tí a ṣàpèjúwe nínú Jeremáyà 6:14? (b) Èé ṣe tí àwọn aṣáájú àjọ UN fi wà lára àwọn tí a ṣàpèjúwe nínú Aísáyà 33:7?
12 Ayẹyẹ àjọ̀dún àádọ́ta ọdún àjọ UN ti kùnà láti ṣí ìfojúsọ́nà gidi èyíkéyìí fún “àlàáfíà lórí ilẹ̀ ayé” payá. Òǹkọ̀wé kan fi ìdí kan hàn nínú ìwé agbéròyìnjáde náà, The Toronto Star, ti Kánádà, nígbà tí ó kọ̀wé pé: “Kìnnìún tí kò léyín lẹ́nu ni àjọ UN, tí ń bú ramúramù nígbà tí ẹ̀dá òǹrorò kan bá dojú kọ ọ́, ṣùgbọ́n tí ó ní láti dúró kí àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ bá a fi eyín àtọwọ́dá rẹ̀ sẹ́nu rẹ̀, kí ó tó lè buni jẹ.” Ọ̀pọ̀ ìgbà tí ó bá sì buni jẹ rèé, oró ẹnu rẹ̀ kì í lágbára tó, ẹ̀pa kì í sì í bóró mọ́. Àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà nínú ètò ìgbékalẹ̀ ayé ìsinsìnyí, pàápàá jù lọ àwọn tí ó wà ní Kirisẹ́ńdọ̀mù, ti ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ Jeremáyà 6:14 ní àsọtúnsọ pé: “Wọ́n sì ti wo ọgbẹ́ ọmọbìnrin ènìyàn mi fẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n wí pé, Àlàáfíà! Àlàáfíà! nígbà tí kò sí àlàáfíà.”
13 Àwọn agbapò akọ̀wé àgbà àjọ UN ti fi torí tọrùn ṣiṣẹ́, kò sì sí iyè méjì pé wọ́n ṣe é tọkàntọkàn, láti mú kí àjọ UN ṣàṣeyọrí. Ṣùgbọ́n awuyewuye gbígbóná janjan ìgbà gbogbo láàárín àwọn mẹ́ńbà 185, tí wọ́n ní ète ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́kàn nípa bí wọn yóò ṣe dín ogun kù, bí wọn yóò ṣe gbé ìlànà kalẹ̀, àti bí wọn yóò ṣe gbọ́ bùkátà, ti dabarú ìfojúsọ́nà fún àṣeyọrí. Nínú ìròyìn ọdọọdún rẹ̀ ti 1995, akọ̀wé àgbà nígbà náà lọ́hùn-ún kọ̀wé nípa ìlọsílẹ̀ “ìdààmú ọkàn nípa ìjàǹbá ogun àgbáyé ti átọ́míìkì” gẹ́gẹ́ bí èyí tí ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún “àwọn orílẹ̀-èdè láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀ síhà ìtẹ̀síwájú ọrọ̀ ajé àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà fún gbogbo ìran ènìyàn.” Ṣùgbọ́n, ó fi kún un pé: “Ó bani nínú jẹ́ pé, àkọsílẹ̀ àwọn àlámọ̀rí ayé jálẹ̀ ọdún díẹ̀ tí ó ti kọjá, ti fi hàn pé àwọn ìfojúsọ́nà fún rere wọ̀nyẹn kò láyọ̀lé.” Ní tòótọ́, àwọn tí a rò pé wọn yóò jẹ́ ońṣẹ́ àlàáfíà ‘ń sọkún kíkorò.’
14. (a) Èé ṣe tí a fi lè sọ pé, àjọ UN ti wọko gbèsè, àti pé ìwà wọn ti bà jẹ́ bàlùmọ̀? (b) Báwo ni Jeremáyà 8:15 ṣe ń ní ìmúṣẹ?
14 Ọ̀rọ̀ àkọlé kan nínú ìwé agbéròyìnjáde náà, The Orange County Register, ti California, kà pé: “Àjọ U.N. Ti Wọko Gbèsè, Ìwà Rẹ̀ Sì Ti Bà Jẹ́ Bàlùmọ̀.” Àpilẹ̀kọ náà sọ pé, láàárín 1945 sí 1990, ogun tí ó jà lé ní 80, tí ó sì gba ẹ̀mí tí ó lé ní 30 mílíọ̀nù. Ó ṣàyọlò ọ̀rọ̀ òǹkọ̀wé kan nínú ìwé ìròyìn náà, Reader’s Digest, ìtẹ̀jáde October 1995, tí ó “ṣàpèjúwe ìgbésẹ̀ ológun tí àjọ U.N. ń gbé gẹ́gẹ́ bí èyí tí a fi ‘àwọn ọ̀gágun tí kò dáńgájíá, àwọn ọmọ ogun tí kò mọ̀wàá hù, lílẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn òfinràn, kíkùnà láti dènà ìwà burúkú àti dídákún ìfòyà nígbà míràn pàápàá’ dá mọ̀ yàtọ̀. Ní àfikún sí i, ‘ìfi-nǹkan-ṣòfò, jìbìtì, àti ìwà ìkà wọn kò ṣeé fẹnu sọ.’” Nínú abala kan tí a pe àkọlé rẹ̀ ní, “Àádọ́ta Ọdún Àjọ U.N.,” ìwé agbéròyìnjáde náà, The New York Times, gbé àkọlé náà, “Àìsábòójútó Dídáńgájíá àti Ìfi-Nǹkan-Ṣòfò Bomi Paná Èrò Rere Àjọ U.N.” Ìwé agbéròyìnjáde náà, The Times, ti London, England, gbé àpilẹ̀kọ kan pẹ̀lú àkọlé gàdàgbà náà, “Ẹni Àádọ́ta Ọdún Abara Hẹ́gẹhẹ̀gẹ—Àjọ UN nílò ètò ìmárale láti lè pa dà sí ipò rẹ̀ àtẹ̀yìnwá.” Ní tòótọ́, bí a ṣe kà á gan-an nínú Jeremáyà orí 8, ẹsẹ 15, ni ó rí: “Àwá retí àlàáfíà, ṣùgbọ́n kò sí ìrètí kan, àti ìgbà dídá ara, sì kíyè sí i, ìdààmú!” Ewu ìparun runlé rùnnà ti átọ́míìkì ṣì ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ lórí aráyé. Ó ṣe kedere pé, àjọ UN kì í ṣe ońṣẹ́ àlàáfíà tí aráyé nílò.
15. Báwo ni Bábílónì ìgbàanì àti àwọn ìsìn tí ó bí ṣe jẹ́ apanirun àti asọnidarìndìn?
15 Ibo ni gbogbo èyí yóò jálẹ̀ sí? Ọ̀rọ̀ alásọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ṣe kedere. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kí ní ń dúró de àwọn ìsìn èké ayé, tí wọ́n ti fìgbà gbogbo jẹ́ ọ̀rẹ́ kò-rí-kò-sùn àjọ UN? Wọ́n jẹ́ ọmọ ìyá olórìṣà kan náà, Bábílónì ìgbàanì. Lọ́nà tí ó ṣe wẹ́kú, a ṣàpèjúwe wọn nínú Ìṣípayá 17:5 gẹ́gẹ́ bíi “Bábílónì Ńlá, ìyá àwọn aṣẹ́wó àti ti àwọn ohun ìríra ilẹ̀ ayé.” Jeremáyà ṣàpèjúwe ègbé tí ń bọ̀ wá sórí ètò àjọ ńlá alágàbàgebè yí. Gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́wó, wọn ti fa ojú àwọn òṣèlú ayé mọ́ra, ní fífi ẹnu pọ́n àjọ UN, tí wọ́n sì ń ṣe panṣágà pẹ̀lú àwọn agbára òṣèlú tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà rẹ̀. Wọ́n ti kó ipa pàtàkì nínú ogun tí a ti jà nínú ìtàn. Oníròyìn kan sọ nípa ogun ìsìn ní Íńdíà pé: “Karl Marx tọ́ka sí ìsìn gẹ́gẹ́ bí oògùn apanilọ́bọlọ̀ fún gbogbo mùtúmùwà. Ṣùgbọ́n, gbólóhùn yẹn kò lè fi bẹ́ẹ̀ tọ̀nà nítorí pé oògùn apanilọ́bọlọ̀ máa ń múni rọ wọ́jọ́, ó sì ń sọni di arìndìn. Rárá o, kokéènì tí ń pani bí ọtí ni ìsìn jọ. Ó ń múni hùwà bí ayírí, ó sì jẹ́ ipá tí ń ṣèparun gidigidi.” Òǹkọ̀wé yẹn kò fi bẹ́ẹ̀ tọ̀nà pẹ̀lú. Ìsìn ń sọni di arìndìn, ó sì ń pani run.
16. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí àwọn aláìlábòsí ọkàn sá lọ kúrò nínú Bábílónì Ńlá nísinsìnyí? (Tún wo Ìṣípayá 18:4, 5.)
16 Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ó yẹ kí àwọn aláìlábòsí ọkàn ṣe? Jeremáyà, ońṣẹ́ Ọlọ́run, fún wa ní ìdáhùn pé: “Ẹ sá lọ kúrò nínú Bábílónì, kí olúkúlùkù sì pèsè fún ọkàn rẹ̀. . . . Nítorí ó jẹ́ àkókò ẹ̀san tí ó jẹ́ ti Jèhófà.” A láyọ̀ pé, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ti jáde kúrò nínú àhámọ́ Bábílónì Ńlá, ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ìwọ ha jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí bí? Nígbà náà, o lè lóye dáradára bí Bábílónì Ńlá ti ṣe nípa lórí àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé tó: “Àwọn orílẹ̀-èdè ti mu nínú ọtí wáìnì rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń ṣe bí ayírí ṣáá.”—Jeremáyà 51:6, 7, NW.
17. Ìdájọ́ wo ni ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé sórí Bábílónì Ńlá, ìgbésẹ̀ wo ni yóò sì tẹ̀ lé e?
17 Láìpẹ́, Jèhófà yóò fọgbọ́n darí àwọn “ayírí” mẹ́ńbà àjọ UN láti kọlu ìsìn èké, gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 17:16, 17 ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀: “Àwọn wọ̀nyí yóò kórìíra aṣẹ́wó náà wọn yóò sì sọ ọ́ di ìparun dahoro àti ìhòòhò, wọn yóò sì jẹ àwọn ibi kìkìdá ẹran ara rẹ̀ tán wọn yóò sì fi iná sun ún pátápátá.” Èyí yóò sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ ìpọ́njú ńlá, tí a tọ́ka sí nínú Mátíù 24:21, tí yóò sì dé òtéńté rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì, ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè. Gẹ́gẹ́ bíi Bábílónì ìgbàanì, Bábílónì Ńlá yóò gba ìdájọ́ tí a kéde nínú Jeremáyà 51:13, 25 pé: “Ìwọ ẹni tí ń gbé ẹ̀bá omi púpọ̀, tí ó pọ̀ ní ìṣúra, òpin rẹ dé, ìwọ̀n ìkógun olè rẹ kún. Wò ó, èmi dojú kọ ọ́, ìwọ òkè ìparun! ni Olúwa wí, tí ó pa gbogbo ilẹ̀ ayé run; èmi óò sì na ọwọ́ mi sórí rẹ, èmi óò sì yí ọ lulẹ̀ láti orí àpáta wá, èmi óò sì ṣe ọ́ ní òkè jíjóná.” Àwọn orílẹ̀-èdè oníwà ìbàjẹ́, arógunyọ̀, yóò tẹ̀ lé ìsìn èké lọ sínú ìparun, bí ọjọ́ ẹ̀san Jèhófà ti ń dé bá àwọn náà pẹ̀lú.
18. Nígbà wo ni Aísáyà 48:22 yóò ní ìmúṣẹ, báwo sì ni yóò ṣe ní ìmúṣẹ?
18 Ní Tẹsalóníkà Kíní 5:3, a sọ nípa àwọn olubi pé: “Ìgbà yòó wù tí ó jẹ́ tí wọ́n bá ń wí pé: ‘Àlàáfíà àti ààbò!’ nígbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn gan-an gẹ́gẹ́ bí ìrora gógó wàhálà lórí aboyún; wọn kì yóò sì yè bọ́ lọ́nà kọnà.” Àwọn wọ̀nyí ni wòlíì Aísáyà sọ nípa wọn pé: “Kíyè sí i, . . . àwọn [ońṣẹ́, NW] àlàáfíà sọkún kíkorò.” (Aísáyà 33:7) Ní tòótọ́, gẹ́gẹ́ bí a ti kà á nínú Aísáyà 48:22 ni ó rí, “àlàáfíà kò sí fún àwọn ènìyàn búburú, ni Olúwa wí.” Ṣùgbọ́n, ọjọ́ ọ̀la wo ni ó dúró de àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà tòótọ́ ti Ọlọ́run? Àpilẹ̀kọ wa tí ó tẹ̀ lé e yóò sọ ọ́.
Ìbéèrè fún Àtúnyẹ̀wò
◻ Àwọn ọ̀rọ̀ lílágbára wo ni àwọn wòlíì Ọlọ́run fi táṣìírí àwọn èké ońṣẹ́?
◻ Èé ṣe tí àwọn àjọ ẹ̀dá ènìyàn fi kùnà nínú ìgbìyànjú wọn láti mú àlàáfíà pípẹ́ títí wá?
◻ Báwo ni àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà tòótọ́ ṣe yàtọ̀ pátápátá sí àwọn alátìlẹ́yìn àjọ UN?
◻ Kí ni àwọn ọlọ́kàn tútù gbọ́dọ̀ ṣe láti baà lè gbádùn àlàáfíà tí Jèhófà ṣèlérí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Aísáyà, Jeremáyà, àti Dáníẹ́lì lápapọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ nípa ìkùnà ẹ̀dá ènìyàn lásán láti mú àlàáfíà wá
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
“Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.”—Àpọ́sítélì Jòhánù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
“Wọ́n . . . wà nínú òkùnkùn ní ti èrò orí.”—Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù