Àwọn Àgùntàn Míràn àti Májẹ̀mú Tuntun
“Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè . . . , gbogbo àwọn tí ń pa sábáàtì mọ́ kí wọ́n má baà sọ ọ́ di aláìmọ́, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi, dájúdájú, èmi yóò mú wọn wá sí òkè ńlá mímọ́ mi pẹ̀lú.”—AÍSÁYÀ 56:6, 7, NW.
1. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú ìran Jòhánù, kí ni ohun tí a ṣàṣeparí nígbà tí a di ẹ̀fúùfù ìdájọ́ Jèhófà mú? (b) Ogunlọ́gọ̀ pípẹtẹrí wo ni Jòhánù rí?
NÍNÚ ìran kẹrin inú ìwé Ìṣípayá, àpọ́sítélì Jòhánù rí bí a ṣe di ẹ̀fúùfù aṣèparun ti ìdájọ́ Jèhófà mú nígbà tí fífi èdìdì di àwọn mẹ́ńbà “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ń parí lọ. Àwọn wọ̀nyí ni a kọ́kọ́ bù kún nípasẹ̀ Jésù, olórí irú ọmọ Ábúráhámù. (Gálátíà 6:16; Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Ìṣípayá 7:1-4) Nínú ìran kan náà yẹn, Jòhánù rí ‘ogunlọ́gọ̀ ńlá kan, èyí tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n, wọ́n ń ké pẹ̀lú ohùn rara, wí pé: “Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni àwa jẹ ní gbèsè fún ìgbàlà.”’ (Ìṣípayá 7:9, 10) Ní sísọ pé, “Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni àwa jẹ ní gbèsè fún ìgbàlà,” ogunlọ́gọ̀ ńlá náà fi hàn pé a bù kún àwọn pẹ̀lú nípasẹ̀ Irú Ọmọ Ábúráhámù.
2. Nígbà wo ni ogunlọ́gọ̀ ńlá fara hàn, báwo sì ni a ṣe dá a mọ̀?
2 Láti ọdún 1935 ni a ti dá ogunlọ́gọ̀ ńlá yìí mọ̀, lónìí, ó ti lé ní mílíọ̀nù márùn-ún. Níwọ̀n bí a ti sàmì sí i láti la ìpọ́njú ńlá já, a óò ya àwọn mẹ́ńbà rẹ̀ sọ́tọ̀ fún ìyè àìnípẹ̀kun nígbà tí Jésù bá ń ya “àwọn àgùntàn” sọ́tọ̀ kúrò lára “àwọn ewúrẹ́.” Àwọn Kristẹni ogunlọ́gọ̀ ńlá wà lára “àwọn àgùntàn míràn” nínú òwe àkàwé Jésù ti àwọn agbo àgùntàn. Wọ́n nírètí láti wà láàyè títí láé nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Mátíù 25:31-46; Jòhánù 10:16; Ìṣípayá 21:3, 4.
3. Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn ṣe yàtọ̀ síra ní ti májẹ̀mú tuntun?
3 Fún àwọn 144,000, a pín ìbùkún májẹ̀mú Ábúráhámù kàn wọ́n nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun. Gẹ́gẹ́ bí olùkópa nínú májẹ̀mú yìí, wọ́n wá “[sábẹ́] inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí” àti “[sábẹ́] òfin sí Kristi.” (Róòmù 6:15; Kọ́ríńtì Kíní 9:21) Nítorí náà, kìkì àwọn 144,000 mẹ́ńbà Ísírẹ́lì Ọlọ́run ni ó ti ṣàjọpín lọ́nà yíyẹ nínú àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ nígbà Ìṣe Ìrántí ikú Jésù, àwọn nìkan sì ni Jésù bá dá májẹ̀mú Ìjọba kan. (Lúùkù 22:19, 20, 29) Àwọn mẹ́ńbà ogunlọ́gọ̀ ńlá kò kópa nínú májẹ̀mú tuntun náà. Ṣùgbọ́n, wọ́n ń kẹ́gbẹ́ pọ̀ pẹ̀lú Ísírẹ́lì Ọlọ́run, wọ́n sì ń gbé pẹ̀lú wọn nínú “ilẹ̀” wọn. (Aísáyà 66:8) Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé àwọn pẹ̀lú wá sábẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà àti sábẹ́ òfin sí Kristi. Bí wọn kò tilẹ̀ jẹ́ olùkópa nínú májẹ̀mú tuntun, wọ́n jẹ́ olùjàǹfààní nínú rẹ̀.
“Àwọn Ọmọ Ilẹ̀ Òkèèrè” àti “Ísírẹ́lì Ọlọ́run”
4, 5. (a) Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ti sọ, àwùjọ wo ni yóò máa ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà? (b) Báwo ni Aísáyà 56:6, 7 ṣe nímùúṣẹ sí ogunlọ́gọ̀ ńlá lára?
4 Wòlíì Aísáyà kọ̀wé pé: “Àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó . . . ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà láti máa ṣe ìránṣẹ́ fún un àti láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà, láti lè di ìránṣẹ́ fún un, gbogbo àwọn tí ń pa sábáàtì mọ́ kí wọ́n má baà sọ ọ́ di aláìmọ́, tí wọ́n sì rọ̀ mọ́ májẹ̀mú mi, dájúdájú, èmi yóò mú wọn wá sí òkè ńlá mímọ́ mi pẹ̀lú, èmi yóò sì mú kí wọ́n máa yọ̀ nínú ilé àdúrà mi. Odindi ọrẹ ẹbọ sísun wọn àti àwọn ẹbọ wọn yóò jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lórí pẹpẹ mi.” (Aísáyà 56:6, 7, NW) Ní Ísírẹ́lì, èyí túmọ̀ sí pé “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè,” àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, yóò jọ́sìn Jèhófà—ní nínífẹ̀ẹ́ orúkọ rẹ̀, ṣíṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀ inú májẹ̀mú Òfin náà, ní pípa Sábáàtì mọ́, àti ní ṣíṣèrúbọ ní tẹ́ńpìlì, “ilé àdúrà” Ọlọ́run.—Mátíù 21:13.
5 Ní ọjọ́ wa, àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá ni “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tí ó . . . ti dara pọ̀ mọ́ Jèhófà.” Àwọn wọ̀nyí ń ṣe ìránṣẹ́ fún Jèhófà ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ísírẹ́lì Ọlọ́run. (Sekaráyà 8:23) Wọ́n ń rúbọ tí ó ṣètẹ́wọ́gbà kan náà gẹ́gẹ́ bíi ti Ísírẹ́lì Ọlọ́run. (Hébérù 13:15, 16) Wọ́n ń jọ́sìn nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Ọlọ́run, “ilé àdúrà” rẹ̀. (Fi wé Ìṣípayá 7:15.) Wọ́n ha ń pa ọjọ́ Sábáàtì ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ mọ́ bí? A kò pàṣẹ fún yálà àwọn ẹni àmì òróró tàbí àwọn àgùntàn míràn láti ṣe èyí. (Kólósè 2:16, 17) Ṣùgbọ́n, Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ Hébérù pé: “Ìsinmi sábáàtì kan ṣì kù fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run. Nítorí ẹni tí ó ti wọ inú ìsinmi Ọlọ́run òun fúnra rẹ̀ pẹ̀lú ti sinmi kúrò nínú àwọn iṣẹ́ tirẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú tirẹ̀.” (Hébérù 4:9, 10) Àwọn Hébérù wọ̀nyẹn wọnú “ìsinmi sábáàtì” yí nígbà tí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ “òdodo Ọlọ́run,” tí wọ́n sì sinmi nínú gbígbìyànjú láti dá ara wọn láre nípasẹ̀ iṣẹ́ Òfin. (Róòmù 10:3, 4) Àwọn Kèfèrí tí ó jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró ń gbádùn irú ìsinmi kan náà nípa fífi ara wọn sábẹ́ òdodo Jèhófà. Ogunlọ́gọ̀ ńlá ń dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ìsinmi náà.
6. Báwo ni àwọn àgùntàn míràn lónìí ṣe fi ara wọ́n sábẹ́ májẹ̀mú tuntun?
6 Ní àfikún sí i, àwọn àgùntàn míràn ń fi ara wọn sábẹ́ májẹ̀mú tuntun, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ìgbàanì ṣe fi ara wọn sábẹ́ májẹ̀mú Òfin. Lọ́nà wo? Kì í ṣe nípa dídi olùkópa nínú rẹ̀ bí kò ṣe nípa mímú ara wọn wá sábẹ́ àwọn òfin tí ó wé mọ́ ọn, kí wọ́n sì jàǹfààní láti inú ìṣètò rẹ̀. (Fi wé Jeremáyà 31:33, 34.) Bíi ti àwọn ẹni àmì òróró alájọṣepọ̀ wọn, a kọ òfin Jèhófà ‘sí ọkàn àyà’ àwọn àgùntàn míràn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àṣẹ àti ìlànà Jèhófà gidigidi, wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i. (Orin Dáfídì 37:31; 119:97) Bíi ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, wọ́n mọ Jèhófà. (Jòhánù 17:3) Ìkọlà ńkọ́? Ní nǹkan bí 1,500 ọdún ṣáájú kí a tó dá májẹ̀mú tuntun, Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kọ àyà yín ní ilà.” (Diutarónómì 10:16; Jeremáyà 4:4) Bí ìkọlà ti ẹran ara tilẹ̀ bá Òfin kọjá lọ, àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn gbọ́dọ̀ “kọ” ọkàn àyà wọn “ní ilà.” (Kólósè 2:11) Níkẹyìn, Jèhófà dárí àìṣedéédéé àwọn àgùntàn míràn jì wọ́n lórí ìpìlẹ̀ “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” Jésù tí a ta sílẹ̀. (Mátíù 26:28; Jòhánù Kíní 1:9; 2:2) Ọlọ́run kò gbà wọ́n ṣọmọ gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí, bí ó ti ṣe fún àwọn 144,000. Ṣùgbọ́n, ó polongo àwọn àgùntàn míràn ní olódodo, ní ọ̀nà tí a gbà polongo Ábúráhámù ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run.—Mátíù 25:46; Róòmù 4:2, 3; Jákọ́bù 2:23.
7. Ìrètí wo ni ó ṣí sílẹ̀ fún àwọn àgùntàn míràn lónìí, tí a polongo ní olódodo gẹ́gẹ́ bí a ti polongo Ábúráhámù?
7 Fún àwọn 144,000, pípolongo wọn ní olódodo ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún níní tí wọ́n ní ìrètí ṣíṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba ọ̀run. (Róòmù 8:16, 17; Gálátíà 2:16) Fún àwọn àgùntàn míràn, pípolongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run fún wọn láǹfààní láti tẹ́wọ́ gba ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú párádísè lórí ilẹ̀ ayé—yálà nípa líla Amágẹ́dọ́nì já gẹ́gẹ́ bí ara ogunlọ́gọ̀ ńlá tàbí nípasẹ̀ “àjíǹde àwọn olódodo.” (Ìṣe 24:15) Ẹ wo irú àǹfààní tí ó jẹ́ láti ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀ àti láti jẹ́ ọ̀rẹ́ Ọba Aláṣẹ àgbáyé, láti jẹ́ “àtìpó nínú àgọ́ [rẹ̀]”! (Orin Dáfídì 15:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, a bù kún àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn lọ́nà àgbàyanu nípasẹ̀ Jésù, Irú Ọmọ Ábúráhámù.
Ọjọ́ Ètùtù Gíga Jù
8. Kí ni àwọn ìrúbọ Ọjọ́ Ètùtù lábẹ́ Òfin dúró fún?
8 Nígbà tí ó ń jíròrò nípa májẹ̀mú tuntun, Pọ́ọ̀lù rán àwọn òǹkàwé rẹ̀ létí Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún lábẹ́ májẹ̀mú Òfin. Ní ọjọ́ náà, a máa ń ṣe àwọn ìrúbọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀—ọ̀kan fún ẹ̀yà àlùfáà Léfì àti òmíràn fún ẹ̀yà 12 tí kì í ṣe àlùfáà. A ti ṣàlàyé èyí tipẹ́ pé ó ń ṣàpẹẹrẹ ìrúbọ ńlá ti Jésù tí yóò ṣàǹfààní fún àwọn 144,000 tí wọ́n ní ìrètí ti ọ̀run àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ó ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé.a Pọ́ọ̀lù fi hàn pé nínú ìmúṣẹ náà, àwọn àǹfààní ẹbọ Jésù yóò wá nípasẹ̀ Ọjọ́ Ètùtù gíga jù kan lábẹ́ májẹ̀mú tuntun. Gẹ́gẹ́ bí Àlùfáà Àgbà ti ọjọ́ gíga jù yí, Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ pípé lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ètùtù láti lè gba “ìdáǹdè àìnípẹ̀kun” fún ẹ̀dá ènìyàn.—Hébérù 9:11-24.
9. Níwọ̀n bí wọ́n ti wà nínú májẹ̀mú tuntun, kí ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí ó jẹ́ Hébérù lè tẹ́wọ́ gbà?
9 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ Kristẹni tí ó jẹ́ Hébérù ṣì jẹ́ “onítara fún Òfin [Mósè].” (Ìṣe 21:20) Nígbà náà, lọ́nà tí ó bá a mu wẹ́kú, Pọ́ọ̀lù rán wọn létí pé: “[Jésù] jẹ́ alárinà májẹ̀mú tuntun kan, kí àwọn ẹni tí a ti pè lè gba ìlérí ogún àìnípẹ̀kun, nítorí tí ikú kan ti ṣẹlẹ̀ fún ìtúsílẹ̀ wọn nípasẹ̀ ìràpadà kúrò nínú àwọn ìrélànàkọjá lábẹ́ májẹ̀mú ti ìṣáájú.” (Hébérù 9:15) Májẹ̀mú tuntun tú àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Hébérù sílẹ̀ nínú májẹ̀mú láéláé, tí ó tú ipò ẹ̀ṣẹ̀ wọn fó. Ọpẹ́lọpẹ́ májẹ̀mú tuntun, wọ́n lè gba “ìlérí ogún àìnípẹ̀kun [ti ọ̀run].”
10. Kí ni àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún?
10 “Olúkúlùkù” ẹni “tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọkùnrin” yóò jàǹfààní nínú ẹbọ ìràpadà náà. (Jòhánù 3:16, 36) Pọ́ọ̀lù wí pé: “A fi Kristi rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé láti ru ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀; ní ìgbà kejì tí ó bá sì fara hàn yóò jẹ́ láìsí ẹ̀ṣẹ̀ àti fún àwọn wọnnì tí ń fi taratara wá a fún ìgbàlà wọn.” (Hébérù 9:28) Lónìí, àwọn tí ń fi taratara wá Jésù ní àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti Ísírẹ́lì Ọlọ́run tí wọ́n ṣì wà láàyè àti àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ó para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí àwọn pẹ̀lú ní ogún àìnípẹ̀kun, nínú. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún májẹ̀mú tuntun àti fún ìbùkún tí ń fúnni ní ìyè, tí ó bá a rìn, títí kan Ọjọ́ Ètùtù gíga jù àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ ti Àlùfáà Àgbà, Jésù, nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní ọ̀run.
Ọwọ́ Wọn Dí Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀
11. Pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tí a wẹ̀ mọ́ nípasẹ̀ ẹbọ Jésù, kí ni àwọn ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn míràn ń ṣe tayọ̀tayọ̀?
11 Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Hébérù, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ìníyelórí gíga lọ́lá tí ẹbọ Jésù ní nínú ìṣètò májẹ̀mú tuntun ní ìfiwéra pẹ̀lú ti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ lábẹ́ májẹ̀mú láéláé. (Hébérù 9:13-15) Ẹbọ Jésù tí ó dára jù lè “wẹ ẹ̀rí ọkàn wa mọ́ kúrò nínú àwọn òkú iṣẹ́ kí àwa lè ṣe iṣẹ́ ìsìn [ọlọ́wọ̀] fún Ọlọ́run alààyè.” Fún àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Hébérù, “àwọn òkú iṣẹ́” ní “ìrélànàkọjá lábẹ́ májẹ̀mú ti ìṣáájú” nínú. Fún àwọn Kristẹni lónìí, wọ́n kan àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti dá sẹ́yìn, tí wọ́n ti fi ìrònúpìwàdà tòótọ́ hàn lórí rẹ̀, tí Ọlọ́run sì ti dárí rẹ̀ jì wọ́n. (Kọ́ríńtì Kíní 6:9-11) Pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tí a wẹ̀ mọ́, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ń ṣe “iṣẹ́ ìsìn [ọlọ́wọ̀] fún Ọlọ́run alààyè.” Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá pẹ̀lú. Níwọ̀n bí a ti wẹ ẹ̀rí ọkàn wọn mọ́ nípasẹ̀ “ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” wọ́n wà nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí ti Ọlọ́run, “wọ́n . . . ń ṣe iṣẹ́ ìsìn [ọlọ́wọ̀] fún un tọ̀sán tòru.”—Ìṣípayá 7:14, 15.
12. Báwo ni a ṣe ń lè fi hàn pé a ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìgbàgbọ́”?
12 Ní àfikún sí i, Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a wá pẹ̀lú ọkàn àyà tòótọ́ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìgbàgbọ́, níwọ̀n bí a ti wẹ ọkàn-àyà wa mọ́ kúrò nínú ẹ̀rí-ọkàn burúkú tí a sì ti fi omi tí ó mọ́ wẹ ara wa.” (Hébérù 10:22) Báwo ni a ṣe lè fi hàn pé a ní “ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdánilójú ìgbàgbọ́”? Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni tí ó jẹ́ Hébérù pé: “Ẹ jẹ́ kí a di ìpolongo ìrètí wa [ti ọ̀run] ní gbangba mú ṣinṣin láìmikàn, nítorí olùṣòtítọ́ ni ẹni tí ó ṣèlérí. Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kíní kejì láti ru ara wa lọ́kàn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kíní kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ̀yin ti rí ọjọ́ náà tí ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:23-25) Bí ìgbàgbọ́ wa bá wà láàyè, àwa pẹ̀lú kì yóò “máa ṣá ìpéjọpọ̀ ara wa tì.” Inú wa yóò dùn láti ru àwọn ará wa sókè, kí àwọn náà sì ru wá sókè sí ìfẹ́ àti sí iṣẹ́ àtàtà, kí a sì fún wa lókun fún iṣẹ́ pàtàkì ti pípolongo ìrètí wa ní gbangba, yálà ó jẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé tàbí ti òkè ọ̀run.—Jòhánù 13:35.
“Májẹ̀mú Àìnípẹ̀kun”
13, 14. Ní àwọn ọ̀nà wo ni májẹ̀mú tuntun gbà jẹ́ àìnípẹ̀kun?
13 Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn tí ó kẹ́yìn nínú àwọn 144,000 bá gba ìrètí wọn ti ọ̀run? Májẹ̀mú tuntun náà yóò ha dẹ́kun ṣíṣiṣẹ́ bí? Ní àkókò yẹn, kì yóò sí mẹ́ńbà èyíkéyìí tí ó ṣẹ́ kù nínú Ísírẹ́lì Ọlọ́run mọ́ lórí ilẹ̀ ayé. Gbogbo àwọn olùkópa nínú májẹ̀mú náà yóò ti wà pẹ̀lú Jésù “nínú ìjọba Bàbá [rẹ̀].” (Mátíù 26:29) Ṣùgbọ́n a rántí ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn Hébérù pé: “Ọlọ́run àlàáfíà . . . gbé olùṣọ́ àgùntàn ńlá ti àwọn àgùntàn dìde kúrò nínú òkú pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú àìnípẹ̀kun.” (Hébérù 13:20; Aísáyà 55:3) Ọ̀nà wo ni májẹ̀mú tuntun náà gbà jẹ́ àìnípẹ̀kun?
14 Lákọ̀ọ́kọ́, láìdàbí májẹ̀mú Òfin náà, a kò lè fi òmíràn rọ́pò rẹ̀. Èkejì, ìyọrísí iṣẹ́ rẹ̀ wà pẹ́ títí, àní bí ọ̀ràn ipò ọba Jésù ti wà pẹ́ títí. (Fi Lúùkù 1:33 wéra pẹ̀lú Kọ́ríńtì Kíní 15:27, 28.) Ìjọba ọ̀run ní àyè ayérayé nínú ète Jèhófà. (Ìṣípayá 22:5) Ẹ̀kẹta ni pé, àwọn àgùntàn míràn yóò máa jàǹfààní nìṣó láti inú ìṣètò májẹ̀mú tuntun náà. Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, àwọn ẹ̀dá ènìyàn olùṣòtítọ́ yóò máa bá a nìṣó ‘ní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Jèhófà tọ̀sán tòru nínú tẹ́ńpìlì rẹ̀,’ gan-an gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń ṣe nísinsìnyí. Jèhófà kì yóò mú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn àtẹ̀yìnwá tí a ti dárí rẹ̀ jì wọ́n lórí ìpìlẹ̀ “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” Jésù pa dà wá sí ìrántí mọ́. Wọn yóò máa bá a lọ láti gbádùn ìdúró òdodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Jèhófà, òfin rẹ̀ yóò sì wà ní ọkàn àyà wọn síbẹ̀.
15. Ṣàpèjúwe ipò ìbátan tí yóò wà láàárín Jèhófà àti àwọn olùjọsìn rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé nínú ayé tuntun.
15 Jèhófà yóò ha lè sọ nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn wọ̀nyí nígbà náà pé: ‘Èmi ni Ọlọ́run wọn, àwọn sì ni ènìyàn mi’ bí? Bẹ́ẹ̀ ni. “Òun yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn.” (Ìṣípayá 21:3) Wọn yóò di “ibùdó àwọn ẹni mímọ́,” aṣojú ti ilẹ̀ ayé fún “ìlú ńlá olùfẹ́ ọ̀wọ́n,” ìyàwó òkè ọ̀run ti Jésù Kristi. (Ìṣípayá 14:1; 20:9; 21:2) Gbogbo èyí yóò ṣeé ṣe nítorí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” Jésù tí a ta sílẹ̀ àti ìtẹríba tí wọ́n ní fún àwọn ọba àti àlùfáà ti ọ̀run, tí wọ́n jẹ́ Ísírẹ́lì Ọlọ́run nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣípayá 5:10.
16. (a) Kí ni ó ṣeé ṣe kí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a bá jí dìde sórí ilẹ̀ ayé? (b) Àwọn ìbùkún wo ni yóò wá ní òpin ẹgbẹ̀rún ọdún náà?
16 Àwọn òkú tí a jí dìde sórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? (Jòhánù 5:28, 29) A óò ké sí àwọn pẹ̀lú láti “bù kún ara wọn” nípasẹ̀ Jésù, Irú Ọmọ Ábúráhámù. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18, NW) Wọn yóò tún ní láti nífẹ̀ẹ́ orúkọ Jèhófà, ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún un, ní rírú ẹbọ tí ó ṣètẹ́wọ́gbà, àti ní ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ nínú ilé àdúrà rẹ̀. Àwọn tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò wọnú ìsinmi Ọlọ́run. (Aísáyà 56:6, 7) Nígbà tí ẹgbẹ̀rún ọdún náà yóò bá fi dópin, a óò ti mú gbogbo àwọn olùṣòtítọ́ wá sí ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn nípasẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù Kristi àti ti àwọn 144,000 àlùfáà ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Wọn yóò jẹ́ olódodo, kì í ṣe pé a óò wulẹ̀ polongo wọn ní olódodo gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Wọn yóò “wá sí ìyè,” ní bíbọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí a ti jogún láti ọ̀dọ̀ Ádámù pátápátá. (Ìṣípayá 20:5; 22:2) Ìbùkún ńlá ni èyí yóò mà jẹ́ o! Láti inú ojú ìwòye wa lónìí, ó dà bíi pé iṣẹ́ àlùfáà ti Jésù àti ti àwọn 144,000 yóò ti parí nígbà náà. Àwọn ìbùkún Ọjọ́ Ètùtù gíga jù náà yóò ti ṣiṣẹ́ ní kíkún. Ní àfikún sí i, Jésù yóò “fi ìjọba náà lé Ọlọ́run àti Bàbá rẹ̀ lọ́wọ́.” (Kọ́ríńtì Kíní 15:24) Ìdánwò ìkẹyìn yóò wà fún aráyé, lẹ́yìn náà, a óò pa Sátánì àti àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ run títí láé.—Ìṣípayá 20:7, 10.
17. Lójú ìwòye ayọ̀ tí ń dúró dè wá, kí ni ó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pinnu láti ṣe?
17 Bí ó bá tilẹ̀ wà rárá, ipa wo ni “májẹ̀mú àìnípẹ̀kun” náà yóò kó nínú sànmánì alárinrin tí yóò bẹ̀rẹ̀ nígbà náà? Ìyẹn kì í ṣe tiwa láti sọ. Ìwọ̀nba ohun tí Jèhófà ti ṣí payá ti tó fún wa fún ìsinsìnyí. Ó múni wárìrì tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀. Rò ó wò ná—ìyè àìnípẹ̀kun gẹ́gẹ́ bí apá kan “àwọn ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun”! (Pétérù Kejì 3:13) Ǹjẹ́ kí ohunkóhun má ṣe mú ìfẹ́ ọkàn wa rẹ̀wẹ̀sì láti jogún ìlérí náà. Dídúró gbọn-in lè má rọrùn. Pọ́ọ̀lù wí pé: “Ẹ nílò ìfaradà, kí ó baà lè jẹ́ pé, lẹ́yìn tí ẹ ti ṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run tán, kí ẹ lè rí ìmúṣẹ ìlérí náà gbà.” (Hébérù 10:36) Ṣùgbọ́n, rántí pé ìṣòro èyíkéyìí tí a lè ní láti ṣẹ́pá, àtakò èyíkéyìí tí a lè ní láti borí, kò tó nǹkan kan bí a bá fi wé ayọ̀ tí ń dúró dè wá. (Kọ́ríńtì Kejì 4:17) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wa má ṣe jẹ́ “irú àwọn tí ń fà sẹ́yìn sí ìparun.” Kàkà bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kí a lè fi ẹ̀rí hàn pé a jẹ́ “irú àwọn tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ fún fífi ààbò pa ọkàn mọ́ láàyè.” (Hébérù 10:39) Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pátá ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Jèhófà, Ọlọ́run májẹ̀mú, sí ìbùkún ayérayé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, orí 13, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.
Ìwọ Ha Lóye Rẹ̀ Bí?
◻ Yàtọ̀ sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, àwọn wo ni a tún ń bù kún nípasẹ̀ Irú Ọmọ Ábúráhámù?
◻ Ní rírí ìbùkún gbà nípasẹ̀ májẹ̀mú tuntun, báwo ni àwọn àgùntàn míràn ṣe dà bí àwọn aláwọ̀ṣe lábẹ́ májẹ̀mú láéláé?
◻ Báwo ni a ṣe bù kún àwọn àgùntàn míràn nípasẹ̀ ìṣètò Ọjọ́ Ètùtù gíga jù?
◻ Èé ṣe tí Pọ́ọ̀lù fi pe májẹ̀mú tuntun ni “májẹ̀mú àìnípẹ̀kun”?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́wọ̀ Nínú Tẹ́ńpìlì
Ogunlọ́gọ̀ ńlá ń jọ́sìn pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nínú àgbàlá ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:14, 15; 11:2) Kò sí ìdí kankan láti parí èrò pé wọ́n wà nínú Àgbàlá kan tí ó yàtọ̀, tí ó jẹ́ ti àwọn Kèfèrí. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, Àgbàlá àwọn Kèfèrí wà nínú tẹ́ńpìlì. Ṣùgbọ́n, nínú àwòrán tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì àti ti Ìsíkẹ́ẹ̀lì tí ó ní ìmísí Ọlọ́run, kò sí ìpèsè fún Àgbàlá àwọn Kèfèrí. Nínú tẹ́ńpìlì Sólómọ́nì, àgbàlá kan wà lẹ́yìn òde níbi tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti àwọn aláwọ̀ṣe, lọ́kùnrin lóbìnrin, ti jọ́sìn papọ̀. Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ alásọtẹ́lẹ̀ fún àgbàlá orí ilẹ̀ ayé ti tẹ́ńpìlì nípa tẹ̀mí, níbi tí Jòhánù ti rí ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀.
Ṣùgbọ́n, kìkì àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì nìkan ni ó lè wọnú àgbàlá inú lọ́hùn-ún, níbi tí pẹpẹ ńlá wà; kìkì àwọn àlùfáà nìkan ni ó lè wọ Ibi Mímọ́; àlùfáà àgbà nìkan ni ó sì lè wọ Ibi Mímọ́ Jù Lọ. A lóye àgbàlá inú lọ́hùn-ún àti Ibi Mímọ́ sí ibi tí ó ń ṣàpẹẹrẹ ipò tẹ̀mí ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró lórí ilẹ̀ ayé. Ibi Mímọ́ Jù Lọ sì ń ṣàpẹẹrẹ ọ̀run gan-an, níbi tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ti gba ìyè àìleèkú pẹ̀lú Àlùfáà Àgbà wọn ti ọ̀run.—Hébérù 10:19, 20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Lójú ìwòye ayọ̀ tí ń dúró dè wá, ẹ jẹ́ kí a “ní ìgbàgbọ́ fún fífi ààbò pa ọkàn mọ́ láàyè”