Jèhófà, Ọlọ́run Tí “Ó Múra Àtidáríjì”
“Ìwọ, Olúwa, o ṣeun, o sì múra àtidáríjì.”—ORIN DÁFÍDÌ 86:5.
1. Ẹrù ìnira wíwọnilọ́rùn wo ni Ọba Dáfídì rù, báwo sì ni ó ṣe rí ìtùnú fún ọkàn àyà rẹ̀ tí ìdààmú bá?
ỌBA DÁFÍDÌ ti Ísírẹ́lì ìgbàanì mọ bí ẹrù ìnira ẹ̀bi ẹ̀rí ọkàn ti wúwo tó. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi borí mi mọ́lẹ̀, bí ẹrù wúwo, ó wúwo jù fún mi. Ara mi hù, ó sì kan bà jẹ́; èmi ti ń kérora nítorí àìsinmi àyà mi.” (Orin Dáfídì 38:4, 8) Ṣùgbọ́n, Dáfídì rí ìtùnú fún ọkàn àyà rẹ̀ tí ìdààmú bá. Ó mọ̀ pé bí Jèhófà tilẹ̀ kórìíra ẹ̀ṣẹ̀, kò kórìíra ẹlẹ́ṣẹ̀ náà—bí onítọ̀hún bá ronú pìwà dà ní tòótọ́, tí ó sì kọ ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀. (Orin Dáfídì 32:5; 103:3) Pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún nínú ìmúratán Jèhófà láti nawọ́ àánú sí àwọn tí ó bá ronú pìwà dà, Dáfídì wí pé: “Ìwọ, Olúwa, o ṣeun, o sì múra àtidáríjì.”—Orin Dáfídì 86:5.
2, 3. (a) Nígbà tí a bá dẹ́ṣẹ̀, ẹrù ìnira wo ni a lè rù gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, èé sì ti ṣe tí èyí fi ń ṣàǹfààní? (b) Ewu wo ni ó wà nínú jíjẹ́ kí ìmọ̀lára ẹ̀bi ‘gbéni mì’? (d) Ìdálójú wo ni Bíbélì fún wa nípa ìmúratán Jèhófà láti dárí jì?
2 Nígbà tí a bá dẹ́ṣẹ̀, ó lè yọrí sí pé kí àwa pẹ̀lú ru ẹrù ìnira wíwọnilọ́rùn ti ẹ̀rí ọkàn tí ń mú ìrora báni. Ìmọ̀lára ẹ̀dùn ẹ̀ṣẹ̀ yí jẹ́ ìwà ẹ̀dá, ó sì ń ṣeni láǹfààní pàápàá. Ó lè sún wa láti gbé ìgbésẹ̀ yíyẹ láti ṣàtúnṣe àwọn àṣìṣe wa. Ṣùgbọ́n, ìmọ̀lára ẹ̀bi ti bo àwọn Kristẹni kan mọ́lẹ̀. Ọkàn àyà wọn tí ń dá wọn lẹ́bi lè rin kinkin mọ́ ọn pé bí ó ti wù kí wọ́n ronú pìwà dà tó, Ọlọ́run kò ní dárí jì wọ́n pátápátá. Nígbà tí ó rántí àṣìṣe kan tí ó ṣe, arábìnrin kan sọ pé: “Ó jẹ́ ìmọ̀lára búburú jáì láti ronú pé Jèhófà kò nífẹ̀ẹ́ rẹ mọ́.” Àní lẹ́yìn ìgbà tí ó ronú pìwà dà, tí ó sì tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn tí ń ranni lọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà ìjọ, ó ṣì ń nímọ̀lára pé òun kò yẹ fún ìdáríjì Ọlọ́run. Ó ṣàlàyé pé: “Ọjọ́ kan kò lè kọjá kí n má tọrọ ìdáríjì lọ́wọ́ Jèhófà.” Bí ìmọ̀lára ẹ̀bi ‘bá gbé wa mì,’ Sátánì lè gbìyànjú láti mú kí a juwọ́ sílẹ̀, kí a nímọ̀lára pé a kò yẹ ni ẹni tí ń sin Jèhófà.—Kọ́ríńtì Kejì 2:5-7, 11.
3 Ṣùgbọ́n kì í ṣe ojú tí Jèhófà fi ń wo ọ̀ràn nìyẹn rárá! Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un dá wa lójú pé nígbà tí a bá fi ojúlówó ìrònúpìwàdà àtọkànwá hàn, Jèhófà ṣe tán, àní ó múra tán pàápàá láti dárí jì wá. (Òwe 28:13) Nítorí náà, bí o kò bá tí ì fìgbà kan rò pé o lè rí ìdáríjì Ọlọ́run, ó lè jẹ́ pé òye kíkún sí i nípa ìdí tí ó fi ń dárí jì àti bí ó ṣe ń dárí jì ni ohun tí o nílò.
Èé Ṣe Tí Jèhófà fi “Múra Àtidáríjì”?
4. Kí ni Jèhófà ń rántí nípa ẹ̀dá wa, báwo sì ni èyí ṣe ń nípa lórí bí ó ṣe ń bá wa lò?
4 A kà pé: “Bí ìlà oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀ oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni ó mú ìrékọjá wa jìnnà kúrò lọ́dọ̀ wa. Bí bàbá ti í ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” Èé ṣe tí Jèhófà fi máa ń fẹ́ láti fi àánú hàn? Ẹsẹ tí ó tẹ̀ lé e dáhùn pé: “Nítorí tí ó mọ ẹ̀dá wa; ó rántí pé erùpẹ̀ ni wá.” (Orin Dáfídì 103:12-14) Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà kì í gbàgbé pé ẹ̀dá erùpẹ̀, tí ó ní àìlera, tàbí ìkù-díẹ̀-káàtó ni wá, gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí àìpé. Gbólóhùn náà pé ó mọ “ẹ̀dá wa” rán wa létí pé Bíbélì fi Jèhófà wé amọ̀kòkò, tí ó sì fi wá wé ìkòkò tí ó mọ.a (Jeremáyà 18:2-6) Amọ̀kòkò máa ń di ohun èlò amọ̀ tí ó mọ mú pinpin síbẹ̀ yóò dì í mú bí ohun ẹlẹgẹ́, kò jẹ́ gbàgbé irú ohun tí ó jẹ́. Bákan náà pẹ̀lú, Jèhófà, Atóbilọ́lá Amọ̀kòkò, ń bá wa lò lọ́nà tí ó bá àìlera ìwà ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ wa mu.—Fi wé Kọ́ríńtì Kejì 4:7.
5. Báwo ni ìwé Róòmù ṣe ṣàpèjúwe bí ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ ṣe lágbára tó lórí ẹran ara àìpé wa?
5 Jèhófà mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti lágbára tó. Ìwé Mímọ́ ṣàpèjúwe ẹ̀ṣẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ipá lílágbára tí ènìyàn wà nínú ìwàmú rẹ̀ tí ń ṣekú pani. Báwo tilẹ̀ ni ìwàmú ẹ̀ṣẹ̀ yí ti lágbára tó? Nínú ìwé Róòmù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí a mí sí ṣàlàyé èyí lọ́nà ṣíṣe kedere: A wà “lábẹ́ ẹ̀ṣẹ̀,” gẹ́gẹ́ bí àwọn sójà ṣe wà lábẹ́ ọ̀gágun wọn (Róòmù 3:9); ó “ti ṣàkóso” lórí aráyé gẹ́gẹ́ bí ọba (Róòmù 5:21); ó “ń gbé” inú wa (Róòmù 7:17, 20); “òfin” rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ nínú wa láìdáwọ́ dúró, ìyẹn ni pé, ó ń gbìyànjú láti ṣàkóso ọ̀nà wa. (Róòmù 7:23, 25) Ẹ wo irú ìjàkadì nínira tí a ní láti jà kí a baà lè dènà agbára ńlá tí ẹ̀ṣẹ̀ ní lórí ẹran ara àìpé wa!—Róòmù 7:21, 24.
6. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tí ń fi ọkàn àyà onírònúpìwàdà wá àánú rẹ̀?
6 Nítorí náà, Ọlọ́run wa aláàánú mọ̀ pé bí ó ti wù kí a fẹ́ ṣègbọràn sí i tó láti inú ọkàn àyà wa, kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe é lọ́nà pípé pérépéré. (Àwọn Ọba Kìíní 8:46) Ó mú un dá wa lójú tìfẹ́tìfẹ́ pé bí a bá fi ọkàn àyà onírònúpìwàdà wá àánú bíi-ti-bàbá tí òun ní, òun yóò nawọ́ ìdáríjì sí wa. Onísáàmù náà, Dáfídì, wí pé: “Ẹbọ Ọlọ́run ni ìròbìnújẹ́ ọkàn: ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà, Ọlọ́run, òun ni ìwọ kì yóò gàn.” (Orin Dáfídì 51:17) Láéláé, Jèhófà kì yóò kọ ọkàn àyà kan tí ìmọ̀lára ẹ̀bi ti mú ìbànújẹ́ bá, tí ó sì ti fa ìrora fún. Ẹ wo bí ìyẹn ti ṣàpèjúwe lọ́nà rere tó nípa bí Jèhófà ti múra tán láti dárí jì!
7. Èé ṣe tí a kò fi lè gùn lé àánú Ọlọ́run?
7 Ṣùgbọ́n, èyí ha túmọ̀ sí pé a lè gùn lé àánú Ọlọ́run, ní fífi ipò ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ wa kẹ́wọ́ láti dẹ́ṣẹ̀? Rárá o! Jèhófà kì í jẹ́ kí ìmọ̀lára lásán darí òun. Àánú rẹ̀ ní ààlà. Lọ́nàkọnà, òun kì yóò dárí ji àwọn tí ń forí kunkun sọ ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, oníjàǹbá dàṣà, láìronú pìwà dà. (Hébérù 10:26-31) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí ó bá rí ọkàn àyà kan tí ó ní “ìròbìnújẹ́ àti ìrora,” ó “múra àtidáríjì.” (Òwe 17:3) Ẹ jẹ́ kí a gbé díẹ̀ yẹ̀ wò nínú àwọn ọ̀rọ̀ akúnfúntumọ̀ tí a lò nínú Bíbélì láti ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run ti ń dárí jini pátápátá porogodo tó.
Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dárí Jini Pátápátá Porogodo Tó?
8. Ní ti gidi, kí ni Jèhófà ń ṣe, nígbà tí ó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ipa wo sì ni ó yẹ kí èyí ní lórí wa?
8 Ọba Dáfídì tí ó ronú pìwà dà wí pé: “Èmi jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi fún ọ, àti ẹ̀ṣẹ̀ mi ni èmi kò sì fi pa mọ́. Èmi wí pé, èmi óò jẹ́wọ́ ìrékọjá mi fún Olúwa: ìwọ sì dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” (Orin Dáfídì 32:5) Gbólóhùn ọ̀rọ̀ náà ‘dárí jì’ tú ọ̀rọ̀ Hébérù tí ó túmọ̀ sí “gbé dìde,” “gbé, rù,” ní pàtàkì. Ìlò rẹ̀ níhìn-ín dúró fún ‘láti mú ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀, ìrékọjá kúrò.’ Nítorí náà Jèhófà gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì dìde, ó sì rù wọ́n lọ, kí a sọ ọ́ lọ́nà bẹ́ẹ̀. (Fi wé Léfítíkù 16:20-22.) Kò sí iyè méjì pé èyí dín ìmọ̀lára ẹ̀bi tí Dáfídì ti ń rù kiri kù. (Fi wé Orin Dáfídì 32:3.) Àwa pẹ̀lú lè ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Ọlọ́run tí ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn tí ń wá ìdáríjì rẹ̀ lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi. (Mátíù 20:28; fi wé Aísáyà 53:12.) Nípa báyìí, àwọn tí Jèhófà gbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn dìde, tí ó sì rù wọ́n lọ kò ní láti máa ru ẹrù ìnira ìmọ̀lára ẹ̀bi fún ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti kọjá kiri mọ́.
9. Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù náà: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá”?
9 Jésù lo ipò ìbátan awínni àti ajigbèsè láti ṣàkàwé bí Jèhófà ṣe ń dárí jì. Fún àpẹẹrẹ, Jésù rọ̀ wá láti gbàdúrà pé: “Dárí àwọn gbèsè wa jì wá.” (Mátíù 6:12) Jésù tipa báyìí fi “ẹ̀ṣẹ̀” wé “gbèsè.” (Lúùkù 11:4) Nígbà tí a bá dẹ́ṣẹ̀, a di “ajigbèsè” lọ́dọ̀ Jèhófà. Ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì náà tí a tú sí “dárí jì” lè túmọ̀ sí “láti yááfì gbèsè kan, láti gbàgbé rẹ̀, nípa ṣíṣàìbéèrè rẹ̀ mọ́.” Lọ́nà kan, nígbà tí Jèhófà bá dárí jini, ó ń fagi lé gbèsè tí à bá kà sí wa lọ́rùn. Nípa báyìí, àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó ronú pìwà dà lè rí ìtùnú. Jèhófà kì yóò sìn wá ní gbèsè kan tí ó ti fagi lé mọ́ láé!—Orin Dáfídì 32:1, 2; fi wé Mátíù 18:23-35.
10, 11. (a) Àwòrán wo ni àpólà ọ̀rọ̀ náà ‘di èyí tí a pa rẹ́,’ tí ó wà nínú Ìṣe 3:19 gbé wá sọ́kàn? (b) Báwo ni a ṣe ṣàkàwé bí Jèhófà ti ń dárí jini pátápátá porogodo tó?
10 Nínú Ìṣe 3:19, Bíbélì lo àkànlò èdè ayàwòrán mìíràn tí ó ṣe kedere láti ṣàpèjúwe bí Ọlọ́run ṣe ń dárí jini: “Nítorí náà, ẹ ronú pìwà dà kí ẹ sì yí pa dà kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” Àpólà ọ̀rọ̀ náà ‘kí a pa rẹ́’ tú ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì yẹn, tí ó lè túmọ̀ sí “láti nu nǹkan nù, láti mú nǹkan kúrò lọ́kàn, láti fagi lé nǹkan tàbí pa nǹkan run,” bí a bá lò ó gẹ́gẹ́ bí àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ti sọ, èrò tí ó fi hàn ni ti pípa nǹkan àfọwọ́kọ rẹ́. Báwo ni èyí ṣe ṣeé ṣe? Àpòpọ̀ èédú, oje igi, àti omi ni a fi ṣe tàdáwà tí a sábà máa ń lò nígbà àtijọ́. Kété lẹ́yìn tí ẹnì kan bá ti fi irú tàdáwà bẹ́ẹ̀ kọ nǹkan, ó lè fi kànìnkànìn tí ó ti rẹ sínú omi pa ohun tí ó kọ náà rẹ́.
11 Èyí jẹ́ àpèjúwe nípa bí Jèhófà ti ń dárí jini pátápátá porogodo tó. Nígbà tí ó bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì, ṣe ni ó dà bíi pé ó mú kànìnkànìn, tí ó sì fi nù wọ́n nù. Kò yẹ kí a bẹ̀rù pé yóò ka irú ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ sí wa lọ́rùn ní ọjọ́ ọ̀la, nítorí Bíbélì ṣí ohun mìíràn tí ó kàmàmà payá nípa àánú Jèhófà: Nígbà tí ó bá ń dárí jì, ó máa ń gbàgbé rẹ̀!
“Èmi Kì Yóò . . . Rántí Ẹ̀ṣẹ̀ Wọn Mọ́”
12. Nígbà tí Bíbélì sọ pé Jèhófà dárí ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá, ó ha túmọ̀ sí pé wọn kò lè wá sí iyè rẹ̀ mọ́, èé sì ti ṣe tí o fi dáhùn bẹ́ẹ̀?
12 Nípasẹ̀ wòlíì Jeremáyà, Jèhófà ṣèlérí nípa àwọn tí ó wà nínú májẹ̀mú tuntun pé: “Èmi óò dárí àìṣedéédéé wọn jì, èmi kì yóò sì rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” (Jeremáyà 31:34) Èyí ha túmọ̀ sí pé nígbà tí Jèhófà bá dárí jì, ẹ̀ṣẹ̀ náà kò lè wá sí iyè rẹ̀ mọ́ bí? Ìyẹn kò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ rárá. Bíbélì sọ fún wa nípa ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn kan tí Jèhófà dárí jì, títí kan Dáfídì. (Sámúẹ́lì Kejì 11:1-17; 12:1-13) Ó hàn gbangba pé, Jèhófà ṣì rántí àwọn ìṣìnà wọn, ó sì yẹ kí àwa pẹ̀lú ṣe bẹ́ẹ̀. A pa àkọsílẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, àti ti ìrònúpìwàdà wọn àti bí Ọlọ́run ti dárí jì wọ́n, mọ́ fún àǹfààní wa. (Róòmù 15:4) Nígbà náà, kí ni Bíbélì ń sọ nígbà tí ó wí pé Jèhófà kì í “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí ó ti dárí jì?
13. (a) Kí ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà tí a tú sí “èmi . . . yóò rántí” ní nínú? (b) Nígbà tí Jèhófà sọ pé, “Èmi kì yóò rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́,” kí ni ó ń mú dá wa lójú?
13 Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Hébérù náà tí a tú sí “èmi . . . yóò rántí” kún ju wíwulẹ̀ rántí ohun àtẹ̀yìnwá lọ. Gẹ́gẹ́ bí ìwé Theological Wordbook of the Old Testament ti sọ, ó ní “ìtumọ̀ mìíràn ti gbígbé ìgbésẹ̀ yíyẹ,” nínú. Nítorí náà, lọ́nà yí, láti “rántí” ẹ̀ṣẹ̀ ní gbígbé ìgbésẹ̀ lòdì sí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ nínú. Nígbà tí wòlíì Hóséà sọ nípa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aṣetinú-ẹni pé, “Òun [Jèhófà] yóò rántí àìṣedéédéé wọn,” ohun tí wòlíì náà ní lọ́kàn ni pé Jèhófà yóò gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí wọn fún àìronúpìwàdà wọn. Nípa báyìí, ìyókù ẹsẹ náà fi kún un pé: “Yóò bẹ ẹ̀ṣẹ̀ wọn wò.” (Hóséà 9:9) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, nígbà tí Jèhófà sọ pé, “Èmi kì yóò rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́,” ó ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé tí òun bá ti lè dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà, òun kì yóò gbé ìgbésẹ̀ lòdì sí i mọ́ lẹ́yìnwá ọ̀la nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọnnì. (Ìsíkẹ́ẹ̀lì 18:21, 22) Nípa báyìí, ó gbàgbé ní ti pé òun kì í mú ẹ̀ṣẹ̀ wa wá sójútáyé lemọ́lemọ́ kí ó baà lè fẹ̀sùn kàn wá tàbí kí ó baà lè fìyà jẹ wá léraléra. Nípa báyìí, Jèhófà fi àpẹẹrẹ dídára lélẹ̀ fún wa láti tẹ̀ lé nínú ìbálò wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí èdè àìyedè bá ṣẹlẹ̀, kò dára láti wu àwọn àṣìṣe àtẹ̀yìnwá tí o ti gbà láti dárí rẹ̀ jini síta.
Àbájáde Rẹ̀ Ńkọ́?
14. Èé ṣe tí ìdáríjì kò fi túmọ̀ sí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà ti bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ọ̀nà àìtọ́ rẹ̀?
14 Mímúra tí Jèhófà múra tán láti dárí jì ha túmọ̀ sí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà ti bọ́ lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ọ̀nà àìtọ́ rẹ̀ bí? Rárá o. A kò lè dẹ́ṣẹ̀ láìjìyà rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun yòó wù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni òun yóò ká pẹ̀lú.” (Gálátíà 6:7) A lè dojú kọ àwọn àbájáde kan tí ó jẹ́ ti ìgbésẹ̀ tàbí ìṣòro wa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí ó bá ti nawọ́ ìdáríjì sí wa, Jèhófà kì í mú ìpọ́njú bá wa. Nígbà tí ìdààmú bá dé, kò yẹ kí Kristẹni kan rò pé, ‘Ó ṣeé ṣé kí ó jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ mi àtẹ̀yìnwá ni Jèhófà ń fìyà rẹ̀ jẹ mí.’ (Fi wé Jákọ́bù 1:13.) Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, Jèhófà kì í gbà wá lọ́wọ́ gbogbo àbájáde ìwà àìtọ́ wa. Ìkọ̀sílẹ̀, oyún tí a kò fẹ́, àrùn tí ìbálòpọ̀ ń tàtaré rẹ̀, dídí ẹni tí a kò gbẹ́kẹ̀ lé tàbí tí a kò bọ̀wọ̀ fún mọ́—gbogbo ìwọ̀nyí lè jẹ́ àbájáde bíbaninínújẹ́ ti ẹ̀ṣẹ̀, Jèhófà kì yóò sì ràdọ̀ bò wá lọ́wọ́ wọn. Rántí pé bí ó tilẹ̀ dárí ji Dáfídì fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ní ti Bátí-ṣébà àti Ùráyà, Jèhófà kò ràdọ̀ bo Dáfídì lọ́wọ́ àbájáde oníjàǹbá tí ó tẹ̀ lé e.—Sámúẹ́lì Kejì 12:9-14.
15, 16. Báwo ni òfin tí a kọ sínú Léfítíkù 6:1-7 ṣe ṣàǹfààní fún ẹni tí a jí nǹkan rẹ̀ àti oníláìfí náà?
15 Ẹ̀ṣẹ̀ wa lè ní àwọn àbájáde mìíràn pẹ̀lú. Fún àpẹẹrẹ, gbé àkọsílẹ̀ Léfítíkù orí 6 yẹ̀ wò. Níhìn-ín, Òfin Mósè sọ nípa ipò tí ẹnì kan ti dẹ́ṣẹ̀ búburú jáì nípa fífi ipá gba ẹrù ọmọ Ísírẹ́lì ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan nípa jíjà á lólè, lílọ́ ọ lọ́wọ́ gbà, tàbí lílù ú ní jìbìtì. Tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà sì sẹ́ pé òun kò jẹ̀bi, àní tí ó láyà tó bẹ́ẹ̀ láti búra èké. Ọ̀ràn tí kò ní ẹlẹ́rìí ní èyí tí a n sọ nípa rẹ̀. Ṣùgbọ́n, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ẹ̀rí ọkàn oníláìfí náà dà á láàmú, tí ó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kí Ọlọ́run lè dárí jì í, ó ní láti ṣe ohun mẹ́ta mìíràn: kí ó dá ohun tí ó mú pa dà, kí ó san owó ìtanràn tí ó jẹ́ ìpín 20 nínú ọgọ́rùn-ún iye owó ohun tí ó mú fún oní-ǹ-kan, kí ó sì fi àgbò kan rúbọ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀bi. Lẹ́yìn náà, òfin náà wí pé: “Àlùfáà yóò sì ṣètùtù fún un níwájú OLÚWA, a óò sì dárí rẹ̀ jì í.”—Léfítíkù 6:1-7; fi wé Mátíù 5:23, 24.
16 Òfin yìí jẹ́ ìpèsè aláàánú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó ṣàǹfààní fún ẹni tí a jí nǹkan rẹ̀, tí a dá ẹrù rẹ̀ pa dà, tí kò sì sí iyè méjì pé ará tù ú nígbà tí oníláìfí náà gbà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé òun dẹ́ṣẹ̀. Lọ́wọ́ kan náà, òfin náà ṣàǹfààní fún ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ sún un nígbẹ̀yìngbẹ́yín láti tẹ́wọ́ gba ẹ̀bi rẹ̀, kí ó sì ṣàtúnṣe ìwà àìtọ́ rẹ̀. Ní tòótọ́, bí ó ba ti kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, kò ní sí ìdáríjì fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.
17. Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá pa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn lára, kí ni Jèhófà ń retí pé kí a ṣe?
17 Bí a kò tilẹ̀ sí lábẹ́ Òfin Mósè, ó fún wa ní ìjìnlẹ̀ òye ṣíṣeyebíye sínú èrò inú Jèhófà, títí kan ìrònú rẹ̀ lórí ìdáríjì. (Kólósè 2:13, 14) Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá pa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn lára tàbí tí ó pọ́n wọn lójú, inú Jèhófà yóò dùn nígbà tí a bá ṣe ohun tí a lè ṣe láti ‘ṣàtúnṣe àìtọ́ náà.’ (Kọ́ríńtì Kejì 7:11) Èyí kan gbígbà pé a dẹ́ṣẹ̀, pé a jẹ̀bi, kí a tún tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ẹni tí a ṣẹ̀. Nígbà náà a lè bẹ Jèhófà lórí ìpìlẹ̀ ẹbọ Jésù, kí a sì ní ìtura ẹ̀rí ọkàn mímọ́ àti ìdálójú pé Ọlọ́run ti dárí jì wá.—Hébérù 10:21, 22.
18. Ìbáwí wo ni ó lè bá ìdáríjì Jèhófà rìn?
18 Gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́ èyíkéyìí, Jèhófà lè dárí jì wá, kí ó sì bá wa wí. (Òwe 3:11, 12) Ó lè pọn dandan fún Kristẹni kan tí ó ronú pìwà dà láti pàdánù sísìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tàbí aṣáájú ọ̀nà. Ó lè dùn ún láti pàdánù àwọn àǹfààní tí ó ṣeyebíye fún un fún àkókò kan. Ṣùgbọ́n, irú ìbáwí bẹ́ẹ̀ kò túmọ̀ sí pé ó ti pàdánù ojú rere Jèhófà tàbí pé Jèhófà ti fawọ́ ìdáríjì rẹ̀ sẹ́yìn. Ní àfikún sí i, a gbọ́dọ̀ rántí pé ìbáwí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà jẹ́ ẹ̀rí ìfẹ́ rẹ̀ sí wa. Títẹ́wọ́gbà á àti fífi í sílò jẹ́ fún ire wa dídára jù lọ, ó sì lè sìn wá lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Hébérù 12:5-11.
19, 20. (a) Bí o bá ti hùwà àìtọ́, èé ṣe tí o kò fi ní láti nímọ̀lára pé àánú Jèhófà kò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ? (b) Kí ni a óò jíròrò nínu àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e?
19 Ẹ wo bí ó ti tuni lára tó láti mọ̀ pé a ń sin Ọlọ́run tí ó “múra àtidáríjì”! Jèhófà ń wò ré kọjá ẹ̀ṣẹ̀ àti àṣìṣe wa. (Orin Dáfídì 130:3, 4) Ó mọ ohun tí ó wà ní ọkàn àyà wa. Bí o bá nímọ̀lára pé ọkàn àyà rẹ kún fún ìròbìnújẹ́ àti ìrora nítorí àwọn ìwà àìtọ́ àtẹ̀yìnwá, má ṣe parí èrò sí pé àánú Jèhófà kò lè dé ọ̀dọ̀ rẹ láé. Àṣìṣe yòó wù tí ì báà jẹ́, bí o bá ti ronú pìwà dà ní tòótọ́, tí o ti gbé ìgbésẹ̀ láti ṣàtúnṣe lórí ìwà àìtọ́ náà, tí o sì gbàdúrà tọkàntọkàn fún ìdáríjì Jèhófà lórí ìpìlẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù tí a ta sílẹ̀, o lè ní ìgbọ́kànlé kíkún pé ọ̀rọ̀ Jòhánù Kíní 1:9 yóò ṣẹ sí ọ lára: “Bí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, òun jẹ́ aṣeégbíyèlé àti olódodo tí yóò fi dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá tí yóò sì wẹ̀ wá mọ́ kúrò nínú gbogbo àìṣòdodo.”
20 Bíbélì rọ̀ wá láti fara wé bí Jèhófà ti ń dárí jini nínú ìbálò wa pẹ̀lú ẹnì kíní kejì. Ṣùgbọ́n, dé àyè wo ni a lè retí pé kí a dárí ji àwọn ẹlòmíràn, kí a sì gbàgbé rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣẹ̀ wá? Èyí ni a óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tí ó tẹ̀ lé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó dùn mọ́ni pé, ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí a tú sí “ẹ̀dá wa” ni a lò fún ohun èlò àfamọ̀ṣe tí amọ̀kòkò mọ.—Aísáyà 29:16.
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Èé ṣe tí Jèhófà fi “múra àtidáríjì”?
◻ Báwo ni Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe bí Jèhófà ti ń dárí jini pátápátá porogodo tó?
◻ Nígbà tí Jèhófà bá dárí jini, lọ́nà wo ni ó fi máa ń gbàgbé rẹ̀?
◻ Kí ni Jèhófà ń retí kí a ṣe nígbà tí ẹ̀sẹ̀ wa bá pa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn lára?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ wa bá pa ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn lára, Jèhófà ń retí pé kí a ṣàtúnṣe