Bárúkù Akọ̀wé Jeremáyà Tó Dúró Tì Í Gbágbáágbá
ǸJẸ́ o mọ “Bárúkù ọmọkùnrin Neráyà”? (Jeremáyà 36:4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orí mẹ́rin nínú Bíbélì ló sọ̀rọ̀ nípa Bárúkù, àwọn tó ń ka Bíbélì mọ̀ ọ́n dáadáa, wọ́n mọ̀ pé akọ̀wé wòlíì Jeremáyà ni, ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ sì ni wọ́n. Àwọn méjèèjì jọ wà ní Júdà ni ní gbogbo ọdún méjìdínlógún oníhílàhílo tó gbẹ̀yìn ìjọba Júdà, wọ́n sì rí bí àwọn ará Bábílónì ṣe pa Jerúsálẹ́mù run pátápátá lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni àti bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe sá lọ sí Íjíbítì lẹ́yìn náà.
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, wọ́n ṣàwárí àwọn èdìdì amọ̀a méjì tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ kan sí lára, tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ohun tí wọ́n kọ sára rẹ̀ ni: “Èyí Jẹ́ Ti Berekhyahu [ìyẹn orúkọ Bárúkù lédè Hébérù], ọmọ Neriyahu [ìyẹn orúkọ Neráyà lédè Hébérù], tí í ṣe Akọ̀wé.” Àwárí yìí jẹ́ káwọn ọ̀mọ̀wé máa ronú gan-an nípa Bárúkù tí Bíbélì mẹ́nu kàn yìí. Ta ni Bárúkù? Ìdílé wo ni wọ́n bí i sí, báwo ló ṣe kàwé tó, kí sì ni ipò rẹ̀ láwùjọ? Kí ni dídúró tí Bárúkù dúró gbágbáágbá ti Jeremáyà fi hàn nípa Bárúkù? Ẹ̀kọ́ wo la lè kọ́ lára rẹ̀? Ká lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ohun tí Bíbélì àtàwọn ìwé ìtàn sọ nípa rẹ̀.
Ìdílé Tó Ti Wá àti Ipò Rẹ̀ Láwùjọ
Lónìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé ló sọ pé inú ìdílé tó gbajúmọ̀ kan nílẹ̀ Júdà tí ìran wọn jẹ́ akọ̀wé ni wọ́n bí Bárúkù sí. Wọ́n sì sọ onírúurú nǹkan tó mú kí wọ́n sọ bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fi orúkọ oyè pàtàkì kan pe Bárúkù, ìyẹn ní “akọ̀wé.” Ìwé Mímọ́ tún sọ pé èèyàn pàtàkì kan ni Seráyà arákùnrin rẹ̀ láàfin Sedekáyà Ọba.—Jeremáyà 36:32; 51:59.
Awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ Philip J. King kọ̀wé nípa àwọn akọ̀wé tó wà nígbà ayé Jeremáyà, ó ní: “Sàràkí èèyàn láwùjọ làwọn akọ̀wé tí wọ́n wà nílẹ̀ Júdà ní apá ìparí ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni àti apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni . . . Àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ló máa ń ṣe akọ̀wé.”
Yàtọ̀ síyẹn, ìtàn tó wà nínú Jeremáyà orí kẹrìndínlógójì tá a máa gbé yẹ̀ wò kínníkínní fi hàn pé Bárúkù láǹfààní láti lọ máa rí àwọn tó ń gba ọba nímọ̀ràn, ó sì tún láǹfààní láti máa wọ yàrá ìjẹun tàbí yàrá ìpàdé tó jẹ́ ti Gemaráyà. Ọmọọba tàbí ìjòyè pàtàkì kan sì ni Gemaráyà yìí jẹ́. Ọ̀mọ̀wé James Muilenberg tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí, ó ní: “Bárúkù lè wọnú yàrá ìjẹun àwọn akọ̀wé torí pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti wọbẹ̀, ó sì wà lára àwọn ìjòyè tí wọ́n pé jọ nígbà ayẹyẹ pàtàkì tí wọ́n ti ka àkájọ ìwé náà ní gbangba. Ó wà lára àwọn lọ́gàálọ́gàá.”
Síwájú sí i, ìwé kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Corpus of West Semitic Stamp Seals tún fi hàn pé akọ̀wé ni Bárúkù, ó ní: “Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ibi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èdìdì amọ̀ àwọn lọ́gàálọ́gàá kan wà ni wọ́n ti rí èdìdì amọ̀ Berekhyahu, ó bọ́gbọ́n mu láti sọ pé irú ipò gíga táwọn lọ́gàálọ́gàá wọ̀nyẹn wà náà ni Bárúkù, tàbí Berekhyahu wà.” Àwọn ẹ̀rí tá a rí yìí fi hàn pé àfàìmọ̀ ni ò jẹ́ pé Bárúkù àti Seráyà arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ ọba ni wọ́n ṣètìlẹyìn fún Jeremáyà wòlíì olóòótọ́ láwọn ọdún tí onírúurú ìṣẹ̀lẹ̀ kíkàmàmà ń ṣẹlẹ̀ kí Jerúsálẹ́mù tó pa run.
Ó Ṣàtìlẹ́yìn fún Jeremáyà ní Gbangba
Tá a bá ní ká to ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Bárúkù lẹ́sẹẹsẹ nínú Bíbélì, inú ìwé Jeremáyà orí kẹrìndínlógójì ni orúkọ rẹ̀ ti máa kọ́kọ́ yọ, èyí sì jẹ́ ní “ọdún kẹrin Jèhóákímù,” tó jẹ́ nǹkan bí ọdún 625 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Lákòókò yẹn, Jeremáyà ti ṣiṣẹ́ wòlíì fún ọdún mẹ́tàlélógún.—Jeremáyà 25:1-3; 36:1, 4.
Jèhófà wá sọ fún Jeremáyà pé: “Mú àkájọ ìwé kan fún ara rẹ, kí o sì kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ti bá ọ sọ lòdì sí Ísírẹ́lì àti lòdì sí Júdà àti lòdì sí gbogbo orílẹ̀-èdè, . . . láti ọjọ́ Jòsáyà, títí di òní yìí sínú rẹ̀.” Bíbélì tún sọ pé: “Jeremáyà sì tẹ̀ síwájú láti pe Bárúkù ọmọkùnrin Neráyà, kí Bárúkù lè kọ̀wé láti ẹnu Jeremáyà gbogbo ọ̀rọ̀ Jèhófà tí Ó ti sọ fún un.”—Jeremáyà 36:2-4.
Kí nìdí tí Jeremáyà fi pe Bárúkù? Jeremáyà sọ fún un pé: “A ti sé mi mọ́. Èmi kò lè wọ ilé Jèhófà.” (Jeremáyà 36:5) Ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ti pàṣẹ pé Jeremáyà ò gbọ́dọ̀ dé apá ibi tí wọ́n ti máa ka ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi rán an nínú tẹ́ńpìlì, bóyá nítorí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà fi rán Jeremáyà tẹ́lẹ̀ bí àwọn aláṣẹ nínú. (Jeremáyà 26:1-9) Láìsí àní-àní, Bárúkù jẹ́ ẹni tó ń fi tọkàntọkàn sin Jèhófà, ó “sì tẹ̀ síwájú láti ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jeremáyà wòlíì ti pa láṣẹ fún un.”—Jeremáyà 36:8.
Àkókò gígùn ló gba Bárúkù láti kọ ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ tí wòlíì Ọlọ́run ti ń sọ bọ̀ láti ohun tó lé ní ọdún mẹ́tàlélógún, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni Jeremáyà ń wá àkókò tó dáa láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́ nígbà tó di oṣù November tàbí December ọdún 624 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, tìgboyàtìgboyà ni Bárúkù “bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ọ̀rọ̀ Jeremáyà sókè láti inú ìwé náà ní ilé Jèhófà, ní yàrá ìjẹun Gemaráyà . . . , ní etí gbogbo àwọn ènìyàn náà.”—Jeremáyà 36:8-10.
Mikáyà ọmọkùnrin Gemaráyà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún bàbá rẹ̀ àtàwọn ọmọ aládé tí wọ́n pé jọ, wọ́n sì pe Bárúkù pé kó padà wá ka ohun tó wà nínú àkájọ ìwé náà sétígbọ̀ọ́ wọn. Bíbélì sọ pé: “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé gbàrà tí wọ́n gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ náà, wọ́n wo ara wọn tìbẹ̀rùbojo-tìbẹ̀rùbojo; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí wí fún Bárúkù pé: ‘Láìkùnà, àwa yóò sọ gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún ọba. . . . Lọ, fi ara rẹ pa mọ́, ìwọ àti Jeremáyà, tí ẹnì kankan kò fi ní mọ ibi tí ẹ wà.’”—Jeremáyà 36:11-19.
Nígbà tí Jèhóákímù Ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà ní kí Bárúkù kọ sílẹ̀, ó fìbínú fa àkájọ ìwé náà ya, ó sọ ọ́ sínú iná, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ pé kí wọ́n lọ mú Jeremáyà àti Bárúkù wá. Àmọ́ Jèhófà tún ní kí wọ́n kọ àkájọ ìwé mìíràn níbi táwọn méjèèjì fara pa mọ́ sí.—Jeremáyà 36:21-32.
Láìsí àní-àní, Bárúkù mọ̀ pé ewu ń bẹ nínú iṣẹ́ tí òun gbà yìí. Ó dájú pé yóò ti mọ bí wọ́n ṣe fẹ́ pa Jeremáyà láwọn ọdún díẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn. Bákan náà, yóò ti gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Úríjà, ẹni tó sàsọtẹ́lẹ̀ “ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀rọ̀ Jeremáyà” ṣùgbọ́n tí Jèhóákímù Ọba pa. Síbẹ̀, Bárúkù múra tán láti lo ìmọ̀ àti òye rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé àti àǹfààní mímọ̀ tó mọ àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba láti fi ran Jeremáyà lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ yìí.—Jeremáyà 26:1-9, 20-24.
Má Ṣe Wá “Àwọn Ohun Ńláńlá”
Ìgbà kan wà tí ìbànújẹ́ bá Bárúkù lákòókò tó ń kọ àkájọ ìwé àkọ́kọ́. Ó sọ pé: “Mo gbé wàyí, nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ibi ìsinmi kankan.” Kí ló mú kí ìbànújẹ́ bá Bárúkù?—Jeremáyà 45:1-3.
Bíbélì kò sọ ní pàtó. Ṣùgbọ́n, ìwọ náà gbìyànjú láti fojú inú wo ipò tí Bárúkù wà. Bó ṣe ń ṣàkọsílẹ̀ ìkìlọ̀ tí Jèhófà ti ń fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì àti Júdà láti ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn á ti jẹ́ kó rí i kedere bí àwọn èèyàn náà ṣe fi ìjọsìn Jèhófà sílẹ̀ àti bí wọ́n ṣe kọ Jèhófà sílẹ̀. Bí Jèhófà sì ṣe sọ pé òun máa pa Jerúsálẹ́mù àti Júdà run, tí òun yóò sì jẹ́ káwọn ará Bábílónì kó àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè náà lọ sígbèkùn fún àádọ́rin ọdún yóò ti kó ìbànújẹ́ bá a. Ọdún tí Bárúkù kọ àkájọ ìwé àkọ́kọ́ yẹn ni Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ yẹn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà yẹn náà ni Bárúkù kọ ọ́ sínú àkájọ ìwé náà. (Jeremáyà 25:1-11) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ohun mìíràn tó tún lè kó ìbànújẹ́ bá a ni pé, bó ṣe dúró ti Jeremáyà gbágbáágbá nígbà tí gbogbo nǹkan le koko yìí lè jẹ́ kí wọ́n yọ ọ́ kúrò nípò tó wà kí iṣẹ́ sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.
Èyí ó wù kó jẹ́, Jèhófà fúnra rẹ̀ bá Bárúkù sọ̀rọ̀ kó lè fi ìdájọ́ Ọlọ́run tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sọ́kàn. Jèhófà ní: “Ohun ti mo kọ́ ni èmi yóò ya lulẹ̀, ohun tí mo sì gbìn ni èmi yóò fà tu, àní gbogbo ilẹ̀ náà.” Ó wá gba Bárúkù lámọ̀ràn pé: “Ṣùgbọ́n ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.”—Jeremáyà 45:4, 5.
Jèhófà kò sọ ohun tí “àwọn ohun ńláńlá” wọ̀nyí jẹ́, àmọ́ Bárúkù yóò mọ̀ lọ́kàn ara rẹ̀ bóyá ipò ọlá lòun ń lépa tàbí òun fẹ́ di gbajúmọ̀ tàbí ọlọ́rọ̀. Jèhófà gbà á nímọ̀ràn pé kó má hùwà òmùgọ̀, kó má sì gbàgbé ìparun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara, . . . èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.” Ohun tó ṣeyebíye jù lọ fún Bárúkù ni ẹ̀mí rẹ̀, èyí sì ni ohun tí Ọlọ́run máa pa mọ́ níbikíbi tí ì báà lọ.—Jeremáyà 45:5.
Lẹ́yìn tí gbogbo àwọn ohun tó wà nínú orí kẹrìndínlógójì àti orí karùnlélógójì nínú ìwé Jeremáyà yìí ṣẹlẹ̀, èyí tó wáyé látọdún 625 sí 624 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Bíbélì ò sọ ohunkóhun mọ́ nípa Bárúkù títí di nǹkan bí oṣù mélòó kan ṣáájú kí àwọn ará Bábílónì tó pa Jerúsálẹ́mù àti Júdà run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn?
Bárúkù Tún Dúró Ti Jeremáyà
Ìgbà táwọn ará Bábílónì gbógun ti Jerúsálẹ́mù ni orúkọ Bárúkù tún yọ nínú Bíbélì. Nígbà tí Jeremáyà “wà lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,” Jèhófà sọ fún Jeremáyà pé kó ra ilẹ̀ ìbátan rẹ̀ kan tó wà ní Ánátótì, èyí tó jẹ́ àmì pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò padà sí ilẹ̀ wọn. Wọ́n pe Bárúkù pé kó wá bá wọn ṣe ìwé ilẹ̀ náà.—Jeremáyà 32:1, 2, 6, 7.
Jeremáyà ṣàlàyé pé: “Mo kọ ìwé àdéhùn, mo sì fi èdìdì sí i, mo sì gba àwọn ẹlẹ́rìí bí mo ti ń wọn owó náà lórí òṣùwọ̀n. Lẹ́yìn náà, mo mú ìwé àdéhùn ọjà rírà, èyí tí a fi èdìdì dì . . . àti èyí tí a ṣí sílẹ̀; mo sì wá fi ìwé àdéhùn ọjà rírà náà fún Bárúkù.” Jeremáyà wá pàṣẹ fún Bárúkù pé kó tọ́jú àwọn ìwé àdéhùn ọjà rírà náà sínú ohun èlò amọ̀. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé nígbà tí Jeremáyà sọ pé òun “kọ” ìwé àdéhùn ọjà rírà náà, ohun tó ní lọ́kàn ni pé òun ń sọ ohun tí Bárúkù ọ̀jáfáfá akọ̀wé máa kọ síwèé fún un.—Jeremáyà 32:10-14; 36:4, 17, 18; 45:1.
Bárúkù àti Jeremáyà tẹ̀ lé òfin tí wọ́n máa ń lò láyé ìgbà yẹn. Lára ohun tí wọ́n máa ń ṣe ni pé wọ́n máa ń ṣe ìwé àdéhùn ọjà rírà méjì. Ìwé Corpus of West Semitic Stamp Seals ṣàlàyé pé: “Ìdí tí wọ́n fi pe ìwé àdéhùn àkọ́kọ́ ní ìwé àdéhùn tí a ‘fi èdìdì dì’ ni pé ńṣe ni wọ́n á ká a tí wọ́n á sì fi èdìdì amọ̀ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ dì í; òun gan-an ló jẹ́ ojúlówó. . . . Ìwé àdéhùn kejì, ìyẹn ‘èyí tá a ṣí sílẹ̀’ jẹ́ ẹ̀dà ti àkọ́kọ́ tí wọ́n fi èdìdì dì, tó jẹ́ àdéhùn tí a kò lè yí padà, ohun tí èkejì yìí sì wà fún ni pé, wọ́n lè máa yẹ̀ ẹ́ wò látìgbàdégbà. Nípa báyìí, ìwé méjì ló wà, ojúlówó àti ẹ̀dà, tí wọ́n kọ sórí òrépèté méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.” Àwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ti ṣàwárí ti jẹ́rìí sí i pé àṣà àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn ni pé kí wọ́n máa tọ́jú àwọn ìwé àkọsílẹ̀ méjèèjì náà sínú ìkòkò amọ̀.
Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù, wọ́n finá sun ún, wọ́n sì kó gbogbo èèyàn ibẹ̀ lọ sígbèkùn, àyàfi àwọn tálákà díẹ̀ ni wọ́n fi sílẹ̀ sẹ́yìn. Nebukadinésárì fi Gedaláyà ṣe gómìnà, ṣùgbọ́n oṣù méjì péré lẹ́yìn náà làwọn Júù pa á. Gbogbo àwọn Júù yòókù bá pinnu pé àwọn yóò lọ sí Íjíbítì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jeremáyà ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé Jèhófà ní kí wọ́n má lọ. Ìgbà tí Bíbélì ń sọ ìtàn nǹkan wọ̀nyí ló tún mẹ́nu kan Bárúkù.—Jeremáyà 39:2, 8; 40:5; 41:1, 2; 42:13-17.
Àwọn olórí àwọn Júù sọ fún Jeremáyà pé: “Èké ni ìwọ ń sọ. Jèhófà Ọlọ́run wa kò rán ọ, pé, ‘Má ṣe wọ Íjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀.’ Ṣùgbọ́n Bárúkù ọmọkùnrin Neráyà ń dẹ ọ́ sí wa fún ète àtifi wá lé àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, láti fi ikú pa wá tàbí láti mú wa lọ ní ìgbèkùn sí Bábílónì.” (Jeremáyà 43:2, 3) Ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Jeremáyà yìí fi hàn pé ó jọ pé àwọn olórí àwọn Júù gbà gbọ́ pé Bárúkù gan-an ló ń ti Jeremáyà. Ṣé ohun tí wọ́n rò ni pé, nítorí ipò tí Bárúkù wà tàbí nítorí pé òun àti Jeremáyà ti ń ṣọ̀rẹ́ bọ̀ tipẹ́, Bárúkù kì í wulẹ̀ ṣe akọ̀wé fún wòlíì Jeremáyà mọ́? Ó kúkú lè jẹ́ bẹ́ẹ̀, àmọ́ ohunkóhun tí wọn ì báà rò, ohun kan tó dájú ni pé àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni ọ̀rọ̀ ìkìlọ̀ náà ti wá.
Pẹ̀lú gbogbo ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run fún àwọn Júù tó kù nílẹ̀ Júdà, wọ́n ṣì kúrò níbẹ̀, wọ́n sì mú “Jeremáyà wòlíì àti Bárúkù ọmọkùnrin Neráyà” dání pẹ̀lú wọn. Jeremáyà kọ̀wé pé: “Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, wọ́n wá sí ilẹ̀ Íjíbítì, nítorí wọn kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà; ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ wọ́n wá dé Tápánẹ́sì,” ìlú kan tó wà nítòsí ààlà Íjíbítì àti ilẹ̀ Sínáì, ní apá ìlà oòrùn odò Náílì. Látorí ìtàn yìí síwájú ni Bíbélì ò ti mẹ́nu kan Bárúkù mọ́.—Jeremáyà 43:5-7.
Kí La Lè Rí Kọ́ Lára Bárúkù?
Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ pàtàkì la lè rí kọ́ lára Bárúkù. Ẹ̀kọ́ kan tó ṣe pàtàkì gidigidi ni pé tinútinú ló fi lo ìmọ̀ àti òye tó ní nínú iṣẹ́ akọ̀wé àti àǹfààní mímọ̀ tó mọ àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn láti fi mú kí iṣẹ́ ìsìn Jèhófà tẹ̀ síwájú, láìbẹ̀rù ohun tí èyí lè yọrí sí. Bákan náà lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́kùnrin lóbìnrin ló fìwà jọ Bárúkù, tí àwọn náà ń lo ìmọ̀ àti òye wọn nínú iṣẹ́ ìsìn ní Bẹ́tẹ́lì, nínú iṣẹ́ ìkọ́lé àti nínú irú àwọn nǹkan míì bẹ́ẹ̀. Báwo ni ìwọ náà ṣe lè fìwà jọ Bárúkù?
Nígbà tí Jèhófà ní kí Jeremáyà sọ fún Bárúkù pé ìgbà yẹn kọ́ ló yẹ kó máa kó “àwọn ohun ńláńlá” jọ ní àwọn ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìjọba Júdà, kò sí àní-àní pé ó ṣègbọràn, nítorí pé Jèhófà dá ẹ̀mí rẹ̀ sí. Á dára káwa náà tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí o, torí pé àwọn ọjọ́ tó kẹ́yìn ètò àwọn nǹkan yìí la wà. Bí Jèhófà ṣe ṣèlérí fún Bárúkù pé òun máa dá ẹ̀mí rẹ̀ sí ló ṣe ṣèlérí pé òun máa dá ẹ̀mí tiwa náà sí. Bíi ti Bárúkù, ǹjẹ́ kò yẹ ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run?
Ẹ̀kọ́ kan tún wà tá a lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí. Nígbà tí Jeremáyà ra ilẹ̀ lọ́wọ́ ọmọ arákùnrin bàbá rẹ̀ kan, Bárúkù ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bá wọn ṣèwé ilẹ̀, àní bó tilẹ̀ jẹ́ pé mọ̀lẹ́bí làwọn tí ọ̀rọ̀ owó dà pọ́ yìí. Ó yẹ káwọn Kristẹni tí ọ̀rọ̀ owó bá da àwọn àtàwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wọn nípa tẹ̀mí pọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ yìí. Bá a bá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ yìí, tí àwa náà ń ṣèwé àdéhùn nígbà tí ọ̀rọ̀ owó bá da àwa àti ẹlòmíràn pọ̀, ohun tó bá Ìwé Mímọ́ mu, tó bọ́gbọ́n mu, tó sì fi ìfẹ́ hàn la ṣe yẹn.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì ò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Bárúkù, ó yẹ kí gbogbo àwa Kristẹni lóde òní tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Ṣé wàá tẹ̀ lé àpẹẹrẹ akọ̀wé Jeremáyà tó dúró tì í gbágbáágbá yìí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ohun tó ń jẹ́ èdìdì amọ̀ ni amọ̀ tútù tí wọ́n máa ń lẹ̀ mọ́ okùn tí wọ́n fi di ìwé pàtàkì kan. Wọ́n máa ń fi òǹtẹ̀ tí orúkọ ẹni tó ni ìwé náà tàbí ẹni tó fi ránṣẹ́ wà lára rẹ̀ lu amọ̀ náà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Èdìdì amọ̀ Bárúkù
[Credit Line]
Èdìdì amọ̀: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Israel Museum, Jerusalem